ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 26-36
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Thursday, March 1
  • Friday, March 2
  • Saturday, March 3
  • Sunday, March 4
  • Monday, March 5
  • Tuesday, March 6
  • Wednesday, March 7
  • Thursday, March 8
  • Friday, March 9
  • Saturday, March 10
  • Sunday, March 11
  • Monday, March 12
  • Tuesday, March 13
  • Wednesday, March 14
  • Thursday, March 15
  • Friday, March 16
  • Saturday, March 17
  • Sunday, March 18
  • Monday, March 19
  • Tuesday, March 20
  • Wednesday, March 21
  • Thursday, March 22
  • Friday, March 23
  • Saturday, March 24
  • Sunday, March 25
  • Monday, March 26
  • Tuesday, March 27
  • Wednesday, March 28
  • Thursday, March 29
  • Friday, March 30
  • Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
    Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
    Saturday, March 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 26-36

March

Thursday, March 1

Wọ́n . . . lé Jẹ́fútà jáde. ​—Oníd. 11:2.

Torí pé àwọn arákùnrin Jẹ́fútà kórìíra ẹ̀ wọ́n sì ń jowú ẹ̀, wọ́n lé e kúrò ní ilẹ̀ bàbá rẹ̀. (Oníd. 11:​1-3) Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, kò lọ́ tìkọ̀, ó ràn wọ́n lọ́wọ́. (Oníd. 11:​4-11) Ó pinnu pé òun á jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Èyí sì mú kí Jèhófà bù kún òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Héb. 11:32, 33) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Jẹ́fútà? Kí la máa ṣe táwọn ará wa bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tí wọ́n bá ṣàìdáa sí wa? Kò yẹ ká lá ò ní sin Jèhófà mọ́ torí pé ẹnì kan ṣẹ̀ wá. Má torí ìyẹn sọ pé o ò ní lọ sípàdé mọ́ tàbí pé o ò ní bá àwọn ará ìjọ ṣe mọ́. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jẹ́fútà ká sì ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Èyí á mú ká borí àwọn ìṣòro tó le koko, àá sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ.​—Róòmù 12:​20, 21; Kól. 3:13. w16.04 1:​7,9, 10

Friday, March 2

Àwa kò . . . juwọ́ sílẹ̀.​—2 Kọ́r. 4:1.

A gbọ́dọ̀ fara dà á, kì í wulẹ̀ ṣe fúngbà díẹ̀, àmọ́ títí dé òpin. Ká sọ pé ọkọ̀ òkun kan ń rì, táwọn èrò inú ọkọ̀ náà ò bá fẹ́ bómi lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ lúwẹ̀ẹ́ lọ sí etíkun. Ṣe lẹni tó bá lóun ò wẹ̀ mọ́ láì tiẹ̀ tíì lúwẹ̀ẹ́ débì kan á bómi lọ. Bẹ́ẹ̀ náà lẹni tó ti ń wẹ̀ bọ̀ tó wá kù díẹ̀ kó dé etíkun, tó wá ní òun ò wẹ̀ mọ́, àfàìmọ̀ kóun náà má bómi lọ. Tá a bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun, àfi ká fara dà á títí dé òpin. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fìwà jọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀.” (2 Kọ́r. 4:16) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó dá wa lójú hán-ún hán-ún pé Jèhófà máa mú ká lè fara dà á dé òpin. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa. Nítorí mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”​—Róòmù 8:​37-39. w16.04 2:17, 18

Saturday, March 3

Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, . . . a ó sì fi í fún un.​—Ják. 1:5.

Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o lè fòye mọ àwọn ohun tó lè mú kó ṣòro fún ẹ láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Sọ fún un pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ohun tó tọ́ nígbà ìṣòro. Wọ́n lè rán ẹ lọ sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n fìyà jẹ ọ́ torí pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà kó o lè ṣàlàyé ìdí tó ò fi lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á. (Ìṣe 4:​27-31) Jèhófà fún wa ní Bíbélì kó lè máa fún wa lókun nípa tẹ̀mí. Máa ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Há àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sórí torí bó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò ní Bíbélì lọ́wọ́, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ló máa kù ẹ́ kù. Bíbélì tún lè mú kí ìrètí tó o ní nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú túbọ̀ dájú. Ìrètí tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ lágbára tá a bá máa fara da inúnibíni. (Róòmù 8:25) Mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé àwọn ohun tó ò ń fojú sọ́nà fún nínú ayé tuntun, kó o wá máa wo ara rẹ níbẹ̀. w16.04 4:​14, 15

Sunday, March 4

Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.​—Mát. 10:8.

Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kì í wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Bí wọ́n bá tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ rárá, ohun tí púpọ̀ lára wọn máa ń sọ ni pé inú ọkàn àwọn Kristẹni ni Ìjọba Ọlọ́run wà. (Lúùkù 17:21) Wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba gidi kan ni Ìjọba Ọlọ́run àti pé Jésù Kristi ni Alákòóso Ìjọba náà. Bákan náà, wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba yìí ló máa fòpin sí gbogbo ìṣòro táwọn èèyàn ń kojú, àti pé láìpẹ́ ó máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 19:​11-21) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọdún Kérésìmesì àti ayẹyẹ Ọdún Àjíǹde ni wọ́n ń ṣe, wọ́n á láwọn ń fìyẹn rántí Jésù. Kò jọ pé wọ́n mọ àwọn ohun tí Jésù máa ṣe nígbà tí ìṣàkóso rẹ̀ bá nasẹ̀ dé ilẹ̀ ayé. Wọn ò mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wàásù. Kò yẹ kó jẹ́ torí àtikówó jọ ká sì tún kọ́ àwọn ilé àwòṣífìlà. Kò yẹ ká máa ta Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 2:17) Kò yẹ káwọn tó ń wàásù máa wá bí wọ́n á ṣe fi iṣẹ́ náà wá èrè sápò ara wọn.​—Ìṣe 20:​33-35. w16.05 2:​7, 8

Monday, March 5

Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì. ​—1 Kọ́r. 10:24.

Ká sọ pé o fẹ́ràn láti máa wọ aṣọ kan tó sì ṣeé ṣe kíyẹn máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn kan láàmú nínú ìjọ. Síbẹ̀, o mọ̀ pé kò sófin kankan nínú Bíbélì tó kà á léèwọ̀. Ó dáa, kí lèrò Jèhófà nípa ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tím. 2:​9, 10) Gbogbo Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló yẹ kó máa fi ìlànà yìí sílò, kì í ṣàwọn obìnrin nìkan. Ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a kì í ronú lórí ohun tá a bá ṣáà ti fẹ́ nìkan, a máa ń gba tàwọn míì rò, torí náà, a máa ń ronú lórí ipa tí aṣọ wa àti ìmúra wa máa ní lórí àwọn míì. Tá a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àá máa gba tiwọn rò, a ò sì ní fẹ́ ṣohun tó máa mú wọn kọsẹ̀ tàbí tó tiẹ̀ lè bí wọn nínú pàápàá.​—1 Kọ́r. 10:23; Fílí. 3:17. w16.05 3:14

Tuesday, March 6

Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.​—Aísá. 64:8.

Ádámù pàdánù àǹfààní tó ní láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Síbẹ̀, bí ọmọ aráyé ṣe ń gbilẹ̀ sí i, a rí lára àwọn ọmọ Ádámù tó yàn láti fi ara wọn sábẹ́ àkóso Ọlọ́run, kódà wọ́n pọ̀ gan-an, bí “àwọsánmà.” (Héb. 12:1) Bí wọ́n ṣe fara wọn sábẹ́ àkóso Ẹlẹ́dàá wọn yìí fi hàn pé òun ni wọ́n gbà ní Baba àti Amọ̀kòkò wọn, kì í ṣe Sátánì. (Jòh. 8:44) Bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run jẹ́ ká rántí ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Lóde òní, gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ní ẹ̀mí àti òtítọ́ ń sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì tún ń fara wọn sábẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n gbà pé ohun iyì gbáà ni pé káwọn máa pe Jèhófà ní Baba àwọn, káwọn sì mọ̀ ọ́n ní Amọ̀kòkò àwọn. Ǹjẹ́ o ka ara rẹ sí amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ṣó wù ẹ́ pé kí Ọlọ́run mọ ẹ́, kó o sì di ohun èlò tó fani mọ́ra, tínú rẹ̀ dùn sí? Ṣé ojú kan náà lo fi ń wo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, pé àwọn náà dà bí amọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà, àti pé ó ṣì ń mọ wọ́n lọ́wọ́? w16.06 1:​2, 3

Wednesday, March 7

Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́.​—2 Kọ́r. 13:5.

Bá a ṣe ń sún mọ́ ayé tuntun, a máa dán ìgbàgbọ́ tiwa náà wò. Torí náà, á dáa ká ronú lórí bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú lórí ojú tá a fi ń wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mo kà sí pàtàkì àtàwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé lóòótọ́ ni mo gba ohun tí Jésù sọ gbọ́? Tó bá di pé kí n máa pa ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí jẹ kí owó tó ń wọlé fún mi lè túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i, kí ni màá ṣe? Tí iṣẹ́ tí mò ń ṣe ò bá jẹ́ kí n ráyè ńkọ́? Ṣé màá gbà kí ayé sọ mí dà bó ṣe dà, kó sì fà mí kúrò nínú ètò Ọlọ́run?’ Àpẹẹrẹ míì ni ti ìránṣẹ́ Jèhófà kan tí kì í fẹ́ fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lórí irú ẹni tó yẹ kó máa bá ṣọ̀rẹ́, irú eré ìnàjú tó yẹ kí Kristẹni máa ṣe àti ìtọ́ni Bíbélì tó ní ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé bọ́rọ̀ tèmi náà ṣe rí nìyẹn?’ Tá a bá rí i pé bó ṣe rí nìyẹn, ó yẹ ká tètè yá a wá bí ìgbàgbọ́ wa ṣe máa túbọ̀ lágbára! Ó yẹ ká máa fi ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yẹ ara wa wò nígbà gbogbo. w16.06 2:​8, 9

Thursday, March 8

Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.​—Aísá. 60:22.

