February
Thursday, February 1
Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré.—Ják. 1:4.
“Iṣẹ́” wo ni ìfaradà gbọ́dọ̀ ṣe pé pérépéré? Ìfaradà máa jẹ́ ká ‘pé pérépéré, ká sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.’ (Ják. 1:4) Tá a bá ń kojú àdánwò, ó ṣeé ṣe ká kíyè sí i pé ó yẹ ká túbọ̀ máa mú sùúrù, ká túbọ̀ máa ronú jinlẹ̀ ká lè mọ ọpẹ́ dá tàbí ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń fara da àdánwò, bẹ́ẹ̀ la ó máa túbọ̀ mú sùúrù, àá mọpẹ́ dá, àá túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ máa hùwà tó yẹ Kristẹni. Torí a mọ̀ pé ṣe ni ìfaradà máa ń mú kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára, a ò ní fẹ́ rú òfin Jèhófà tàbí ká gbọ̀nà ẹ̀bùrú wá ojútùú sí àdánwò tó bá dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, tí èrò tí kò tọ́ bá ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣáá, má ṣe jẹ́ kíyẹn mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́! Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé èrò búburú náà kúrò lọ́kàn kíá. Ṣé mọ̀lẹ́bí rẹ kan ló ń ṣe inúnibíni sí ẹ? Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì! Pinnu pé wàá máa sin Jèhófà nìṣó. Ìyẹn á mú kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Má gbàgbé pé, ká tó lè rí ojú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ní ìfaradà.—Róòmù 5:3-5; Ják. 1:12. w16.04 2:15, 16
Friday, February 2
Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.—Fílí. 2:3.
Àwọn èèyàn sábà máa ń fọ́nnu nípa ẹ̀yà wọn, ìlú wọn, orílẹ̀-èdè wọn, tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa fi yangàn pàápàá. Àmọ́ lójú Jèhófà, kò sẹ́ni tó sàn ju ẹnì kan lọ, orílẹ̀-èdè kan ò sì sàn ju òmíì. Bákan náà ni gbogbo wa rí lójú Jèhófà. Lóòótọ́, ànímọ́ tá a ní ò jọra, àmọ́ bí àwọn ànímọ́ tá a ní ṣe yàtọ̀ síra yẹn gan-an ni kì í jẹ́ káyé tètè súni. Kì í ṣe pé Jèhófà fẹ́ ká pa àṣà ìbílẹ̀ wa tì. Àmọ́, kò fẹ́ ká máa ronú pé a dáa ju àwọn ẹlòmíì lọ. (Róòmù 10:12) Kò yẹ ká máa fi orílẹ̀-èdè wa yangàn débi pé àá wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó dáa ju àwọn tó kù lọ. Tó bá jẹ́ nǹkan tá à ń ṣe nìyẹn, ó máa ṣòro fún wa láti wà láìdá sí tọ̀tún-tòsì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn. Àwọn Hébérù kan ń ṣe ojúṣàájú sáwọn opó tó jẹ́ Gíríìkì. (Ìṣe 6:1) Àmọ́, báwo la ṣe máa mọ̀ tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í nírú ìwà bẹ́ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ ìlú wa bá gbà wá nímọ̀ràn, ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa sọ fún un pé, ‘Àwa ti gbọ́n ju gbogbo ìyẹn lọ níbí,’ ká sì fọwọ́ rọ́ ohun tó sọ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ìmọ̀ràn pàtàkì tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. w16.04 4:12, 13
Saturday, February 3
Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.—Lúùkù 4:43.
“Ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” ni Jésù wàásù rẹ̀, ohun tó sì retí pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà máa ṣe nìyẹn. Àwùjọ àwọn èèyàn wo ló ń wàásù ìhìn rere náà ní “gbogbo orílẹ̀-èdè”? (Mát. 28:19) Ìdáhùn náà ò lọ́jú pọ̀ rárá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni. Àlùfáà kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé òun ti gbé ní oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè tóun bá sì ti dé lòun máa ń bi àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ pé kí ni lájorí ohun tí wọ́n ń wàásù. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí náà máa ń sọ fún un? Àlùfáà náà sọ pé: “Inú wọn pò débi pé ìdáhùn kan náà ni gbogbo wọn ń fún mi, wọ́n á ní: ‘Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni.’” Inú àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn ò kúkú pò, torí pé gbogbo wọn wà níṣọ̀kan lohùn wọn ṣe ṣọ̀kan, bó sì ṣe yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa fohùn ṣọ̀kan nìyẹn. (1 Kọ́r. 1:10) Wọ́n sì tún ń wàásù ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Ìwé ìròyìn yìí wà ní èdè igba ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta [254], iye ẹ̀dà tá a sì ń tẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́ta [59,000,000], èyí ló sì wá mú kó jẹ́ ìwé ìròyìn tí ìpínkiri rẹ̀ pọ̀ jù lọ láyé. w16.05 2:6
Sunday, February 4
Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀. — 2 Kọ́r. 9:7.
