APÁ 4
Iléèwé Àtàwọn Ojúgbà Rẹ
Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣe dáadáa nínú àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n ń kọ́ yín níléèwé?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣé wọ́n ti halẹ̀ mọ́ ẹ níléèwé rí àbí wọ́n ti fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ rí?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣó máa ń ṣe ẹ́ nígbà míì bíi pé kó o dara pọ̀ mọ́ àwọn ojúgbà ẹ láti hùwà tí kò dáa?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
O lè máa rò ó nínú ara ẹ pé, ‘Bí mo bá lè kẹ́sẹ járí níléèwé, kò sí ohunkóhun tí mi ò lè ṣe mọ́ nìyẹn!’ Òótọ́ díẹ̀ sì wà nínú ọ̀rọ̀ yẹn o. Ó ṣe tán, iléèwé máa ń jẹ́ kéèyàn mọ ibi tí ọpọlọ òun já fáfá dé, ibi tóun lè fara da nǹkan mọ àti bóun ṣe lè dá ṣèpinnu sí. Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ kíkọ́ láì jẹ́ káwọn kan lára àwọn ojúgbà ẹ kó ìwàkiwà ràn ẹ́? Orí 13 sí 17 nínú ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó yẹ kó o mọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 112, 113]