April
Sunday, April 1
Ẹ̀yin tí a sọ di àjèjì àti ọ̀tá nígbà kan rí nítorí tí èrò inú yín wà lórí àwọn iṣẹ́ tí ó burú, ni ó tún ti mú padà rẹ́ nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹran ara ẹni yẹn nípasẹ̀ ikú rẹ̀. —Kól. 1:21, 22.
Ojúṣe wa ni láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n lè dọ̀rẹ́ Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wọn. Bí ọ̀tá laráyé jẹ́ lójú Ọlọ́run kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tí Jésù rú. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòh. 3:36) A mà dúpẹ́ o, pé ẹbọ tí Kristi rú mú ká lè bá Ọlọ́run rẹ́. (2 Kọ́r. 5:18-20) À ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ó sì ń mú káwọn èèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Apá pàtàkì lèyí jẹ́ tó bá di pé ká jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ọlọ́run. w16.07 4:8-10
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Jòhánù 19:1-42
Monday, April 2
Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. —Mát. 6:9.
Ohun àkọ́kọ́ tí Jésù ní ká máa gbàdúrà fún ni pé kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tá a sọ di mímọ́. Torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀ náà jẹ́ mímọ́. Síbẹ̀, Sátánì dọ́gbọ́n fẹ̀sùn kan Jèhófà ní ọgbà Édẹ́nì pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fún èèyàn lófin. Ṣe ni Sátánì ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ nígbà tó parọ́ mọ́ ọn. (Jẹ́n. 3:1-5) Jésù ní tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà gan-an. (Jòh. 17:25, 26) Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Sm. 40:8-10) Ó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ó tọ́, ó sì yẹ pé kí Jèhófà fún àwa èèyàn lófin. Bó ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà mú kó ṣe kedere pé èèyàn pípé lè ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sáwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run. w17.02 2:2-4
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 16) Jòhánù 20:1
Tuesday, April 3
Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí . . . ọlá àti ògo . . . wà fún.—Ìṣí. 5:13.
Jésù Kristi ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ìyẹn “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòh. 1:29) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ju gbogbo àwọn ọba tó tíì jẹ láyé yìí lọ títí kan àwọn tó wà lórí ìtẹ́ báyìí. Bíbélì pe Jésù ní “Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa, ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú, ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́, ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.” (1 Tím. 6:14-16) Ká sòótọ́, ọba míì wo ló ti yọ̀ǹda ẹ̀mí ara rẹ̀ kó lè rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀? Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ àwọn áńgẹ́lì tó ń sọ pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa ni ó yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.” (Ìṣí. 5:12) Ó pọn dandan pé ká bọlá fún Jèhófà àti Jésù, ìdí sì ni pé tá ò bá bọlá fún wọn, a lè pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun.—Sm. 2:11, 12; Jòh. 5:23. w17.03 1:3, 4
Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Jòhánù 20:2-18
Wednesday, April 4
Bí ẹ bá ń mú mi padà . . . , èmi, ní tèmi, yóò di olórí yín! —Oníd. 11:9.
Ọwọ́ tí Jèhófà fi mú àwọn èèyàn Rẹ̀ jẹ́ kí Jẹ́fútà mọ èrò Ọlọ́run lórí ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Oníd. 11:12-27) Jẹ́fútà jẹ́ kí òótọ́ tó mọ̀ yìí darí gbogbo ìpinnu tó ṣe nígbèésí ayé rẹ̀. Ó mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn Rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ó sì mọ̀ pé kò fẹ́ kí wọ́n máa bínú síra wọn tàbí kí wọ́n máa gbẹ̀san. Yàtọ̀ síyẹn, Òfin Mósè jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kóun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn títí kan àwọn tó kórìíra òun pàápàá. (Ẹ́kís. 23:5; Léf. 19:17, 18) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ló ran Jẹ́fútà lọ́wọ́. Ó ti ní láti gbọ́ bí Jósẹ́fù ṣe fojú àánú hàn sáwọn arákùnrin rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kórìíra rẹ̀. (Jẹ́n. 37:4; 45:4, 5) Ó lè jẹ́ pé bí Jẹ́fútà ṣe ronú lórí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ló mú kó ṣe ohun tó múnú Jèhófà dùn. Ohun táwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe sí i dùn ún gan-an lóòótọ́, àmọ́ kò torí ìyẹn lóun ò ní báwọn èèyàn Jèhófà ṣe mọ́ tàbí kó lóun ò ní sin Jèhófà mọ́.—Oníd. 11:1-3. w16.04 1:8, 9
Thursday, April 5
Kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.—Héb. 10:24, 25.
