ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es17 ojú ìwé 26-36
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, March 1
  • Thursday, March 2
  • Friday, March 3
  • Saturday, March 4
  • Sunday, March 5
  • Monday, March 6
  • Tuesday, March 7
  • Wednesday, March 8
  • Thursday, March 9
  • Friday, March 10
  • Saturday, March 11
  • Sunday, March 12
  • Monday, March 13
  • Tuesday, March 14
  • Wednesday, March 15
  • Thursday, March 16
  • Friday, March 17
  • Saturday, March 18
  • Sunday, March 19
  • Monday, March 20
  • Tuesday, March 21
  • Wednesday, March 22
  • Thursday, March 23
  • Friday, March 24
  • Saturday, March 25
  • Sunday, March 26
  • Monday, March 27
  • Tuesday, March 28
  • Wednesday, March 29
  • Thursday, March 30
  • Friday, March 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2017
es17 ojú ìwé 26-36

March

Wednesday, March 1

Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.​—Ják. 4:14.

Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn Jèhófà dénú, tí wọ́n sì ń ro ohun tó máa ṣe ìjọ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú, máa ń ṣètò déédéé láti ṣàjọpín ìrírí wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó kéré sí wọn. (Sm. 71:​17, 18) Àwọn alàgbà tó ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ìbùkún fún agbo. Wọ́n ń jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ jẹ́ alágbára kí wọ́n lè borí ìdẹwò. Lọ́nà wo? Tí àwọn alàgbà bá ń sapá láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, a máa rí àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i tí wọ́n á lè ran ìjọ lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan nísinsìnyí, àti pàápàá jù lọ lákòókò tí nǹkan bá le koko nígbà ìpọ́njú ńlá. (Ìsík. 38:​10-12; Míkà 5:​5, 6) Nítorí náà, ẹ̀yin alàgbà wa ọ̀wọ́n, à ń rọ̀ yín pé láti àkókò yìí lọ ẹ máa dá àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ déédéé bẹ́ ẹ ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín. A mọ̀ pé àkókò tẹ́ ẹ̀ ń lò láti bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ pọ̀, ó tiẹ̀ lè dà bíi pé ó ń tán yín lókun. Nítorí náà, ó lè pọn dandan pé kí ẹ dín àkókò tí ẹ̀ ń lò fún àwọn nǹkan yẹn kù, kí ẹ lè ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. (Oníw. 3:⁠1) Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń pọn omi sílẹ̀ de òùngbẹ. w15 4/15 1:8-10

Thursday, March 2

Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé, “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”​—Aísá. 30:21.

Kò sí àní-àní pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì wà fún gbogbo èèyàn. Àmọ́, ǹjẹ́ Bíbélì sọ bí ìwọ alára ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lọ́nà wo? Bó o ṣe ń ka Bíbélì déédéé tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tó o bá ń kíyè sí bí ohun tó sọ ṣe rí lára rẹ, tó o sì ń ronú lórí bó o ṣe lè fi ohun tó o kà náà sílò, ò ń jẹ́ kí Jèhófà lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti bá ẹ sọ̀rọ̀ nìyẹn. Èyí á sì jẹ́ kí o ní àjọṣe tó túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Héb. 4:12; Ják. 1:​23-25) Bí àpẹẹrẹ, ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, “ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé,” kó o sì ṣàṣàrò lé e lórí. Tí ọkàn ẹ bá balẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run lo fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ, o máa mọ̀ ọ́n lára pé inú Jèhófà dùn sí ẹ. Ṣùgbọ́n tó o bá wá rí i pé ó yẹ kó o jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ ẹ lọ́rùn kó o sì máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a jẹ́ pé Jèhófà ti jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kí o ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ òun.​—Mát. 6:19, 20. w15 4/15 3:3-5

Friday, March 3

Olúwa dúró lẹ́bàá mi, ó sì fi agbára sínú mi, pé nípasẹ̀ mi, kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù náà ní kíkún àti kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ; a sì dá mi nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún.​—2 Tím. 4:17.

Bíi ti Pọ́ọ̀lù, tá a bá ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù, a jẹ́ pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fi gbogbo nǹkan mìíràn tó ṣe pàtàkì “kún un fún” wa. (Mát. 6:33) À ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, torí náà a ti ‘fi ìhìn rere sí ìkáwọ́’ wa, Jèhófà sì kà wá sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀. (1 Tẹs. 2:4; 1 Kọ́r. 3:⁠9) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó máa jẹ́ ká lè ṣe sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa mú ìtura wá. Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká lo àkókò tá a wà yìí láti mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán sí i. Bí ohunkóhun bá mú ká máa ṣàníyàn, ẹ jẹ́ ká lo àǹfààní náà láti sún mọ́ Jèhófà sí i. Tí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tí à ń gbàdúrà láìdabọ̀, tí à sì tún tẹra mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó lè kó wa yọ nínú àwọn ìṣòro ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tó fi mọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ká sì gbà pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. w15 4/15 4:17, 18

Saturday, March 4

Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín?​—Ják. 4:1.

