Wíwo Ayé
Àrùn AIDS àti Éṣíà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ní àrùn AIDS ti ń dín kù ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn, ńṣe ni àjàkálẹ̀ àrùn náà ń pọ̀ sí i ní ibi púpọ̀ ní Éṣíà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Asiaweek ti sọ, iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà ní Íńdíà “fi ìgbà 71 pọ̀ sí i ní apá ìlàjì àkọ́kọ́ ti àwọn ọdún 1990.” Thailand, tí iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà ní 1990 fi sí ipò kẹtàdínlọ́gọ́ta, wà ní ipò karùn-ún nígbà tí ó di àárín àwọn ọdún 1990. Cambodia gbéra láti ipò kẹtàléláàádọ́sàn-án lọ sí ipò kọkàndínlọ́gọ́ta. Philippines sì ní ìbísí ìpín 131 lórí ọgọ́rùn-ún ní àkókò kan náà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ pé òwò bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tí ń gbilẹ̀ nínú mélòó kan lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ń fa èyí lápá kan, ṣùgbọ́n ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé, àwọn òṣèlú kan tí àwọn orílẹ̀-èdè wọn “gbára lé dọ́là tí wọ́n ń pa lọ́dọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ gan-an . . . ń lọ́ra láti gbé ìgbésẹ̀ gúnmọ́” lòdì sí i.
Àwọn Èèwọ̀ Ara ní Germany
Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung sọ pé ìwádìí kan tí Àjọ Ètò Ìbánigbófò Ìlera ti Ìjọba Àpapọ̀ fún Àwọn Ilé Iṣẹ́ ní Germany tẹ̀ jáde ti fi hàn pé ọmọ ilẹ̀ Germany kan nínú 4 tó ti lé ní ọmọ ọdún 14 ní èèwọ̀ ara. Irú èèwọ̀ ara tó wọ́pọ̀ jù lọ ni àsín-ìnsíntán, tí ń bá nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà ènìyàn jà níbẹ̀. Nǹkan bíi mílíọ̀nù 2.3 ni oòrùn ń yọ lẹ́nu, àwọn tí iye wọn sì lé ní mílíọ̀nù 2 ni wọ́n ní èèwọ̀ ara fún irun ẹranko. Àwọn tí ń lo oògùn lára àwọn tí wọ́n ní èèwọ̀ ara lé ní ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún, ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn sì sọ pé, àwọn àmì àrùn náà ń ṣèdíwọ́ gan-an fún ìgbòkègbodò ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àwọn. Ìwádìí náà tún fi hàn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe irú “àwọn òwò àti àwọn iṣẹ́ àmọ̀dunjú kan, bí àwọn aṣebúrẹ́dì, àwọn tí ń fi ègé pákó ṣe ọnà, àwọn nọ́ọ̀sì, àti àwọn dókítà, ni wọ́n wà nínú ewu èèwọ̀ ara jù.”
Fọ Ọwọ́ Rẹ!
Ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera ti Ítálì sọ pé: “Fífọ ọwọ́ rẹ ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ, tí ó rọrùn jù lọ, tí kò sì náni lówó jù lọ láti ṣèdíwọ́ fún títan ọ̀pọ̀ àrùn kálẹ̀.” Síbẹ̀, “ó lé ní 3 lára àwọn ará Ítálì 10 tí kì í fọ ọwọ́ wọn bí wọ́n bá yàgbẹ́ tàbí tọ̀, kódà bí wọ́n yóò bá jẹun lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ṣe tán.” Àbájáde ìwádìí yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú àbájáde àwọn irú ìwádìí náà tí a ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Onímọ̀ nípa ohun alààyè tín-tìn-tín náà, Enrico Magliano, ṣàlàyé pé: “Ọwọ́ lè gbé kòkòrò àrùn dénú oúnjẹ, kí ó sì mú kí àrùn náà gbèèràn.” Báwo ni a ṣe lè ṣèdíwọ́ fún ìgbèèràn náà? Fi ọṣẹ àti omi gbígbóná tàbí omi lílọ́wọ́ọ́rọ́ fọ ọwọ́ rẹ—àti abẹ́ èékánná pẹ̀lú—ó kéré tán, fún 30 ìṣẹ́jú àáyá (àkókò kíkéré jù lọ tí a nílò láti pa bakitéríà). Èyí ní nínú, fífi ọwọ́ wẹ ara wọn fún ìṣẹ́jú àáyá 10 sí 15. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, ṣàn wọ́n, kí o sì nù wọ́n dáadáa, bẹ̀rẹ̀ láti apá títí dé ọmọ ìka rẹ.
