Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí A Sọ̀rọ̀ Nípa Rẹ̀
“Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.”—Òwe 27:17, Bíbélì.
WÍWULẸ̀ fi àwọn ọ̀bẹ lu ara wọn kọ́ ló ń jẹ́ kí wọ́n mú. Ó gba ẹ̀sọ̀ láti pọ́n ọ̀bẹ. Bákan náà, àwọn ọ̀nà tó tọ́ wà, èyí tí kò sì tọ́ wà tí a lè gbà lo ìjíròrò láti mú èrò inú yè kooro, pàápàá nípa àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó gba ọgbọ́n bí ìsìn.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún iyì ẹnì kejì, kí a sì jẹ́ kí ọ̀wọ̀ yẹn hàn nínú ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ àti ìṣarasíhùwà wa. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kólósè 4:6) A kì í fi àṣẹ sọ ọ̀rọ̀ tí ó ní oore ọ̀fẹ́, tí ó dùn mọ́ni, kódà tí ó bá dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ náà lójú pé òun tọ̀nà àti pé ẹnì kejì kọ̀ tọ̀nà.
Oore ọ̀fẹ́ tún máa ń hàn nínú ọ̀nà tí a ń gbà fetí sílẹ̀. A kò lè sọ pé a ń fetí sílẹ̀ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́ bí a bá ń já lu ọ̀rọ̀ ẹnì kejì tàbí tí ọkàn wa kò bá sí nínú ọ̀rọ̀ tí a ń gbọ́ nítorí pé a ń ro ohun tí a ó sọ lẹ́yìn tí ó bá sọ̀rọ̀ tán. Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lè ṣàkíyèsí pé a kò nífẹ̀ẹ́ sí èrò tòun, ó sì lè fòpin sí ìjíròrò náà. Bákan náà, a kò ní láti fipá mú ẹlòmíràn tàbí kí a kó o láyà jẹ kí ó bàa lè yí èrò rẹ̀ padà. Ó ṣe tán, ‘Ọlọ́run ló ń mú kí èso òtítọ́ máa dàgbà’ nínú ọkàn-àyà ẹni tó fetí sílẹ̀ tó sì ń dáhùn padà.—1 Kọ́ríńtì 3:6.
A ní àpẹẹrẹ rere ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó lo “ìfèròwérò” àti “ìyíniléròpadà” nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Ìṣe 17:17; 28:23, 24) Pọ́ọ̀lù bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ìsìn níbikíbi tó bá ti rí wọn, bí ọjà àti ní ilé wọn. (Ìṣe 17:2, 3; 20:20) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tiraka láti ṣàfarawé àpẹẹrẹ yẹn nípa lílọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rí àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń fèrò wérò pẹ̀lú wọn láti inú Ìwé Mímọ́.
Yẹra fún Àṣìlóye
Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Ilẹ̀ Ìlérí, àṣìlóyé nípa pẹpẹ kan fẹ́rẹ̀ẹ́ mú wọn ja ogun abẹ́lé. Àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ̀dó sí ìhà ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì mọ pẹpẹ kan, àmọ́, àwọn ẹ̀yà yòókù rò pé pẹpẹ náà jẹ́ fún ìjọsìn èké. Nítorí náà, wọ́n múra ogun láti fìyà jẹ àwọn arákùnrin wọn. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n borí. Àwọn tí wọ́n fẹ́ gbógun náà kọ́kọ́ rán àwọn aṣojú láti lọ wádìí ohun tó fà á tí wọ́n fi mọ pẹpẹ náà. Ọkàn wọn balẹ̀ nígbà tí wọ́n sọ fún wọn pé ohun ìrántí lásán ni—“ẹ̀rí kan”—tí yóò rán gbogbo ẹ̀yà náà létí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn níwájú Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ ni kò jẹ́ kí yánpọnyánrin ṣẹlẹ̀—òun ni kò sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò!—Jóṣúà 22:9-34.
Bákan náà, àṣìlóye sábà máa ń dá ọ̀tá àti ẹ̀tanú pàápàá sílẹ̀ lónìí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn díẹ̀ ti rò pé agbawèrèmẹ́sìn ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí àwọn ìròyìn tí wọ́n ń gbọ́ pé wọn kì í gbẹ̀jẹ̀. Àmọ́, ó sábà máa ń ya àwọn tí wọ́n béèrè nípa ọ̀ràn yìí lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́nu láti gbọ́ pé ìdí tí wọ́n fi mú ìdúró yẹn wà nínú Bíbélì àti pé àwọn ìtọ́jú àfirọ́pò tí kò léwu, tí ó sì gbéṣẹ́ wà. (Léfítíkù 17:13, 14; Ìṣe 15:28, 29) Ní gidi, nítorí ìṣòro tí àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ń rí gbà ń ní, akọ̀ròyìn kan kọ̀wé pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nípa ohun àfirọ́pò ẹ̀jẹ̀.”