Tipẹ́tipẹ́ ló ti máa ń wu àwọn èèyàn Jèhófà pé kí wọ́n wà pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, inú àwọn Kristẹni máa ń dùn láti pé jọ kí wọ́n lè jọ́sìn Jèhófà kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ó dájú pé ìwọ náà máa ń fojú sọ́nà fún lílọ sí ìpàdé ìjọ. Bíi ti àwọn ará wa kárí ayé, ó lè má rọrùn fún ẹ láti máa lọ sípàdé déédéé. Ó lè jẹ́ pé o máa ń pẹ́ níbiiṣẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lè wà tó o fẹ́ ṣe, ó sì lè jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló máa ń rẹ̀ ọ́. Àwọn ará kan ò lè lọ sípàdé déédéé torí ipò tí wọ́n wà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa ṣàìsàn tó le koko. Àwọn alàgbà lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa gbádùn ìpàdé náà lórí fóònù tàbí kí wọ́n bá wọn gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. w16.04 3:3
Friday, April 6
Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé. —Jòh. 16:33.
A rí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó lo ìgboyà, tí wọ́n sì fọgbọ́n ṣe àwọn ìpinnu tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Ronú nípa bí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe kọ̀ láti jọ́sìn ère tó dúró fún ìjọba ìlú Bábílónì tí wọ́n ní kí wọ́n forí balẹ̀ fún. (Dán. 3:16-18) Ìtàn Bíbélì yìí ti fún ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí nígboyà láti ṣàlàyé ìdí tí wọn fi kọ̀ láti kí àsíá orílẹ̀-èdè wọn. Jésù ò lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí àwọn ọ̀rọ̀ míì tó lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Ó mọ̀ pé àpẹẹrẹ rere tóun bá fi lélẹ̀ máa ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tó fi sọ fún wọn pé kí wọ́n “mọ́kànle.” Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ rẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Táwọn míì nínú ìjọ bá mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, wọ́n á fún ẹ níṣìírí kó o má bàa juwọ́ sílẹ̀. Sọ pé kí wọ́n rántí rẹ nínú àdúrà wọn. Àmọ́, ó yẹ káwa náà máa ti àwọn arákùnrin wa lẹ́yìn ká sì máa gbàdúrà fún wọn.—Mát. 7:12. w16.04 4:16, 18
Saturday, April 7
Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn.—Sm. 110:3.
Ṣé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbégbá owó láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn àpéjọ wa? Rárá o. Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe. (2 Kọ́r. 9:7) Síbẹ̀, lọ́dún tó kọjá nìkan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjì wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, ó sì lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ lóṣooṣù. Ohun tó tiẹ̀ tún wá yani lẹ́nu níbẹ̀ ni pé, yàtọ̀ sí pé wọn kì í gba owó kankan fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n tún fi ń náwó nára lórí iṣẹ́ náà. Nígbà tí ẹnì kan tó ń ṣèwádìí ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, ó sọ pé: “Ohun tó jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún ni bí wọ́n á ṣe wàásù tí wọ́n á sì kọ́ni. . . . Wọn ò ní àlùfáà tí wọ́n ń sanwó fún, torí náà wọn kì í kó sí ìnáwó rẹpẹtẹ.” Kí wá nìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù? Ní kúkúrú, àwa fúnra wa la yàn láti máa wàásù torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Bá a ṣe ń yọ̀ǹda ara wa tinútinú yìí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa tòní. w16.05 2:9
Sunday, April 8
Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere.—Ják. 3:17.
Èyí jẹ́ ká rí i pé kò dáa kéèyàn máa fọkàn yàwòrán ìṣekúṣe torí pé ìyẹn lè mú kéèyàn dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tó jẹ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ tí Bíbélì dá lẹ́bi tí kò sì bá èrò Jèhófà mu. Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè bóyá òun lè ka àwọn ìwé kan, wo irú àwọn fíìmú kan tàbí gbá géèmù tó ní àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra nínú. Ó mọ̀ pé Jèhófà kórìíra irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣèpinnu, ohun tẹ́nì kan ṣe lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, síbẹ̀ kí ìpinnu táwọn méjèèjì ṣe múnú Jèhófà dùn. Àmọ́, tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára, á dáa ká fọ̀rọ̀ lọ àwọn alàgbà tàbí àwọn Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. (Títù 2:3-5; Ják. 5:13-15) Àmọ́ o, kò yẹ ká máa sọ pé káwọn míì ṣèpinnu fún wa. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ kọ́ agbára ìmòye wọn kí wọ́n sì máa lò ó. (Héb. 5:14) Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa rántí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Gál. 6:5. w16.05 3:15, 16
Monday, April 9
Mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.—1 Tím. 1:13.
