ORÍ 1
“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí!”
1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè wo lo máa fẹ́ bi Ọlọ́run? (b) Kí ni Mósè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run?
KÁ NÍ o kàn dédé gbóhùn Ọlọ́run, tó ń bá ẹ sọ̀rọ̀, kí lo máa ṣe ná? Pé o kàn tiẹ̀ gbóhùn Olódùmarè, àyà ẹ á kọ́kọ́ já! Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ súnra kì ná, lẹ́yìn náà kó o ṣọkàn akin, kó o sì gbìyànjú láti dá a lóhùn. Ká sọ pé òun náà fèsì, tó fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, tó wá sọ fún ẹ pé o lè bi òun ní ìbéèrè èyíkéyìí. Kí lo máa bi í?
2 Ọkùnrin kan wà tírú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí nígbà àtijọ́. Mósè lorúkọ ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ ohun tó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Kò béèrè nǹkan kan nípa ara ẹ̀, kò béèrè nípa bí ọjọ́ ọ̀la òun ṣe máa rí, bẹ́ẹ̀ ni kò béèrè nípa ìdí tí ìṣòro fi pọ̀ láyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, orúkọ Ọlọ́run ló béèrè. O lè máa ronú pé kí nìdí tí Mósè fi béèrè orúkọ Ọlọ́run nígbà tó jẹ́ pé ó ti mọ orúkọ náà tẹ́lẹ̀. A jẹ́ pé nǹkan míì ni Mósè fẹ́ mọ̀. Ká sòótọ́, ìbéèrè pàtàkì ni Mósè béèrè yìí. Ohun tí Ọlọ́run fi dá a lóhùn sì máa ṣe àwa náà láǹfààní. Torí ó máa jẹ́ kó wù wá gan-an láti sún mọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìjíròrò pàtàkì yẹn.
3, 4. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ kí Ọlọ́run tó bá Mósè sọ̀rọ̀, kí làwọn méjèèjì sì sọ?
3 Nígbà tí Mósè jẹ́ ẹni ogójì (40) ọdún, ó sá kúrò ní Íjíbítì níbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn ẹ̀ ti ń ṣẹrú. Odindi ogójì (40) ọdún ló fi wà níbi tó sá lọ náà. Ó ti wá pé ẹni ọgọ́rin (80) ọdún báyìí. Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń da agbo ẹran bàbá ìyàwó rẹ̀ nínú pápá, ó rí ohun kan tó yà á lẹ́nu. Iná ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún kan. Iná yìí ń jó láìdáwọ́ dúró, àmọ́ igi náà ò jó. Mósè wá sún mọ́ ibẹ̀ láti wò ó. Ló bá dédé gbọ́ ohùn láti inú iná yẹn! Ohùn áńgẹ́lì ni, Ọlọ́run ló rán an pé kó wá bá Mósè sọ̀rọ̀, àwọn méjèèjì sì jọ sọ̀rọ̀ fúngbà díẹ̀. Ọlọ́run ní kí Mósè fi ìgbé ayé ìdẹ̀ra tó ń gbé sílẹ̀, kó sì pa dà sí Íjíbítì láti lọ gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú.—Ẹ́kísódù 3:1-12.
4 Rò ó wò ná, ohun tó bá wu Mósè ló lè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run lásìkò yẹn. Ṣùgbọ́n, kíyè sí ohun tó béèrè, ó ní: “Ká ní mo lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí mo sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì bi mí pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n sọ fún wọn?”—Ẹ́kísódù 3:13.
5, 6. (a) Ohun pàtàkì wo la rí kọ́ nínú ìbéèrè tí Mósè bi Ọlọ́run? (b) Kí ni ọ̀kan lára ìwà àfojúdi táwọn ẹlẹ́sìn hù? (d) Àǹfààní wo ni Ọlọ́run fẹ́ ká ní bó ṣe sọ orúkọ rẹ̀ fún wa?
5 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìbéèrè yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lórúkọ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò gbà pé ó yẹ káwọn mọ orúkọ náà. Torí náà, àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, wọ́n sì fi orúkọ oyè bí “Olúwa” àti “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ ọ̀kan lára ìwà àfojúdi tó burú jù lọ táwọn ẹlẹ́sìn hù. Jẹ́ ká wò ó báyìí ná, kí lo kọ́kọ́ máa ń ṣe nígbà àkọ́kọ́ tíwọ àti ẹnì kan bá pàdé? Wàá fẹ́ mọ orúkọ ẹ̀, àbí? Bí ọ̀rọ̀ mímọ Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn. Òun náà lórúkọ, ó ṣeé sún mọ́, ó bìkítà, ọ̀rọ̀ wa sì yé e dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí Ọlọ́run, ó wà lóòótọ́. Ó lórúkọ, Jèhófà sì ni orúkọ rẹ̀.
