ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 57-67
  • June

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • June
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, June 1
  • Saturday, June 2
  • Sunday, June 3
  • Monday, June 4
  • Tuesday, June 5
  • Wednesday, June 6
  • Thursday, June 7
  • Friday, June 8
  • Saturday, June 9
  • Sunday, June 10
  • Monday, June 11
  • Tuesday, June 12
  • Wednesday, June 13
  • Thursday, June 14
  • Friday, June 15
  • Saturday, June 16
  • Sunday, June 17
  • Monday, June 18
  • Tuesday, June 19
  • Wednesday, June 20
  • Thursday, June 21
  • Friday, June 22
  • Saturday, June 23
  • Sunday, June 24
  • Monday, June 25
  • Tuesday, June 26
  • Wednesday, June 27
  • Thursday, June 28
  • Friday, June 29
  • Saturday, June 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 57-67

June

Friday, June 1

Èmi yóò . . . fi ẹni náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.​—Oníd. 11:31.

Jẹ́fútà ò lọ́mọ míì, torí náà, kò ní sẹ́ni táá jogún àwọn ilẹ̀ tí Jẹ́fútà ní, orúkọ rẹ̀ á sì pa rẹ́. (Oníd. 11:34) Síbẹ̀, Jẹ́fútà sọ pé: “Èmi sì ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí padà.” Jèhófà gba ẹbọ tí Jẹ́fútà fínnúfíndọ̀ rú yìí, ó sì bù kún un. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Jẹ́fútà, ṣé wàá mú ìlérí rẹ ṣẹ? Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ìfẹ́ rẹ̀ la ó máa ṣe ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. A mọ̀ pé ìyẹn ò lè fìgbà gbogbo rọrùn. Àmọ́, kí la máa ṣe bí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ohun kan, tí nǹkan ọ̀hún ò sì rọrùn? Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì fínnúfíndọ̀ ṣe ohun tó ní ká ṣe, ṣe là ń mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Ó lè nira fún wa gan-an láti yááfì àwọn ohun tá a yááfì, àmọ́ ìbùkún Jèhófà ju gbogbo ohun tá a lè yááfì lọ.​—Mál. 3:10. w16.04 1:​11, 14, 15

Saturday, June 2

Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. ​—Ìṣí. 2:7.

Ẹ̀mí mímọ́ ni Jésù fi ń darí ìjọ. Ẹ̀mí mímọ́ lè jẹ́ ká borí ìdẹwò ká sì máa fi ìgboyà wàásù. Ó tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa sa gbogbo ipá wa ká lè wà nípàdé kí Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. Ní ìpàdé, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń jíròrò bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe ń ṣẹ. Èyí sì lè mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú máa ṣẹ. Kì í ṣe ìgbà táwọn ará bá ń ṣiṣẹ́ nípàdé nìkan ni wọ́n máa fún wa níṣìírí, ìdáhùn wọn àti orin ìyìn tí wọ́n ń kọ sí Jèhófà látọkàn wá tún máa ń gbé wa ró. (1 Kọ́r. 14:26) Ọ̀rọ̀ tá a máa ń bára wa sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé sì máa ń mú kára tù wá torí a mọ̀ pé àwọn tó fẹ́ràn wa là ń bá sọ̀rọ̀.​—1 Kọ́r. 16:​17, 18. w16.04 3:​6, 7