Ìgbéraga lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́. Kò sí àní-àní, tá a bá kórìíra àwọn èèyàn, tá a sì gbà pé a lọ́lá jù wọ́n lọ, ó lè mú ká sọ̀rọ̀ tàbí hùwà àìdáa sí wọn, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. (Òwe 12:18) Tá a bá ní in lọ́kàn pé a lọ́lá ju àwọn ẹlòmíì lọ, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé, “olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Òwe 16:⁠5) Ó tún máa dáa ká kíyè sí èrò wa nípa àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà míì, àwọn tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa tàbí tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì. Tá a bá ní in lọ́kàn pé ẹ̀yà wa tàbí orílẹ̀-èdè wa lọ́lá ju tàwọn míì, á jẹ́ pé a ò gbà pé ‘láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.’ (Ìṣe 17:26) Tá a bá fi ohun tí Bíbélì sọ yìí sọ́kàn, a ó rí i pé ẹ̀yà kan péré ló wà, torí pé láti ara Ádámù tó jẹ́ baba ńlá wa ni gbogbo wa ti ṣẹ̀ wá. Nítorí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé àwọn ẹ̀yà kan lọ́lá ju àwọn míì lọ. Irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ṣètìlẹyìn fún ètekéte Sátánì láti ba ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni jẹ́. (Jòh. 13:35) Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a gbọ́dọ̀ kíyè sára ká má ṣe máa gbéra ga lọ́nàkọnà.​—Òwe 16:18. w15 5/15 2:8, 9

Sunday, March 5

Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run.​—Éfé. 5:1.

Láìsí àní-àní, ayọ̀ wá kún torí pé Ọlọ́run ti ṣèlérí àìleèkú ní ọ̀run fún àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró àti ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. (Jòh. 10:16; 17:3; 1 Kọ́r. 15:53) Ó dájú pé àwọn tó máa gba àìleèkú ní ọ̀run àtàwọn tó máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé kò ní fojú winá ìjìyà èyíkéyìí mọ́. Jèhófà mọ ìyà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ nígbà tí wọ́n wà lóko ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ náà ló sì mọ ohun tá à ń dojú kọ lónìí. Àní sẹ́, “nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísá. 63:⁠9) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìbẹ̀rùbojo mú àwọn Júù torí pé àwọn ọ̀tá ń dí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì kọ́, àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sek. 2:⁠8) Bí ìyá kan ṣe máa tọ́jú ọmọ rẹ̀ jòjòló lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, Jèhófà náà máa ń fìfẹ́ gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. (Aísá. 49:15) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara rẹ̀ wò, ó sì dá àwa náà lọ́nà tá a fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.​—Sm. 103:13, 14. w15 5/15 4:2

Monday, March 6

Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.​—Mát. 26:11.

Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kò sígbà tí kò ní sí àwọn òtòṣì láyé? Rárá o, ohun tó ń sọ ni pé bí ètò nǹkan ìsinsìnyí tó ti dìdàkudà yìí bá ṣì ń bá a nìṣó, kò sígbà tí kò ní sí àwọn òtòṣì. Lóde òní, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kò ní àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé torí pé ìjọba èèyàn ń ṣojúsàájú. Àmọ́, ìtura dé tán! (Sm. 72:16) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe mú kó dá wa lójú pé ó lágbára láti lo ọlá àṣẹ tó ní láti fi ṣe ohun rere fún wa, ó sì wù ú láti lò ó láìpẹ́. (Mát. 14:​14-21) Òótọ́ ni pé a ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu, àmọ́ a lè lo gbogbo okun wa káwọn èèyàn lè gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì mú kó dá wa lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Torí pé Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ni wá, tá a sì láǹfààní láti mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ǹjẹ́ kò yẹ ká sọ fún àwọn ẹlòmíì náà nípa rẹ̀? (Róòmù 1:​14, 15) Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí èyí, á mú ká lè sọ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn.​—Sm. 45:1; 49:3. w15 6/15 1:7, 10, 11

Tuesday, March 7

Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, . . . kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara.​—Ják. 4:8.

Tá a bá ka àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà sí ohun tó ṣeyebíye, àá sapá láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, títí kan àwọn ohun tá à ń rò lọ́kàn. Tá a bá fẹ́ “mọ́ ní ọkàn-àyà,” ó yẹ ká máa ronú lórí ohun tí ó mọ́, ohun tó tọ́ àti ohun tí ó yẹ fún ìyìn. (Sm. 24:​3, 4; 51:6; Fílí. 4:⁠8) Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń gbójú fo àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tí àìpé wa máa ń fà, torí ó mọ̀ pé èròkerò lè wá sí wa lọ́kàn. Síbẹ̀, a mọ̀ pé inú Ọlọ́run ò ní dùn tá a bá fàyè gba èrò tí kò tọ́ lọ́kàn wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti má ṣe fàyè gbà á. (Jẹ́n. 6:​5, 6) Tá a bá ń ronú lórí kókó yìí, èyí á jẹ́ kí ìpinnu wa láti mú kí èrò ọkàn wa jẹ́ mímọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Ọ̀nà pàtàkì kan tó máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ni pé, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká lè borí èrò tí kò tọ́. Tá a bá sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà, òun náà á sún mọ́ wa. Jèhófà máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ní fàlàlà ká lè túbọ̀ dúró lórí ìpinnu wa láti sá fún èrò ìṣekúṣe, ká sì jẹ́ oníwà mímọ́. w15 6/15 3:4, 5

Wednesday, March 8

Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.​—Mát. 6:11.

