April
Saturday, April 1
Ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.—1 Pét. 5:8.
Áńgẹ́lì kan wà tó rí ojú rere Jèhófà nígbà kan rí. Àmọ́, nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí àwọn èèyàn á ṣe máa jọ́sìn òun. Dípò tí ì bá fi gbé èrò búburú yẹn kúrò lọ́kàn, ṣe ló ń ronú nípa rẹ̀ ṣáá, títí tí èrò náà fi gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ̀ tó sì mú un dẹ́ṣẹ̀. (Ják. 1:14, 15) Áńgẹ́lì yẹn la wá mọ̀ sí Sátánì, ẹni tí kò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” Ó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó sì wá di “baba irọ́.” (Jòh. 8:44) Látìgbà tí Sátánì ti ṣọ̀tẹ̀ ló ti di olórí ọ̀tá Jèhófà, ó sì dájú pé kì í ṣe ọ̀rẹ́ àwa náà. Àwọn orúkọ tá a fi ń pe Sátánì jẹ́ ká mọ bí ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Sátánì túmọ̀ sí “Alátakò,” ìyẹn fi hàn pé áńgẹ́lì búburú yìí kò ti ìṣàkóso Ọlọ́run lẹ́yìn, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló kórìíra ìṣàkóso náà tó sì ń gbógun tì í. Olórí ohun tó wà lọ́kàn Sátánì ni bó ṣe máa fòpin sí ìṣàkóso Jèhófà. w15 5/15 1:1, 2
Sunday, April 2
Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.—1 Kọ́r. 8:3.
Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó máa jẹ́ ká mọ bí àjọṣe àwa àti Jèhófà ṣe lè túbọ̀ dán mọ́rán. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ ká mọyì ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà ń ṣe nǹkan, ká sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe ń jinlẹ̀ sí i ni Ọlọ́run á túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ wa, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á sì máa lágbára sí i. Ká bàa lè sún mọ́ Jèhófà, ó yẹ kí ìdí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ tọ̀nà. Jòhánù 17:3 sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ni la lè kọ́ tá a bá ń ka Bíbélì, àmọ́ ohun tó yẹ ká fi ṣe àfojúsùn wa ni bá a ṣe máa mọ Jèhófà. (Ẹ́kís. 33:13; Sm. 25:4) Tá a bá ti wá mọ Jèhófà dáadáa, kò ní yà wá lẹ́nu púpọ̀ tá a bá ka àwọn ìtàn kan nínú Bíbélì tá ò sì mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe ohun tó ṣe. w15 4/15 3:6-8
Monday, April 3
[Tímótì] yóò rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mo gbà ń ṣe nǹkan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń kọ́ni níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ.—1 Kọ́r. 4:17.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà kan nípa ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà tí wọ́n fi dá ọ̀pọ̀ arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ débi tí òtítọ́ fi jinlẹ̀ nínú wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí àwọn arákùnrin yìí ń gbé àti ipò wọn yàtọ̀ síra, ó gbàfiyèsí pé ìdáhùn wọn jọra gan-an ni. Kí lèyí kọ́ wa? Ó jẹ́ ká rí i pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé ka Bíbélì máa ń ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn “níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ,” bó sì ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà láyé. Olùkọ́ gbọ́dọ̀ mú kí ara tu akẹ́kọ̀ọ́ kí ohun tó ń kọ́ ọ bàa lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Bó ṣe jẹ́ pé àgbẹ̀ máa ń kọ́kọ́ túlẹ̀ kó tó gbin irúgbìn sí oko rẹ̀, bákan náà ló ṣe yẹ kí olùkọ́ múra ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ tàbí kó fún un níṣìírí kó tó kọ́ ọ lóhun tuntun. Ọ̀nà wo wá ni olùkọ́ lè gbà múra ọkàn àwọn míì sílẹ̀ kó tó dá wọn lẹ́kọ̀ọ́? Ọ̀nà tó lè gbà ṣe é ni pé kó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì ìgbàanì Sámúẹ́lì nígbà tó ń múra ọkàn Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ láti jẹ́ aṣáájú ní Ísírẹ́lì.—1 Sám. 9:15-27; 10:1. w15 4/15 1:11, 12
Tuesday, April 4
Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 5:19.
