ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 3/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣìlò Oògùn Tí Dókítà Kọ Fúnni
  • Àwọn Òjìyà Ìpalára Tí Wọn Kò Mọwọmẹsẹ̀ ní Rwanda
  • Ìṣòro Ẹsẹ̀
  • Sísọ Ọjà Rírà Di Bárakú
  • “Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Àwọn Ọmọ Wẹẹrẹ Olùwo-Tẹlifíṣọ̀n”
  • Àwọn Obìnrin àti Ìṣekúpara-Ẹni
  • “Ọ̀gangan” Àrùn AIDS “Lágbàáyé”
  • Àwọn Ìfarapa Inú Eré Ìdárayá
  • Ṣọ́ra fún Bakitéríà E. Coli O157:H7
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 3/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àṣìlò Oògùn Tí Dókítà Kọ Fúnni

Ní ìpínlẹ̀ Victoria, Australia, ìwé agbéròyìnjáde ti Melbourne náà, Herald Sun, ròyìn pé, “àwọn ará Australia ń ná bílíọ̀nù 3 dọ́là lọ́dún sórí oògùn, wọ́n sì ti ń sọ àwọn oògùn apàrora tí a ń kọ fún wọn di bárakú.” Mínísítà ètò ìlera ní Victoria kìlọ̀ pé, “àṣìlò oògùn tí a kọ fúnni ti ń di ìṣòro tí àwọn ènìyàn kò fura sí, ó sì lè dà bí èròjà onímájèlé fún ìlera àti ọ̀nà ìgbésí ayé bí oògùn líle tí kò bófin mu ti jẹ́ gan-an.” Ó tún sọ àníyàn nípa ìròyìn pé àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ‘ń tọ onírúurú dókítà lọ’ nísinsìnyí láti gba àkànpọ̀ oògùn. Wọ́n máa ń tọ́jú àwọn tábúlẹ́ẹ̀tì kan, tí ó bá yá wọn óò lọ̀ ọ́, wọn óò sì fi abẹ́rẹ́ gún un sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, iye ìpín ọ̀rún àwọn ènìyàn tí ń lo àwọn oògùn apàrora fún ìdí tí kì í ṣe fún wíwo arùn sàn lọ́nà bíbófinmu, fò láti orí ìpín 3 nínú ọgọ́rùn-ún ní 1993 sí ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún ní 1995.

Àwọn Òjìyà Ìpalára Tí Wọn Kò Mọwọmẹsẹ̀ ní Rwanda

Nígbà ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ní Rwanda, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn obìnrin ni wọ́n fipá bá lò, wọ́n tilẹ̀ mú àwọn kan pa mọ́ bí ẹrú tí a ń lò fún ìbálòpọ̀. Nínú ọ̀ràn púpọ̀, àwọn afipábáni-lòpọ̀ náà máa ń jẹ́ àwọn ọkùnrin náà gan-an tí wọ́n pa ọkọ àwọn obìnrin náà àti àwọn ìbátan wọn lọ́nà ẹhànnà. Nǹkan bí ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n jìyà ìfipá-bánilòpọ̀ náà ní ń lóyún. Àwọn obìnrin kan yan ìṣẹ́yún tàbí pípa ọmọ ọwọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà yanjú ìṣòro wọn; àwọn mìíràn gbé àwọn ọmọ wọn jù sílẹ̀ tàbí kí wọ́n gbé wọn sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, síbẹ̀, “pẹ̀lú ìfojúdíwọ̀n àfìṣọ́raṣe, àwọn ọmọ tí a kò fẹ́ tí iye wọ́n jẹ́ láti 2,000 sí 5,000, ni wọ́n fipá bá àwọn ìyá wọn lò pọ̀ nígbà ogun abẹ́lé ní Rwanda.” Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn opó àti àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ti di ẹni tí a ta nù láwùjọ wọn. Ìwé agbéròyìnjáde Times náà sọ pé, “àwọn obìnrin púpọ̀ ni kò rọrùn fún láti rí ọkọ tuntun tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun.” Àwọn ìyá kan ń rí ìránnilétí ìtìjú wọn àti ikú burúkú tí a fi pa àwọn olólùfẹ́ wọn bí wọ́n ti ń rí àwọn ọmọ wọn látìgbàdégbà. Nítorí àwọn ìrántí aronilára wọ̀nyí, ó ṣòro fún àwọn ìyá kan láti fi ìfẹ́ni hàn sí àwọn ọmọ ọwọ́ wọn.