Ẹ kíyè sí i pé ìbéèrè ara ẹni yìí kì í wulẹ̀ ṣe pé fún “mi” ní oúnjẹ fún ọjọ́ òní, àmọ́ fún “wa” ní oúnjẹ fún ọjọ́ òní. Alábòójútó àyíká kan nílẹ̀ Áfíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor sọ pé: “Mo sábà máa ń fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti ìyàwó mi kì í dààmú lórí ohun tá a máa jẹ tàbí bá a ṣe máa rí owó ilé san. Àwọn ará ló máa ń fìfẹ́ bójú tó wa lójoojúmọ́. Àmọ́, mo máa ń gbàdúrà pé kí àwọn tó ń ràn wá lọ́wọ́ lè rí ọ̀nà láti bójú tó ìṣúnná owó wọn.” Tá a bá ní oúnjẹ tó pọ̀ tó láti jẹ fáwọn ìgbà kan, a lè ronú kan àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ṣaláìní tàbí àwọn tí ìjábá ti ba nǹkan ìní wọn jẹ́. Kì í ṣe pé ká kàn gbàdúrà fún wọn nìkan, àmọ́ ká tún ṣe ohun tó bá àdúrà náà mu. Bí àpẹẹrẹ, a lè fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ṣaláìní látinú ohun tá a ní. Bákan náà, a lè máa fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé déédéé, bá a ṣe mọ̀ pé a máa ń lo irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó yẹ.​—1 Jòh. 3:17. w15 6/15 5:4-6

Thursday, March 9

Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa títí a ó fi kú.​—Sm. 48:14.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyípadà àgbàyanu kan tó máa wáyé nínú apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà wà nínú ìwé Aísáyà 60:17. Àwọn ọ̀dọ́ tàbí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ti ka ọ̀pọ̀ ohun tó jẹ́rìí sí i pé ìyípadà yìí ń wáyé tàbí kí wọ́n ti gbọ́ nípa rẹ̀ látẹnu àwọn míì. Àmọ́ àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí àwọn ìyípadà náà ṣojú wọn. Abájọ tó fi dá wọn lójú pé Jèhófà ń lo Ọba tó gbé gorí ìtẹ́ láti ṣamọ̀nà àwọn tó wà nínú ètò Rẹ̀, ó sì ń lò ó láti darí wọn. Wọ́n mọ̀ pé ẹni tí àwọn gbẹ́kẹ̀ lé ò ní já àwọn kulẹ̀, gbogbo wa la sì ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀. Tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ látọkàn wá, ó máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti wà nínú òtítọ́, ó pọn dandan pé ká máa sọ fún àwọn èèyàn nípa ètò Jèhófà. Ohun ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé Párádísè tẹ̀mí wà nínú ayé búburú tí ìwà ìbàjẹ́ àti àìnífẹ̀ẹ́ ti gbilẹ̀ yìí! w15 7/15 1:12, 13

Friday, March 10

Wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.​—Ìṣí. 16:16.

Ogun Amágẹ́dọ́nì máa gbé orúkọ mímọ́ Jèhófà ga. Nígbà yẹn, gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ewúrẹ́ máa “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” (Mát. 25:​31-33, 46) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, gbogbo ìwà ibi á ti di àwátì, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá á sì la apá tó kẹ́yìn lára ìpọ́njú ńlá náà já. Bá a ti ń fojú sọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá yìí, kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe báyìí? Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti kọ̀wé pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, . . . Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pét. 3:​11, 12, 14) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé a óò máa wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí, a ó sì máa ti Ọba Àlàáfíà náà lẹ́yìn. w15 7/15 2:17, 18

Saturday, March 11

Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.​—Sm. 127:1.

Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ètò Jèhófà ń ṣe láti pèsè owó kí wọ́n sì tún kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn tí a kì í sanwó fún, tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn, ló ń bá wa bójú tó yíya àwòrán, kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí ṣíṣe àtúnṣe èyí tó ti wà tẹ́lẹ̀. Láti November 1, ọdún 1999, a ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà, èyí tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n [28,000] kárí ayé. Ìyẹn fi hàn pé láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tá a bá pín in dọ́gbadọ́gba, Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún là ń kọ́ lójoojúmọ́. Ètò Ọlọ́run ń sapá láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba níbikíbi tí àwọn ará bá ti nílò rẹ̀. Ìpèsè tó fìfẹ́ hàn yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa bí àṣẹ́kùsílẹ̀ àwọn kan ṣe lè dí ànító àwọn míì, kí “ìmúdọ́gba lè ṣẹlẹ̀.” (2 Kọ́r. 8:​13-15) Látàrí ìyẹn, a ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà fún àwọn ìjọ tí wọn ì bá tí ní àǹfààní láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn. w15 7/15 4:9-11

Sunday, March 12

Máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un!​—Háb. 2:3.

