June
Thursday, June 1
Ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.—Òwe 25:15.
Tá a bá fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ kódà tí ẹnì kan bá sọ ohun tó múnú bí wa, àlááfíà á wà láàárín wa. (Òwe 15:1) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ arábìnrin anìkàntọ́mọ kan ń kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. Arábìnrin kan sọ fún ìyá ọmọ náà pé: “Ẹ ò kọ́ ọmọ yín yìí rárá.” Ìyá ọmọ náà ronú fún bí ìṣẹ́jú mélòó kan, ó wá sọ pé: “Òótọ́ ni pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ nísinsìnyí, àmọ́ ó ṣì máa yí pa dà. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, a máa mọ̀ bóyá mo kọ àbí mi ò kọ́ ọ.” Bí ìyá ọmọ yìí ṣe fohùn pẹ̀lẹ́ bá arábìnrin yìí sọ̀rọ̀ pa àlááfíà tó wà láàárín wọn mọ́. Ìjíròrò yìí ta sọ́mọ yẹn létí, ó sì wú u lórí láti mọ̀ pé ìyá òun ò tíì sọ̀rètí nù lórí òun. Ohun tó gbọ́ yìí ló mú kó yé kẹ́gbẹ́ burúkú mọ́. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi ó sì lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Yálà a wà láàárín àwọn ará, ẹbí tàbí àwọn àjèjì, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa fìgbà gbogbo jẹ́ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Kól. 4:6. w15 12/15 3:15, 17
Friday, June 2
Àwọn ahọ́n bí ti iná . . . bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.—Ìṣe 2:3.
Tó o bá wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní yàrá òkè lọ́jọ́ yẹn, o ò ní gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn láé. Jèhófà fún wọn lágbára láti fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀. Èyí mú kó dá gbogbo wọn lójú pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Ìṣe 2:6-12) Àmọ́, àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ yìí kì í ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Kristẹni tó di ẹni àmì òróró lẹ́yìn náà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ò sọ pé ohun kan tó dà bí iná yọ sórí àwọn ẹgbẹ̀rún mélòó kan tí Jèhófà tún fẹ̀mí yàn ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ náà. Ìgbà tí wọ́n ṣe batisí ni Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ́n. (Ìṣe 2:38) Bákan náà, kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni tó di ẹni àmì òróró ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n ṣe batisí ni Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí àwọn ará Samáríà ṣe batisí ni Jèhófà tó fẹ̀mí yàn wọ́n. (Ìṣe 8:14-17) Ti Kọ̀nílíù àtàwọn ará ilé ẹ̀ tiẹ̀ tún wá yàtọ̀, kí wọ́n tó ṣe batisí ni Jèhófà ti fẹ̀mí yàn wọ́n.—Ìṣe 10:44-48. w16.01 3:3, 5
Saturday, June 3
Ẹ máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.—Éfé. 4:3.
Àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ. Wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ tí Jèhófà fún àwọn kò ju èyí tó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kù lọ. Wọn kì í sì í ronú pé àwọn lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ ju gbogbo àwọn yòókù lọ. Wọn ò sì jẹ́ sọ fẹ́nì kan pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn án torí náà kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ búrẹ́dì kó sì máa mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló ń yan àwọn tó máa lọ sọ́run. Àwọn ẹni àmì òróró kì í retí pé káwọn èèyàn máa fún àwọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. (Éfé. 1:18, 19; Fílí. 2:2, 3) Wọ́n sì mọ̀ pé nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí yan àwọn, kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀. Torí náà, ẹni àmì òróró kan ò ní jẹ́ kó ya òun lẹ́nu táwọn kan ò bá tètè gbà pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan òun.—Ìṣí. 2:2. w16.01 4:6, 7
Sunday, June 4
Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!—Róòmù 11:33.
Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ táwọn kan mú Sárà tó jẹ́ arẹwà lọ, tí ẹ̀mí Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ sì wà nínú ewu, àmọ́ Jèhófà dáàbò bo Ábúráhámù àti Sárà lọ́nà ìyanu. (Jẹ́n. 12:10-20; 20:2-7, 10-12, 17, 18) Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lágbára sí i. Ṣé a lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni! Bíi ti Ábúráhámù, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àwa náà sì lè ní ìmọ̀ àti ìrírí táá mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Lónìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tá a lè mọ̀ nípa Jèhófà. (Dán. 12:4) Àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa “Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” kún inú Bíbélì. Àwọn ohun tá à ń kọ́ nípa Jèhófà ń mú ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń mú ká ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un. (Jẹ́n. 14:22) Bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún un yìí ló ń mú ká máa ṣègbọràn sí i. Bá a sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń rí bó ṣe ń bù kún wa tó sì ń dáàbò bò wá, ìyẹn ló ń jẹ́ ká ní ìrírí tó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Tá a bá fi gbogbo ayé wa sin Jèhófà, ọkàn wa á balẹ̀, àá sì ní àlàáfíà àti ayọ̀. (Sm. 34:8; Òwe 10:22) Bá a ṣe ń mọ Jèhófà sí i ni Jèhófà á máa bù kún wa, bẹ́ẹ̀ sì ni àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ á máa lágbára sí i. w16.02 1:7, 8
Monday, June 5
Ó ti wá ṣe àrànṣe fún Ísírẹ́lì . . . , gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn baba ńlá wa.—Lúùkù 1:54, 55.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ níbí yìí fi hàn pé ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Lọ́nà wo? Àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ níbẹ̀ jọ àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà tí Hánà, ìyá Sámúẹ́lì gbà. (1 Sám. 2:1-10) Ó jọ pé nǹkan bí ìgbà ogún ni Màríà fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. Ó ṣe kedere pé Màríà fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Bíi ti Màríà, Jèhófà lè gbé àwọn iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́, àmọ́ nígbà míì a lè máa rò pé iṣẹ́ náà ti le jù. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Màríà, ká fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà, ká sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀nà míì tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Màríà ni pé ká máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jèhófà, ká sì máa ronú lórí àwọn ohun tá a ti kọ́ nípa rẹ̀ àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Ìgbà yẹn la tó lè fayọ̀ sọ àwọn ohun tá a ti kọ́ fáwọn èèyàn.—Sm. 77:11, 12; Lúùkù 8:18; Róòmù 10:15. w16.02 2:17, 18
Tuesday, June 6
Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?—Lúùkù 14:28.
