September
Friday, September 1
[Ábúráhámù] rìnnà àjò lọ sí ibi tí Ọlọ́run tòótọ́ tọ́ka sí fún un.—Jẹ́n. 22:3.
Nígbà tí Ábúráhámù sún mọ́ ibi tó ti fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró síhìn-ín ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ṣùgbọ́n èmi àti ọmọdékùnrin náà fẹ́ tẹ̀ síwájú lọ sí ọ̀hún yẹn láti jọ́sìn kí a sì padà wá bá yín.” (Jẹ́n. 22:5) Kí ni Ábúráhámù ní lọ́kàn? Ṣé irọ́ ló ń pa nígbà tó sọ pé òun àti Ísákì á pa dà wá, nígbà tó mọ̀ pé òun máa fi rúbọ? Rárá. Bíbélì sọ pé Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà lè jí Ísákì dìde tó bá tiẹ̀ kú. (Héb. 11:19) Ábúráhámù mọ̀ pé Jèhófà ló jẹ́ kí òun àti Sárà bímọ lọ́jọ́ ogbó àwọn. (Héb. 11:11, 12, 18) Torí náà, ó mọ̀ pé kò sí ohun tí Jèhófà ò lè ṣe. Ábúráhámù ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ó nígbàgbọ́ pé bí ọmọ òun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí i dìde kí gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe lè nímùúṣẹ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”—Róòmù 4:11. w16.02 1:3, 13
Saturday, September 2
Nítorí Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.—1 Sám. 12:22.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó di aláìgbọràn, Jèhófà sì ti kọ̀ ọ́. (1 Sám. 15:17-23) Síbẹ̀, Ọlọ́run gbà kí Sọ́ọ̀lù ṣàkóso fún ọ̀pọ̀ ọdún. Torí náà, ó ṣòro fáwọn èèyàn náà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run torí pé ọba tó wà lórí “ìtẹ́ Jèhófà” ń ṣe ohun tó burú jáì. (1 Kíró. 29:23) Jónátánì ò fi Jèhófà sílẹ̀. Àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ká máa ṣègbọràn sáwọn tó ń ṣàkóso ní orílẹ̀-èdè tá à ń gbé, bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Jèhófà fàyè gba “àwọn aláṣẹ onípò gíga” yìí láti máa ṣàkóso wa, ó sì fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn. (Róòmù 13:1, 2) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ bí wọn ò tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ tá a sì rò pé wọn ò yẹ lẹ́ni tó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún. Kódà, ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn tí Jèhófà fi sípò àṣẹ.—1 Kọ́r. 11:3; Héb. 13:17. w16.02 3:5, 6, 8
Sunday, September 3
Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn.—Sm. 110:3.
Bíbélì sọ pé gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà, tó fi mọ́ àwọn ọ̀dọ́, á máa sìn ín “tinútinú.” Torí náà, ó yẹ kó dá ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi lójú pé ó ti ọkàn rẹ̀ wá. Ìyẹn lè gba pé kó o ronú lórí ohun tó o fẹ́ ṣe yìí dáadáa, pàápàá tó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí tó tọ́ ẹ dàgbà. Bó o ṣe ń dàgbà, o lè máa rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣèrìbọmi, lára wọn sì lè jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn àbúrò rẹ tàbí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Àmọ́, ṣọ́ra kó o má lọ bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ìwọ náà gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kìkì nítorí pé àwọn kan ti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí kó o bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ìwọ náà kì í ṣọmọdé mọ́, ó sì yẹ kó o ti ṣèrìbọmi. Kí ló máa mú kó dá ẹ lójú pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìrìbọmi ni ìwọ náà fi ń wò ó? Fara balẹ̀ ronú lórí ìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì. w16.03 1:11, 12
Monday, September 4
Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: “Máa bọ̀!” Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.—Ìṣí. 22:17.
