ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 11/8 ojú ìwé 12-16
  • Títọ́mọ Ní Áfíríkà Lákòókò Tí Nǹkan Ò Rọgbọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títọ́mọ Ní Áfíríkà Lákòókò Tí Nǹkan Ò Rọgbọ
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Forí Lé Áfíríkà, Mo Lọ́kọ
  • A Kó Lọ sí Ìhà Gúúsù Rhodesia
  • Wọ́n Sọ Èmi àti Bertie Sẹ́wọ̀n
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Lẹ́yìn Tí Ogun Parí
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Àyànfúnni Tuntun
  • Ewu Tí A Dojú Ko Nígbà Táà Ń Padà Lọọlé
  • Ọlọ́run Fi Ìdílé Onífẹ̀ẹ́ Jíǹkí Wa
  • Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé fún Mi Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Didagbasoke Pẹlu Eto-ajọ Jehofa ni South Africa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Mo Gbádùn ‘Ìgbésí Ayé Ìsinsìnyí’ Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Mo Ti Rí i Pé Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Nígbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 11/8 ojú ìwé 12-16

Títọ́mọ Ní Áfíríkà Lákòókò Tí Nǹkan Ò Rọgbọ

BÍ CARMEN MCLUCKIE ṢE SỌ Ọ́

Ní ọdún 1941 ni. Ogun Àgbáyé Kejì ń jà lọ́wọ́. Mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, mo sì ti bímọ, Ọsirélíà ni mo ti wá, ṣùgbọ́n inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni èmi àti ọmọ oṣù márùn-ún tí mo ń tọ́ lọ́wọ́ wà ní Gwelo, Gúúsù Rhodesia (tó ń jẹ́ Gweru, Zimbabwe nísinsìnyí). Ọkọ mi ń ṣẹ̀wọ̀n ní Salisbury (tó ń jẹ́ Harare nísinsìnyí). Àwọn ọmọ ọkọ mi méjì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba ni wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọ wa yòókù—ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún méjì, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe bá ara mi nínú ipò yìí.

ÈMI àti Mọ́mì àti Dádì la jọ ń gbé ní Port Kembla, tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sí gúúsù Sydney, Ọsirélíà. Ní ọdún 1924, Clare Honisett ké sí Màmá, ó ru ìfẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sókè nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó lóye ohun tí Àdúrà Olúwa túmọ̀ sí. Clare ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, ó sì sọ nípa bí Ìjọba náà yóò ṣe mú ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. (Mátíù 6:9, 10) Ẹnu ya Mọ́mì gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bàbá ṣàtakò, Mọ́mì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèwádìí tó jinlẹ̀ nípa àwọn òtítọ́ Bíbélì wọ̀nyẹn.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, a kó lọ sí àgbègbè kan lẹ́bàá ìlú Sydney. Láti ibẹ̀ ni èmi àti Mọ́mì ti máa ń rin ìrìn nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bàbá ò di Ẹlẹ́rìí, ó jẹ́ kí wọ́n máa ṣe àwọn ìpàdé tí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé wa. Méjì lára àwọn àbúrò rẹ̀—Max àti Oscar Seidel—di Ẹlẹ́rìí, bákan náà ni díẹ̀ lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé Max àti àbúrò mi ọkùnrin, Terry, àti àbúrò mi obìnrin, Mylda di Ẹlẹ́rìí.

Ní ọdún 1930, Watch Tower Society ra ọkọ̀ ojú omi kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ mítà mẹ́rìndínlógún, tí wọ́n wá yí orúkọ rẹ̀ padà sí Olùtànmọ́lẹ̀. Odidi ọdún méjì ni wọ́n fi dá ọkọ̀ náà ró sínú Odò Georges tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wa. Ibẹ̀ ni wọ́n ti tún un ṣe kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bàa lè máa rí i lò nínú iṣẹ́ ìwàásù wa ní àwọn erékùṣù Indonesia. Èmi àti àbúrò mi obìnrin, Coral máa ń tún àwọn yàrá inú ọkọ̀ náà àti òkè rẹ̀ ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a sì máa ń yá àtùpà orí òpó ọkọ̀ náà gbé lọ pa edé.

Mo Forí Lé Áfíríkà, Mo Lọ́kọ

Ètò ọrọ̀ ajé Ọsirélíà jó rẹ̀yìn ní àárín àwọn ọdún 1930, èmi àti Mọ́mì sì gbéra lọ sí Gúúsù Áfíríkà láti lọ wò ó bóyá ìdílé wa á lè fi ibẹ̀ ṣelé. A gba lẹ́tà kan tó ṣàlàyé nípa wa dání láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà, a mú un fún George Phillips, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní ìhà gúúsù Áfíríkà nígbà yẹn. George ti ń dúró de ọkọ̀ wa ní ibùdókọ̀ tó wà ní Cape Town ká tó débẹ̀. Ó fi ìwé Ọrọ tí Watch Tower Society ṣe há abíyá kí a lè dá a mọ̀. Lọ́jọ́ yẹn, ní June 6, 1936, ó fi wá han àwọn márùn-ún tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka náà, Robert A. McLuckie jẹ́ ọ̀kan lára wọn.a Láàárín ọdún yẹn, èmi àti Bertie—bí gbogbo wa ṣe ń pè é nígbà yẹn—ṣègbéyàwó.

Bàbá Bertie àgbà, William McLuckie, wá sí Áfíríkà ní ọdún 1817 láti Paisley, ní Scotland. Nígbà tí William bẹ̀rẹ̀ rírìnrìn-àjò kiri, ó di ojúlùmọ̀ Robert Moffat, ọkùnrin tó ṣiṣẹ́ lórí kíkọ èdè Tswana sílẹ̀, tó sì tú Bíbélì sí èdè yẹn.b Ní ìgbà yẹn lọ́hùn-ún, William àti ẹnì kejì rẹ̀ Robert Schoon nìkan ni òyìnbó tí Mzilikazi fọkàn tán, Mzilikazi yìí ni jagunjagun kan tó gbajúmọ̀ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun olóyè Zulu tó lókìkí náà, Shaka. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé William àti Robert nìkan ni òyìnbó tí wọ́n gbà láyè láti máa wọ abúlé Mzilikazi, níbi tí ìlú Pretoria, ní Gúúsù Áfíríkà, wà lónìí. Nígbà tó yá, Mzilikazi di òṣèlú, ó sì so ẹ̀yà púpọ̀ ṣọ̀kan di ilẹ̀ ọba àárín gbùngbùn Áfíríkà ní àárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún.

Opó ni Bertie nígbà tí mo mọ̀ ọ́n, nígbà yẹn, ó ní ọmọbìnrin kan, ìyẹn Lyall ọmọ ọdún méjìlá, àti ọmọkùnrin kan, Donovan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá. Ọdún 1927 ni Bertie ti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, ní oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀, Edna, kú. Láàárín ọdún mẹ́sàn-án tó tẹ̀ lé e, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn erékùṣù Mauritius àti Madagascar àti káàkiri Nyasaland (tó ń jẹ́ Màláwì nísinsìnyí), Ìlà Oòrùn Áfíríkà tí àwọn Potogí ń ṣàkóso (tó ń jẹ́ Mòsáńbíìkì nísinsìnyí), àti Gúúsù Áfíríkà.

Lẹ́yìn oṣù mélòó kan tí èmi àti Bertie ṣègbéyàwó, a kó lọ sí Johannesburg, pẹ̀lú Lyall àti Donovan, níbi tí Bertie á ti tètè ríṣẹ́. Fún ìgbà díẹ̀, mo ń ṣiṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, bí a ṣe ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni mo lóyún Peter.

