ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 11/8 ojú ìwé 8-11
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Èé Ṣe Tó Fi Léwu Gan-an?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Èé Ṣe Tó Fi Léwu Gan-an?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtàn Tó Ń Lani Lóye
  • Orísun Tó Léwu
  • Bí Oògùn “Oríire” àti Ìbọ̀rìṣà Ṣe Bára Tan
  • Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Nípa Ọjọ́ Iwájú
  • Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
  • Ǹjẹ́ Gbígba Ohun Asán Gbọ́ Bá Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Mu?
    Jí!—2008
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Kí Ló Dé Tí Ò Kásẹ̀ Ńlẹ̀?
    Jí!—1999
  • Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìdáàbòbò Gidi Ha Ṣeéṣe Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 11/8 ojú ìwé 8-11

Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Èé Ṣe Tó Fi Léwu Gan-an?

ǸJẸ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lè pa ọ́ lára? Àwọn kan lè fọwọ́ rọ́ ọ̀rọ̀ yìí dà nù tàbí kí wọ́n fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ewu tó wà nídìí ẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọ̀jọ̀gbọ́n Stuart A. Vyse kìlọ̀ nínú ìwé rẹ̀ Believing in Magic—The Psychology of Superstition pé: “Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lè sọ ayé ẹni di rádaràda báa bá ń ná owó gọbọi fún àwọn abẹ́mìílò, àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn tí ń fi nọ́ńbà woṣẹ́, tàbí àwọn tí ń fi káàdì woṣẹ́, tàbí tí àwọn ohun asán téèyàn gbà gbọ́ bá jẹ́ kó nira láti jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa.” Jíjẹ́ kí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣàkóso ìgbésí ayé wa lè yọrí sí àwọn ohun tó burú jáì.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, ọ̀pọ̀ ohun asán tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ ló wà fún lílé ìbẹ̀rù nípa ọjọ́ iwájú jìnnà. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀yàtọ̀ tó wà láàárín ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìmọ̀ tó ṣeé gbíyè lé nípa ohun tí a ń retí lọ́jọ́ iwájú. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.

Ìtàn Tó Ń Lani Lóye

Ní ọdún 1503, lẹ́yìn tí Christopher Columbus ti lọ káàkiri fún oṣù mélòó kan ní etíkun Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, ló tó jàjà gúnlẹ̀, pẹ̀lú ọkọ̀ méjì tó kù lára àwọn tó kó lọ, sí etíkun tí a wá mọ̀ sí erékùṣù Jàmáíkà lónìí. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn olùgbé erékùṣù náà kò foúnjẹ ṣahun sí àwọn olùyẹ̀wòkiri tó tàn náà. Àmọ́, bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìwàkiwà táwọn atukọ̀ náà ń hù mú kí àwọn olùgbé erékùṣù náà yé fún wọn lóúnjẹ. Ọ̀ràn náà le gan-an fún wọn, nítorí pé á pẹ́ díẹ̀ kí ọkọ̀ mìíràn tó dé láti gbà wọ́n sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ṣe lọ, Columbus wo ìwé ìsọfúnni rẹ̀ nípa ojú ọjọ́, ó sì rí i pé oòrùn yóò ṣíji bo òṣùpá pátápátá ní February 29, 1504. Ó pe ajá lọ́bọ fún àwọn olùgbé erékùṣù náà tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ohun asán, ó kìlọ̀ fún wọn pé òkùnkùn á bo òṣùpá mọ́lẹ̀ àyàfi tí wọ́n bá kó oúnjẹ wá fún agbo òṣìṣẹ́ òun. Àwọn olùgbé erékùṣù náà kọtí ikún sí ìkìlọ̀ rẹ̀—àfìgbà tí òkùnkùn bẹ̀rẹ̀ sí ṣú bo òṣùpá! Nígbà náà, “pẹ̀lú igbe ńlá àti ìpohùnréré ẹkún,” wọ́n “ń gbọ̀tún kó oúnjẹ wá, wọ́n sì ń gbòsì kó oúnjẹ wá sínú àwọn ọkọ̀ náà títí wọ́n fi kún fọ́fọ́.” Ńṣe ni wọ́n ń kó oúnjẹ wá fún àwọn olùyẹ̀wòkiri náà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà níbẹ̀.