6 Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run sọ orúkọ rẹ̀ fáwa èèyàn, ohun ńlá kan ló fẹ́ ṣe fún wa. Ó fẹ́ fún wa láǹfààní láti mọ òun, ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Torí ó mọ̀ pé ìyẹn lohun tó dáa jù lọ tá a lè fayé wa ṣe. Àmọ́ o, kì í ṣe pé Jèhófà kàn sọ orúkọ ẹ̀ fún wa, ó tún jẹ́ ká mọ irú ẹni tóun jẹ́.
Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run
7. (a) Kí ni ẹ̀rí fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí? (b) Kí ni Mósè ní lọ́kàn nígbà tó bi Ọlọ́run lórúkọ tó ń jẹ́?
7 Ọlọ́run ló sọ ara ẹ̀ ní orúkọ náà Jèhófà, orúkọ yìí sì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé orúkọ náà “Jèhófà” túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Kò sẹ́ni tó dà bíi rẹ̀ láyé àti lọ́run, torí òun ló dá ohun gbogbo, kò sì sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Kódà, ó lè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ aláìpé ní okun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè ṣe ohunkóhun tó bá ní lọ́kàn. Ẹ ò rí i pé ìyẹn jọni lójú gan-an! Àmọ́ o, orúkọ Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa irú ẹni tó jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi bi Ọlọ́run ní ìbéèrè yẹn. Ká sòótọ́, ó mọ̀ pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá, ó sì mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ rẹ̀. Àwọn èèyàn ti mọ orúkọ yẹn ṣáájú ìgbà ayé Mósè, wọ́n sì ti ń lò ó láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Torí náà, nígbà tí Mósè ń béèrè orúkọ Ọlọ́run, ńṣe ló fẹ́ mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tó ń béèrè ni pé: ‘Kí ni màá sọ nípa rẹ fáwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, kó lè dá wọn lójú pé wàá gbà wọ́n là lóòótọ́?’
8, 9. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn ìbéèrè Mósè, kí sì nìdí tí ọ̀nà táwọn kan gbà túmọ̀ ohun tí Ọlọ́run sọ kò fi tọ̀nà? (b) Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà, “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́”?
8 Nígbà tí Jèhófà máa fèsì, ó jẹ́ kó mọ ohun kan tó jọni lójú nípa irú ẹni tóun jẹ́, tó sì hàn nínú ìtumọ̀ orúkọ Rẹ̀. Ó sọ fún Mósè pé: “Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì túmọ̀ ibí yìí sí: “Èmi ni ẹni tí ó wà.” Ṣùgbọ́n àwọn Ìwé Mímọ́ tí ìtumọ̀ wọn péye fi hàn pé, kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ń sọ fún Mósè pé òun wà lóòótọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà ń kọ́ Mósè àti gbogbo wa lónìí, pé òun “yóò di” ohunkóhun tó bá yẹ kóun lè mú àwọn ìlérí òun ṣẹ. Bíbélì J. B. Rotherham túmọ̀ ẹsẹ yìí lọ́nà tó rọrùn. Ó sọ pé: “Èmi Yóò Di ohunkóhun tó bá wù mí.” Ọkùnrin kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì ṣàlàyé gbólóhùn yìí pé: “Láìka ohun tó bá ṣẹlẹ̀ tàbí bí ipò nǹkan bá ṣe nira tó . . . , Ọlọ́run máa ‘di’ ohunkóhun kó lè yanjú ìṣòro náà.”
9 Kí nìyẹn wá túmọ̀ sí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ó túmọ̀ sí pé láìka bí nǹkan ṣe nira fún wọn tó tàbí ìṣòro yòówù kó dé bá wọn, Jèhófà máa di ohunkóhun tó bá yẹ kó lè dá wọn nídè kúrò lóko ẹrú, kó sì mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ó dájú pé orúkọ yẹn mú kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Orúkọ yẹn lè mú káwa náà gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sáàmù 9:10) Lọ́nà wo?
10, 11. Báwo ni orúkọ Ọlọ́run ṣe mú ká gbà pé Baba tó ju baba lọ ni? Ṣàpèjúwe.