A Kó Lọ sí Ìhà Gúúsù Rhodesia

Nígbà tó yá, ẹ̀gbọ́n Bertie ọkùnrin tó ń jẹ́ Jack ní ká wá máa bá òun ṣiṣẹ́ wíwa góòlù nítòsí Filabusi, ní ìhà Gúúsù Rhodesia. Èmi àti Bertie lọ síbẹ̀, a gbé Peter, tó jẹ́ ọmọ ọdún kan nígbà yẹn, dání lọ, màmá mi sì ń bá wa tọ́jú Lyall àti Donovan títí a fi máa padà dé. Nígbà tí a dé Odò Mzingwani, ó ti kún àkúnya, àpótí kan tí wọ́n gbé kọ́ okùn ni a wọ̀ kọjá rẹ̀, wọ́n ta okùn kọjá orí odò náà, wọ́n sì ń wọ́ àpótí náà lára okùn náà títí ó fi dé òdì kejì. Oyún Pauline ti pé oṣù mẹ́fà nínú mi nígbà yẹn, ńṣe ni mo wa Peter mọ́ àyà pinpin! Ó bani lẹ́rù gan-an, pàápàá nígbà tí okùn náà fẹ́rẹ̀ẹ́ kan omi lágbedeméjì odò náà. Ó tún ṣẹlẹ̀ pé àárín òru la wà nígbà yẹn, òjò sì ń pọn mùúmùú! Lẹ́yìn tí a sọdá odò náà, a rin ìrìn bíi kìlómítà méjì kí a tó dé ilé ìbátan wa kan.

Nígbà tó pẹ́ díẹ̀, a rẹ́ǹtì ògbólógbòó ahéré ọ̀sìn ẹṣin kan tí ikán ti bà jẹ́. Àwọn àga ìjókòó wa ò fi bẹ́ẹ̀ dára—pákó àwọn àpótí tí wọ́n fi ṣe ohun abúgbàù àti ibi tí a ti ń tanná mànàmáná la fi ṣe àwọn kan lára wọn. Gbogbo ìgbà ni Pauline ń ní ìṣòro àtimí dáadáa, a ò sì rówó ra oògùn. Ọkàn mi bà jẹ́, àmọ́ a dúpẹ́ pé Pauline máa ń yè é ní gbogbo ìgbà tó bá ní ìṣòro náà.

Wọ́n Sọ Èmi àti Bertie Sẹ́wọ̀n

Ẹ̀ẹ̀kan lóṣù la máa ń lọ sí ìlú Bulawayo, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà síbi táa wà, láti lọ ta góòlù wa ní báńkì. A tún máa ń lọ sí Gwanda, ìlú kékeré kan tó wà nítòsí Filabusi, láti lọ ra èlò oúnjẹ àti láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ní ọdún 1940, ọdún tó tẹ̀ lé ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa ní Gúúsù Rhodesia.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n mú mi níbi tí mo ti ń wàásù ní Gwanda. Nígbà yẹn, oyún ọmọ mi kẹta, Estrella, ló wà nínú mi. Nígbà tí wọ́n ń gbé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn mi yẹ̀ wò lọ́wọ́, wọ́n mú Bertie nítorí pé ó ń wàásù, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n ní Salisbury, tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà síbi tí a ń gbé.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà yẹn nìyí: Peter wà ní ilé ìwòsàn ní Bulawayo, akọ èfù ń ṣe é, a ò sì mọ̀ bóyá yóò yè é. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí Estrella nígbà yẹn ni, ọ̀rẹ́ wa kan sì gbé mi láti ilé ìwòsàn láti lọ fi ọmọbìnrin tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí han Bertie ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí wọ́n fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí mo pè, ọkùnrin oníṣòwò kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íńdíà, ṣàánú mi, ó gba ìdúró mi. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ọlọ́pàá mẹ́ta wá mú mi níbi ìwakùsà wa láti lọ tì mí mọ́lé. Wọ́n ní kí n yan bí mo bá ṣe fẹ́ ṣẹ̀wọ̀n mi. Yálà kí n gbé ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ oṣù márùn-ún lọ sí ẹ̀wọ̀n tàbí kí n gbé e fún àwọn ọmọ wa tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba, Lyall àti Donovan, láti máa tọ́jú rẹ̀. Mo pinnu láti gbé e lọ.

