Ọ̀nà 2
Jẹ́ Kí Ilé Rẹ Jẹ́ Ilé Aláyọ̀
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ó yẹ ká fẹ́ràn àwọn ọmọdé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn ò ní ya ọmọ rere. Láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1959, onímọ̀ nípa ẹ̀dá èèyàn, Ọ̀gbẹ́ni M. F. Ashley Montagu kọ̀wé pé: “Kọ́mọ bàa lè yàn kó yanjú, àfi ká máa fìfẹ́ hàn sí i; ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé láìsí ìfẹ́ ńṣe lọmọ á rán, pàápàá láàárín ọdún mẹ́fà tó bá kọ́kọ́ lò láyé.” Bí Ọ̀gbẹ́ni Montagu ṣe sọ lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lójú àwọn ògbógi tó ń ṣèwádìí nípa ọ̀ràn ọmọ títọ́ lóde òní. Ohun tí ọ̀gbẹ́ni Montagu sì fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé “báwọn ọmọ ò bá rẹ́ni fìfẹ́ hàn sí wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ńṣe ni wọ́n máa ń ya ọmọkọ́mọ.”
Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Ńṣe layé bó o bá a o pa á, bó ò bá a o bù ú lẹ́sẹ̀, táwọn èèyàn ti ya onímọ̀-tara-ẹni nìkan tá à ń gbé yìí ń mú kí àìsí ìṣọ̀kan túbọ̀ máa wà láàárín ọkọ, aya àtàwọn ọmọ. (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn lọ́kọláya sì tún ti lè rí i pé ńṣe ni ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó máa ń ga sí i bí ọ̀rọ̀ gbígbọ́ bùkátà àwọn ọmọ àti gbígba tiwọn rò bá wọ̀ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé tọkọtaya ti níṣòro àtimáa bára wọn sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ wọn á túbọ̀ máa burú sí i bó bá tún wá lọ jẹ́ pé èrò wọn kì í ṣọ̀kan lórí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa gbà bá ọmọ wí àti ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa gbà gbóríyìn fáwọn ọmọ.
Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Ẹ jùmọ̀ máa ṣe nǹkan pọ̀ déédéé gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ó tún yẹ káwọn tọkọtaya máa wá àkókò tí wọ́n á fi jọ máa finú konú. (Ámósì 3:3) Ẹ máa lo àkókò tó bá ṣẹ́ kù fún yín lọ́nà rere lẹ́yìn táwọn ọmọ bá ti lọ sùn. Ẹ má ṣe jẹ́ kí tẹlifíṣọ̀n gba àkókò ṣíṣeyebíye yẹn mọ́ ọn yín lọ́wọ́. Ẹ máa fìfẹ́ hàn síra yín déédéé kẹ́ ẹ má bàa ṣá lójú ara yín. (Òwe 25:11; Orin Sólómọ́nì 4:7-10) Dípò tẹ́ ẹ ó fi máa “wá àléébù” ara yín ní gbogbo ìgbà, ṣe ni kẹ́ ẹ máa wá ọ̀nà tẹ́ ẹ ó fi máa gbóríyìn fúnra yín lójoojúmọ́.—Sáàmù 103:9, 10; Òwe 31:28.
Máa sọ fáwọn ọmọ ẹ pó o fẹ́ràn wọn. Jèhófà Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀ fáwọn òbí nípa sísọ fún Jésù tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ pé òun fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. (Mátíù 3:17; 17:5) Baálé ilé kan tó ń jẹ́ Fleck, tó ń gbé ní Austria, sọ pé: “Mo ti wá rí i pé bí òdòdó làwọn ọmọdé rí. Bí òdòdó ṣe máa ń tẹ̀ síbi tí ìtànṣán oòrùn bá wà kó lè gba ìmọ́lẹ̀ àti ooru sára, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ máa ń fẹ́ káwọn òbí fìfẹ́ hàn sáwọn, kí wọ́n sì tún máa mú un dá àwọn lójú pé àwọn ò kóyán àwọn kéré nínú ìdílé.”
Yálà o ti ṣègbéyàwó tàbí o jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ, bó o bá jẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé ẹ nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wàá rí i pé ìyàtọ̀ á wà nínú ìdílé ẹ.
Àmọ́, kí tiẹ̀ lọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa bó o ṣe lè máa lo àṣẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí nínú ilé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
“Ìfẹ́ . . . jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:14