November
Wednesday, November 1
Ábúráhámù gbẹ́mìí mì, ó sì kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an, ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Jẹ́n. 25:8.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ábúráhámù ò fẹ́ gbé nínú ayé tuntun. Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 11:10) Fojú inú wo bí inú Ábúráhámù á ṣe dùn tó nígbà tó bá ń gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé tó sì ń mú kí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run máa lágbára sí i. Inú rẹ̀ á dùn gan-an láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ń ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́! Nínú Párádísè ló ti máa mọ̀ pé ohun ńlá kan ni ẹbọ tóun rú lórí Òkè Móráyà dúró fún. (Héb. 11:19) Ó sì tún máa mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tó ní nígbà tó fẹ́ fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ ṣe ran ọ̀pọ̀ olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe dun Jèhófà tó nígbà tó fi Jésù Kristi Ọmọ Rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún aráyé.—Jòh. 3:16. w16.02 1:15, 16
Thursday, November 2
Ìwọ ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti ọlọ̀tẹ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, èmi kò ha mọ̀ dáadáa pé ìwọ ń yan ọmọkùnrin Jésè sí ìtìjú ara rẹ àti sí ìtìjú apá ìkọ̀kọ̀ ìyá rẹ?—1 Sám. 20:30.
A lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà kódà bí arákùnrin kan tó ń múpò iwájú bá hùwà tí ò dáa sí wa. Ọlọ́run ló yan Sọ́ọ̀lù ọba sípò, síbẹ̀ Sọ́ọ̀lù fi ojú ọmọ òun fúnra ẹ̀ rí màbo. Sọ́ọ̀lù ò mọ ìdí tí Jónátánì fi fẹ́ràn Dáfídì tó bẹ́ẹ̀. Torí náà, nígbà tí Jónátánì gbìyànjú láti ran Dáfídì lọ́wọ́, Sọ́ọ̀lù gbaná jẹ, ó sì tún dójú ti Jónátánì lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Síbẹ̀, Jónátánì ṣì bọ̀wọ̀ fún bàbá rẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jónátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti sí Dáfídì tí Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. (1 Sám. 20:31-41) Nínú àwọn ìjọ wa lónìí, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú máa ń gbìyànjú láti gbọ́ ti gbogbo èèyàn tó wà nínú ìjọ. Àmọ́, aláìpé làwọn arákùnrin yìí, wọ́n sì lè máà lóye ìdí tá a fi ṣe nǹkan tá a ṣe nígbà míì. (1 Sám. 1:13-17) Torí náà, tí wọ́n bá ṣì wá lóye, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. w16.02 3:14, 15
Friday, November 3
Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀.—Mát. 16:24.
Àwọn ọ̀dọ́ kan lè má mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Àwọn kan lè sọ pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà àmọ́ àwọn ò tíì ṣe tán láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, ṣé irú ẹ̀ ṣeé ṣe? Ìyàsímímọ́ ni àdúrà tó o gbà láti ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá máa sìn ín títí láé. Tó o bá wá ṣèrìbọmi làwọn èèyàn á tó mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Torí náà, kó o tó ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o sọ fún un pé o ti di tiẹ̀ báyìí. O ṣèlérí pé ìjọsìn Ọlọ́run ni nǹkan tó máa ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ìlérí tó o bá Ọlọ́run ṣe yìí kì í ṣe ohun tó yẹ kó o fọwọ́ yẹpẹrẹ mú.—Mát. 5:33. w16.03 1:14, 15
Saturday, November 4
Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo.—Éfé. 4:15.
Pọ́ọ̀lù lo àwọn ẹ̀yà ara láti ṣe àpèjúwe pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan lè pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ kí gbogbo wọn lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ. Ó sọ pé gbogbo ẹ̀yà ara máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ “nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò.” (Éfé. 4:16) Torí náà, kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe, yálà a jẹ́ ọmọdé àbí àgbàlagbà, yálà a ní ìlera tó dáa tàbí a jẹ́ aláìlera? Jésù yàn àwọn alàgbà láti máa múpò iwájú nínú ìjọ, ó sì fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa. (Héb. 13:7, 17) Èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Àmọ́, a lè bẹ Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni táwọn alàgbà ń fún wa. Tún ronú nípa àǹfààní tó máa ṣe ìjọ tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà. Ìjọ á wà ní ìṣọ̀kan, ìfẹ́ tá a ní síra wa nínú ìjọ á sì túbọ̀ lágbára. w16.03 3: 8, 9
Sunday, November 5
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.—Héb. 4:12.
Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ń dàgbà, kò sẹ́ni tó fún wọn níṣìírí láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ kò fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn. (Mát. 10:24) Torí náà, ó yẹ kí alàgbà kan wá àyè láti di ọ̀rẹ́ arákùnrin tó ń sapá láti nífẹ̀ẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Bó ṣe ń dá a lẹ́kọ̀ọ́, kó jẹ́ kó mọ̀ pé a nílò rẹ̀ nínú ìjọ. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, kí alàgbà náà pẹ̀lú arákùnrin náà jọ jókòó sọ̀rọ̀, kí ó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pàtó, kó sì ràn án lọ́wọ́ láti ronú nípa ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà. (Oníw. 5:4; Aísá. 6:8; Mát. 6:24, 33; Lúùkù 9:57-62; 1 Kọ́r. 15:58; 2 Kọ́r. 5:15; 13:5) Alàgbà yẹn lè bi í pé, ‘Ìlérí wo lo ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún un?’ Kó lè dé ọkàn rẹ̀, o lè bi í pé, ‘Báwo lo ṣe rò pé ó rí lára Jèhófà nígbà tó o ṣe ìrìbọmi?’ (Òwe 27:11) ‘Báwo ló ṣe rí lára Sátánì?’ (1 Pét. 5:8) Káwọn alàgbà má ṣe fojú kéré ipa tí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n fara balẹ̀ yàn tí wọ́n sì kà fún arákùnrin náà lè ní lórí rẹ̀. w15 4/15 2:9, 11
Monday, November 6
Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.—1 Pét. 5:7.
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà wa ni Jèhófà máa ń dáhùn lójú ẹsẹ̀? Má gbàgbé pé Ọlọ́run fi àjọṣe àwa àti òun wé àjọṣe tó máa ń wà láàárín ọmọ àti baba. (Sm. 103:13) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan ò le retí pé kí òbí òun fún òun ní gbogbo nǹkan tí òun bá ṣáà ti béèrè tàbí kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà míì ọmọdé lè béèrè ohun kan torí ó kàn wù ú. Àwọn nǹkan míì sì máa gba pé kí ọmọ náà ṣe sùúrù díẹ̀ títí ó fi máa tó àkókò lójú òbí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọ náà lè béèrè nǹkan míì tó lè ṣe ìpalára fún un tàbí kó ṣàkóbá fún àwọn ẹlòmíì. Síwájú sí i, tó bá jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni òbí kan máa ń fún ọmọ rẹ̀ ní gbogbo ohun tó bá béèrè, a jẹ́ pé òbí náà ti di ẹrú ọmọ náà nìyẹn, ọmọ náà sì ti di ọ̀gá. Bákan náà, Jèhófà lè rí i pé ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù ni pé kí àkókò díẹ̀ kọjá kó tó dáhùn àwọn àdúrà kan. Òun ló láṣẹ láti ṣèpinnu yẹn torí pé òun ní Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, Ọ̀gá tó nífẹ̀ẹ́ wa àti Baba wa ọ̀run. Tó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan tá à ń béèrè náà ni Jèhófà ń ṣe fún wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ìyẹn lè sọ àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín wa dìdàkudà.—Aísá. 29:16; 45:9. w15 4/15 4:6, 7
Tuesday, November 7
Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.—Ják. 4:7.
Bí a ti ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, àwa náà ń gbé ní àkókò tó le. Sátánì ń fẹ́ kí àwa náà dẹra nù, “kí á ṣàánú” ara wa kí á máa wá ibi tó tutù nínú ayé yìí láti fara pa mọ́ sí, tá ò sì ní lè wà lójúfò mọ́. Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ láé! Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘máa ṣọ́nà.’ (Mát. 16:22, 23; 24:42) Má ṣe gba ìpolongo ẹ̀tàn Sátánì gbọ́ pé òpin ayé ò tíì lè dé báyìí tàbí pé kò tiẹ̀ ní dé rárá. Sátánì ń gbìyànjú láti mú ká rò pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ò ní ìdáríjì. Gbogbo ìyẹn jẹ́ ara ìpolongo ẹ̀tàn látọ̀dọ̀ Sátánì. Ó ṣe tán, ta lẹni náà gan-an tí Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́? Sátánì ni. Ta lẹni náà gan-an tí ò lè rí ìdáríjì? Sátánì náà ni. Àmọ́, Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Jèhófà mọrírì ìsapá wa bi á ti ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ ìsìn wa kò sì já sásán. (1 Kọ́r. 15:58) Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ìpolongo Sátánì tàn wá jẹ. w15 5/15 1:16-19
Wednesday, November 8
Wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n.—Héb. 11:13.