Ká sọ pé ó wù ẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ kí àwọn ohun ìní díẹ̀ lè tẹ́ ọ lọ́rùn. Àmọ́, o tún bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bóyá ìwọ̀nba ohun ìní díẹ̀ á tẹ́ ọ lọ́rùn tí wàá sì lè bójú tó àwọn ohun tó o nílò nípa tara. Lóòótọ́, kò sófin kankan nínú Bíbélì tó sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó ṣe tán èèyàn lè jẹ́ akéde kó sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́, Jésù fi dá wa lójú pé Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn tó bá yááfì àwọn nǹkan nítorí Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 18:29, 30) Yàtọ̀ síyẹn, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn “ẹbọ ìyìn àtọkànwá” wa, inú rẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìjọsìn tòótọ́ lè máa tẹ̀ síwájú. (Sm. 119:108, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Tó o bá ronú lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ yìí, tó o sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, ǹjẹ́ o ò ní fòye mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Tó o bá ń ronú jinlẹ̀ lọ́nà yìí, wàá lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, Baba wa ọ̀run á sì bù kún rẹ. w16.05 3:13
Monday, February 5
Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá . . . ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé.—Oníw. 12:1.
Kì í ṣàwọn ọ̀dọ́ nìkan ló máa ń kojú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro tá a máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́. Gbogbo wa la ní láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa, ká máa kó ara wa níjàánu, ká má jẹ́ káyé sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà, ká má kẹ́gbẹ́ búburú ká má sì lọ́wọ́ sáwọn eré ìnàjú tí kò yẹ Kristẹni. Àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì la máa ń jíròrò nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́. Ṣó yẹ káwọn àgbàlagbà máa ronú pé àwọn ti dàgbà ju ẹni tó ń ka àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́? Rárá! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ la dìídì ṣe àwọn ìtẹ̀jáde yìí fún, orí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ṣàǹfààní fún tọmọdétàgbà ni gbogbo ẹ̀ dá lé, gbogbo wa sì ni àwọn ìtẹ̀jáde yìí máa ṣe láǹfààní. Yàtọ̀ sí pé àwọn ìtẹ̀jáde yìí máa ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro, ó tún máa ń mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wọn, kí wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ gbọ́ ná, ṣáwọn ọ̀dọ́ nìkan làwọn ìtẹ̀jáde yìí wúlò fún ni? Rárá!—Oníw. 12:13. w16.05 5:15, 16
Tuesday, February 6
Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Diu. 6:4, 5.
“Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.” Ọ̀rọ̀ yìí fakíki lóòótọ́! Ìránnilétí yìí mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbára dì láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá pà dé bí wọ́n ṣe ń múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Táwa náà bá fi ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn, àá lè kojú ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, àá sì gbádùn Párádísè lẹ́yìn náà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tá à ń sìn ín tọkàntọkàn, tá a sì ń sapá láti pa ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni mọ́. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó dájú pé a máa rí ìmúṣẹ ìlérí tí Jésù ṣe fún àwọn ẹni bí àgùntàn pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.”—Mát. 25:34. w16.06 3:2, 20
Wednesday, February 7
Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ.—Jer. 17:9.
Ìgbéraga lè mú kéèyàn máa dá ara rẹ̀ láre, ìyẹn sì lè mú kéèyàn ṣòro tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún. Ǹjẹ́ inú ti bí ẹ rí torí ohun tí ará kan ṣe sí ẹ tàbí torí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́? Nígbà tó ṣẹlẹ̀, kí lo ṣe? Ṣé o wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga ni, àbí ohun tó gbà ẹ́ lọ́kàn jù ni bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà tí wàá sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà? (Sm. 119:165; Kól. 3:13) Téèyàn bá ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹní mu omi, bóyá tó tiẹ̀ ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá, ṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa kọtí ikún sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run. Tó bá yá, ẹ̀ṣẹ̀ á wá di bárakú sí i lára. (Oníw. 8:11) Arákùnrin kan tó máa ń wo àwòrán oníhòòhò sọ pé: “Mo dẹni tó ń ṣàríwísí àwọn alàgbà.” Ìwòkuwò tó ń wò náà wá mú kó máa jó rẹ̀yìn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Nígbà tí ohun tó ń ṣe lu síta, àwọn alàgbà ràn án lọ́wọ́. Ká sòótọ́, ẹlẹ́ran ara ni gbogbo wa. Àmọ́, tó bá di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí àwọn ará tàbí tá à ń ronú pé kò sóhun tó burú nínú ìwàkiwà tá à ń hù, tá ò tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, tá ò sì jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́, a jẹ́ pé ọkàn wa ti ń le nìyẹn. w16.06 2:5, 6
Thursday, February 8
Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín.—Matt. 6:25.
Àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n da ara wọn láàmú lé lórí. Ó sì nídìí tí Jésù fi sọ pé kí wọ́n má ṣàníyàn mọ́. Ìdí ni pé téèyàn bá ń ṣàníyàn, kò ní lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé. Ọ̀pọ̀ nǹkan tá a gbà pé ó pọn dandan pàápàá ni ò yẹ ká máa ṣàníyàn lé. Jésù tẹ ọ̀rọ̀ yìí mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn torí pé ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kìlọ̀ fún wọn nínú Ìwàásù Lórí Òkè. (Mát. 6:27, 28, 31, 34) Ó mọ ohun táwọn èèyàn nílò lójoojúmọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó mọ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á máa gbé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1) Irú àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn ni àìríṣẹ́ ṣe, owó ọjà tó ń lọ sókè, àìtó oúnjẹ àti ipò òṣì tó ń ni ọ̀pọ̀ lára. Síbẹ̀, Jésù mọ̀ pé ‘ọkàn ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ, ara sì sàn ju aṣọ lọ.’ w16.07 1:8, 9
Friday, February 9
Mo di òjíṣẹ́ èyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.—Éfé. 3:7.
Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí Jèhófà ní ká máa ṣe là ń ṣe lọ́nà tó pé pérépéré, a jẹ́ pé a lẹ́tọ̀ọ́ sí inú rere tó fi hàn sí wa. Àmọ́, kò sí bá a ṣe mọ̀ ọ́n rìn tó tí orí wa kò ní mì. Ìyẹn bá ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Sólómọ́nì Ọba sọ mu, pé: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníw. 7:20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,” àti pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 3:23; 6:23a) Ó ṣe kedere pé ikú ló tọ́ sọ́mọ aráyé. Àmọ́ Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ aráyé ní ti pé ó ṣe inú rere sí wa lọ́nà tó ga lọ́lá bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Ẹ̀bùn tó ga jù lọ tó fún wa ni “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo” tó rán wá sáyé pé kó wá kú fún wa. (Jòh. 3:16) Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé Ọlọ́run ‘fi ògo àti ọlá dé e ládé nítorí tí ó kú, kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.’ (Héb. 2:9) Lóòótọ́, “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23b. w16.07 3:3, 4
Saturday, February 10
Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un.—Jẹ́n. 2:18.
Látijọ́ táláyé ti dáyé làwọn èèyàn ti máa ń ṣègbéyàwó. Tá a bá ronú lórí bí ìgbéyàwó ṣe bẹ̀rẹ̀ àtohun tó wà fún, àá lè fojú tó tọ́ wo ìgbéyàwó, àá sì lè jadùn àwọn ìbùkún tó ń tibẹ̀ wá. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó ní kó sọ àwọn ẹranko lórúkọ. Bíbélì wá sọ nípa Ádámù pé “kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” Torí náà, Ọlọ́run mú kí Ádámù sùn lọ fọnfọn, ó wá mú ọ̀kan lára àwọn eegun ìhà rẹ̀, ó fi dá obìnrin kan, ó sì mú un wá fún Ádámù. (Jẹ́n 2:20-24) Ó wá ṣe kedere pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Jésù kín ọ̀rọ̀ Jèhófà lẹ́yìn nígbà tó sọ pé: “Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” (Mát. 19:4, 5) Bí Ọlọ́run ṣe lo ọ̀kan lára àwọn eegun ìhà Ádámù láti dá obìnrin àkọ́kọ́ jẹ́ kí Ádámù àti ìyàwó rẹ̀ yìí mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́kan. Ọlọ́run ò fẹ́ káwọn tọkọtaya máa kọ ara wọn sílẹ̀ tàbí kí wọ́n ní ju ọkọ tàbí aya kan lọ. w16.08 1:1, 2
Sunday, February 11
[Jésù] mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti ibẹ̀ láti kọ́ni àti láti wàásù nínú àwọn ìlú ńlá wọn.—Mát. 11:1.
Jésù máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ létí kànga Jékọ́bù tó wà nítòsí ìlú Síkárì. Ìjíròrò yìí gbádùn mọ́ obìnrin yìí débi pé òun àtàwọn ẹlòmíì di ọmọlẹ́yìn. (Jòh. 4:5-30) Ó tún bá agbowó orí kan tó ń jẹ́ Mátíù tàbí Léfì sọ̀rọ̀. Bíbélì sì sọ pé Mátíù gbà láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Nígbà kan tí Mátíù ṣe àsè nílé rẹ̀, òun àtàwọn míì gbọ́ àwọn ohun tí Jésù sọ fáwọn èèyàn. (Mát. 9:9; Lúùkù 5:27-39) Ẹlòmíì tí Jésù bá sọ̀rọ̀ ni Nàtáníẹ́lì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú tí Nàtáníẹ́lì fi ń wo àwọn èèyàn Násárẹ́tì kù díẹ̀ káàtó, síbẹ̀ Jésù fìfẹ́ bá a sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó pinnu láti mọ ohun tí Jésù fi ń kọ́ni bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará Násárẹ́tì ni Jésù. (Jòh. 1:46-51) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa kọ́ àwọn akéde tuntun bí wọ́n á ṣe máa fìfẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì jẹ́ kára tù wọ́n. Ẹ wo bí inú àwọn akéde yìí á ṣe dùn tó pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ń fetí sọ́rọ̀ wọn! Ìdí táwọn èèyàn náà sì ṣe fetí sílẹ̀ ni pé àwọn akéde náà pọ́n wọn lé, wọ́n sì mọyì wọn. w16.08 4:7-9
Monday, February 12
Kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀. . . . Kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀. —1 Kọ́r. 7:10, 11.