Tá a bá wà “ní ìṣọ̀kan,” tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nìkan la lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyọrí. (Éfé. 4:16) Ká tó lè wàásù kárí ayé, àfi ká wà létòlétò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé wa sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè wà létòlétò. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń pàdé pọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá ká tó jáde lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. A tún máa ń fáwọn èèyàn ní àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Kódà, ọ̀kẹ́ àìmọye ìtẹ̀jáde yìí la ti pín fáwọn èèyàn kárí ayé. Nígbà míì, a máa ń gba ìtọ́ni pé ká kópa nínú àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù. Bó o ṣe ń kópa nínú àkànṣe iṣẹ́ yìí, ohun kan náà tí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà kárí ayé ń ṣe nìwọ náà ń ṣe! Yàtọ̀ síyẹn, o tún ń bá àwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́ torí pé àwọn ló ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.—Ìṣí. 14:6. w16.03 3:4, 5
Tuesday, September 5
A ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀.—Ìṣí. 20:12.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nínú ayé tuntun, Jèhófà máa fún wa ní àwọn àkájọ ìwé tó máa ní àwọn ìtọ́ni tuntun. Ó ní láti jẹ́ pé àwọn àkájọ ìwé yìí ló máa jẹ́ káráyé mọ àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Àwọn àkájọ ìwé yìí máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tó jíǹde, mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wọn. Àwọn àkájọ ìwé náà máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́. A máa túbọ̀ lóye Bíbélì, torí náà, nínú Párádísè, gbogbo wa á nífẹ̀ẹ́ ara wa, àá máa bọ̀wọ̀ fúnra wa, àá sì máa buyì kúnra wa. (Aísá. 26:9) Ẹ sì wo bí àwọn ohun tá a máa mọ̀ nígbà ìṣàkóso Jésù Kristi Ọba náà á ṣe pọ̀ tó, tá ó sì tún fi kọ́ àwọn míì! Tá a bá tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni “tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà,” tá a sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà àdánwò ìkẹyìn, Jèhófà máa kọ orúkọ wa sínú “àkájọ ìwé ìyè.” Àá wá wà láàyè títí láé! w16.03 4:19, 20
Wednesday, September 6
Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá.—Sm. 71:5.
Àwọn alàgbà tó nírìírí sọ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, pàápàá tí wọ́n bá ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Ìyẹn gba pé ká máa fún wọn níṣẹ́ tó bá ọjọ́ orí wọn mu. Tí a bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, nígbà tí wọ́n bá fi máa pé ọmọ ogún ọdún, àwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni wọ́n á máa lépa dípò àwọn nǹkan ayé tó sábà máa ń pín ọkàn àwọn ọ̀dọ́ níyà. (Sm. 71:17) Alàgbà kan tún lè mú kó wu akẹ́kọ̀ọ́ kan láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó bá ṣàlàyé ohun tó yẹ kó ṣe àti ìdí tó fi yẹ kó ṣe é. Táwọn alàgbà bá ń sọ ìdí tó fi yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àwọn nǹkan kan, ńṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó gbé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́, ó sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó wá fi kún un pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mát. 28:18, 19. w15 4/15 2:5, 6
Thursday, September 7
Olúwa dúró lẹ́bàá mi, ó sì fi agbára sínú mi, . . . a sì dá mi nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún.—2 Tím. 4:17.
Àwọn èèyàn ń fojú àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi rí màbo ní ìlú Róòmù, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé àwọn ló dáná sun ìlú Róòmù ní ọdún 64 Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò tí nǹkan ò rọgbọ yìí ni wọ́n ju àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì ní ìlú Róòmù. Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni míì máa wá ràn án lọ́wọ́? Pọ́ọ̀lù lè kọ́kọ́ máa rò pé bóyá lẹni kẹ́ni máa rí tòun rò torí ó sọ fún Tímótì pé: “Nínú ìgbèjà mi àkọ́kọ́, kò sí ẹnì kankan tí ó wá síhà ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ṣá mi tì.” (2 Tím. 4:16) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ṣì rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa fún òun lókun láti fara da àwọn àdánwò tí òun ń kojú àti àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé lọ́jọ́ iwájú. Abájọ tó fi sọ pé: “Olúwa yóò dá mi nídè lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú.” (2 Tím. 4:18) Pọ́ọ̀lù ti wá mọ̀ pé tí kò bá tiẹ̀ sí nǹkan kan táwọn èèyàn lè ṣe, ó dájú pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ á ṣèrànwọ́! w15 4/15 4:1-3
Friday, September 8
Òun yóò pa ọ́ ní orí.—Jẹ́n. 3:15.
Nígbà tí wọ́n bí Jésù, Sátánì mọ̀ pé ọmọ tuntun yẹn máa dàgbà, á sì di Mèsáyà tá a ṣèlérí. Ṣé Sátánì rò pé ó burú tóun bá gba ẹ̀mí ọmọ náà? Rárá o, nítorí oníwàkiwà ni Sátánì. Nígbà tó dórí ọ̀ràn Jésù ọmọ kékeré náà, Sátánì gbógun tì í láìjáfara. Báwo ló ṣe ṣe é? Inú bí Hẹ́rọ́dù Ọba gan-an nígbà táwọn awòràwọ̀ ń ṣèwádìí nípa “ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù,” ó sì pinnu láti pa á. (Mát. 2:1-3, 13) Kí ó bàa lè rí i pé iṣẹ́ náà di ṣíṣe, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n wà ní ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀ tí wọ́n ń gbé ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀. (Mát. 2:13-18) Jésù bọ́ lọ́wọ́ ikú nígbà ìpànìyàn tó burú jáì yẹn, àmọ́ kí ni ọ̀ràn náà jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀tá wa Sátánì? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí èèyàn kò jọ Èṣù lójú. Ó dájú pé kò láàánú àwọn ọmọdé. Kò sí àní-àní pé kìnnìún tó “ń ké ramúramù” ni Sátánì. (1 Pét. 5:8) Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré ìwà ìkà rẹ̀ láé! w15 5/15 1:10, 12, 13
Saturday, September 9
Wọn kò rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré.—Héb. 11:13.