Bí Jèhófà ṣe ń kíyè sí ọmọ aráyé, kì í ṣe ẹwà tàbí ìrísí wa ló ń wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn wa ló ń wò, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. (1 Sám. 16:7b) Ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí Ọlọ́run dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Onírúurú èèyàn tí àwọn èèyàn ò kà sí ni Jèhófà mú kó wá sọ́dọ̀ Jésù, ọmọ rẹ̀. (Jòh. 6:44) Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ Farisí tẹ́lẹ̀. Àmọ́, Jèhófà tó jẹ́ ‘olùṣàyẹ̀wò ọkàn,’ mọ̀ pé amọ̀ tó ṣì máa wúlò ni Sọ́ọ̀lù. (Òwe 17:3) Ohun tí Ọlọ́run rí lára ọkùnrin yìí yàtọ̀ pátápátá, Ọlọ́run rí i pé amọ̀ táá ṣeé fi mọ ohun èlò tó fani mọ́ra ni Sọ́ọ̀lù. Àní sẹ́, “ohun èlò tí a ti yàn ni” láti jẹ́rìí fún “àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣe 9:15) Àwọn míì tí Ọlọ́run rí i pé wọ́n máa jẹ́ ohun èlò “fún ìlò ọlọ́lá” ni àwọn tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀mùtí, oníṣekúṣe àti olè. (Róòmù 9:21; 1 Kọ́r. 6:9-11) Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń lo ìgbàgbọ́, wọ́n sì gbà kí Jèhófà mọ àwọn bí amọ̀kòkò ṣe máa ń mọ amọ̀. w16.06 1:4
Tuesday, April 10
Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ní ọwọ́ mi.—Jer. 18:6.
Lára àwọn nǹkan tí Jèhófà fún wa ká lè dà bí amọ̀ tó rọ̀ ni Bíbélì, ìjọ Kristẹni àti iṣẹ́ ìwàásù. Bí omi ṣe máa ń mú kí amọ̀ rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti ṣíṣàṣàrò ṣe ń mú ká dà bí amọ̀ tó ṣeé mọ lọ́wọ́ Jèhófà. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kọ ẹ̀dà Òfin Ọlọ́run fún ara wọn, kí wọ́n sì máa kà á lójoojúmọ́. (Diu. 17:18, 19) Àwọn àpọ́sítélì náà mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa ka Ìwé Mímọ́, káwọn sì máa ṣàṣàrò káwọn lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Tí wọ́n bá ń kọ̀wé sí ìjọ, àìmọye ìgbà ni wọ́n máa ń tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tàbí kí wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ nínú wọn. Wọ́n sì máa ń rọ àwọn tí wọ́n ń wàásù fún pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 17:11) Lóde òní, àwa náà gbà pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí tàdúràtàdúrà. (1 Tím. 4:15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà á dùn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, àá sì dà bí amọ̀ tó ṣeé mọ lọ́wọ́ rẹ̀. w16.06 2:10
Wednesday, April 11
Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.—Jòh. 13:35.
Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká pa àṣẹ yìí mọ́, pàápàá jù lọ torí bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń bára wọn jagun tó ń bani lẹ́rù láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bíi mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́ta [55] èèyàn ni wọ́n pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nìkan. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe pààyàn ní ìpakúpa yẹn. (Míkà 4:1, 3) Èyí mú kí “ọrùn [wa] mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.” (Ìṣe 20:26) Àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbèrú sí i bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé burúkú tí Sátánì ń darí là ń gbé. Bíbélì pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́r. 4:4) Òun ló ń darí ètò ìṣèlú ayé bó ṣe ń darí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò. Àmọ́ kò lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. Sátánì mọ̀ pé àkókò kúkúrú ló kù fún òun, torí náà ó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú káwọn èèyàn pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Onírúurú ọ̀nà ló sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣí. 12:12. w16.06 4:3, 4
Thursday, April 12
Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára àwọn òdòdó lílì pápá.—Mát. 6:28.
Jésù pe àfíyèsí wa sí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ lára “àwọn òdòdó lílì pápá.” Ó lè jẹ́ pé àwọn òdòdó kan tó lẹ́wà ni Jésù ní lọ́kàn, bí àwọn òdòdó etí odò àtàwọn òdòdó míì tó láwọ̀ mèremère. Àwọn òdòdó yìí kì í ránṣọ tàbí hun aṣọ fún ara wọn. Síbẹ̀, tí wọ́n bá tanná, wọ́n máa ń dùn ún wò gan-an. Kódà, “Sólómọ́nì pàápàá nínú gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́ bí ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí.” Ẹ má gbàgbé ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí . . . , òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?” (Mát. 6:29, 30) Ó dájú pé Jèhófà máa pèsè, àmọ́ ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. (Mát. 8:26; 14:31; 16:8; 17:20) Torí náà, wọ́n ní láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àwa ńkọ́? Ṣó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti pèsè ohun tá a nílò àti pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀? w16.07 1:15, 16
Friday, April 13
Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.—1 Pét. 4:10.
