Aráyé Ń Fẹ́ Ìlera Tó Jíire!
Ó TI lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún báyìí tí wòlíì kan ti sàsọtẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àìsàn ò ní sí mọ́. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí wà títí dòní olónìí, a sì lè rí i nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàanì tí wòlíì Aísáyà kọ. Ó sọ pé àkókò kan ń bọ̀ tí “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí,’” ó wá fi kún un pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 33:24; 35:5, 6) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé máa rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣípayá tó parí Bíbélì, sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run á mú ìrora kúrò.—Ìṣípayá 21:4.
Ṣé àwọn ìlérí yìí á nímùúṣẹ lóòótọ́? Ṣé lóòótọ́ lọjọ́ kan ń bọ̀ tí ara gbogbo ẹ̀dá èèyàn á dá ṣáṣá, tí wọn ò sì ní ṣàìsàn mọ́? Òótọ́ ni pé lóde tòní, ọ̀pọ̀ àìsàn tó ń dá àwọn ará àtijọ́ wólẹ̀ ni kì í rí wa gbé ṣe báyìí. Àmọ́, pé ara èèyàn dá ṣáṣá ò túmọ̀ sí pé àìsàn ò lè ṣe onítọ̀hún mọ́. Àìsàn ò tíì yé fojú aráyé rí màbo. Ìbẹ̀rù kéèyàn má ṣàìsàn lásán ń pa àwọn míì sára. Èyí tó tún wá burú jù níbẹ̀ ni pé lóde tòní yìí pàápàá, kò sẹ́ni tó ṣàgbà àìlera àti ìdààmú ọkàn.
Ọ̀nà Tó Gbà Kan Ìwọ Náà
Onírúurú ọ̀nà lọ̀ràn àìlera ara gbà kan gbogbo èèyàn. Ọ̀kan tó ń mú káwọn èèyàn ṣàníyàn jù lọ ni ti bí àìsàn ṣe ń gbọ́nni lówó lọ. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mílíọ̀nù ọjọ́ làwọn èèyàn fi pa ibi iṣẹ́ jẹ nílẹ̀ Yúróòpù nítorí ọ̀rọ̀ àìsàn kò ṣe àìsàn. Bọ́ràn ọ̀hún sì ṣe rí láwọn ibòmíì náà nìyẹn. Àìlèṣiṣẹ́ dójú àmì níbi iṣẹ́, títí kan owó gọbọi tí ìtọ́jú aláìsàn ń gbà, ń dá ìnáwó tó kan àwọn èèyàn nílé lóko sílẹ̀. Àwọn iléeṣẹ́ olókòwò àtàwọn ìjọba náà ń fara gbá a. Nítorí àtilè rówó san àfikún ìnáwó tí àìsàn dá sílẹ̀, àwọn oníṣòwò máa ń gbówó lé ọjà wọn, ìjọba náà sì máa ń fi kún owó orí. Ta ló wá ń san ẹ̀kúnwó náà? Ta ni ì bá tún jẹ́ bí ò ṣèwọ, àfi bó ò bá rajà!
Èyí tó tún dunni níbẹ̀ ni pé ó máa ń sábàá ṣòro fáwọn tálákà láti rí ìtọ́jú tó yẹ, ìyẹn bí wọ́n bá tiẹ̀ rí ìtọ́jú rárá. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ohun tójú àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ èèyàn tó ṣeé ṣe kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní àtirí ìtọ́jú tó jíire tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ rí ìtọ́jú rárá, ń rí gan-an nìyẹn. Àní láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ pàápàá, àwọn kan ní láti ṣe wàhálà kí wọ́n tó lè rí gbà lára ìtọ́jú tó sunwọ̀n, èyí tí wọ́n ń fáwọn èèyàn níbẹ̀. Bọ́ràn ṣe rí fún ọ̀pọ̀ lára mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́ta èèyàn rèé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nítorí pé wọn ò sí lábẹ́ ètò ìbánigbófò tó wà fún aláìlera.
Kì í wulẹ̀ ṣe ti owó gbígbọ́n lọ yìí nìkan lọ̀nà tí àìlera gbà kan gbogbo èèyàn o. Pabanbarì ọ̀nà tó gbà kàn wá ni ohun tójú ń rí bí àìsàn tí ò gbóògùn bá ń ṣeni, àìsùn àìwo tí ìrora gógó máa ń fà, bí ọkàn ẹni ṣe máa ń bà jẹ́ téèyàn bá rí àwọn ẹlòmíì tí wọ́n ń ṣàìsàn gan-an àti bí ọkàn èèyàn ṣe máa ń pami nígbà tí ẹbí, ọ̀rẹ́ tàbí èèyàn ẹni bá kú.
Kò sóhun tó dùn bíi kéèyàn mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ téèyàn á máa gbé nínú ayé tí ò ti ní sí àìsàn mọ́. Aráyé ń fẹ́ ìlera tó jíire! Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé bí ìrètí náà tiẹ̀ dà bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́, ohun tó dájú hán-ún hán-ún ni. Àwọn kan tiẹ̀ wà tí wọ́n gbà gbọ́ pé, bópẹ́ bóyá, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ẹ̀dá á fẹ́rẹ̀ẹ́ mú gbogbo àrùn àti àìsàn kúrò. Àmọ́, àwọn tó gba Bíbélì gbọ́ nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run á mú ìlérí tó ṣe nígbàanì pé kò ní sí àìsàn mọ́ láyé ṣẹ. Ṣé àwọn èèyàn lè pa ìgbà dà lóòótọ́ débi tí àìsàn ò fi ní í sí mọ́? Àbí Ọlọ́run ló máa mú irú ìgbà bẹ́ẹ̀ wá? Kí ló ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú?