ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kc orí 15 ojú ìwé 141-150
  • Awọn Aduroṣinṣin Alágbàwí Ijọba Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Aduroṣinṣin Alágbàwí Ijọba Naa
  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • GBÍGBÈJÀ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN
  • “BABILONI NLA” ṢUBU!
  • A BẸRẸ IJẸRII KÁRÍ-AYÉ
  • “ẸRÚ” OLUṢOTITỌ KAN
  • Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ ní Gbogbo Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
“Kí Ijọba Rẹ Dé”
kc orí 15 ojú ìwé 141-150

ORI 15

Awọn Aduroṣinṣin Alágbàwí Ijọba Naa

1. Awọn iṣẹlẹ pataki wo ni Danieli sọtẹlẹ?

TIPẸTIPẸ ṣaaju, ni asọtẹlẹ Danieli ti tọkasi 29 C.E. gẹgẹ bi ọdun naa tí Messia yoo farahan bi eniyan, ati 1914 pẹlu gẹgẹ bi ọdun tí oun yoo gùn ori ìtẹ́ ninu ògo ọrun. Siwaju sii, Danieli sọtẹlẹ ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bi ariyanjiyan nla naa nipa ijọba agbaye yoo ṣe di eyi tí a yanju.

2. Ariyanjiyan wo ni a nilati dájọ́ rẹ̀ nisinsinyi, ninu ile-ẹjọ wo sì ni?

2 Nisinsinyi ariyanjiyan nla naa nipa ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ si iṣakoso ayé ni a nilati yanju rẹ̀ patapata. Ṣugbọn ninu ile-ẹjọ wo? Họwu, ninu ile-ẹjọ tí ó gajulọ ni gbogbo agbaye ni! Danieli ṣapejuwe rẹ̀ ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:

“Mo sì wò titi a fi sọ ìtẹ́ wọnni kalẹ, titi Ẹni-Agba Ọjọ naa fi jokoo, aṣọ ẹni tí ó fún bi ẹ̀gbọ̀n-òwú, irun ori rẹ̀ sì dabi irun agutan tí ó mọ́: ìtẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀wọ́-iná, àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ iná tí ń jó. Ìṣàn iná ń ṣẹ́yọ, ó sì ń tújáde lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun ń ṣe iranṣẹ fun un, ati awọn ẹgbẹẹgbaarun lọna ẹgbaarun duro niwaju rẹ̀: awọn Onidaajọ jokoo, a sì ṣí iwe wọnni silẹ.”​—⁠Danieli 7:​9, 10.

3. (a) Ta ni Onidaajọ naa? (b) Ki ni awọn “iwe naa” fihan? (c) Idajọ wo ni a sì ṣe?

3 “Ọba ayeraye naa,” Jehofa Ọlọrun, nipa bayii ti jokoo lati ṣe idajọ. (Ìfihàn 15:⁠3) Ṣugbọn awọn “iwe” wo ni wọn wà ní ṣíṣísílẹ̀ niwaju rẹ̀ nisinsinyi? Wọn jẹ́ awọn akọsilẹ bibanininujẹ nipa iṣakoso tí awọn orilẹ-ede ti ṣe jálẹ̀ gbogbo itan. Pẹlu Akoko awọn Keferi tí ó dopin ní 1914 C.E., bi ó ti yẹ, ‘ile-ẹjọ naa’ gbà ọla-aṣẹ “agbara” wọn kuro ní ọwọ wọn, bi ó tilẹ jẹ́ pe “a ti yàn akoko ati igba fun wọn bi olukuluku yoo ti pẹ́ tó”​—⁠titi a ó fi mú idajọ ṣẹ nitootọ sori wọn ní Armageddoni.​—⁠Danieli 7:12; Ìfihàn 16:​14, 16.

4, 5. (a) Ta ni a fun ní iṣakoso? (b) Kìkì lọna wo ni a lè gbà wòye wíwàníhìn-ín Ọba naa?