Kò sí irú àdánwò tó lè dé bá wa láyé yìí tí Jèhófà ò ní ràn wá lọ́wọ́ láti kojú. (1 Pét. 1:6) Irú àdánwò tíì báà jẹ́, Ọlọ́run máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa, àá sì lè fara dà á. Torí pé onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà fi inú rere hàn, ọ̀pọ̀ ìbùkún làwa èèyàn rẹ̀ ń gbádùn. Ọ̀kan ni ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa tá à ń rí gbà. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ló ń mú kí Jèhófà dárí jì wá. Àmọ́ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, ká sì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kápá ẹran ara tó máa ń mú wa dẹ́ṣẹ̀. (1 Jòh. 1:8, 9) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí àánú rẹ̀, ká sì máa yìn ín lógo. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn ẹni àmì òróró bíi tiẹ̀, ó sọ pé: ‘[Jèhófà] dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá àṣẹ òkùnkùn, ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́, nípasẹ̀ ẹni tí a gba ìtúsílẹ̀ wa nípa ìràpadà, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.’ (Kól. 1:13, 14) Torí pé Jèhófà ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ṣe ni òjò ìbùkún míì ń rọ̀ yàà lé wa lórí. w16.07 3:7-9
Saturday, April 14
Òun yóò pa ọ́ ní orí.—Jẹ́n. 3:15.
Láìka gbogbo ohun tí Sátánì ṣe ní ọgbà Édẹ́nì sí, Jèhófà tún fi aráyé lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la máa dáa nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Jèhófà sọ pé ‘irú-ọmọ obìnrin náà’ máa pa Èṣù run. Èyí á wá mú káwọn onígbọràn gbádùn ohun tí tọkọtaya àkọ́kọ́ pàdánù, ìyẹn gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn á wá ṣẹ. (Jòh. 3:16) Àtìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ ni nǹkan ò ti lọ dáadáa láàárín wọn mọ́, ọ̀tẹ̀ yìí kan náà ló sì kó bá gbogbo ìdílé látìgbà yẹn wá. Bí àpẹẹrẹ, Éfà àti gbogbo obìnrin á máa jẹ̀rora nínú oyún àti nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bímọ, ọ̀dọ̀ ọkọ wọn lọkàn wọn á sì máa wà ní gbogbo ìgbà. Àwọn ọkọ náà á máa jọba lé wọn lórí, kódà wọ́n á máa pọ́n wọn lójú. Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí nìyẹn. (Jẹ́n. 3:16) Bíbélì sọ pé kí àwọn ọkọ máa fìfẹ́ lo ipò orí wọn. Ó sì ní káwọn aya náà máa fọ̀wọ̀ wọ àwọn ọkọ wọn. (Éfé. 5:33) Torí pé àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, àwọn nǹkan tó lè fa wàhálà kì í pọ̀, wọ́n sì máa ń tètè yanjú rẹ̀. w16.08 1:6, 7
Sunday, April 15
Aya, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là? Tàbí, ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?—1 Kọ́r. 7:16.
Láwọn ìdílé míì, ó lè jẹ́ ìyàwó nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà míì ó sì lè jẹ́ ọkọ. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, Bíbélì mú kó ṣe kedere pé wọ́n ṣì lè máa gbé pọ̀. (1 Kọ́r. 7:12-14) Yálà ọkọ tàbí aya tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà mọ̀ tàbí kò mọ̀, a ti sọ ọ́ “di mímọ́” torí pé ìránṣẹ́ Jèhófà ló fẹ́. Àwọn ọmọ wọn náà jẹ́ “mímọ́,” tó túmọ̀ sí pé àwọn náà ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti máa ń rí àwọn tọkọtaya tó jẹ́ pé ọ̀kan lára wọn ni Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ tó wá ran ẹnì kejì lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn aya Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ wọn, “kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pét. 3:1-4. w16.08 2:14, 15
Monday, April 16
Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.—1 Pét. 1:22.
Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́. (Lúùkù 22:24-27) Àpẹẹrẹ kan ni ti Jésù, gbogbo ohun tó ní ló fún àwọn èèyàn kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run, títí kan ẹ̀mí rẹ̀. (Mát. 20:28) Àpẹẹrẹ míì ni ti Dọ́káàsì tó “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.” (Ìṣe 9:36, 39) Ẹlòmíì tún ni Màríà tó ń gbé ní Róòmù. Bíbélì sọ pé ó máa ń ṣiṣẹ́ kára torí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ. (Róòmù 16:6) Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ káwọn náà lè rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa ran àwọn ará lọ́wọ́? Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run lè mú àwọn ẹni tuntun dání tí wọ́n bá fẹ́ lọ kí àwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn àgbàlagbà. Nígbà míì, àwọn òbí lè mú àwọn ọmọ wọn dání tí wọ́n bá fẹ́ lọ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àwọn alàgbà lè ṣètò bí àwọn àtàwọn míì nínú ìjọ á ṣe rí sí i pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ilé wọn sì wà ní mímọ́. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ẹni tuntun á mọ béèyàn ṣe ń ṣoore fáwọn ẹlòmíì, wọ́n á sì gbà pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí.—Róòmù 12:10. w16.08 4:13, 14
Tuesday, April 17
Èyí ni ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí òye rẹ̀ sì ń yé e, ẹni tí ń so èso ní ti gidi.—Mát. 13:23.
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Faransé sọ pé: “Ó máa ń ya àwọn tíṣà iléèwé mi lẹ́nu pé àwa akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣì wà tá a gba ohun tó wà nínú Bíbélì gbọ́.” Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọ wa àtẹ̀yin ọ̀dọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìyẹn? Ṣé àwọn ọmọ iléèwé rẹ náà máa ń fẹ́ kó o tẹ̀ síbi táyé tẹ̀ sí, kó o gbà pé ẹfolúṣọ̀n ló mú káwọn nǹkan wà dípò Ẹlẹ́dàá? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe táá mú kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ẹlẹ́dàá túbọ̀ lágbára. Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o lo làákàyè rẹ torí pé ó “máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” Kò ní jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ ayé yìí ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́. (Òwe 2:10-12) Kó o tó lè nígbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (1 Tím. 2:4) Torí náà, tó o bá ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìwé wa, má kàn máa wò wọ́n gààràgà, ṣe ni kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ wọn. Máa ronú lé ohun tó ò ń kà, kó o lè lóye rẹ̀. w16.09 4:1-3
Wednesday, April 18
Máa fi ire ṣẹ́gun ibi.—Róòmù 12:21.
Ká tiẹ̀ sọ pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún wa nígbà tá a wà ní kékeré tàbí bóyá ìṣòro tó ń bá wa fínra báyìí kọjá agbára wa, ẹ jẹ́ ká máa forí tì í, ká má sì bọ́hùn. Ó dájú pé tá ò bá bọ́hùn, Jèhófà máa bù kún wa. (Jẹ́n. 39:21-23) Ronú díẹ̀ ná nípa ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. Bóyá ṣe ni wọ́n ń rẹ́ ọ jẹ tàbí wọ́n ń ṣẹ̀tanú sí ẹ, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Àbí kẹ̀, bóyá ẹnì kan fẹ̀sùn èké kàn ẹ́ torí pé onítọ̀hún ń jowú rẹ. Má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan yẹn mú kó o bọ́hùn, kàkà bẹ́ẹ̀ máa rántí ohun tó mú kí Jékọ́bù, Rákélì àti Jósẹ́fù máa fayọ̀ sin Jèhófà nígbà ìṣòro. Jèhófà fún wọn lókun, ó sì bù kún wọn torí pé ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀. Wọn ò dákẹ́ àdúrà, wọ́n sì jà fitafita láti ṣe ohun tó bá àdúrà wọn mu. Àwa ńkọ́? Ayé búburú tá à ń gbé yìí kò ní pẹ́ wá sópin; torí náà kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ ká fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìrètí tá a ní! Ṣé wàá ṣì máa jà fitafita kó o lè rí ojúure Jèhófà, àbí wàá jáwọ́? w16.09 2:8, 9
Thursday, April 19
Èso ti ẹ̀mí ni . . . ìgbàgbọ́. —Gál. 5:22.
Ohun míì ni pé kó o fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tìẹ kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Àwọn ọmọ rẹ máa kíyè sí ohun tí ìwọ fúnra rẹ ń ṣe, àwọn náà á sì máa ṣe bíi tìẹ. Torí náà, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí i pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ohun tí tọkọtaya kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bermuda máa ń ṣe tí wọ́n bá ní ìdààmú ọkàn ni pé, wọ́n á pe àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì jọ gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà. Wọ́n tún máa ń rọ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà láyè ara wọn. Àwọn tọkọtaya náà sọ pé: “A máa ń sọ fún ọmọbìnrin wa àgbà pé, ‘Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, máa lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, má sì máa ṣàníyàn ju bó ti yẹ lọ.’ Nígbà tóun náà bá wá rí bí nǹkan ṣe pa dà rí fún wa, ó máa ń gbà pé Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́. Èyí ti mú kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára, ó sì túbọ̀ dá a lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.” Òótọ́ kan ni pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe máa lágbára tó. Àmọ́ ẹ̀yin òbí lè gbin ohun tó dáa sọ́kàn wọn, kẹ́ ẹ sì bomi rin ín. A mọ̀ pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí irúgbìn náà dàgbà. (1 Kọ́r. 3:6) Torí náà, gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́, kó o sì sapá gan-an láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run máa bù kún ìsapá rẹ.—Éfé. 6:4. w16.09 5:16-18
Friday, April 20
Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn [ọ̀rọ̀ wọ̀nyí] sínú ọmọ rẹ.—Diu. 6:7.