Lójú àwọn olùgbé erékùṣù náà, iṣẹ́ ìyanu ńlá kan ni Columbus ṣe. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n gba ohun asán gbọ́ ló jẹ́ kí wọ́n ronú bẹ́ẹ̀. Ní gidi, orí ohun tó gbé “àsọtẹ́lẹ̀” yẹn kà ni bí ayé, òṣùpá, àti oòrùn ṣe ń yí, lọ́nà tí kì í yẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà lè sàsọtẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ gan-an pé oòrùn yóò ṣíji bo òṣùpá lọ́nà tó ṣeé gbíyè lé, àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí sì máa ń wà nínú àwọn ìwé ìsọfúnni nípa ojú ọjọ́. Síwájú sí i, ìyíkiri ìṣẹ̀dá inú sánmà ló ń mú kí àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà lè sọ ibi tí wọ́n wà gangan ní àkókò kan pàtó. Ìdí nìyẹn tóo fi máa ń gbà ohun tí ìwé ìròyìn rẹ sọ gbọ́ nígbàkigbà tó bá kéde ìgbà tí oòrùn yóò yọ tàbí ìgbà tí yóò wọ̀.

Ohun tí a ń wí ni pé, Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run ni orísun ìsọfúnni táwọn èèyàn ń tẹ̀ jáde nípa ìgbà tí oòrùn ń ṣíji bo òṣùpá, ìgbà tí oòrùn ń yọ, àti ìgbà tó ń wọ̀. Ṣùgbọ́n ibi tó yàtọ̀, tí Ọlọ́run Olódùmarè lòdì sí, ni orísun àsọtẹ́lẹ̀ àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn abẹ́mìílò, àwọn tí ń woṣẹ́ lójú ọpọ́n, àti àwọn tí ń fi káàdì woṣẹ́. Gbé ohun tí a ní lọ́kàn yẹ̀ wò.

Orísun Tó Léwu

Nínú Ìṣe 16:16-19, àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ náà ròyìn pé, “ìránṣẹ́bìnrin kan” wà ní Fílípì, ìlú àtijọ́ náà, tó máa ń mú èrè gọbọi wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀ nípa “fífi ìsọtẹ́lẹ̀ ṣiṣẹ́.” Ohun yòówù kó jẹ́, àkọsílẹ̀ náà sọ ní kedere pé, kì í ṣe Ẹlẹ́dàá alágbára ńlá gbogbo ló ń fún un lágbára tó fi ń sàsọtẹ́lẹ̀, bí kò ṣe “ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́.” Nítorí náà, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ìránṣẹ́bìnrin náà, agbára ìsàsọtẹ́lẹ̀ tó ní pòórá.

Tí a bá mọ̀ pé irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn wá láti orísun tó lọ́wọ́ ẹ̀mí èṣù nínú, àá lóye ìdí tí Òfin Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì fi sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ . . . Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Kódà, Òfin yẹn sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó la ikú lọ ni ṣíṣe irú nǹkan báwọ̀nyẹn.—Léfítíkù 19:31; 20:6.

Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àṣà tó jọ pé kò lè pani lára tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé Sátánì “a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù tí òun ń ṣàkóso lè mú kí àwọn àṣà tó léwu dà bí èyí tí kò lè pani lára, pé wọ́n tilẹ̀ ń ṣàǹfààní. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n lè fúnra wọn fa àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ kan wá, kí wọ́n sì mú kí wọ́n nímùúṣẹ, kí wọ́n wá máa tan àwọn tó ń wò wọ́n jẹ láti máa ronú pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni irú àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wá. (Fi wé Mátíù 7:21-23; 2 Tẹsalóníkà 2:9-12.) Ìdí nìyẹn tí díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àwọn tó ń sọ pé àwọ́n lágbára àrà ọ̀tọ̀ fi máa ń ṣẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ pé àwọn lágbára àrà ọ̀tọ̀, tí kì í bá ṣe gbogbo wọn, ló jẹ́ ẹlẹ́tàn lásánlàsàn, tó ń wá ẹni tí ò fura tí wọ́n máa lo gbájú-ẹ̀ fún. Àmọ́, yálà wọ́n jẹ́ ẹlẹ́tàn tàbí wọn kì í ṣe ẹlẹ́tàn, gbogbo wọn ló jẹ́ ọmọ iṣẹ́ Sátánì tó ń lò láti kẹ̀yìn àwọn èèyàn sí Jèhófà, tó sì ń fọ́ ojú inú wọn kí wọ́n má bàa gbọ́ “ìhìn rere ológo.”—2 Kọ́ríńtì 4:3, 4.