Inú ètò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ làwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe, síbẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ níbi gbogbo láyé láti máa gbèrú sí i. Nígbà tí òpin ètò nǹkan yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà nígbà yẹn. Àmọ́ Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìwàásù wọn. Bọ́dún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òun máa pọ̀ gan-an bó ṣe wà nínú ẹsẹ̀ ojúmọ́ wa tòní, ó sì fi kún un pé: “Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” Ó hàn gbangba pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti nímùúṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ìdí ni pé tá a bá fi iye àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé báyìí wé àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bẹ láyé, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jẹ́ pé àwọn èèyàn inú wọn kò tó iye wa. w16.06 4:​1, 2

Friday, March 9

Ẹ kò ha níye lórí ju [àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run] lọ bí?​—Mát. 6:26.

Jésù mọ̀ pé tí Jèhófà bá ń pèsè oúnjẹ fáwọn ẹyẹ, ó dájú pé ó máa pèsè oúnjẹ fún àwa èèyàn náà. (1 Pét. 5:​6, 7) Jèhófà ò ní fi oúnjẹ nù wá, àmọ́ ó lè mú kí àwọn ohun tá a gbìn hù tàbí kó pèsè owó tá a máa fi ra ohun tá a nílò. Jèhófà tún lè mú kí àwọn míì fún wa lára ohun tí wọ́n ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò sọ bí Ọlọ́run ṣe ń pèsè ilé fáwọn ẹyẹ, síbẹ̀ Jèhófà ti fún wọn ní ọgbọ́n àti ohun tí wọ́n á fi kọ́ ìtẹ́ tí wọ́n á máa gbé. Jèhófà lè ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè rí ilé tó dáa tí àwa àti ìdílé wa máa gbé. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀kọ́ ojúmọ́ wa tòní, ó dájú pé ó mọ̀ pé òun máa tó fi ẹ̀mí òun rúbọ fún aráyé. (Fi wé Lúùkù 12:​6, 7.) Kì í ṣe àwọn ẹyẹ tàbí àwọn ẹranko ni Jésù kú fún. Àwa èèyàn ló kú fún ká lè wà láàyè títí láé.​—Mát. 20:28. w16.07 1:​11-13

Saturday, March 10

Ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀gá lórí yín, níwọ̀n bí ẹ kò ti sí lábẹ́ òfin bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. ​—Róòmù 6:14.

Báwo làwa èèyàn ṣe kó sínú àjàgà ẹ̀ṣẹ̀ tá a sì ń kú? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Nípa àṣemáṣe ọkùnrin kan [ìyẹn Ádámù] ni ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” lé àtọmọdọ́mọ Ádámù lórí. (Róòmù 5:​12, 14, 17) Àmọ́, inú wa dùn pé a lè pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa darí wa. Tá a bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà láá máa darí wa. (Róòmù 5:​20, 21) Lóòótọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì ni wá, síbẹ̀ ìyẹn ò ní ká wá máa mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a lè bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá. Torí náà, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí là ń jẹ́ kó máa darí wa. Àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run . . . fún wa ní ìtọ́ni láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”​—Títù 2:​11, 12. w16.07 3:​5, 6

Sunday, March 11

[Ọlọ́run] sì mú un wá fún ọkùnrin náà.​—Jẹ́n. 2:22.

Ìgbéyàwó àkọ́kọ́ forí ṣánpọ́n torí pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà. “Ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” Sátánì Èṣù tan Éfà jẹ nígbà tó sọ fún un pé tó bá jẹ èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” á lè dá pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Éfà ò ronú pé ó yẹ kóun dúró de ọkọ òun kóun lè gbọ́ ohun tó máa sọ. Kàkà kí Ádámù náà ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ṣe ló kàn gba èso tí Éfà fún un, ó sì jẹ ẹ́. (Ìṣí. 12:9; Jẹ́n. 2:​9, 16, 17; 3:​1-6) Nígbà tí Jèhófà béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ Ádámù, ṣe ló di ẹ̀bi náà ru ìyàwó rẹ̀. Éfà náà tún di ẹ̀bi ru ejò pé òun ló tan òun jẹ. (Jẹ́n. 3:​12, 13) Àmọ́ gbogbo àwáwí yẹn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Torí pé tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Jèhófà kà wọ́n sí ọlọ̀tẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ ńlá lèyí kọ́ wa! Kí ìgbéyàwó tó lè yọrí sí rere, àtọkọ àtìyàwó gbọ́dọ̀ mẹ̀bi wọn lẹ́bi, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà. w16.08 1:​1, 4, 5

Monday, March 12

Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀. ​—Mát. 19:6.