Ábúráhámù ti rí ẹ̀rí tó pọ̀ rẹpẹtẹ tó jẹ́ kó gbà pé ohun tó ń retí lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹlẹ̀, àfi bíi pé ó rí ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú! Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run mú kó túbọ̀ tẹra mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Torí ìgbàgbọ́ tó ní, ó kúrò ní ìlú Úrì, kò sì jókòó pa sí èyíkéyìí nínú àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì. Àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì dà bí ìlú Úrì, wọn ò láyọ̀lé torí pé àwọn alákòóso wọn ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. (Jóṣ. 24:2) Ní gbogbo ọjọ́ gígún tí Ábúráhámù fi gbé láyé ló fi ń “dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 11:10) Ábúráhámù “rí” ara rẹ̀ bíi pé ó ti wà ní ibì kan tí yóò máa gbé títí láé, èyí tí Jèhófà ń ṣàkóso rẹ̀. Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ bíi tiwọn nígbàgbọ́ pé àwọn òkú máa jíǹde, wọ́n sì ń retí ìgbà tí wọ́n á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́.” Bí wọ́n ṣe fọkàn yàwòrán irú àwọn ìbùkún yìí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.—Héb. 11:15, 16. w15 5/15 3:8, 9
Thursday, November 9
Kristi [ni] agbára Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 1:24.
Jèhófà fi agbára rẹ̀ hàn láwọn ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe àlàyé fún wa nípa mélòó kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, èyí sì máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Ó ṣeé ṣe kí Jésù tún ṣe àwọn iṣé ìyanu míì. (Mát. 9:35; Lúùkù 9:11) Dájúdájú, ohun tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí bí agbára Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa rẹ̀ pé: “Kristi [ni] agbára Ọlọ́run.” Àmọ́, ipa wo ni àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù lè ní lórí wa? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tàbí “àmì àgbàyanu.” (Ìṣe 2:22) Kékeré ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣe nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ ìyanu tó máa gbé ṣe kárí ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run! Bákan náà, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti ti Baba rẹ̀. w15 6/15 1:1, 2
Friday, November 10
Ó ń sọ ṣáá pé: “Bí mo bá fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi yóò dá.”—Máàkù 5:28.
Bí Jésù ti mọ̀ pé Baba òun, ìyẹn Jèhófà ló mú obìnrin náà lára dá, ó fi pẹ̀lẹ́tù bá a sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” (Máàkù 5:34) Tẹ̀gàn ni hẹ̀, onínúure ẹ̀dá ni Jésù! A ti rí i pé ó máa ń káàánú àwọn tí àìsàn ń bá fínra. Sátánì fẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe mú kó ṣe kedere sí wa pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa dénúdénú àti pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro wa. Ẹ ò rí i pé Àlùfáà Àgbà àti Ọba wa yìí lójú àánú! (Héb. 4:15) A lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ́ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó ń ṣàìsàn kan tó le koko, pàápàá bí irú àìsàn bẹ́ẹ̀ kò bá tíì ṣe wá rí. Ṣùgbọ́n, kò yẹ ka gbàgbé pé Jésù káàánú àwọn tó ń ṣàìsàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣàìsàn rí. Ǹjẹ́ kí àpẹẹrẹ Jésù mú káwa náà ṣe ohun kan náà, débi tí agbára wa gbé e dé.—1 Pét. 3:8. w15 6/15 2:11, 12
Saturday, November 11
Orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.—Róòmù 2:24.