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún. (Oníw. 12:1) Ó yẹ káwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí àtàwọn alàgbà rí i dájú pé àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìpinnu yìí fúnra wọn, wọ́n sì mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣèrìbọmi. Ìgbésí ayé tuntun yìí máa mú ká rí ìbùkún Jèhófà, àmọ́ ó máa mú kí Sátánì ṣàtakò sí wa. (Òwe 10:22; 1 Pét. 5:8) Ìdí nìyẹn tó fi pọn dandan pé káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni rí i dájú pé àwọn ń wáyè láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè mọ ohun tó túmọ̀ sí ní ti gidi láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Tí òbí àwọn ọmọ kan kì í bá ṣe Kristẹni, àwọn alàgbà ìjọ á fìfẹ́ ran irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. (Lúùkù 14:27-30) Bó ṣe jẹ́ pé ẹni bá fẹ́ kọ́lé máa ń gbéṣirò lé e, bákan náà, àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ kí wọ́n tó ṣèrìbọmi, kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà “dé òpin.”—Mát. 24:13. w16.03 1:1, 2
Wednesday, June 7
Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.—Ìṣe 10:34, 35.
Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn àti bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn Rẹ̀. Àmọ́, láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kì í tún ṣe orílẹ̀-èdè kan làwọn èèyàn Ọlọ́run ti wá mọ́, wọ́n wá láti onírúurú ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè, Ísírẹ́lì tẹ̀mí la sì ń pè wọ́n. “Òfin Kristi” ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ìyẹn òfin tó dá lórí àwọn ìlànà tá a kọ sínú ọkàn wọn kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sórí òkúta. Ibi yòówù káwọn Kristẹni máa gbé, òfin yìí á ṣe wọ́n láǹfààní, á sì máa tọ́ wọn sọ́nà. (Gál. 6:2) Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti jàǹfààní gan-an látinú àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà tipasẹ̀ Jésù fún wọn. Kí Jésù tó dá májẹ̀mú tuntun sílẹ̀, ó pa àṣẹ pàtàkì méjì kan fún wọn. Ọ̀kan dá lórí iṣẹ́ ìwàásù. Ìkejì dá lórí bó ṣe yẹ káwa Kristẹni máa ṣe síra wa. Kò sí Kristẹni tí ìtọ́ni yìí ò kàn, torí náà, gbogbo wa ni wọ́n wà fún, yálà a nírètí láti bá Jésù jọba lọ́run tàbí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. w16.03 4:10, 11
Thursday, June 8
Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.—Róòmù 12:10.
Kí alàgbà kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá arákùnrin míì lẹ́kọ̀ọ́ ó yẹ kó mú kí ara tu onítọ̀hún kó sì mú un lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ìgbésẹ̀ tí alàgbà kan máa gbé kó tó lè di ọ̀rẹ́ ẹni tó fẹ́ dá lẹ́kọ̀ọ́ máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, ó máa sinmi lórí ipò kálukú àti àṣà wọn. Síbẹ̀, ibi yòówù kó o máa gbé, tó o bá ń wáyè láti wà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí alàgbà máa ń mú kí ọwọ́ rẹ dí, ohun tó ò ń sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ni pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ mí lógún gan-an ni.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ibi yòówù kó o máa gbé, àwọn tó múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ á mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, wọ́n á sì mọyì rẹ̀ gan-an. Yàtọ̀ sí pé olùkọ́ tó kẹ́sẹ járí máa ń fẹ́ dá ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́, ó tún máa nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń dá lẹ́kọ̀ọ́. (Fi wé Jòh. 5:20.) Kò ní pẹ́ rárá tí akẹ́kọ̀ọ́ náà á fi rí i pé olùkọ́ náà nífẹ̀ẹ́ òun, èyí sì máa jẹ́ kí ohun tó ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Nítorí náà, ẹ̀yin alàgbà, bí ẹ ṣe ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ẹ má ṣe jẹ́ olùkọ́ nìkan, ẹ di ọ̀rẹ́ wọn.—Òwe 17:17; Jòh. 15:15. w15 4/15 1:19, 20
Friday, June 9
Jèhófà fi àrùn kọlu ọba, ó sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.—2 Ọba 15:5.