Lẹ́yìn tí Serge àti Muriel ìyàwó rẹ̀ ti sìn fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì, wọ́n rí i pé ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] ò láyọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Serge wá sọ pé: “Nígbà tá a rí i pé ìtara ọmọ wa ti ń dín kù, ṣe la pa dà sí ìjọ tá a wà tẹ́lẹ̀.” Kí ló lè mú káwọn òbí pinnu pé àwọn á pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kí wọ́n wò ó bóyá àwọn máa ráyè kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lédè tí wọ́n lóye, lẹ́sẹ̀ kan náà kí wọ́n sì tún kọ́ wọn lédè àjèjì tí wọ́n ń sọ níbi tí wọ́n ti ń sìn. Ohun kejì ni pé wọ́n lè kíyè sí pé àwọn ọmọ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nítara fún iṣẹ́ ìsìn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n má nífẹ̀ẹ́ sí ibi tí wọ́n ti ń sìn mọ́. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí lè pinnu pé á dáa káwọn pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa títí dìgbà tí òtítọ́ á fi jinlẹ̀ lọ́kàn wọn.—Diu. 6:5-7. w16.10 2:14, 15
Saturday, April 21
Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.—Héb. 11:7.
Kò sí àní-àní pé àwọn aládùúgbò Nóà á máa béèrè ìdí tó fi ń kan ọkọ̀ gàgàrà yẹn lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣé Nóà kàn dákẹ́ ni àbí ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má yọ òun lẹ́nu? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀! Torí pé ó nígbàgbọ́, ó fìgboyà wàásù fún wọn, ó sì kìlọ̀ fún wọn nípa ìdájọ́ Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jèhófà ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà fún Nóà lòun náà ṣe sọ ọ́ fáwọn èèyàn pé: “Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi, nítorí tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nítorí wọn . . . Èmi yóò mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé láti run gbogbo ẹran ara tí ipá ìyè ń ṣiṣẹ́ nínú wọn lábẹ́ ọ̀run. Ohun gbogbo tí ó wà ní ilẹ̀ ayé yóò gbẹ́mìí mì.” Ó dájú pé Nóà tún máa sọ ohun táwọn èèyàn náà gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Á sọ fún wọn pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ wọnú áàkì náà.’ Ohun tí Nóà ṣe yìí mú kó túbọ̀ fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Abájọ tí Bíbélì fi pè é ní “oníwàásù òdodo.”—Jẹ́n. 6:13, 17, 18; 2 Pét. 2:5. w16.10 4:7
Sunday, April 22
Kì í ṣe ti ènìyàn . . . láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.—Jer. 10:23.
Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn. Wọn kì í jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ tó bá ta ko ìlànà Bíbélì nípa lórí bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn. Àwa Kristẹni kì í sì í fàyè gba ẹ̀mí ayé nínú ilé wa. (Éfé. 2:2) Kò yẹ kí bàbá kan tó ti ṣèrìbọmi máa ronú pé, ‘Nílùú wa, àwọn obìnrin ló máa ń kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́.’ Ìlànà Bíbélì ṣe kedere lórí kókó yìí, ó ní: “Ẹ̀yin baba, . . . ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àwọn òbí tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn dà bíi Sámúẹ́lì torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe ń dàgbà, ó sì dúró tì í. (1 Sám. 3:19) Ó yẹ ká kọ́kọ́ ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ ká tó ṣèpinnu tó máa kan àwọn ará ilé wa tàbí iṣẹ́ táa fẹ́ ṣe. Ìdí ni pé Baba wa ọ̀run ló gbọ́dọ̀ máa tọ́ wa sọ́nà torí pé a ò lè darí ara wa. w16.11 3:14, 15
Monday, April 23
Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn.—Sm. 8:3, 4.