Táwọn tọkọtaya kan bá níṣòro, tí ìṣòro ọ̀hún ò sì yanjú, wọ́n máa ń ronú pé á dáa káwọn pínyà tàbí káwọn kọ ara wọn sílẹ̀. Ìpínyà kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Tọkọtaya kan lè máa ronú pé ìpínyà ló máa yanjú ìṣòro wọn, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ló tún máa ń bí àwọn ìṣòro mí ì. Jésù mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé ọkùnrin máa fi bàbá àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:3-6; Jẹ́n. 2:24) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ọkọ tàbí aya kò gbọ́dọ̀ ya ohun tí Ọlọ́run ti sọ pọ̀. Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya máa bára wọn gbé títí lọ gbére, ikú nìkan ló sì lè yà wọ́n. (1 Kọ́r. 7:39) Tí tọkọtaya bá ń rántí pé gbogbo wa la máa jíhìn fún Jèhófà, àwọn méjèèjì á máa sapá láti yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín wọn kí ìṣòro náà tó di ńlá. w16.08 2:10, 11
Tuesday, February 13
Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ. —Róòmù 12:21.
Ìgbà tá ò fura tàbí tá ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí, làwọn ọ̀tá yìí máa ń fẹ́ kọlù wá, torí náà a ò gbọ́dọ̀ sàsùnpara. Ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé ká má ṣe jẹ́ “kí ibi ṣẹ́gun” wa fi hàn pé a lè ṣẹ́gun ibi. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá ò bá ṣíwọ́ àtimáa gbógun tì í. Àmọ́, tá a bá dẹra nù pẹ́nrẹ́n tàbí tá a ṣíwọ́ ìjà, wẹ́rẹ́ báyìí ni Sátánì, ayé èṣù yìí àti àìpé wa máa borí wa. Torí náà, má ṣe gbà láé kí Sátánì dẹ́rù bà ẹ́ débi tí wàá fi juwọ́ sílẹ̀! (1 Pét. 5:9)Tá a bá máa mókè nínú ìjà yìí, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìdí tá a fi ń ja ìjà náà. Tá a bá fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run ká sì rí ìbùkún rẹ̀, àfi ká máa rántí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó wà nínú Hébérù 11:6, tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà tá a tú sí “fi taratara wá” túmọ̀ sí kéèyàn fi gbogbo ara àti ọkàn ṣe nǹkan.—Ìṣe 15:17. w16.09 2:4, 5
Wednesday, February 14
Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 10:31.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó ṣeé múlò tó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa fògo fún Ọlọ́run. Síbẹ̀, a lómìnira láti yan ohun tó wù wá láti wọ̀. Ohun tí kálukú wa nífẹ̀ẹ́ sí yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ sì làpò wa ò dọ́gba. Síbẹ̀, ó yẹ kí aṣọ tá a bá wọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, kó jẹ́ ti ọmọlúàbí, kó bá ibi tá a wà mu, kó má sì kọ àwọn míì lóminú. Ó ṣe kedere pé tá a bá fi àwọn kókó tá a jíròrò tán yìí sílò, àá lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa ìmúra wa. Àmọ́, ká sòótọ́, kì í rọrùn láti rí aṣọ tó bójú mu rà lọ́jà. Ìdí ni pé àwọn aṣọ táyé ń gbé lárugẹ ló kúnnú ọjà lónìí. Torí náà, ó lè gbà wá lákòókò, ká sì fẹ́rẹ̀ẹ́ rin inú ọjà tán ká tó rí síkẹ́ẹ̀tì àti búláòsì àtàwọn aṣọ míì tí kò fún mọ́ra pinpin tó sì yẹ ọmọlúàbí. Síbẹ̀, inú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà máa dùn tí wọ́n bá rí i pé aṣọ wa rẹwà, ó sì buyì kúnni. Ó dájú pé tá a bá ń múra lọ́nà tó ń fògo fún Jèhófà Baba wa ọ̀run, ayọ̀ tá a máa ní á ju gbogbo wàhálà tá a ṣe láti rí aṣọ náà rà. w16.09 3:15, 16
Thursday, February 15
Ó na àríwá sórí ibi ṣíṣófo, ó so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.— Jóòbù 26:7.