10 Bí àpẹẹrẹ: Oríṣiríṣi nǹkan làwọn òbí máa ń ṣe kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń pèsè oúnjẹ fún wọn, wọ́n máa ń bá wọn wí, wọ́n máa ń parí ìjà, nígbà míì sì rèé, wọ́n ní láti tọ́jú ọmọ tó ń ṣàìsàn tàbí kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan míì. Ẹ̀rù máa ń ba ọ̀pọ̀ òbí tí wọ́n bá ronú nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ní láti ṣe kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn. Torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ọmọ wọn fọkàn tán wọn. Ó ṣe tán àwọn ọmọ gbà pé kò sí ìṣòro táwọn òbí wọn ò lè yanjú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ máa ń retí pé káwọn òbí tọ́jú wọn tára àwọn ò bá yá, kí wọ́n báwọn parí ìjà, kí wọ́n báwọn tún ohun tó bà jẹ́ ṣe, kí wọ́n sì dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí táwọn bá ní. Àwọn nǹkan yìí máa ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ òbí, torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ò ní lè ṣe gbogbo ohun táwọn ọmọ wọn retí pé kí wọ́n ṣe.
11 Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà náà jẹ́. Àmọ́ òun yàtọ̀ sáwa èèyàn, torí kò sóhun tí kò lè dà kó lè tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà láyé. Tó bá sì ń tọ́jú wọn, kò ní tẹ àwọn ìlànà rẹ̀ lójú. Torí náà, ńṣe ni orúkọ náà Jèhófà ń jẹ́ ká rí i pé Baba tó ju baba lọ ni Ọlọ́run jẹ́. (Jémíìsì 1:17) Àwọn ohun kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kí Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ yòókù rí i pé orúkọ ń ro Jèhófà lóòótọ́. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí bó ṣe sọ ara rẹ̀ di onírúurú nǹkan kó lè gbà wọ́n là. Bí àpẹẹrẹ, ó bá wọn ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn, ó pín Òkun Pupa sí méjì, ó fún wọn ní òfin tó pé, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó pèsè oúnjẹ àti omi fún wọn lọ́nà àrà, kò jẹ́ kí aṣọ àti bàtà wọn gbó, ó sì ṣe àwọn nǹkan àrà míì fún wọn.
12. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín èrò tí Mósè ní àti èrò tí Fáráò ní nípa Jèhófà?
12 Nípa báyìí, Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ orúkọ òun, ó tún jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó jọni lójú nípa òun fúnra ẹ̀ tó ń jẹ́ orúkọ yẹn. Àwọn nǹkan tó ń ṣe sì fi hàn pé irú ẹni tó jẹ́ gan-an nìyẹn. Torí náà, ó dájú pé Ọlọ́run fẹ́ ká mọ òun. Ṣó wu ìwọ náà pé kó o mọ̀ ọ́n? Ó wu Mósè pé kó mọ Ọlọ́run. Èyí ló mú kó ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ nígbèésí ayé rẹ̀ kó lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ ọ̀run. (Nọ́ńbà 12:6-8; Hébérù 11:27) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà láyé nígbà ayé Mósè ni kò wù láti mọ Ọlọ́run. Nígbà tí Mósè dárúkọ Jèhófà fún Fáráò tó jẹ́ Ọba Íjíbítì, bí ọba agbéraga yẹn ṣe fèsì fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ó béèrè pé: “Ta ni Jèhófà?” (Ẹ́kísódù 5:2) Kì í ṣe pé Fáráò fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń sọ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ò já mọ́ nǹkan kan níbi tóun wà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ò ka Ọlọ́run sí. Ìdí nìyẹn tí wọ́n ò fi lóye òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí pé, Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ.
Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ
13, 14. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè nínú Bíbélì, kí sì ni díẹ̀ lára wọn? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 14.) (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo la lè pè ní “Olúwa Ọba Aláṣẹ”?
13 Jèhófà lágbára láti ṣe ohun gbogbo, ìdí nìyẹn tó fi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ oyè nínú Bíbélì. Kì í ṣe pé àwọn orúkọ oyè yìí ṣe pàtàkì ju orúkọ tó ń jẹ́ gangan; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ kọ́ wa nípa ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pè é ní “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” (2 Sámúẹ́lì 7:22) Orúkọ oyè yìí fara hàn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà tóbi lọ́lá. Òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
14 Jèhófà nìkan ni Ẹlẹ́dàá, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ìfihàn 4:11 sọ pé: “Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo àti ọlá àti agbára, torí ìwọ lo dá ohun gbogbo, torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Ká sòótọ́, Jèhófà nìkan làwọn ọ̀rọ̀ yìí tọ́ sí. Ká sọ pé Jèhófà ò dá ohun gbogbo, kò sóhun tó máa wà láyé àtọ̀run! Láìsí àní-àní, Jèhófà ló yẹ ká fi ọlá, agbára àti ògo fún torí pé òun ni Olúwa Ọba Aláṣẹ àti Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.