Kí lo máa ṣe ká sọ pé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìtàn Asaráyà Ọba (tá a tún ń pè ní Ùsáyà Ọba) ò sí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bó ṣe rí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì? (2 Ọba 15:7, 32; 2 Kíró. 26:3-5, 16-21) Ṣé o kò ní máa rò pé ohun tí Ọlọ́run ṣe kò bá ìdájọ́ òdodo mu? Àbí wàá gbà pé ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì ti tó láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tí ó tọ́, àti pé, Òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́? (Diu. 32:4) Bá a ṣe ń mọ Jèhófà sí i tó sì jẹ́ ẹni gidi sí wa, a máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì máa mọrírì ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan gan-an débi pé a kò ní nílò àlàyé fún gbogbo ohun tó bá ṣe. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá ń sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run fi ń bá ẹ sọ̀rọ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, wàá túbọ̀ máa mọyì Jèhófà sí i. (Sm. 77:12, 13) Èyí sì máa mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, kó sì jẹ́ ẹni gidi sí ẹ. w15 4/15 3:8, 10
Saturday, June 10
Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Sm. 103:20.
Àwọn áńgẹ́lì tá ò lè fojú rí yìí “tóbi jọjọ nínú agbára.” Wọ́n lágbára ju àwa èèyàn lọ fíìfíì, torí náà ọgbọ́n wọn àti okun wọn ju tiwa lọ gan-an. Ohun kan ni pé àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa ń fi agbára wọn ṣe ohun rere. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan áńgẹ́lì Jèhófà kan ṣoṣo pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run. Kò sí ẹgbẹ́ ológun kan tó lè ṣe irú iṣẹ́ ńlá yìí, ká má tiẹ̀ wá sọ ẹ̀dá èèyàn kan ṣoṣo. (2 Ọba 19:35) Àpẹẹrẹ míì ni ańgẹ́lì kan tó lo agbára ńlá àti ọgbọ́n gíga rẹ̀ láti dá àwọn àpọ́sítélì Jésù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Áńgẹ́lì náà wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n láìsí ìdíwọ́ kankan, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn, ó mú àwọn àpọ́sítélì náà jáde, ó sì tún pa ìlẹ̀kùn dé, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ẹ̀ṣọ́ náà dúró láìlè ta pútú! (Ìṣe 5:18-23) Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa ń lo agbára wọn láti ṣe ohun rere, àmọ́ Sátánì máa ń lo agbára tiẹ̀ láti ṣe ohun búburú. Ẹ wo bí agbára tó ní lórí àwọn èèyàn ṣe pọ̀ tó! Ìwé Mímọ́ pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòh. 12:31. w15 5/15 1:5, 6
Sunday, June 11
Kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má . . . sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.—Héb. 3:13.
Yálà a ti lọ́kọ tàbí láya tàbí a ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ sapá gidigidi ká má ṣe fàyè gba ìṣekúṣe. Ṣé ó rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé kò rọrùn! Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o lè gbọ́ táwọn ọmọléèwé rẹ̀ ń fọ́nnu pé àwọn máa ń gbé ara wọn sùn tàbí pé àwọn máa ń fi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònú, èyí táwọn kan kà sí wíwo àwòrán ìhòòhò ọmọdé. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́r. 6:18) Àwọn àrùn táwọn èèyàn máa ń kó látinú ìṣekúṣe ti fojú àwọn èèyàn rí màbo, ó sì ń pa wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ti mọ ọkùnrin tàbí tó ti mọ obìnrin láìtíì ṣègbéyàwó ni wọ́n sọ pé àwọn kábàámọ̀ ohun táwọn ṣe. Kì í ṣe ohun tí ìwà ìṣekúṣe jẹ́ gan-an làwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n, rédíò, àwọn fíìmù àtàwọn ìwé máa ń gbé jáde, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń mú káwọn èèyàn gbà pé kò sóhun tó máa tìdí rẹ̀ yọ béèyàn bá rú àwọn òfin Ọlọ́run. Irú èrò yìí ti mú kí “agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀” dẹkùn mú àwọn èèyàn. w15 5/15 2:14
Monday, June 12
Ẹni Gíga Jù Lọ . . . jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.—Lúùkù 6:35.