4 Nigba naa, ta ni a ó fi iṣakoso naa fun? Danieli ń baa lọ pe:

“Mo ríi ní iran òru, sì kiyesii, ẹnikan bi ọmọ eniyan wá pẹlu awọsanma ọrun, ó sì wá sọdọ Ẹni-Agba Ọjọ naa, wọn sì mú un sunmọ iwaju rẹ̀. A sì fi agbara ijọba, ati ogo, ati ijọba fun un, ki gbogbo eniyan, ati orilẹ, ati ede, ki ó lè maa sìn ín; agbara ijọba rẹ̀ sì jẹ́ agbara ijọba ainipẹkun, eyi tí a ki yoo rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyi tí a ki yoo lè parun.”​—⁠Danieli 7:​13, 14.

5 Ta ni ẹni yii tí ó rí “bi ọmọ eniyan”? Kii ṣe ẹlomiran bikoṣe Jesu Kristi Oluwa tí a ti ṣelogo. Niwọn bi “awọsanma ọrun” ti duro fun àìṣeéfojúrí, ó jẹ́ pẹlu oju ìwòye ti igbagbọ ni a fi wòye “ami” ọrun ti wíwàníhìn-ín rẹ̀, papọ pẹlu “ami” ti o han kedere ninu awọn iṣẹlẹ ori ilẹ̀-ayé nigba ‘ibẹrẹ ipọnju’ ní 1914 C.E.​—⁠Matteu 24:​3, 7, 8, 30; Ìfihàn 1:⁠7.

6. (a) Nipa awọn miiran wo ni a tún ṣe idajọ? (b) Ki ni awọn wọnyi gbà, bawo sì ni?

6 A ṣakiyesi lati inu asọtẹlẹ Danieli tẹle eyi pe a ṣe idajọ ní “idalare fun awọn eniyan mímọ́ ti Ọga-ogo,” ati pe awọn wọnyi, pẹlu, sì gba “ijọba, ati agbara ijọba ati ipá gbogbo ijọba ní gbogbo abẹ́ ọrun.” (Danieli 7:​22, 27) Awọn wo ni awọn “eniyan mímọ́” wọnyi? Dajudaju, wọn yatọ ní ifiwera pẹlu awọn oluṣakoso ijọba eniyan oníwà-ìbàjẹ́, olùmọtara-ẹni-nìkan, ti wọn ti ń pọ́n awọn eniyan lójú tipẹtipẹ. Wọn kii ṣe awọn ẹlomiran bikoṣe awọn 144,000 “eniyan mímọ́” ti a fi ororo yan, awọn eniyan tí wọn jẹ́ “alailabawọn” niti ìwàtítọ́ wọn tí wọn sì jẹ́ awọn tí “a ràpadà lati inu awọn eniyan wá” lati di alajumọṣakoso pẹlu “Ọmọ eniyan” ninu Ijọba rẹ̀ ọrun. A jí wọn dide lati wà pẹlu rẹ̀ “ni ikẹhin ọjọ.” (Ìfihàn 14:​3-⁠5; Matteu 24:30; Johannu 6:40) Nigba tí Jesu wá sinu Ijọba rẹ̀, a rí iyoku “awọn eniyan mímọ́” wọnyi ti wọn ṣi walaaye lori ilẹ̀-ayé. Wọn ni iṣẹ kan lati ṣe!

GBÍGBÈJÀ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN

7, 8. (a) Awujọ wo ni ó bẹrẹ iṣẹ imurasilẹ kan, nigba wo sì ni? (b) Ki ni wọn patì si apakan? (c) Ki ni wọn si fi taratara ṣe alágbàwí rẹ̀? (d) Ọdun wo ni wọn tọka siwaju si? (e) Ohun-eelo wo ni wọn lò ní pipolongo Ijọba Ọlọrun?

