ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 5/8 ojú ìwé 10-11
  • Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Ran Ìdílé Kan Lọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Ran Ìdílé Kan Lọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Íńdíà—“Ìṣọ̀kan Láàárín Onírúurú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • A Mọ Ohun Tó Tọ́, A Sì Ṣe É
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Gẹgẹ Bi Opó kan, Mo Rí Ìtùnú Tootọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Jí!—2004
g04 5/8 ojú ìwé 10-11

Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Ran Ìdílé Kan Lọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú

ÀÌSÀN ò yọ ọmọbìnrin rírẹwà kan tó ń jẹ́ India, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tó wá láti ìpínlẹ̀ Wisconsin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sílẹ̀. Kódà, wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ tó le gan-an fún un lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ìtọ́jú pẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn tí ò lóǹkà. Lori, ìyá ọmọ náà, sọ pé: “Fọ́dún mẹ́fà gbáko la fi ń gbé e lọ fún ìtọ́jú pàjáwìrì, tá à ń sùn nílé ìwòsàn, tá ò sì yé pààrà ọ̀dọ̀ dókítà.”

Ọmọ ọdún kan ààbọ̀ ni India nígbà tí àìsàn yìí bẹ̀rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn àmì àrùn tó ṣàjèjì, léyìí tó ń yàgbẹ́ gbuuru, tí ara rẹ̀ ń gbóná fòò, tí ikùn rẹ̀ ń wú, tó sì ń rù. Ikùn tún máa ń ro ó. Ní òròòru, fún ọdún méjì gbáko, ẹ̀ẹ̀mẹsàn-án ẹ̀ẹ̀mẹwàá ni India wa jòjòló máa ń jí lójú oorun tá máa sunkún, tá máa hu, tá sì máa ké rara nígbà míì bó bá ń jẹ̀rora.

Ní gbogbo ìgbà táwọn dókítà ń sapá láti mọ ohun tó ń ṣe India, ìrora tó jẹ gàgaàrá. Lori sọ pé: “Ńṣe ló dà bí ẹni pé ó ń joró títí tó fi máa kú.” Mark, bàbá ọmọ náà wá sọ pé: “Ó lé lọ́dún kan tí ọmọbìnrin wa ọ̀wọ́n fi ń rù tó sì ń gbẹ, tá ò sì mọ ọ̀nà tá a lè gbà ràn án lọ́wọ́. Mo rántí pé ìgbà kan tiẹ̀ wà tí gbogbo ẹ̀ tojú sú mi lóru ọjọ́ kan báyìí témi àti Lori fi bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ìsìnkú India, èyí tá a rò pé kò lè yẹ̀ mọ́ lákòókò náà.”

Nígbà tó ṣe, àwọn dókítà sọ pé àrùn ulcerative colitis, èyí tó máa ń dégbò sára ìtẹ́nú ìwọ́rọ́kù, ló ń ṣe India. Àrùn sclerosing cholangitis, tó máa ń bá àpò òróòro tó wà lára ẹ̀dọ̀ jà tún ń dà á láàmú pẹ̀lú. Àìsàn tó ṣeé wò làwọn àìsàn náà. Àmọ́, ó la iṣẹ́ abẹ lọ o, oògùn ni wọ́n sì máa ń lò sí àìsàn kejì tó máa ń dégbò sára ìtẹ́nú ìwọ́rọ́kù. Bí ara ẹni tí èyíkéyìí nínú àìsàn yìí ń ṣe bá ti ń yá lọ, wọn ò gbọ́dọ̀ dáwọ́ ìtọ́jú dúró.

Ó ti ju ọdún méje lọ báyìí tí àìsàn India ti bẹ̀rẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn oníṣègùn tí wọn ò fi iṣẹ́ wọn jáfara, ńṣe lara ẹ̀ túbọ̀ ń mókun sí i báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Mark àti Lori ronú pé ìgbàgbọ́ àwọn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pàápàá jù lọ, ohun tó sọ nípa àìsàn, ikú, àti ìrètí àjíǹde lọ́jọ́ iwájú, ló ran àwọn lọ́wọ́ láti fara dà á. Ìgbàgbọ́ kan náà yìí ló ran India lọ́wọ́. Lori sọ pé: “Fàlàlà falala ni India máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀. Ìrètí náà dá a lójú hán-ún hán-ún.”

Nígbà kan tí India wà nínú yàrá ìṣeré nínú ilé ìwòsàn náà, ó rí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí àbúrò rẹ̀ ní àrùn sẹ̀jẹ̀ domi. Lori ròyìn pé: “Ọmọbìnrin náà sọ fún India pé ẹ̀rù ń ba òun pé àbúrò òun lè lọ kú. India wá sọ ohun tí ikú jẹ́ fún un bí Bíbélì ṣe fi kọ́ni, àti pé òun ò bẹ̀rù ikú ní tòun. Lọ́jọ́ kejì, ìyá ọmọbìnrin náà tọ̀ mí wá ó sì bi mí ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un pé India lè sọ̀rọ̀ fàlàlà bẹ́ẹ̀ nípa ikú láìbẹ̀rù.”

Mark àti Lori ti wá rí i pé àdúrà àwọn onígbàgbọ́ bíi tàwọn ti ran àwọn lọ́wọ́ gidigidi. Mark sọ pé: “Nígbà kan, bí mo bá sọ fáwọn èèyàn pé mà á rántí wọn nínú àdúrà mi tàbí nígbà tá a bá jọ gbàdúrà, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún wọn. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ bí àdúrà tá à ń gbà pẹ̀lú àwọn mìíràn àtèyí tá à ń gbà fún wọn ṣe ṣe pàtàkì tó ni. Olórí ohun tẹ́nìkan lè ṣe fún wa lákòókò ìṣòro ni pé kó gbàdúrà fún wa. Ìfẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará wa mà kúrò ní kékeré o!”

Mark tún rí i pé àìsàn India ti ran àwọn lọ́wọ́ láti tún èrò pa lórí ohun táwọn á máa fi sí ipò àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Ojú tá a fi ń wo àwọn nǹkan tara ti yí padà pátápátá. Wọn ò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan tára ọmọ rẹ ò bá yá! Àwọn ohun tó já mọ́ pàtàkì tá a sì tún lè kà sí pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa ni àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti ẹgbẹ́ ará wa onífẹ̀ẹ́.”

Mark àti Lori, pẹ̀lú India àtàwọn ọmọ yòókù ń wọ̀nà fún àkókò tí wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

India Erickson

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ilé Ìwòsàn Àwọn Ọmọdé ní San Diego

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

India àtàwọn aráalé rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́