APÁ 1
Ìgbà Ìṣẹ̀dá sí Ìgbà Ìkún-Omi
Ibo ni ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ti wá? Báwo ni oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe di ohun tó wà? Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tó tọ̀nà nígbà tó sọ pé Ọlọ́run ló dá wọn. Nítorí náà, àwọn ìtàn Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá la fi bẹ̀rẹ̀ ìwé wa yìí.
Bíbélì sọ fún wa pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, tí wọ́n jọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. Áńgẹ́lì ni wọ́n. Àmọ́, àwọn èèyàn bíi tiwa ni Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé fún. Nítorí náà, Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń jẹ́ Ádámù àti Éfà ó sì fi wọ́n sínú ọgbà ẹlẹ́wà kan. Àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run wọ́n sì pàdánù ẹ̀tọ́ wọn láti máa wà láàyè nìṣó.
Tá a bá ro gbogbo rẹ̀ pọ̀, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá Ádámù títí di ìgbà Ìkún-omi ńlá, ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [1,656] ọdún. Láàárín àkókò yìí, ọ̀pọ̀ ẹni burúkú ló wà. Ní ọ̀run, Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí wà. Lórí ilẹ̀ ayé, Kéènì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn búburú mìíràn wà títí kan àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n lágbára lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́ àwọn èèyàn rere tún wà lórí ilẹ̀ ayé. Lára wọn ni Ébẹ́lì, Énọ́kù àti Nóà. A ó kà nípa gbogbo àwọn wọ̀nyí àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ní Apá KÌÍNÍ.