July
Saturday, July 1
Ẹ má gbàgbé aájò àlejò.—Héb. 13:2.
Kí là ń pè ní “aájò àlejò”? Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “ṣíṣe inúure sí àwọn tá ò mọ̀ rí.” Gbólóhùn yìí lè mú ká rántí Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì. Àwọn méjèèjì yìí ṣe inúure sí àwọn àlejò tí wọn ò mọ̀ rí. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ni Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì wá mọ̀ pé áńgẹ́lì làwọn ṣe lálejò. (Jẹ́n. 18:2-5; 19:1-3) Báwo làwa náà ṣe lè fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sáwọn èèyàn? A lè pe àwọn ará kan wá sílé wa ká jọ jẹun tàbí ká fún ara wa níṣìírí. Bá ò tiẹ̀ mọ alábòójútó àyíká wa àti ìyàwó rẹ̀ dáadáa, a lè pè wọ́n wá sílé wa tí wọ́n bá bẹ ìjọ wa wò. (3 Jòh. 5-8) Kò pọn dandan ká filé pọntí fọ̀nà rokà tàbí ká náwó rẹpẹtẹ tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ará wa lálejò. A fẹ́ fún àwọn ará wa níṣìírí ni kì í ṣe pé a fẹ́ fi àwọn ohun ìní wa ṣe fọ́rífọ́rí. Kò sì yẹ kó jẹ́ pé àwọn tó lè san oore tá a ṣe wọ́n pa dà nìkan la máa pè wá sílé wa. (Lúùkù 10:42; 14:12-14) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ wa dí débi tá ó fi gbàgbé aájò àlejò. w16.01 1:11, 12
Sunday, July 2
A fi èdìdì dì yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí, èyí tí ó jẹ́ àmì ìdánilójú ṣáájú ogún wa.—Éfé. 1:13, 14.
Ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà ń lò láti mú kó ṣe kedere sí àwọn Kristẹni yìí pé òun ti yàn wọ́n láti lọ sọ́run. Lọ́nà yìí, ẹ̀mí mímọ́ ni “àmì ìdánilójú ṣáájú” tàbí ẹ̀rí tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé, lọ́jọ́ iwájú, ọ̀run ni wọ́n á máa gbé títí láé, kì í ṣe orí ilẹ̀ ayé. (2 Kọ́r. 1:21, 22; 5:5) Ìyẹn wulẹ̀ mú kó dá ẹni náà lójú pé Jèhófà ti pè é láti wá bá Jésù jọba lọ́run. Àmọ́, tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀ nìkan ló máa gba èrè yìí. Pétérù ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà yìí, ó ní: “Fún ìdí yìí, ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ máa sa gbogbo ipá yín láti mú pípè àti yíyàn yín dájú fún ara yín; nítorí bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ kì yóò kùnà lọ́nàkọnà láé. Ní ti tòótọ́, nípa báyìí ni a ó pèsè ìwọlé fún yín lọ́pọ̀ jaburata sínú ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pét. 1:10, 11) Torí náà, ẹni àmì òróró kankan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun ṣí òun lọ́wọ́ sísin Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pè é tàbí yàn án láti lọ sọ́run, tí kò bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, kò ní gba èrè kankan.—Héb. 3:1; Ìṣí. 2:10. w16.01 3:6, 7
Monday, July 3
Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.—Mát. 23:12.
Kò dáa ká máa fún ẹnì kan láfiyèsí kọjá bó ṣe yẹ, kódà bí ẹni náà tìẹ jẹ́ arákùnrin Kristi. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn alàgbà, ó gbà wá níyànjú pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn, àmọ́ kò sọ pé ká sọ èèyàn èyíkéyìí di aṣáájú wa. (Héb. 13:7) Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé àwọn kan “yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì.” Àmọ́ èyí jẹ́ nítorí pé wọ́n “ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” wọ́n sì “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” kì í ṣe torí pé wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (1 Tím. 5:17) A máa dójú ti àwọn ẹni àmì òróró tá a bá ń fún wọn láfiyèsí tàbí tá a bá ń yìn wọ́n kọjá bó ṣe yẹ. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé a lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. (Róòmù 12:3) Ó sì dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa táá fẹ́ ṣe ohun tó lè mú kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin Kristi ṣe irú àṣìṣe ńlá bẹ́ẹ̀.—Lúùkù 17:2. w16.01 4:9
Tuesday, July 4
Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà.—Òwe 17:17.
Bí ìṣura iyebíye ni àjọṣe tímọ́tímọ́ rí. Kò dà bí àwo òdòdó olówó iyebíye tí wọ́n kàn fi ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ lásán. Ṣe ló dà bí òdòdó rírẹwà téèyàn á máa bomi rin táá sì máa tọ́jú kó lè dàgbà kó sì máa rẹwà sí i. Ábúráhámù mọyì àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà kò sì jẹ́ kó bà jẹ́. Báwo ló ṣe ṣe é? Ábúráhámù túbọ̀ ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run ó sì ń mú kí ìbẹ̀rù tó ní fún un lágbára sí i. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹrú rẹ̀ rìnrìn-àjò lọ sí ìlú Kénáánì, ó ń jẹ́ kí Jèhófà darí gbogbo ìpinnu tó ń ṣe. Nígbà tí Ábúráhámù wà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99], ìyẹn ọdún kan ṣáájú kó tó bí Ísákì, Jèhófà sọ fún un pé kó dádọ̀dọ́ gbogbo ọkùnrin tó wà nínú agbo ilé rẹ̀. Ṣé Ábúráhámù ṣiyè méjì nípa ohun tí Jèhófà sọ fún un àbí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwáwí kó má bàa ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe? Rárá o, ńṣe ló gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ‘ọjọ́ yẹn gan-an’ ló sì ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe.—Jẹ́n. 17:10-14, 23. w16.02 1:9, 10
Wednesday, July 5
Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.—Òwe 20:11.
