ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g23 No. 1 ojú ìwé 12-14
  • Afẹ́fẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Afẹ́fẹ́
  • Jí!—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Ba Afẹ́fẹ́ Jẹ́
  • Ọlọ́run Dá Ayé Yìí Kó Lè Wà Títí Láé
  • Ohun Táwọn Èèyàn Ti Ṣe
  • Bíbélì Mú Ká Nírètí
  • Ì Bá Dára Ká Ní Afẹ́fẹ́ Mímọ́ Gaara Díẹ̀!
    Jí!—1996
Jí!—2023
g23 No. 1 ojú ìwé 12-14
Tọkọtaya kan ń rìn níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kan tí yìnyín bò, wọ́n ń wo adágún omi tí igbó àti òkè yí ká, ojú ọ̀run sì mọ́lẹ̀ kedere.

ṢÉ AYÉ YÌÍ Ò NÍ BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

AFẸ́FẸ́

AFẸ́FẸ́ wúlò gan-an, àmọ́ iṣẹ́ tó ń ṣe kọjá pé à ń mí i sínú. Afẹ́fẹ́ tún máa ń dáàbò bo ayé yìí kí ìtànṣán tó léwu tó ń wá látinú oòrùn máa bàa pa wá lára. Láìsí afẹ́fẹ́, ńṣe ni gbogbo ayé á tutù nini tí gbogbo nǹkan á sì dì gbagidi.

Ohun Tó Ń Ba Afẹ́fẹ́ Jẹ́

Àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ pọ̀ gan-an láyé yìí, ó sì ń ṣàkóbá tó pọ̀ fáwọn ohun alààyè. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ní gbogbo ayé yìí, àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń mí afẹ́fẹ́ tí kò léwu sínú.

Afẹ́fẹ́ tó léwu táwọn èèyàn ń mí sínú ti fa àwọn ìṣòro bíi kéèyàn má lè mí dáadáa, àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró àti àrùn ọkàn. Lọ́dọọdún, nǹkan bíi mílíọ̀nù méje èèyàn ló ń kú torí pé wọ́n ń mí afẹ́fẹ́ tó léwu sínú.

Ọlọ́run Dá Ayé Yìí Kó Lè Wà Títí Láé

Ọlọ́run dá ayé yìí lọ́nà tí gbogbo ohun abẹ̀mí tó wà láyé á fi máa jàǹfààní afẹ́fẹ́ tó mọ́, tó sì tura. Àmọ́ kí èyí tó lè ṣeé ṣe, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn nǹkan tó lè ba afẹ́fẹ́ jẹ́. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.

  • Àwọn igbó kìjijkìji ló máa ń gba afẹ́fẹ́ carbon dioxide sára. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé àwọn igi ẹ̀gbà tó wà láwọn ilẹ̀ tó wà létíkun tún lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn igi ẹ̀gbà máa ń gba afẹ́fẹ́ carbon dioxide sára ní ìlọ́po márùn-ún ju báwọn igbó kìjikìji ṣe máa ń gbà á sára lọ.

  • Ìwádìí táwọn kan ṣe lẹ́nu àipẹ́ yìí fi hàn pé àwọn ohun alààyè kan tí wọ́n ń pè ní kelp máa ń yọ afẹ́fẹ́ carbon dioxide kúrò nínú afẹ́fẹ́, wọ́n sì máa ń tọ́jú ẹ̀ pa mọ́. Àpò kékeré kan wà lára àwọn ohun alààyè yìí tí afẹ́fẹ́ kún inú ẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n léfòó dáadáa lórí omi. Tí wọ́n bá ti wá dé àárín òkun, àpò tó wà lára wọn á bẹ́, wọ́n á wá rì sí ìsàlẹ̀ òkun lọ́hùn-ún. Ó sì jọ pé àìmọye ọdún ni wọ́n á fi wà níbẹ̀.

  • Lọ́dún 2020 nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé tí afẹ́fẹ́ bá tiẹ̀ bà jẹ́ gan-an, ó lè pa dà di èyí tó mọ́, tó sì tura. Nígbà yẹn, àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá dáṣẹ́ dúró, àwọn mọ́tò náà ò sì fi bẹ́ẹ̀ sí níta, torí náà èéfín olóró tó ń tú sínú afẹ́fẹ́ mọ níwọ̀n gan-an. Ó gbàfiyèsí pé kò pẹ́ rárá tí afẹ́fẹ́ fi mọ́, tó sì tura. Lọ́dún 2020, ìròyìn tó jáde látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí bí afẹ́fẹ́ ṣe rí lágbàáyé sọ pé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣèwádìí ló sọ pé kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tí ìjọba ṣòfin pé káwọn èèyàn má ṣe jáde nílé táwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn afẹ́fẹ́ tó mọ́, tó sì tura.

    ǸJẸ́ O MỌ̀?

