Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Àkọlé Sí/Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Orúkọ Òǹṣèwé sí
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
Àìléwu kárí-ayé labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia” jẹ́ idaniloju dídájú hán-ún hán-ún. Ọlọrun Olodumare mú eyi da wa loju ninu asọtẹlẹ naa nipa ìbí ati iṣẹ́ ìgbésí-ayé “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ninu Isaiah 9:6, 7: “A o sì maa pe orukọ rẹ̀ ní . . . Ọmọ-Aládé Alaafia. Ijọba yoo bísíi, alaafia kì yoo ní ipẹkun . . . Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yoo ṣe eyi.” Bi awọn onkawe iwe yii ṣe lè murasilẹ lati wọnu ọ̀pọ̀ yanturu iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ni a ṣalaye ni kedere ninu ìdìpọ̀ ìwé yii.
—Awa Oluṣewejade.
Ayafi bi a ba fihan pe omiran ni, ẹsẹ Bibeli ti a lo jẹ lati inu Bibeli Yoruba. NW to̩kasi New World Translation of the Holy Scriptures itẹjade ti 1984.