October
Sunday, October 1
Àwọn tí ó yàn ṣáájú ni àwọn tí ó pè.—Róòmù 8:30.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ẹni àmì òróró. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni ẹni àmì òróró. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ni kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti gidi. Síbẹ̀ náà, láàárín àwọn ọdún yẹn, Jèhófà fẹ̀mí yan ìwọ̀nba àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Ńṣe ni wọ́n dà bí àlìkámà tí Jésù sọ pé á máa dàgbà láàárín àwọn èpò. (Mát. 13:24-30) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ń bá a nìṣó láti yan àwọn èèyàn tó máa di ara àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. Torí náà, bí Ọlọ́run bá pinnu láti yan àwọn kan lára wọn ní àkókò díẹ̀ ṣáájú kí òpin tó dé, ó dájú pé kò sẹ́ni tó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. (Aísá. 45:9; Dán. 4:35; Róòmù 9:11, 16) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ wa má bàa dà bíi tàwọn òṣìṣẹ́ tó ń bínú sí ọ̀gá wọn torí iye owó tó san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó dé kẹ́yìn.—Mát. 20:8-15. w16.01 4:15
Monday, October 2
Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì rìnnà àjò lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè ńlá tí èmi yóò tọ́ka sí fún ọ.—Jẹ́n. 22:2.
Jèhófà ò sọ pé ká fàwọn ọmọ wa rúbọ sí òun, àmọ́ ó ní ká pa àwọn àṣẹ òun mọ́. Nígbà míì, a lè máà lóye ìdí tí Jèhófà fi ní ká ṣe ohun kan, ó sì lè má rọrùn fún wa láti ṣègbọràn nígbà míì. Ṣé ó ti ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀ rí? Ó máa ń ṣòro fún àwọn kan láti wàásù. Ojú lè máa tì wọ́n kó má sì rọrùn fún wọn láti bá àwọn tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Àwọn míì ò sì fẹ́ dá yàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ wọn níléèwé tàbí níbi iṣẹ́. (Ẹ́kís. 23:2; 1 Tẹs. 2:2) Tí wọ́n bá ní kó o ṣe ohun kan tí kò rọrùn fún ẹ láti ṣe, ronú nípa bí Ábúráhámù ṣe lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Tá a bá ń ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ìyẹn á mú ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọ̀rẹ́ wa.—Héb. 12:1, 2. w16.02 1:3, 14
Tuesday, October 3
Sọ́ọ̀lù bá Jónátánì ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa fífi ikú pa Dáfídì.—1 Sám. 19:1.
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù sọ pé òun máa pa Dáfídì, ó ṣòro fún Jónátánì láti mọ ohun tí ì bá ṣe. Kò fẹ́ dalẹ̀ bàbá rẹ̀, kò sì fẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ òun àti Dáfídì já. Jónátánì mọ̀ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn Dáfídì, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run ti kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀, torí náà Jónátánì yàn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì. Jónátánì ní kí Dáfídì lọ fara pa mọ́, ó sì bẹ Sọ́ọ̀lù pé kó má pa Dáfídì. (1 Sám. 19:1-6) Ó yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa jẹ́ kí ohunkóhun gba ìjọsìn Jèhófà mọ́ wa lọ́wọ́. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan, iléèwé tàbí orílẹ̀-èdè wa ò gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì sí wa ju ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà lọ. Bí àpẹẹrẹ, Henry fẹ́ràn láti máa ta ayò kan tí wọ́n ń pè ní chess pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ tó ń tayò náà níléèwé wọn torí pé ó fẹ́ gba àmì ẹ̀yẹ fún iléèwé rẹ̀. Àmọ́, torí pé gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ló fi ń tayò yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ, kò sì lọ sóde ẹ̀rí déédéé mọ́. Henry sọ pé iléèwé òun ti wá ṣe pàtàkì sí òun ju ìdúróṣinṣin òun sí Ọlọ́run lọ. Torí náà, ó pinnu pé òun ò ní tayò náà fún iléèwé òun mọ́.—Mát. 6:33. w16.02 3:10, 12
Wednesday, October 4
Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn.—Sm. 110:3.
Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ̀ tó bá jẹ́ pé ó tọkàn ẹ wá pé kó o ṣèrìbọmi ni pé kó o kíyè sí àdúrà tó ò ń gbà. Ṣé o máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lemọ́lemọ́? Ṣé àdúrà rẹ máa ń ṣe pàtó? Ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ kó o mọ bí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà ṣe lágbára tó. (Sm. 25:4) Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àdúrà wa nígbà tá a bá ka Bíbélì. Ọ̀nà míì tó o lè gbà mọ̀ bóyá òótọ́ lo fẹ́ sún mọ́ Jèhófà tó sì ti ọkàn ẹ wá láti sìn ín ni pé kó o ṣàyẹ̀wò bí o ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́. (Jóṣ. 1:8) Ó yẹ kó o bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé? Ṣé wọn kì í fipá mú mi tó bá di pé ká ṣe Ìjọsìn Ìdílé?’ Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ló tọkàn rẹ wá pé kó o ṣèrìbọmi. w16.03 1:11, 13
Thursday, October 5
Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara náà, nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀.—Éfé. 4:16.
