ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/08 ojú ìwé 3
  • Wàhálà Ti Bá Ìgbéyàwó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wàhálà Ti Bá Ìgbéyàwó
  • Jí!—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Ṣera Wọn Lọ́kan Kí Wọ́n sì Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣé Ìjì Tó Ń Jà Yìí Ò Ní Í Gbé Ìgbéyàwó Lọ?
    Jí!—2006
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbé Pọ̀ Láìṣègbéyàwó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 7/08 ojú ìwé 3

Wàhálà Ti Bá Ìgbéyàwó

“Ó ti sú mi o jàre!” Ṣó o ti gbọ́ káwọn èèyàn sọ bẹ́ẹ̀ nípa ìgbéyàwó wọn rí? Bó o bá ti ṣègbéyàwó, ṣé ọ̀rọ̀ ti rí báyìí lára tìẹ náà rí?

Ọ̀NÀ méjì ni ìfẹ́ tó mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún tọkọtaya fẹ́ra wọn sábà máa ń pín sí: ó lè jẹ́ ìfẹ́ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ tàbí ìfẹ́ gbígbóná. Síbẹ̀, wọ́n á máa retí kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí. Ẹnì kan tó máa ń gba àwọn tó ti ṣègbéyàwó nímọ̀ràn sọ pé: “Bó bá fi máa di pé wọ́n tọ̀ mí wá, ọ̀pọ̀ lára wọn á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́hùn. Ẹnì kejì wọn á ti sú wọn, ìgbéyàwó á ti rùn sí wọn, ìfẹ́ ọjọ́sí á ti wọ̀ọ̀kùn, nígbà míì sì rèé, ayé á ti sú wọn.” Èyí tó fi hàn pé kìkì ohun tó kù tó so wọ́n pọ̀ ni ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó wọn àti ilé tí wọ́n jọ ń gbé.

Másùnmáwo àti àìbalẹ̀ ọkàn tó ń peléke sí i ló ń jẹ́ káwọn ìgbéyàwó kan tú ká. Iṣẹ́ tí kì í jẹ́ kéèyàn gbélé, iṣẹ́ bóojí-o-jí-mi àti iṣẹ́ àṣedòru sì máa ń gba ìwọ̀nba okun tí tọkọtaya tó fẹ́ràn ara wọn ì bá tún rí lò fúnra wọn. Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí tọkọtaya ní síra wọn tún lè bẹ̀rẹ̀ sí yingin bí ìṣúnná owó, títọ́ àwọn ọmọ, yíyí ibùgbé pa dà, wíwá iṣẹ́ mìíràn àti ìtọ́jú ara, bá di ìṣòro. Ní kúkúrú ṣá, àwọn ìyípadà tó máa ń wáyé bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ lè fa ìnira tó lè mú kí àárín tọkọtaya máà gùn.

Iṣẹ́ méjì lọ̀pọ̀ ìyá ń ṣe pa pọ̀, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti iṣẹ́ ilé. Èyí lè mú kí wọ́n máà rí àyè fún ohunkóhun mìíràn ju iṣẹ́ ajé àti àbójútó àwọn ọmọ lọ. Lẹ́yìn tí wàhálà iṣẹ́ bá ti mú kó rẹ ọkọ àti aya tẹnutẹnu, agbára káká ni èyíkéyìí nínú wọn á fi rí ti ẹnì kejì rẹ̀ rò. Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ tọkọtaya máa ń ronú pé ó ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí nǹkan tojú sú wọn, kí wọ́n sì tún dà bí àjèjì síra wọn. Kí ló fà á tí wàhálà tó pọ̀ tó báyìí fi ń bá ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó? Kí lo lè ṣe tí ayọ̀ ìgbéyàwó rẹ ò fi ní pẹ̀dín, tí kò sì ní forí ṣánpọ́n?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́