ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 6/8 ojú ìwé 30
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Kí Ọmọ Ọwọ́ Máa Sùn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Kí Ọmọ Ọwọ́ Máa Sùn?
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ọwọ́ Nílò àti Ohun Tí Wọ́n Fẹ́
    Jí!—2004
  • Bí Ọmọ Ṣe Ń Yí Nǹkan Pa Dà Láàárín Tọkọtaya
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
Jí!—1999
g99 6/8 ojú ìwé 30

Báwo Ló Ṣe Yẹ Kí Ọmọ Ọwọ́ Máa Sùn?

Ọ̀PỌ̀ ọmọ ọwọ́ káàkiri àgbáyé ni Ikú Òjijì Àwọn Ọmọdé (SIDS) ti pa. Òun ló ń pa ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ọwọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín oṣù kan sí ọdún kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ǹjẹ́ ọ̀nà kankan wà láti dín ewu náà kù? Ìwádìí tí ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association (JAMA), ṣe ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé ó jọ pé ewu SIDS dín kù gan-an nígbà tí àwọn ọmọ ọwọ́ ń fẹ̀yìn lélẹ̀ sùn ju ìgbà tí wọ́n bá dakùn délẹ̀ sùn lọ. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti gbé ìlànà kalẹ̀ láti mú kí àwọn òbí wà lójúfò sí ìsopọ̀ tó wà láàárín bọ́mọ ṣe ń sùn àti SIDS. Ó kéré tán SIDS dín kù sí ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lẹ́yìn ọdún kan sí méjì tí wọ́n fi pàrọwà sí gbogbo èèyàn láti máa fẹ̀yìn ọmọ lé bẹ́ẹ̀dì ní Ọsirélíà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Denmark, New Zealand, àti Norway.

A kò tí ì mọ bí dídakùndélẹ̀ sùn ọmọ ọwọ́ ṣe kan SIDS gan-an, àmọ́, àwọn olùwádìí kan fi hàn pé sísùn ní ọ̀nà yìí lè mú kí ọmọ kan máa fa afẹ́fẹ́ tó ń mí jáde padà sínú, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìwọ̀n gáàsì carbon dioxide inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i. Ooru tún lè mú ọmọ náà jù nítorí pé ooru ara rẹ̀ kò rọ́nà jáde dáadáa nígbà tó dakùn délẹ̀ sùn. Bó ti wù kó rí, ọ̀nà táa bá gbà tẹ́ àwọn ọmọ ọwọ́ sùn ló máa ń mọ́ wọn lára, yálà a fẹ̀yìn wọn lélẹ̀ tàbí a dakùn wọn délẹ̀. Ìwádìí tún fi hàn pé fífẹ̀yìn ọmọ ọwọ́ tí nǹkan ò ṣe, ti ara rẹ̀ le lélẹ̀ sàn ju fífẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lélẹ̀ lọ.

Èé ṣe tí àwọn ìyá fi yan ọ̀nà kan tí a ń gbà tẹ́ ọmọ láàyò ju òmíràn lọ? Ìwé ìròyìn JAMA sọ pé àṣà àdúgbò ni àwọn ìyá sábà máa ń tẹ̀ lé—wọ́n máa ń tẹ́ àwọn ọmọ wọn sùn bí ìyá tiwọn tàbí àwọn mìíràn lágbègbè wọn ti ń ṣe. Tàbí kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn àṣà tí wọ́n rí ní ilé ìwòsàn. Àwọn ìyá kan tún máa ń rò pé ó tẹ́ ọmọ wọn lọ́rùn tàbí pé wọ́n máa ń sùn dáradára jù ní ọ̀nà kan pàtó. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ló máa ń fẹ̀yìn ọmọ wọn lélẹ̀ léraléra ní oṣù àkọ́kọ́ àmọ́ tí wọ́n ń yí padà sí dídakùn wọn délẹ̀ lẹ́yìn náà. Ìwé ìròyìn JAMA sọ pé: “Ìtẹ̀sí yìí ń bani nínú jẹ́, nítorí pé ewu SIDS máa ń lọ sókè jù lọ láàárín àwọn ọmọ oṣù méjì sí mẹ́ta.” Àwọn dókítà ń tiraka láti sọ fún àwọn òbí ọlọ́mọ kéékèèké nípa ohun tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ìgbésẹ̀ rírọrùn láti dín ewu SIDS kù—fífẹ̀yìn àwọn ọmọ tí ara wọ́n le lélẹ̀ sùn.a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ọmọ kan bá ní ìṣòro èémí tàbí kó máa wọ́tọ́ lẹ́nu lọ́nà tó ṣàjèjì, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni láti lọ rí dókítà láti béèrè nípa bó ṣe yẹ kó máa sùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́