Jésù náà jẹ́ onínúure bíi ti Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Jésù máa ń ro bí ọ̀rọ̀ àti ìṣe òun ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíì, èyí sì jẹ́ kó tipa bẹ́ẹ̀ fi inúure hàn sáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó ń sunkún, ó sì ń fi omijé ojú rẹ̀ rin ẹsẹ̀ Jésù. Jésù fòye mọ̀ pé obìnrin náà ti ronú pìwà dà, ó sì mọ̀ pé òun máa bàá lọ́kàn jẹ́ tí òun bá kanra mọ́ ọn. Torí náà, Jésù yìn ín fún ohun tó ṣe yẹn, ó sì dárí jì í. Kódà nígbà tí Farisí kan kọminú sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jésù lo inú rere nígbà tó fún un lésì. (Lúùkù 7:36-48) Báwo la ṣe lè jẹ́ onínúure bíi ti Jèhófà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn [tàbí ẹni tó ń fi ọgbọ́n bá gbogbo èèyàn lò].” (2 Tím. 2:24) Tá a bá ń fi ara wa sípò àwọn ẹlòmíì, tá a sì ń ronú lórí ipa tí ọ̀rọ̀ wa lè ní lórí wọn, èyí á jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká sọ̀rọ̀ ká sì hùwà lọ́nà tó máa fi hàn pé a jẹ́ onínúure bíi ti Jèhófà.—Òwe 15:28. w15 5/15 4:8, 9
Tuesday, June 13
Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.—Òwe 3:27.
áwọn ará wa bá wà nínú ìnira, a lè tù wọ́n nínú, ká sì tì wọ́n lẹ́yìn nípa tara, ká bá wọn kẹ́dùn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Òwe 17:17) Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣèrànwọ́ fún wọn kí wọ́n lè borí ìjábá tó dé bá wọn. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ tí opó kan sọ tọkàntọkàn lẹ́yìn tí ìjì líle kan ba ilé rẹ̀ jẹ́ kọjá àlà, ó ní: “Mo dúpẹ́ púpọ̀ pé mo wà nínú ètò Jèhófà, kì í ṣe torí ìrànwọ́ nípa tara tí wọ́n ṣe nìkan, mo tún dúpẹ́ fún ìrànwọ́ tẹ̀mí náà.” Gbogbo nǹkan tojú sú arábìnrin kan tí kò lọ́kọ, lẹ́yìn tó rí ọṣẹ́ tí ìjì líle ṣe sí ilé rẹ̀, kò sì mọ ibi tó máa yà sí, àmọ́ lẹ́yìn táwọn ará ràn án lọ́wọ́, ó sọ pé: “Ó kọjá àfẹnusọ! Mi ò mọ bí màá ṣe sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi . . . Jèhófà, o ṣeun!” A dúpẹ́ pé a wà nínú ètò kan tí wọn ò ti fi ọ̀rọ̀ ara wọn ṣeré. Ohun míì tó tún mú kí ayọ̀ wa kún sí i ni bí Jèhófà àti Jésù Kristi ṣe fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. w15 6/15 1:17
Wednesday, June 14
[Máa wo] àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.—1 Tím. 5:2.
Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìṣekúṣe ní ti pé ó fún wa ní ìmọ̀ràn nípa bó ṣe yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin máa ṣe sí ara wọn. Ìmọ̀ràn yìí fi hàn pé kò tọ̀nà kéèyàn máa tage. Àwọn kan rò pé kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn kàn fojú sọ̀rọ̀, kó fara sọ̀rọ̀ tàbí kéèyàn dínjú sẹ́nì kan lọ́nà tó lè mú kí ọkàn onítọ̀hún fà sí ìṣekúṣe, tí kò bá ṣáà ti fara kan onítọ̀hún. Àmọ́, tẹ́nì kan bá ń tage tàbí tó fàyè gbà á, o lè mú kí onítọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí í ro èròkerò, ó sì lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ tó burú jáì. Ó ti ṣẹlẹ̀ rí, ó sì tún lè ṣẹlẹ̀. Ní ti Jósẹ́fù, ó fi ọgbọ́n hùwà. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra, Jósẹ́fù kọ̀ jálẹ̀. Àmọ́, ìyàwó Pọ́tífárì kò jáwọ́, ojoojúmọ́ ló fi ń rọ Jósẹ́fù pé kó wà pẹ̀lú òun. (Jẹ́n. 39:7, 8, 10) Síbẹ̀, Jósẹ́fù ti pinnu pé òun ò ní ṣe ohun táá jẹ́ kó fa ojú òun mọ́ra tàbí gbà á láyè láti bá òun ṣe ohunkóhun, èyí ni kò sì jẹ́ kí èròkerò ráyè jọba lọ́kàn rẹ̀. w15 6/15 3:10, 11
Thursday, June 15
Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.—Mát. 6:12.
Jèhófà kò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ipò tẹ̀mí tara wa nìkan jẹ wá lógún, ó fẹ́ ká ro ti àwọn ẹlòmíì náà, títí kan àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣẹ̀ wá. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í tó nǹkan. Torí náà, àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa àti pé a múra tán láti dárí jì wọ́n, bí Ọlọ́run náà ṣe ń fi àánú hàn sí wa tó sì ń dárí jì wá. (Kól. 3:13) Torí a jẹ́ aláìpé, ó ṣeni láàánú pé nígbà míì a máa ń di àwọn èèyàn sínú. (Léf. 19:18) Tá a bá lọ ro ẹjọ́ fáwọn ẹlòmíì, wọ́n lè gbè sẹ́yìn wa, ìyẹn sì lè fa ìpínyà nínú ìjọ. Tí a bá fàyè gba irú ẹ̀mí yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a kò mọrírì àánú Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ìràpadà náà nìyẹn. Tí a kò bá ní ẹ̀mí ìdáríjini, Baba wa kò ní jẹ́ kí ìtóye ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún wa mọ́. (Mát. 18:35) Jésù túbọ̀ ṣàlàyé lórí kókó yìí ní gbàrà tó sọ àdúrà àwòṣe náà tán. (Mát. 6:14, 15) Paríparí rẹ̀, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa kí á má ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì dàṣà.—1 Jòh. 3:4, 6. w15 6/15 5:9-11
Friday, June 16
Ìdùnnú ọba ń bẹ nínú ìránṣẹ́ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà.—Òwe 14:35.