Èyí tó pọ̀ jú lára ohun tí ayé ń gbé lárugẹ ló lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì. Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ohun tó wà láyé ló burú. Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé Sátánì máa fẹ́ lo ayé yìí láti tàn wá jẹ, kó sì mú kí ọkàn wa máa fà sí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ká nífẹ̀ẹ́ ayé, ká sì pa ìjọsìn Jèhófà tì. (1 Jòh. 2:15, 16) Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nífẹ̀ẹ́ ayé. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Démà ti ṣá mi tì nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (2 Tím. 4:10) Bíbélì kò sọ ohun náà gan-an tí Démà nífẹ̀ẹ́ nínú ayé tó mú kó pa Pọ́ọ̀lù tì. Ó ṣeé ṣe kí Démà bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara ju àwọn nǹkan tẹ̀mí. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé Démà pàdánù àwọn àǹfààní àgbàyanu tẹ̀mí nìyẹn. Tìtorí kí ni? Kí ni Démà máa rí gbà nínú ayé yìí tó lè dà bí ìbùkún táá rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà bó ṣe ń bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́?—Òwe 10:22. w15 5/15 2:10, 11
Wednesday, April 5
Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.—Sm. 103:8.
Jésù mọ bí ìrora tí àwọn èèyàn ní ṣe ń rí lára, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn dojú kọ ló tíì ṣẹlẹ̀ sí i rí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó di ẹrù òfin àtọwọ́dá lé wọn lórí, tí wọ́n sì ń ṣì wọ́n lọ́nà. (Mát. 23:4; Máàkù 7:1-5; Jòh. 7:13) Kò sí ohunkóhun tó ba Jésù lẹ́rù rí, kò sì sí ẹnikẹ́ni tó lè ṣì í lọ́nà, àmọ́ ó mọ bí nǹkan ṣe rí fáwọn tó wà nírú ipò yẹn. Abájọ tó fi jẹ́ pé, “nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Torí náà, Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀, ó jẹ́ aláàánú àti onífẹ̀ẹ́. Nígbà tí Jésù rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, àánú wọn ṣe é, torí náà, ó fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fi ìfẹ́ jọ Baba òun. Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì Jésù dé láti ọ̀nà jíjìn, ìyẹn níbi tí wọ́n ti lọ wàásù, wọ́n fẹ́ lọ síbì kan táwọn èèyàn kò ti ní rí wọn kí wọ́n lè sinmi. Àmọ́ torí pé Jésù káàánú ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń dúró dè é, ó yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ kó lè “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—Máàkù 6:30, 31, 34. w15 5/15 4:3, 4
Thursday, April 6
Ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.—Òwe 8:31.
Àkọ́bí ọmọkùnrin Ọlọ́run ni ẹni àkọ́kọ́ tó gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Jèhófà yọ. Bíbélì ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n àti “àgbà òṣìṣẹ́” tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀. Ẹ fojú inú wo ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó máa ní bó ṣe ń wo Baba rẹ̀ tó ń “pèsè ọ̀run” tó sì ń “fàṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé kalẹ̀.” Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run dùn pé Baba rẹ̀ dá àwọn ohun tí kò lẹ́mìí yìí, ó “ní ìfẹ́ni” àrà ọ̀tọ̀ “sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:22-31) Dájúdájú, Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn èèyàn tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kó tó wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn. Nígbà tó yá, kí Àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run lè fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin àti pé òun nífẹ̀ẹ́ Baba òun, tí òun sì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún “àwọn ọmọ ènìyàn,” ó fínnúfíndọ̀ “sọ ara rẹ̀ di òfìfo” ó sì wá ní ìrí èèyàn. Kí nìdí tó fi ṣe gbogbo èyí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè ṣe “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Fílí. 2:5-8; Mát. 20:28) Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ tí Jésù ní fún àwa èèyàn pọ̀ gan-an! w15 6/15 2:1, 2
Friday, April 7
Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.—1 Jòh. 4:9.
Ṣé o mọ rírì ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ? Tó o bá mọ rírì ẹ̀, ó yẹ kó o ṣe ìyàsímímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi. Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́, ṣe lò ń ṣèlérí fún Ọlọ́run pé ohun tó fẹ́ ni wàá máa ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Ṣó wá yẹ kó o máa bẹ̀rù láti ṣe ìyàsímímọ́? Rárá! Ohun tó dáa jù ni Jèhófà fẹ́ fún ẹ, ó sì máa san èrè fún gbogbo àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Héb. 11:6) Tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run tó o sì ṣèrìbọmi, ìgbésí ayé rẹ á máa dáa sí i ni, kò ní bà jẹ́! Ohun tó dáa jù lọ ni Jèhófà fẹ́ fún ẹ. Àmọ́, bí Sátánì ṣe máa pa ẹ́ jẹ ló ń wá, kò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ rárá. Kò sóhun rere kan tó máa fún ẹ tó o bá tẹ̀ lé e. Báwo ló tiẹ̀ ṣe máa fún ẹ lóhun tí kò ní? w16.03 2:16, 18, 19
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Lúùkù 19:29-44
Saturday, April 8
Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, èmi mọ̀ pé ìwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo.—Jòh. 11:41, 42.