Àpèjúwe tó gbéṣẹ́ tún lè mú kó túbọ̀ dá ọmọ rẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Kí lo lè ṣe láti mú kọ́mọ rẹ gbà pé Jèhófà ló mí sí Jóòbù láti sọ̀rọ̀ yẹn? O kàn lè sọ fún un pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣáà ni. Dípò bẹ́ẹ̀, o ò ṣe wọ́nà àtimú kọ́rọ̀ náà túbọ̀ yé ọmọ rẹ? Rán an létí pé ìgbà tí kò sí awò téèyàn fi ń wo sánmà tàbí ọkọ̀ òfuurufú ni Jóòbù gbáyé. Ní kí ọmọ rẹ ṣàlàyé bó ti rọrùn tó fáwọn èèyàn ìgbà yẹn láti gbà pé bí ayé yìí ṣe tóbi tó, ṣe ló rọ̀ dirodiro láìsí ohun tó gbé e dúró. Wá sọ fún un pé kó wò ó bóyá bọ́ọ̀lù tàbí òkúta kan lè dá dúró sójú òfuurufú láìsí ohun tó dì í mú. Síbẹ̀, òótọ́ lohun tí ẹsẹ yẹn sọ, ayé ò dúró sórí ohunkóhun. Àpèjúwe yìí máa jẹ́ kí ọmọ rẹ gbà pé Jèhófà ló jẹ́ kí Jóòbù mọ òótọ́ yẹn, torí pé ó pẹ́ káwọn èèyàn tó wá mọ̀ pé kò sí ohun tó gbé ayé dúró.—Neh. 9:6. w16.09 5:9, 12
Friday, February 16
Lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ.—Róòmù 10:9.
Ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ kọjá kéèyàn kàn lóye àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ téèyàn ní láá mú kó máa wù ú láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ tá a ní pé Ọlọ́run máa gba aráyé là máa ń mú ká wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Tá a bá máa ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó ṣe pàtàkì ká nígbàgbọ́, ìgbàgbọ́ ọ̀hún ò sì gbọ́dọ̀ kú. A lè fọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ wé òdòdó téèyàn máa ń bomi rin. Tá a bá ń bomi rin òdòdó, á máa jà yọ̀yọ̀ á sì máa rú sí i, àmọ́ tá ò bá bomi rin ín, á bẹ̀rẹ̀ sí í rọ, tó bá sì yá, á kú. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ rí. Tá ò bá ṣọ́ra, ìgbàgbọ́ wa lè kú. (Lúùkù 22:32; Héb. 3:12) Àmọ́, tá a bá ń kíyè sí bí ìgbàgbọ́ wa ṣe rí, àá máa ṣe ohun táá jẹ́ kó lágbára, ìgbàgbọ́ wa máa “gbèrú,” àá sì jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—2 Tẹs. 1:3; Títù 2:2. w16.10 4:4, 5
Saturday, February 17
Sàràkí náà tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin sì fún wọn ní orúkọ. Ó sì fún Dáníẹ́lì ní orúkọ náà Bẹliteṣásárì. —Dán. 1:7.
Nígbà tí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wà nígbèkùn ní Bábílónì, àwọn èèyàn ibẹ̀ kọ́ wọn lédè wọn kí wọ́n lè di ọmọ ìbílẹ̀. Bákan náà, aṣojú ọba tó ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ tún fún wọn lórúkọ Bábílónì. (Dán. 1:3-7) Ohun tó bẹ̀rẹ̀ orúkọ tí wọ́n fún Dáníẹ́lì ni Bẹli, ìyẹn sì ni orúkọ òrìṣà tó lágbára jù táwọn èèyàn Bábílónì ń bọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Ọba Nebukadinésárì fẹ́ kí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbà pé òrìṣà táwọn ń bọ ní Bábílónì lágbára ju Jèhófà Ọlọ́run wọn. (Dán. 4:8) Lóòótọ́ wọ́n rọ Dáníẹ́lì pé kó jẹ àwọn oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, àmọ́ Dáníẹ́lì pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé òun ò ní “sọ ara òun di eléèérí.” (Dán. 1:8) Torí pé Dáníẹ́lì máa ń ka Ìwé Mímọ́ tó wà lédè ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn mú kí àárín òun àti Jèhófà gún régé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ àjèjì ló wà. (Dán. 9:2) Abájọ tó fi jẹ́ pé, lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún tó ti wà ní Bábílónì, orúkọ Hébérù tó ń jẹ́ làwọn èèyàn ṣì mọ̀ ọ́n sí.—Dán. 5:13. w16.10 2:7, 8
Sunday, February 18
Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ, ni wọ́n ń lọ.—Ìsík. 1:20.