Iṣẹ́ rírán aṣọ tó ya àti ìtọ́jú àyíká ni wọ́n yàn fún mi. Bákan náà, wọ́n fún mi ní olùtọ́jú ọmọ láti máa bá mi tọ́jú Estrella. Ọ̀dọ́ ni, òun náà ń ṣẹ̀wọ̀n ni, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Matossi, ẹ̀wọ̀n gbére ni wọ́n fi í sí nítorí pé ó pa ọkọ rẹ̀. Matossi sunkún nígbà tí wọn tú mi sílẹ̀, nítorí kò ní rí Estrella tọ́jú mọ́. Obìnrin wọ́dà wa mú mi lọ sílé rẹ̀ láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán, lẹ́yìn náà, ó fi mí lé ọkọ̀ ojú irin kí n lè lọ wo Bertie nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Salisbury.

Nígbà tí èmi àti Bertie wà lẹ́wọ̀n, Lyall àti Donovan ló ń tọ́jú àwọn ọmọ wa kéékèèké méjèèjì, Peter àti Pauline. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni Donovan nígbà yẹn, ó ń ṣe iṣẹ́ ìwakùsà wa lọ. Nígbà tí wọ́n tú Bertie sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, a pinnu láti kó lọ sí Bulawayo, nítorí pé iṣẹ́ ìwakùsà wa kò lọ dáadáa mọ́. Bertie rí iṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ rélùwéè, èmí sì ń ṣe iṣẹ́ aránṣọ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ láti mú kí owó tí ń wọlé fún wa lè gbé pẹ́ẹ́lí sí i.

Wọ́n ka iṣẹ́ títo irin pọ̀ tí Bertie ń ṣe pẹ̀lú ilé iṣẹ́ rélùwéè sí pàtàkì, nítorí náà wọn ò kó o mọ́ àwọn tó ń lọ fún iṣẹ́ ológun. Láàárín àwọn ọdún tí ogun ń jà yẹn, àwọn òyìnbó bíi méjìlá tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Bulawayo máa ń wá ṣèpàdé nínú iyàrá kóńkó tí a ń gbé, díẹ̀ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ adúláwọ̀ sì ń pàdé níbòmíràn láàárín ìlú. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ti lé ní ìjọ mẹ́rìndínláàádọ́ta tó wà ní Bulawayo, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àtòyìnbó àtadúláwọ̀, wà!

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Lẹ́yìn Tí Ogun Parí

Lẹ́yìn tí ogun parí, Bertie ní kí ilé iṣẹ́ rélùwéè gbé òun lọ sí Umtali (tó ń jẹ́ Mutare nísinsìnyí), ìlú dáadáa kan tó sún mọ́ ààlà Mòsáńbíìkì. A ti ń fẹ́ sìn ní ibi tí àìní fún àwọn oníwàásù Ìjọba gbé pọ̀, ó sì jọ pé Umtali ló dára jù, nítorí kò sí Ẹlẹ́rìí kankan ní ìlú náà. Láàárín àkókò díẹ̀ tí a lò níbẹ̀, ìdílé Holtshauzen, tí wọ́n ní ọmọkùnrin márùn-ún, di Ẹlẹ́rìí. Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ìjọ mẹ́tàlá ló ti wà ní ìlú yẹn!