Àwọn ọmọdé pàápàá lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe ohun tó tọ́ kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá wọn. Ó ti wá ṣe kedere pé bí ọ̀dọ́ kan bá ti gbọ́njú tó sì ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó ṣèrìbọmi. (Òwe 20:7) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn dàgbà dénú? Ohun kan ni pé béèyàn ṣe tó tàbí ọjọ́ orí ẹni kọ́ la fi ń màgbà. Kódà, Bíbélì sọ pé àwọn tó dàgbà dénú ti kọ́ “agbára ìwòye” wọn kí wọ́n lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Héb. 5:14) Torí náà, ẹni tó dàgbà dénú ni ẹni tó gbọ́n tó láti ṣèpinnu, tó mọ ohun tó tọ́, tó sì ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé ohun tó tọ́ lòun á máa ṣe. Kì í ṣẹni téèyàn lè tì ṣe ohun tí kò tọ́, kò sì dìgbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún un kó tó ṣe ohun tó tọ́. Ó yẹ kí ọkàn èèyàn balẹ̀ pé ohun tó tọ́ ni ọ̀dọ́ kan tó ti ṣèrìbọmi máa ṣe kódà tí àwọn òbí ẹ̀ tàbí àwọn àgbàlagbà mí ì ò bá tiẹ̀ sí níbẹ̀.—Fílí. 2:12. w16.03 1:4, 5
Thursday, July 6
Má fòyà . . . , ìwọ ni yóò sì jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ.—1 Sám. 23:17.
Ó dájú pé ìgboyà tí Dáfídì ní máa ya Jónátánì lẹ́nu gan-an. Dáfídì ti pa Gòláyátì òmìrán, ó sì gbé “orí Filísínì náà” lọ fún bàbá Jónátánì, ìyẹn Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì. (1 Sám. 17:57) Ó dá Jónátánì lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn Dáfídì, àtìgbà yẹn sì ni Dáfídì àti Jónátánì ti di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Wọ́n ṣèlérí fúnra wọn pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara àwọn. (1 Sám. 18:1-3) Látìgbà náà lọ ni Dáfídì ti dúró gbágbáágbá ti Jónátánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ni Jèhófà yàn dípò Jónátánì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù, síbẹ̀ Jónátánì ò dalẹ̀ Dáfídì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù sì fẹ́ pa Dáfídì, ọkàn Jónátánì ò balẹ̀ torí pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Dáfídì. Jónátánì mọ̀ pé Dáfídì wà ní aginjù kan ní Hóréṣì, torí náà ó lọ síbẹ̀ láti fún un níṣìírí pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní ló sì sọ fún un.—1 Sám. 23:16. w16.02 3:1, 2
Friday, July 7
Mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Jèhófà] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́.—Òwe 8:30.
Látìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ni Jèhófà àti Jésù ti wà níṣọ̀kan. Kí Jèhófà tó dá gbogbo ohun mìíràn ló ti dá Jésù, Jésù sì bá Jèhófà baba rẹ̀ ṣiṣẹ́. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà náà máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà bá ní kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Nóà àti ìdílé ẹ̀ pawọ́ pọ̀ kan ọkọ̀ áàkì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà pawọ́ pọ̀ kọ́ àgọ́ ìjọsìn, wọ́n jọ máa ń tú u palẹ̀, wọ́n á sì tún jọ gbé e láti ibì kan sí ibòmíràn. Nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n máa ń jùmọ̀ lo àwọn ohun èlò ìkọrin, wọ́n sì máa ń pa ohùn pọ̀ kọrin aládùn sí Jèhófà. Torí pé àwọn èèyàn Jèhófà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ló jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan yìí láṣeyọrí. (Jẹ́n. 6:14-16, 22; Núm. 4:4-32; 1 Kíró. 25:1-8) Àwọn Kristẹni tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní, iṣẹ́ wọn ò sì dọ́gba, gbogbo wọn ṣera wọn lọ́kan. Àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wọn ni gbogbo wọn ń tẹ̀ lé. Pọ́ọ̀lù fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn wé bí àwọn ẹ̀yà ara ṣe máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀.—1 Kọ́r. 12:4-6, 12. w16.03 3:1, 2
Saturday, July 8
Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19.