Kó o tó lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ dá ẹ lójú pé ó ń gbọ́ àdúrà rẹ. Rò ó wò ná: Kí Jésù tó wá sáyé, ó ti máa ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àdúrà ló fi ń bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀. Ká sọ pé Jèhófà kì í gbọ́ àdúrà ni, ǹjẹ́ Jésù máa gbàdúrà sí i rárá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé ó tún lo gbogbo òru ọjọ́ kan láti gbàdúrà sí i? (Lúùkù 6:12; 22:40-46) Ǹjẹ́ ó máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà ká sọ pé oògùn amáratuni lásán ni àdúrà jẹ́? Ó ṣe kedere pé Jésù mọ̀ pé Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sm. 65:2. w15 4/15 3:11, 13
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Lúùkù 19:45-48; Mátíù 21:18, 19; 21:12, 13
Sunday, April 9
Ábà, Baba, ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, bí kò ṣe ohun tí ìwọ fẹ́.—Máàkù 14:36.
Tí àwọn ọmọ rẹ bá gbọ́ bó o ṣe ń gbàdúrà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, àwọn náà á mọ̀ pé ó yẹ káwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ana tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Nígbà tá a bá níṣòro, àwọn òbí mi máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí ara àwọn òbí mi àgbà ò yá, wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún àwọn lókun táwọn á fi lè fara da ìṣòro náà, kó sì fún àwọn lọ́gbọ́n káwọn lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Kódà nígbà tí nǹkan bá nira fún wọn, wọ́n máa ń kó gbogbo àníyàn wọn lé Jèhófà. Torí náà, èmi náà kọ́ láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Tó o bá ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, bó o ṣe ń gbàdúrà fún wọn, tún máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ran ìwọ náà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè bá ọ̀gá rẹ sọ̀rọ̀ pé kó fún ẹ láyè láti lọ sí àpéjọ, o sì tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o nígboyà kó o lè wàásù fún aládùúgbò yín kan tàbí kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn ọmọ rẹ náà á sì kọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. w15 11/15 1:7,8
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Lúùkù 20:1-47
Monday, April 10
Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.—Mát. 22:37.
Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà lágbára sí i ni pé kó o máa fara balẹ̀ ronú lórí ẹ̀bùn tó ga jù lọ ti Ọlọ́run fún aráyé, ìyẹn ìràpadà. (2 Kọ́r. 5:14, 15; 1 Jòh. 4:9, 19) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á wù ẹ́ láti mọ rírì ẹ̀bùn àgbàyanu tí Ọlọ́run fún wa yìí. Jẹ́ ká wo àpèjúwe kan tó máa jẹ́ kó o rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o mọ rírì ìràpadà: Fojú inú wò ó pé omi ń gbé ẹnì kan lọ, àmọ́ ṣàdédé lẹnì kan wá yọ ọ́ jáde. Ṣé á kàn lọ wá aṣọ míì wọ ní tìẹ, táá sì gbà gbé ohun tẹ́ni náà ṣe fún un ni? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ìgbà tó bá ti rí ẹni tí kò jẹ́ kó bómi lọ yẹn láá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó gbẹ̀mí òun là. Bákan náà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù torí ẹ̀bùn ìràpadà náà. Torí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa, a ti wá nírètí láti gbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé! w16.03 2:16, 17
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Lúùkù 22:1-6; Máàkù 14:1, 2, 10, 11
Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Tuesday, April 11
Kristi kú fún wa.—Róòmù 5:8.
Jèhófà fọkàn tán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, torí ó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run ó sì ti jẹ́ adúróṣinṣin fún àìmọye ọdún. Síbẹ̀ nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó sì fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kódà nígbà tó kojú àwọn àdánwò tó nira gan-an, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Baba rẹ̀ títí tó fi kú. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká kún fún ọpẹ́ pé nípasẹ̀ ikú rẹ̀ ó tún san ìràpadà tí aráyé nílò, ká lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí! Àpọ́sítélì Jòhánù náà kọ̀wé pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòh. 4:9, 10. w15 11/15 3:13, 14
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Lúùkù 22:7-13; Máàkù 14:12-16 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Lúùkù 22:14-65
Wednesday, April 12
Ikú sì tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.—Róòmù 5:12.
Gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú láti ọ̀dọ̀ Ádámù, torí náà kò sẹ́ni tó lè sọ pé, “Mi ò nílò ìràpadà.” Kódà, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́ jù lọ pàápàá nílò ẹ̀bùn ìràpadà, torí pé Ọlọ́run ti dárí gbèsè ńlá ji ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí ló yẹ kí ìfẹ́ àti àánú tí Jèhófà fi hàn sí wa mú ká ṣe? Tó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti ṣẹ̀ ẹ́,tó sì ṣòro fún ẹ láti dárí jì í, àsìkò yìí ló yẹ kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ẹni tó “ṣe tán láti dárí jini.” (Neh. 9:17; Sm 86:5) Tá a bá mọrírì àánú ńláǹlà tí Jèhófà fi hàn sí wa, a ó máa fi àánú hàn sáwọn ẹlòmíì, a ó sì máa dárí jì wọ́n látọkàn wá. Tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tí a kì í sì í dárí jì wọ́n, a ò lè retí pé kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa kó sì máa dárí jì wá. (Mát. 6:14, 15) Tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, ìyẹn ò sọ pé nǹkan tí wọ́n ṣe ò dùn wá, àmọ́ ó máa jẹ́ ká ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. w16.01 2:5, 15-17
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Lúùkù 22:66-71
Thursday, April 13
Ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.—Mát. 19:28.
Jésù sọ ọ̀rọ̀ tá a kà tán yìí láti kọ́ Pétérù àtàwọn míì tó wà níbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa ronú nípa ọjọ́ iwájú. Wọ́n lè wá máa fọkàn ro ojúṣe wọn nínú ìjọba tó máa ṣàkóso lé ayé lórí, tó sì máa mú ìbùkún jìgbìnnì bá àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ onígbọràn. Ọjọ́ pẹ́ tí ríronú lórí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ ti máa ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé láǹfààní. Ébẹ́lì mọ púpọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe, ìdí nìyẹn tó fi lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun rere tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó jẹ́ kó lo ìgbàgbọ́, kó sì ní ìrètí tó dájú. Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé ó “rí” ohun kan tó jẹ́ kó mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa “irú-ọmọ” náà máa ṣẹ. (Jẹ́n. 3:15) Mósè “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà,” èyí jẹ́ kó ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà sì ń pọ̀ sí i. (Héb. 11:26) Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ táwa náà ní sí Ọlọ́run máa pọ̀ sí i tá a bá ń lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa tó jẹ́ ká lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí, bíi pé wọ́n ti ṣẹ. w15 5/15 3:17, 18
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66
Friday, April 14
Kristi . . . fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.—1 Pét. 2:21.
A rí i nínú àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ pé bí Kristẹni kan bá fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun, kì í ṣe ìmọ̀ oréfèé lásán ló yẹ kó ní nípa Bíbélì. Ó ní láti máa walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó sì gbà pé “oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú.” (Héb. 5:14) Ó dájú pé Kristẹni tó dàgbà dénú máa fẹ́ ní “ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run.” (Éfé. 4:13) Ǹjẹ́ o máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ǹjẹ́ o máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tó o sì ń sapá gidigidi láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, máa kíyè sí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ táá jẹ́ kó o túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Lẹ́yìn náà, sapá láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, jẹ́ kó máa darí àwọn ìpinnu tó o bá ń ṣe, kó o sì túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà. w15 9/15 1:5, 9, 10
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Lúùkù 24:1-12
Saturday, April 15
Kristi [ni] agbára Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 1:24.
Jésù ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa omi, afẹ́fẹ́, àti gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí. Ó mọ bó ṣe lè lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, kó ṣèkáwọ́ rẹ̀, kó sì lò ó fún àǹfààní aráyé ní ọgbọọgba àti lọ́nà tó tọ́. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun ni “agbára Ọlọ́run” nígbà tó kápá ìjì líle àtàwọn nǹkan míì bí afẹ́fẹ́, òkun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ fojú inú yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ náà: Ó ti rẹ Jésù lẹ́yìn ìwàásù tó ṣe látàárọ̀. Ìgbì òkun bẹ̀rẹ̀ sí í bì lu ọkọ̀ ojú omi, ó sì ń da omi tó ń ru gùdù sínú ọkọ̀ náà. Àmọ́, Jésù ń sùn lọ ní tiẹ̀ láìka ariwo ẹ̀fúùfù náà sí àti bí ọkọ̀ náà ṣe ń fì sọ́tùn-ún fì sósì, ara kì í ṣáà ṣe òkúta. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ojora mú jí Jésù lójú oorun, wọ́n sì pariwo pé: “A ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣègbé!” (Mát. 8:25) Ni Jésù bá dìde, ó sì pàṣẹ fún ẹ̀fúùfù àti òkun náà pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ yìì náà sì dáwọ́ dúró. (Máàkù 4:39) Ńṣe ni Jésù pàṣẹ pé kí ẹ̀fúùfù àti òkun náà ṣe wọ̀ọ̀, kó sì wà bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ ó rí bẹ́ẹ̀? Bíbélì ròyìn pé: “Ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.” Ẹ ò rí i pé agbára Jésù pabanbarì! w15 6/15 1:12-14
Sunday, April 16
Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.—Mát. 6:11.