Ohun kan tó máa ń fa èdèkòyédè láàárín àwọn tọkọtaya ni pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Ẹnì kan lè rò pé bóun bá ti lọ́kọ tàbí láya, kóun máa gbádùn ló kù. Àmọ́ tí nǹkan ò bá rí bó ṣe rò lẹ́yìn tó ṣègbéyàwó, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í kanra, kó máa bínú sẹ́nì kejì rẹ̀, ó tiẹ̀ lè ronú pé ìbágbé àwọn kò ni wọ̀ mọ́. Ohun míì tó tún lè fa èdèkòyédè ni pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn méjèèjì dàgbà sí, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn yàtọ̀ síra, ẹnu wọn sì lè má kò tó bá dọ̀rọ̀ owó. Bákan náà, èrò wọn lè yàtọ̀ ní ti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn àna wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ. Àmọ́, inú wa dùn pé púpọ̀ lára àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láìsì wàhálà torí pé wọ́n ń jẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà. Bí àwọn Kristẹni tọkọtaya kan bá níṣòro tó kọjá agbára wọn, ó yẹ kí wọ́n lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn alàgbà yìí á jẹ́ kí wọ́n rí bí wọ́n ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Tá a bá fẹ́ yanjú ìṣòro láàárín àwa àti ẹnì kejì wa, ó yẹ ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò ká sì máa fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù.​—Gál. 5:​22, 23. w16.08 2:​11-13

Tuesday, March 13

Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.​—Lúùkù 5:10.

Àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kò tó nǹkan, síbẹ̀ ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ kan wà tí Jésù jókòó sínú ọkọ̀ ojú omi tó sì ń tibẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ló ṣe iṣẹ́ ìyanu tó jẹ́ kí Pétérù kó ẹja wọ̀ǹtìwọnti jáde lódò. Ó wá sọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ tòní. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe yìí? Pétérù àtàwọn yòókù rẹ̀ “pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé [Jésù].” (Lúùkù 5:​1-11) Nikodémù, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn náà nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù, àmọ́ ẹ̀rù ń bà á torí ohun táwọn èèyàn máa sọ tí wọ́n bá rí i tó ń bá Jésù sọ̀rọ̀ ní gbangba. Torí náà, ó lọ bá Jésù lálẹ́, Jésù ò wá sọ pé ilẹ̀ ti ṣú, ó yẹ kóun lọ sùn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fara balẹ̀ bá a sọ̀rọ̀. (Jòh. 3:​1, 2) Jésù máa ń wá àyè fáwọn èèyàn torí ó fẹ́ kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa sapá láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a ti bá sọ̀rọ̀ ká sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. w16.08 4:​10, 11

Wednesday, March 14

Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.​—Míkà 6:8.

A mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ a sì gbà pé ìlànà Jèhófà ló dára jù lọ fún wa. Torí náà, tá a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tá a sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìlànà rẹ̀ la ó máa tẹ̀ lé nígbà gbogbo. Ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tún máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò tó bá fẹ́ ṣèpinnu. Torí náà, à ń fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà bá Ọlọ́run rìn tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, tá a sì ń ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa. Ó yẹ kó ṣe kedere nínú ọ̀nà tá à ń gbà múra pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Àwọn ará wa àtàwọn tó wà ládùúgbò gbọ́dọ̀ rí i nínú ọ̀nà ìmúra wa pé Ọlọ́run mímọ́ là ń ṣojú fún. Ọlọ́run ní àwọn ìlànà tó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé, inú wa sì máa ń dùn láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. A gbóríyìn fún ẹ̀yin arákùnrin àtẹ̀yin arábìnrin wa pé ẹ̀ ń múra lọ́nà tó bójú mu ẹ sì ń hùwà tó yẹ Kristẹni. Ìyẹn ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè rí ìyè. À ń tipa bẹ́ẹ̀ fògo fún Jèhófà, a sì ń múnú rẹ̀ dùn. w16.09 3:​18-20

Thursday, March 15

Ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn wọ̀jà, o sì borí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.​—Jẹ́n. 32:28.

Jékọ́bù jà fitafita, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí ìbùkún Ọlọ́run gbà ó pinnu pé òun ò ní jáwọ́ lára ẹni tí òun ń bá jà! (Jẹ́n. 32:​24-26) Ọkàn akin tó ṣe yìí sì mérè wá, torí pé ó rí ìbùkún gbà. Áńgẹ́lì náà sọ Jékọ́bù lórúkọ tuntun, ó pè é ní Ísírẹ́lì, (tó túmọ̀ sí “Ẹni tó bá Ọlọ́run wọ̀jà”). Jékọ́bù rí ojúure Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀, ohun táwa náà sì ń fẹ́ nìyẹn. Rákélì ìyàwó Jékọ́bù ń ronú ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà mú ìlérí tó ṣe pé òun máa bù kún ọmọ tí ọkọ òun máa ní ṣẹ. Àmọ́ Rákélì ò bímọ. Nígbà yẹn sì rèé, àbùkù gbáà ni bí obìnrin kan ò bá bímọ. Ó ṣe kedere pé ìṣòro tó kọjá agbára rẹ̀ yìí máa bà á nínú jẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Kí wá ni Rákélì ṣe láti fàyà rán ìṣòro yẹn? Kò sọ̀rètí nù, ìdí nìyẹn tó fi túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà. Jèhófà gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ Rákélì, ó sì fi ọmọ jíǹkí rẹ̀.​—Jẹ́n. 30:​8, 20-24. w16.09 2:​6, 7

Friday, March 16

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ.​—Héb. 4:12.