Sunday, June 3

Sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

Jésù sọ ibi tó yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò dé nígbà tó sọ pé a máa wàásù ìhìn rere yìí “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Látinú “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè” la ti máa rí àwọn tó máa di ọmọ ẹ̀yìn. Èyí fi hàn pé iṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ kárí gbogbo ayé. Ká lè mọ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ pé ká wàásù kárí ayé, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó kan. Àwọn àlùfáà tó wà nínú onírúurú ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000], bẹ́ẹ̀ sì rèé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ tó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba [1,200,000]. Díẹ̀ làwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì tó wà kárí ayé fi lé ní ogún ọ̀kẹ́ [400,000]. Ẹ jẹ́ ká wá wo iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń wàásù ìhìn rere kárí ayé. Kárí ayé, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ làwọn òjíṣẹ́ tó ń yọ̀ǹda ara wọn láti wàásù ní igba ó lé lógójì [240] ilẹ̀. Ẹ ò rí bí iṣẹ́ bàǹtà-banta tá à ń ṣe yìí ṣe ń fi ìyìn àti ògo fún Jèhófà!​—Sm. 34:1; 51:15. w16.05 2:​13,14

Monday, June 4

Ènìyàn tí ó fi ara fún ìbínú ń ru asọ̀ sókè, ẹnikẹ́ni tí ó sì fi ara fún ìhónú ní ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.​—Òwe 29:22.

Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló máa ń gbéra ga, onímọtara-ẹni-nìkan ni wọ́n, wọ́n sì máa ń figa gbága. Ohun tí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa darí òun ń sọ ni pé ohun tí Sátánì sọ mọ́gbọ́n dání, àti pé kò burú téèyàn bá rọ́ gbogbo èèyàn sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kọ́wọ́ ẹ̀ ṣáá lè tẹ ohun tó ń lé. (Jẹ́n. 3:​1-5) Irú ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ kì í bímọọre, gbọ́nmi-si omi-ò-to ló máa ń yọrí sí. Ohun tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn yàtọ̀ pátápátá síyẹn, ó ní kí wọ́n máa wá àlàáfíà kódà bí ìyẹn ò bá tiẹ̀ rọrùn pàápàá. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ ohun tó yẹ ká ṣe kí aáwọ̀ má bàa máa wáyé tàbí tá a bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ onínú tútù, kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kí wọ́n má máa gba ìbínú láyè, kí wọ́n máa tètè yanjú aáwọ̀, kí wọ́n sì máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.​—Mát. 5:​5, 9, 22, 25, 44. w16.05 1:​4, 5

Tuesday, June 5

Agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí.​—Róòmù 7:18.

Ọ̀pọ̀ lára wa ló ti ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kan ká tó ṣèrìbọmi ká lè máa gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu. Lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi, a rí i pé ó ṣì yẹ ká máa ṣe àwọn ìyípadà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan ká lè túbọ̀ máa fìwà jọ Ọlọ́run àti Jésù. (Éfé. 5:​1, 2; 1 Pét. 2:21) Bí àpẹẹrẹ, a lè ti kíyè sí pé a máa ń ṣàríwísí àwọn èèyàn ṣáá, a máa ń ṣòfófó tàbí ká máa sọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa. Ó lè ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́ torí ìbẹ̀rù èèyàn, a sì lè ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ míì. Ṣé àtiṣe àwọn ìyípadà lórí àwọn kókó yìí ṣòro fún wa ju bá a ṣe rò lọ? Ó yẹ ká máa rántí pé aláìpé ṣì ni wá. (Kól. 3:​9, 10) Torí náà, kódà lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi tàbí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tá a ti wà nínú òtítọ́, kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe, a ò rọ́gbọ́n ẹ̀ dá. Nǹkan tí ò dáa lè máa wù wá, a lè ní èrò tí kò tọ́, ó lè sì lè ṣòro fún wa láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. A tiẹ̀ lè máa bá àwọn ìwà búburú kan fà á fún ọ̀pọ̀ ọdún.​—Ják. 3:2. w16.05 4:​3-5

Wednesday, June 6

Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.​—Héb. 12:6.

Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ tẹ́nì kan sọ pé: ‘Mi ò mọyì gbogbo ìbáwí táwọn òbí mi ń fún mi bí mo ṣe ń dàgbà, àfìgbà témi náà wá ní àwọn ọmọ tèmi.’ Bá a ṣe ń dàgbà tá a sì ń gbọ́n sí i, á túbọ̀ máa yé wa pé ìbáwí máa ń mú kéèyàn gbọ́n, àá wá rí i pé ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà bá wa wí. (Héb. 12:​5, 11) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀, sùúrù ló fi máa ń mọ wá bí àwọn amọ̀kòkò ṣe rọra ń mọ amọ̀. Ó fẹ́ ká gbọ́n, ká láyọ̀, ká sì nífẹ̀ẹ́ òun bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. (Òwe 23:15) Inú Jèhófà kì í dùn tá a bá ń jìyà; bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ ká kú ikú “ọmọ ìrunú,” torí ohun tí Ádámù sọ wá dà nìyẹn nígbà tó ṣẹ̀. (Éfé. 2:​2, 3) Gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ìrunú,” a máa ń hu àwọn ìwà kan tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, kódà ìwà tó jọ ti ẹranko làwọn kan ń hù tẹ́lẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára wa, a ti yíwà pa dà, a sì ti wá dà bí àgùntàn báyìí.​—Aísá. 11:​6-8; Kól. 3:​9, 10. w16.06 1:​7, 8

Thursday, June 7

Ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run.​—Mát. 18:4.

Ó máa ń yá ọ̀pọ̀ ọmọdé lára láti kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì sábà máa ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Mát. 18:​1-3) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì máa ń ṣe ohun táá mú káwọn ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tọkàntara. (2 Tím. 3:​14, 15) Àmọ́ o, káwọn òbí tó lè ṣèyẹn láṣeyọrí, àwọn alára gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn tiwọn, kó hàn pé òtítọ́ ló ń darí ìgbésí ayé wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀ nìkan làwọn ọmọ á ti máa kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á tún máa kọ́ ọ nínú ìwà àwọn òbí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwọn ló mú káwọn òbí àwọn máa bá àwọn wí. Táwa náà bá fi ara wa sábẹ́ Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, tá a sì jẹ́ kó hàn nínú bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa, Jèhófà máa kà wá sẹ́ni ọ̀wọ́n bó ṣe ka wòlíì Dáníẹ́lì sẹ́ni ọ̀wọ́n. (Dán. 10:​11, 19) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà á máa mọ wá nìṣó nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. w16.06 2:​14, 17

Friday, June 8

Èmi ti rí Dáfídì ọmọkùnrin Jésè, ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn.​—Ìṣe 13:22.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an, kódà ó sọ pé ó jẹ́ ọkùnrin “tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn.” (1 Sám. 13:​13, 14) Àmọ́, Dáfídì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, obìnrin náà sì lóyún. Ojú ogun ni Ùráyà ọkọ obìnrin náà wà nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Ùráyà wálé fírí, Dáfídì gbìyànjú láti mú kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà kó lè dà bíi pé Ùráyà ló fún un lóyún. Àmọ́ Ùráyà kọ̀ láti ṣe ohun tí Dáfídì fẹ́, ni Dáfídì bá ṣètò bó ṣe máa kú sójú ogun. Dáfídì jìyà ohun tó ṣe torí pé àjálù dé bá òun àti gbogbo ìdílé rẹ̀. (2 Sám. 12:​9-12) Síbẹ̀, Ọlọ́run fi àánú hàn sí i torí pé Dáfídì bá Jèhófà rìn “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà.” (1 Ọba 9:4) Ká sọ pé ìwọ náà gbáyé nígbà yẹn, kí lo ò bá ṣe? Ṣé ìwà burúkú tí Dáfídì hù máa mú ẹ kọsẹ̀? w16.06 4:7

Saturday, June 9

Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.​—Máàkù 13:33.