Kò sí àní-àní pé inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá ń ka ìròyìn nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé nínú Ìwé Ọdọọdún wa. Tún ronú nípa bí gbogbo wa ṣe máa ń wà níṣọ̀kan láwọn àpéjọ wa. Ìtọ́ni kan náà ni gbogbo wa jákèjádò ayé máa ń rí gbà láwọn àpéjọ yìí. Àwọn àsọyé tá à ń gbọ́, àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn àṣefihàn tá à ń wò láwọn àpéjọ yìí ń mú ká túbọ̀ máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwa àtàwọn ará wa jákèjádò ayé máa ń pàdé pọ̀ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. (1 Kọ́r. 11:23-26) A máa ń pàdé pọ̀ lọ́jọ́ kan náà, ìyẹn Nísàn 14, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀, ká lè pa àṣẹ Jésù mọ́ ká sì tún fi hàn pé a mọ rírì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa. Tó bá sì ku ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan ká ṣe Ìrántí Ikú Kristi, a jùmọ̀ máa ń ké sí àwọn èèyàn wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì náà. Lóòótọ, ẹnì kan ṣoṣo ò lè dá wàásù fún gbogbo èèyàn. Àmọ́ torí pé gbogbo wa ń pawọ́ pọ̀ ṣe iṣẹ́ yìí, a ti sọ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn nípa Jèhófà káwọn náà lè máa fi ìyìn àti ọlá fún un. w16.03 3:4, 6, 7
Friday, October 6
Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.—Mát. 3:17.
Àwọn ohun kan wà táwọn alàgbà máa kọ́ àwọn arákùnrin tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè sìn nínú ìjọ. Lára rẹ̀ ni pé kí àwọn arákùnrin bẹ́ẹ̀ máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì nínú ohun gbogbo tí wọ́n bá ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé alàgbà kan ní kí arákùnrin kan máa rí i pé kò sí ohunkóhun tó lè ṣèpalára fáwọn èèyàn lẹ́nu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ibẹ̀ sì máa wà ní mímọ́ tónítóní. Ó lè ka Títù 2:10, kó wá ṣàlàyé fún un pé bó ṣe ń bójú tó ẹnu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́.” Bákan náà, ó lè sọ pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ronú nípa àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ àti bí wọ́n ṣe máa jàǹfààní tó bá ń ṣe ojúṣe rẹ̀. Tá a bá ní irú ìjíròrò yìí pẹ̀lú ẹni tá à ń dá lẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ kó máa ronú nípa àǹfààní tí iṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe ìjọ dípò kó máa ronú nípa ìtọ́ni tá a fun. Inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe ń rí i pé àwọn ará ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ tó ń bójú tó. Síwájú sí i, kí alàgbà náà gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe ń sapá láti fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. Báwo nìyẹn ti ṣe pàtàkì tó? Omi máa ń mú kí irúgbìn dàgbà. Lọ́nà kan náà, tí a bá ń gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ ó máa jẹ́ kó dàgbà nípa tẹ̀mí. w15 4/15 2:7, 8
Saturday, October 7
Olúwa yóò dá mi nídè lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú.—2 Tím. 4:18.
Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bí i pé ìwọ nìkan lo ń fàyà rán ìṣòro rẹ? Ó lè jẹ́ ìṣòro àìníṣẹ́lọ́wọ́, àwọn tó ń fúngun mọ́ ẹ ní ilé ìwé, àìlera tàbí àwọn ohun míì ló ń kó ìdààmú bá ẹ. Bóyá o tiẹ̀ bẹ àwọn kan pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ ṣe ni wọ́n já ẹ kulẹ̀ torí agbára wọn kò gbé e. Ká sòótọ́, àwọn ìṣòro kan wà tágbára ẹ̀dá èèyàn kò ká. Ní irú àwọn àkókò yìí, ṣé ìmọ̀ràn tí kò wúlò ni Bíbélì fún wa nígbà tó sọ pé ká “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà”? (Òwe 3:5, 6) Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn yẹn nítumọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó nítumọ̀! Ó dájú hán-únhán-ún pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ Bíbélì ló sì fi hàn bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, dípò kó o máa bínú tó bá jọ pé kò sẹ́ni tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ńṣe ni kó o máa wò ó pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ fún ẹ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún, kí ìwọ alára lè rí i bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó. Èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. w15 4/15 4:3-5
Sunday, October 8
Ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.—2 Kọ́r. 4:4.
Àfi tí Sátánì bá lò ẹ̀tàn ló tó lè mú kí àwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Sátánì má ń fẹ̀tàn mú àwọn èèyàn kí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí” má bàa jẹ wọ́n lọ́kàn. (Mát. 5:3) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ń “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.” Ìsìn èké jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó lágbára jù lọ tí Sátánì ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa ń dùn, tó bá rí i táwọn èèyàn ń jọ́sìn baba ńlá wọn tàbí àwọn òkè, omi, ẹranko, ẹyẹ, èèyàn tàbí ohunkóhun míì tó yàtọ̀ sí Jèhófà tó ń fẹ́ “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe”! (Ẹ́kís. 20:5) Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n rò pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ èké àtàwọn ààtò ìsìn tí kò wúlò ti mú lẹ́rú. Ipò tí wọ́n wà máa ń ṣeni láàánú, ńṣe ni wọ́n dà bí àwọn tí Jèhófà pàrọwà fún pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe làálàá fún ohun tí kì í yọrí sí ìtẹ́lọ́rùn? Ẹ fetí sí mi dáadáa, kí ọkàn yín sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀rá.”—Aísá. 55:2. w15 5/15 1:14, 15
Monday, October 9
Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.—Jẹ́n. 3:15.
Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì ti ronú jinlẹ̀ lórí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, kó sì rí i pé ó máa gba pé kí wọ́n ‘pa ẹnì kan ni gìgísẹ̀’ kí àwọn ẹ̀dá èèyàn tó lè di ẹ̀dá pípé, bí Ádámù àti Éfà ṣe rí kó tó di pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run, Jèhófà sì tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀. (Jẹ́n. 4:3-5; Héb. 11:4) Torí pé Nóà nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó la Ìkún omi náà já. (Héb. 11:7) Lẹ́yìn Ìkún omi náà, ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú kó fi ẹran rúbọ sí Jèhófà. (Jẹ́n. 8:20) Bíi ti Ébẹ́lì, òun náà ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹ̀dá èèyàn máa bọ́ nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nóà ṣì ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí nínú Jèhófà kódà lẹ́yìn Ìkún omi lákòókò táwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Jèhófà, ìyẹn lákòókò tí Nímírọ́dù tako àṣẹ Jèhófà. (Jẹ́n. 10:8-12) Ó ṣeé ṣe kí Nóà máa fọkàn yàwòrán ìgbà tí ẹ̀dá èèyàn máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n jogún, tí wọ́n á sì bọ́ lọ́wọ́ àwọn alákòóso aninilára. Àwa náà lè “rí” àkókò alárinrin yìí. Ó sì ti dé tán báyìí!—Róòmù 6:23. w15 5/15 3:4, 6
Tuesday, October 10
Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.—Òwe 12:25.
Tá a bá ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ó lè kó bá ìlera wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì gbàgbé ohun tí ẹsẹ ojúmọ́ tòní ń sọ. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tẹ́nì kan tó lóye wa dáadáa sọ fún wa lè mú kí ayọ̀ kúnnú ọkàn wa. Àníyàn wa lè dín kù tá a bá ń finú han àwọn òbí wa, ọkọ tàbí ìyàwó wa tàbí ọ̀rẹ́ wa kan tá a fọkàn tán tó máa ń fojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Kò sẹ́lòmíì tó mọ àníyàn ọkàn wa tó Jèhófà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Ó ṣe tán, a láwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, àwọn alàgbà, ẹrú olóòótọ́, àwọn áńgẹ́lì, Jésù àti Jèhófà tí wọ́n ń dáàbò bò wá kí àjọṣe àwa àti Jèhófà má bàa bà jẹ́. w15 5/15 4:16, 17
Wednesday, October 11
Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti wà nínú àìsàn rẹ̀ fún ọdún méjìdínlógójì.—Jòh 5:5.
Odò kan wà ní apá àríwá tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ń pè ní Bẹtisátà. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn àtàwọn aláìlera ló máa ń rọ́ wá sí odò adágún yẹn, wọ́n gbà gbọ́ pé ara àwọn máa yá lọ́nà ìyanu. Àánú àwọn èèyàn ló ṣe Jésù ìdí nìyẹn tó fi lọ bá ọkùnrin kan tó ti ń ṣàìsàn tipẹ́tipẹ́, kódà ọdún ti ọkùnrin náà fi wà lórí àìsàn ju ọdún tí Jésù fúnra rẹ̀ ti lò lórí ilẹ̀ ayé lọ. (Jòh. 5:6-9) Jésù bi í bóyá ó fẹ́ kí àìsàn náà kúrò lára rẹ̀. Ojú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin náà dáhùn. Ó fẹ́ kí ara òun yá, àmọ́ kò rò pé ìyẹn ṣeé ṣe, torí kò sí ẹni tó máa gbé e sínú odò adágún náà. Jésù wá pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé kó dìde, kó gbé àkéte rẹ̀, kó sì máa rìn, ó dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ láé. Ó ṣe ohun tí Jésù ní kó ṣe lóòótọ́, ọkùnrin náà gbé àkéte rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. Àbí ẹ ò rí nǹkan, ìtọ́wò ohun tí Jésù máa ṣe nínú ayé tuntun nìyẹn o! A tún rí i nínú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí pé ó jẹ́ aláàánú. Ó dìídì lọ sọ́dọ̀ ẹni tó nílò ìrànwọ́. Ó yẹ kí ohun tí Jésù ṣe yìí mú káwa náà máa bá a nìṣó láti máa wá àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tí àwọn nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí ń kó ìbànújẹ́ bá. w15 6/15 2:8-10
Thursday, October 12
Kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí.—Mát. 6:9.