7 Bi akoko ti ń sunmọ etílé fun “Ọmọ eniyan” lati gba Ijọba rẹ̀, ó hàn gbangba pe ó jẹ́ ifẹ-inu Ọlọrun pe ki a ṣe iṣẹ imurasilẹ kan níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé. Ní awọn ọdun 1870 Charles T. Russell ṣeto awujọ awọn Kristian kereje kan tí wọn ti ya araawọn si mímọ́ ní Pittsburgh, Pennsylvania, U.S.A. Kò pẹ́ ki awọn wọnyi tó mọ̀lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pe awọn isin Kristẹndọm ni a gbeka awọn ẹkọ igbagbọ ati ààtò Babiloni, papọ pẹlu ẹkọ Plato nipa aileeku ọkàn, kii sì ṣe lori Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ní pipa isin eke tì sẹ́gbẹ̀ẹ́kan, awujọ kereje yii wá di alágbàwí aduroṣinṣin fun awọn ẹkọ Bibeli nipa irapada Jesu, ajinde ati Ijọba Ọlọrun gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun araye tí ń jiya.

8 Nipasẹ iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà, tí a ti bẹrẹsii tẹjade laidawọduro lati July 1879, Russell ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ fi taratara gbèjà ẹkọ Bibeli nipa iṣẹda ní ilodisi àbá-èrò-orí Darwin nipa ẹfoluṣọn. Wọn ‘bu omi pa hẹẹli’ nipa fifihan lati inu Bibeli pe kò si ibi idaloro fun ‘awọn ọkàn tí ó ti ṣaláìsí,’ ṣugbọn pe “hẹẹli” Bibeli jẹ́ ibojì. (Orin Dafidi 16:10; Iṣe 2:​29-⁠32) Wọn tọka siwaju si 1914 C.E. gẹgẹ bi akoko kan tí a sami si niti ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun. Titi di òní-olónìí, Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kede Ijọba Jehofa, tí a ń tẹjade ní oriṣi ede tí ó lé ni 100, tí ẹ̀dà itẹjade kọọkan tí ń jade jẹ ni araadọta ọkẹ, ń fi pẹlu iduroṣinṣin ṣe alágbàwí Ijọba Ọlọrun nipasẹ Kristi gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun awọn orilẹ-ede ayé.​—⁠Matteu 12:21; Orin Dafidi 145:​10-⁠12.

9. Bawo ni a ṣe mú Ìfihàn 11:​7-⁠12 ṣẹ si “awọn ẹlẹ́rìí” wọnyi lara?

9 Lẹhin ṣiṣiṣẹsin pẹlu iṣotitọ fun eyi tí ó jù 30 ọdun lọ gẹgẹ bi ààrẹ akọkọ fun Watch Tower Society, C. T. Russell kú ní October 31, 1916, J. F. Rutherford sì rọ́pò rẹ̀. Awọn alufaa onisin lo ipò ogun naa lati ru atako soke si ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa. Awọn ipade Kristian ni a túká. Ní ọpọ orilẹ-ede, awọn iranṣẹ Ọlọrun oloootọ ni a fisẹ́wọ̀n. Rutherford ati awọn ojiṣẹ meje miiran tí ẹru-iṣẹ jálé-léjìká lati orile-iṣẹ Watch Tower ní Brooklyn, New York, U.S.A., ni a dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọpọlọpọ ọdun fun. Bi ó ti wù ki ó rí, awọn iranṣẹ Ọlọrun wọnyi kò rẹwẹsi, nitori pe asọtẹlẹ Bibeli ti sọ asọtẹlẹ irúfẹ́ awọn inunibini bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, Ìfihàn 11:​7-⁠12 ṣapejuwe awọn orilẹ-ede ayé, labẹ ami naa ‘ẹranko-ẹhànnà,’ bi ẹni ń gbogun ti “awọn ẹlẹ́rìí” Ọlọrun lati “ṣẹgun wọn,” ki ó “sì pa wọn.” Isọtẹlẹ wọn ni a ó dádúró, lọna apẹẹrẹ wọn yoo dabi òkú tí a gbé jù sita fun igba pípẹ́ tobẹẹ tí yoo fi di òórùn ní “òpópó ọ̀nà” Kristẹndọm. Gbogbo eyi ṣẹlẹ, bi a ti fi awọn iranṣẹ Ọlọrun jakejado ayé ṣẹ̀sín ní gbangba. Bi ó ti wù ki ó rí, bi ìgbónágbóoru ogun ti ń lọsilẹ, tí a sì tú awọn tí a fi sẹ́wọ̀n silẹ​—⁠tí a sì dá wọn nídè patapata kuro ninu awọn ẹ̀sùn eke tí a fi kàn wọn​—⁠“ẹmi ìyè lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wọ̀ inu wọn.” A gbé wọn ga si ipò ojurere atọrunwa, wọn sì wọnú akoko igbokegbodo iṣẹ Ijọba onitara lati 1919.​—⁠Isaiah 52:​7, 8; Romu 10:⁠15.