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a ò kàn mọ orúkọ Ọlọ́run nìkan, a tún ń jẹ́ orúkọ náà gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 15:14; Aísá. 43:10) À ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run pé: “Kí orúkọ [rẹ̀] di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Ẹ̀bẹ̀ yìí lè mú kó o sọ fún Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o máa bàa sọ tàbí ṣe ohunkóhun tó máa tàbùkù sí orúkọ rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́. A ò fẹ́ dà bí àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní tí ìwà wọn yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ń wàásù, bó ṣe wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. Kí la nílò kí orúkọ Ọlọ́run tó lè di mímọ́ pátápátá, tí kò sì ní sí ẹ̀gàn kankan lórí orúkọ rẹ̀ mọ́? Kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀, ó pọn dandan pé kí Jèhófà mú gbogbo àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ kẹ̀yìn sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kúrò. (Ìsík. 38:22, 23) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, aráyé yóò di ẹ̀dá pípé. À ń fojú sọ́nà fún àkókò kan tí gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì yóò máa ṣe ohun tó fi hàn pé orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́! Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò “jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́r. 15:28. w15 6/15 4:7, 10
Sunday, November 12
Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.—Aísá. 66:1.
Nínú Bíbélì, ayé nìkan kọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, “àpótí ìtìsẹ̀” túmọ̀ sí. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tún lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti ṣàpèjúwe tẹ́ńpìlì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbà àtijọ́. (1 Kíró. 28:2; Sm. 132:7) Ayé ni tẹ́ńpìlì náà wà, ibẹ̀ làwọn èèyàn sì máa ń péjọ sí láti sin Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi lẹ́wà gan-an lójú Jèhófà, wíwà rẹ̀ sì ṣe ayé tó jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ Jèhófà lógo. (Aísá. 60:13) Lónìí, àwọn èèyàn ò péjọ láti sin Ọlọ́run tòótọ́ nínú tẹ́ńpìlì tá a fi ọwọ́ kọ́ mọ́. Àmọ́, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kan wà tó ń fi ògo fún Jèhófà ju ilé èyíkéyìí lọ. Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí ni ètò tó mú ká lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ Jésù Kristi tó jẹ́ àlùfáà àti nípasẹ̀ ẹbọ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, tí Jèhófà sì fi ẹ̀mí yàn án gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí náà.—Héb. 9:11, 12. w15 7/15 1:1-3
Monday, November 13
Wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.—Lúùkù 21:27.
Ìgbà yẹn ló máa san èrè fún àwọn olóòótọ́ tó sì máa fi ìyà jẹ àwọn aláìṣòótọ́. (Mát. 24:46, 47, 50, 51; 25:19, 28-30) Bí Mátíù ṣe sọ, àmì kan tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ni Jésù fi parí àkàwé tó ṣe nípa àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́. Ó ní: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóò sì fi àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.” (Mát. 25:31-33) Ìdájọ́ wo ló máa kéde sórí àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́? Ó parí àkàwé náà pé: “Àwọn wọ̀nyí [àwọn ewúrẹ́] yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mát. 25:46. w15 7/15 2:11, 12
Tuesday, November 14
Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!—Sm. 133:1.
Òótọ́ ni pé a lè nífẹ̀ẹ́ ilẹ̀, àṣà, èdè àti oúnjẹ tó wà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa ronú pé ohun tá a bá nífẹ̀ẹ́ sí ló dáa jù. Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn onírúurú nǹkan tó dá. (Sm. 104:24; Ìṣí. 4:11) Kí nìdí tá ó fi máa ronú pé ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan ló sàn ju tí àwọn míì lọ? Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo onírúurú èèyàn ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ kí wọ́n sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16; 1 Tím. 2:3, 4) Tá a bá gbà pé bí èrò kan tiẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa, ìyẹn ò fi dandan sọ pé kò tọ̀nà, ó máa ṣe wá láǹfààní, á sì jẹ́ ká lè máa wà ní ìṣọ̀kan. Bá a ti ń bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a kò gbọ́dọ̀ máa dá sí awuyewuye tó ń lọ nínú ayé. Kò sí àyè fún kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láàárín wa. Ẹ sì wo bó ṣe yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó pé Jèhófà ti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀mí ìgbéraga, ẹ̀mí ìdíje àti ìyapa tó kún inú ayé Sátánì! w15 7/15 3:17, 18
Wednesday, November 15
[Ọlọ́run] bìkítà fún yín.—1 Pét. 5:7.
Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa tá a bá ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14; 28:19, 20) A tún lè fi hàn pé òótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò tá ò sì jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. (Sm. 84:11; Ják. 1:2-5) Bí àdánwò tó dé bá wa bá ń peléke sí i, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run mọ ìṣòro tá à ń dojú kọ, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ torí pé a ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Sm. 56:8) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a máa ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó dá àtàwọn ohun àgbàyanu míì tó ti ṣe. À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé a fi ọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ń jẹ́ ká gbàdúrà sí i ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bá a sì ṣe ń ronú lórí ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè torí ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìfẹ́ tá a ní sí i á máa jinlẹ̀ sí i. (1 Jòh. 2:1, 2) Gbogbo ohun tá a ti jíròrò yìí jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa. w15 8/15 1:6, 17, 18
Thursday, November 16
[Ó sàn láti jẹ́] onísùúrù.—Oníw. 7:8.