Ìṣòro Ẹsẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n tí Ẹ̀ka Ètò Ìlera ti Àjọ Àwọn Oníṣègùn Àpapọ̀ ní Germany ṣe ti fi hàn, ìdajì lára àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n ní ìṣòro ẹsẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Nassauische Neue Presse sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn kò bójú tó ẹsẹ̀ wọn tàbí wọ́n lò ó nílòkulò nípa wíwọ àwọn bàtà tí ó fún jù tàbí tí ó lè pa wọ́n lára.” Wíwọ àwọn bàtà gogoro tàbí èyí tí kò báni mú déédéé lè fa orúnkún ríro, ìgbáròkó ríro, tàbí ẹ̀yìn ríro. Àwọn àrùn tí olú ń fà, bíi káyùn-ún àti mycosis, pẹ̀lú ti ń ràn kálẹ̀ sí i. Ọ̀nà ìṣèdíwọ́ kan tí Àjọ Àwọn Oníṣègùn Àpapọ̀ dámọ̀ràn ni “fífọ gbogbo ọṣẹ tí ó bá wà láàárín ọmọ ìka kúrò kí a sì nù wọ́n.”

Sísọ Ọjà Rírà Di Bárakú

Ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times sọ pé, ní Ireland, rírajà láìrò ó wò “ni a ti mọ̀ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ohun bárakú, a sì fi sí àyè kan náà pẹ̀lú ìṣòro ọtí líle, oògùn líle, títa tẹ́tẹ́ àti ti oúnjẹ gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe tipátipá ti èrò ìmọ̀lára àti ti èrò orí tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ amọṣẹ́dunjú.” Àwọn tí ìpalára ìsúnniṣe yìí ń ṣẹlẹ̀ sí lè máa lo owó rẹpẹtẹ láti ra àwọn ohun tí wọn kò nílò. Ìròyìn náà ṣàlàyé pé: “Ìṣírí ráńpẹ́ tí ń wá láti inú lílọ ra aṣọ ń ta ìtúsílẹ̀ ásíìdì dopamine àti serotonin jí nínú ara, tí èyí yóò wá fa ìwúrí.” Ní ti ẹni tí ń rajà láìrò ó wò, bíi ti ajòògùnyó, ìmóríyá wá ń di ohun tí ó túbọ̀ ṣòro púpọ̀.

“Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Àwọn Ọmọ Wẹẹrẹ Olùwo-Tẹlifíṣọ̀n”

Ìwádìí kan tí a ṣe láàárín 21,000 ìdílé ní Ítálì ti fi hàn pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọdé ní Ítálì ni wọ́n dara dé tẹlifíṣọ̀n. Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica pe àfiyèsí sí pé, “ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọmọ wẹẹrẹ olùwo-tẹlifíṣọ̀n” ti sọ ọ́ di àṣà láti máa lo ìhùmọ̀ àfidarí tẹlifíṣọ̀n láti òkèèrè láti ìgbà tí wọ́n ti wà lọ́mọ ọdún kan. Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin lára àwọn ọmọdé ilẹ̀ Ítálì tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ta sí mẹ́wàá tí ń jókòó ti tẹlifíṣọ̀n, tí ó máa ń gbà wọ́n níyè ju wákàtí méjì ààbọ̀ lọ lójúmọ́. Àwọn ògbóǹkangí nínú iṣẹ́ ìtọ́jú ọpọlọ ń ṣàníyàn lórí òkodoro náà pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé tí wọ́n kéré tó oṣù mẹ́fà sí mẹ́jọ ti di akíyànyán olùwo-tẹlifíṣọ̀n.

