Ìwàláàyè Ha Wà Lẹ́yìn Ikú Bí?
“Ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù . . . Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?”—MÓSÈ, WÒLÍÌ ÌGBÀANÌ KAN.
1-3. Báwo ni ọ̀pọ̀ ṣe ń wá ìtùnú nígbà tí ikú bá mú olólùfẹ́ wọn lọ?
NÍNÚ ilé ìmúra-òkú fún sísin kan ní New York City, tẹbí tọ̀rẹ́ ń fi ìparọ́rọ́ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ pósí kan tí a ṣí sílẹ̀. Wọ́n ń yọjú wo òkú yẹn, òkú ọmọdékùnrin ẹni ọdún 17 kan. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti ilé ẹ̀kọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè dá a mọ̀ mọ́. Fífi kẹ́míkà ṣèwòsàn ti mú kí irun rẹ̀ gbọ̀n dànù; àrùn jẹjẹrẹ ti mú kí ó rù hangogo. Ṣé ọ̀rẹ́ wọn wá nìyí? Ní nǹkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn, àwọn àròṣe, ìbéèrè, àti okunra tí ó bùáyà ń bẹ nínú rẹ̀—kébé ló ń ta! Ìyá ọmọdékùnrin náà, tí ìbànújẹ́ bá, ń gbìyànjú láti fi èrò náà pé ọmọ òun ṣì wà láàyè bákan ṣá fún ara rẹ̀ ní ìrètí, ó sì fi ń tu ara rẹ̀ nínú. Tomijétomijé ni ó fi ń sọ ohun tí wọ́n ti fi kọ́ ọ lásọtúnsọ, pé: “Inú Tommy a túbọ̀ dùn báyìí. Ṣe ni Ọlọ́run ń fẹ́ kí Tommy wà pẹ̀lú òun ní ọ̀run.”
2 Ní Jamnagar, ní Íńdíà, nǹkan bí 11,000 kìlómítà síhìn-ín, àwọn ọmọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí baba onísòwò kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 58 bí ń tẹ́ òkú baba wọn sórí ibi tí a ti ń dáná sun òkú. Nínú oòrùn ìyálẹ̀ta tí ó mọ́lẹ̀ kedere, èyí àgbà nínú wọn bẹ̀rẹ̀ ààtò jíjó òkú náà nípa fífi ògùṣọ̀ tanná ran àwọn ìtì igi náà, ó sì ń tú àpòpọ̀ èròjà atasánsán àti tùràrí sára òkú baba rẹ̀. Àdúrà ìsìnkú tí àlùfáà Híńdù kan ń gbà léraléra, ní èdè Sanskrit, tí ó túmọ̀ sí: “Ǹjẹ́ kí ọkàn tí kì í kú láé máa bá ìsapá rẹ̀ nìṣó láti di ọ̀kan náà pẹ̀lú ẹni atóbijù,” borí ìtapàrà iná náà.
3 Bí tẹ̀gbọ́n tàbúrò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe ń wo bí òkú náà ṣe ń jó, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ mo gba ìwàláàyè lẹ́yìn ikú gbọ́?’ Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ibi tí wọ́n ti kàwé, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìdáhùn wọn. Ó dá èyí tí ó kéré jù nínú wọn lójú pé baba wọn olùfẹ́ yóò tún padà wá sínú ìgbésí ayé tí ó tún gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Èyí tí ó wà láàárín gbà gbọ́ pé ṣe ni àwọn òkú wà bí pé wọ́n ń sùn, láìmọ ohunkóhun rárá. Èyí àgbà pátápátá kàn gbà bẹ́ẹ̀ ni pé ikú wà lóòótọ́, nítorí ó rò pé kò sí ẹnì kan tí ó lè mọ àmọ̀dájú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú.
Ìbéèrè Kan Ṣoṣo, Ìdáhùn Rẹpẹtẹ
4. Ìbéèrè wo ni ó ti dààmú aráyé látọdúnmọ́dún?
4 Ìwàláàyè ha wà lẹ́yìn ikú bí? jẹ́ ìbéèrè kan tí ó ń da aráyé láàmú láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá. Hans Küng, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì, sọ pé: “Kódà nígbà tí ìbéèrè yìí bá dojú kọ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, kìí bá wọn lára dé.” Látọdúnmọ́dún wá ni àwọn ènìyàn nínú onírúurú àwùjọ ti ń ṣàṣàrò lórí kókó yìí, jáǹtìrẹrẹ sì ni àwọn ìdáhùn tí wọ́n ti dá lábàá.
5-8. Kí ni onírúurú ẹ̀sìn fi ń kọ́ni nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
5 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afẹnujẹ́ Kristẹni nígbàgbọ́ pé ọ̀run àti ọ̀run àpáàdì wà. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ní tiwọn gbà gbọ́ nínú àtúnwáyé. Nígbà tí Amir Muawiyah, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ibùdó ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn Ìsìláàmù kan, ń ṣàlàyé nípa ojú ìwòye àwọn Mùsùlùmí, ó sọ pé: “Àwa gbà gbọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ kan yóò wà lẹ́yìn ikú, nígbà tí o máa wá síwájú Ọlọ́run, Allah, tí yóò sì dà bí ẹní rìn wọnú kóòtù.” Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ti ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ṣe ni Allah yóò gbé ìgbésí ayé olúkúlùkù yẹ̀ wò, tí yóò sì yan onítọ̀hún sínú párádísè tàbí sínú iná àjóòkú.