Kí àwọn èèyàn tó lè lóye àmì alápá púpọ̀ náà, ó gbọ́dọ̀ ṣe kedere débi tí gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” á fi rí i. (Mát. 24:​27, 42) A sì ti ń rí àmì náà láti ọdún 1914. Láti ìgbà yẹn ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó para pọ̀ di àmì náà ti ń wáyé. Láìsí àní-àní, a ti ń gbé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” náà báyìí, ìyẹn àkókò kúkúrú tó máa ṣáájú ìparun ètò búburú yìí àti ìparun ọ̀hún fúnra rẹ̀. (Mát. 24:⁠3) Kí wá nìdí tó fi yẹ kí àwa Kristẹni tòótọ́ máa fojú sọ́nà? À ń fojú sọ́nà torí pé a fẹ́ ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jésù Kristi. Bákan náà, a lóye àwọn àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. Kì í ṣe torí pé a kàn fẹ́ máa gba gbogbo ohun tá a bá ti rí gbọ́ la ṣe ń fojú sọ́nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, à ń fojú sọ́nà torí pé a rí ẹ̀rí tó ṣe kedere látinú Ìwé Mímọ́, èyí tó ń mú ká máa wà lójúfò, ká sì máa sọ́nà bá a ti ń retí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí. w15 8/15 2:8, 9

Monday, March 13

Ìwọ . . . ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.​—Sm. 145:16.

A máa gbádùn ara wa, àá sì ṣe àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àbí, kí nìdí tí Jèhófà fi dá wa lọ́nà táá fi wù wá láti ṣe àwọn nǹkan ká sì tún gbádùn ara wa bí kò bá fẹ́ ká tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa lọ́rùn ní kíkún? (Oníw. 2:24) Lọ́nà yìí àti láwọn ọ̀nà míì, Jèhófà máa “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” Ní báyìí, kò sí ohun tó burú nínú ká najú ká sì ṣeré ìtura. Ṣùgbọ́n wọ́n máa túbọ̀ gbádùn mọ́ni tó bá jẹ́ pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà la fi sípò àkọ́kọ́. Bó sì ṣe máa rí náà nìyẹn nínú Párádísè. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi àwọn ohun tó wù wá sí àyè tó yẹ wọ́n, ká máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ ká sì gbájú mọ́ àwọn ìbùkún tẹ̀mí táwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn báyìí. (Mát. 6:33) Nínú Párádísè tó ń bọ̀, a máa ní ayọ̀ tá ò tíì ní irú rẹ̀ rí. Ẹ jẹ́ ká fi hàn pé ó wù wá lóòótọ́ láti gbé nínú Párádísè nípa mímúra sílẹ̀ fún un nísinsìnyí. w15 8/15 3:17, 18

Tuesday, March 14

Kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.​—Éfé. 4:24.

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀dá èèyàn pípé ni, àmọ́ àwọn èèyàn aláìpé ló yí i ká. Aláìpé làwọn òbí tó tọ́ ọ dàgbà, òun àtàwọn ìbátan rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé ni wọ́n sì jọ ń gbé. Àwọn èèyàn tó wà nígbà náà máa ń wá ipò ọlá, wọ́n máa ń hùwà ẹ̀tàn, wọ́n sì máa ń lo ọgbọ́n àyínìke, èyí pẹ̀lú sì nípa lórí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ìrọ̀lẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù, “awuyewuye gbígbónájanjan kan . . . dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” (Lúùkù 22:24) Àmọ́, ó dá Jésù lójú pé bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n ṣì máa dàgbà dénú, wọ́n á sì para pọ̀ di ìjọ tó wà ní ìṣọ̀kan. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, Jésù gbàdúrà pé kí ìfẹ́ so àwọn àpọ́sítélì òun pọ̀, ó sì bẹ Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, . . . kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan.”​—Jòh. 17:21, 22. w15 9/15 1:10, 11