Jésù kò sọ pé “Baba mi,” àmọ́ ó sọ pé “Baba wa.” Èyí rán wa létí pé a jẹ́ apá kan “ẹgbẹ́ àwọn ará,” tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (1 Pét. 2:17) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́! Ó tọ́ ní ti gidi bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe pe Jèhófà ní “Baba” wọn torí pé Ọlọ́run ti gbà wọ́n ṣọmọ, wọ́n sì nírètí láti lọ gbé ní ọ̀run. (Róòmù 8:15-17) Bákan náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé náà lè pe Jèhófà ní “Baba.” Òun ni Olùfúnni-ní-ìyè wọn, ó sì máa ń fìfẹ́ pèsè ohun tí gbogbo àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn rẹ̀ nílò fún wọn. Àwọn tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò di ọmọ Ọlọ́run ní ti gidi lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá di ẹ̀dá pípé, tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò ìkẹyìn. (Róòmù 8:21; Ìṣí. 20:7, 8) Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye làwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Baba wọn ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Ẹ̀yin òbí, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tẹ́ ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ni pé kẹ́ ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w15 6/15 4:4-6
Friday, October 13
Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.—Mát. 6:13.
Tí a bá fẹ́ gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí Ọlọ́run “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti má ṣe jẹ́ “apá kan ayé [Sátánì].” A kò gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ yálà ayé [Sátánì] tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” (Jòh. 15:19; 1 Jòh. 2:15-17) Èyí kì í ṣe ohun tá à ń ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo o, a gbọ́dọ̀ máa ṣe é ní gbogbo ìgbà. Ìtura gbáà ló máa jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá dáhùn àdúrà yìí tó sì mú Sátánì àti ayé rẹ̀ kúrò! Àmọ́, ẹ jẹ́ ká rántí pé nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, ó mọ̀ pé àkókò tí òun ní kéré gan-an. Pẹ̀lú ìbínú ló fi ń jà fitafita kó lè ba ìṣòtítọ́ wa jẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀. (Ìṣí. 12:12, 17) Ǹjẹ́ ó wù ọ́ kírú àsìkò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣojú rẹ? Tó bá wù ẹ́, máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kó sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó pèsè àwọn ohun tó o nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara fún ọ. Torí náà, pinnu pé wàá máa gbé ìgbé ayé rẹ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà àwòṣe náà.—Mát. 6:9-13. w15 6/15 5:12, 17, 18
Saturday, October 14
Ìpọ́njú ńlá yóò wà.—Mát. 24:21.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìdánwò yẹn, a mọ̀ pé ó máa gba pé ká yááfì àwọn ohun kan. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni ní láti fi gbogbo ohun ìní wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fara da ọ̀pọ̀ ìnira kí wọ́n lè là á já. (Máàkù 13:15-18) Ká bàa lè jẹ́ olóòótọ́, ǹjẹ́ a ṣe tán láti pàdánù àwọn ohun ìní wa? Ṣé a máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? Ẹ tiẹ̀ wo bó ṣe máa rí nígbà yẹn, bíi ti wòlíì àtijọ́ náà, Dáníẹ́lì, àwa nìkan la ó máa sin Ọlọ́run nìṣó, láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí! (Dán. 6:10, 11) Ìgbà yẹn kọ́ ni àkókò láti wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run. Àkókò ìwàásù á ti kọjá. Àkókò “òpin” ohun gbogbo á ti sún mọ́lé. (Mát. 24:14) Ó dájú pé gbankọgbì ọ̀rọ̀ ìdájọ́ làwa èèyàn Ọlọ́run á máa kéde rẹ̀. Ó ṣeé ṣe ká máa polongo pé ayé búburú Sátánì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin pátápátá. w15 7/15 2:3, 8, 9
Sunday, October 15
Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.—Jòh. 17:16.
Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí ayé bá kórìíra wa torí pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, Jésù ti kìlọ̀ fún wa pé wọ́n máa kórìíra wa. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣàtakò sí wa ò mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Àmọ́ ní tiwa, ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a máa dúró gbọn-in nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò. (Dán. 3:16-18) Ìbẹ̀rù èèyàn máa ń nípa lórí tọmọdé tàgbà, àmọ́ ó lè ṣòro fún àwọn ọ̀dọ́ láti dá yàtọ̀ láàárín àwọn ojúgbà wọn. Bí àwọn ọmọ rẹ bá ń dojú kọ ìṣòro bíi kíkí àsíá tàbí àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè, má ṣe jáfara láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé, jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin kí wọ́n bàa lè fìgboyà kojú àwọn ìṣòro náà. Jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n á ṣe ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lọ́nà tó ṣe kedere àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Róòmù 1:16) O tún lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nípa bíbá àwọn olùkọ́ wọn jíròrò àwọn kókó yìí tó bá pọn dandan pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. w15 7/15 3:15, 16
Monday, October 16
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.—Jòh. 3:16.
Ọlọ́run fún wa ní ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ẹ̀bùn tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí kí a lè “jèrè ìyè.” (1 Jòh. 4:9) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí, ó sọ pé: “Kristi kú fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a yàn kalẹ̀. Nítorí èkukáká ni ẹnikẹ́ni yóò fi kú fún olódodo; ní tòótọ́, bóyá ni ẹnì kan á gbójúgbóyà láti kú fún ènìyàn rere. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:6-8) Ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ojúure Jèhófà. Jèhófà tipasẹ̀ ìràpadà náà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí gbogbo aráyé. Tó bá wù wá láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, tá a sì ń sin Jèhófà nìṣó láìyẹsẹ̀, ó dájú pé ìgbésí ayé wa máa ládùn nínú ayé tuntun. Ó bá a mu nígbà náà láti máa wo ìràpadà náà bí ẹ̀rí tó ga jù lọ pé Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa! w15 8/15 1:13, 15
Tuesday, October 17
Ẹ má . . . ba inú jẹ́.—Neh. 8:10.