Nígbà kan, káwọn èèyàn tó lè jọ́sìn Jèhófà àfi kí wọ́n wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (1 Ọba 8:41-43) Àmọ́, nígbà tó yá, Jésù pa àṣẹ tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó ní kí wọ́n “lọ” sọ́dọ̀ gbogbo èèyàn. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Jèhófà mú kó ṣe kedere pé òun fẹ́ kí wọ́n wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé. Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sórí nǹkan bí ọgọ́fà [120] lára àwọn tó di ìjọ tuntun náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú èdè wàásù fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe. (Ìṣe 2:4-11) Lẹ́yìn ìyẹn, ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Samáríà. Nígbà tó sì di ọdún 36, ó gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́. Èyí wá fi hàn pé àwọn Kristẹni ní láti lọ wàásù fún gbogbo èèyàn kárí ayé! w16.03 4:12
Sunday, July 9
Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi . . . , ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́.—2 Tím. 2:2.
Tipẹ́tipẹ́ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti mọ̀ pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú kéèyàn ṣàṣeyọrí. Nígbà tí Ábúrámù, baba ńlá ìgbàanì fẹ́ lọ dá Lọ́ọ̀tì nídè, ó “pe àwọn ọkùnrin tí ó ti kọ́ jọ,” wọ́n sì ṣàṣeyọrí. (Jẹ́n. 14:14-16) Nígbà tí Dáfídì Ọba wà láyé, àwọn “tí a kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà” ló ń kọrin ní ilé Ọlọ́run, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo. (1 Kíró. 25:7) Lónìí, à ń bá Sátánì àtàwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn jagun tẹ̀mí. (Éfé. 6:11-13) Bákan náà, à ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè fi ìyìn fún Jèhófà. (Héb. 13:15, 16) Nítorí náà, bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì ká bàa lè ṣàṣeyọrí. Nínú ìjọ, àwọn alàgbà ni Jèhófà gbé iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ẹlòmí ì lé lọ́wọ́. Kí alàgbà kan tó dá arákùnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́kọ̀ọ́, o lè rí i pé ó máa dáa tóun bá kọ́kọ́ ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn kó sì túbọ̀ fi ẹ̀kọ́ náà sílò.—1 Tím. 4:6. w15 4/15 2:1, 2
Monday, July 10
[Jésù máa] sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, èyíinì ni, Èṣù.—Héb. 2:14.
Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo èèyàn ni Èṣù máa ń pa ní tààràtà o. Àmọ́, ìwà gbẹ̀mígbẹ̀mí rẹ̀ kúnnú ayé yìí. Síwájú sí i, torí pé Éfà gba irọ́ Sátánì gbọ́, tí Ádámù sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú di ohun tó ran gbogbo aráyé. (Róòmù 5:12) Lọ́nà yìí ni Èṣù gbà ní “ọ̀nà àtimú ikú wá.” Ohun tí Jésù pè é náà ló jẹ́, “apànìyàn.” (Jòh. 8:44) Ẹ ò rí i pé ọ̀tá tó lágbára gan-an ni Sátánì! Tá a bá kọjú ìjà sí Sátánì, kì í ṣe òun nìkan la kọjú ìjà sí, a tún kọjú ìjà sí gbogbo àwọn tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti ta ko jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Lára àwọn tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ni àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù, wọ́n sì pọ̀ díẹ̀. (Ìṣí. 12:3, 4) Léraléra làwọn ẹ̀mí èṣù yìí máa ń dán agbára ńlá tí wọ́n ní wò, wọ́n máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn èèyàn tí wọ́n dá lóró. (Mát. 8:28-32; Máàkù 5:1-5) Torí náà, má ṣe fojú kéré agbára táwọn áńgẹ́lì burúkú yìí ní tàbí tí “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù” ní. (Mát. 9:34) Láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a ò ní lè borí Sátánì nínú ìjà náà. w15 5/15 1:6, 7
Tuesday, July 11
Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 6:9, 10.
Tó o bá dojú kọ ìdẹwò tó lè mú ẹ ṣèṣekúṣe, kí lo lè ṣe? Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ. (Róòmù 7:22, 23) Bẹ Ọlọ́run pé kó fún ẹ lókun. (Fílí. 4:6, 7, 13) Máa sá fún àwọn nǹkan tàbí ipò tó lè mú ẹ ṣèṣekúṣe. (Òwe 22:3) Tó o bá sì dojú kọ ìdẹwò, tètè sá fún un. (Jẹ́n. 39:12) Àpẹẹrẹ rere ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká borí ìdẹwò. Kò jẹ́ kí àwọn ìlérí tí Sátánì ṣe tan òun jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò fàyè sílẹ̀ láti ro ọ̀rọ̀ náà síwá sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló dá a lóhùn pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Mát. 4:4-10) Jésù mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú, ìyẹn mú kó tètè gbé ìgbésẹ̀ tó sì fa ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yọ nígbà tí ìdẹwò dé. Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohun tó lè mú wa ṣèṣekúṣe. w15 5/15 2:15, 16
Wednesday, July 12
Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run.—Éfé. 5:1.