Nínú ayé tuntun, àwọn nǹkan míì lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká ní sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbọ́ pé àwọn kan ti jíǹde tí inú àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn sì ń dùn, ṣùgbọ́n kí àwa má tíì rí àwọn èèyàn wa tó ti kú. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé a máa bá wọn yọ̀ ká sì ní sùúrù? (Róòmù 12:15) Tó bá ti mọ́ wa lára láti máa ní sùúrù kí àwọn ìlérí Jèhófà tó ní ìmúṣẹ nísinsìnyí, àá lè máa ní sùúrù nígbà yẹn. A tún lè múra sílẹ̀ de ayé tuntun nípa níní sùúrù bí ìyípadà bá dé bá òye tá a ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Ṣé a máa ń fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́, ṣé a sì ń ní sùúrù bí òye tá a ní nípa Bíbélì ṣe ń ṣe kedere sí i ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kò ní ṣòro fún wa láti máa ní sùúrù nínú ayé tuntun bí Jèhófà bá ṣe ń sọ ohun tó fẹ́ ká ṣe di mímọ̀.—Òwe 4:18; Jòh. 16:12. w15 8/15 3:9,10
Friday, November 17
Dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.—Éfé. 4:13.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé ó yẹ kí wọ́n máa dàgbà nípa tẹ̀mí. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, títí tí wọ́n á fi di géńdé ọkùnrin, tí wọ́n á fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.’ (Éfé. 4:13) Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Éfésù sílẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀ ti dàgbà dénú dáadáa nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ó yẹ kí àwọn kan nínú wọn mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí náà nìyẹn. Ọjọ́ pẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń sin Ọlọ́run, wọ́n sì ti dàgbà dénú dáadáa nípa tẹ̀mí. Àmọ́, ó dájú pé àwọn kan ṣì ní láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹni tuntun ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún, torí náà àwọn kan ṣì ní láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i. Ìwọ ńkọ́?—Kól. 2:6, 7. w15 9/15 1:2, 3
Saturday, November 18
Ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.—1 Tím. 4:8.
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé téèyàn bá ń ṣeré ìdárayá níwọ̀nba, ó máa ń ṣara lóore, ó máa ń mára tuni, ó sì máa ń fini lọ́kàn balẹ̀. Àmọ́, ṣé ẹnikẹ́ni la lè bá ṣeré ìdárayá? Ìwé Òwe 13:20 sọ fún wa pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn pó yẹ ká ṣọ́ra tá a bá fẹ́ yan eré ìtura, ká sì jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ máa tọ́ wa sọ́nà? Ó tún yẹ ká ronú lórí ìgbà tó yẹ ká máa ṣeré ìtura. Ǹjẹ́ o máa ń fi àwọn ìgbòkègbodò bí ìpàdé, òde ẹ̀rí, àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Àbí àkókò tó yẹ kó o lò fún ìjọsìn Ọlọ́run lo fi ń ṣeré ìtura? Àwọn nǹkan wo lo fi sípò àkọ́kọ́? Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:33) Ǹjẹ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ máa ń sún ẹ láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ bí Jésù ṣe sọ? w15 9/15 2:13, 15
Sunday, November 19
Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? . . . Ìwọ yóò ha sì kápá [ẹ̀ṣẹ̀] bí?—Jẹ́n. 4:6, 7.
Ọlọ́run fún Kéènì ní ìmọ̀ràn tó bọ́ sákòókò àti ìtọ́sọ́nà tó wúlò. Lọ́nà yìí, Jèhófà kìlọ̀ fún Kéènì nígbà tó rí i pé ó ti fẹ́ ṣe ohun tí ò dáa. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé Kéènì ò fetí sí ìkìlọ̀ Jèhófà ó sì jìyà ohun tó ṣe yẹn. (Jẹ́n. 4:11-13) Nígbà tí nǹkan tojú sú akọ̀wé Jeremáyà tó ń jẹ́ Bárúkù tí inú rẹ̀ sì bà jẹ́, Jèhófà gbà á nímọ̀ràn kó bàa lè rí ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ̀. Bárúkù ò ṣàìgbọràn bíi ti Kéènì, ó gba ìmọ̀ràn, Jèhófà sì dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. (Jer. 45:2-5) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.” (Héb. 12:6) Kì í ṣe tí wọ́n bá nani lọ́rẹ́ nìkan la lè sọ pé wọ́n báni wí. Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà báni wí. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n dojú kọ àdánwò tó le koko, èyí tó ṣeé ṣe kó la ìbáwí lọ, àmọ́ wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìbáwí náà. w15 9/15 4:12, 13
Monday, November 20
Àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá ní tìtorí orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe.—Jóṣ. 9:9.
Àwọn ará Gíbéónì wá rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ ló ń ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn. Ráhábù náà rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Lẹ́yìn tó gbọ́ bí Jèhófà ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè, ó sọ fún àwọn amí méjì tó wá láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ilẹ̀ yìí fún yín.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Ráhábù ṣe yẹn léwu, ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè dá òun àti ìdílé òun sí. (Jóṣ. 2:9-13; 4:23, 24) Àpẹẹrẹ yìí àtàwọn àpẹẹrẹ míì tó wà nínú Bíbélì ti jẹ́ ká lóye ohun tó túmọ̀ sí pé ká rí Ọlọ́run tàbí ká rí ọwọ́ rẹ̀. Bí àwa náà bá ṣe túbọ̀ ń mọ Ọlọ́run, àá máa rí ọwọ́ rẹ̀ torí à ń mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ a sì ń fi ‘ojú ọkàn wa’ rí àwọn ohun tó ń ṣe. (Éfé. 1:18, Bíbélì Mímọ́) Láìsí àní-àní, àá fẹ́ dà bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ àti lóde òní tí wọ́n rí i kedere pé Jèhófà ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn. w15 10/15 1:6, 7, 9
Tuesday, November 21
Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.—Jòh. 11:5.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màtá nìkan ni Bíbélì dárúkọ rẹ̀ ní tààràtà pé Jésù fẹ́ràn, Jésù tún ní ìfẹ́ àtọkànwá fún àwọn obìnrin míì bíi Màríà ìyá rẹ̀ ọ̀wọ́n àti arábìnrin Màtá tó ń jẹ́ Màríà. (Jòh. 19:25-27) Kí wá nìdí tí ìwé Ìhìn Rere fi sọ̀rọ̀ Màtá lọ́nà yìí? Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àlejò ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Ṣùgbọ́n ohun tó mú kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ni pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára. Màtá gba àwọn ẹ̀kọ́ Jésù gbọ́ tọkàntọkàn, kò sì ṣiyè méjì pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòh. 11:21-27) Síbẹ̀, Màtá kì í ṣe ẹni pípé torí pé òun náà máa ń ṣàṣìṣe bíi ti gbogbo èèyàn. Nígbà kan tí Màtá gba Jésù lálejò, ó sọ fún Jésù pé ó yẹ kó bá Màríà wí torí pé kò bá òun ṣiṣẹ́. Màtá sọ pé: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un . . . kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.”—Lúùkù 10:38-42. w15 10/15 3:1, 2
Wednesday, November 22
Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.—Ják. 4:8.
Tá a bá ń bá a nìṣó láti máa fẹ̀sọ̀ ronú nípa Jèhófà àti Jésù, ìtara tá a ní fún òtítọ́ ò ní jó rẹ̀yìn. Ìtara wa á máa fún àwọn ará àtàwọn ẹni tuntun tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí níṣìírí. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún wa, àá mọyì àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà, Baba wa Mímọ́. (Róòmù 3:24) Arákùnrin Mark tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa tó lo ọdún mẹ́ta lẹ́wọ̀n nítorí ohun tó gbà gbọ́, sọ pé: “Bí ìgbà téèyàn ń rìnrìn-àjò tó gbádùn mọ́ni ni àṣàrò rí. Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ la ó máa mọ àwọn ohun tuntun nípa Jèhófà, Ọlọ́run wa. Nígbà míì tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí mò ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, ńṣe ni màá gbé Bíbélì, màá ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ọkàn mi á sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.” w15 10/15 4:15
Thursday, November 23
Mú mi lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, Kí n sì lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà pa á mọ́.—Sm. 119:34.
Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, jẹ́ káwọn ọmọ rẹ máa mọ ìdí tó o fi fún wọn lófin kan tàbí ìdí tó o fi ṣèpinnu kan, ìyẹn ló máa mú kó rọrùn fún wọn láti ṣègbọràn tinútinú. Arákùnrin Barry, tóun náà lọ́mọ mẹ́rin sọ pé: “Tá a bá ń jẹ́ káwọn ọmọ wa mọ ìdí tá a fi ṣe ìpinnu kan, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a máa ń gba tiwọn rò, a kì í ṣe apàṣẹwàá tàbí aṣèyówùú, wọ́n á sì fọkàn tán wa.” Ó ṣe pàtàkì ká rántí pé àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà náà ní “agbára ìmọnúúrò” tiwọn. (Róòmù 12:1) Arákùnrin Barry tún sọ pé: “Ó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ wa náà láti máa ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó ṣèpinnu.” Tó o bá ń fi pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi ṣèpinnu tó o ṣe fún ọmọ rẹ, òun náà á rí i pé o ò fojú ọmọdé wo òun mọ́, á sì máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀ tó bá fẹ́ ṣèpinnu. w15 11/15 2:11
Friday, November 24
Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.—Gál. 6:10.
Kárí ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń kéde orúkọ Jèhófà, tí wọ́n sì ń sọ ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fáwọn èèyàn. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? (Róòmù 12:10) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ gaara nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” Ó tún sọ pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pét. 1:22; 4:8) Ètò Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sáwọn tá a jọ jẹ́ ará. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà a sì ń ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀, ó ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Èyí ló mú kí gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé wà ní ìṣọ̀kan.—1 Jòh. 4:20, 21. w15 11/15 4:8, 9
Saturday, November 25
Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè . . . [yóò sọ pé]: “Àwa yóò bá yín lọ.”—Sek. 8:23.
Jèhófà ò fi dandan mú wa pé ká kọ́ èdè kan pàtó ká tó lè mọ òun àtàwọn ohun tóun fẹ́ ṣe fáráyé. (Ìṣí. 7:9, 10) Ṣé àwọn ìyàtọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì àti bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ onírúurú èdè mú kó ṣòro fún Ọlọ́run láti bá wọn sọ̀rọ̀? Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti kíyè sí i pé díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n kọ sílẹ̀ bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́. (Mát. 27:46; Máàkù 5:41; 7:34; 14:36) Àmọ́, Jèhófà rí i dájú pé wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sílẹ̀ lédè Gíríìkì, wọ́n sì tún tú u sí àwọn èdè míì nígbà tó yá. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn Júù àtàwọn Kristẹni nígbà yẹn ṣe àdàkọ àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà, kí wọ́n má bàa pa run. Wọ́n wá tú àwọn ìwé tí wọ́n ṣe àdàkọ rẹ̀ yìí sí ọ̀pọ̀ èdè. Ọ̀gbẹ́ni John Chrysostom tó gbé láyé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin sí ìkarùn-ún Sànmánì Kristẹni sọ pé nígbà ayé òun, wọ́n ti tú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sí àwọn èdè àwọn ará Síríà, Íjíbítì, Íńdíà, Páṣíà, Etiópíà àtàwọn èdè tí wọ́n ń sọ láwọn orílẹ̀-èdè míì. w15 12/15 1:10, 11
Sunday, November 26
Ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!—Òwe 15:23.
Ó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tá a sọ fẹ́nì kan ló máa ràn án lọ́wọ́, àmọ́ tá ò bá fòye mọ àkókò tó dáa jù láti sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa ò ní wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, lóṣù March ọdún 2011, ìsẹ̀lẹ̀ tó lágbára kan mú kí omi òkun ya wọ inú àwọn ìlú tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, ó sì run ọ̀pọ̀ ìlú tó wà níbẹ̀. Àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] lọ ló pàdánù ẹ̀mí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjálù yìí ò yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ sílẹ̀, wọ́n lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti sọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Ẹlẹ́sìn Búdà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀, wọn ò sì mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn ará wa fòye mọ̀ pé kò ní dáa kó jẹ́ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn àjálù náà làwọn á máa wàásù ìrètí àjíǹde fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ náà. Ńṣe ni wọ́n lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní láti tu àwọn èèyàn nínú, wọ́n sì lo Bíbélì láti fi ṣàlàyé ìdí tí irú àwọn nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀. w15 12/15 3:7
Monday, November 27
Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.—Òwe 14:15.
