ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • cl ojú ìwé 3
  • Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
  • Sún Mọ́ Jèhófà
Sún Mọ́ Jèhófà
cl ojú ìwé 3

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Òǹkàwé Wa Ọ̀wọ́n:

Ṣé o gbà pé o sún mọ́ Ọlọ́run? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ò rí tàwọn rò, àwọn míì sì gbà pé ìwà àwọn ò dáa, torí náà àwọn ò yẹ lẹ́ni tó lè sún mọ́ Ọlọ́run rárá. Síbẹ̀, Bíbélì fìfẹ́ rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jémíìsì 4:8) Ọlọ́run tiẹ̀ fi dá àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ lójú pé: “Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’”​—Àìsáyà 41:13.

Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run débi tá a fi máa di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Òótọ́ kan ni pé, kéèyàn tó lè dọ̀rẹ́ ẹnì kan, èèyàn á kọ́kọ́ mọ onítọ̀hún, á mọ ìwà àti ìṣe ẹ̀, á sì mọyì wọn. Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì pé ká mọ Ọlọ́run, ká mọ bó ṣe ń ronú, ká mọ ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, ká sì mọyì àwọn ìwà àti ìṣe ẹ̀. Èyí máa gba pé ká ṣèwádìí nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun míì tó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká fara balẹ̀ ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń fi àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ hàn, ká kíyè sí bí Jésù Kristi ṣe ń gbé àwọn ìwà yìí yọ láìkù síbì kan, ká sì wo bí àwa náà ṣe lè fìwà jọ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀. Tá a bá fara balẹ̀ ṣèwádìí yìí, àá rí i pé Jèhófà nìkan ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Àá tún rí i pé òun ni Baba tó ju baba lọ láyé àti lọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, àá gbà pé ó jẹ́ alágbára, onídàájọ́ òdodo, ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ tí kì í kọ àwọn ọmọ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀.

Àdúrà wa ni pé kí ìwé yìí mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, kó o di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, kó o lè wà láàyè títí láé, kó o sì máa yin Jèhófà lógo.

Àwa Òǹṣèwé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́