Àwọn Obìnrin àti Ìṣekúpara-Ẹni

Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London, ròyìn pé: “Àwọn 4,500 ló ń ṣekú pa ara wọn ní Britain lọ́dọọdún: ìpíndọ́gba ọkùnrin márùn-ún sí obìnrin kan.” Àmọ́, iye àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n wà ní ọmọ ọdún 15 sí 24 tí ń ṣekú pa ara wọn ti pọ̀ sí i lọ́nà tí ó gbàfiyèsí ní ọdún mẹ́rin tó kọjá. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Southampton ṣàlàyé ọ̀kan lára ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó máa ṣokùnfà rẹ̀ pé: “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin ń fẹ́ láti pegedé lẹ́nu iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì tún di ẹrù pákáǹleke tí ó wà nínú bíbójútó ìdílé mọ́rí. Àwọn mọ́mì [ìyá] tí wọ́n wà ní ìpele kò-là-kò-ṣagbe ń gba àwọn abánitọ́mọ kí wọ́n baà lè máa gbé ẹrú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn. Nígbà tó bá yá, wọn óò máa banú jẹ́, wọn óò sì máa nímọ̀lára ẹ̀bi. Ìtẹ̀sí àdánidá ara wọn ń wí fún wọn láti máa ṣe mọ́mì, ọkàn wọn sì ń wí fún wọn láti lọ pawó wálé.” Ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbà gbọ́ pé ìtòjọ pelemọ gbogbo másùnmáwo àti pákáǹleke wọ̀nyí túbọ̀ lè máa ṣamọ̀nà sí ìṣekúpara-ẹni.

“Ọ̀gangan” Àrùn AIDS “Lágbàáyé”

Ìwádìí tuntun kan tí Yunifásítì Thames Valley, ní London, ṣe sọ pé, Íńdíà dà bí “ọkọ̀ ojú irin márosẹ̀ kan tí ń já lọ ṣòò lójú irin ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ síbi ìjàǹbá” ó sì yára ń di “ọ̀gangan ọ̀kan lára àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó tí ì pọ́n aráyé lójú rí.” Bákan náà, Ọ̀mọ̀wé Peter Piot, olórí ètò àbójútó Àrùn AIDS fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ níbi ìpàdé kọkànlá lágbàáyé lórí àrùn AIDS pé, Íńdíà ti fara hàn lójijì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí ó ní iye ènìyàn tí ó pọ̀ jù lọ tí fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS ti ta mọ́—ó lé ní mílíọ̀nù 3 lára gbogbo mílíọ̀nù 950 ènìyàn ibẹ̀ tó ní in. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Indian Express ṣe sọ, ìwádìí kan fojú díwọ̀n pé ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọkùnrin Íńdíà tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀, tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù 223, ní ń lọ sílé aṣẹ́wó déédéé. Àwọn aṣẹ́wó tí ń ṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè ìgboro ìlú ńlá, tí a sì ń rí i pé wọ́n ní àkóràn àrùn ni a sábà máa ń dá pa dà sí abúlé wọn níbi tí àìmọ̀kan nípa àrùn náà, níbi tí àwọn ibi ìtọ́jú aláìsàn tí kò ní ohun èèlò tó àwọn ti ìlú ńlá, ti ń mú kí àrùn náà ràn kálẹ̀ lọ́nà yíyára kánkán. A fojú díwọ̀n pé, tí ó bá fi máa di ọdún 2000, Íńdíà yóò ti ní tó mílíọ̀nù márùn-ún sí mílíọ̀nù mẹ́jọ ènìyàn tí wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì HIV àti nǹkan bí àwọn mílíọ̀nù kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hàn pé wọ́n ní àrùn AIDS.

