Ìgbàgbọ́ Ọmọkùnrin náà Fún Ọmọbìnrin Yìí Lókun
ỌMỌDÉBÌNRIN kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kọ̀wé sí iléeṣẹ́ Watch Tower Society tó wà ní Moldova, tó jẹ́ orílẹ̀-èdè olómìnira kan nínú Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, ó fi ìmọrírì rẹ̀ hàn lórí àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n gbé jáde nínú Jí!, June 8, 1998. Àkọlé àpilẹ̀kọ náà ni “Èyí Tí Mo Yàn Nínú Bàbá Méjì,” tó sọ ìrírí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Armenia.
Ọmọdébìnrin náà sọ pé: “Omijé lé ròrò sí mi lójú nígbà tí mo ń ka àpilẹ̀kọ náà nítorí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn òbí mi kò sì ṣàtakò nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ yẹn. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n fárígá. Nígbà tó di ọdún 1997, tí mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sọ àwọn ohun tí mo ń kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, wọ́n bá sọ fún mi pé: ‘Kóo yáa kó ẹrù ẹ tọ àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ ẹ lọ kí wọ́n máa bọ́ ẹ, kí wọ́n máa raṣọ sí ẹ lọ́rùn, kí wọ́n sì wáṣẹ́ fún ẹ. Aláìgbọràn ọmọ ni ẹ́!’ Àwọn òbí mi ò tiẹ̀ sọ pé àwọn ò ṣe mí léṣe, àní wọ́n sẹ orí mi mọ́ ògiri.
“Àdánwò ńlá lèyí jẹ́ fún mi. Mo sábà máa ń nímọ̀lára bíi ti ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Armenia yẹn, tó sọ pé òun máa ń ṣe kàyéfì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bóyá inú Jèhófà dùn sí òun. Mo rò nínú ara mi pé, ‘Àbí mi ò já mọ́ nǹkankan ni? Ǹjẹ́ Jèhófà á dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi àtijọ́ jì mí? Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi mọ́?’
“Nǹkan kì í rọgbọ fún mi, pàápàá ní àwọn ìgbà tí mo bá ń ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́. Ìgbà gbogbo tí mo bá ń gbàdúrà ni mo máa ń bẹ Jèhófà, pẹ̀lú omijé lójú, pé kó ràn mí lọ́wọ́, pé kó fún mi lókun kí n má bàa fi í sílẹ̀. Mo sì rí i lóòótọ́ pé Jèhófà gbọ́ àdúrà mi, ó sì dáhùn ẹ̀bẹ̀ mi. Ó mẹ́sẹ̀ mi dúró, kò jẹ́ kí n yẹsẹ̀, ó sì ki mí láyà. Ní pàtàkì, ó ṣe èyí nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, níbi tí onísáàmù ti fi ìgbọ́kànlé sọ pé: ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.’—Sáàmù 27:10.
“Ní September 27, 1997, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn sí Jèhófà nígbà tí mo ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Kagul. Mo wá rí i kedere pé Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, máa ń mú ìlérí tó ṣe nínú Sáàmù 84:11 ṣẹ, ó sọ níbẹ̀ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ oòrùn àti apata; ojú rere àti ògo ni ó ń fi fúnni. Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.’
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Armenia yẹn tó sọ ìtàn rẹ̀ tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun nínú ìwé ìròyìn Jí! Mo nírètí pé lọ́jọ́ kan, àwọn òbí mi àti àwọn òbí ọmọkùnrin náà yóò wá fìfẹ́ hàn sí àwọn ohun tí Bíbélì ń kọ́ni.”