Gbogbo ipá yòówù ká sà láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò Jèhófà ká sì máa bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wa kò tó àǹfààní tá a máa ní láti gbé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, ipò wa lè yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní kí àwọn kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ máa sìn ní pápá, wọ́n sì ń gbádùn ìbùkún rẹpẹtẹ nínú àwọn apá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mìíràn báyìí. Torí ara tó ti ń dara àgbà tàbí torí àwọn ìdí míì, wọ́n ti ní kí àwọn kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe báyìí. Tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, tá à ń gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, a máa láyọ̀, a sì máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà kódà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí. (Òwe 10:22) Àwọn ohun tá à ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú ńkọ́? Ó ṣeé ṣe ká ní apá ibi tá a fẹ́ gbé nínú ayé tuntun lọ́kàn, àmọ́ tí wọ́n bá sọ pé apá ibòmíì ni ká lọ ńkọ́? Ohun yòówù ká máa ṣe tàbí ibi yòówù ká máa gbé nínú ayé tuntun, ó dájú pé àá máa dúpẹ́, àá ní ìtẹ́lọ́rùn, inú wa á sì máa dùn. w15 8/15 3:8
Wednesday, October 18
[Nóà] fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀.—Jẹ́n. 6:9.
Inú ayé tí àwọn èèyàn ti ń hùwà ìkà ni Nóà gbé, torí náà kò wù ú rara láti fi wọ́n ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ó sì dájú pé Nóà ò wá bó ṣe máa bá àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́. Òun, aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn aya wọn mú kí ọwọ́ wọ́n dí lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́, tó fi mọ́ kíkan ọkọ̀ áàkì. Bí ìyẹn ṣe ń lọ lọ́wọ́, Nóà tún ń wàásù. Bíbélì pè é ní “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Iṣẹ́ ìwàásù tí Nóà ṣe, ọkọ̀ áàkì tó kàn àti àjọṣe tó wà láàárín òun àti ìdílé rẹ̀ mú kí ọwọ́ rẹ̀ dí, kó sì máa ṣe àwọn nǹkan tó múnú Ọlọ́run dùn. Látàrí èyí, Nóà àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún-omi náà já. Àfi ká máa dúpẹ́ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ sin Jèhófà, torí pé àtọmọdọ́mọ wọn ni gbogbo àwa tá à ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Bákan náà, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àti onígbọràn kò bá àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ wọ́n sì la ìparun Jerúsálẹ́mù àti ti ètò àwọn nǹkan àwọn Júù já ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni.—Lúùkù 21:20-22. w15 8/15 4:17, 18
Thursday, October 19
Ìgbà rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri [wà]. —Oníw. 3:4.
Kì í ṣe gbogbo eré ọwọ́dilẹ̀ ló ṣàǹfààní, gbogbo rẹ̀ kọ́ ló ń fára nísinmi tó sì ń mára tuni. Bákan náà, kò yẹ ká máa pẹ́ jù nídìí eré ìtura tàbí ká máa ṣe é ní àṣejù. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbádùn eré ìtura kó sì ṣe wá láǹfààní? Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ohun kan tó pè ní “iṣẹ́ ti ara.” Lára wọn ni “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” Pọ́ọ̀lù wá sọ pé “àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gál. 5:19-21) Látàrí èyí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé ẹ̀rí ọkàn mi kì í fàyè gba àwọn eré ìdárayá táwọn èèyàn ti ń hùwà jàgídíjàgan, tí wọ́n ń bára wọn díje, tí wọ́n ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè lárugẹ, tàbí tí wọ́n ń hùwà ipá? Ṣé ẹ̀rí ọkàn mi sì máa ń kìlọ̀ fún mi nígbà tí mo bá fẹ́ wo àwọn fíìmù tó ní àwòrán oníhòòhò, ìṣekúṣe, ìmutípara tàbí ìbẹ́mìílò nínú?’ w15 9/15 2:11, 12
Friday, October 20
Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.—Jer. 10:23.
Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa dá ṣèpinnu tàbí ká wà láì gbára lé Ọlọ́run, tá ò bá fara mọ́ òtítọ́ yìí, ohun búburú ló máa tìdí ẹ̀ yọ. Ó ṣe pàtàkì ká gbà pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn tá a bá fẹ́ máa láyọ̀. Ó dìgbà tá a bá gbà pé Ọlọ́run láṣẹ lórí wa, ká tó lè ní àlààfíà ká sì wà ní ìṣọ̀kan. Torí náà, àfi ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ ká mọ àwọn ohun pàtàkì yìí! Ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ máa ń jẹ bàbá wọn lógún, ó sì máa ń wù ú pé kí wọ́n ní ohun tó dáa àti ohun tó nítumọ̀ tí wọ́n á fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, tàbí kí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn lépa àwọn ohun tí kò ní láárí. (Sm. 90:10) Torí pé ọmọ Ọlọ́run ni wá, a mọ̀ pé òótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ṣèlérí ọjọ́ ọ̀la tó lárinrin fún wa. Èyí ló mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. w15 9/15 4:10, 11
Saturday, October 21
Kì yóò sí ìrì tàbí òjò . . . bí kò ṣe nípa àṣẹ ọ̀rọ̀ mi!—1 Ọba 17:1.