“BABILONI NLA” ṢUBU!

10. Ki ni awọn isin Kristẹndọm jẹ̀bi rẹ̀, bawo sì ni?

10 Lakooko awọn ọdun ogun wọnni, kii ṣe kiki pe awọn alufaa Kristẹndọm jẹ́ aṣaaju ní ṣiṣe inunibini si awọn Kristian tootọ nikan ni, ṣugbọn wọn tun ṣá ẹ̀rí naa pe Ijọba Ọlọrun ti sunmọle tì. Wọn ní “ijọba” isin tiwọn funraawọn, eyiini “Babiloni Nla.” (Ìfihàn 17:​5, 6, 18) Ní ìhà mejeeji ogun naa, wọn ń rọ awọn ọ̀dọ́ lati kówọnú awọn yàrà ti wọn sì ṣe itilẹhin tọkantọkan fun ipakupa bibanilẹru yẹn. Fun irúfẹ́ ìgbésẹ̀ bẹẹ, awọn alufaa Kristẹndọm yoo nilati ru ẹ̀bi ẹjẹ wiwuwo, gẹgẹ bi awọn aṣaaju isin Jerusalemu igbaani, awọn ẹni tí wolii Jehofa sọ fun pe: “Ẹ̀jẹ̀ ẹmi awọn talaka ati awọn aláìṣẹ̀ ń bẹ lara aṣọ [yin].”​—⁠Jeremiah 2:34; 19:3, 4; tún wò Matteu 23:​34, 35 pẹlu.

11. Bawo ni Esekieli 22:​3, 4, 16 ṣe kàn Kristẹndọm?

11 Ẹ̀bi ẹjẹ yii nisinsinyi ni a fikun ibọriṣa Kristẹndọm ati kíkọ́ni tí oun ń kọni ní awọn ẹkọ igbagbọ eke ti Babiloni. Idi niyii tí awọn ọ̀rọ̀ Esekieli pẹlu fi kàn Kristẹndọm apẹ̀hìndà:

“Bayii ni Oluwa Ọlọrun wí, Ilu tí ó ta ẹjẹ silẹ laaarin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki ó lè dé, ó sì ṣe oriṣa si araarẹ̀ lati sọ araarẹ̀ di àìmọ́. Iwọ ti di ẹlẹ́bi niti ẹjẹ rẹ tí iwọ ti tasilẹ; iwọ sì ti sọ araarẹ di àìmọ́ niti oriṣa rẹ tí iwọ ti ṣe, iwọ sì ti mú ọjọ rẹ sunmọtosi, iwọ sì ti dé ọdun rẹ; nitori naa ni mo ṣe sọ ọ di ẹ̀gàn si awọn keferi, ati ẹ̀sín sí gbogbo ilẹ. A ó sì sọ ọ di àìlọ́wọ̀ ninu araarẹ lójú awọn keferi, iwọ yoo sì mọ̀ pe emi ni [Jehofa, NW].”​—⁠Esekieli 22:​3, 4, 16.

12. (a) Iṣẹlẹ mànigbàgbé wo ni ó ṣẹlẹ ní 1919? (b) Bawo ni eyi si ṣe ṣanfaani fun awọn eniyan Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé?