Ó tún ṣe pàtàkì gan-an pé kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ pé ayé wọn á dùn bí oyin bí wọ́n bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Sm 1:​1-3) Onírúurú ọ̀nà lo lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kí wọ́n wò ó bíi pé àwọn fẹ́ lọ gbé níbi àdádó kan, táwọn míì á sì máa bá wọn gbé níbẹ̀. Wá bi wọ́n pé: “Tẹ́ ẹ bá fẹ́ máa wà ní àlàáfíà, irú ìwà wo lẹ máa fẹ́ káwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé máa hù?” Lẹ́yìn náà, ẹ jọ jíròrò irú àwọn ànímọ́ tó yẹ káwa Kristẹni ní bó ṣe wà nínú Gálátíà 5:​19-23. Tó o bá ń kọ́ wọn bẹ́ẹ̀, ó kéré tán àwọn ọmọ rẹ á kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì. Àkọ́kọ́, wọ́n á mọ̀ pé tá a bá ń fi ìlànà Ọlọ́run sílò, àá wà lálàáfíà, àá sì wà níṣọ̀kan. Ìkejì, á ṣe kedere sí wọn pé bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lónìí, ńṣe ni Jèhófà ń múra wa sílẹ̀ láti gbénú ayé tuntun. (Aísá. 54:13; Jòh. 17:3) O lè wá lo àwọn ìrírí tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa láti mú kí ẹ̀kọ́ yìí wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” tó wà nínu ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. w16.09 5:​13, 14

Saturday, March 17

[Ẹ ra] àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.​—Éfé. 5:16.

Kò sí àní-àní pé ọwọ́ wa máa ń dí, síbẹ̀ ká rí i pé à ń wáyè láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé. (Éfé. 5:15) Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé kì í ṣe torí ká lè tètè parí ìwé tá à ń kà la ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ tàbí torí ká lè dáhùn nípàdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà táá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wá lọ́kàn, táá sì mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Kí ohun tá à ń kọ́ tó lè wọ̀ wá lọ́kàn, ó yẹ ká máa ronú nípa bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe kàn wá, kì í ṣe bá a ṣe fẹ́ fi kọ́ àwọn míì nìkan ló yẹ ká máa rò. (Fílí. 1:​9, 10) Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá ń múra òde ẹ̀rí, tá à ń múra ìpàdé tàbí tá à ń múra iṣẹ́ tá a ní nípàdé, a kì í sábà ronú bọ́rọ̀ náà ṣe kàn wá. Wo àpèjúwe yìí ná: Àwọn tó ń se oúnjẹ tà sábà máa ń tọ́ oúnjẹ tí wọ́n ń sè wò. Síbẹ̀, ìtọ́wò yẹn kò tó láti gbẹ́mìí wọn ró. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn náà gbọ́dọ̀ máa jẹun dáadáa tí wọ́n bá máa lókun. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká rí i pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ohun tá à ń kọ́ á fi wọ̀ wá lọ́kàn. w16.10 2:​10, 11

Sunday, March 18

Nípa ìgbàgbọ́ ni a róye pé àwọn ètò àwọn nǹkan ni a mú wà létòletò nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a rí ti wá di èyí tí ó jáde wá láti inú àwọn ohun tí kò fara hàn.​—Héb. 11:3.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Hébérù 11:1. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé orí ohun méjì tí a kò lè fojú rí ni ìgbàgbọ́ dá lé: (1) “Ohun tí a ń retí.” Lára rẹ̀ ni àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àmọ́ tí kò tíì ṣẹlẹ̀, bí ìgbà tí Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà búburú, táá sì sọ ayé di Párádísè. (2) “Àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” Nínú ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà” túmọ̀ sí “àwọn ẹ̀rí tó dáni lójú” pé àwọn ohun tá ò lè fojú rí wà lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, a gbà pé Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi àtàwọn áńgẹ́lì wà, bẹ́ẹ̀ náà la sì gbà pé Ìjọba Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ohun tá à ń retí ṣì wà lọ́kàn wa digbí àti pé a gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ bá ò tiẹ̀ rí àwọn nǹkan ọ̀hún? Kì í ṣe pé ká kàn sọ pé a nígbàgbọ́, àmọ́ ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. w16.10 4:6

Monday, March 19

Ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú.​—Héb. 3:13.

Jèhófà àti Jésù mọyì ohun tí kálukú wa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, kódà tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba lagbára wa gbé torí ipò wa. (Lúùkù 21:​1-4; 2 Kọ́r. 8:12) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará kan tó jẹ́ àgbàlagbà máa ń sapá gan-an kí wọ́n lè máa wá sípàdé déédéé, wọn ò sì gbẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé kò yẹ ká máa gbóríyìn fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ká sì máa fún wọn níṣìírí? Máa lo àwọn àǹfààní tó o ní láti fún àwọn míì níṣìírí. Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó wú wa lórí, ó yẹ ká gbóríyìn fún un. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ sí Áńtíókù ní Písídíà. Àwọn alága sínágọ́gù tó wà níbẹ̀ sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.” Pọ́ọ̀lù wá sọ àsọyé kan tó fakíki. (Ìṣe 13:​13-16, 42-44) Táwa náà bá ní ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a lè sọ fáwọn ará, ǹjẹ́ kò yẹ ká sọ ọ́? Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa fáwọn èèyàn níṣìírí, àwọn náà á máa fún wa níṣìírí.​—Lúùkù 6:38. w16.11 1:​3, 15, 16

Tuesday, March 20

Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.​—Òwe 15:3.

Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní pé a wà nínú ètò Jèhófà! Torí pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, a sì mọ̀ pé ohun tó tọ́ la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè fi hàn pé Jèhófà la gbà pé ó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ojoojúmọ́ layé yìí ń burú sí i, torí náà a gbọ́dọ̀ “kórìíra ohun búburú” bí Jèhófà náà ṣe kórìíra rẹ̀. (Sm. 97:10) A ò ní fara mọ́ èrò àwọn èèyàn inú ayé tí wọ́n gbà pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.” (Aísá. 5:20) Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń sapá láti jẹ́ mímọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí, a sì máa ń yẹra fún ìwàkiwà torí pé a fẹ́ múnú Jèhófà dùn. (1 Kọ́r. 6:​9-11) Àwọn ìlànà Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé nígbèésí ayé wa torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà a sì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, gbogbo ìgbà la máa ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí nínú ilé, nínú ìjọ, níbi iṣẹ́, níléèwé àti láwọn ibòmíì. w16.11 3:13

Wednesday, March 21

Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.​—Róòmù 13:1.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ inú làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ń ṣe nǹkan, síbẹ̀ láwọn ọdún 1914 sí 1919, wọn ò mọ ibi tó yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ mọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ ogun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pàṣẹ pé káwọn èèyàn ya May 30, 1918, sọ́tọ̀ láti gbàdúrà fún àlàáfíà, ètò Ọlọ́run sọ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ pé káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dara pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ará kan lọ yáwó kí wọ́n lè fowó ti ogun náà lẹ́yìn, nígbà táwọn mélòó kan tiẹ̀ wọṣẹ́ ológun tí wọ́n sì gbébọn lójú ogun. Àmọ́ o, a ò lè sọ pé àṣìṣe táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ṣe ló fà á tí wọ́n fi lọ sígbèkùn Bábílónì kí wọ́n lè gba ìbáwí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn yẹra pátápátá fún ìsìn èké, ó sì ṣe kedere pé lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, wọn ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìsìn èké ayé yìí.​—Lúùkù 12:​47, 48. w16.11 5:9

Thursday, March 22

Àwa . . . ń rìn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.​—Róòmù 8:4.

O lè máa ronú pé kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara.” Lóde òní, Ọlọ́run ti sọ àwọn Kristẹni di ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì ti kà wọ́n sí olódodo, síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa kó sínú ewu yìí. Ó ṣeni láàánú pé kò sẹ́ni tí kò lè bẹ̀rẹ̀ sí í rìn níbàámu pẹ̀lú ẹran ara. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni kan ní Róòmù jẹ́ ẹrú fún ìfẹ́ ọkàn ara wọn. Lára irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ ni ìṣekúṣe, àjẹkì, àmuyíràá àtàwọn nǹkan míì. Àwọn kan tiẹ̀ tún ń tan àwọn aláìmọ̀kan jẹ. (Róòmù 16:​17, 18; Fílí. 3:​18, 19; Júúdà 4, 8, 12) Ẹ tún rántí pé ìgbà kan wà tí arákùnrin kan ní Kọ́ríńtì ń fẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀. (1 Kọ́r. 5:1) Èyí mú ká rídìí tí Ọlọ́run fi lo Pọ́ọ̀lù láti kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe ‘gbé èrò inú wọn ka ẹran ara.’ (Róòmù 8:​5, 6) Ìkìlọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an lónìí. w16.12 2:​5, 8, 9

Friday, March 23

Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.​—Òwe 12:25.

Tó o bá ń sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún ẹnì kan tó ṣeé finú hàn, èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lè fara da àdánwò. O lè fọ̀rọ̀ lọ ọkọ tàbí aya rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tàbí alàgbà ìjọ, wọ́n á sì jẹ́ kọ́rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn rẹ. Tó o bá sọ ohun tó ń ṣe ẹ́, láìfi nǹkan kan pa mọ́, ó ṣeé ṣe kó o rọ́nà àbáyọ. Bíbélì sọ fún wa pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” (Òwe 15:22) Jèhófà tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn àníyàn wa nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ. Níbẹ̀, a máa ń wà pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí. (Héb. 10:​24, 25) Irú “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” yìí máa fún ìgbàgbọ́ ẹ lókun, á sì mú kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti borí àníyàn rẹ.​—Róòmù 1:12. w16.12 3:​17, 18

Saturday, March 24

[Háná] . . . bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà.​—1 Sám. 1:10.