Bí Oògùn “Oríire” àti Ìbọ̀rìṣà Ṣe Bára Tan

Àwọn oògùn “oríire” àti àwọn ààtò ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí àwọn èèyàn fi ń dun ara wọn nínú pé àwọn wà láàbò, tí wọ́n sì gbà pé àwọn fi ń darí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọn kò mọ̀dí rẹ̀ nínú ayé wọn ńkọ́? Ìwọ̀nyí ń fa àwọn ewu bíi mélòó kan tí a kò lè tètè mọ̀. Lọ́nà kan, ó lè wá ṣẹlẹ̀ pé ńṣe lẹni tó gbà gbọ́ nínú ohun asán náà ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìrí ṣàkóso ìgbésí ayé òun. Ó kẹ̀yìn sí ìrònú tó bọ́gbọ́n mu, ó wá yíjú sí ìbẹ̀rù tí kò bọ́gbọ́n mu.

Òǹkọ̀wé kan tọ́ka sí ewu mìíràn tó lè tìdí ẹ̀ yọ. Ó sọ pé: “Bí ẹnì kan bá gbẹ́kẹ̀ lé oògùn oríire kan láti dáàbò bo òun tí oògùn náà ò wá ṣiṣẹ́, ẹni náà lè máa sọ pé àwọn ẹlòmíràn ló ń ṣe [òun], dípò kó gbà pé ohun tí òun fúnrúgbìn lòún ń ká.” (Fi wé Gálátíà 6:7.) Lọ́nà tó gbàfiyèsí, aláròkọ kan tó ń jẹ́ Ralph Waldo Emerson sọ nígbà kan pé: “Àwọn aláìmọ̀kan ló ń gbà gbọ́ nínú oríire . . . Àwọn èèyàn tórí wọ́n pé dáadáa gbà gbọ́ nínú àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá.”

Èròǹgbà “àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá” tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa sábà máa ń fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò mọ̀dí rẹ̀—“ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” tó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. (Oníwàásù 9:11) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò mọ̀dí rẹ̀ kì í ṣe ìyọrísí ìfẹ́ ọkàn àìdájú ti “orí burúkú.” Àwọn Kristẹni mọ̀ pé àwọn ààtò ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àwọn oògùn idán kò ní ipa kankan lórí ìyọrísí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò mọ̀dí rẹ̀. Tí wọ́n bá ṣẹlẹ̀, ó máa ń rán wa létí òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.”—Jákọ́bù 4:14.

Síwájú sí i, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé àwọn èèyàn sábà máa ń júbà fún oògùn oríire àti àwọn ààtò tàbí ìṣe ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Ìdí nìyẹn tí àwọn Kristẹni fi máa ń wo gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bí onírúurú ọ̀nà ìbọ̀rìṣà, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kò dáa.—Ẹ́kísódù 20:4, 5; 1 Jòhánù 5:21.

Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Nípa Ọjọ́ Iwájú

Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ọ̀ràn nípa ọjọ́ iwájú ò kan àwọn Kristẹni o. Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára ìrònú yíyèkooro ń fi hàn kedere pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti mọ ohun tó wà níwájú. Bí a bá ti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀, a lè gbégbèésẹ̀ tó yẹ, tí yóò sì ṣe àwa àti àwọn tí a fẹ́ràn láǹfààní.

Àmọ́, ìdí gidi wà tí a fi ní láti wá ìsọfúnni yìí lọ sọ́dọ̀ ẹni tó yẹ. Wòlíì Aísáyà kìlọ̀ pé: “Àwọn èèyàn á ní kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àti àwọn abẹ́mìílò . . . Kí ẹ dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fetí sí ohun tí Olúwa ń kọ́ yín! Ẹ má ṣe tẹ́tí sí àwọn abẹ́mìílò—ohun tí wọ́n bá sọ fún yín kò ní ṣe yín lóore kankan.’”—Aísáyà 8:19, 20, Today’s English Version.

Orísun ìsọfúnni tòótọ́ tó ṣeé gbíyè lé nípa ọjọ́ iwájú ni Ẹni tó ṣe Bíbélì. (2 Pétérù 1:19-21) Ìwé tó ní ìmísí yìí ní ẹ̀rí tó pọ̀ yanturu pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà, Ọlọ́run alágbára gbogbo sọ ṣeé gbíyè lé—ó dájú pé wọ́n ṣeé gbíyè lé bíi ti ìyíkiri àwọn ìṣẹ̀dá inú òfuurufú tí a “sọ tẹ́lẹ̀” nípa wọn nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwé ìsọfúnni nípa ojú ọjọ́. Láti ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí ìsọfúnni Bíbélì ṣe péye tó, gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò. Jẹ́ ká sọ pé èèyàn ńlá kan lónìí lọ ṣe ìkéde fáráyé gbọ́, ó sì sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní igba ọdún sí àsìkò yìí, ìyẹn ní ọdún 2199. Ara àwọn ohun tó sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ ló tẹ̀ lé e yìí:

◻ Ogun ńlá á bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò tíì di agbára ayé tó ń bára wọn díje ní báyìí, ìyọrísí rẹ̀ yóò sì yí ìtàn padà.