A lè lo ọgbọ́n bíi ti Jèhófà tá a bá ń fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ sí wa rí, ó sì máa jẹ́ ká lè fòye mọ ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde àwọn ìwà wa. Jèhófà lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa jẹ́ àbájáde àwọn ìwà tàbí ìṣe kan, ìyẹn tó bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn ò rí ju igimú wa lọ, ó dáa ká máa ro ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde ohun tá a fẹ́ ṣe. Ká lè fi hàn pé à ń lo ọgbọ́n bíi ti Ọlọ́run, ó máa dáa tá a bá ń ronú lórí ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde ìwà wa tàbí ká fọkàn yàwòrán rẹ̀ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní àfẹ́sọ́nà, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé òòfà ìbálòpọ̀ lágbára. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣèpinnu èyíkéyìí tó máa fi àjọṣe iyebíye tó wà láàárín àwa àti Jèhófà sínú ewu tàbí ká ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe náà jẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, ó ní: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3. w15 5/15 4:10, 11
Thursday, July 13
Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.—Mát. 5:28.
Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba. Bíbélì sọ pé: “Láti orí òrùlé náà ni [Dáfídì] sì ti tajú kán rí obìnrin kan tí ń wẹ.” (2 Sám. 11:2) Kò tètè gbójú kúrò níbẹ̀ kó sì máa ro nǹkan mí ì. Èyí mú kí ọkàn rẹ̀ máa fà sí ìyàwó oníyàwó, ó sì bá a ṣe panṣágà. Tá a bá fẹ́ borí fífọkàn yàwòrán ìṣekúṣe, a ní láti ‘bá ojú wa dá májẹ̀mú’ bíi ti Jóòbù tó jẹ́ adúróṣinṣin. (Jóòbù 31:1, 7, 9) A gbọ́dọ̀ pinnu tọkàntọkàn láti máa darí ojú wa, ká má sì máa ní èrò ìṣekúṣe lọ́kàn tá a bá ń wo àwọn èèyàn. Ó túmọ̀ sí pé ká gbé ojú wa kúrò nínú àwòrán èyíkéyìí tó lè mú ọkàn wa fà sí ìṣekúṣe bóyá lórí kọ̀ǹpútà ni o, nínú pátákó ìpolówó, èèpo ẹ̀yìn ìwé tàbí níbikíbi yòówù kó jẹ́. Torí náà, tó o bá fẹ́ borí èrò ìṣekúṣe tó máa ń wá síni lọ́kàn, ṣe ni kó o gbé ìgbésẹ̀ ní kíá. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pátápátá, èyí á ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀, wàá sì jẹ́ oníwà mímọ́.—Ják. 1:21-25. w15 6/15 3:12-14
Friday, July 14
Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.—Mát. 6:13.
Tá a bá ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù kété tó ṣèrìbọmi tán, a óò lóye ìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà pé: “Má . . . mú wa wá sínú ìdẹwò.” Ẹ̀mí Ọlọ́run ṣamọ̀nà Jésù lọ sínú aginjù. Kí nìdí? “Kí Èṣù lè dẹ ẹ́ wò.” (Mát. 4:1) Ǹjẹ́ ó yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu? Kò ní yà wá lẹ́nu tá a bá lóye ìdí tí Ọlọ́run fi rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé. Ìdí rẹ̀ ni pé kó wá yanjú ọ̀ràn tó jẹ yọ nígbà tí Ádámù àti Éfà kọ Ọlọ́run ní Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn ìbéèrè kan yọjú tó máa gba àkókò kó tó lè níyanjú. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àṣìṣe kankan wà nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá èèyàn ni? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dá èèyàn pípé fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, kódà bí “ẹni burúkú náà” tiẹ̀ ń fínná mọ́ ọn? Àti pé, gẹ́gẹ́ bí Sátánì ṣe sọ, ṣé nǹkan máa sàn fáwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n ò bá sí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:4, 5) Ó máa gba àkókò ká tó lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, àmọ́ ìdáhùn wọn máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì mọ̀ pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ. w15 6/15 5:12
Saturday, July 15
Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà.—Mát. 24:21.
Báwo ni ìpọ́njú ńlá ṣe máa bẹ̀rẹ̀? Ìwé Ìṣípayá dáhùn ìbéèrè yìí fún wa nípa ṣíṣe àpèjúwe ìparun “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 17:5-7) Ẹ sì wo bó ṣe bá a mu wẹ́kú pé a fi gbogbo ìsìn èké wé aṣẹ́wó! Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti bá àwọn aṣáájú inú ayé burúkú yìí ṣe ìṣekúṣe. Dípò kí wọ́n máa kọ́wọ́ ti Jésù àti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn, àwọn alákòóso ayé ni wọ́n ń gbárùkù tì. Kí wọ́n lè rọ́wọ́ mú ní agbo òṣèlú, wọn ò fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ọlọ́run tó yẹ kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ lé. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ́, tí wọ́n sì tún jẹ́ wúńdíá. (2 Kọ́r. 11:2; Ják. 1:27; Ìṣí. 14:4) Àmọ́ ta ló máa pa ètò tó dà bí aṣẹ́wó náà run? Jèhófà Ọlọ́run máa fi “ìrònú” rẹ̀ sínú ọkàn “ìwo mẹ́wàá” ti “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà. Àwọn ìwo náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo agbára òṣèlú tó ń ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lẹ́yìn. “Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà sì ṣàpẹẹrẹ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè.—Ìṣí. 17:3, 16-18. w15 7/15 2: 3, 4
Sunday, July 16
Olúkúlùkù yín ń wí pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” “Ṣùgbọ́n èmi ti Àpólò,” “Ṣùgbọ́n èmi ti Kéfà,” “Ṣùgbọ́n èmi ti Kristi.”—1 Kọ́r. 1:12.