Nígbà tí Jésù mẹ́nu kan oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ohun tá a nílò lójú ẹsẹ̀ ló ní lọ́kàn. Torí náà, ó sọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọ́run ṣe ń wọ àwọn òdòdó pápá láṣọ, ó wá sọ pé: “Òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?” Ó fún wa ní ìmọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì láti fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la.” (Mát. 6:30-34) Èyí fi hàn pé, kàkà tá a fi máa to àwọn nǹkan ìní tara jọ, ńṣe ló yẹ ká ní ìtẹ́lọ́rùn tá a bá ti ní àwọn ohun kòṣeémáàní ojoojúmọ́. Lára rẹ̀ ní ilé tó bójú mu, iṣẹ́ táá jẹ́ ká lè máa pèsè fún àwọn ìdílé wa àti bá a ṣe lè máa fọgbọ́n lo ìlera wa. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwọn nkan ìní tara yẹn nìkan lá ń sọ nínú àdúrà wa, á jẹ́ pé tara wa nìkan la mọ̀ nìyẹn. Àmọ́ o, àwọn nǹkan kan wà tá a nílò nípa tẹ̀mí tí wọ́n ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ. Jésù Ọ̀gá wa sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún wa. w15 6/15 5:4, 7, 8
Monday, April 17
Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.—Mát. 6:13.
Ǹjẹ́ à ń bẹ Jèhófà lóòrèkóòrè pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò? Ó ṣeé ṣe kí ìwà tá à ń hù tẹ́lẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà ti mú ká máa hu àwọn ìwà tí Jèhófà kà léèwọ̀. Síbẹ̀, Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe táá jẹ́ ká lè máa sìn ín lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Èyí dá Dáfídì Ọba lójú, kódà lẹ́yìn tó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà, ó bẹ Jèhófà pé: “Dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, . . . Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sm. 51:10, 12) Torí pé aláìpé ni wá, ó lè wù wá gan-an ká lọ́wọ́ nínú ìwà tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ Jèhófà lè mú kó máa wù wá látọkàn wá láti máa ṣègbọràn sí i. Kódà tí èròkerò bá gbilẹ̀ lọ́kàn wa, tó sì ń darí ìrònú wa láti hu ìwà àìmọ́, Jèhófà lè tọ́ wa sọ́nà ká lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, kó sì hàn bẹ́ẹ̀ nínú bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa. Ó lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ewu èyíkéyìí tó lè fẹ́ borí wa.—Sm. 119:133. w15 6/15 3:5, 6
Tuesday, April 18
Ìgbàlà ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.—Òwe 24:6.
Àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa máa ń rántí ìgbà tí ètò Ọlọ́run ń lo ìránṣẹ́ ìjọ, tí orílẹ̀-èdè máa ń ní ìránṣẹ́ ẹ̀ka, tí ìtọ́ni sì máa ń wá látọ̀dọ̀ ààrẹ Watch Tower Society. Àmọ́ ní báyìí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló ń bójú tó ìjọ, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló ń bójú tó orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, ìtọ́ni sì ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tá a wá mọ̀ sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣeé fiṣẹ́ lé lọ́wọ́ wà tí wọ́n ń ran gbogbo àwọn arákùnrin olùfọkànsìn yìí lọ́wọ́, àwọn nìkan ṣoṣo ni wọ́n ń dá ṣe àwọn ìpinnu nínú ìjọ, ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ní oríléeṣẹ́. Ní ọdún 1970 sí ọdún 1979, àwọn nǹkan yí pa dà, alàgbà kan ṣoṣo ò dá ṣèpinnu mọ́, àwùjọ àwọn alàgbà ló wá ń ṣe ìpinnu. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó túbọ̀ ṣe kedere sí wa ló mú ká ṣe àwọn ìyípadà náà. Dípò tí ẹnì kan ṣoṣo á fi máa pàṣẹ, Jèhófà fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” ètò Ọlọ́run sì ń jàǹfààní látinú ànímọ́ rere tí gbogbo wọ́n ní.—Éfé. 4:8. w15 7/15 1:14, 15
Wednesday, April 19
Wọn kì í ṣe apá kan ayé.—Jòh. 17:16.