◻ Ọgbọ́n ogun tí wọn yóò lò yóò jẹ́ ọgbọ́n àràmàǹdà tí wọn yóò fi darí odò ńlá kan gba ibòmíràn.

◻ Ó sọ orúkọ ẹni tí yóò ṣẹ́gun náà—ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí i.

◻ Ó ṣàpèjúwe ìgbẹ̀yìn ẹni tí yóò pàdánù nínú ogun náà, tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ náà nasẹ̀ dé ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ń bọ̀.

Bí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí bá ṣẹ, ǹjẹ́ kò ní mú kí àwọn èèyàn máa ronú lé àwọn ohun mìíràn tí ẹni yìí ti sọ nípa ọjọ́ iwájú?

Ohun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàpèjúwe yìí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi. Ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú kí àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà tó gba ìṣàkóso lọ́wọ́ Bábílónì, Jèhófà ti sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà pé:

◻ Mídíà òun Páṣíà yóò bá Bábílónì ja ogun ńlá kan.—Aísáyà 13:17, 19.

◻ Ọgbọ́n ogun tí wọ́n máa lò yóò jẹ́ ti mímú kí odò ńlá kan, tó jìn, tó sì jẹ́ odi ìgbèjà, gbẹ. Ní àfikún sí i, àwọn ẹnubodè ìlú ńlá olódi náà yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀.—Aísáyà 44:27–45:2.

◻ Kírúsì ni a óò pe orúkọ aṣẹ́gun náà—tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ní nǹkan bí àádọ́jọ ọdún kí wọ́n tó bí i.—Aísáyà 45:1.

◻ Bí àkókò ti ń lọ, Bábílónì yóò di ahoro pátápátá.—Aísáyà 13:17-22.

Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ló ṣẹ. Nítorí náà, ǹjẹ́ kò wá yẹ kí o wáyè láti gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tí Jèhófà sọ nínú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò?

Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀? Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run yóò mú wá, àìfọkànbalẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú kò ní sí mọ́ láti máa fìyà jẹ ẹnikẹ́ni. Ṣàkíyèsí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn tí yóò wà láàyè nígbà yẹn, ó wí pé: “Kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú [àwọn èèyàn mi] wárìrì.”—Míkà 4:4.

Bíbélì tún ṣèlérí síwájú sí i pé Ọlọ́run yóò ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀, yóò sì tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’ (Sáàmù 145:16) Ǹjẹ́ ìmúṣẹ ìlérí yẹn yóò ṣì pẹ́ gan-an? Rárá o! Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò yìí ni Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo nǹkan tí a ń rí lórí ilẹ̀ ayé lónìí ló para pọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí.—2 Tímótì 3:1-5.

Láìpẹ́, Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ náà yóò fòpin sí àwọn ohun burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. Òun yóò mú gbogbo ogun, tí í ṣe orísun àìfọkànbalẹ̀ àti ìjìyà jákèjádò ayé, kúrò. Síwájú sí i, ìkórìíra, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìwà ọ̀daràn, àti ìwà ipá yóò di ohun àtijọ́ pátápátá. Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

Lára àwọn ìbùkún tí àwọn èèyàn yóò gbádùn nínú ayé tuntun yẹn ni ìlera pípé. Kódà, ikú àti ìsọǹgbè rẹ̀ tí í ṣe ìbànújẹ́, kò ní sí mọ́. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.

Ní ìgbà yẹn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò mọ̀dí rẹ̀ tó ń yí ìgbésí ayé padà lónìí, tó sì ń pa á run kò ní máa ṣàkóso ẹnikẹ́ni. Àwọn ẹ̀mí èṣù àti Sátánì pàápàá, tó jẹ́ orísun ìbẹ̀rù àti irọ́ burúkú tí a gbé karí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, kò ní sí mọ́. Àwọn òtítọ́ amúniláyọ̀ wọ̀nyí wà nínú Bíbélì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àṣà ìbẹ́mìílò so mọ́ra pẹ́kípẹ́kí

[Credit Line]

Yàtọ̀ sí ti obìnrin tó wà nínú ọpọ́n ìwoṣẹ́: Les Wies/Tony Stone Images

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kò ní sí àṣà gbígba ohun asán gbọ́ nínú ayé tuntun Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́