Bá a ṣe lè fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí a kò tíì rí jẹ́ ẹ̀bùn kan tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa. Ó máa ń jẹ́ ká ṣe àwọn ètò tó mọ́gbọ́n dání, ká sì máa retí àwọn ohun tó dáa lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sábà máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti sọ fún wa nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kó tó di pé wọ́n ṣẹlẹ̀, èyí sì lè jẹ́ ká fọkàn yàwòrán ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ká sòótọ́, bá a ṣe lè fọkàn yàwòrán ohun tí a kò rí máa ń jẹ́ ká lè lo ìgbàgbọ́. (2 Kọ́r. 4:18) Nígbà tí Hánà ń ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí tí òun bá mú Sámúẹ́lì ọmọkùnrin òun lọ sìn nínú àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn kì í ṣe àlá lásán torí pé ó ní ìdí pàtàkì tó fi ronú bẹ́ẹ̀. Ohun tó ti pinnu láti ṣe nìyẹn, èyí sì jẹ́ kó lè mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. (1 Sám. 1:22) Tá a bá ń fọkàn yàwòrán ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa ṣe, ohun tó dájú pé ó máa ṣẹlẹ̀ là ń fọkàn rò yẹn. (2 Pét. 1:19-21) Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn ló fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí. w15 5/15 3:1-3
Sunday, September 10
Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ . . . dà bí ògiri adáàbòboni nínú èrò-ọkàn rẹ̀.—Òwe 18:11.
Èrò tó léwu tó sì yẹ ká yẹra fún ni kéèyàn máa ronú bó ṣe máa dolówó rẹpẹtẹ, èyí ò sì ní jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ ráyè gbọ́ ti Ọlọ́run. Jésù sọ ìtàn kan tó fi ṣàpèjúwe ìbànújẹ́ tó máa bá ẹnì kan “tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:16-21) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ṣe ohun tó fẹ́. (Òwe 27:11) Ẹ ò rí i pé inú wa máa dùn gan-an tá a bá rójú rere Ọlọ́run torí pé a to “ìṣúra” jọ pa mọ́ fún ara wa ní “ọ̀run”! (Mát. 6:20) Láìsí àní-àní, àjọṣe tó dán mọ́rán tó wà láàárín àwa àti Jèhófà ni ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ tá a lè ní. Ẹ fojú inú yàwòrán bí àníyàn ṣe máa bò wá mọ́lẹ̀ tó, tá a bá ń forí ṣe fọrùn ṣe torí ká lè to “ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara [wa] lórí ilẹ̀ ayé.” (Mát. 6:19) Jésù sọ àpèjúwe kan tó fi hàn pé “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè fún ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run pa lọ́kàn wa.—Mát. 13:18, 19, 22. w15 5/15 4:15, 16
Monday, September 11
Ogunlọ́gọ̀ náà ṣe kàyéfì bí wọ́n ti rí tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn arọ sì ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran.—Mát. 15:31.