Ìfìyàjẹ-Ọmọdé àti Ìgbékalẹ̀ Ìdènà Àrùn
Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì Mie ní Japan ti sọ, bí a bá ń fìyà jẹ ọmọdé kan fún ìgbà pípẹ́, agbára ìdènà àrùn rẹ̀ yóò máa jagọ̀, èyí yóò sì mú kí àrùn lè tètè kọ lu ọmọ náà. Yunifásítì náà lo òkú àwọn 50 ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín oṣù kan sí ọdún mẹ́sàn-án, tí ìṣẹ̀jẹ̀ ọpọlọ tàbí àwọn ohun mìíràn tí ìlunibolẹ̀ ń fà pa, nínú ìwádìí náà. Ìwé agbéròyìnjáde Mainichi Daily News náà sọ pé, ẹṣẹ́ lymph àwọn ọmọdé náà, “tí ń darí ìṣiṣẹ́ agbára ìdènà àrùn, ti sún kì di ìdajì ìwọ̀n rẹ̀ gidi.” Bí ìfìyàjẹni náà bá ṣe pẹ́ tó ni ìsúnkì náà yóò ṣe pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ṣe sọ, ní ti gidi, “ẹṣẹ́ ọmọdé kan tí a ti fìyà jẹ fún àkókò tí ó ju oṣù mẹ́fà lọ tẹ̀wọ̀n ìdá mẹ́rìndínlógún ti ọmọ tí a kò fìyà jẹ.” Àwọn olùṣèwádìí ti rí irú ìsúnkì ẹṣẹ́ kan náà nínú àwọn ọmọdé tí wọ́n ti jìyà ìdààmú ọpọlọ tàbí àìjẹunrekánú látàrí ìkùnà àwọn òbí láti pèsè oúnjẹ fún wọn.
Ohun Tó So China àti Mesopotámíà Pọ̀
Tipẹ́tipẹ́ ni a ti ń ronú pé ọ̀làjú ilẹ̀ China àtayébáyé pilẹ̀ ṣẹ̀ ní Àfonífojì Hwang He ní China, tí kò ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú ipa òde kankan. Lẹ́yìn àwárí kan tí a walẹ̀ kàn láìpẹ́ yìí, a ti wá ń ṣiyè méjì nípa àlàyé yìí. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà, Courrier International, ròyìn pé, àwùjọ àwọn awalẹ̀pìtàn kan ti hú àwọn àmì ohun tí ó jọ tẹ́ńpìlì àtayébáyé kan tí a kọ́ sáàárín ibì kan tí a mọ ògiri yí ká lórí ilẹ̀ kan nítòsí Ch’eng-tu, ní Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Szechwan ní China. Àwọn awalẹ̀pìtàn náà ròyìn pé, ìgbékalẹ̀ àti ìrísí tẹ́ńpìlì náà ń ránni létí àwọn ilé ìṣọ́ orí tẹ́ńpìlì Mesopotámíà ìgbàanì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ichiro Kominami, láti Yunifásítì Kyoto, sọ pé, “ó ṣeé ṣe kí [Szechwan] jẹ́ orírun ọ̀làjú aláìlẹ́gbẹ́ ti China ìgbàanì tí ó ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ti Indu àti Mesopotámíà.”
Àwọn Tí Àrùn Mẹ́dọ̀wú Ìpele B Ń Pa
Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú díwọ̀n pé ó lé ní mílíọ̀nù kan ènìyàn tí àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele B ń pa lọ́dọọdún. Olùtọ́jú àrùn ọmọdé náà, Jagdish Chinnappa, sọ pé, Íńdíà ló ti ń pa iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 150,000 lára àwọn tí ó ń pa náà. Ìwé agbéròyìnjáde The Times of India sọ pé, ní ìpàdé àpérò kan tí ilé iṣẹ́ apòògùn kan tí ó ní ẹ̀ka ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kan ṣètò, ó ṣàlàyé pé ní Íńdíà, “àwọn tí wọ́n ní àrùn HBV [fáírọ́ọ̀sì àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele B] tó mílíọ̀nù 35 sí 40 mílíọ̀nù tí ó jẹ́ ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n ní in lágbàáyé.” Ìwé agbéròyìnjáde náà fi kún un pé, “ìṣẹ̀lẹ̀ ẹyọ kan lára méjì àrùn ẹ̀dọ̀ki tí ó ti di bárakú àti ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́jọ nínú mẹ́wàá àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀ki tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni àrùn Mẹ́dọ̀wú Ìpele B ń fà.”