Ọwọ́ pàtàkì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ìkìlọ̀ Jésù. Ìdí sì ni pé a mọ̀ pé òpin ti dé tán àti pé àkókò tó kù kí “ìpọ́njú ńlá” bẹ̀rẹ̀ kò tó nǹkan mọ́. (Dán. 12:4; Mát. 24:21) Kárí ayé ni ogun ti ń jà, ìṣekúṣe ń peléke sí i, ìwàkiwà túbọ̀ ń gbilẹ̀, ọ̀rọ̀ ìsìn ò lójú, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìmìtìtì ilẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ káàkiri. A tún rí i pé àwa èèyàn Jèhófà ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà kárí ayé. (Mát. 24:​7, 11, 12, 14; Lúùkù 21:11) Ìdí nìyẹn tá a fi ń fojú sọ́nà fún ohun tí Jésù máa ṣe fún wa tó bá dé, àti bó ṣe máa mú kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣẹ. (Máàkù 13:​26, 27) Síbẹ̀, kò sí bá a ṣe mọ̀ ọ́n ṣe tó, a ò lè mọ ọdún pàtó tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀, ká má tíì wá sọ ọjọ́ tàbí wákátì tó máa bẹ̀rẹ̀. w16.07 2:​2-4

Sunday, June 10

Sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. ​—Héb. 4:16.

Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà ní sí wa mú kó fún wa láǹfààní pé ká wá síwájú ìtẹ́ rẹ̀, ká sì gbàdúrà sí i. Ọlá Jésù ni Jèhófà fi fún wa láǹfààní yìí. Bíbélì sọ nípa Jésù pé, “nípasẹ̀ ẹni tí àwa ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yìí àti ọ̀nà ìwọlé pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.” (Éfé. 3:12) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó ga lọ́lá gbáà ni pé a lè gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà! Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká tọ Jèhófà lọ, ká sì bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà, “kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16b) Nígbàkigbà tá a bá níṣòro tàbí tá a ní ìdààmú ọkàn, a lè ké pe Jèhófà pé kó ṣàánú wa, kó sì ràn wá lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ojú rere Ọlọ́run, síbẹ̀ ó ń gbọ́ àdúrà wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ará wa, “kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’ ”​—Héb. 13:6. w16.07 3:​12, 13

Monday, June 11

Sárà máa ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, ní pípè é ní “olúwa.” Ẹ sì ti di ọmọ rẹ̀.​—1  Pét. 3:6.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aya kọ̀ọ̀kan làwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fẹ́, àwọn kan wà láyé ìgbà yẹn tí wọ́n ní ju ìyàwó kan lọ. Láwọn ilẹ̀ kan, wọn ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, kódà ìṣekúṣe wà lára ààtò ìsìn wọn. Nígbà tí Ábúráhámù àtìyàwó rẹ̀ Sárà lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n kíyè sí i pé ìwà àwọn èèyàn ibẹ̀ kò sunwọ̀n. Ìdí sì ni pé ìṣekúṣe ló kúnnú ìlú náà débi pé wọn ò ka ìgbéyàwó sí nǹkan iyì. Ìlú míì tí ìṣekúṣe àwọn èèyàn ibẹ̀ tún burú jáì ni Sódómù àti Gòmórà, abájọ tí Jèhófà fi pinnu pé òun máa pa wọ́n run. Ábúráhámù ò fọ̀rọ̀ ìdílé rẹ̀ ṣeré, Sárà náà sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá di pé kí obìnrin tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀. (1 Pét. 3:​3-5) Ábúráhámù rí i dájú pé olùjọsìn Jèhófà ni Ísákì ọmọ rẹ̀ fẹ́. Ọ̀rọ̀ ìjọsìn tòótọ́ yìí náà ló wà lọ́kàn Jékọ́bù, ọmọ Ísákì. Àwọn ọmọ Jékọ́bù yìí ló wá di ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì. w16.08 1:10

Tuesday, June 12

Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.​—Aísá. 60:22.