Wednesday, March 15

Ó wí pé: “Máa bọ̀!” Lójú ẹsẹ̀, ní sísọ̀kalẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi, Pétérù rìn lórí omi, ó sì gbọ̀nà ọ̀dọ̀ Jésù lọ.​—Mát. 14:29.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù nígbà tó ń rìn láàárín ìgbì òkun, tí ìjì sì ń jà la lè fi wé àwọn àdánwò àti ìdẹwò tá à ń dojú kọ torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Kódà bí ìdẹwò tàbí ìṣòro náà bá le koko, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè dúró gbọn-in. Rántí pé kì í ṣe ìró afẹ́fẹ́ tàbí ìjì líle ló mú kí Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé: “Ní wíwo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ó fòyà.” (Mát. 14:​24-32) Pétérù ò pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Jésù mọ́, ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í mì. Ìgbàgbọ́ tiwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í mì tá a bá ń wo àwọn ìṣòro wa bí ìgbà tá à ń ‘wo ìjì ẹlẹ́fùúùfù,’ tá à ń ronú lórí bó ṣe lágbára tó, tá a sì ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn. Ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa lè jó rẹ̀yìn, torí pé Bíbélì pe ìgbàgbọ́ tó jó rẹ̀yìn tàbí àìnígbàgbọ́ ní “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Héb. 12:⁠1) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù yìí fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa lè tètè jó rẹ̀yìn tá a bá ń pọkàn pọ̀ sórí ohun tí kò tọ́. w15 9/15 3:1, 6, 7

Thursday, March 16

Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.​—Ják. 1:17.

Tí ẹnì kan bá fún ọ lẹ́bùn, kí lo máa ṣe? Ó dájú pé wàá fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn náà. Yàtọ̀ síyẹn, wàá tún lo ẹ̀bùn náà lọ́nà tó fi hàn pé o kà á kún. Jèhófà ń fún wa ní àwọn nǹkan tá a nílò láìkùnà ká lè wà láàyè ká sì máa láyọ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyẹn mú kí àwa náà fẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà lábẹ́ àbójútó Jèhófà. Ó fìfẹ́ hàn sí wọn, ó sì bù kún wọn lọ́pọ̀ yanturu nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Diu. 4:​7, 8) Àmọ́, kí wọ́n lè máa rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Èyí sì gba pé kí wọ́n máa fi “èyí tí ó dára jù lọ nínú àkọ́pọ́n àwọn èso” ilẹ̀ wọn rúbọ sí Jèhófà. (Ẹ̀kís. 23:19) Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn mọrírì ìbùkún tí àwọn ń rí gbà àti ìfẹ́ tí Jèhófà ń fi hàn sáwọn.​—Diu. 8:7-11. w15 9/15 5:5, 6

Friday, March 17

Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.​—Mát. 5:8.

Báwo la ṣe lè rí ọwọ́ Jèhófà láyé wa? Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé: O lè máa sọ lọ́kàn rẹ pé ọwọ́ Ọlọ́run wà nínú bó o ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àbí o lọ sípàdé, tó o sì gbọ́ àsọyé kan, tó o wá sọ pé: “Ohun tí mo nílò gan-an nìyí”? Tàbí kó o rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà tó o gbà. Bóyá o pinnu láti mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i, o wá rí bí Jèhófà ṣe mú kí ètò tó o ṣe yọrí sí rere. Àbí ńṣe lo fi iṣẹ́ tó ò ń ṣe sílẹ̀ kó o lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, tó o sì wá rí i pé òótọ́ ni ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò . . . kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà”? (Héb. 13:⁠5) Tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, tá a sì jẹ́ ẹni tó ‘mọ́ gaara ní ọkàn-àyà’, àá lè fòye mọ onírúurú ọ̀nà tó ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè ‘mọ́ gaara ní ọkàn-àyà’? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá ò bá gba èrò tó ń sọni di aláìmọ́ láyè, tá a sì jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́ èyíkéyìí. (2 Kọ́r. 4:⁠2) Tá a bá mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i, tá à ń hùwà títọ́, àwa náà á wà lára àwọn tó ń rí Ọlọ́run. w15 10/15 1:17, 19

Saturday, March 18

Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣe ìránṣẹ́ fún mi, Baba yóò bọlá fún un.​—Jòh. 12:26.

Àwọn Gíríìkì aláwọ̀ṣe wà lára àwọn èrò tó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn ohun tí Jésù ṣe wú wọn lórí débi pé wọ́n sọ fún àpọ́sítélì Fílípì pé kó bá àwọn ṣètò báwọn ṣe máa rí Jésù bá sọ̀rọ̀. Àmọ́, Jésù ò jẹ́ kíyẹn fa ìpínyà ọkàn fóun, ó pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tó wà níwájú rẹ̀. Kò gbìyànjú láti di gbajúmọ̀ kó lè sá fún ikú ìrúbọ látọwọ́ àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Torí náà, lẹ́yìn tó ṣàlàyé fún Áńdérù àti Fílípì pé wọ́n máa tó pa òun, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni fún ọkàn rẹ̀ ń pa á run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra ọkàn rẹ̀ nínú ayé yìí, yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Kàkà kó máa wá bó ṣe máa tẹ́ àwọn Gíríìkì yẹn lọ́rùn, ó gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n múra tán láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ torí àwọn míì, ó wá sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ yìí gbé Fílípì ró, ó sì lọ jábọ̀ fún àwọn tó rán an sí Jésù. (Jòh. 12:​20-25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù pọkàn sórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, kì í ṣe aláṣekúdórógbó. w15 10/15 3:13, 14

