ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 6/8 ojú ìwé 31
  • ‘Báwo Ni Iṣẹ́ Yín Ṣe Ń Ṣe Àwùjọ Láǹfààní Tó?’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Báwo Ni Iṣẹ́ Yín Ṣe Ń Ṣe Àwùjọ Láǹfààní Tó?’
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Ran Ìdílé Kan Lọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú
    Jí!—2004
  • Ṣé Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà
    Jí!—1997
  • Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 6/8 ojú ìwé 31

‘Báwo Ni Iṣẹ́ Yín Ṣe Ń Ṣe Àwùjọ Láǹfààní Tó?’

ÌBÉÈRÈ tí Chandrakant Patel, ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan tó jẹ́ akọ̀ròyìn, béèrè lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ kan ní orílé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó wà ní Brooklyn, New York, nìyí. Ọ̀gbẹ́ni Patel wá láti rin orílé iṣẹ́ náà káàkiri, ohun tó rí tó sì gbọ́ mú un láyọ̀ débi pé nígbà tó padà sí Íńdíà, ó kọ àpilẹ̀kọ kan fún ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń ṣe jáde ní èdè Gujarati.

Ọ̀gbẹ́ni Patel fi díẹ̀ lára ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wé ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní Íńdíà pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run Olódùmarè, Jèhófà, ní ìyàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan tí wọ́n máa ń kọ́ni lemọ́lemọ́ ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti pé wọn kì í lo ère nínú ìjọsìn wọn. Ó ṣàkíyèsí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga nítorí pé gírígírí ni wọ́n di àwọn ìlànà Kristẹni mú, àwọn táa là sílẹ̀ nínú Bíbélì nípa panṣágà, ìṣẹ́yún, àti kíkórìíra tàbí pípa ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni. Ó ṣàpèjúwe Àwọn Ẹlẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ àlàáfíà, onífẹ̀ẹ́, onípamọ́ra, tí iṣẹ́ ìsìn sì ká lára, bákan náà ni wọn kì í bẹ̀rù, wọ́n sì ní ìtara nínú títan ìhìn iṣẹ́ Bíbélì kálẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.

Èsì wo ni akọ̀ròyìn láti Íńdíà náà rí gbà sí ìbéèrè rẹ̀ pé, ‘Báwo ni iṣẹ́ yín ṣe ń ṣe àwùjọ láǹfààní tó?’ Ó kọ ọ́ pé: ‘Ìdáhùn náà ni pé ẹ̀kọ́ Bíbélì láǹfààní ní gbogbo apá ìgbésí ayé.’ Ọ̀gbẹ́ni Patel fẹ́ mọ̀ nípa àbójútó ìlera àti iṣẹ́ ní pàtó. Ní mímẹ́nukàn lára àwọn àlàyé tí wọ́n ṣe fún un, ó ròyìn pé: ‘Bí ẹnì kan bá tẹ̀ lé àmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ láti yàgò fún àwọn ohun tí ń pani lára bíi tábà àti oògùn líle tó sì gbé ìgbésí ayé tó mọ́ tónítóní, ó lè bọ́ lọ́wọ́ onírúurú àrùn. Àti pé ó rọrùn fún àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì jẹ́ aláìlábòsí láti ríṣẹ́ ṣe. Ní àfikún sí i, fífi ìfẹ́ àti inúure yanjú àwọn ìṣòro ń yọrí sí níní ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà kíkọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Bíbélì wí ń ṣe àwùjọ láǹfààní.’

Akọ̀ròyìn yìí rí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń ṣiṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àpilẹ̀kọ rẹ̀ gbóríyìn fún ìmọ́tótó àti ìtúraká àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda láti fara wọn jìn fún iṣẹ́ ní àárín gbùngbùn ìgbòkègbodò tẹ̀mí yẹn. Ìwọ náà lè jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti fi bí wọ́n ṣe ń ṣe é hàn ọ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìwé ìròyìn táa kọ̀wé lé: Lọ́lá àṣẹ Naya Padkar, Ìwé Ìròyìn Ojoojúmọ́ ti Gujarati tí wọ́n ń tẹ̀ ní Anand, Íńdíà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́