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2015, àwọn akéde tí ó tó 8,220,105 ló kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Síbẹ̀, ó yẹ kí gbogbo wa ronú lórí ohun tí Jèhófà sọ lápá ìgbẹ̀yìn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pé: “Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” Gbogbo wa là ń fojú ara wa rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lónìí. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti rí i pé òun ń bá ètò Ọlọ́run rìn bó ṣe ń tẹ̀ síwájú? Ṣé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù? Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ń ṣí lọ síbi tí àìní gbé pọ̀ táwọn míì sì ń kópa nínú àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn míì. Ohun kan ni pé yálà a jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin, gbogbo wa pátá la ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’​—1 Kọ́r. 15:58. w16.08 3:​1, 2

Wednesday, June 13

Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù tí kò fi lè gbani là.​—Aísá. 59:1.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì làwọn ọmọ Ámálékì gbéjà kò wọ́n. Mósè sọ pé kí Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sójú ogun. Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè mú Áárónì àti Húrì lọ sórí òkè kan tí wọ́n á ti lè rí ìjà náà dáadáa. Mósè ṣe ohun kan tó jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun. Ó fọwọ́ méjèèjì gbé ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ sókè. Gbogbo ìgbà tí ọwọ́ Mósè wà lókè ni Jèhófà ń fún ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lókun láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì. Àmọ́, nígbà tí ọwọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ro Mósè, àwọn ọmọ Ámálékì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun. Nígbà tí Áárónì àti Húrì rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ kíákíá láti ran Mósè lọ́wọ́. Wọ́n gbé òkúta kan fún Mósè láti fi jókòó, “Áárónì àti Húrì sì gbé àwọn ọwọ́ rẹ̀ ró, ọ̀kan ní ìhà ìhín àti èkejì ní ìhà ọ̀hún, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọwọ́ rẹ̀ dúró pa sójú kan títí oòrùn fi wọ̀.” Lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà lo ọwọ́ agbára rẹ̀, ó sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ogun náà.​—Ẹ̀kís. 17:​8-13. w16.09 1:​5-7

Thursday, June 14

Tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.​—Róòmù 7:21.

Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òun á borí ìjà yìí torí pé lemọ́lemọ́ ló ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Àwa náà ńkọ́? A lè borí tá a bá ń bá àìpé wa jà. Àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ ṣe? Ẹ jẹ́ ká fara wé Pọ́ọ̀lù, ká má ṣe gbára lé ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ká máa gbára lé Jèhófà nígbà gbogbo, ká sì máa lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà. Nígbà míì, Ọlọ́run lè fàyè gba àwọn nǹkan kan, ká bàa lè fi hàn pé lóòótọ́ lohun kan ń jẹ wá lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ pé àwa tàbí ẹnì kan nínú ìdílé wa ń ṣàìsàn tàbí bóyá ṣe ni wọ́n rẹ́ wa jẹ. Ó dájú pé a ò ní fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré ká lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Tá a bá ń gbàdúrà, ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lókun ká lè jẹ́ olóòótọ́, kí ayọ̀ wa má pẹ̀dín, ká sì lè máa fìtara jọ́sìn rẹ̀. (Fílí. 4:13) Ìrírí àwọn tó gbára lé Jèhófà láyé Pọ́ọ̀lù àti lóde òní fi hàn pé àdúrà máa ń jẹ́ kéèyàn rókun gbà, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn lè fàyà rán ìṣòro láì bọ́hùn. w16.09 2:​14, 15

Friday, June 15

Ìkùnsínú dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì lòdì sí àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù.​—Ìṣe 6:1.

Báwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ìgbà yẹn ṣe ń pọ̀ sí i, ó jọ pé àwọn kan láàárín wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì ń ṣàròyé pé wọn ò bójú tó àwọn opó wọn. Nígbà tọ́rọ̀ náà dé etí àwọn àpọ́sítélì, wọ́n yan àwọn ọkùnrin méje kí wọ́n lè rí i dájú pé gbogbo opó tó wà nínú ìjọ la bójú tó. Orúkọ Gíríìkì làwọn ọkùnrin méje náà ń jẹ́, tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì fẹ́ kára tu gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, kó má sì tún sọ́rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà mọ́ láàárín wọn. (Ìṣe 6:​2-6) Yálà a mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí a ò mọ̀, gbogbo wa pátá ni àṣà ìbílẹ̀ wa máa ń mú ká ronú tàbí hùwà lọ́nà kan. (Róòmù 12:2) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe káwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tá a jọ wà níléèwé máa pẹ̀gàn àwọn tí àwọ̀ wọn, àṣà wọn tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Ṣé irú ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bẹ́ẹ̀ kò tíì ràn wá? Báwo ló sì ṣe máa ń rí lára wa táwọn èèyàn bá fi èdè wa, àṣà wa tàbí ìlú wa ṣe yẹ̀yẹ́, bóyá tí wọ́n tiẹ̀ bẹnu àtẹ́ lù wá? w16.10 1:​7, 8

Saturday, June 16

Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere . . . A ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.​—Róòmù 1:20.

Ohun téèyàn ò rí dáadáa tàbí téèyàn ń wò lọ́ọ̀ọ́kán la sábà máa ń fi “òye mọ̀.” (Héb. 11:3) Torí náà, olóye èèyàn máa ń ronú jinlẹ̀, láfikún sí ohun tó fojú rí àtohun tó fetí gbọ́. Ètò Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwádìí, wọ́n sì ti ṣàkójọ àwọn ìwádìí náà kó lè ràn wá lọ́wọ́. Àwọn nǹkan yìí ń jẹ́ ká lè máa fojú ìgbàgbọ́ rí Ẹlẹ́dàá wa. (Héb. 11:27) Lára ohun tí ètò Ọlọ́run fún wa làwọn ìtẹ̀jáde bíi fídíò The Wonders of Creation Reveal God’s Glory, àwọn ìwé pẹlẹbẹ tá a pè ní Was Life Created? àti The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking, òmíràn ni ìwé Is There a Creator Who Cares About You? A tún máa ń kà nípa àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì nínú ìwé ìròyìn Jí! tí wọ́n ṣàlàyé ohun tó mú kí wọ́n wá gbà pé Ọlọ́run wà. Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan àràmàǹdà tó yí wa ká. Ó ṣe tán, àwọn nǹkan àràmàǹdà tó yí wa ká yìí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń wò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe jáde. w16.09 4:​4, 5

Sunday, June 17

Wọ́n . . . ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí wọn nípa ìgbàgbọ́ wọn.​—Héb. 11:39.

Àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ tí ìwé Hébérù orí 11 mẹ́nu kan ti kú kí Jésù tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti lọ sọ́run. (Gál. 3:16) Torí pé àwọn ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa jí àwọn olóòótọ́ yìí dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Sm. 37:11; Aísá. 26:19; Hós. 13:14) Hébérù 11:13 sọ nípa àwọn olóòótọ́ tó gbé láyé àtijọ́ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n.” Ábúráhámù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ yìí. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù máa ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí lábẹ́ àkóso “irú-ọmọ” tí a ṣèlérí náà? Jésù dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tó sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé: “Ábúráhámù baba yín yọ̀ gidigidi nínú ìfojúsọ́nà fún rírí ọjọ́ mi, ó sì rí i, ó sì yọ̀.” (Jòh. 8:56) Ohun kan náà ni Sárà, Ísákì, Jékọ́bù àtàwọn míì ń fojú sọ́nà fún, ìyẹn Ìjọba tí “olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.”​—Héb. 11:​8-11. w16.10 3:​4, 5

Monday, June 18

Máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà.​—Éfé. 6:18.