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà yọ̀ǹda fún wa láti fi kún ẹwà Párádísè tẹ̀mí wa. Báwo la ṣe ń fi kún ẹwà Párádísè náà? À ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbàkigbà tá a bá ran ẹnì kan lọ́wọ́ tó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́, a ti mú kí ààlà Párádísè tẹ̀mí náà gbòòrò sí i nìyẹn. (Aísá. 26:15; 54:2) A tún lè fi kún ẹwà Párádísè tẹ̀mí tá a bá ń sapá láti mú kí ìwà wa máa sunwọ̀n sí i. Lọ́nà yẹn, a óò túbọ̀ mú kí Párádísè yìí fa àwọn tí kò tíì wá síbẹ̀ mọ́ra. Ìmọ̀ Bíbélì ní àyè tirẹ̀, àmọ́ ìwà mímọ́ wa àti bá a ṣe ń gbé ní ìrẹ́pọ̀ ló kọ́kọ́ máa ń fa àwọn èèyàn wá sínú ètò Ọlọ́run, á sì wá mú kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà àti Jésù. Ó dájú pé inú Jèhófà àti Jésù á máa dùn gan-an bí wọ́n ti ń wo Párádísè tẹ̀mí tó rẹwà tá a wà nínú rẹ̀ lónìí. À ń láyọ̀ bá a ṣe ń mú kí Párádísè tẹ̀mí tá a wà nínú rẹ̀ rẹwà sí i. Àmọ́, ìtọ́wò lásán nìyẹn jẹ́ tá a bá fi wé ayọ̀ tá a máa ní nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ayé di Párádísè. w15 7/15 1:18-20
Saturday, June 17
Ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.—Jẹ́n. 3:5.
Lónìí, gbogbo wa gbọ́dọ̀ fi hàn bóyá a gbà lóòótọ́ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso ló sàn ju ti Sátánì lọ tàbí kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ǹjẹ́ o fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ dípò kó o máa ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ? Ǹjẹ́ o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú ìṣòro tó ń bá àwa ẹ̀dá èèyàn fínra? Àbí o gbà pé àwọn èèyàn lè ṣàkóso ara wọn? Ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí ló máa sọ bó o ṣe máa dáhùn táwọn èèyàn bá ní kó o dá sí ọ̀rọ̀ kan tó ń jà ràn-ìn. Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn olóṣèlú, àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti àwọn alátùn-únṣe ìsìn ti ń sapá bóyá wọ́n á lè rí ojútùú sí ìyapa tó máa ń wà. Èrò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè dáa, kí wọ́n sì fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé, kó sì rí i dájú pé ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀. Àfi ká yáa jẹ́ kí Jèhófà fi ọwọ́ ara rẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣe tán, bí àwọn Kristẹni tòótọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá ń wá ojútùú tí wọ́n rò pé ó máa yanjú ìṣòro aráyé, ǹjẹ́ ìjọ ò ní pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ? w15 7/15 3:7, 8
Sunday, June 18
Èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ.—Sm 77:12.
Ṣé òótọ́ ni pé tá a bá ń kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá, a máa rí i pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wa? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìdí sì ni pé ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan. (Róòmù 1:20) Ó dá ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ká lè máa wà láàyè ká sì ní ìlera tó dáa. Àmọ́, kò dá wa lásán, ó tún fẹ́ ká máa gbádùn ara wa. Ó di dandan ká jẹun ká tó lè máa wà láàyè. Torí náà, kí àwa èèyàn lè máa rí oúnjẹ tó gbámúṣé jẹ, Jèhófà rí i dájú pé onírúurú ewéko ń hù jáde. Kódà, ó tún mú kí àwọn oúnjẹ náà ládùn kí wọ́n sì gbádùn mọ́ni. (Oníw. 9:7) Bí Jèhófà ṣe dá wa mú ká lè máa ṣe iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni tó sì nítumọ̀, èyí sì máa ń mú ká túbọ̀ gbádùn ara wa. (Oníw. 2:24) Ó wù ú pé kí àwọn èèyàn kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì máa jọba lórí ẹja, àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù. (Jẹ́n. 1:26-28) Jèhófà dá wa pẹ̀lú àwọn ànímọ́ tó lè mú ká fìwà jọ ọ́, ẹ ò rí i bí ìfẹ́ tó ní sí wa ṣe pọ̀ tó!—Éfé. 5:1. w15 8/15 1:4, 5
Monday, June 19
Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa . . . lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.—Lúùkù 21:34, 35.
Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé mú kó ṣe kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ báyìí àti pé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ lérò pé àkókò púpọ̀ ṣì máa kọjá kó tó di pé “ìwo mẹ́wàá” àti “ẹranko ẹhànnà” inú Ìṣípayá 17:16 máa pa Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ́ ọba ìsìn èké àgbáyé run. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Ọlọ́run máa “fi í sínú ọkàn-àyà wọn” láti gbé ìgbésẹ̀ yìí, èyí sì lè ṣẹlẹ̀ lọ́nà yíyára kánkán àti nígbàkigbà. (Ìṣí. 17:17) Kò ní pẹ́ mọ́ tí òpin gbogbo ètò àwọn nǹkan yìí á fi dé. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fetísílẹ̀ sí ìkìlọ̀ Jésù gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. (Ìṣí. 16:15) Ẹ jẹ́ ká wà lójúfò, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa “gbé ìgbésẹ̀ ní tìtorí [àwọn] tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.”—Aísá. 64:4. w15 8/15 2:17
Tuesday, June 20
Ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá mi.—Máàkù 3:35.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká máa hùwà tó dáa sí gbogbo èèyàn, a kò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tí kì í pa òfin Ọlọ́run mọ́ kẹ́gbẹ́ tàbí ká jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Torí náà, kò tọ́ kí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fẹ́ ẹni tí kò ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tí kì í ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí kì í sì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká pa ìwà títọ́ Kristẹni wa mọ́ ju ká gbayì lọ́dọ̀ àwọn tí kì í pa òfin Jèhófà mọ́. Àwọn tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ ká yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jìyà àbájáde búburú torí pé wọ́n kó ẹgbẹ́ búburú. (Ẹ́kís. 23:24, 25; Sm. 106:35-39) Torí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, Jésù sọ fún wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mát. 23:38) Jèhófà fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fi sórí ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀.—Ìṣe 2:1-4. w15 8/15 4:7, 8
Wednesday, June 21
Ète àṣẹ pàtàkì yìí ni ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere.—1 Tím. 1:5.
Jèhófà Ọlọ́run fún wa ní òmìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́. Ó fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ àtàwọn ọmọ wọn ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn tó dà bí ọlọ́pàá inú tó máa jẹ́ kí wọ́n fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Tá a bá lo ẹ̀rí ọkàn wa bó ṣe yẹ, á jẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́ ká sì máa sá fún ìwà àìtọ́. Ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wa yìí jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa ṣe ohun tó tọ́. Àwa èèyàn ṣì ní ẹ̀rí ọkàn. (Róòmù 2:14, 15.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn kan ṣì ń ṣe ohun tó dára, wọ́n sì kórìíra ohun tó burú. Ẹ̀rí ọkàn ni kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn hùwà tó burú. Ẹ wo bí nǹkan ì bá ṣe burú tó nínú ayé ká ní kò sẹ́ni tó ní ẹ̀rí ọkàn! Àfi ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn. w15 9/15 2:1, 2
Thursday, June 22
Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa!—1 Jòh. 3:1.
Ó yẹ ká mọrírì ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ nínú 1 Jòhánù 3:1, ká sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí. Nígbà tí Jòhánù sọ pé, “ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa,” ńṣe ló ń rọ àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n ronú lórí irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wọn àti bí ìfẹ́ náà ṣe pọ̀ tó. Ó sì tún fẹ́ kí wọ́n ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí wa, ìfẹ́ tá a ní fún un á pọ̀ sí i, àá sì tún ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn kan wà tí wọn ò gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn. Wọ́n gbà pé ẹni ẹ̀rù tó yẹ ká máa ṣègbọràn sí ni. Tàbí kí àwọn ẹ̀kọ́ èké kan tí wọ́n ti kọ́ mú kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa, a ò sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ àwọn míì gbà pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ò láàlà, wọ́n gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn láìka ohun tí àwọn bá ṣe sí. Nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yé ẹ pé ìfẹ́ ni ànímọ́ Jèhófà tó ta yọ jù lọ, ìfẹ́ tó ní sí wa ló sì sún un láti fi Ọmọ rẹ̀ rúbọ torí wa.—Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:8. w15 9/15 4:1, 2
Friday, June 23
Ìbáwí jẹ́ akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni.—Héb. 12:11.
Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn ò túmọ̀ sí pé ìbáwí ò ṣe pàtàkì tàbí pé kò wúlò torí ó tún sọ pé: “Síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní máa dágunlá tàbí ká máa bínú tó bá bá wa wí. Nínú ayé onímọtara-ẹni-nìkan táwọn èèyàn kì í ti í rí tẹlòmíì rò yìí, kò rọrùn láti gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tàbí láti bá wọn wí ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọ́n fara mọ́ ọn. Kódà agbára káká ni àwọn tó jọ pé wọ́n ń gba ìbáwí tàbí ìmọ̀ràn fi ń gbà á. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” Kàkà bẹ́ẹ ó yẹ ká máa fòye mọ ‘ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó pé.’ (Róòmù 12:2) Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa nímọ̀ràn tó bágbà mu nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwa, àwọn tó yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́ àti irú eré ìtura tó yẹ ká máa ṣe. Tá a bá ń fara mọ́ irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ tá a sì ń fi sílò, ìyẹn á fi hàn pé a moore a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn.—Jòh. 14:31; Róòmù 6:17. w15 9/15 5:13, 15
Saturday, June 24
Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!—Máàkù 9:24.