“Ẹrú olóòótọ́” nìkan ni Jésù yàn pé kó máa fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa. (Mát. 24:45-47) Láti ọdún 1919 ni Jésù ti ń lo ẹrú olóòótọ́ yìí láti mú káwọn èèyàn Ọlọ́run lóye Bíbélì, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Tá a bá a ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan máa wà nínú ìjọ, ìjọ sì máa jẹ́ mímọ́. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jésù ń fún wa nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́?’ Bíbélì jẹ́ ká mọ apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìran kan, wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run tó dúró fún apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. (Ìsík. 1:4-28) Bí Kristi àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ṣe ń gbára dì láti pa ayé búburú yìí run, kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jèhófà túbọ̀ ń báṣẹ́ lọ kó lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run! w16.11 3:9, 10
Monday, February 19
Kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé. —Héb. 10:25.
Bíi tàwọn Kristẹni àtijọ́, àwa náà máa ń pé jọ pọ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ ká sì tún rí ìṣírí gbà. (1 Kọ́r. 14:31) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó nírìírí náà nílò ìṣírí. Àpẹẹrẹ kan ni ti Jóṣúà. Jóṣúà ti ń sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ Jèhófà ní kí Mósè fún un níṣìírí. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Fàṣẹ yan Jóṣúà, kí o sì fún un ní ìṣírí, kí o sì fún un lókun, nítorí pé òun ni ẹni tí yóò lọ níwájú àwọn ènìyàn yìí, òun sì ni ẹni tí yóò mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí ìwọ yóò rí.” (Diu. 3:27, 28) Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà gbé lé Jóṣúà lọ́wọ́ yìí, òun ló máa kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sójú ogun kí wọ́n lè gba Ilẹ̀ Ìlérí. Ó máa ní ìjákulẹ̀, ìgbà kan sì máa wà táwọn ọ̀tá máa ṣẹ́gun rẹ̀. (Jóṣ. 7:1-9) Abájọ tí Jèhófà fi sọ fún Mósè pé kó fún un níṣìírí, kó sì fún un lókun. Lónìí, ó yẹ ká máa fún àwọn alàgbà níṣìírí, ká sì máa gbóríyìn fáwọn alábòójútó àyíká torí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó agbo Ọlọ́run.—1 Tẹs. 5:12, 13. w16.11 1:12, 13
Tuesday, February 20
Èmi yóò fi ìdájọ́ lórí aṣẹ́wó ńlá tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ hàn ọ́. —Ìṣí. 17:1.
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ó dáa báwọn ṣe sọ fún tẹbí tọ̀rẹ́ àtàwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì wọn tẹ́lẹ̀ pé àwọn kì í ṣe ọmọ ìjọ wọn mọ́, àmọ́ wọ́n gbà pé ìyẹn nìkan ò tó. Gbogbo ayé ló gbọ́dọ̀ mọ̀ pé aṣẹ́wó amúnisìn ni Bábílónì Ńlá! Torí náà, láàárín December 1917 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918 nìkan, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá ìwé àṣàrò kúkúrú táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pín fáwọn èèyàn. Bí ẹni sọ̀kò ìbànújẹ́ lu àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ̀rọ̀ inú ìwé náà torí pé àkòrí ìwé náà ni, “The Fall of Babylon,” ìyẹn, Bábílónì Ṣubú. Ẹ fojú inú wo bó ṣe máa rí lára àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, ṣe ni wọ́n fárígá. Àmọ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò tiẹ̀ wojú wọn, ṣe làwọn ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ ràì. Wọ́n pinnu pé àwọn “gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Kí wá la lè sọ níbi tọ́rọ̀ dé yìí? Kókó náà ni pé, dípò táwọn Kristẹni tòótọ́ yẹn ì bá fi dẹrú Bábílónì Ńlá lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, ṣe ni wọ́n ń jára wọn gbà lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti dòmìnira. w16.11 5:2, 4
Wednesday, February 21
Àwọn tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí gbé e ka àwọn ohun ti ẹ̀mí.—Róòmù 8:5.
Àwọn kan rò pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fi àwọn tó mọ òtítọ́ wé àwọn tí kò mọ òtítọ́ tàbí pé ó ń fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn Kristẹni àtàwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Àmọ́ àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ ìwé yìí sí ni “àwọn tí ó wà ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́.” (Róòmù 1:7) Torí náà, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tó ń rìn níbàámu pẹ̀lú ẹran ara àtàwọn Kristẹni tó ń rìn níbàámu pẹ̀lú ẹ̀mí. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara” ni àwọn tó ń jẹ́ kí “ìfẹ́ onígbòónára tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀” máa ‘ṣiṣẹ́ nínú àwọn ẹ̀yà ara wọn.’ (Róòmù 7:5) Èyí jẹ́ ká lóye ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tó ń gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara.” Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí àwọn tó gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn. Àwọn yìí máa ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ ẹran ara àìpé wọn lọ́rùn, ó lè jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tàbí àwọn nǹkan míì. w16.12 2:5, 7
Thursday, February 22
Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì.—Sm. 32:1.
