ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g23 No. 1 ojú ìwé 15
  • Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé
  • Jí!—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀bùn Tó Máa Wà Títí Láé Tí Ẹlẹ́dàá Fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2023
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—2023
g23 No. 1 ojú ìwé 15
Adágún omi kan tó wà láàárín òkè àti igbó.

Oleh_Slobodeniuk/E+ via Getty Images

Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé

“Ayé yìí lágbára láti tún ara ẹ̀ ṣe ju bá a ṣe rò lọ.”

Ibi tí àwùjọ kan tó ń ṣèwádìí karí ayé nípa bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà parí èrò wọn sí nìyẹn. Ohun tí wọ́n sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ńṣe ni Ọlọ́run dá ayé yìí lọ́nà tó fi lè máa tún ara ẹ̀ ṣe, ìyẹn sì fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa.

Torí pé àwọn èèyàn ti ba ayé yìí jẹ́ gan-an, kò lè tún ara ẹ̀ ṣe mọ́, àfi kí Ọlọ́run bá wa tún un ṣe. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa tún un ṣe lóòótọ́?

Kíyè sí ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àpótí yìí sọ tó jẹ́ ká gbà pé ayé yìí máa wà títí láé, á sì dùn-ún gbé.

  • Ọlọ́run ló dá ayé yìí. “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.” —Jẹ́nẹ́sísì 1:1

  • Ọlọ́run ló ni ayé yìí. “Jèhófàa ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.”—Sáàmù 24:1

  • Ọlọ́run dá ayé kó lè wà títí láé. “Ó ti gbé ayé kalẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò ṣí i nípò títí láé àti láéláé.”—Sáàmù 104:5

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn ohun alààyè á máa gbé ayé títí láé. “Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó dá ayé, . . . kò kàn dá a lásán, àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.”—Àìsáyà 45:18

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn èèyàn á máa gbé ayé títí láé. “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—Sáàmù 37:29

Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ń ṣe àwọn nǹkan tó ń pa ayé yìí lára, àmọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ayé yìí ò lè jẹ́ kí wọ́n bà á jẹ́ kọjá àtúnṣe. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, Jèhófà Ọlọ́run ò ní gbà káwọn èèyàn pa ayé yìí run, ó ti yan àkókò tó máa run gbogbo àwọn tó ń ba ayé yìí jẹ́.—Ìfihàn 11:18

Bíbélì ṣèlérí pé tó bá yá Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè tó rẹwà, ó sì máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.” —Sáàmù 145:16

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́