Ní ọdún 1947, ìdílé wa jíròrò nípa bóyá kí Bertie tún gba iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan sí i. Lyall, tó fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀ tó sì padà wálé láti Gúúsù Áfíríkà, fọwọ́ sí èrò yẹn. Donovan ń ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Gúúsù Áfíríkà nígbà yẹn. Lọ́rọ̀ kan ṣá, nígbà tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Cape Town gbọ́ pé Bertie tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, wọ́n ní kó kúkú ṣí ibi tí wọ́n lè máa já ẹrù ìwé sí ní Bulawayo. Nítorí náà, ó kọ̀wé fiṣẹ́ rélùwéè sílẹ́, a sì kó padà síbẹ̀. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wá sí Gúúsù Rhodesia gúnlẹ̀ sí Bulawayo, lára wọn ni Eric Cooke, George àti Ruby Bradley, Phyllis Kite, àti Myrtle Taylor.

Ní ọdún 1948, Nathan H. Knorr, ààrẹ kẹta Watch Tower Society, àti akọ̀wé rẹ̀, Milton G. Henschel, ṣèbẹ̀wò sí Bulawayo, wọ́n sì ṣètò pé kí a sọ ibi ìjáwèésí náà di ẹ̀ka ilé iṣẹ́, kí Arákùnrin Cooke sì jẹ́ alábòójútó ibẹ̀. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni a bí ọmọbìnrin wa, Lindsay. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ní ọdún 1950, wọ́n kó ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà lọ sí Salisbury, olú ìlú Gúúsù Rhodesia, àwa náà sì kó lọ síbẹ̀. A ra ilé ńlá kan tí a gbé fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn aṣáájú ọ̀nà àti àwọn àlejò sábà máa ń dé sọ́dọ̀ wa, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ilé wa ní òtẹ́ẹ̀lì McLuckie!

Ní ọdún 1953, èmi àti Bertie lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Pápá Ìṣeré Yankee tó wà ní New York City. Àkókò mánigbàgbé gbáà ló jẹ́! Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, Lyall, Estrella, Lindsay, àti Jeremy tó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́rìndínlógún nígbà yẹn bá wa lọ sí ìpàdé ńlá ọlọ́jọ́ mẹ́jọ náà, ìyẹn ni àpéjọpọ̀ àgbáyé ti ọdún 1958 tí a ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee àti Ibi Ìṣeré Ìdárayá Polo tí kò jìnnà síbẹ̀. Fún ìgbà àkọ́kọ́, iye àwọn tó wá gbọ́ àsọyé ní ọjọ́ tó kẹ́yìn ìpàdé náà lé ní ìdá mẹ́rin mílíọ̀nù kan!

Iṣẹ́ Ìwàásù Àyànfúnni Tuntun

Ọdún mẹ́rìnlá ni Bertie fi ń ti ilé lọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Salisbury, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, a wá pinnu láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní Seychelles. A ta ilé àti àwọn ẹrù wa mìíràn, a sì di àwọn ẹrù wa yòókù sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa gígùn tó jẹ́ ẹ̀yà Opel. Àwa àti Lindsay, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá àti Jeremy, tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún nígbà yẹn rìnrìn àjò nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kìlómítà lójú ọ̀nà jágajàga tó jẹ́ eléruku, a gba Àríwá Rhodesia (tó ń jẹ́ Zambia nísinsìnyí), Tanganyika (tó jẹ́ apá kan Tanzania nísinsìnyí), àti Kẹ́ńyà kọjá, a sì gúnlẹ̀ sí ìlú Mombasa, tí àwọn ọkọ̀ òkun máa ń gúnlẹ̀ sí.

Ooru pọ̀ gan-an ní Mombasa, ṣùgbọ́n àwọn etíkun rẹ̀ wuni. A gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa sọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan níbẹ̀, a sì gbéra ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta lọ sí Seychelles nínú ọkọ̀ ojú omi. Nígbà tí a débẹ̀, a pàdé Norman Gardner, ọkùnrin náà ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìpìlẹ̀ òtítọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan ní Dar es Salaam, ní Tanganyika. Ó ṣètò bí a ṣe rẹ́ǹtì ilé tó wà ní Ibi Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Àárín Òkè Sans Souci tí wọ́n kọ́ fún ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Makarios ti Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Gíríìkì, tí wọ́n lé kúrò ní Kípírọ́sì ní ọdún 1956.

