Ǹjẹ́ O Ti Ríbi Tí Ẹja Ti Ń Rìn Rí?
ÀRÀ MÉRÌÍYÌÍRÍ! Ẹ̀gbẹ́ ọ̀gọ̀dọ̀ kan tó kún fún igi ẹ̀gbà ni mo wà, tí mo ń wo ohun tí mo rò pé ó jẹ́ ilẹ̀ ẹlẹ́rọ̀fọ̀ tí kò ní ẹ̀dá abẹ̀mí kankan. Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá rí i pé àwọn nǹkan abẹ̀mí ń bẹ ńbẹ̀. Ló bá di pé àwọn abàmì ẹ̀dá kan bẹ̀rẹ̀ sí fara pitú. Abàmì ẹ̀dá kẹ̀? Tíntìntín báyìí ni wọ́n, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ò gùn ju sẹ̀ǹtímítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ẹja làwọn ẹ̀dá ọ̀hún.
Ẹní bá sọ pé òun rí ẹja tó ń rìn, tó lóun rí ẹja tó ń tọ kúṣọ́-kúṣọ́, àfi bí ẹní sọ pé òun rí erin tó ń fò lọ̀ràn náà rí, àmọ́, ohun tí mo fojú mi rí nìyẹn. Báwo wá ni ẹja ṣe ń rìn, tó ń gun nǹkan, tó sì ń tọ kúṣọ́-kúṣọ́—àní tó tilẹ̀ ń mí—láìsí nínú omi?
Atọkúṣọ́-nínú-ẹrọ̀fọ̀ lorúkọ tí wọ́n ń pe àwọn ẹja tí mo rí. Ojú àwọn ẹja yìí, àràmàǹdà ni, bó ṣe ń yọ gọngọ síta, ló tún ń kó wọnú padà. Ohun àrà ọ̀tọ̀ míì tó tún wà lára àwọn ẹja atọkúṣọ́-nínú-ẹrọ̀fọ̀ ni lẹbẹ tó wà láyà wọn, èyí ni wọ́n fi ń gbéra nínú ẹrẹ̀—bí ìgbà téèyàn ń fi igi ìtìlẹ̀ rìn ló jọ. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹja yìí ṣe ń tọ? Ẹja abàmì yìí lè fi ìrù rẹ̀ dúró, kó ta síwájú páá, kó sì fo ọgọ́ta sẹ̀ǹtímítà kó tó balẹ̀. Àgbà ẹnjiníà ni àwọn ẹja atọkúṣọ́-nínú-ẹrọ̀fọ̀ yìí o, tẹ́ẹ bá rí wọn níbi tí wọ́n ti ń fi lẹbẹ wọn gbẹ́hò nínú ẹrọ̀fọ̀, bí ẹní ń lo ṣọ́bìrì ló jọ.
Ẹja yìí ní àwọn ibì kan tó ń tọ́jú afẹ́fẹ́ oxygen pa mọ́ sí—ìyẹn ni lẹ́nu àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tó máa ń kún fómi nígbà tó bá “ń bẹ́” kiri lórí ilẹ̀. Nígbà tó bá lo afẹ́fẹ́ oxygen tó wà lẹ́nu àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tán, á tún bẹ́ padà sínú ẹrọ̀fọ̀ láti lọ wá kún un.
Bóo bá lè dé àwọn ilẹ̀ ẹlẹ́rọ̀fọ̀ tó wà ní Áfíríkà tàbí Éṣíà, bóo bá sì lè fara da yànmùyánmú àti oòrùn ilẹ̀ olóoru, o ò ṣe wá bóo ṣe lè fojú gán-án-ní ẹja atọkúṣọ́-nínú-ẹrọ̀fọ̀? Kí ìwọ náà lè sọ pé o ti rí ẹja tí ń rìn!—Àkọfiránṣẹ́.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]
Lọ́wọ́ ẹ̀yìn: Jane Burton/Bruce Coleman Inc.
Àwọn fọ́tò inú àkámọ́: Látọwọ́ Richard Mleczko