Agbára Ọlọ́run mú kí Jésù Kristi lè ṣe onírúurú iṣẹ́ ìyanu tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kì í ṣe àwọn tó lárùn ẹ̀tẹ̀ nìkan ló wò sàn, ó tún mú àwọn tó ní onírúurú àìsàn lára dá. Jésù ò nílò kí ẹnikẹ́ni fi ẹ̀yà ara rẹ̀ tọrọ kó tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú àwọn ẹ̀yà ara tó níṣòro náà pa dà bọ̀ sípò. Ó wo àwọn èèyàn sàn lójú ẹsẹ̀, kódà nígbà míì ẹni tó ń ṣàìsàn náà lè máà sí lọ́dọ̀ rẹ̀. (Jòh. 4:46-54) Kí ni àwọn àpẹẹrẹ àtàtà yìí jẹ́ ká mọ̀? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé Jésù ẹni tó ti di Ọba lókè ọ̀run báyìí wulẹ̀ ní agbára láti woni sàn nìkan ni, ó tún wù ú pé kí aráyé bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àìsàn. Ohun tá a kọ́ nínú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn èèyàn jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé nínú ayé tuntun, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí máa ṣẹ, tó ní: “Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì.” (Sm. 72:13) Nígbà yẹn, Jésù yóò ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ran gbogbo àwọn tójú ń pọ́n lọ́wọ́. w15 6/15 2:6
Tuesday, September 12
Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.—Mát. 6:9.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló lè ka Àdúrà Olúwa láìwo ìwé. Nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a sábà máa ń tọ́ka sí àdúrà yìí káwọn èèyàn lè mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ṣe é fọkàn tán, òun ló sì máa mú àyípadà rere bá ilẹ̀ ayé. Nígbà míì sì rèé, a lè tọ́ka sí apá àkọ́kọ́ nínú àdúrà náà ká lè fi hàn pé Ọlọ́run ní orúkọ kan, èyí tó yẹ kó di mímọ́, a ò sì gbọ́dọ̀ tàbùkù sí i. (Mát. 6:9) Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ inú àdúrà yìí léraléra ní gbogbo ìgbà tá a bá ti ń gbàdúrà, bí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń ṣe lónìí? Rárá o. Ṣáájú kí Jésù tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àdúrà àwòṣe yìí, ó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mát. 6:7) Ní àkókò mìíràn, Jésù tún gba àdúrà yìí, àmọ́ ó lo àwọn ọ̀rọ̀ míì. (Lúùkù 11:1-4) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ àwọn ohun tá a lè béèrè nínú àdúrà wa, ká sì mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù. Torí náà, àdúrà àwòṣe gan-an ló yẹ ká máa pè é. w15 6/15 4:1, 2
Wednesday, September 13
Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.—1 Kọ́r. 10:12.
Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára, tó lè fún wa nígboyà kó sì mú ká yàgò fún ìdẹwò. Ọlọ́run tún ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ láti kìlọ̀ fún wa ká lè mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún, irú bíi ká máa lo okun wa, owó àti àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan ìní tara tí kò pọn dandan. Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Espen àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Janne tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ní ọmọ méjì. Arákùnrin Espen sọ pé: “A máa ń gbàdúrà ní gbogbo ìgbà sí Jèhófà pé ká má ṣe kó sínú ìdẹwò ní báyìí tó jẹ́ pé a ò lè lo àkókò tó pọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi ti ìgbà kan. A máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀, kí ìtara wa má sì jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.” Ìdẹwò míì tó tún gbòde kan lóde òní ni wíwo àwòrán, fídíò tàbí gbígbọ́ àwọn orin tó ń mú kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìdẹwò yìí dẹkùn mú wọn torí pé wọ́n fàyè gba èròkerò lọ́kàn wọn. Àmọ́, ó dájú pé a lè sá fún un. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 10:13. w15 6/15 5:15, 16
Thursday, September 14
Àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ènìyàn onípò gíga jù lọ àti àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára àti olúkúlùkù ẹrú àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní òmìnira fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn hòrò àti sínú àwọn àpáta ràbàtà àwọn òkè ńlá.—Ìṣí. 6:15.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìparun gbogbo ètò ìsìn èké? Àkókò yẹn ni ohun tó wà lọ́kàn wa máa fara hàn kedere. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ààbò lọ sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó dà bí “àpáta orí òkè” ìyẹn àwọn àjọ tí àwọn èèyàn dá sílẹ̀. Àmọ́, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa sá lọ síbi ààbò tí Jèhófà pèsè. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àkókò díẹ̀ tí àwọn Kristẹni ní láti fi sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù kì í ṣe àkókò láti sọ gbogbo àwọn Júù di Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, àkókò tí àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kí wọ́n sì ṣègbọràn ni. Bákan náà, a ò lè retí pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ní àkókò tí ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ fi máa dáwọ́ dúró díẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn á ní àǹfààní láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa kọ́wọ́ ti àwọn arákùnrin Kristi.—Mát. 25:34-40. w15 7/15 2:7
Friday, September 15
Bí ẹnì kan, nítorí ẹ̀rí-ọkàn sí Ọlọ́run, bá ní àmúmọ́ra lábẹ́ àwọn ohun tí ń kó ẹ̀dùn-ọkàn báni, tí ó sì jìyà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.—1 Pét. 2:19.
Nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ ẹ tàbí ibi tó o gbé dàgbà, ṣé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ tàbí ìlú tó o ti wá? Ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ ṣì wà lọ́kàn rẹ? Kò yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ kí ọwọ́ tí wọ́n fi mú orílẹ̀-èdè wọn máa nípa lórí ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn èèyàn. Àmọ́ kí lo máa ṣe tó o bá kíyè sí i pé o ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn èèyàn tí orílẹ̀-èdè wọn, àṣà, èdè tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tìẹ? Ó máa dára kó o ṣe àṣàrò lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Wàá rí i pé ó tọ́ kó o ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà àti àwọn kókó tó fara jọ ọ́. Lẹ́yìn náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà wò ó. (Róòmù 12:2) Ìdí ni pé bó pẹ́ bó yá, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa bá ara wọn nínú ipò kan tó ti máa pọn dandan pé kí wọ́n dá yàtọ̀ sí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ọmọléèwé wọn, aládùúgbò wọn, àwọn ìbátan wọn tàbí àwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ dá yàtọ̀. w15 7/15 3:14, 15
Saturday, September 16
Jónà gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ láti ìhà inú ẹja náà.—Jónà 2:1.
Bí ẹnikẹ́ni ò bá tiẹ̀ mọ ohun tó ń ṣe wá, Jèhófà máa ń gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa ó sì máa ń lóye wa. Bó ṣe ń dáhùn àdúrà wa fi hàn pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wa. Ọ̀pọ̀ nńkan la lè rí kọ́ nínú àwọn àdúrà tó wà nínú Bíbélì. Torí náà, ó máa dáa ká jíròrò irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ nígbà ìjọsìn ìdílé wa. Tá a bá ń ronú lórí bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ ṣe sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún Ọlọ́run, á jẹ́ kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí Jónà ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run nígbà tó wà nínú ikùn ẹja ńlá. (Jónà 1:17–2:10) Ṣe àgbéyẹ̀wò àdúrà àtọkànwá tí Sólómọ́nì gbà sí Jèhófà nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì. (1 Ọba 8:22-53) Ronú nípa ohun tá a lè rí kọ́ nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà. (Mát. 6:9-13) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, “ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run” nígbà gbogbo. Látàrí èyí, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”—Fílí. 4:6, 7. w15 8/15 1:11, 12
Sunday, September 17
Ẹ . . . jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.—Héb. 13:17.
Ohun ayọ̀ ló máa jẹ́ láti wà nínú ayé tuntun lábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà, a ó máa lọ́wọ́ nínú sísọ ilẹ̀ ayé di ibi ẹlẹ́wà, a ó máa kọ́ àwọn tó jíǹde lẹ́kọ̀ọ́, a ó sì máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ká wá sọ pé wọ́n ní ká ṣe iṣẹ́ kan tí kò wù wá ńkọ́? Ṣé a máa fara mọ́ ìtọ́ni tí wọ́n fún wa, ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, ká sì fi ayọ̀ ṣe é? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ni ọ̀pọ̀ nínú wa máa dáhùn. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìgbà gbogbo là ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni tó ń wá látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run nísinsìnyí? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn fi hàn pé à ń múra sílẹ̀ láti gbé títí láé lábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà. A lè múra sílẹ̀ fún gbígbé nínú ayé tuntun nípa fífara mọ́ ètò tí Jèhófà ṣe ní àkókò tá à ń gbé yìí, a sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ọwọ́ sowọ́ pọ̀ àti níní ìtẹ́lọ́rùn. Tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń múpò iwájú lónìí, tá a sì ń rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tuntun tá a bá ní, irú ẹ̀mí yẹn náà la máa ní nínú ayé tuntun. w15 8/15 3:6, 7
Monday, September 18
Àwọn aya [abọ̀rìṣà] tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, . . . Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.—1 Ọba 11:4, 6.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì gbọ́n, ẹgbẹ́ búburú mú kó hùwà òmùgọ̀, ó sì fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. (1 Ọba 11:1-6) Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n lè máa ronú láti fẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ti fẹ́ aláìgbàgbọ́ kó tó di olùjọ́sìn Ọlọ́run ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn.” (1 Pét. 3:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni la darí ọ̀rọ̀ yìí sí, ọ̀rọ̀ náà kan ọkọ kan tó ti fẹ́ aláìgbàgbọ́ kó tó di olùjọ́sìn Jèhófà. Ìkìlọ̀ Bíbélì yìí ṣe kedere, ìyẹn sì ni pé kó o jẹ́ ọkọ tàbí aya rere, kó o sì máa tẹ̀ lé ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn tó ti ṣègbéyàwó. Ọ̀pọ̀ ọkọ tàbí aya aláìgbàgbọ́ ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọ́n kíyè sí ìyípadà tó wáyé nígbà tí ẹnì kejì wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò. w15 8/15 4:15, 16
Tuesday, September 19
Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.—Òwe 14:15.
