“Àkókò Oúnjẹ Máa Ń Mú Ká Túbọ̀ Sún Mọ́ra”
ǸJẸ́ ìdílé rẹ máa ń jẹun pa pọ̀, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́? Ó bani nínú jẹ́ pé torí ìgbésí ayé kòó-kòó jàn-án jàn-án tá à ń gbé lónìí, kálukú ló máa ń jẹ oúnjẹ tiẹ̀ lásìkò tó bá wù ú. Síbẹ̀ yàtọ̀ sí pé ohun tó dáa ni kí ìdílé máa jẹun pa pọ̀, ó tún lè ṣàǹfààní míì tó tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó tura, ó sì lè mú kí ìdílé túbọ̀ mọwọ́ ara wọn.
Orílẹ̀-èdè Lithuania tó wà níhà àríwá Yúróòpù ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Algirdas, aya rẹ̀ tó ń jẹ́ Rima àtàwọn ọmọbìnrin wọn mẹ́ta ń gbé. Ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń lọ síbi iṣẹ́, táwọn ọmọbìnrin wa sì ń lọ síléèwé, síbẹ̀ a ṣètò àkókò wa ká lè máa jẹun pa pọ̀. Lásìkò oúnjẹ, gbogbo wa la máa ń sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà, a tún máa ń sọ ìṣòro wa, àwọn ohun tá a bá rò lọ́kàn, ohun tá a fẹ́ ṣe, ohun tó wù wá àtohun tá ò fẹ́. A tún máa ń lo àkókò yìí láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa. Kò síyè méjì pé, àkókò oúnjẹ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra.”
Rima tó jẹ́ aya Algirdas sọ pé: “Bí àwọn ọmọbìnrin wa ṣe máa ń wà lọ́dọ̀ mi bí mo bá ń gbọ́únjẹ tún máa ń jẹ́ ká lè finú han ara wa. Ó máa ń dùn mọ́ àwọn ọmọbìnrin wa pé kí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́ nílé ìdáná, lọ́wọ́ kan náà, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ tó máa wúlò fún wọn. Nípa báyìí, à ń ṣiṣẹ́ a sì tún ń gbádùn ara wa.”
Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni Algirdas, Rima aya rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin wọn ń gbádùn nítorí pé wọ́n ṣètò àkókò láti jọ máa jẹun. Bí ìdílé tìẹ náà ò bá tíì máa jẹun pọ̀, o ò ṣe ṣètò pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ lẹ́ẹ̀kan péré lóòjọ́, kódà kò yọ àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ sílẹ̀. Èrè tó wà ńbẹ̀ pọ̀ ju ìsapá tó gbà lọ.