15. Kí nìdí tá a fi ń pe Jèhófà ní “Ọba ayérayé”?
15 Orúkọ oyè míì tí kò sí ẹnì kankan tó ń jẹ́ ẹ àfi Jèhófà ni “Ọba ayérayé.” (1 Tímótì 1:17; Ìfihàn 15:3) Kí ni ìtumọ̀ orúkọ oyè yìí? Ká sòótọ́, a ò lè lóye ohun tó túmọ̀ sí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, síbẹ̀ ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì lè ní òpin. Sáàmù 90:2 sọ pé: “Láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.” Ẹsẹ yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀ rárá, kò sì sígbà kankan tí kò ní sí. Bíbélì tún pè é ní “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé ó ti wà láti ayérayé ṣáájú kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó wà láyé àti lọ́run! (Dáníẹ́lì 7:9, 13, 22) Torí náà, ó dájú pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ.
16, 17. (a) Kí nìdí tá ò fi lè rí Jèhófà, kí sì nìdí tí kò fi yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu? (b) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jèhófà wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí i?
16 Àmọ́, àwọn kan ò gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ, bí Fáráò ọba Íjíbítì ayé ìgbà yẹn náà ò ṣe gbà. Ohun tó sì fà á ni pé, kìkì ohun táwọn èèyàn aláìpé bá lè fojú rí ni wọ́n sábà máa ń fẹ́ gbà gbọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a ò lè fojú rí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ torí pé ẹ̀mí ni. (Jòhánù 4:24) Yàtọ̀ síyẹn, téèyàn ẹlẹ́ran ara bá dé tòsí ibi tí Jèhófà wà lásán, ńṣe ni onítọ̀hún máa kú. Ó ṣe tán, òun fúnra ẹ̀ sọ fún Mósè pé: “O ò lè rí ojú mi, torí kò sí èèyàn tó lè rí mi, kó sì wà láàyè.”—Ẹ́kísódù 33:20; Jòhánù 1:18.
17 Kò yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu. Ìgbà kan wà tí áńgẹ́lì kan mú kí Mósè rí díẹ̀ lára ògo Jèhófà. Ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i? Fúngbà díẹ̀, ńṣe ni “ìtànṣán ń jáde” lára awọ ojú Mósè débi tẹ́rù fi ń ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wojú ẹ̀. (Ẹ́kísódù 33:21-23; 34:5-7, 29, 30) Torí náà, ó dájú pé kò sí èèyàn kankan tó lè fojú rí Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ! Àmọ́, bó ṣe jẹ́ pé a ò lè fojú rí Ọlọ́run, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò sí ni? Rárá o. Ó ṣe tán àwọn nǹkan kan wà tá ò lè rí, síbẹ̀ tá a gbà pé wọ́n wà, irú bí afẹ́fẹ́. Torí náà, bó ṣe jẹ́ pé a gbà pé àwọn nǹkan kan wà, yálà a rí wọn tàbí a ò rí wọn, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run wà. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tá a lè fojú rí tàbí fọwọ́ kàn ló máa ń gbó, tó sì máa ń bà jẹ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, kò yí pa dà láìka ti pé ó ti wà láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. (Mátíù 6:19) Ṣùgbọ́n, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé alágbára kan tá ò lè rí, tó kàn ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀ láìrí ti ẹnikẹ́ni rò ni Ọlọ́run? Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́.
Ọlọ́run Tí Ìwà àti Ìṣe Rẹ̀ Ṣàrà Ọ̀tọ̀
18. Ìran wo ni Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì, kí sì ni ojú mẹ́rin tí ‘àwọn ẹ̀dá alààyè’ tó wà láyìíká Jèhófà ń ṣàpẹẹrẹ?
18 Òótọ́ ni pé a ò lè rí Ọlọ́run, àmọ́ àwọn àkọsílẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ bí ọ̀run ṣe rí. Àpẹẹrẹ kan lèyí tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí kìíní. Jèhófà jẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì rí ìran kan nípa apá ti ọ̀run lára ètò Rẹ̀. Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí náà dà bíi kẹ̀kẹ́ ẹṣin ńlá kan. Bí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá tó wà láyìíká Jèhófà ṣe rí wú Ìsíkíẹ́lì lórí gan-an. (Ìsíkíẹ́lì 1:4-10) ‘Àwọn ẹ̀dá alààyè’ yìí sún mọ́ Jèhófà gan-an, ìrísí wọn sì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì nípa Ọlọ́run tí wọ́n ń sìn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin, ìyẹn ojú akọ màlúù, ojú kìnnìún, ojú ẹyẹ idì àti ojú èèyàn. Ẹ̀rí fi hàn pé, ńṣe làwọn nǹkan yìí ṣàpẹẹrẹ ànímọ́ mẹ́rin tó dà bí ìpìnlẹ̀ fáwọn ànímọ́ tó ta yọ tí Jèhófà ní.—Ìfihàn 4:6-8, 10.
