Èèpo Ẹ̀yìn Ìwé
Ìwé yìí á bá ẹ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó dá lórí
Ó dájú pó o nílò ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé! Irú ìmọ̀ràn yẹn gan-an lo máa rí nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Apá kìíní ìwé yìí wà ní èdè tó lé ní ọgọ́rin [80], ó sì lé ní ogójì [40] mílíọ̀nù ẹ̀dà tá a tẹ̀ jáde. Bíi ti apá kìíní, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tá a ṣe pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀dọ́ láti onírúurú ibi kárí ayé la gbé apá kejì yìí kà. Ìmọ̀ràn tí kì í bà á tì látinú Bíbélì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọpọ́n sún kan ìwọ náà báyìí láti rí ọ̀nà tó lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́.
“Ní ọgbọ́n, ní òye.”—Òwe 4:5.