Kí ni ojútùú sí irú ọ̀rọ̀ tó lè fa ìpínyà yìí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, . . . pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́r. 1:10, 11, 13) Lóde òní ńkọ́? Kò yẹ kí ìyapa èyíkéyìí wà nínú ìjọ Kristẹni. (Róòmù 16:17, 18) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀tọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aráàlú ní ọ̀run dípò àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Fílí. 3:17-20) Wọ́n ní láti máa ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi. Àwọn tó jẹ́ ikọ̀ kì í dá sí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wọn lọ. Ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tiwọn ló máa ń jẹ wọ́n lógún. (2 Kọ́r. 5:20) Ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run náà ni àwọn Kristẹni tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, torí náà kò bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n máa dá sí awuyewuye inú ayé. w15 7/15 3:9, 10
Monday, July 17
Ó jẹ́ aláàánú; òun a sì bo ìṣìnà náà, kì yóò sì mú ìparun wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì mú kí ìbínú rẹ̀ yí padà, kì í sì í ru gbogbo ìhónú rẹ̀ dìde.—Sm. 78:38.
Tó o bá ń ronú lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, wàá rí i pé Jèhófà fẹ́ràn ìwọ alára, ó sì bìkítà nípa rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà kà ẹ́ kún. (1 Pét. 5:6, 7) Ó yẹ ká fi ọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì torí pé òun ni ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run ń gbà bá wa sọ̀rọ̀. Kí àwọn òbí àti àwọn ọmọ lè fọkàn tán ara wọn kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa bára wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó nítumọ̀ tó sì fi ìgbatẹnirò hàn. Kí la retí pé kí Jèhófà náà ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò rí Ọlọ́run rí tàbí ká gbọ́rọ̀ rẹ̀ ní tààràtà, ó ń bá wa “sọ̀rọ̀” nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, a sì gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí i. (Aísá. 30:20, 21) Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ó wù ú kó máa tọ́ wa sọ́nà kó sì máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu. Ó tún fẹ́ ká mọ òun ká sì gbẹ́kẹ̀ lé òun.—Sm. 19:7-11; Òwe. 1:33. w15 8/15 1:6, 7
Tuesday, July 18
Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.—Ják. 4:8.
Bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún Párádísè ọjọ́ iwájú, ohun tó máa mú ká láyọ̀ jù lọ nínú ayé tuntun ni àwọn ìbùkún tẹ̀mí. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti mọ̀ nípa ìyàsímímọ́ orúkọ Jèhófà àti ìdáláre ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ! (Mát. 6:9, 10) Inú wa máa dùn gan-an láti rí i pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé àti ilẹ̀ ayé ti ní ìmúṣẹ. Ẹ sì wo bó ṣe máa rọ̀ wá lọ́rùn tó láti sún mọ́ Jèhófà bá a ṣe ń sún mọ́ ìjẹ́pípé, àti nígbà tá a bá di ẹni pípé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn! (Sm. 73:28) Àwa náà lè rí ìbùkún yìí gbà, torí Jésù mú kó dá wa lójú pé “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mát. 19:25, 26) Ṣùgbọ́n tá a bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun yẹn, ká sì tún wà láàyè lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, a gbọ́dọ̀ sapá nísinsìnyí láti “di” ìyè àìnípẹ̀kun “mú gírígírí.” (1 Tím. 6:19) Bá a ṣe ń gbé nínú ayé búburú yìí, a gbọ́dọ̀ máa fojú sọ́nà fún òpin rẹ̀ ká sì ṣe ohun tó yẹ nísinsìnyí láti múra sílẹ̀ de gbígbé nínú ayé tuntun. w15 8/15 3:2, 3
Wednesday, July 19
Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.—Jòh. 17:3.
Ọ̀pọ̀ ohun táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ayé yìí ń gbé jáde lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde náà kì í mú kéèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀. Ńṣe ni wọ́n ń gbé ayé búburú Sátánì àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ lárugẹ. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi kó má lọ jẹ́ pé àwọn ohun táá mú kí “àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé” ru sókè lọ́kàn wa la máa yàn. (Títù 2:12) Ohun tí ètò Jèhófà ń pèsè fún wa yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tí ayé yìí ń gbé jáde. Ohun tó máa jẹ́ ká jogún ìyè ayérayé ni ètò Ọlọ́run ń kọ́ wa ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Àfi ká máa dúpẹ́ pé a ní àwọn ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ńlá, àwọn fídíò àti ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ! Ètò Ọlọ́run tún ṣètò àwọn ìpàdé tá à ń ṣe déédéé ní àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000] kárí ayé. Ní àwọn ìpàdé, àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè, a máa ń jíròrò àwọn ìsọfúnni látinú Bíbélì, èyí tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀.—Héb. 10:24, 25. w15 8/15 4:9, 11
Thursday, July 20
Ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí.—Róòmù 2:15.
Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sí gbogbo èèyàn torí pé wọ́n máa ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wọn máa gún wọn ní kẹ́ṣẹ́ kí wọ́n lè máa fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ, á mú ká máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ìjọ. Àmọ́, ṣíṣe ohun tó wà nínú Bíbélì nìkan kọ́ ni ohun tó túmọ̀ sí láti kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa lò ó. Bíbélì fi hàn pé ká tó lè ní ẹ̀rí ọkàn rere, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ète àṣẹ pàtàkì yìí ni ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.” (1 Tím. 1:5) Bá a ṣe ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń ṣe ohun tó sọ fún wa, ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà á máa pọ̀ sí i, ìgbàgbọ́ wa á sì máa lágbára sí i. Kódà, ọ̀nà tá à ń gbà lo ẹ̀rí ọkàn wa tún ń fi irú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà hàn, ó ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá ọkàn wa ń fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, ó sì ń jẹ́ ká mọ bó ṣe wù wá tó láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ẹ̀rí ọkàn wa yìí ló ń sọ irú ẹni tá a jẹ́ ní ti gidi. w15 9/15 2:2, 3
Friday, July 21
Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ti fi fún wa!—1 Jòh. 3:1.
Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá gbogbo èèyàn. (Sm. 100:3-5) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ádámù ní “ọmọkùnrin Ọlọ́run,” tí Jésù náà sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ pé “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run” tí wọ́n bá ń gbàdúrà. (Lúùkù 3:38; Mát. 6:9) Torí pé Jèhófà ló dá wa, òun ni Baba wa, àjọṣe baba sí ọmọ la sì ní pẹ̀lú rẹ̀. Látàrí èyí, bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. Aláìpé ni àwọn bàbá tó bí wa. Bó ti wù kí wọ́n gbìyànjú tó, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ wa bíi ti Jèhófà. Kódà, àwọn kan ti ní ọgbẹ́ ọkàn torí ìwà òǹrorò tí wọ́n hù sí wọn nínú ìdílé tí wọ́n gbé dàgbà. Ìyẹn máa ń fa ìrora ó sì máa ń kó ìbànújẹ́ báni. Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà kì í ṣe irú bàbá bẹ́ẹ̀. (Sm. 27:10) Tá a bá mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ó sì ń tọ́jú wa, ó dájú pé ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Ják. 4:8. w15 9/15 4:3, 4
Saturday, July 22
Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.—Fílí. 2:13.
Tá a bá ń ṣèpinnu láì kọ́kọ́ ronú lórí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, èyí á fi hàn pé a ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run a ò sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí Sámúẹ́lì wà láyé pé àwọn Filísínì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú ogun. Àwọn èèyàn Ọlọ́run nílò ìrànlọ́wọ́ àti ààbò gan-an. Kí ni wọ́n wá ṣe? Wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ṣílò wá sọ́dọ̀ ara wa, kí ó lè wá sí àárín wa, kí ó sì lè gbà wá là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Bíbélì sọ pé: ‘Ìpakúpa náà sì wá pọ̀ gidigidi, tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn fi ṣubú láti inú Ísírẹ́lì. Àpótí Ọlọ́run pàápàá ni a sì gbà.’ (1 Sám. 4:2-4, 10, 11) Ó lè dà bíi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ kí Jèhófà ran àwọn lọ́wọ́ ní wọ́n ṣe gbé Àpótí yẹn dání lọ sójú ogun. Àmọ́, wọn ò wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, èrò ara wọn ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ibi tí ọ̀rọ̀ náà já sí ò sì dáa.—Òwe 14:12. w15 9/15 5:16, 17
Sunday, July 23
Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.—Lúùkù 17:5.
Kí lo lè ṣe kí ìgbàgbọ́ rẹ lè máa lágbára sí i, kó má sì yingin? Rí i dájú pé ò ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ kódà lẹ́yìn tó o ti ṣèrìbọmi. (Héb. 6:1, 2) Bí àpẹẹrẹ, máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó ti nímùúṣẹ, ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára sí i, kó má sì yingin. O tún lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara rẹ wò bóyá ìgbàgbọ́ rẹ lágbára bíi tàwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. (Ják.1:25; 2:24, 26) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni lè máa fún ara wọn ní “ìṣírí . . . nípasẹ̀ ìgbàgbọ́” ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. (Róòmù 1:12) Bá a ṣe ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, àá máa gbé ìgbàgbọ́ ara wa ró lẹ́nì kìíní kejì, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé àwọn tá a ti ‘dán ìjójúlówó’ ìgbàgbọ́ wọn wò là ń bá kẹ́gbẹ́. (Ják. 1:3) Ẹgbẹ́ búburú máa ń ba ìgbàgbọ́ jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere máa ń gbé ìgbàgbọ́ ẹni ró. (1 Kọ́r. 15:33) Ìdí kan nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gbà wá níyànjú pé ká má máa kọ “ìpéjọpọ̀ ara wa” sílẹ̀.—Héb.10:24, 25. w15 10/15 2:2, 8, 9
Monday, July 24
Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá.—1 Tím. 4:15.
Ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ká ronú lórí ìbéèré tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn tàbí àpèjúwe tó máa mú kí ohun tá à ń kọ́ wọn tètè yé wọn, kí wọ́n sì lè fi sílò. Àkókò tá a fi ń ronú nípa àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń gbádùn mọ́ni gan-an torí pé ó máa mú kí ìgbàgbọ́ tiwa náà lágbára sí i, a ó sì lè máa fi ìtara darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́nà tó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Bó ṣe máa rí náà nìyẹn tá a bá ń múra ohun tá a máa sọ sílẹ̀ ká tó lọ sóde ẹ̀rí. (Ẹ́sírà 7:10) Tá a bá ka orí kan nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì ká tó lọ sóde ẹ̀rí, ó máa “rú” ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù “sókè bí iná.” Tá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a fẹ́ lò lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn, àá lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́nà tó múná dóko. (2 Tím. 1:6) Ẹ máa ronú nípa àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín àti ohun tó máa mú kí wọ́n fẹ́ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ yín. Tá a bá ń múra sílẹ̀ láwọn ọ̀nà tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, àá lè wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́ “pẹ̀lú ìfihàn ẹ̀mí àti agbára” látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 2:4. w15 10/15 4:9
Tuesday, July 25
Bí ojú ọ̀tún rẹ . . . bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde.—Mát. 5:29.
Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ọmọ mi mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe? Ǹjẹ́ ohun kan wà tó lè mú kó fẹ́ láti máa wò ó? Ṣé kì í ṣe pé mo ti le koko jù débi pé á ṣòro fáwọn ọmọ mi láti wá bá mi fún ìrànlọ́wọ́ nígbàkigbà tó bá ń ṣe wọ́n bíi kí wọ́n wo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?’ Kódà nígbà táwọn ọmọ rẹ bá ṣì kéré, o lè sọ fún wọn pé: “Jọ̀ọ́ wá sọ fún mi nígbàkigbà tó o bá já sí ìkànnì kan tó ní àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe tó sì ń ṣe ẹ́ bíi kó o wò ó. Má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́. Màá ràn ẹ́ lọ́wọ́.” Ó ṣe pàtàkì kí ìwọ òbí náà kíyè sára nípa irú eré ìnàjú tó o máa yàn. Bàbá kan tó ń jẹ́ Pranas sọ pé: “Àpẹẹrẹ táwa òbí bá fi lélẹ̀ nípa irú orin, fí ìmù tàbí ìwé tá a yàn láàyò làwọn ọmọ náà á máa tẹ̀ lé. O lè ti sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wọn nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtohun tí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe, àmọ́ ohun tí wọ́n bá rí tó ò ń ṣe làwọn náà á máa ṣe.” Táwọn ọmọ rẹ bá rí i pé eré ìnàjú tó dára nìwọ náà yàn láàyò, ohun táwọn náà á ṣe nìyẹn.—Róòmù 2:21-24. w15 11/15 1:12-14
Wednesday, July 26
Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀.—Sm. 32:8.
Ní báyìí, ètò Ọlọ́run túbọ̀ ń kọ́ wa pé ká máa wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí, irú bí àwọn ibùdókọ̀ yálà ti mọ́tò tàbí rélùwéè, àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, àwọn gbàgede ìlú àti ní ọjà. Bí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ láti wàásù láwọn ibi tá a mẹ́nu kàn yìí, o ò ṣe gbàdúrà nípa rẹ̀, kó o sì ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Angelo Manera, Jr., tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò sọ. Ó ní: “Bí ètò Ọlọ́run bá gbé ọ̀nà tuntun mí ì tá a lè gbà máa wàásù jáde, ńṣe la máa ń rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà mí ì tá a lè gbà sin Jèhófà, ọ̀nà mí ì tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin àti ọ̀nà mí ì tá a lè gbà pa ìwà títọ́ wa mọ́, a sì máa ń fẹ́ kí Jèhófà rí i pé a ṣe tán láti sìn ín lọ́nà èyíkéyìí tó bá fẹ́.” Tá a bá ń lo ọ̀nà tuntun tí ètò Ọlọ́run ní ká máa gbà wàásù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wa, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á sì túbọ̀ dán mọ́rán. (2 Kọ́r. 12:9, 10) Ọ̀pọ̀ akéde máa ń darí àwọn èèyàn lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org, ìkànnì yìí ń mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere lónìí, kódà láwọn ibi tó jìnnà réré pàápàá. w15 11/15 5:12, 13, 15
Thursday, July 27
Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.—Òwe 27:17.
Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì tá a kọ́kọ́ ṣe jáde, ọ̀rọ̀ Hébérù náà tá a tú sí “Ṣìọ́ọ̀lù” [tàbí, “Hédíìsì” lédè Gírí ìkì] la lò nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì bí Oníwàásù 9:10 bí àwọn Bíbélì mí ì tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe ṣe. Ẹsẹ Bíbélì yẹn wá kà pé: “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Èyí dá ìṣòro sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè mí ì. Lára àwọn ìṣòro náà sì ni pé: Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń sọ èdè wọn kò mọ ohun tó ń jẹ́ “Ṣìọ́ọ̀lù,” kò sí nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè wọn, ńṣe ló sì máa ń dà bí ìgbà téèyàn ń dárúkọ ibì kan létí wọn. Nítorí èyí, nínú Bíbélì tí wọ́n tún ṣe ní ọdún 2013, ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “Grave,” ìyẹn sàréè, kó lè yé àwọn èèyàn dáadáa. A tún fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó bóde mu rọ́pò èyí táwọn èèyàn ò lò mọ́, a sì sapá gan-an kí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè ṣe kedere kó sì rọrùn lóye láì yí ìtumọ̀ rẹ̀ pa dà. Ohun táwọn tó túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè wọn ti ṣe mú kí àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò nínú àtúnṣe ti èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí sunwọ̀n sí i. w15 12/15 2:10, 12
Friday, July 28
Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀; Ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè.—Sm. 41:1, 2.