Àwọn Ìfarapa Inú Eré Ìdárayá

• Ìwé agbéròyìnjáde Vancouver Sun ti Kánádà ròyìn pé: “Eré gígun kẹ̀kẹ́ pọ́n òkè ńlá ń yára pọ̀ sí i, àwọn agunkẹ̀kẹ́ sì ń darí sí ilé ìwòsàn.” Ìwé agbéròyìnjáde náà ròyìn pé, láàárín 1987 sí 1994, iye ènìyàn tí ń gun kẹ̀kẹ́ pọ́n òkè ńlá ní United States fi ìpín 512 lórí ọgọ́rùn-ún ga, láti orí mílíọ̀nù 1.5 sí mílíọ̀nù 9.2. Kẹ̀kẹ́ máa ń sọ àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ya onítara òdì, tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ré kọjá ìpele tí agbára wọ́n gbé lórí ọ̀gangan ọ̀nà àti ipa ọ̀nà nù, wọ́n sì máa ń ṣèṣe tí kò mọ sórí fífi ara ya nǹkan àti bíbó lára, àmọ́ wọ́n tún máa ń fi ọrùn ẹsẹ̀, ọrùn ọwọ́, èjìká, àti àwọn egungun tí ó gbé èjìká ró pa lọ́nà tí ó burú gan-an. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìfarapa kan kì í halẹ̀ mọ́ ìwàláàyè, wọ́n lè ní àbájáde onígbà pípẹ́ tí ó le gan-an. Dókítà Rui Avelar, tí ó mọṣẹ́ dunjú nípa ìtọ́jú ìfarapa nídìí eré ìdárayá, gbà gbọ́ pé bí ọ̀kan lára àwọn egungun tínríntínrín mẹ́jọ tí ó wà lọ́rùn ọwọ́ bá dá, a lè máà rí i nínú àwòrán X ray. Ó kìlọ̀ pé: “Bí o bá ṣubú lé ọwọ́ kan tí ó nà sílẹ̀, mú un lógìírí.” Ó lè mú kí ẹnì kan ní ìṣòro egungun oríkèé ọrùn ọwọ́ ríro àti ìbàjẹ́ tí kò ṣeé wò sàn.

• Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung sọ pé: “Ìfarapa tí eré ìdárayá ń fà lọ́dọọdún jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù 1.2 sí mílíọ̀nù 1.5 ní Germany.” Àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn ní Yunifásítì Bochum ti ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ 85,000 ìpalára tí fàájì àti eré ìdárayá ń fà nínú ìsapá láti ṣàkójọ ìsọfúnni pípéye, tí ó kún nípa wọn. Ìfarapa tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn agbábọ́ọ̀lù. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a bá ń ronú nípa iye àwọn olùkópa nínú onírúurú eré ìdárayá, àwọn olùwádìí náà ṣàwárí pé bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá, bọ́ọ̀lù àfọwọ́jù, àti bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ ní ìwọ̀n ìfarapa tí ó dọ́gba nínú. Nǹkan bí 1 lára ìfarapa 3 tí eré ìdárayá ń fà ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọrùn ẹsẹ̀, tí 1 nínú 5 tí ń ṣẹlẹ̀ sí orúnkún sì gba ipò tẹ̀ lé e.

Ṣọ́ra fún Bakitéríà E. Coli O157:H7

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times kìlọ̀ pé: “Àjàkálẹ̀ májèlé oúnjẹ tí irú bakitéríà E. coli ń fà . . . ti ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé. Iye bakitéríà tí ó lè gbé oró májèlé náà ń pọ̀ sí i, bí iye àkóràn àti ikú ṣe ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé.” Irú bakitéríà náà, ẹ̀yà O157:H7, ni a kọ́kọ́ mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣòro kan ní 1982. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láti ìgbà náà wá ni ó ti wá apilẹ̀ àbùdá tuntun kan rí láti sọ ara rẹ̀ di oró májèlé Shiga, tí ń fa ìgbẹ́ ọ̀rìn Shigella. Bí a kò bá tọ́jú rẹ̀ ní kánmọ́, àrunṣu náà lè yọrí sí àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀, bíba kíndìnrín jẹ́, àti ikú. Ní 1993, ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn United States, ẹni 4 ló kú, àwọn 700 sì ṣàìsàn lẹ́yìn tí wọ́n jẹ ẹran lílọ̀ tí kò jinná, ní ilé àrójẹ lílókìkí ńlá kan. Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àjàkálẹ̀ rẹ̀ tún ti ṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà, Australia, Europe, àti Japan. Ní United States nìkan, bakitéríà E. coli O157:H7 lè ṣokùnfà 20,000 àìsàn lọ́dọọdún, kí ó sì fa 250 sí 500 ikú. Ìwé agbéròyìnjáde Times náà sọ pé: “Àwọn aláràjẹ lè mú kí ipò ṣíṣàìkó àrùn náà sunwọ̀n sí i fún wọn nípa rírí i dájú pé àwọn se ẹran, ní pàtàkì ẹran lílọ̀, kí ìwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù inú ẹran náà fi dé orí ìwọ̀n 155 lórí òṣùwọ̀n Fahrenheit [ìwọ̀n 68 lórí òṣùwọ̀n Celsius], tí ó lọ́ wọ́ọ́rọ́ tó tí kò fi ní ní àwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú kankan mọ́ rárá.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́