Sísọ Afẹ́fẹ́ Di Eléèérí Nínú Ilé
Ìwádìí kan tí Àjọ Tata Tí Ń Ṣèwádìí Nípa Ohun Àmúṣagbára (TERI) ní New Delhi, Íńdíà, ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé, mílíọ̀nù 2.2 lára àwọn ará Íńdíà ni àwọn àrùn tí ó tan mọ́ ìbafẹ́fẹ́jẹ́ ń pa lọ́dọọdún. Ìwé agbéròyìnjáde The Indian Express sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí náà ti sọ, bíbafẹ́fẹ́jẹ́ nínú ilé ni lájorí okùnfà rẹ̀. Àwọn obìnrin tí ń gbé àwọn ilé elérò, tí wọ́n ń fi èédú, igi, àti ẹlẹ́bọ́tọ dáná wà nínú ewu tó pọ̀ jù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé ìgbésẹ̀ láti kápá bíbafẹ́fẹ́jẹ́ níta, àwọn ògbógi ronú pé a kò ṣe ohun tí ó pọ̀ tó láti dín ewu tí ń wu àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn nínú ilé wọn kù. Olùdarí àjọ TERI, R. K. Pachauri, sọ pé: “Ìṣòro fífarasin kan wà tí ó jọ pé kò sí ohun tí a lè ṣe sí i lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”
Ogun Omi
Wọ́n sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi nípa ìpèsè omi lọ́jọ́ iwájú níbi Àpéjọ Àgbáyé Nípa Omi, tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tó wáyé ní Marrakech, Morocco, ní March 1997. Ìsọdeléèérí, ọ̀gbẹlẹ̀, àti àpọ̀jù iye ènìyàn ń kó pákáǹleke tí kò dábọ̀ bá àwọn orísun ìpèsè omi. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Faransé náà, Le Monde, ti sọ, “àìní fún omi ń yára pọ̀ sí i ní ìlọ́po méjì ju bí àwọn olùgbé ayé ti ń pọ̀ sí i lọ.” Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Alásọtẹ́lẹ̀ Ojú Ọjọ́ Àgbáyé ti sọ, nígbà tí ó bá fi di ọdún 2025, ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn olùgbé ayé ni yóò máa gbé àwọn àgbègbè tí ìwọ̀n omi tí a ń pèsè kò ti ní kájú ìwọ̀n tí a nílò. Àyàfi tí a bá rí ojútùú tí ó lè mú nǹkan wà lọ́gbọọgba, àwọn aláṣẹ kan bẹ̀rù pé omi yóò jẹ́ okùnfà ogun ní ọ̀rúndún kọkànlélógún. Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde sọ pé, ní báyìí ná, “àjọ UN ti tọ́ka sí nǹkan bí 300 àgbègbè tí ìforígbárí ti lè ṣẹlẹ̀.”
Ìwà Ọ̀daràn Bíburú Jáì ní Venezuela
Ìwé agbéròyìnjáde El Universal sọ pé, pẹ̀lú 20,000,000 ènìyàn tí ń gbé Venezuela, ìpíndọ́gba nǹkan bí 400 ènìyàn ni wọ́n ń pa níbẹ̀ lóṣooṣù. Ìwádìí kan tí àjọ kan ṣe sọ pé, lájorí ohun tí ń mú kí ìwà ọ̀daràn máa pọ̀ sí i kì í ṣe ọ̀ràn ti ọrọ̀ ajé ṣùgbọ́n ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwùjọ. Lábẹ́ àkọlé náà, “Ipò Òṣì Kọ́ Ni Lájorí Okùnfà Ìyapòkíì,” ìwé ìròyìn náà sọ pé ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn náà, ìwà ipá tí ń ṣẹlẹ̀ ní Venezuela jẹ́ ìyọrísí àìsí ìlànà ìhùwà rere ẹ̀dá àti ẹ̀kọ́ ilé láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí. Láti ṣàtúnṣe ipò náà, àwọn ògbógi dámọ̀ràn kíkọ́ni ní ọ̀nà ìgbàtọ́mọ tí ó nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé, kí a sì fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti túbọ̀ máa ṣàníyàn nípa ìdílé.
Gbígbé Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Gbígbámúṣé Lárugẹ
Nínú ìtẹ̀jáde náà, World Health Report 1997, Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) kìlọ̀ pé ìran ènìyàn ń kojú “ìṣòro àìlera” tí ń pọ̀ sí i. Lọ́dọọdún, àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn àyà, àti àwọn àrùn bárakú, ń pa àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù 24, ó sì ń halẹ̀ láti sọ ìnira ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn mìíràn di púpọ̀. A retí pé iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn jẹjẹrẹ ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò di ìlọ́po méjì láàárín ọdún 25 tí ń bọ̀. Àrùn ọkàn àyà àti àrùn ẹ̀gbà, àwọn àrùn tí ń pa àwọn ènìyàn jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀, yóò wá wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀. Ní ìhùwàpadà sí àwọn ìṣeéṣe wọ̀nyí, àjọ WHO pè fún ìgbétásì “aláápọn tí ó wà pẹ́ títí” jákèjádò ayé láti gbé ìgbésí ayé gbígbámúṣé lárugẹ àti láti dín àwọn ohun tí ń ṣokùnfà ewu kù—oúnjẹ tí kò dára, sìgá mímu, ìsanra-jọ̀kọ̀tọ̀, àti àìṣeré-ìmárale—tí ó sábà máa ń yọrí sí àrùn tí ń ṣekú pani.