Sunday, March 19

Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí.​—Ìṣí. 3:19.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò yéé bára wọn jiyàn nípa “ẹni tí ó tóbi jù” láàárín wọn, Jésù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn sú òun. Nígbà tó sì rí i pé wọn ò fi ìmọ̀ràn òun sílò, ó fìfẹ́ bá wọn wí lákòókò tó tọ́ àti níbi tó yẹ. (Máàkù 9:​33-37) Máa bá àwọn ọmọ rẹ wí kí wọ́n lè mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn. Nígbà míì, ohun tó o nílò ò ju pé kó o jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí ohun kan fi dáa tàbí ìdí tí kò fi dáa. Nígbà míì sì rèé, wọ́n lè ṣàìgbọràn. (Òwe 22:15) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Máa fìfẹ́ bá wọn wí lákòókò tó tọ́ àti níbi tó yẹ, kó sì jẹ́ lóhùn pẹ̀lẹ́. Máa fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà kó o sì máa fún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Arábìnrin Elaine tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Àwọn òbí mi kì í fìbínú bá mi wí, wọn kì í sì bá mi wí láìsọ ohun tí mo ṣe. Torí náà, ọkàn mi máa ń balẹ̀. Mi ò kì í kọjá àyè mi, mo mọ ohun tí wọ́n fẹ́ àtohun tí wọn ò fẹ́.” w15 11/15 1:5, 6

Monday, March 20

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.​—1 Jòh. 4:16.

Tiẹ̀ rò ó wò ná, báwo lo ṣe rò pé nǹkan máa rí ká ní Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ aráyé? Kò sí nǹkan táà bá ṣe ju pé ká kàn máa wo àwọn láabi tó ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn èèyàn ṣe ń jọba lórí ara wọn, tí Sátánì Èṣù tó jẹ́ òǹrorò sì ń darí wọn. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Jòh. 5:19; Ìṣí. 12:​9, 12) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé bí Ọlọ́run bá yọwọ́ pátápátá lọ́rọ̀ àwa èèyàn, ayé yìí á bà jẹ́ bàlùmọ̀ ju bó ṣe wà yìí lọ. Nígbà tí Èṣù ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ńṣe ló ń sọ pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti pé ìṣàkóso rẹ̀ kò lè ṣe aráyé láǹfààní. Nípa báyìí, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ìṣàkóso òun máa dára ju ti Ẹlẹ́dàá lọ. (Jẹ́n. 3:​1-5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gba Sátánì láyè láti ṣe ohun tó rò pé ó tọ́ lójú ara rẹ̀, fúngbà díẹ̀ ni. Torí pé Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó ti mú sùúrù tó kó lè hàn gbangba pé kò sí ìṣàkóso kankan tó lè ṣàṣeyọrí yàtọ̀ sí ìṣàkóso òun. Gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé sì fi hàn pé, ẹ̀dá èèyàn kankan tàbí Sátánì pàápàá ò lè ṣàkóso àwọn èèyàn lọ́nà tó dára. w15 11/15 3:3, 4

Tuesday, March 21

Ṣe ìgbèjà . . . pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.​—1 Pét. 3:15.

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa máa ń mú ká tẹ̀ lé ìlànà pàtàkì tí Jésù fún wa. Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mát. 5:​43-45) Ó yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa’ láìka ohun yòówù kí wọ́n ṣe sí wa sí. Nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ìwà àti ìṣe pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn kan ò bá tiẹ̀ fetí sí ìwàásù wa, ìyẹn ò ní ká má ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ wa. w15 11/15 4:17, 19, 20

Wednesday, March 22

Wọ́n lóye ọ̀rọ̀ tí a ti sọ di mímọ̀ fún wọn.​—Neh. 8:12.

Àwọn èèyàn Ọlọ́run ń fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ àti èdè yin Jèhófà, wọ́n sì ń sọ ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Ní báyìí, iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì tún wá ni ọ̀nà tó pabanbarì táwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbà ti ìjọsìn mímọ́ lẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló wà, àmọ́ wọ́n péye jura wọn lọ. Lọ́dún 1940 sí 1949, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun gbé àwọn ìlànà kan kalẹ̀, èyí tí wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń túmọ̀ Bíbélì. Ìlànà yìí kan náà sì ni àwọn èdè tó lé ní àádóje [130] tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì. Àwọn ìlànà yìí ni: (1) Láti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ kí orúkọ náà lè di sísọ di mímọ́. (Mát. 6:⁠9) (2) Ká túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, àmọ́ níbi tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá ti máa yí ohun tí ọ̀rọ̀ túmọ̀ sí pa dà, ká tú ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn gan-an. (3) Láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn lóye táá mú kí Bíbélì máa wu èèyàn kà.​—Neh. 8:8. w15 12/15 2:1, 2

Thursday, March 23

Bí kàkàkí bá mú ìpè tí kò dún ketekete jáde, ta ni yóò gbára dì fún ìjà ogun?​—1 Kọ́r. 14:8.