Tá a bá ní ìṣòro àìlera tàbí ìṣòro míì tó kọjá agbára wa, ó yẹ ká kó gbogbo ìṣòro náà fún Jèhófà, ká sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó máa tọ́jú wa. (1 Pét. 5:​6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká sapá láti máa wá sí ìpàdé déédéé, ká sì máa kópa nínú àwọn apá ìjọsìn míì. (Héb. 10:​24, 25) Àwọn òbí tí ọmọ wọn ti fi Jèhófà sílẹ̀ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Sámúẹ́lì. Àwọn ọmọ Sámúẹ́lì ò ṣe ìfẹ́ Jèhófà, Sámúẹ́lì ò sì lè fipá mú àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti dàgbà yìí pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tó kọ́ wọn. (1 Sám. 8:​1-3) Ńṣe ló fi ọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. Síbẹ̀, Sámúẹ́lì kò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run yingin, ó sì ṣe ohun tó múnú Jèhófà, Baba rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Lónìí, àwọn òbí Kristẹni kan ti bá ara wọn nírú ipò bẹ́ẹ̀. Ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:20) Síbẹ̀, àwọn òbí náà gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà torí èyí lè mú kí ọmọ náà ronú, kó sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. w17.01 1:​15, 16

Sunday, March 25

Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.​— Fílí. 2:3.

Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn sábà máa ń mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó mọ ibi tágbára òun mọ, ó máa ń gba àṣìṣe rẹ̀, ó sì máa ń gbàmọ̀ràn. Inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn onírẹ̀lẹ̀. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lòun lè ṣe, kì í sì kọjá àyè rẹ̀. Èdè Gíríìkì tí wọ́n lò fún ìmẹ̀tọ́mọ̀wà nínú Bíbélì fi hàn pé amẹ̀tọ́mọ̀wà èèyàn máa ń ro tàwọn míì mọ́ tiẹ̀, kì í sì kọjá àyè rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Báwo lèèyàn a ṣe mọ̀ pé òun ti fẹ́ máa kọjá àyè òun? Díẹ̀ rèé lára àwọn nǹkan téèyàn fi lè mọ̀. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ka ara wa sí bàbàrà torí pé a láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. (Róòmù 12:16) Ó lè jẹ́ pé à ń pe àfiyèsí sí ara wa lọ́nà tí kò tọ́. (1 Tím. 2:​9, 10) A sì lè máa wá báwọn èèyàn á ṣe gba èrò tiwa kìkì nítorí pé a lẹ́nu láwùjọ, tàbí torí pé a mọ àwọn èèyàn dáadáa, tàbí kẹ̀ torí a rò pé èrò tiwa ló tọ̀nà. Tírú ìwà yìí bá ti mọ́ wa lára, a tiẹ̀ lè má fura pé àṣejù ti fẹ́ máa wọ ọ̀rọ̀ wa, àti pé a ti ń kọjá àyè wa.​—1 Kọ́r. 4:6. w17.01 3:​6-8

Monday, March 26

Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn, ọlá ńlá àwọn arúgbó sì ni orí ewú wọn.​—Òwe 20:29.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí iṣẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lójoojúmọ́, ó sì ń gbòòrò sí i. Bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan tuntun, bẹ́ẹ̀ là ń rí àwọn ọ̀nà tuntun tá a lè gbà ṣe wọ́n, kódà ó lè gba pé ká lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé nígbà míì. Torí náà, kì í rọrùn fáwọn tó ti dàgbà láti bójú tó àwọn iṣẹ́ tuntun tó ń yọjú yìí. (Lúùkù 5:39) Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn àgbàlagbà yìí lè ṣe àwọn iṣẹ́ náà, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà tó wọn lọ́jọ́ orí ṣì lágbára àti okun jù wọ́n lọ. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn àgbàlagbà dá àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́ láti bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run. (Sm. 71:18) Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn tó ń múpò iwájú láti gbé lára iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí. Ó máa ń ká àwọn míì lára pé àwọn ò ní lè bójú tó àwọn ojúṣe kan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò dá wọn lójú pé àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí á lè ṣe iṣẹ́ náà dáadáa. Àwọn kan sì lè ronú pé àwọn ò lè ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Bó ti wù kó rí, kò yẹ káwọn tí kò tó àwọn àgbàlagbà lọ́jọ́ orí bínú bí wọn ò bá fún wọn láfikún iṣẹ́, ṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe sùúrù. w17.01 5:​3, 4

Tuesday, March 27

Nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.​—Róòmù 5:18.

Jésù di èèyàn pípé bíi ti Ádámù. (Jòh. 1:14) Àmọ́ Jésù kò ṣe bíi ti Ádámù ní tiẹ̀, ohun tí Jèhófà retí pé kí ẹni pípé ṣe náà ló ṣe. Kódà nígbà tí Jésù kojú àdánwò tó lágbára, kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì rú òfin Ọlọ́run kankan. Torí pé ẹni pípé ni Jésù, ikú rẹ̀ lè gba àwa èèyàn là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹni pípé ni Jésù, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, ohun tó yẹ kí Ádámù náà ṣe nìyẹn. (1 Tím. 2:6) Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kí ‘ọ̀pọ̀ ènìyàn,’ lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà lè wà láàyè títí láé. (Mát. 20:28) Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé ìràpadà tí Jésù san ló máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (2 Kọ́r. 1:​19, 20) Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. w17.02 1:​15, 16

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Jòhánù 12:​12-19; Máàkù 11:​1-11

Wednesday, March 28

Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara dà [á].​—Héb. 12:2.