Tá a bá ń ṣàìsàn, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó tù wá nínú, kó fún wa lọ́gbọ́n kó sì ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láyé àtijọ́. A mọ̀ pé, nígbà ayé Dáfídì kò sẹ́nì kankan tí kò kú torí pé ó ń ṣàánú àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Torí náà, nígbà tí Dáfídì ń sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yẹn, kò ní i lọ́kàn pé kí Jèhófà dá ẹni náà sí lọ́nà ìyanu, kó má bàa kú mọ́. Ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé Ọlọ́run máa ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ṣe é? Dáfídì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sm. 41:3) Ó yẹ kó dá ẹni tó bá ń ṣojú àánú sí ẹni rírẹlẹ̀ lójú pé Ọlọ́run rí gbogbo ìwà rere rẹ̀, kò sì ní gbàgbé láé. Ara rẹ̀ sì lè yá torí Ọlọ́run ti dá wa lọ́nà tí ara wa fi lè gbógun ti àìsàn. w15 12/15 4:7
Saturday, July 29
Ẹ máa fi àwọn tí ń bẹ lẹ́wọ̀n sọ́kàn.—Héb. 13:3.
Àwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ lẹ́tà yìí. Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni torí pé wọ́n fi ‘ìbánikẹ́dùn hàn fún àwọn tí ń bẹ lẹ́wọ̀n.’ (Héb. 10:34) Àwọn ará kan ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láàárín ọdún mẹ́rin tó lò lẹ́wọ̀n, àmọ́ ibi tó jìn làwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni yẹn ń gbé. Báwo ni wọ́n ṣe máa ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́? Wọ́n lè máa gbàdúrà fún un kíkankíkan. (Fílí. 1:12-14; Héb. 13:18, 19) Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló wà lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn ará tó wà nítòsí lè lọ bẹ̀ wọ́n wò tàbí kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan mí ì láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára wa ò gbé nítòsí àwọn ará wa tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́, tá ò sì ní gbàgbé wọn? Ìfẹ́ ará tá a ní á mú ká máa gbàdúrà kíkankíkan fún wọn. w16.01 1:13, 14
Sunday, July 30
Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀míwa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.—Róòmù 8:16.
Orí ilẹ̀ ayé yìí ni Ọlọ́run dá káwa èèyàn lè máa gbé títí láé lórí rẹ̀, kì í ṣe ọ̀run. (Jẹ́n. 1:28; Sm. 37:29) Àmọ́, Jèhófà ti yan àwọn kan láti jẹ́ ọba àti àlùfáà lọ́run. Torí náà, nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ́n, ìrètí wọn àti bí wọ́n ṣe ń ronú yí pa dà, tó fi jẹ́ pé ọ̀run ni wọ́n ń retí láti gbé. (Éfé. 1:18) Àmọ́ báwo lẹnì kan á ṣe mọ̀ pé Jèhófà ti yan òun láti lọ sọ́run? Gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ẹni àmì òróró tó wà ní Róòmù, ìyẹn àwọn “tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́.” Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gba ẹ̀mí ìsìnrú tí ó tún ń fa ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ ” (Róòmù 1:7; 8:15) Ọlọ́run ló ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mú kó dá ẹnì kan lójú pé òun ti yàn án láti wá bá Jésù jọba lọ́run.—1 Tẹs. 2:12. w16.01 3:8, 9
Monday, July 31
Má [ṣe] máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.—1 Tẹs. 4:11.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn? A ò ní máa béèrè lọ́wọ́ wọn pé báwo ni wọ́n ṣe di ẹni àmì òróró. Ó yẹ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àárín àwọn àti Jèhófà ni, a ò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀. (2 Tẹs. 3:11) Kò sì yẹ ká máa ronú pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yan ọkọ tàbí aya wọn, àwọn òbí wọn tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Ó yẹ ká mọ̀ pé ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní kì í ṣe ogún ìdílé. (1 Tẹs. 2:12) Kò sì tún yẹ ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa béèrè lọ́wọ́ ìyàwó ẹni àmì òróró kan pé báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀ tó bá ń rántí pé òun máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé tí ọkọ rẹ̀ sì máa wà lọ́run. Ó ṣe tán, ó dá wa lójú pé, nínú ayé tuntun, Jèhófà máa “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sm. 145:16) A máa dáàbò bo ara wa tá a bá ń fojú tó tọ́ wo àwọn ẹni àmì òróró, tí a kì í wò wọ́n bí ẹni pé wọ́n ṣe pàtàkì ju àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó kù lọ. Lọ́nà wo? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn èké arákùnrin” lè wà nínú ìjọ, wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ pé ẹni àmì òróró làwọn.—Gál. 2:4, 5; 1 Jòh. 2:19. w16.01 4:10, 11