Bákan náà, àwọn kan kì í bá Àwọn Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀ nítorí àwọn kan ti sọ fún wọn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba Jésù Kristi gbọ́. Irọ́ ńlá gbáà mà lèyí o! Ní gidi, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń tẹnu mọ́ ipa tí Jésù kó nínú ìgbàlà wa, wọ́n ń ṣàlàyé pé Ọmọ Ọlọ́run ni ó jẹ́, ẹni tí Ọlọ́run rán wá sí ilẹ̀ ayé láti ra àwọn ènìyàn padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nípa bíbá Àwọn Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí, àwọn ènìyàn ti rí àlàyé sí àwọn ohun tí wọ́n ṣì lóye.—Mátíù 16:16; 20:28; Jòhánù 3:16; 14:28; 1 Jòhánù 4:15.
Òtítọ́—Ó Gbajúmọ̀ Àbí Kò Gbajúmọ̀?
Ohun tó ń ya ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́nu ni pé tó bá kan ọ̀rọ̀ nípa ìsìn, ọ̀nà ti ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́wọ́ gbà ló sábà máa ń jẹ́ èyí tí kò tọ̀nà. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi kọ́ni pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.
Nígbà ayé Nóà, ẹni mẹ́jọ péré ló ń sọ òtítọ́ ti Ọlọ́run—Nóà, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àti àwọn ìyàwó wọn. Láìsí àní-àní, ìkìlọ̀ tí wọ́n ń ṣe àti ọkọ̀ áàkì tí wọ́n kàn sọ wọ́n di ẹni tí àwọn kan ń fi ṣẹ̀sín, tí wọ́n sì ń bú pàápàá. Síbẹ̀, Nóà àti ìdílé rẹ̀ kò bẹ̀rù; wọ́n ń bá ìwàásù àti iṣẹ́ ọkọ̀ kíkàn wọn lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 14; 7:21-24; 2 Pétérù 2:5) Bákan náà, ẹni mẹ́ta péré ló ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, tí wọ́n sì la ìparun Sódómù àti Gòmórà já.—Jẹ́nẹ́sísì 19:12-29; Lúùkù 17:28-30.
Àkókò tiwa ńkọ́? Onílé kan tí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sọ̀rọ̀ sọ pé: “Bí Kristi bá padà wá nínú ẹran ara lónìí, àwọn ènìyàn tún lè pa á.” Ẹni yìí ronú pé àwọn ènìyàn kò ní tẹ́wọ́ gba àwọn ohun tí Jésù yóò fi kọ́ni àti àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n gíga rẹ̀ fún ìwà rere lónìí bó ṣe rí ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Ǹjẹ́ o gbà pẹ̀lú rẹ̀?
Tí o bá gbà pẹ̀lú rẹ̀, òtítọ́ lo sọ, nítorí Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó . . . jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi”—àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ní ìmúṣẹ. (Mátíù 24:9) Àwọn aṣáájú Júù ní Róòmù sọ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa ìsìn Kristẹni pé: “Ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí . . . , níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn kò tẹ́wọ́ gba ìsìn Kristẹni, ìyẹn kò dá àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi dúró láti má ṣe bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá àwọn aláìlábòsí-ọkàn dúró láti má ṣe bá àwọn Kristẹni sọ̀rọ̀.—Ìṣe 13:43-49.
Lónìí, ìsọfúnni tí Jésù ní ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Èé ṣe? Nítorí pé ipò ayé fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìgbékalẹ̀ yìí ni a ń gbé nísinsìnyí àti pé àwọn ọjọ́ yìí yóò dópin nínú ìgbésẹ̀ fífọ ìwà àìtọ́ mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Jésù fi àkókò wa wé àwọn ọjọ́ Nóà. (2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:37-39) Nítorí náà, kì í ṣe àkókò yìí ni a ó wá máa fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìgbàgbọ́ wa, nítorí pé kìkì àwọn tó mọ Ọlọ́run tí wọ́n sì “jọ́sìn [rẹ̀] ní ẹ̀mí àti òtítọ́” ni a óò fún ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 4:24; 2 Tẹsalóníkà 1:6-9.
Bí A Ṣe Lè Mọ Ọ̀nà Títọ́
Francis Bacon, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n èrò orí, olùkọ́ àròkọ, amòfin, àti òṣèlú ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, gba àwọn tí ń wá òtítọ́ nímọ̀ràn “láti díwọ̀n rẹ̀ wò, kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀.” Thomas Jefferson, ààrẹ kẹta tó jẹ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ìrònú àti àyè láti ṣèwádìí láìsídìíwọ́ ni ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kàn ṣoṣo tí a lè gbà kápá àṣìṣe. . . . Àwọn ni ọ̀tá àtayébáyé tí àṣìṣe ní.” Nítorí náà, bí a bá ń fi tinútinú wá òtítọ́, kí a “díwọ̀n rẹ̀ wò, kí a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀” kí a “ronú, kí a sì ṣèwádìí láìsídìíwọ́.”
Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Alàgbà Hermann Bondi, ṣàlàyé ìdí tí ọ̀nà ìgbékalẹ̀ bẹ́ẹ̀ fi ṣe pàtàkì pé: “Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹ̀sìn kan ṣoṣo péré ni yóò jẹ́ òtítọ́, nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn fi tọkàntọkàn àti ìdúróṣinṣin gba ohun tí kì í ṣe òtítọ́ gbọ́ tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. À bá ti retí pé kí òkodoro ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere yìí mú àwọn ènìyàn fi ìwọ̀n ìrẹ̀lẹ̀ díẹ̀ hàn, kí wọ́n ronú pé bí ó ti wù kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára tó, èrò ẹni lè má tọ̀nà.”
Nítorí náà, báwo ni ẹnì kan ṣe lè mọ̀ bí òun ní gidi bá wà ní ‘ojú ọ̀nà híhá tí ó lọ sínú ìyè’? Jésù fi kọ́ni pé a gbọ́dọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run ‘ní òtítọ́.’ Nítorí náà, ìrònú yóò súnni láti parí èrò pé bí oríṣi ẹ̀kọ́ méjì bá tako ara wọn, méjèèjì kò lè jẹ́ òtítọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti bóyá ènìyàn ní ọkàn tí ń wà nìṣó lẹ́yìn ikú tàbí wọn kò ní in. Bóyá Ọlọ́run yóò dá sí àlámọ̀rí ayé tàbí kò ní í dá sí i. Bóyá Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan tàbí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwọn tí ń wá òtítọ́ ń fẹ́ ìdáhùn gidi sí irú àwọn ìbéèrè yẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti pèsè ìdáhùn fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì.a
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” ọ̀nà pàtàkì tí a lè gbà ṣàyẹ̀wò onírúurú ẹ̀kọ́ ni láti fi Bíbélì díwọ̀n wọn. (2 Tímótì 3:16) Nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ‘fúnra rẹ ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Ǹjẹ́ o lè ‘fúnra rẹ ṣàwárí’ pé Bíbélì ni orísun àwọn ohun tí o gbà gbọ́? Lílè ṣe bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nítorí pé Ọlọ́run kò fẹ́ kí a ṣì ọ́ lọ́nà pẹ̀lú “gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 12:9.
Ǹjẹ́ Ó Pọndandan Kí A Ní Olùkọ́?
Jésù kò wulẹ̀ fa àwọn àkójọ ìwé mélòó kan lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó sì sọ pé: “Gbogbo ìdáhùn àwọn ìbéèrè yín wà níbẹ̀. Ẹ lọ máa wá wọn fúnra yín nílé.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú sùúrù, ó sì fẹ̀sọ̀ kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tó yá, àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ohun tó kọ́ wọn lo ọ̀nà tí ó gba kọ́ wọn nígbà tí àwọn náà ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Wo àpẹẹrẹ ọmọ ẹ̀yìn náà, Fílípì. Ó jíròrò pẹ̀lú olóòótọ́ ọkàn kan tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ará Etiópíà tí ó ti mọ Ìwé Mímọ́ tẹ́lẹ̀ nígbà tó wà pẹ̀lú àwọn Júù. Àmọ́, ọkùnrin náà nílò ìrànlọ́wọ́. Nítorí náà, a darí Fílípì—aṣojú ìjọ Kristẹni—láti lọ ràn án lọ́wọ́. Ká ní òṣìṣẹ́ yìí kò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn ni, kò ní mọ̀ nípa ipa tí Jésù kó nínú ète Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ rere gbáà ni ará Etiópíà yìí mà jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń wá òtítọ́ o!—Ìṣe 8:26-39.
Ǹjẹ́ ìwọ yóò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí o gbà gbọ́, kí o sì béèrè ìbéèrè bí ará Etiópíà yìí ti ṣe? Ìwọ yóò jàǹfààní púpọ̀ tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ayọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó jẹ́ láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní òtítọ́ inú láti mọ ohun tí ó sọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí kì í sọ èrò ti ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú láti fi ohun tí Bíbélì sọ han àwọn ènìyàn.
Òṣìṣẹ́ ará Etiópíà náà kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ kan nípa Jésù Kristi, bí ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò gbà lò ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbàlà wa. Lónìí, ète Ọlọ́run fẹ́rẹ̀ẹ́ ní ìmúṣẹ rẹ̀. Àwọn ohun àrà, tí ń bani lẹ́rù yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ lórí ilẹ̀ ayé yìí. Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yóò fi hàn pé yóò kan olúkúlùkù ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ṣá o, bí yóò ṣe kàn wá yóò sinmi lórí ìṣarasíhùwà wa àti ìgbésẹ̀ tí a gbé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ẹ̀rí pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, jọ̀wọ́ wo ìwé The Bible—God’s Word or Man’s?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Òṣìṣẹ́ ará Etiópíà kan gbà láti jíròrò Bíbélì