    Afẹ́fẹ́ Tó Bà Jẹ́ Lè Mọ́ Pa Dà

    Àtẹ kan tó jẹ́ ká rí bí àwọn ohun olóró tín-tìn-tín ṣe pọ̀ tó nínú afẹ́fẹ́ nílùú New Delhi, lórílẹ̀-èdè India. Ní January 2020, ó wà ní ìwọ̀n 128.1, èyí sì léwu gan-an fún gbogbo èèyàn. Àmọ́ nígbà tó fi máa di August 2020, ó ti dín díẹ̀ sí ìwọ̀n 35.5, èyí tó ṣì sàn díẹ̀ fún ìlera àwọn èèyàn.

    Nígbà tí ìjọba ṣòfin pé káwọn èèyàn má ṣe jáde nílé nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ dín kù gan-an nílùú New Delhi, lórílẹ̀-èdè India. Ìdí ni pé àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ò ṣiṣẹ́, àwọn onímọ́tò náà ò sì jáde. Kò pẹ́ rárá táwọn nǹkan olóró tó wà nínú afẹ́fẹ́ fi dín kù gan-an. Àwọn ohun tín-tìn-tín kan wà nínú afẹ́fẹ́ yìí tó lè fa àìsàn ẹ̀dọ̀fóró àtàwọ̀n àìsàn míì tó le gan-an. Òótọ́ ni pé nǹkan tún pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn táwọn ilé iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pa dà táwọn onímọ́tò sì tún jáde, àmọ́ ńṣe ni èyí fi hàn pé afẹ́fẹ́ tó ti bà jẹ́ lè pa dà di èyí tó mọ́ tó sì tura.

    Bí ìlú New Delhi, lórílẹ̀-èdè India ṣe rí níparí ọdún 2019. Àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ kò jẹ́ kí ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ kedere.

    © Amit kg/Shutterstock

    Ìparí ọdún 2019

    Bí ìlú New Delhi, lórílẹ̀-èdè India ṣe rí nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà tí ìjọba ṣòfin pé káwọn èèyàn má ṣe jáde nílé. Ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ kedere torí pé àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ dín kù.

    © Volobotti/Shutterstock

    Nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà

Ohun Táwọn Èèyàn Ti Ṣe

Ọkùnrin kan gbé kẹ̀kẹ́ ẹ̀ síbì kan nígbà tó dé ibiṣẹ́.

Táwọn èèyàn bá ń gun kẹ̀kẹ́, ó lè dín àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ kù

Kárí ayé, àwọn ìjọba máa ń sọ fáwọn ilé iṣẹ́ pé kí wọ́n dín àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ kù. Bákan náà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ń ṣèwádìí nìṣó nípa bí wọ́n ṣe lè ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tó ti bà jẹ́ láyìíka wa nítorí afẹ́fẹ́ olóró. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń lo àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín láti yọ àwọn nǹkan tó léwu kúró nínú afẹ́fẹ́, omi, iyẹ̀pẹ̀ àtàwọn nǹkan míì. Bákan náà, wọ́n gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn pé dípò kí wọ́n máa wa mọ́tò, kí wọ́n gbìyànjú láti máa fẹsẹ̀ rìn tàbí kí wọ́n máa gun kẹ̀kẹ́, kí wọ́n má sì jẹ́ káwọn nǹkan tó ń lo iná mànàmáná pọ̀ nínú ilé wọn.

Obìnrin kan jókòó sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀, ó ń se oúnjẹ. Àdògán kékeré kan ló fi ń dáná, síbẹ̀ ó ṣì ń ṣèéfín.

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìjọba fún àwọn ará ìlú láwọn ohun ìdáná ìgbàlódé kí ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ lè dín kù, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò rí gbà

Àmọ́, ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé, Báńkì Àgbáyé àtàwọn àjọ míì lọ́dún 2022 fi hàn pé gbogbo ìgbìyànjú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì yanjú ìṣòro yìí.

Ìròyìn yẹn sọ pé lọ́dún 2020, nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn tó wà láyé ló jẹ́ pé àwọn nǹkan tó lè ba afẹ́fẹ́ jẹ́ ni wọ́n ń lò jù láti fi dáná àti láti ṣàwọn nǹkan míì. Àwọn èèyàn díẹ̀ ló rówó ra àwọn ohun ìdáná ìgbàlódé tàbí tí wọ́n lè dáná láwọn ọ̀nà míì tí kò ní ba afẹ́fẹ́ jẹ́.

Bíbélì Mú Ká Nírètí

“Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, sọ nìyí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti . . . Ẹni tó tẹ́ ayé àti èso rẹ̀, Ẹni tó fún àwọn èèyàn inú rẹ̀ ní èémí.”—Àìsáyà 42:5.

Ọlọ́run ló dá afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú, ó sì tún ṣètò pé káwọn ohun alààyè kan máa ṣiṣẹ́ pọ̀ láti tún afẹ́fẹ́ ṣe. Bákan náà, agbára Ọlọ́run kò lópin, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ó máa mú àwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ kúrò láyé. Ka àpilẹ̀kọ náà, “Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Lọ.”

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I

Àwòrán Ayé, téèyàn bá wò ó látinú gbalasa òfúrufú.

Ta ló dá afẹ́fẹ́? Wo fídíò náà, Ṣé Ọlọ́run Ló Dá Àgbáálá Ayé Yìí? lórí jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́