Àwòrán Tí Kò Lè Gbàgbé
Ó TI lé ní ogún ọdún báyìí tí Karen ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ bàbá rẹ̀ kò gbà á láyè rí láti bá òun sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. Àmọ́, láìpẹ́ yìí, nǹkan yí dà o. Bàbá náà pẹ́ díẹ̀ ní ọsibítù kan tó ti ń gbàtọ́jú lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Lọ́jọ́ kan, tí gbogbo nǹkan tojú sú u, ó ka ìwé ìròyìn kan látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Àyà rẹ̀ já. Nígbà tó wá padà délé, ó ké pe ọmọ rẹ̀. Karen tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní: “Lórí fóònù, Dádì sọ fún mi pé, ‘Karen, ayé ti bà jẹ́ o.’ Inú bí i gan-an nítorí ìwà àìdáa táwọn èèyàn ń hù sáwọn ọmọdé.
“Kí n tiẹ̀ tó ráyè fún un níṣìírí, ṣe ló kàn sọ pé: ‘Àwọn obìnrin méjì wá sílé mi lónìí. Inú ọgbà mi tó wà lẹ́yìnkùlé ni mo máa ń wà, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe kòńgẹ́ mi nígbà tí mo yọjú síwájú ilé. Ọ̀kan lára wọ́n fi àwòrán ọgbà mèremère kan hàn mí. Mo fẹ́ sọ fún un pé, “Ò bá wá wo ẹ̀yìnkùlé mi—ọgbà mèremère ni,” ṣùgbọ́n mi ò sọ bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ló wá sọ pé láìpẹ́ àlàáfíà yóò wà kárí ayé. Ó sọ pé ṣe ni yóò rí bí ọgbà tóun fi hàn mí yẹn, tí kálukú yóò gbádùn. Mi ò gba ìwé náà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n lọ, àwòrán yẹn ò kúrò lọ́kàn mi. Mo kàn ń ronú nípa rẹ̀ ṣáá ni àti nípa èrò náà pé gbogbo èèyàn á wà lálàáfíà. Ǹjẹ́ o mọ ìwé tí mò ń sọ? Ǹjẹ́ o lè bá mi wá ẹ̀dà kan rẹ̀?’”
Inú Karen dùn láti bá bàbá rẹ̀ wá ẹ̀dà kan ìwé náà. Àwòrán tí bàbá rẹ̀ ń sọ ni eléyìí tí o ń wò yìí. Orúkọ ìwé náà ni Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí Bíbélì pé láìpẹ́ Ọlọ́run yóò sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di ọgbà ńlá níbi táwọn èèyàn yóò máa gbé lálàáfíà? O lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ìwé yìí gbà nípa kíkọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sí ojú ìwé karùn-ún nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, gbà.
Sọ èdè tí o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.