Àwọn àìsàn kan lè wà tí kò gbóògùn. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣọ́ra fún irú ìtọ́jú kan táwọn èèyàn gbà pé ó jẹ́ kì-í-bà-á-tì, àmọ́ tí kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ló rí. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílí. 4:5) Tá a bá jẹ́ afòyebánilò, a ò ní máa lo gbogbo àkókò wa lórí ọ̀rọ̀ ìlera débi tá ò fi ní rí àkókò fún ìjọsìn Jèhófà mọ́. Tá ò bá rí nǹkan míì gbọ́ mọ́ ju ọ̀rọ̀ ìlera lọ, ńṣe la máa di onímọtara-ẹni-nìkan. (Fílí. 2:4) Kò yẹ ká máa ronú pé a lè rí ojútùú sí gbogbo àìlera wa, torí náà a gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ká sì máa rántí pé ìjọsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù. (Fílí. 1:10) Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ múra tán láti pinnu irú ìtọ́jú tá a fẹ́, ká sì fara mọ́ ohun tó bá tìdí ẹ̀ yọ. w15 9/15 2:8, 10
Wednesday, September 20
Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde. Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.—Sm. 43:3.
Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ó sì wù ú kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ máa tàn kó lè máa tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn, pàápàá jù lọ nínú ìjọsìn wọn. Òtítọ́ wo ni Jèhófà ń fi hàn wá, báwo nìyẹn sì ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà sọ òtítọ́ nípa ara rẹ̀ fún wa. Ó sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa, orúkọ yìí ló sì fara hàn jù lọ nínú gbogbo orúkọ tó wà nínú Bíbélì. Lọ́nà yìí, Jèhófà ń jẹ́ ka mọ òun, ó sì ń jẹ́ ká lè ní àjọṣe pẹ̀lú òun. (Ják. 4:8) Jèhófà tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tí òun ní àti irú Ọlọ́run tí òun jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbáyé wa ń fi agbára àti ọgbọ́n rẹ̀ hàn, Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ìfẹ́ rẹ̀ kò sì láfiwé. (Róòmù 1:20) Ó dà bíi bàbá kan tí kì í ṣe pé ó kàn lágbára tó sì gbọ́n nìkan ni, àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ó sì máa ń fòye báni lò, èyí wá mú kó rọrùn fún àwọn ọmọ rẹ̀ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. w15 9/15 4:8, 9
Thursday, September 21
A ó sì sọ ọwọ́ Jèhófà di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Aísá. 66:14.
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé kò sí ohun tó kan Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ àwọn. Àwọn kan sì gbà pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn ò kan Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí ìjì líle kan jà ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Philippines ní oṣù November ọdún 2013, ohun tí olórí ìlú ńlá kan níbẹ̀ sọ ni pé: “Ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ò rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí.” Àwọn míì máa ń ṣe bíi pé Ọlọ́run ò rí ohun tí wọ́n ń ṣe. (Aísá. 26:10, 11; 3 Jòh. 11) Wọ́n dà bí àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “wọn kò . . . tẹ́wọ́ gba mímọ Ọlọ́run.” Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ “kún fún gbogbo àìṣòdodo, ìwà burúkú, ojúkòkòrò, ìwà búburú.” (Róòmù 1:28, 29) Ṣé bíi tàwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tán yìí lọ̀rọ̀ wá rí? Rárá o. A mọ̀ pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe. Àmọ́, ṣé àwa náà ń rí i pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún àti pé ó ń tì wá lẹ́yìn? w15 10/15 1:1-3
Friday, September 22
Èmi yóò . . . fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.—Ják. 2:18.
Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jẹ́ ọ̀nà títayọ tá a lè gbà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ká tó lè wàásù, a gbọ́dọ̀ gbà pé àkókò tí Ọlọ́run máa fòpin sí ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé, àti pé “kì yóò pẹ́.” (Háb. 2:3) Torí náà, bó ṣe ń wù wá tó láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà mọ̀ bóyá a ní ìgbàgbọ́. Ǹjẹ́ à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, ṣé a sì ń wá bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i? (2 Kọ́r. 13:5) Láìsí àní-àní, ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn wa ni pé ká máa ṣe “ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) A tún lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Bá a tiẹ̀ ń ṣàìsàn, tá a rẹ̀wẹ̀sì, tá a sorí kọ́, tá ò lówó lọ́wọ́, tàbí táwọn ìṣòro míì tó le koko ń bá wa fínra, ó dá wa lójú pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ “ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16) A lè fi hàn pé a ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí. w15 10/15 2:12-14
Saturday, September 23
Ẹ̀mí mímọ́ . . . yóò . . . mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.—Jòh. 14:26.