Nígbà àtijọ́, àwọn èèyàn láǹfààní láti rí bí Ọlọ́run ṣe gbèjà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì gbọ́ nípa rẹ̀. Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Íjíbítì lọ́nà ìyanu, lẹ́yìn náà wọ́n ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ àwọn ọba. (Jóṣ. 9:3, 9, 10) Àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì ò gbà pé Ọlọ́run ló ń jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí ló sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun wọn. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lẹ́yìn náà mú kó ṣeé ṣe fún Áhábù Ọba búburú láti rí ọwọ́ Ọlọ́run. Áhábù rí bí iná ṣe já bọ́ láti ọ̀run nígbà tí Èlíjà gbàdúrà pé kí iná jẹ ọrẹ ẹbọ òun run. Lẹ́yìn náà, Èlíjà sọ fún Áhábù pé Jèhófà máa fòpin sí ọ̀dá náà, ó sì tún sọ fún un pé: “Sọ̀ kalẹ̀ lọ kí eji wọwọ má bàa dá ọ dúró!” (1 Ọba 18:22-45) Áhábù rí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, síbẹ̀ ó kọ̀ láti gbà pé agbára ńlá Ọlọ́run ló mú kí èyí ṣeé ṣe. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àtàwọn àpẹẹrẹ míì kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa mọ̀ bí Jèhófà bá ṣe ohun tó lè mú ká rí ọwọ́ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. w15 10/15 1:4, 5
Sunday, October 22
Olódodo yóò wà láàyè nítorí ìgbàgbọ́.—Gál. 3:11.
Ó yẹ kó dá wa lojú pé tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹni tó dájú pé ó lè ràn wá lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé Ọlọ́run ni “ẹni tí ó lè ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò, ní ìbámu pẹ̀lú agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.” (Éfé. 3:20) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè ṣèfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ torí pé wọ́n mọ ibi tí agbára wọ́n mọ, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á bù kún ìsapá wọn. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Ọlọ́run wa kò ní fi wá sílẹ̀? Jèhófà máa fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i “tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀.” (1 Jòh. 5:14) Ó ṣe kedere pé inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Jèhófà máa fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i tá a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, ìyẹn á sì mú kó ‘kà wá yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.’—2 Tẹs. 1:3, 5. w15 10/15 2:16-18
Monday, October 23
Má ṣe sú lọ láé.—Héb. 2:1.
Tá a bá ń ṣàṣàrò nípa Jèhófà àti Jésù, òtítọ́ á jinlẹ̀ nínú wa. (Héb. 5:14; 6:1) Bí àkókò tí ẹnì kan ń lò láti ṣàṣàrò nípa Jèhófà àti Jésù ò bá tó nǹkan, ìgbàgbọ́ rẹ̀ á jó rẹ̀yìn. Ó ṣeé ṣe kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sú lọ díẹ̀díẹ̀ tàbí kó lọ kúrò nínú òtítọ́. (Héb. 3:12) Jésù kìlọ̀ fún wa pé tá ò bá gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí ká gbà á “pẹ̀lú ọkàn-àyà àtàtà àti rere,” a ò ní lè “dì í mú ṣinṣin.” “Àwọn àníyàn àti ọrọ̀ àti adùn ìgbésí ayé yìí” lè gbé wa lọ, a ò sì ní lè mú “nǹkan kan wá sí ìjẹ́pípé.” (Lúùkù 8:14, 15) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí á mú ká máa gbé ògo Jèhófà yọ, ká sì fìwà jọ ọ́. (2 Kọ́r. 3:18) Àfi ká máa dúpẹ́ pé a láǹfààní láti mọ Ọlọ́run àti pé ó jẹ́ ká máa gbé ògo òun yọ. Bá a ṣe ń bá a nìṣó láti fìwà jọ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, títí láé la ó máa ní ìmọ̀ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀, tá ó sì máa gbé ògo rẹ̀ yọ.—Oníw. 3:11. w15 10/15 4:13, 14
Tuesday, October 24
Ọgbọ́n [dáa] fún ọkàn rẹ. Bí ìwọ bá ti wá a rí, nígbà náà, ọjọ́ ọ̀la yóò wà.—Òwe 24:14.