Bí ìrò kàkàkí kan ò bá dún ketekete, ó lè ṣi àwọn ọmọ ogun lọ́nà. Lọ́nà kan náà, tí ọ̀rọ̀ wa ò bá ṣe kedere tàbí tó bá lọ́jú pọ̀, àwọn èèyàn ò ní lóye ohun tá à ń sọ, a sì lè ṣì wọ́n lọ́nà. (1 Kọ́r. 14:⁠9) Àmọ́, kò yẹ ká torí pé a fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe kedere ká wá máa sọ̀rọ̀ tó máa bí wọn nínú tàbí tó máa rín wọn fín. Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀ràn ká sọ̀rọ̀ tó tọ́. Ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nínú ìwé Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje. Jésù ò lo àwọn ọ̀rọ̀ kànkà-kàǹkà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòroó lóye. Kò fọ̀rọ̀ gún àwọn èèyàn lára, kò sì sọ̀rọ̀ tó máa tàbùkù sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ̀rọ̀ tó ṣe kedere tó sì máa tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń sọ ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n máa ṣàníyàn nípa àtijẹ àtimu, ó ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe ń bọ́ àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?” (Mát. 6:26) Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn lóye tí Jésù lò yìí máa mú kí ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ wọn tètè yé wọn, á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. w15 12/15 3:13, 14

Friday, March 24

Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.​—Héb. 13:1.

Kí ni ìfẹ́ ará? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “ìfẹ́ téèyàn ní sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni.” Ó jẹ́ ìfẹ́ tó lágbára gan-an bí irú èyí tí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ọmọ ìyá kan náà máa ń ní síra wọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé okùn ọmọ ìyá yi. (Jòh. 11:36) Kì í ṣe pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn ń pe ara wa ní arákùnrin àti arábìnrin, ohun tá a jẹ́ gan-an nìyẹn. (Mát. 23:⁠8) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ará wa ṣe lágbára tó. Ìfẹ́ ará yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà Bíbélì ló ń jẹ́ káwa èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan, ká sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa. Gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ ni “arákùnrin” wa, láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. (Róòmù 10:12) Jèhófà ti kọ́ wa pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa bíi tẹ̀gbọ́n tàbúrò.​—1 Tẹs. 4:9. w16.01 1:5, 6

Saturday, March 25

Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.​—2 Kọ́r. 5:14.

Ìfẹ́ tá a ní fún Jésù máa mú ká fìtara wàásù ká sì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. (Mát. 28:​19, 20; Lúùkù 4:43) Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, ǹjẹ́ o lè ṣètò àkókò rẹ kó o lè gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kó o sì lo ọgbọ̀n [30] tàbí àádọ́ta [50] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Bàbá kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] tí ìyàwó rẹ̀ sì ti kú rò pé òun ò lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà torí àìlera àti ara tó ti dara àgbà. Àmọ́, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ládùúgbò rẹ̀ ràn án lọ́wọ́. Wọ́n fún un ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó máa rọrùn fún un, wọ́n sì ṣètò ohun ìrìnnà táá máa gbé e lọ, gbé e bọ̀. Èyí ran arákùnrin náà lọ́wọ́ láti dójú ìlà ọgbọ̀n wákàtí. Ṣé ìwọ náà lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lásìkò Ìrántí Ikú Kristi? Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo wa la lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ a lè lo àkókò àti okun wa láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà á fi hàn bíi ti Pọ́ọ̀lù pé a mọrírì ìfẹ́ tí Jésù ní sí wa. w16.01 2:7, 11

Sunday, March 26

Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.​—Sek. 8:23.

Bó bá wá jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún àwọn àgùntàn mìíràn láti mọ orúkọ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí, báwo ni wọ́n ṣe lè ‘bá wọn lọ’? Bíbélì sọ pé “ọkùnrin mẹ́wàá” máa “di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’ ” Júù kan ni ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu bà. Àmọ́ àwọn tí “yín” méjèèjì tó wà nínú ẹsẹ náà ń tọ́ka sí ju ẹnì kan lọ. Èyí túmọ̀ sí pé kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni Júù náà ń tọ́ka sí, àmọ́ ó dúró fún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró. Àwọn àgùntàn mìíràn mọ èyí, àwọn àti àwùjọ yìí ló sì jùmọ̀ ń sin Jèhófà. Kò pọn dandan kí wọ́n mọ orúkọ gbogbo àwọn tó jẹ́ ara àwùjọ yìí kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Jésù ni Aṣáájú wa, Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé òun nìkan la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé.​—Mát. 23:10. w16.01 4:4

Monday, March 27

Ìwọ, Ísírẹ́lì, ni ìránṣẹ́ mi, ìwọ, Jékọ́bù, ẹni tí mo ti yàn, irú-ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi.​—Aísá. 41:8.