A ò lè ní ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ agbára àwa fúnra wa. Ó ṣe tán, ara èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni ìgbàgbọ́. (Gál. 5:22) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù, ká máa bẹ Jèhófà pé kó túbọ̀ máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. Jésù sì fi dá wa lójú pé Baba yóò “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Lẹ́yìn tí ìgbàgbọ́ wa bá ti fìdí múlẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kó máa pọ̀ sí i. Bí ìgbà téèyàn ń dáná igi ni ìgbàgbọ́ rí. Tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dáná ọ̀hún, ńṣe lá máa jó lala. Àmọ́, tá ò bá koná mọ́ ọn, ńṣe ni iná ọ̀hún á kú táá wá ku ẹ̀ṣẹ́ná nìkan, tó bá sì yá, ẹ̀ṣẹ́ná ọ̀hún á di eérú. Ṣùgbọ́n tó o bá ń figi sí i tó o sì ń koná mọ́ ọn, iná náà ò ní kú. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nípa ìgbàgbọ́ wa náà nìyẹn, tá ò bá fẹ́ kó dòkú, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ìfẹ́ tá a ní fún Bíbélì àti fún Jèhófà á máa pọ̀ sí i, ìyẹn láá sì wá mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i. w15 10/15 2:6, 7
Sunday, June 25
Èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ.—Sm. 77:12.
Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe fi hàn pé téèyàn bá ń ka ọ̀rọ̀ sókè nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́, ó máa rọrùn fún un láti rántí ohun tó kà. Ọlọ́run tó dá ọpọlọ wa náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ fún Jóṣúà pé kó máa fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” ka ìwé Òfin Ọlọ́run. (Jóṣ.1:8) Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti rí i pé tó o bá ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka Bíbélì, wàá lè pọkàn pọ̀ dáadáa, ohun tó ò ń kà á sì túbọ̀ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé kíkà lè má gba ìsapá rẹpẹtẹ, èèyàn gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ kó tó lè ṣàṣàrò. Ìdí nìyẹn tí ọpọlọ àwa ẹ̀dá aláìpé fi máa ń fẹ́ ṣe ohun tí kò gba ìsapá púpọ̀. Torí náà, ìgbà tí ara wa bá silé, tá a wà níbi tí kò sí ariwo, tí ọkàn wa sì pa pọ̀ ló dáa jù ká ṣe àṣàrò. Onísáàmù náà rí i pé ìgbà tóun bá jí lóru ló wu òun jù lọ láti máa ṣàṣàrò. (Sm. 63:6) Kódà, Jésù tó ní ọpọlọ pípé mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa wá ibi tó parọ́rọ́ láti ṣàṣàrò àti láti gbàdúrà.—Lúùkù 6:12. w15 10/15 4:4, 6, 7
Monday, June 26
Òun tìkára rẹ̀ mọ ohun tí ó wà nínú ènìyàn.—Jòh. 2:25.
Lọ́jọ́ kan, àwọn kan lára àwọn tó gbọ́rọ̀ Jésù ní Gálílì ń tẹ̀ lé e kiri ṣáá. (Jòh. 6:22-24) Àmọ́ torí pé Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, ó fòye mọ̀ pé torí oúnjẹ ni wọ́n ṣe ń wá òun kì í ṣe torí kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ òun. Jésù rí i pé wọ́n ní èrò tí kò tọ́, ó wá fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà, ó sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe. (Jòh. 6:25-27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o kì í ṣe arínú-róde, o lè fòye mọ̀ bóyá ọmọ rẹ fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù tàbí kò fẹ́ràn rẹ̀. Àwọn òbí kan máa ń wáyè fún ìsinmi ráńpẹ́ kí wọ́n sì fi nǹkan díẹ̀ panu nígbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí. Síbẹ̀, o lè wò ré kọjá ohun tó hàn sójú táyé kó o sì bi ara rẹ pé, ‘Ṣé iṣẹ́ ìwàásù gan-an ni ọmọ mi fẹ́ràn ni àbí àkókò tá a fi ń wá nǹkan panu?’ Tó o bá róye pé àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe kí ọmọ rẹ lè túbọ̀ fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù kó sì máa jàǹfààní nínú rẹ̀, wá bó o ṣe lè ràn án lọ́wọ́. Ronú oríṣiríṣi ọ̀nà tó o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì jọ máa ṣiṣẹ́ déédéé lóde ẹ̀rí. w15 11/15 1:10, 11
Tuesday, June 27
Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.—Ìṣí. 21:4.
Ó dájú pé èyí máa ṣẹ torí pé ohun tó máa ṣe àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ láǹfààní ni Ọlọ́run máa ń ṣe. Bíbélì sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Ẹ ò rí i pé ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu ló ń dúró de gbogbo àwa tá a bá mọrírì ìfẹ́ tí Jèhófà ní, tá a sì ń ṣègbọràn sí i torí pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso wa! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán, Nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà. Ṣùgbọ́n ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀.” (Sm. 37:37, 38) Àwọn “aláìlẹ́bi” làwọn tó mọ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 17:3) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 2:17 tó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Bí ayé yìí ṣe ń lọ sópin, ó ṣe pàtàkì ká “ní ìrètí nínú Jèhófà, [ká] sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.”—Sm. 37:34. w15 11/15 3:11, 12
Wednesday, June 28
Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.—Mát. 9:37.