12 Isin Kristẹndọm ẹlẹ́bi-ẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun naa gan-an, Jehofa, tí ó sọ pe oun ń jọsin, ṣugbọn tí oun kò fẹran lati lo orukọ rẹ̀ mọ́, ti tanù. Ní ọdun 1919 C.E., papọ pẹlu gbogbo isin Babiloni yika-ayé, oun jiya iṣubu ńláǹlà. Laelae kò tún lè ní iduro eyikeyii mọ́ niwaju Ọga-ogo Julọ. Oun kò tún lè lò agbara mọ́ lori awọn olujọsin tootọ fun Jehofa lae. Bẹẹni, kò si apá eyikeyii ninu Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye tí ó lè ṣe bẹẹ. Nitori pe “Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ” nisinsinyi ṣe ikede yii jade fun “awọn eniyan mímọ́” oloootọ lori ilẹ̀-ayé pe:

“Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, tí ó kọ́ ọ fun èrè, ẹni tí ó tọ ọ ní ọna tí iwọ ìbá maa lọ. Ẹ jade kuro ninu Babiloni. . . . Ẹ fi ohùn orin sọ ọ, wi eyi.” (Isaiah 48:​16, 17, 20)

Ki ni “ohùn orin” yii, nibo ni a sì ti gbọ́ ọ?

A BẸRẸ IJẸRII KÁRÍ-AYÉ

13. (a) Apá wo ninu “ohùn orin” naa ni ó ti di olókìkí nisinsinyi? (b) Ìpè olóhùn-gooro wo ni ó dún jade?

13 “Ọmọ eniyan” ṣapejuwe apá olokiki ninu “ohùn orin” yii ninu asọtẹlẹ rẹ̀ nipa ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,’ ní wiwi pe:

“A ó sì waasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.” (Matteu 24:​3, 14, 27)

Ṣugbọn ó yẹ ki a ṣeto “awọn eniyan mímọ́” ki wọn baa lè mu iṣẹ yii ṣe. Bẹẹ ni wọn kò sì lè ṣe é yọri nipasẹ okun eniyan lasan. Ó dunmọni pe, ní awọn apejọpọ agbaye tí a ṣeto ní Cedar Point, Ohio, U.S.A., ní 1919, ati lẹẹkan sii ní 1922, a tú ẹmi Jehofa jade sori wọn lọna agbayanu. Ó ṣeto wọn jọ ti ó sì fun wọn lagbara lati ‘fọnrere, fọnrere, fọnrere Ọba naa ati ijọba rẹ̀.’ (Matteu 24:31) Fun awọn “ayanfẹ” wọnyi, tí wọn di ireti ti ọrun mú ṣinṣin, iṣẹ titobi kan ń bẹ niwaju fun wọn.

14. Bawo ni asọtẹlẹ Joeli ṣe ní imuṣẹ titobiju nisinsinyi?

14 Gan-an gẹgẹ bi asọtẹlẹ Joeli ti ní imuṣẹ ní Pentekosti 33 C.E. nigba “awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan Ju, nisinsinyi asọtẹlẹ naa bẹrẹsii ní imuṣẹ titobiju kan nigba “awọn ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ ayé Satani. Pẹlu ìlàlóye ati isunniṣe ẹmi Ọlọrun, “awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin” Jehofa ti ode-oni tí wọn jẹ́ ẹni-ami-ororo “sọtẹlẹ nitootọ,” bi wọn ti kún fun iṣẹ pẹrẹu ní kikilọ fun ayé araye nipa “ọjọ nla ati olókìkí ti Jehofa” tí ó sunmọle, ati nipa aini kanjukanju naa lati “képè orukọ Jehofa” ki a baa lè gbà wọn lá.​—⁠Iṣe 2:16-⁠21, NW; Joeli 2:​28-⁠32.

“ẸRÚ” OLUṢOTITỌ KAN

15. (a) Ta ni “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa? (b) Bawo ni a ṣe dá a mọ̀yàtọ̀ lẹẹkan sii ní akoko ode-oni?