Nítorí pé ilé wa wà níbi àdádó, lẹ́yìn tí a lo oṣù kan níbẹ̀, a kó lọ sí ilé kan níwájú òkun Beau Vallon. A ké sí àwọn èèyàn ibẹ̀ wá gbọ́ àwọn àsọyé tí Bertie sọ ní iwájú ilé wa. A bẹ̀rẹ̀ sí bá tọkọtaya Bindschedler ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lẹ́yìn oṣù mélòó kan, Bertie ṣèrìbọmi fún àwọn àti ọmọbìnrin tí wọ́n gbà ṣọmọ, àti Norman Gardner àti ìyàwó rẹ̀. A tún bá Norman lọ sí Erékùṣù Cerf nínú ọkọ̀ ojú omi rẹ̀, Bertie sì sọ àsọyé Bíbélì nínú ilé kan tí wọ́n ń tọ́jú ọkọ̀ sí.

Nígbà tí a ti lò tó nǹkan bí oṣù mẹ́rin ní Seychelles, ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá sọ pé kí a yé wàásù, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn á lé wa kúrò nílùú àwọn. A ò lówó lọ́wọ́, mo sì tún ti lóyún. A pinnu láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ nílùú náà. Ó ṣe tán, a mọ̀ pé a ò ní pẹ́ lọ. Nígbà tí ọkọ̀ ojú omi mìíràn sì dé láti Íńdíà ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn náà, wọ́n lé wa kúrò nílùú wọn.

Ewu Tí A Dojú Ko Nígbà Táà Ń Padà Lọọlé

Nígbà tí a padà dé Mombasa, a lọ gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, a sì gba ọ̀nà oníyanrìn tó sún mọ́ etíkun lọ sí gúúsù. Nígbà tí a dé Tanga, ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa kọṣẹ́. Owó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán lọ́wọ́ wa, ṣùgbọ́n ìbátan wa kan àti Ẹlẹ́rìí mìíràn ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí a wà ní Mombasa, arákùnrin kan sọ pé òun á fowó ràn wá lọ́wọ́ tí a bá lè lọ wàásù ní Sòmálíà tó wà ní ìhà àríwá. Àmọ́ ara mi ò fi bẹ́ẹ̀ yá, nítorí náà ká sáà ti dé ilé wa ní Gúúsù Rhodesia ló wà lọ́kàn wa.

A gba Tanganyika sọdá sí Nyasaland, a sì gbéra lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn Adágún Nyasa, tí wọ́n ń pè ní Adágún Màláwì nísinsìnyí. Àìsàn tó kì mí mọ́lẹ̀ le débi pé mo ní kí Bertie gbé mi sọ sí ẹ̀gbẹ́ títì kí n kú síbẹ̀! A ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ìlú Lilongwe, ó sì gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn níbẹ̀. Wọ́n fún mi ní abẹ́rẹ́ apàrora to mú kí ara mi balẹ̀ díẹ̀. Níwọ̀n bí ara mi ò ti yá tó láti máa bá ìrìn àjò náà lọ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, Bertie àti àwọn ọmọ ń bá ìrìn àjò náà nìṣó nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ sí Blantyre tó jẹ́ nǹkan bí irínwó kìlómítà. Ìbátan wa kan ṣètò fún mi láti wọkọ̀ òfuurufú lọ bá wọn níbẹ̀ ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà. Láti Blantyre, ọkọ̀ òfuurufú gbé mi padà sí Salisbury, Bertie àti àwọn ọmọ sì fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rin ìyókù ìrìn àjò náà délé.