19. Ìwà àti ìṣe wo làwọn nǹkan yìí ṣàpẹẹrẹ? (a) ojú akọ màlúù (b) ojú kìnnìún (d) ojú ẹyẹ idì (e) ojú èèyàn
19 Nínú Bíbélì, akọ màlúù sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ agbára, ìyẹn sì bá a mu torí pé akọ màlúù lágbára gan-an. Kìnnìún sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo ní tiẹ̀. Ìdí ni pé ó gba ìgboyà kẹ́nì kan tó lè jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé kìnnìún jẹ́ ẹranko tó nígboyà. Ojú ẹyẹ idì máa ń ríran jìnnà, débi pé ó lè rí àwọn nǹkan kéékèèké tó wà níbi tó jìnnà gan-an. Torí náà, a lè fi ojú ẹyẹ idì wé ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi máa ń rí tàbí mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kí wá ni ojú èèyàn ń ṣàpẹẹrẹ? Ìfẹ́ ni. Àwòrán Ọlọ́run làwa èèyàn jẹ́, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé èèyàn nìkan ló lè fi ìfẹ́ hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìfẹ́ yìí ló sì ṣe pàtàkì jù lára àwọn ìwà àti ìṣe Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́ yìí ni Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ nípa wọn jù tó bá ń sọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Torí náà, a lè sọ pé àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló ṣe pàtàkì jù lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà.
20. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò tíì yí pa dà?
20 Ṣé Ọlọ́run ti wá yí pa dà lẹ́yìn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tí Bíbélì ti sọ irú ẹni tó jẹ́? Rárá o, àwọn ìwà àti ìṣe Ọlọ́run ò lè yí pa dà. Ó sọ fún wa pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kì í yí pa dà.” (Málákì 3:6) Dípò tí Jèhófà á fi yí pa dà, ṣe ló máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ síra kó lè ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn sì jẹ́ ká gbà pé Baba tó ju baba lọ ni. Ìfẹ́ ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an nínú gbogbo ìwà àti ìṣe rẹ̀. Ó máa ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe, títí kan ọ̀nà tó gbà ń lo agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó lára àwọn ìwà àti ìṣe Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Kíyè sí i pé Bíbélì ò sọ pé Ọlọ́run ní ìfẹ́ tàbí pé Ọlọ́run máa ń fìfẹ́ hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ gan-an ni Ọlọ́run, ìfẹ́ yìí ló sì ń sún un ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe.
“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí!”
21. Báwo ló ṣe máa rí lára wa tá a bá túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́?
21 Ṣé o ti ríbi tí ọmọ kékeré kan ti ń fi bàbá rẹ̀ han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tínú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń sọ fún wọn pé, “Bàbá mi nìyẹn”? Ó dájú pé wàá gbà pé ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ bàbá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ṣe yẹ kí Jèhófà rí sáwọn tó ń sìn ín. Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn olóòótọ́ èèyàn máa kéde pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí!” (Àìsáyà 25:8, 9) Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, bẹ́ẹ̀ láá túbọ̀ máa dá ẹ lójú pé Baba tó ju baba lọ ni.
22, 23. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Bàbá wa ọ̀run, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ó fẹ́ ká sún mọ́ òun?
22 Àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́sìn àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí gbà pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì rí tiwa rò. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ sún mọ́ irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún gan-an. Kódà Bíbélì sọ pé, “Ọlọ́run aláyọ̀” ni. (1 Tímótì 1:11) Ohun tá a bá ṣe lè múnú Jèhófà dùn, ó sì lè bà á nínú jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó fún àwọn èèyàn ní òfin káyé wọn lè dáa. Torí pé wọn ò tẹ̀ lé òfin náà, Bíbélì sọ pé: ‘Ọkàn rẹ̀ bà jẹ́.’ (Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Sáàmù 78:41) Ṣùgbọ́n tá a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tá a sì ń ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, a máa “mú ọkàn [rẹ̀] yọ̀.”—Òwe 27:11.
23 Bàbá wa ọ̀run fẹ́ ká sún mọ́ òun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wá níyànjú pé ká ‘táràrà fún un, ká sì rí i ní ti gidi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.’ (Ìṣe 17:27) Àmọ́ o, báwo làwa èèyàn lásánlàsàn ṣe lè sún mọ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run?