15 Ninu asọtẹlẹ nla rẹ̀ nipa “ami” naa, Jesu ti beere ibeere kan pe:

“Ta ni iṣe [ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa, NW], ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi ounjẹ wọn fun wọn ní akoko?”

Ẹgbẹ “ẹrú” oluṣotitọ kan ti ṣiṣẹsin laaarin awọn Kristian akọkọbẹrẹ titi di igba tí ìpẹ̀hìndà nla naa wọle dé. Awa ha tún rí irúfẹ́ eto-ajọ “ẹrú” kan bẹẹ tí ó ń ṣe ipinkiri ounjẹ tẹmi nigba tí Jesu Oluwa dé sinu Ijọba rẹ̀ bi? A ri i! “Awọn Akẹkọọ Bibeli” wọnni, gẹgẹ bi a ṣe ń pè wọn nigba naa, ti ṣe iṣẹ imurasilẹ ti o kari ayé. Jesu sì wi pe:

“Alabukun-fun ni [ẹrú, NW] naa, nigba ti oluwa rẹ̀ bá dé, ẹni ti yoo bá a ki o maa ṣe bẹẹ. Loootọ ni mo wí fun yin pe, Oun o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ní.”​—⁠Matteu 24:​45-⁠47.

16. (a) Bawo ni “ẹrú” naa ṣe bojuto “awọn ohun-ìní” Ọ̀gá naa? (b) Orukọ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni “ẹrú” naa ti fi pẹlu idunnu tẹwọgba?

16 Ní mimọriri ìyànsípò yii lati ọ̀dọ̀ Ọ̀gá naa, ẹgbẹ “ẹrú” ẹni-ami-ororo alapapọ naa ti ṣìkẹ́ awọn ire Ijọba lori ilẹ̀-ayé, ni rírí pe a kede “ihinrere” naa. Ní awọn ọdun 1920, awọn ìhìn-iṣẹ́ idajọ alagbara ni a pokiki lodisi Satani ati eto-ajọ rẹ̀, ati ní pataki lodisi isin Babiloni. Ní 1931, “ẹrú” naa fi pẹlu idunnu tẹwọgba orukọ naa tí ó fi i hàn gedegbe yatọ si gbogbo isin eke​—⁠orukọ naa “awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa”​—⁠papọ pẹlu ẹru-iṣẹ ati anfaani tí wolii Isaiah tọka si ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:

“Ẹyin ni ẹlẹ́rìí mi, ni [Jehofa, NW] wi, àtí iranṣẹ mi tí mo ti yàn. . . . Emi, ani emi ni [Jehofa, NW]; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan. . . . Ẹyin ni ń ṣe ẹlẹ́rìí mi,’ ni [Jehofa, NW] wi, pe Emi ni Ọlọrun.”​—⁠Isaiah 43:​10-⁠12.

17. Ibeere wo ni ó yẹ fun idahun nisinsinyi?

17 Bawo ni “ẹrú” naa, pẹlu iyoku mẹmba ẹni-ami-ororo tí iye wọn jẹ́ kiki ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa-mẹwaa, ṣe lè mú ki ‘a waasu ihinrere Ijọba yii ní gbogbo ayé fun ẹ̀rí’? Jehofa laipẹ pese idahun naa.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 148, 149]

ẸṢIN-ỌRỌ IJỌBA inu BIBELI

ILERI “IRU-ỌMỌ” IJỌBA NÍ EDENI

“IRU-ỌMỌ” TÍ Ó JẸ́ ỌBA NI A SỌTẸLẸ NIPASẸ ABRAHAMU, DAFIDI

WIWAASU IJỌBA​—⁠ẸBỌ IRAPADA ỌBA

A FI IDI IJỌBA MULẸ​—⁠“AWỌN ỌJỌ IKẸHIN” LATI 1914

IJỌBA “DÉ” LATI PA IṢAKOSO ENIYAN RUN

IJỌBA ẸLẸGBẸRUN ỌDUN YOO MÚ PARADISE PADABỌSIPO

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́