Nígbà ogun àti láwọn ìgbà míì, ó máa ń pọn dandan fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí wọ́n sì ta kété sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwọn á jẹ́ adúróṣinṣin, àwọn á sì máa ṣègbọràn sí i. (1 Jòh. 5:3) Láìka ibi tá à ń gbé sí, yálà a jẹ́ olówó tàbí òtòṣì, orílẹ̀-èdè yòówù ká ti wá, tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa, àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run la fẹ́ máa tẹ̀ lé. Jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ borí àjọṣe èyíkéyìí tá a lè ní pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. (Mát. 6:33) Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe jẹ́ adúróṣinṣin yìí gba pé kí wọ́n má ṣe máa dá sí ìjà àti àríyànjiyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. (Aísá. 2:4; Jòh. 17:11, 15, 16) Ó lè jẹ́ pé ohun mìíràn ni àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ yàn láàyò, irú bí orílẹ̀-èdè wọn, ẹ̀yà wọn, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè wọn pàápàá. Bí ẹnikẹ́ni bá ní èrò tó yàtọ̀ sí tiwọn, ó máa ń yọrí sí bíbá ara ẹni díje àti ìfagagbága, ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí ìpẹ̀yàrun nígbà míì. Tá ò bá ṣọ́ra, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ èrò àwọn èèyàn, ká sì máa dá sí àríyànjiyàn tó ń lọ nínú ayé. w15 7/15 3:1, 2
Thursday, April 20
Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.—1 Kọ́r. 14:40.
Lẹ́yìn tí a bá ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tán, ó yẹ ká máa tọ́jú rẹ̀ kó lè máa wà ní mímọ́ àti létòlétò, ìyẹn á sì fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà àti ìṣe Jèhófà, tó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́r. 14:33) Bíbélì fi hàn pé ká lè jẹ́ mímọ́, ìjọsìn wa ò gbọ́dọ̀ ní àbààwọ́n, àwa náà sì gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní. (Ìṣí. 19:8) Torí náà, bí àwọn èèyàn bá fẹ́ láti jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́. Tá a bá fi ìlànà yìí sọ́kàn, á máa yá wa lára láti ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn wá sí àwọn ìpàdé wa, torí ó dá wa lójú pé ipò tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa wà ò ní tàbùkù sí ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀ fún wọn. Wọ́n á rí i pé Ọlọ́run mímọ́ là ń sìn, kò sì ní pẹ́ sọ ayé di Párádísè tí kò ní àbààwọ́n. (Aísá. 6:1-3; Ìṣí. 11:18) Bó ti wù kí nǹkan rí, ó yẹ kí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa máa wà ní mímọ́ tónítóní ní gbogbo ìgbà torí pé orúkọ Jèhófà la fi ń pè é, a sì ń ṣe ìjọsìn mímọ́ níbẹ̀.—Diu. 23:14. w15 7/15 4:13-15
Friday, April 21
Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.—Máàkù 13:35.
Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé ọdún 1914 ni ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀, torí náà wọ́n múra sílẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé ìgbàkigbà ni òpin lè dé. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nípa títúbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Jésù sọ pé òun lè dé yálà ní “ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀.” Ìgbà yòówù kí Jésù dé, kí ló yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe? Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Torí náà, bí òpin ò bá tiẹ̀ tètè dé, ìyẹn ò ní ká máa rò pé kò ní dé mọ́ tàbí ká má fojú sọ́nà fún un mọ́. Nínú ayé tuntun, àá rántí pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú òpin ètò àwọn nǹkan ló ti ṣẹ. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ibi tí gbogbo nǹkan wá já sí, àá túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà, àá sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó máa mú èyí tó kù lára àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Jóṣ. 23:14) Ó dájú pé àá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó ‘ti fi àwọn ìgbà àti àsìkò sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀,’ tó sì ti kìlọ̀ fún wa láti máa fi sọ́kàn pé “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.”—Ìṣe 1:7; 1 Pét. 4:7. w15 8/15 2:10, 11, 14
Saturday, April 22
Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.—2 Tím. 3:12.