Nínú ayé oníwọra yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń purọ́ gba tọwọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn. Káwọn èèyàn tàbí iléeṣẹ́ kan lè jèrè rẹpẹtẹ, wọn máa ń polówó àwọn ògùn tàbí àwọn èròjà tówó ẹ̀ wọ́n gan-an fáwọn èèyàn, káwọn èèyàn lè máa rò pé èyí tówó ẹ̀ wọ́n gan-an ló máa ṣiṣẹ́ jù. Aláìsàn tó ń fẹ́ kí ara òun yá, tí ò sì fẹ́ kú lè gba irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́. “Afọgbọ́nhùwà” máa ń wà lójúfò pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìmọ̀ ìṣègùn ló ń gbà á nímọ̀ràn nípa àìlera rẹ̀. Á bi ara rẹ̀ pé: ‘Wọ́n ní ògùn tàbí egbòogi yìí ti wo ẹnì kan sàn, àmọ́ ṣé mo ti rí àwọn tí ògùn náà wò sàn lóòótọ́? Àwa èèyàn sì yàtọ̀ síra. Tó bá tiẹ̀ ṣiṣẹ́ fún ẹnì kan, ṣó wá túmọ̀ sí pé ó máa ṣiṣẹ́ fún èmi náà ni? Ǹjẹ́ kò ní dáa kí n ṣe ìwádìí síwájú sí i àbí màá ní láti lọ rí ẹnì kan tó mọ̀ nípa àìsàn náà dáadáa?’—Diu. 17:6. w15 12/15 4:14, 15
Tuesday, November 28
Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.—2 Kọ́r. 5:14.
Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tá a bá mọrírì ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Jésù ní sí wa, á mú ká bọlá fún Jésù ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tá a bá lóye àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa lóòótọ́, ìfẹ́ tó ní sí wa á mú ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé à ń bọlá fún Jésù. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà á mú ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí. (1 Pét. 2:21; 1 Jòh. 2:6) Tá a bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Kristi, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 14:21; 1 Jòh. 5:3) Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Àwọn apá wo nínú ìgbésí ayé mi ni mo ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Àwọn apá wo ló yẹ kí n ṣàtúnṣe sí?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí torí ohun táyé ń fẹ́ ni pé ká dà bí wọ́n ṣe dà.—Róòmù 12:2. w16.01 2:7-9
Wednesday, November 29
A ó dà bí rẹ̀, nítorí a óò rí i gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí.—1 Jòh. 3:2.
Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí iṣẹ́ míì tó o kúndùn bí iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé o fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì gan-an tó sì máa ń wù ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? (1 Kọ́r. 2:10) Ṣé ò ń wò ó pé Jèhófà ti jẹ́ kó o ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́? Ṣé kò sí nǹkan míì tó máa ń wù ẹ́ bíi kó o ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́? Ṣé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sin Jèhófà? Ṣó o ti rí ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbèésí ayé rẹ? Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Rárá, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti fẹ̀mí yàn ẹ́ láti lọ sọ́run. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà lè fún èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ tí wọ́n á fi ṣàṣeyọrí láwọn ọ̀nà yìí, bóyá ọ̀run ni èrè wọn wà o àbí ilẹ̀ ayé. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó o bá ń ṣiyè méjì bóyá o wà lára àwọn tó ń lọ sọ́run, a jẹ́ pé Jèhófà ò tíì yàn ẹ́ nìyẹn. w16.01 3:14, 15
Thursday, November 30
Mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.—Òwe 8:30.
Nígbà tí Jésù bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀, inú rẹ̀ dùn torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣe láṣeyọrí, ó sì mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Àwa náà ńkọ́? Jésù sọ pé a máa láyọ̀ nígbà tá a bá fúnni àti nígbà tá a bá rí gbà. (Ìṣe 20:35) Inú wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ kí nìdí tínú wa tún fi ń dùn bá a ṣe ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ìdí ni pé à ń rí i bínú wọn ṣe ń dùn bí wọ́n bá jàjà lóye ẹ̀kọ́ kan nínú Bíbélì tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí wọn tí wọ́n ń yí èrò wọn pa dà tí wọ́n sì ń tún ìgbésí ayé wọn ṣe. Iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, òun sì ni iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ jù lọ. Iṣẹ́ yìí ló máa mú kí àwọn tó bá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní ìyè àìnípẹ̀kun.—2 Kọ́r. 5:20. w16.01 5:6, 7