6 Ní Sri Lanka, ṣe ni àwọn ẹlẹ́sìn Búdà àti ti Kátólíìkì máa ń ṣí àwọn ilẹ̀kùn àti fèrèsé sílẹ̀ gbayawu nígbà tí ẹnì kan bá kú nínú agboolé wọn. Wọn yóò tan àtùpà kan, wọn yóò sì tẹ́ òkú náà sílẹ̀ ní kíkọ ẹsẹ̀ rẹ̀ síhà ẹnu ọ̀nà àbájáde. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ṣíṣe báyìí yóò mú kí ó rọrùn fún ẹ̀mí, tàbí ọkàn òkú náà láti jáde kúrò nínú ilé náà.
7 Ronald M. Berndt, ní Yunifásítì Western Australia, sọ pé àwọn Ọmọ Onílẹ̀ ní Australia gbà gbọ́ pé “a kò lè pa ẹ̀mí àwọn ènìyàn run.” Àwọn ẹ̀yà kan nílẹ̀ Áfíríkà gbà gbọ́ pé, lẹ́yìn ikú, ṣe ni àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ máa ń di àkúdàáyà, ṣùgbọ́n àwọn gbajúmọ̀ a di òòṣà àkúnlẹ̀bọ tí a ń bọlá fún tí a sì ń ké pè gẹ́gẹ́ bí ẹni àìrí tí ó jẹ́ aṣáájú agbègbè náà.
8 Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ọkàn àwọn òkú jẹ́ àyípọ̀ àṣà ìbílẹ̀ àti ti àwọn afẹnujẹ́ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, pé kí a fi nǹkan bo àwọn dígí nígbà tí ẹnì kan bá kú kí ẹnikẹ́ni má báa wò ó kí ó sì lọ rí àfarahàn ẹni tí ó kú. Lẹ́yìn èyí, 40 ọjọ́ lẹ́yìn ikú olólùfẹ́ náà, tẹbí tọ̀rẹ́ yóò wá ṣayẹyẹ ìgòkè re ọ̀run ọkàn rẹ̀.
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Kan Náà
9, 10. Inú ẹ̀kọ́ ṣíṣe kókó wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn ti bára mu?
9 Àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá kú yàtọ̀ síra gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti ìgbàgbọ́ àwọn tí ń dáhùn wọn bá ṣe yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, èrò ṣíṣe kókó kan bára mu nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn: Ohun kan lára ènìyàn—ọkàn, ẹ̀mí, òjìji ènìyàn—jẹ́ aláìleèkú, ó sì ń bá a lọ láti wà láàyè lẹ́yìn ikú.
10 Ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀sìn àti ẹ̀ya ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ó jẹ́ olórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù pẹ̀lú. Nínú ẹ̀sìn àwọn Híńdù, ìgbàgbọ́ yìí gan-an ni ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àtúnwáyé. Àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ pé ṣe ni ọkàn àti ara jọ máa ń wà láàyè pọ̀, àmọ́ tí ara bá kú, ọkàn ṣì máa ń wà láàyè. Àwọn ẹ̀sìn mìíràn—àwọn Abọmọlẹ̀ ní Áfíríkà, ẹ̀sìn Ṣintó, àti ẹ̀sìn Búdà pàápàá—ń fi ẹṣin ọ̀rọ̀ kan náà yìí kọ́ni lọ́nà tí ó yàtọ̀ síra.
11. Báwo ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣe wo èrò náà pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú?
11 Ojú ìwòye àwọn kan jẹ́ òdì-kejì, ìyẹn ni pé, ìwàláàyè ń dópin nígbà ikú. Lójú tiwọn, èrò náà pé ìwàláàyè, ní ti ìmọ̀lára àti ti ìrònú, ṣì ń bá a lọ nínú ọkàn kan tí ó dà bí òjìji, tí kò ní ara, kò mọ́gbọ́n dání. Miguel de Unamuno, òǹkọ̀wé àti ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ọ̀rúndún ogún, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì, kọ̀wé pé: “Láti gba àìleèkú ọkàn gbọ́ ni láti fẹ́ kí ọkàn di aláìleèkú, ṣùgbọ́n láti fi tipátipá fẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò súni dépò pé a óò gbójú fo ìrònú tí ó bọ́gbọ́n mu dá tí a óò sì hùwà òpònú.” Lára àwọn tí ó kọ̀ láti gbà gbọ́ pé ènìyàn jẹ́ aláìleèkú ni àwọn gbajúmọ̀ ọlọ́gbọ́n èrò orí ìgbàanì bí, Aristotle àti Epicurus, Hippocrates tí ó jẹ́ oníṣègùn, ọlọ́gbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Scotland náà, David Hume, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Arébíà náà, Averroës, àti Jawaharlal Nehru, olórí ìjọba ilẹ̀ Íńdíà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbòmìnira.
12, 13. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni ó jẹyọ nípa ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn?
12 Ìbéèrè náà ni pé, Ṣé a ní ọkàn tí kò lè kú lóòótọ́? Bí ọkàn kò bá jẹ́ aláìleèkú lóòótọ́, báwo wá ni irú ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ ṣe di apá ṣíṣe kókó kan nínú ọ̀pọ̀ jú lọ àwọn ẹ̀sìn òde òní? Ibo ni irú èrò bẹ́ẹ̀ ti pilẹ̀? Bí ó bá jẹ́ pé ọkàn ń dẹ́kun wíwàláàyè nígbà ikú, ìrètí wo ni ó wá wà fún àwọn òkú?
13 A ha lè rí ìdáhùn tí ó jóòótọ́ tí ó sì tẹ́ni lọ́rùn sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìwọ̀nyí àti àwọn ìbéèrè mìíràn ni a óò dáhùn nínú àwọn ojú ìwé tí ó tẹ̀ lé e. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe bẹ̀rẹ̀.