Látìgbà tí wọ́n bá ti bíni títí dọjọ́ ikú, kòṣeémáàní ni ìfẹ́ jẹ́. Ó máa ń wu àwa èèyàn ká rẹ́ni tá a jọ mọwọ́ ara wa tó sì tún nífẹ̀ẹ́ wa bá ṣọ̀rẹ́. Àmọ́, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà pé àwa èèyàn lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ torí pé agbára rẹ̀ ò láfiwé. Àmọ́, àwa mọ̀ pé èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run! A ti rí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nínú Bíbélì. Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò sóhun tá a lè fi wé kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù yẹ̀ wò. (Ják. 2:23) Báwo ló ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní ló mú kó dọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”​—Róòmù 4:11. w16.02 1:1, 2

Tuesday, March 28

Kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀.​—2 Ọba 18:5.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ọba tó burú jù lọ ní Júdà ni bàbá Hesekáyà, Hesekáyà di ọ̀kan lára àwọn ọba tó dáa jù lọ ní ilẹ̀ náà. (2 Ọba 18:⁠6) Ó yàn láti má ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú bàbá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló tún ọ̀pọ̀ nǹkan tí bàbá ẹ̀ ti bà jẹ́ ṣe. Ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́, ó bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji àwọn èèyàn náà, ó sì fọ́ àwọn òrìṣà tó wà ní gbogbo ilẹ̀ náà túútúú. (2 Kíró. 29:​1-11, 18-24; 31:⁠1) Nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà halẹ̀ mọ́ Hesekáyà pé òun á gbógun ja Jerúsálẹ́mù, Hesekáyà ṣe ohun tó fi hàn pé ó ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára. Ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà á dáàbò bo àwọn, Hesekáyà sì fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun. (2 Kíró. 32:​7, 8) Nígbà kan, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, àmọ́ nígbà tí Jèhófà bá a wí, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. (2 Kíró. 32:​24-26) Ó ṣe kedere pé àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Hesekáyà jẹ́. Kò jẹ́ kí ilé búburú tó ti jáde sọ ọ́ di dà bí mo ṣe dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ọ̀rẹ́ Jèhófà lòun. w16.02 2:11

Wednesday, March 29

Bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.​—Gál. 6:1.

Ìwọ náà lè kọ́kọ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kó o sì tún jẹ́ onínúure sáwọn tó sún mọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní ẹ̀rí tó dájú pé arákùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. O lè máà fẹ́ tú àṣírí rẹ̀ pàápàá tó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tàbí mẹ́ńbà ìdílé rẹ. Síbẹ̀, o mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Torí náà, bíi ti Nátánì, ṣègbọràn sí Jèhófà kó o sì jẹ́ onínúure sí arákùnrin rẹ. Sọ fún un pé kó tètè lọ sọ ohun tó ṣe fáwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Tó bá kọ̀, kí ìwọ fúnra rẹ lọ sọ fáwọn alàgbà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, o ti fi inú rere hàn sí arákùnrin rẹ torí àwọn alàgbà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn alàgbà náà á sì fìfẹ́ tọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà.​—Léf. 5:1. w16.02 4:14

Thursday, March 30

Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run?​—2 Pét. 3:11.

“Àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” ni àwọn ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọ, bíi lílọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, àdúrà tó o máa ń gbà sí Jèhófà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ náà wà lára ẹ̀. Ẹnì kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ò ní máa rò pé gbogbo nǹkan yìí ti nira jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lá máa ṣe bíi ti Dáfídì Ọba tó sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sm. 40:⁠8) Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, wàá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, kò yẹ kó jẹ́ àwọn òbí rẹ àbí ẹlòmíì láá máa pinnu ohun tó o máa ṣe fún Jèhófà. Ìṣe ìwà mímọ́ rẹ àtàwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run tó ò ń ṣe ló máa fi hàn pé òtítọ́ tó o gbà gbọ́ dá ọ lójú, á sì fi hàn pé òótọ́ lo fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kò ní pẹ́ tí wàá fi ṣèrìbọmi. w16.03 2:10, 12, 15

Friday, March 31

Kí ìgbàgbọ́ náà tó dé, a ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí wa lábẹ́ òfin, . . . Nítorí náà, Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.​—Gál. 3:23, 24.

Òfin dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìsìn èké àti ìṣekúṣe táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń ṣe. Nígbàkigbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó máa ń bù kún wọn. Àmọ́ bí wọ́n bá kọ̀ láti ṣe ohun tó fẹ́, wọ́n máa ń jìyà rẹ̀. (Diu. 28:​1, 2, 15) Ìdí míì tún wà tó fi pọn dandan pé kí Jèhófà fáwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ìtọ́ni tuntun. Òfin múra àwọn ọmọ Ísírẹ́lì de ohun pàtàkì kan, ìyẹn dídé Jésù Kristi tí í ṣe Mèsáyà. Òfin yìí jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé aláìpé làwọn. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n nílò ìràpadà, ìyẹn ẹbọ pípé táá mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò pátápátá. (Gál. 3:19; Héb. 10:​1-10) Yàtọ̀ síyẹn, Òfin dáàbò bo ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti wá, ó sì tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá a mọ̀ nígbà tó dé. Ní ti gidi, ṣe ni Òfin dà bí amọ̀nà tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi. w16.03 4:6, 7

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́