Gẹ́gẹ́ bí òbí, ó dájú pé ẹ kò ní fẹ́ kí àjọṣe táwọn ọmọ yín ní pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Ọlọ́run sì fẹ́ kẹ́ ẹ tọ́ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ẹ̀yin òbí ni Ọlọ́run gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín, torí náà ẹ ṣe iṣẹ́ yín bí iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, torí pé ẹ mọ̀ pé ẹ̀kọ́ dára ẹ sì fẹ́ kí wọ́n fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lẹ ṣe ń rán wọn lọ síléèwé. Bákan náà, àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ń lọ sípàdé, wọ́n sì máa ń rí i dájú pé wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run káwọn ọmọ wọn lè jàǹfààní látinú “ìlànà èrò orí Jèhófà.” Torí pé ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì, ó yẹ kẹ́yin òbí ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, kí wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè fún àwọn lọ́gbọ́n. Bíi ti Jésù, ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jáde òde ẹ̀rí déédéé kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù. w15 11/15 2:6
Wednesday, October 25
Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 11:3.
Ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an nínú ètò Ọlọ́run torí pé ìlànà ipò orí là ń tẹ̀ lé. Àmọ́, kò yẹ káwọn tó wà ní ipò orí jẹ́ apàṣẹwàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ ni orí aya, Bíbélì sọ pé kí àwọn ọkọ máa “fi ọlá fún” àwọn aya wọn. (1 Pét. 3:7) Ọ̀kan lára ọ̀nà táwọn ọkọ lè gbà bọlá fún àwọn aya wọn ni pé kí wọ́n mọ ohun tí aya wọn nílò kí wọ́n sì máa gba tiwọn rò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:25) Kódà, Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ débi pé ó kú fún wọn. Tí ọkọ kan bá ń fìfẹ́ lo ipò orí rẹ̀ bí Jésù ti ṣe, ó máa túbọ̀ rọrùn fún aya rẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un, kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì tẹrí ba fún un.—Títù 2:3-5. w15 11/15 4:6, 7
Thursday, October 26
Ìkùnsínú dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì lòdì sí àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù.—Ìṣe 6:1.
Bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń gbilẹ̀ sí i, èdè Gíríìkì ni àwọn Kristẹni ń sọ jù lọ láàárín ara wọn. Kódà, èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lọ́wọ́. Torí náà, èdè Gíríìkì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń sọ nígbà yẹn dípò èdè Hébérù. Èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ àwọn lẹ́tà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn Ìwé Mímọ́ míì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lọ́wọ́ nígbà yẹn. Inú Bíbélì Septuagint ni àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì ti sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ tí wọ́n bá fẹ́ tọ́ka sí àwọn ẹsẹ kan nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn òǹkọ̀wé yìí fà yọ látinú Bíbélì Septuagint wá di ara Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí, bó tílẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ náà lè yàtọ̀ díẹ̀ sí bí wọ́n ṣe kọ ọ́ lédè Hébérù. Ìtumọ̀ tí àwọn atúmọ̀ èdè aláìpé yìí ṣe wá di ara àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí, níwọ̀n bó ti jẹ́ Ọlọ́run tí kì í gbé èdè tàbí ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ.—Ìṣe 10:34. w15 12/15 1:8, 9
Friday, October 27
Jèhófà, kí o ṣí ètè tèmi yìí, kí ẹnu mi lè máa sọ ìyìn rẹ jáde.—Sm. 51:15.
Ojoojúmọ́ la máa ń sọ̀rọ̀, àmọ́ kò pọn dandan ká máa sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà. Kódà, Bíbélì sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà. (Oníw. 3:7) Tá a bá dákẹ́ nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn. (Jóòbù 6:24) Bákan náà, tá a bá ń pa ọ̀rọ̀ àṣírí tá a mọ̀ nípa rẹ̀ mọ́, ìyẹn á tún fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n àti olóye. (Òwe 20:19) Tí ẹnì kan bá sì mú inú bí wa, ìwà ọgbọ́n ló máa jẹ́ tá a bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ láì sọ ohunkóhun. (Sm. 4:4) Bákan náà, Bíbélì tún sọ pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:7) Ó dájú pé tí ọ̀rẹ́ rẹ bá fún ọ lẹ́bùn tó o fẹ́ràn gan-an, o ò kàn ní lọ wá ibì kan jù ú sí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lo máa lo ẹ̀bùn náà dáadáa kí ọ̀rẹ́ rẹ lè mọ̀ pé o mọrírì rẹ̀. Ó yẹ ká mọrírì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Jèhófà fún wa, ká máa lò ó lọ́nà tó dáa. Oríṣiríṣi ọ̀nà la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, bí àpẹẹrẹ, a lè yin Ọlọ́run lógo, a lè gbé àwọn ẹlòmíì ró, a lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa ká sì sọ àwọn nǹkan tá a nílò fún àwọn ẹlòmíì. w15 12/15 3:4, 5
Saturday, October 28
Má mu omi mọ́, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí àpòlúkù rẹ àti ọ̀ràn àìsàn rẹ tí ó ṣe lemọ́lemọ́.—1 Tím. 5:23.