Àwọn nǹkan tí Jèhófà Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé Olùṣètò tí kò láfiwé ni. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n ni Jèhófà fúnra rẹ̀ fi fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ìfòyemọ̀ ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 3:19) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, bíńtín la tíì mọ̀ nípa Ọlọ́run, kódà ‘àhegbọ́ lásán ṣì ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’ (Jóòbù 26:14) Síbẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ tá a mọ̀ nípa àwọn ìràwọ̀, àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì jẹ́ ká rí i pé àwọn nǹkan yìí wà létòletò. Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ìràwọ̀ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, gbogbo wọn ń yípo lọ́nà tó wà létòletò, láìgbún ara wọn. Bákan náà, ayé yìí àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì míì ń yípo oòrùn lọ́nà tó wà létòletò. Gbogbo nǹkan àgbàyanu yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà “fi òye ṣẹ̀dá ọ̀run,” torí náà òun nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn ká sì máa yìn.—Sm. 136:1, 5-9. w16.11 2:3
Tuesday, April 24
Dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo. —Mál. 3:3.
Málákì 3:1-3 ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, pé Ọlọ́run máa yọ́ àwọn ẹni àmì òróró “ọmọ Léfì” mọ́. Láwọn ọdún yẹn, “Olúwa tòótọ́,” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run wá sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí pẹ̀lú Jésù Kristi tí Bíbélì pè ní “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” láti wá wo àwọn tó ń sìn nínú tẹ́ńpìlì náà. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí tó sì ti yọ́ wọn mọ́, ó mú kí wọ́n gbára dì láti gba àfikún iṣẹ́. Abájọ tó fi jẹ́ pé lọ́dún 1919, Jèhófà yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé kó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn ará ilé ìgbàgbọ́. (Mát. 24:45) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ pátápátá lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá. Jèhófà fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sáwọn èèyàn rẹ̀, àtìgbà yẹn ló sì ti mú kí wọ́n túbọ̀ máa lóye ìfẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Baba wọn ọ̀run. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀! w16.11 5:14
Wednesday, April 25
“Ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò . . . ,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.”—Mal. 3:10.
A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà “nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòh. 4:19) Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin gan-an, ọ̀nà kan tó sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń bù kún wọn. Bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà bá ṣe jinlẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa ṣe máa lágbára tó. Kì í ṣe pé a mọ̀ pé Ọlọ́run wà nìkan ni, a tún mọ̀ pé ó máa ń sẹ̀san fáwọn tó nífẹ̀ẹ́. (Héb. 11:6) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti ohun tó lè ṣe, kò sí bá ò ṣe ní mẹ́nu kan jíjẹ́ tó jẹ́ olùsẹ̀san. Kí ìgbàgbọ́ wa tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé Ọlọ́run máa ń san èrè fáwọn tó ń fi taratara wá a, torí pé “ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí.” (Héb. 11:1) Ó dájú pé tá a bá nígbàgbọ́, àá gbà pé Ọlọ́run máa bù kún wa. A rí i nínú ìkẹ́ẹ́kọ̀ ojoojúmọ́ wa tòní pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló rọ̀ wá pé ká wá ojúure òun. Tá a bá ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí rọ̀ wá, à ń fi hàn pé a mọrírì ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà. w16.12 4:1-3
Thursday, April 26
Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú.—Róòmù 8:6.
Ẹnì kan lè ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ tí kò bá ṣọ́ra, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé èrò inú rẹ̀ ka ẹran ara. Èyí kò túmọ̀ sí pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan Kristẹni kan ò lè ronú nípa oúnjẹ, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ìgbafẹ́ tàbí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya. Kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí. Jésù náà máa ń gbádùn oúnjẹ, ó sì bọ́ àwọn míì. Kódà ó máa ń lọ sí àpèjẹ. Pọ́ọ̀lù náà sì sọ pé kò sóhun tó burú tí tọkọtaya bá ń gbádùn ìbálòpọ̀. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “kéèyàn máa ronú ṣáá nípa nǹkan kan, kéèyàn pàfiyèsí sí nǹkan ọ̀hún, kó sì gbájú mọ́ ọn.” Àwọn tó bá ń gbé níbàámu pẹ̀lú ẹran ara máa ń ṣe ohun tára àìpé wọn bá ṣáà ti fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ohun tí ọ̀mọ̀wé kan sọ nípa Róòmù 8:5 ni pé: “Ohun téèyàn gbé èrò inú rẹ̀ kà ni ohun téèyàn sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, téèyàn máa ń lọ́wọ́ sí, tó sì fi ń ṣayọ̀.” w16.12 2:5, 9, 10
Friday, April 27
Ta ni ọ́ tí o fi ní láti máa ṣèdájọ́ aládùúgbò rẹ? —Jak. 4:12.