Ńṣe lọ̀rọ̀ ìgbésí ayé dà bí ìgbà tẹ́nì kan ń rìnrìn-àjò. Tó sì ṣẹlẹ̀ pé ó máa gba ibì kan tó ṣókùnkùn kọjá. Àmọ́, ó mọ̀ dájú pé bó ti wù kó rí, òun máa tó pa dà já síbi tí ìmọ́lẹ̀ wà. Ìgbésí ayé lè dà bí irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀. Ìgbà míì wà tá a máa dojú kọ ìṣòro tó nira gan-an, táá sì wá dà bíi pé ìṣòro ọ̀hún ò ní tán. Bóyá ó ti ṣe Jésù náà bẹ́ẹ̀ rí nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Kó tó di pó kú sorí òpó igi oró tí wọ́n kàn án mọ́, àwọn èèyàn fi í ṣẹ̀sín, ó sì fara da ọ̀pọ̀ ìrora. Ó dájú pé àkókò yìí ló nira fún un jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀! (Héb. 12:3) Síbẹ̀, Jésù fara dà á. Ó pọkàn pọ̀ sórí ibi tí ìfaradà rẹ̀ máa já sí, ní pàtàkì jù lọ, ó máa yọrí sí yíya orúkọ Ọlọ́run sí mímọ́, ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun gbà pé Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti máa ṣàkóso. Ó mọ̀ pé àdánwò náà ò ní máa lọ títí ayé, àmọ́ èrè tóun á gbà lọ́run máa wà títí láé. Ó lè dà bíi pé àwọn àdánwò tíwọ náà ń kojú lónìí ò ní tán mọ́, ó sì lè máa fa ẹ̀dùn ọkàn fún ẹ, àmọ́ gbogbo ẹ̀ máa tó dópin. w16.04 2:10

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Jòhánù 12:​20-50

Thursday, March 29

Nípasẹ̀ rẹ̀ [Jésù] àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa. ​—Éfé. 1:7.

Lónìí, ńṣe làwọn èèyàn ń gbé ìgbésí ayé bó ṣe wù wọ́n, wọn ò sì rídìí tí wọ́n á fi máa wá ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fáwọn kan ni wọ́n tó mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ gan-an, ipa tó ń ní lórí wa àti ohun tó yẹ ká ṣe ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Inú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti rà wá pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. (1 Jòh. 4:​9, 10) Ẹbọ ìràpadà Kristi yìí ni ẹ̀rí tó ga jù lọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ṣe lágbára tó. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rà wá pa dà, àá rí ìdáríjì gbà, àá sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Héb. 9:14) Ẹ ò rí i pé ìròyìn rere lèyí jẹ́, kò ṣeé bò mọ́ra! w16.07 4:​6, 7

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Lúùkù 21:​1-36

Friday, March 30

[Kristi] sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa.​—Héb. 9:12.

Tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá pátápátá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé Jèhófà máa ‘pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́.’ (Ìṣe 3:​19-21) Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà ti gba àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣọmọ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Róòmù 8:​15-17) Ní ti àwa “àgùntàn mìíràn,” ṣe lọ̀rọ̀ wa dà bí ìgbà tí Jèhófà kọ orúkọ wa sílẹ̀ pé òun máa gbà wá ṣọmọ. Lẹ́yìn tá a bá ti di pípé, tá a sì ti yege ìdánwò ìkẹyìn, Jèhófà máa gbà wá ṣọmọ, bí ìgbà tó buwọ́ lu ìwé tó kọ orúkọ wa sí. (Róòmù 8:​20, 21; Ìṣí. 20:​7-9) Títí ayé ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Títí láé sì ni ìràpadà náà á máa ṣe wá láǹfààní. Àǹfààńí tí ẹ̀bùn yìí ń ṣe wá kò ní pẹ̀dín láé. Kò sẹ́ni náà tàbí ohunkóhun tó lè gba ẹ̀bùn náà lọ́wọ́ wa. w17.02 2:​15, 16

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Mátíù 26:1-5, 14-16; Lúùkù 22:1-6

Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Saturday, March 31

Bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi.​—1 Jòh. 2:1.

Nígbà tí Jèhófà ní ká wá sin òun, ó dájú pé ó mọ àwọn ohun táá máa bá wa fínra. Ó sì mọ̀ pé kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, Jèhófà ò torí ìyẹn sọ pé òun ò lè bá irú wa ṣọ̀rẹ́. Ìfẹ́ mú kí Ọlọ́run fún wa lẹ́bùn iyebíye kan, ìyẹn ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jòh. 3:16) Tá a bá ronú pìwà dà, tá a sì tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà yìí, ọkàn wa á balẹ̀ pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà ò yingin, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé.​—1 Tím. 1:15. w16.05 4:​6, 7

Bíbélì kíkà nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Mátíù 26:17-19; Máàkù 14:12-16; Lúùkù 22:7-13 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 14) Jòhánù 13:1-5; 14:1-3

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́