Ó lè má rọrùn láti rí Bíbélì kà láwọn ipò kan, àmọ́ wà á ṣì lè ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀, irú bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o yàn láàyò àtàwọn orin Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 16:25) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run á sì jẹ́ kó o rántí gbogbo nǹkan rere tó o ti kọ́. A lè ya àwọn ọjọ́ kan sọ́tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ láti múra sílẹ̀ fún Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ká sì ṣàṣàrò lé e lórí. A lè fi àwọn ọjọ́ mìíràn ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jésù ṣe àtàwọn ohun tó sọ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Àwọn ìwé yìí ló ṣàlàyé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti ìgbésí ayé rẹ̀, wọ́n sì wà lára àwọn ìwé Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ jù. (Róòmù 10:17; Héb. 12:2; 1 Pét. 2:21) Kódà, àwa èèyàn Ọlọ́run ní ìwé kan tó ṣàlàyé nípa Jésù àtohun tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Wàá jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ tó o bá fara balẹ̀ ka ìwé yìí tó o sì ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú ìtàn kọ̀ọ̀kan.—Jòh. 14:6. w15 10/15 4:11, 12
Sunday, September 24
Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.—Jòh. 15:15.
Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gan-an. Láyé àtijọ́, ó lójú ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀gá máa ń bá àwọn ẹrú wọn sọ. Àmọ́, Jésù ò mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bí ẹrú, ńṣe ló mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Ó máa ń wà pẹ̀lú wọn, ó máa ń sọ èrò rẹ̀ fún wọn, ó sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn tí wọ́n bá ń sọ tinú wọn. (Máàkù 6:30-32) Bí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe jọ máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ yìí mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ìyẹn sì mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tóótun fún iṣẹ́ ìwàásù tó gbé lé wọn lọ́wọ́. Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀wọ́n rí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, ó wù ú kí wọ́n máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ká sòótọ́, Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn láṣeyọrí! Ó sì fọkàn wọn balẹ̀ pé òun á ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí.—Mát. 28:19, 20. w15 11/15 2:3, 5
Monday, September 25
Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.—Mát. 22:39.
Ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ Jèhófà Ọlọ́run. (1 Jòh. 4:16) Jésù ni Jèhófà kọ́kọ́ dá, ó sì ti wà pẹ̀lú Ọlọ́run fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún, torí náà ó ti ní láti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ ṣe nǹkan. (Kól. 1:15) Nínú gbogbo ohun tí Jésù ń ṣe títí kan ìgbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun mọ Jèhófà sí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, òun náà sì ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ó dá wa lójú pé ìfẹ́ ni Jèhófà àti Jésù máa fi ṣàkóso wa títí láé. Nígbà tí ẹnì kan bi Jésù pé èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin, Jésù sọ fún un pé: “ ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” (Mát. 22:37-39) Kíyè sí i pé Jésù ní ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. Èyí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn. w15 11/15 4:1-3
Tuesday, September 26
Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.—Róòmù 15:4.
Jèhófà lo èdè míì láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn táwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò nígbèkùn ní Bábílónì, èdè Árámáíkì làwọn kan lára wọn ń sọ lójoojúmọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi mí sí àwọn wòlíì bíi Dáníẹ́lì àti Jeremáyà àti Ẹ́sírà àlùfáà láti fi èdè Árámáíkì kọ àwọn kan lára àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ. Nígbà tó yá, Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìlú tó wà láyé ìgbà yẹn, nítorí èyí èdè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní Koine tó wọ́pọ̀ jù lọ nígbà yẹn wá di èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ kárí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè yẹn, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí làwọn èèyàn wá mọ̀ sí Bíbélì Septuagint, ọ̀pọ̀ sì gbà pé èèyàn méjìléláàádọ́rin [72] ló túmọ̀ rẹ̀. Ohun ni ìtumọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣe pàtàkì jù. Bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe ẹnì kan ló tú Bíbélì yìí mú kí ọ̀nà tí wọ́n gbà tú àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yàtọ̀ síra, àwọn kan tú u lólówuuru, àwọn kan ò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì àtàwọn Kristẹni tó wá lo Bíbélì Septuagint lẹ́yìn náà gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. w15 12/15 1:4-6
Wednesday, September 27
Wò ó! Bí iná tí a fi ń dáná ran igbó igi tí ó tóbi gan-an ti kéré tó!—Ják. 3:5.
Ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ wá ṣe kedere ní ẹsẹ kẹfà. Ó ní: “Tóò, ahọ́n jẹ́ iná.” Ahọ́n ló ń jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀. Bí iná ṣe lè jó nǹkan run kó sì ba nǹkan jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ahọ́n wa lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀. Kódà, Bíbélì sọ pé “ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n.” (Òwe 18:21) Lóòótọ́, a ò ṣáà ní torí pé a ò fẹ́ múnú bí àwọn ẹlòmíì, ká wá pa ẹnu mọ́, bó ṣe jẹ́ pé a ò lè sọ pé a ò ní lo iná mọ́ torí pé ó lè jó nǹkan run. Kókó ibẹ̀ ni pé ká ṣọ́ ohun tá a máa sọ. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi iná se oúnjẹ, a lè tanná sínú yàrá tó ṣókùnkùn, a sì lè yáná nígbà òtútù. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kó ahọ́n wa níjàánu, a lè fi yin Ọlọ́run lógo ká sì sọ̀rọ̀ tó máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. (Sm. 19:14) Yálà ẹnu la fi ń sọ̀rọ̀ tàbí ọwọ́ la fi ń sọ̀rọ̀, bá a ṣe lè sọ èrò wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó sì yẹ ká máa fi ẹ̀bùn yìí gbé àwọn ẹlòmíì ró ká má sì kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn.—Ják. 3:9, 10. w15 12/15 3:1-3
Thursday, September 28
Lúùkù oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n ní kí a kí yín.—Kól. 4:14.
Ó ṣeé ṣe kí Lúùkù fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò míṣọ́nnárì nímọ̀ràn nípa ìlera kó sì tún tọ́jú wọn. Kí nìdí tó fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀? Torí pé Pọ́ọ̀lù pàápàá ṣàìsàn nígbà tó ń rìnrìn àjò. (Gál. 4:13) Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Àwọn tí ó lera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.” (Lúùkù 5:31) A ò mọ ìgbà tí Lúùkù kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn a ò sì mọ ibi tó ti kọ́ ọ. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fi ìkíni Lúùkù ránṣẹ́ sí àwọn ará tó wà ní Kólósè, ó pè é ní oníṣègùn torí pé àwọn ará tó wà ní Kólósè pàápàá mọ̀ pé oníṣègùn ni. Ó sì lè jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn kan ní ìlú Laodíkíà ló lọ, nítòsí ìlú Kólósè. Lúùkù kì í wulẹ̀ ṣe agbọ̀ràndùn kan lásán tó ń júwe irú ògùn tó yẹ káwọn èèyàn lò fún wọn, oníṣègùn ni. Àwọn èdè ìṣègùn tó lò nínú ìwé Ìhìn Rere tó kọ àti nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì àti bó ṣe ṣàlàyé àwọn ìwòsàn tí Jésù ṣe jẹ́rìí sí i pé oníṣègùn ni lóòótọ́. w15 12/15 4:11, 12
Friday, September 29
Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.—2 Kọ́r. 9:15.
Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa mú kó fún wa lẹ́bùn tó ṣeyebíye jù lọ, ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé. (Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:9, 10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ẹ̀bùn yìí ní ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.’ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ẹbọ ìràpadà Jésù ló jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe máa nímùúṣẹ. (2 Kọ́r. 1:20) Èyí túmọ̀ sí pé ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ ti Ọlọ́run ní nínú, ẹbọ ìràpadà Jésù, gbogbo oore tí Jèhófà ń ṣe fún wa àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ń fi hàn sí wa. Kò sí bá a ṣe ṣàlàyé ẹ̀bùn pàtàkì yìí tó, tó máa yé àwa èèyàn yékéyéké. Báwo ló ṣe yẹ kí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ yìí rí lára wa? Báwo ni ẹ̀bùn tá a ní yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? Ṣé ẹ̀bùn yìí á mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà tó yẹ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé á mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn míì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kó o máa dárí ji àwọn tó ṣàìdáa sí ẹ, kó o sì tún fi kún ìwà ọ̀làwọ́ rẹ? Máa rántí pé ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa yìí ṣeyebíye ju ẹ̀bùn èyíkéyìí lọ.—1 Pét. 3:18. w16.01 2:1, 2, 4, 5
Saturday, September 30
Ẹ̀fúùfù ń fẹ́ síbi tí ó wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó ti wá àti ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti inú ẹ̀mí.—Jòh. 3:8.
Ẹnì kan tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn lè máa ronú pé, ‘Ó ṣe jẹ́ èmi ni Jèhófà yàn?’ Ó tiẹ̀ lè máa ronú pé ṣé irú òun yìí ni irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ tọ́ sí ṣá. Àmọ́, kò jẹ́ ṣiyè méjì láé pé bóyá Jèhófà yan òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ̀ á dùn gan-an, á sì mọyì irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Pétérù náà ló rí lára gbogbo àwọn ẹni àmì òróró. Àpọ́sítélì Pétérù ní: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú òkú, sí ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá. A fi í pa mọ́ ní ọ̀run de ẹ̀yin.” (1 Pét. 1:3, 4) Bí àwọn ẹni àmì òróró bá ń ka ibí yìí, wọ́n á mọ̀ dájú pé àwọn ni Jèhófà Baba wọn ń bá sọ̀rọ̀ níbí yìí. w16.01 3:11, 12