Bíbélì sọ pé ìwà ipá, ìṣekúṣe, ìbẹ́mìílò àti àwọn ìwà míì tí kò múnú Ọlọ́run dùn kò dára. Ṣùgbọ́n eré tó ń gbé àwọn nǹkan yìí lárugẹ ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń najú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìkannì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn fíìmù, ìwé ìtàn àti àwọn ìwé ìròyìn máa ń mú kí àwọn èèyàn rí ìwà ipá àti ìṣekúṣe bí ohun tí kò burú. Wọ́n ti sọ àwọn ìwà táwọn èèyàn kórìíra tẹ́lẹ̀ di ohun tó bófin mu láwọn orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. (Róòmù 1:28-32) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kọ̀ láti lọ́wọ́ sí àwọn eré ìnàjú tí kò dára. Nítorí èyí àti ìwà tó ń múnú Ọlọ́run dùn tí wọ́n ń hù, àwọn èèyàn ṣáátá wọn, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wọn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Nítorí ẹ [àwọn Kristẹni] kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.”—1 Pét. 4:4. w15 8/15 4:2, 3
Sunday, April 23
Ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.—Éfé. 4:16.
Bí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá dàgbà dénú, ńṣe ni yóò máa pa kún ìṣọ̀kan ìjọ. (Éfé. 4:1-6, 15) Àfojúsùn gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run ni pé ká wà “ní ìṣọ̀kan” ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa. Bí Bíbélì ṣe sọ, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká tó lè wà ní ìṣọ̀kan. Arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó dàgbà dénú máa ń wá bó ṣe máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn míì kódà tí àìpé wọn bá mú kó ṣòro fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àìpé arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ bá mú kó ṣe ohun tó kù-díẹ̀-káàtó, kí lo máa ṣe? Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ọ́ nínú ìjọ ńkọ́? Ṣé o máa bẹ̀rẹ̀ sí í yàn án lódì? Àbí ńṣe lo máa yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín yín? Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń yanjú ìṣòro ni, kì í dá kún un. Ṣó máa ń wu ìwọ náà láti pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ? w15 9/15 1:12, 13
Monday, April 24
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.—Jòh. 17:17.
Ó dá Jésù lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ ló sì dára jù lọ. Kó bàa lè dá àwa náà lójú bíi ti Jésù pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, a gbọ́dọ̀ máa kà á lójoojúmọ́, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a bá kọ́ nínú rẹ̀. Bá a ṣe ń ka Bíbélì, ó tún yẹ ká máa ṣèwádìí lórí àwọn nǹkan tá a bá rí pé kò yé wa. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé a ti ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn nínú Ìwé Mímọ́, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé ní tòótọ́. Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó ti ṣẹ, ìgbẹ́kẹ̀lé tó o ní nínú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ọjọ́ iwájú á lágbára sí i. Tó o bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé àwa èèyàn pa dà, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó wúlò. (1 Tẹs. 2:13) O lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ. (Héb. 12:2) Má wulẹ̀ wo àwọn ìlérí yìí bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún aráyé lápapọ̀, ṣùgbọ́n wò ó bíi pé ìwọ gan-an ni Ọlọ́run ṣe ìlérí náà fún. w15 9/15 3:16, 17
Tuesday, April 25
Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.—Òwe 3:9.
Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? A lè fi àwọn ohun ìní wa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe nínú ìjọ wa tàbí kárí ayé. Ọ̀nà kan tó dáa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nìyẹn yálà a ní ohun díẹ̀ tàbí púpọ̀ nípa tara. (2 Kọ́r. 8:12) Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Rántí pé Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe máa ṣàníyàn nípa oúnjẹ tàbí aṣọ, àmọ́ kí wọ́n máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Ó sọ pé Baba wa mọ ohun tá a nílò ní ti gidi. (Mát. 6:31-33) Tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìlérí yẹn, á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú torí pé ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé jọ máa ń rìn pọ̀ ni. Ó ṣe tán a ò lè nífẹ̀ẹ́ èèyàn dénú tá ò bá fọkàn tán an. (Sm. 143:8) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn àfojúsùn mi àti bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́? Ǹjẹ́ àwọn ohun tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè àwọn ohun tí mo nílò fún mi?’ w15 9/15 5:7, 8
Wednesday, April 26
Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa.—Héb. 11:6.
Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé, ‘Ṣé irú èèyàn bíi tèmi ni Jèhófà máa fẹ́ gbà là nígbà ìpọ́njú ńlá táá sì mú wọnú ayé tuntun?’ Ohun pàtàkì kan tó pọn dandan pé ká ṣe ni pé ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká mọ bí ìgbàgbọ́ ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ìjójúlówó” rẹ̀ “tí a ti dán wò, . . . èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (1 Pét. 1:7) Níwọ̀n bí ìpọ́njú ńlá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán báyìí, ǹjẹ́ kò yẹ ká rí i dájú pé a ní irú ìgbàgbọ́ tó máa mú ká wà lára àwọn tí Ọba wa ológo máa yìn nígbà ìṣípayá rẹ̀ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́? Ó dájú pé àá fẹ́ jẹ́ “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Héb. 10:39) Tá a bá fẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, àwa náà lè bẹ̀bẹ̀ bíi ti ọkùnrin tó sọ pé: “Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!” (Máàkù 9:24) Tàbí ká ṣe bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n sọ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”—Lúùkù 17:5. w15 10/15 2:1, 2
Thursday, April 27
Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò.—Héb. 12:1.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pọkàn pọ̀ sórí “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” Ó ṣiṣẹ́ kára láti wàásù ìhìn rere, ó rìnrìn-àjò jákèjádò ìlú Síríà, Éṣíà Kékeré, Makedóníà àti Jùdíà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje.” (Fílí. 1:10; 3:8, 13, 14) Pọ́ọ̀lù lo àǹfààní jíjẹ́ tó jẹ́ àpọ́n láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ sin “Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.” (1 Kọ́r. 7:32-35) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ti yàn láti wà láì lọ́kọ tàbí aya kí bùkátà wọn lè ṣẹ́ pẹ́rẹ́ kí wọ́n sì lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Mát. 19:11, 12) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ṣègbéyàwó sábà máa ń ní bùkátà tó pọ̀ láti gbọ́ nínú ìdílé. Àmọ́, yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣègbéyàwó, gbogbo wa lè “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò,” ká lè sin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn. Ó lè gba pé ká dín àkókò tá à ń lò lórí àwọn ohun tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan kù, ká sì pinnu láti lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. w15 10/15 3:15, 16
Friday, April 28
Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.—2 Tím. 3:13.
Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn fi hàn gbangba pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Ó ṣe kedere pé Jèhófà ò dá àwa èèyàn láti máa darí ara wa. Bí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ìjọba èèyàn ò lè ṣàṣeyọrí láé. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣàṣeyọrí. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti mú gbogbo ìwà ibi àtàwọn tó ń fà á kúrò, bí ẹnikẹ́ni bá tún yọwọ́kọ́wọ́ tó wá sọ pé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso ò dáa, Jèhófà ò ní gba irú ọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀ láyè mọ́ láé. Ọlọ́run máa lo àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó fi yẹ kó mú ìdájọ́ wá sórí irú àwọn ọlọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́gán, kò sì ní jẹ́ kí ìwà ibi tún gbérí mọ́ láé. w15 11/15 3:5, 6
Saturday, April 29
Kí Ọlọ́run àlàáfíà . . . fi ohun rere gbogbo mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Héb. 13:20, 21.
Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù máa ń sọ jù lọ. Kódà, ó ju ọgọ́rùn-ún ìgbà lọ tó fi sọ̀rọ̀ nípa ìjọba náà nígbà tó ń wàásù. Ó dájú pé ọwọ́ pàtàkì ni Jésù fi mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 12:34) Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ló fara han àwọn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ lára àwọn tó wá pa dà di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (1 Kọ́r. 15:6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn náà ló pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” Iṣẹ́ tí kò rọrùn lèyí jẹ́ nígbà yẹn! Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á máa ṣe iṣẹ́ ribiribi náà nìṣó títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà wà lára àwọn tó ń wàásù ìhìn rere tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ. (Mát. 28:19, 20) Ọlọ́run sì ti fún wa ní àwọn “ohun rere gbogbo” tá a máa fi ṣe iṣẹ́ náà. w15 11/15 5:1-3
Sunday, April 30
Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.—Ẹ́kís. 3:15.
Àwọn kan ka àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Hébérù àtijọ́ irú bí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí bí àwọn ibi tí lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn ṣe pọ̀ tó. Kì í ṣe inú àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Hébérù àtijọ́ yìí nìkan ni orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn, ó tún fara hàn nínú Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì tó wà láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Láìka bí ẹ̀rí ṣe pọ̀ lọ jáǹtirẹrẹ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì, ńṣe lọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò pátápátá nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Bíbélì Revised Standard Version tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún méjì lẹ́yìn náà yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì American Standard Version ti ọdún 1901 lo orúkọ Ọlọ́run, àmọ́ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Revised Standard Version tó yẹ kó jẹ́ àtúnṣe Bíbélì American Standard Version yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò. Kí nìdí tí wọ́n fi yọ ọ́ kúrò? Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó wà nínú Bíbélì Revised Standard Version, wọ́n sọ pé: “Kò bójú mu rárá . . . pé kí àwọn Kristẹni máa fi orúkọ èyíkéyìí pe Ọlọ́run.” Ohun táwọn atúmọ̀ míì sì ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn èdè míì. w15 12/15 2:3-5