Ọba náà tún ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónírúurú ọ̀nà. Ìyẹn sì ṣe pàtàkì torí pé “díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́” tó ń wàásù ìhìn rere náà nígbà yẹn. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, a lo àwọn ìwé ìròyìn káwọn èèyàn tó pọ̀ sí i lè gbọ́ ìwàásù wa, tó fi mọ́ àwọn tó wà níbi táwọn Ẹlẹ́rìí ò tí tó nǹkan. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, Arákùnrin Charles Taze Russell máa ń fi wáyà tẹ àsọyé Bíbélì ránṣẹ́ sí àwọn aṣojú iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn. Àwọn aṣojú iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn náà á wá fi wáyà tẹ àsọyé náà ránṣẹ́ sáwọn iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn míì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Kánádà àti ilẹ̀ Yúróòpù. Nígbà tó fi máa di ọdún 1913, mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000,000] làwọn tó ń rí àsọyé Arákùnrin Russell kà nínú àwọn ìwé ìròyìn tó tó ẹgbẹ̀rún méjì [2,000]! Lẹ́yìn ikú Arákùnrin Russell, a bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà míì tá a rí pé ó wúlò gan-an láti wàásù ìhìn rere. Ní April 16, ọdún 1922, Arákùnrin Joseph F. Rutherford sọ ọ̀kan lára àwọn àsọyé rẹ̀ àkọ́kọ́ lórí rédíò, àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ sì tó ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000]. Àmọ́ nígbà tó di February 24, ọdún 1924, ètò Ọlọ́run dá ilé iṣẹ́ rédíò rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn WBBR sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti wàásù. w15 11/15 5:10, 11
Thursday, June 29
Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.—Ẹ́kís. 3:14.
Jèhófà tún lè sọ àwọn ohun tó dá di ohunkóhun tó bá fẹ́. Ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ yìí sì máa ń rò ó. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mú kí Nóà di ẹni tó ń kan ọkọ̀ áàkì, ó mú kí Bẹ́sálẹ́lì di ọ̀gá àwọn oníṣẹ́-ọnà, ó sọ Gídíónì di ajagunṣẹ́gun, ó sì mú kí Pọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ṣe kedere pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun ò sì jẹ́ kóyán irú orúkọ pàtàkì bẹ́ẹ̀ kéré láé débi táá fi yọ ọ́ kúrò nínú Bíbélì. Gbogbo Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà lédè tó lé ní àádóje [130], ló lo orúkọ Ọlọ́run ní gbogbo ibi tó ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́. (Mál. 3:16) Àmọ́ ohun tí àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì ń ṣe báyìí yàtọ̀ síyẹn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí orúkọ òrìṣà wọn rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì kí gbogbo èèyàn lè rí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kà ní èdè wọn. w15 12/15 2:7-9
Friday, June 30
Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”—Aísá. 33:24.
Ó dájú pé Ọlọ́run lágbára láti woni sàn, ó sì tún lágbára láti fi àìsàn ṣeni. Bíbélì pàápàá jẹ́rìí sí èyí. Nígbà míì Ọlọ́run lè mú kí àìsàn kọlu ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mú kí àìsàn kọlu Fáráò ìgbà ayé Ábúráhámù àti Míríámù ẹ̀gbọ́n Mósè. (Jẹ́n. 12:17; Núm. 12:9, 10; 2 Sám. 24:15) Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọn ò bá pa àṣẹ òun mọ́, òun á fi ‘àìsàn àti ìyọnu àjàkálẹ̀’ hàn wọ́n léèmọ̀. (Diu. 28:58-61) Bákan náà, Jèhófà lè mú kí àrùn kásẹ̀ nílẹ̀ tàbí kó dáàbò bo èèyàn kúrò lọ́wọ́ àìsàn. (Ẹ́kís. 23:25; Diu. 7:15) Jèhófà tún lè woni sàn. Nígbà tí Jóòbù ṣàìsàn títí débi pé ó bẹ̀bẹ̀ pé kí òun kú, Ọlọ́run wò ó sàn! (Jóòbù 2:7; 3:11-13; 42:10, 16) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run lágbára láti wo aláìsàn kan sàn. Jésù náà lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù wo àwọn alárùn wárápá àtàwọn alárùn ẹ̀gbà sàn, ó sì tún wo àwọn afọ́jú àtàwọn arọ sàn lọ́nà ìyanu. (Mát. 4:23, 24; Jòh. 9:1-7) Ó dájú pé ó máa tù wá nínú gan-an láti mọ̀ pé ìtọ́wò lásán ni àwọn ìwòsàn tí Jésù ṣe yìí wulẹ̀ jẹ́ tá a bá fi wé èyí tó máa ṣe kárí ayé nínú ayé tuntun. w15 12/15 4:3, 4