Nígbà míì, ó lè jẹ́ àṣìṣe tẹ́nì kan ṣe sẹ́yìn ló ń kó àníyàn bá a. Àwọn ìgbà kan wà tí Ọba Dáfídì sọ pé ‘àwọn ìṣìnà òun ti gba orí òun kọjá.’ Ó wá fi kún un pé: “Mo ti ké ramúramù nítorí ìkérora ọkàn-àyà mi.” (Sm. 38:3, 4, 8, 18) Nínú ipò tí Dáfídì wà yìí, ó ṣe ohun kan tó mọ́gbọ́n dání. Ó yíjú sí Jèhófà pé kó fàánú hàn sí òun, kó sì dárí ji òun. (Sm. 32:2, 3, 5) Láwọn ìgbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ló ń mú kó o máa ṣàníyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì kọ Sáàmù 55, ẹ̀rù ń bà á pé òun lè kú. (Sm. 55:2-5) Síbẹ̀, kò jẹ́ kí àníyàn yẹn mú kóun sọ̀rètí nù nínú Jèhófà. Dáfídì sọ àwọn ìṣòro rẹ̀ fún Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́, ó rí i pé ó yẹ kóun náà gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan táá jẹ́ kóun borí ìṣòro náà. (2 Sám. 15:30-34) Ẹ̀kọ́ gidi nìyẹn kọ́ wa. Dípò tí wàá fi fọwọ́ lẹ́rán, kí àníyàn wá bò ẹ́ mọ́lẹ̀, o ò ṣe gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó bá ìlànà Bíbélì mu láti bójú tó ìṣòro náà, kó o sì fọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. w16.12 3:14, 15
Friday, February 23
Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.—2 Sám. 12:13.
Dáfídì gba ìbáwí tí Jèhófà fún un nípasẹ̀ wòlíì Nátánì. Dáfídì tún gbàdúrà sí Jèhófà, ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ Jèhófà pé kó fi ojú rere hàn sí òun. (Sm. 51:1-17) Kàkà kí Dáfídì kárísọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ńṣe ló kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó ṣe, kò sì dán irú ẹ̀ wò mọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Dáfídì kú, Jèhófà ò sì gbàgbé àwọn ohun rere tó ṣe. (Héb. 11:32-34) Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Dáfídì ṣe? Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, ó yẹ ká ronú pìwà dà, ká sì bẹ Jèhófà tọkàntọkàn pé kó dárí jì wá. (1 Jòh. 1:9) Bákan náà, ó yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́, ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Ják. 5:14-16) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dárí jì wá àti pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa dà ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Lẹ́yìn náà, ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe wa, ká máa bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ, ká sì nírètí pé ọ̀la máa dáa.—Héb. 12:12, 13. w17.01 1:13, 14
Saturday, February 24
Fa ìránṣẹ́ rẹ sẹ́yìn kúrò nínú àwọn ìṣe ìkùgbù.—Sm. 19:13.
Kí la lè pè ní “àwọn ìṣe ìkùgbù”? Ẹni tó máa ń kùgbù ṣe nǹkan kì í fara balẹ̀ ronú kó tó ṣe nǹkan, ó sì máa ń kọjá àyè rẹ̀. Torí àìpé wa, gbogbo wa pátá la máa ń kọjá àyè wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Ọba Sọ́ọ̀lù, tó bá ti mọ́ọ̀yàn lára láti máa kọjá àyè rẹ̀, kò ní pẹ́ tí onítọ̀hún á fi kọjá àyè rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Sáàmù 119:21 sọ pé Jèhófà máa ‘bá àwọn oníkùgbù wí lọ́nà mímúná.’ Kí nìdí tó fi máa ṣe bẹ́ẹ̀? Kéèyàn kọjá àyè rẹ̀ burú ju kéèyàn ṣèèṣì ṣe ohun tí kò yẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, tá a bá kọjá àyè wa, ó fi hàn pé a ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Èkejì ni pé, tá a bá ń kọjá àyè wa, àá máa ní ìforígbárí pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Òwe 13:10) Ẹ̀kẹta sì ni pé, táwọn èèyàn bá mọ̀ pé a ti kọjá àyè wa, ó lè kó ìtìjú bá wa, ká sì dẹni ẹ̀tẹ́. (Lúùkù 14:8, 9) Ó ṣe kedere pé ìkùgbù kì í bímọre. Bí Bíbélì ṣe sọ, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. w17.01 3:4, 5
Sunday, February 25
Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; Wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àbùkù náà jẹ́ tiwọn.—Diu. 32:5.