Lónìí, a ò lè retí pé kí àwọn Kristẹni bíi tiwa máa fi “ẹ̀bùn ìmúniláradá” wò wá sàn. (1 Kọ́r. 12:9) Àmọ́, àwọn ará kan tó ní ire wa lọ́kàn máa ń fún wa nímọ̀ràn nípa ìlera wa bá ò tiẹ̀ béèrè pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, ẹnì kan lè sọ pé ká ṣe ohun kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ dáadáa. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn nígbà tí Tímótì ní àìsàn inú, bóyá torí pé omi tó wà ládùúgbò wọn ò dáa. Ìyẹn yàtọ̀ sí pé ká máa rọ àwọn ará pé kí wọ́n lo egbòogi tàbí ògùn kan tàbí pé kí wọ́n máa jẹ irú àwọn oúnjẹ kan. Àwọn egbòogi tàbí oúnjẹ yìí sì lè má ṣiṣẹ́ kankan lára wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ léwu. Nígbà míì, àlàyé táwọn kan máa ń ṣe ni pé: ‘Irú àìsàn yìí ti ṣe ẹbí mi kan rí, ògùn báyìí báyìí ló lò, ara ẹ sì ti yá.’ Bó ti wù kí àbá náà jóòótọ́ tó, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ìtọ́jú táwọn èèyàn máa ń gbà tàbí ògùn tí wọ́n máa ń lò dáadáa lè léwu nígbà míì.—Òwe 27:12. w15 12/15 4:13
Sunday, October 29
Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ láìtún kú mọ́ láé, olódodo fún àwọn aláìṣòdodo.—1 Pét. 3:18.
Gbogbo wa la jogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ádámù, ikú sì ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa mú kó rán Jésù wá sáyé láti kú fún wa, kó lè “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn.” (Héb. 2:9) Àmọ́, ẹbọ ìràpadà Jésù máa ṣe ju ìyẹn lọ. Ó máa gbé ikú mì títí láé. (Aísá. 25:7, 8; 1 Kọ́r. 15:22, 26) Gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa láyọ̀, wọ́n á sì máa gbé lálàáfíà títí láé, yálà wọ́n wà lára àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run tàbí lára àwọn tí yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Róòmù 6:23; Ìṣí. 5:9, 10) Àwọn ìbùkún míì wo ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí máa mú wá? Lára ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa ni pé ilẹ̀ ayé á di Párádísè, ara àwọn aláìsàn á yá, àwọn òkú á sì jíǹde. (Aísá. 33:24; 35:5, 6; Jòh. 5:28, 29) A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n torí ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ tí wọ́n fún wa.—2 Kọ́r. 9:15. w16.01 2:5, 6
Monday, October 30
A gbọ́dọ̀ tún yín bí.—Jòh. 3:7.
Kí Jèhófà tó fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí láti lọ sọ́run, wọ́n ti nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Wọ́n ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò táá sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Wọ́n tiẹ̀ ti lè máa fojú inú yàwòrán bí wọ́n á ṣe kí ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ wọn kan tó jíǹde káàbọ̀ sínú ayé tuntun. Wọ́n lè ti máa fojú inú wo ara wọn bíi pé àwọn ti ń kọ́ ilé, àwọn sì ti ń gbé inú rẹ̀, tàbí pé àwọn ti ń gbin igi àwọn sì ti ń jẹ èso rẹ̀. (Aísá. 65:21-23) Àmọ́ kí ló dé tí ìrònú wọn fi wá yí pa dà? Ṣé torí pé nǹkan tojú sú wọn ni àbí torí pé wọ́n ti fìyà jẹ wọ́n jù? Ṣé wọ́n kàn ṣàdéédéé pinnu pé ayé yìí ò dùn mọ́ ni àti pé á sú àwọn táwọn bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé? Àbí ṣe ló kàn bẹ̀rẹ̀ sí í wù wọ́n láti lọ wo bí nǹkan á ṣe rí táwọn bá ń gbé lọ́run? Rárá, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀! Ọlọ́run ló yàn fún wọn, àwọn kọ́ ló yàn fúnra wọn. Nígbà tí Ọlọ́run yàn wọ́n, ó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yí bí wọ́n ṣe ń ronú pa dà, ó sì tún yí èrè tí wọ́n á máa fojú sọ́nà fún pa dà. w16.01 3:11, 13
Tuesday, October 31
Ní bíbá a ṣiṣẹ́ pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.—2 Kọ́r. 6:1.
Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ. Òun ló dá ohun gbogbo, ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ ò sì láàlà. Lẹ́yìn tí Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù lóye òtítọ́ yìí, Jóòbù sọ fún Jèhófà pé: ‘Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo, kò sì sí èrò-ọkàn kankan tí ó jẹ́ aláìṣeélébá fún ọ.’ (Jóòbù 42:2) Jèhófà lè ṣe ohunkóhun tó bá pinnu láti ṣe láì tiẹ̀ pe ẹnikẹ́ni sí i. Àmọ́ torí pé ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó pe àwọn míì kí wọ́n wá bá òun ṣiṣẹ́ láti mú àwọn ìpinnu òun ṣẹ. Kí Jèhófà tó dá ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míì ló ti dá Jésù, Ọmọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ló wá fún Ọmọ rẹ̀ yìí láǹfààní láti dá gbogbo ohun tó kù. (Jòh. 1:1-3, 18) Torí náà, kì í ṣe pé Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ yìí níṣẹ́ pàtàkì láti ṣe nìkan ni, ó tún jẹ́ káwọn míì mọ iṣẹ́ pàtàkì tó gbé lé e lọ́wọ́. Àǹfààní ńlá mà nìyẹn o!—Kól. 1:15-17. w16.01 5:1, 2