Ara tu gbogbo wa gan-an nígbà tí a dé Salisbury nílé ọmọ wa obìnrin, Pauline àti ọkọ rẹ̀! Ní ọdún 1963, a bí àbíkẹ́yìn wa, Andrew. Ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ sún kì, a ò sì rò pé ó lè yè é, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé ó yè é. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a kó lọ sí Gúúsù Áfíríkà, a sì fìdí kalẹ̀ sí Pietermaritzburg níkẹyìn.

Ọlọ́run Fi Ìdílé Onífẹ̀ẹ́ Jíǹkí Wa

Ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún ni Bertie nígbà tó fọwọ́ rọrí kú ní ọdún 1995, èmi nìkan ni mo sì ń gbé ilé wa níhìn-ín láti ìgbà yẹn. Àmọ́, mi ò dá wà! Lyall àti Pauline ń sin Jèhófà pẹ̀lú ìdílé wọn níhìn-ín ní Gúúsù Áfíríkà, àwọn kan lára wọ́n sì ń gbé níhìn-ín ní Pietermaritzburg. Lindsay àti ìdílé rẹ̀ wà ní California, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Ẹlẹ́rìí hán-únhán-ún sì ni gbogbo wọn níbẹ̀. Àwọn ọmọ wa méjì tó kéré jù, Jeremy àti Andrew, kó lọ sí Ọsirélíà, àwọn méjèèjì ń láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn, wọ́n sì ń sìn bí alàgbà nínú ìjọ wọn.

Gbogbo àwọn ọmọ wa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ló ti kópa rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lákòókò kan tàbí òmíràn, mẹ́fà lára wọ́n sì ti sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society. Donovan kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní kíláàsì kẹrìndínlógún ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní February 1951, ó sì sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kó tó padà lọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní Gúúsù Áfíríkà. Kristẹni alàgbà ni báyìí, ó wà ní Klerksdorp, tó jẹ́ nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] kìlómítà sí Pietermaritzburg. Estrella pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Jack Jones, wà ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York.

Peter tó jẹ́ àkọ́bí mi lo ọdún mélòó kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower tó wà ní Rhodesia. Àmọ́, inú mi bà jẹ́ lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn nígbà tí kò dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni mọ́.

Nígbà tí mo ronú bí ìgbésí ayé mi ṣe lọ, mo lè sọ pé inú mi dùn gidigidi pé mo bá màmá mi lọ sí Áfíríkà nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba. Lóòótọ́, ìgbésí ayé ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àǹfààní fún mi láti ṣètìlẹ́yìn fún ọkọ mi àti láti bójú tó ìdílé tó ṣèrànwọ́ láti fìdí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ ní gúúsù Áfíríkà.—Mátíù 24:14.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn ti Robert McLuckie fúnra rẹ̀ wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1990, ojú ìwé 26 sí 31.

b Wo ojú ìwé kọkànlá ìwé pẹlẹbẹ Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

Cape Town

Pietermaritzburg

Klerksdorp

Johannesburg

Pretoria

ZIMBABWE

Gwanda

Bulawayo

Filabusi

Gweru

Mutare

Harare

ZAMBIA

MÒSÁŃBÍÌKÌ

MÀLÁWÌ

Blantyre

Lilongwe

TANZANIA

Dar es Salaam

Tanga

KẸ́ŃYÀ

Mombasa

SEYCHELLES

Erékùṣù Cerf

SÒMÁLÍÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Èmi àti Peter, Pauline, àti Estrella, kí n tó gbé Estrella lọ ṣẹ̀wọ̀n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Lyall àti Donovan níwájú ahéré táa ti ń sin ohun ọ̀sìn nítòsí Filabusi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Èmi àti Bertie, Lyall, Pauline, Peter, pẹ̀lú Donovan ní ọdún 1940

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Carmen àti márùn-ún lára àwọn ọmọ rẹ̀ (láti apá òsì yí po lọ sọ́tùn-ún): Donovan, nígbà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ọdún 1951, àti Jeremy, Lindsay, Estrella, àti Andrew lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́