Torí pé wọ́n ti di aláìpé, Ádámù ò lè gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ lọ́nà pípé. Yàtọ̀ sí pé ó fi ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ tàfàlà, ó tún sọ àwa àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di aláìpé, ó mú ká máa dẹ́ṣẹ̀ ká sì máa kú. (Róòmù 5:12) Ó mú kó ṣòro fáwa ọmọ rẹ̀ láti wà láàyè títí láé. Bákan náà, kò ṣeé ṣe fún Ádámù àti Éfà láti bí ọmọ pípé, àwa àtọmọdọ́mọ wọn náà ò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí Sátánì Èṣù ti sọ tọkọtaya náà di ọ̀tá Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ sí í tan ọmọ aráyé jẹ títí dòní olónìí. (Jòh. 8:44) Àmọ́ o, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwa ọmọ èèyàn kò yẹ̀ rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà ṣì fẹ́ kí àárín òun àtàwa èèyàn gún régé. Kò wù ú pé ká máa kú. (2 Pét. 3:9) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn tí Sátánì àtàwọn tọkọtaya náà ṣọ̀tẹ̀ ni Ọlọ́run ṣètò bí aráyé ṣe lè pa dà bá òun rẹ́ láìsí pé ohunkóhun tẹ ìlànà òun lójú.—Jòh. 3:16. w17.02 1:12-14
Monday, February 26
Ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.—Òwe 13:10.
Tá a bá ń wo ibi táwọn míì dáa sí, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì iṣẹ́ táwa náà ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Kò yẹ kó jẹ́ pé àwa làwọn èèyàn á máa rí ṣáá tàbí pé àwa làá máa darí àwọn míì pé kí wọ́n ṣe tibí ṣe tọ̀hún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n mọ̀ wá sẹ́ni tó máa ń fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún un. Táwọn míì bá gba àwọn àfikún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, àá bá wọn yọ̀. Àá sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe ń bù kún “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé.” (1 Pét. 5:9) Tá a bá ń fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, àá máa ṣèpinnu tó múnú rẹ̀ dùn. Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá à ń gbàdúrà, tá a sì ń fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ sílò, ẹ̀rí ọkàn wa á túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa. (1 Tím. 1:5) A tún gbọ́dọ̀ máa fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa ‘parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa,’ á jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa ká sì tún ní àwọn ànímọ́ Kristẹni míì.—1 Pét. 5:10. w17.01 4:17, 18
Tuesday, February 27
Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì, ní pàtàkì, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.—1 Tím. 5:17.
Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ ká sì tún máa bọlá fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, pàápàá jù lọ àwọn alàgbà tó ń múpò iwájú. A máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin yìí láìka ibi tí wọ́n ti wá, bí wọ́n ṣe kàwé tó, bí wọ́n ṣe gbajúmọ̀ tó láwùjọ tàbí bí wọ́n ṣe lówó lọ́wọ́ sí. Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.” Wọ́n wà lára àwọn tí Jèhófà ṣètò pé kó máa bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. (Éfé. 4:8) Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fáwọn tó ń múpò iwájú, ohun táwa náà sì ń ṣe lónìí nìyẹn. A kì í sọ àwọn aṣojú tí ètò Ọlọ́run ń lò di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, tá a bá sì wà pẹ̀lú wọn, a ò ní máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ bíi pé áńgẹ́lì ni wọ́n. Síbẹ̀, a máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin yìí torí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní, a sì máa ń bọlá fún wọn.—2 Kọ́r. 1:24; Ìṣí. 19:10. w17.03 1:13
Wednesday, February 28
Èé ṣe tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.—Máàkù 10:18.
Ẹ ò rí i pé Jésù yàtọ̀ pátápátá sí Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní tó di ọba ilẹ̀ Jùdíà! Níbi ìpàdé ìlú kan, Hẹ́rọ́dù gúnwà pẹ̀lú aṣọ aláràbarà. Àwọn èrò tó pé jọ bẹ̀rẹ̀ sí í júbà rẹ̀ pé: “Ohùn ọlọ́run kan ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Ó dájú pé ńṣe ni inú Hẹ́rọ́dù ń dùn bí wọ́n ṣe ń yìn ín. Sùgbọ́n “ní ìṣẹ́jú akàn, áńgẹ́lì Jèhófà kọlù ú, nítorí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run; àwọn kòkòrò mùkúlú sì jẹ ẹ́, ó sì gbẹ́mìí mì.” (Ìṣe 12:21-23) Ó ṣe kedere pé kò sí aláròjinlẹ̀ èèyàn kan tó máa sọ pé Jèhófà ló yan Hẹ́rọ́dù ṣe aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé Jèhófà ló yan Jésù, ìgbà gbogbo ló sì máa ń gbógo fún Jèhófà torí ó mọ̀ pé Jèhófà ni Aṣáájú Tó Ga Jù Lọ fún àwa èèyàn rẹ̀. Kì í ṣe ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ni Jésù fi máa ṣe aṣáájú àwa èèyàn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó wá fi kún un pé: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:18-20. w17.02 3:20, 21