Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
IRÚ ÈÈYÀN TÍ A JẸ́
Ẹ̀kọ́ 1 sí 4
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní ilẹ̀ tí ó tó igba ó lé ogójì (240), a sì wá látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Kí ló mú ká wà ní ìṣọ̀kan? Irú èèyàn wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
IṢẸ́ WA
Ẹ̀kọ́ 5 sí 14
Àwọn èèyàn mọ iṣẹ́ ìwàásù wa dáadáa. A tún máa ń pé jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, a sì máa ń jọ́sìn níbẹ̀. Báwo la ṣe ń ṣe àwọn ìpàdé wa, àwọn wo ló sì lè wá síbẹ̀?
ÈTÒ ÌJỌSÌN WA
Ẹ̀kọ́ 15 sí 28
Ètò ìjọsìn wa wà kárí ayé, a kì í fi ẹ̀sìn ṣòwò, àwọn èèyàn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ló wà nínú àwọn ìjọ wa. Báwo la ṣe ṣètò ìjọsìn wa? Ta ló ń darí ètò náà? Báwo la ṣe ń rí owó tí à ń ná? Ṣé òótọ́ ni ètò náà ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ lóde òní?