Téèyàn bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gba òun lọ́kàn, wẹ́rẹ́ báyìí lonítọ̀hún á bẹ̀rẹ̀ sí í kọjá àyè ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìlara àti ìbínú òdì wà lára ohun tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn kọjá àyè wọn. Nínú Bíbélì, àwọn èèyàn bí Ábúsálómù, Ùsáyà àti Nebukadinésárì jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ ti ara wọ̀ wọ́n lẹ́wù débi pé wọ́n kọjá àyè wọn, Jèhófà sì rẹ̀ wọ́n wálẹ̀. (2 Sám. 15:1-6; 18:9-17; 2 Kíró. 26:16-21; Dán. 5:18-21) Àmọ́ ṣá o, àwọn ìdí míì wà tó lè mú kéèyàn kọjá àyè rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Bíbélì ròyìn pé ó ṣẹlẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 20:2-7 àti Mátíù 26:31-35. Ṣé a lè sọ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ló fà á tó fi jọ pé Ábímélékì àti Pétérù kọjá àyè ara wọn? Àbí ohun tó fà á ni pé wọn ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti pé wọn ò wà lójúfò? Torí pé a ò rínú, á dáa ká má ṣe máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. w17.01 3:9, 10
Saturday, April 28
Obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.—Lúùkù 21:4.
Bí nǹkan ṣe wá rí fún opó aláìní náà, ó dá wa lójú pé tá a bá ń fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú láyé wa, Jèhófà máa rí i dájú pé a ò ṣaláìní ohunkóhun. (Mát. 6:33) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Malcolm. Ọ̀pọ̀ ọdún ni òun àtìyàwó rẹ̀ fi sin Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn. Ó sọ pé: “Ayé yìí ti dojú rú, kò sì sẹ́ni tó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́la, ṣùgbọ́n, Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e.” Arákùnrin Malcolm fi kún un pé: “Kéèyàn gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kóun lè máa kó ipa tó jọjú kóun sì máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ débi tó bá ṣeé ṣe dé. Kéèyàn máa pọkàn pọ̀ sórí ohun tó lè ṣe, kì í ṣe ohun tí kò lè ṣe.” Bí ayé yìí ṣe túbọ̀ ń burú sí i, a mọ̀ pé nǹkan á túbọ̀ máa nira. (2 Tím. 3:1, 13) Torí náà, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ó yẹ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ káwọn ìṣòro ayé yìí mú ká dẹwọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ. w17.01 1:17-19
Sunday, April 29
Ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ ilé tí èmi yóò máa gbé.—1 Kíró. 17:4.
Kò dùn mọ́ ọn nínú pé kò sí “ilé” tàbí tẹ́ńpìlì kankan fún Jèhófà, torí náà ó wù ú Dáfídì pé kó kọ́ ilé fún Jèhófà. Àmọ́ ohun tí Jèhófà sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ ìwé mímọ́ tòní ṣe sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an tó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun á bù kún un, síbẹ̀ Jèhófà sọ fún un pé Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Dáfídì? (1 Kíró. 17:1-4, 8, 11, 12; 29:1) Dáfídì kò torí ìyẹn káwọ́ gbera, kó wá máa bínú pé wọn ò kúkú ní dárúkọ òun nígbà tí wọ́n bá ń sọ ẹni tó kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Ká sòótọ́, tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ni wọ́n pe ilé náà, kì í ṣe ti Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má dùn mọ́ Dáfídì nínú pé Jèhófà ò jẹ́ kóun ṣe ohun tó wà lọ́kàn òun, síbẹ̀ tọkàntara ló fi ṣètò àwọn òṣìṣẹ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí tí wọ́n sì kó irin, bàbà, fàdákà àti wúrà jọ títí kan àwọn igi kédárì. Bákan náà, ó tún fún Sólómọ́nì níṣìírí pé: “Wàyí o, ọmọkùnrin mi, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere, kí o sì kọ́ ilé Jèhófà.”—1 Kíró. 22:11, 14-16. w17.01 5:6, 7
Monday, April 30
Kí o sì dá wa nídè, kí o sì bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní tìtorí orúkọ rẹ. —Sm. 79:9.
Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́. Bá a ṣe ń hùwà mímọ́, ṣe là ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún orúkọ Jèhófà. (Mát. 5:14-16) Torí pé a jẹ́ èèyàn Jèhófà, ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa fi hàn pé àwọn òfin Jèhófà ṣàǹfààní àti pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà. Nítorí àìpé wa, gbogbo wa la máa ń ṣàsìṣe. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ká sì jáwọ́ nínú ìwà èyíkéyìí tó lè tàbùkù sórúkọ Jèhófà. Lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Jèhófà máa ń gbà káwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún un di ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó ka àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sí olódodo, ó sì gbà wọ́n ṣọmọ. Bákan náà, ó ka “àwọn àgùntàn mìíràn” sí olódodo, ó sì kà wọ́n sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòh. 10:16; Róòmù 5:1, 2; Ják. 2:21-25) Kódà ní báyìí, ìràpadà ń mú ká rí ojúure Jèhófà Baba wa, a sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. w17.02 2:5, 6