A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú ká lóye òtítọ́, ẹ̀mí mímọ́ yìí ló sì jẹ́ ká gba ìhìn rere náà gbọ́. (Lúùkù 10:21) Ṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó mú wa wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù, ẹni tí Bíbélì pè ní “Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.” (Héb. 12:2) Ká lè fi hàn pé a mọyì ohun bàǹtà-banta tí Jèhófà ṣe yìí, ó yẹ ká máa gbàdúrà, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ lágbára. (1 Pét. 2:2) Ó yẹ ká túbọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà. A sì gbọ́dọ̀ ṣe èyí lọ́nà tó máa hàn kedere sáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ máa wàásù nìṣó, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. A tún gbọ́dọ̀ máa ṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Bákan náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.”​—Kól 3:5, 8-10. w16.10 4:​11, 12

Tuesday, June 19

[Jèhófà] . . . fi òye ṣẹ̀dá ọ̀run. ​—Sm. 136:5.

Gbogbo ohun tí Jèhófà dá ló wà létòletò. Torí náà, ó dájú pé Jèhófà máa fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ náà wà létòletò. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní Bíbélì kó lè máa tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, tá a sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa, a máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì nítumọ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà wà létòletò. Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ìránṣẹ́bìnrin kan wà “tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn àfètòṣe ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” (Ẹ̀kís. 38:8) Nígbà tó yá, Dáfídì Ọba ṣètò àwọn ọmọ Léfì àtàwọn àlùfáà sí àwùjọ àwùjọ kí iṣẹ́ wọn lè máa wà létòletò. (1 Kíró. 23:​1-6; 24:​1-3) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà wà létòletò, wọ́n sì jàǹfààní látinú àwọn ìtọ́ni tí ìgbìmọ̀ olùdarí ń fún wọn. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn àpọ́sítélì nìkan ló para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí. (Ìṣe 6:​1-6) Nígbà yẹn, ìgbìmọ̀ olùdarí tàbí àwọn míì tó bá wọn ṣiṣẹ́ máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kí wọ́n lè fún àwọn ará láwọn ìtọ́ni tí wọ́n nílò.​—1 Tím. 3: 1-13; Títù 1:​5-9. w16.11 2:​3, 6, 8, 9

Wednesday, June 20

Ẹnì yòówù tí ó bá sì wà fún oko òǹdè, sí oko òǹdè!​—Jer. 15:2.

Ní ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọba Nebukadinésárì Kejì kó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ọmọ ogun Bábílónì, wọ́n sì lọ gbógun ja ìlú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Bíbélì ń ròyìn bí ogun yẹn ṣe rí, ó sọ pé: “[Nebukadinésárì] fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn nínú ilé ibùjọsìn wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyọ́nú sí ọ̀dọ́kùnrin tàbí wúńdíá, arúgbó tàbí ọ̀jọ̀kútọtọ. . . . Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi iná sun ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì bi ògiri Jerúsálẹ́mù wó; gbogbo àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ sì ni wọ́n fi iná sun àti gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra pẹ̀lú, láti lè mú ìparun wá.” (2 Kíró. 36:​17, 19) Kò yẹ kí ìparun Jerúsálẹ́mù ya àwọn Júù lẹ́nu. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún làwọn wòlíì Ọlọ́run ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé tí wọn ò bá yéé tàpá sí òfin Ọlọ́run, àwọn ará Bábílónì máa kó wọn lẹ́rú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa fi idà pa ọ̀pọ̀ lára wọn, èyí tí kò bá sì tojú idà kú á di ẹrú àwọn ará Bábílónì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbèkùn yẹn ló máa kú sí. w16.11 4:​1, 2

Thursday, June 21

Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé.​—Róòmù 5:12.

Ádámù ni “ènìyàn kan” tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tipasẹ̀ rẹ̀ “wọ ayé.” Torí náà, ‘nípa àṣemáṣe ọkùnrin yẹn ni ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.’ Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé a rí ọ̀pọ̀ yanturu inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọ́run] gbà “nípasẹ̀ ènìyàn kan, Jésù Kristi.” (Róòmù 5:​12, 15, 17) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí sì ti mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún aráyé. Bí àpẹẹrẹ, “nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan [Jésù], ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” Ó ṣe kedere pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run máa fún wa ní ‘ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kristi.’ (Róòmù 5:​19, 21) Kì í ṣe ọ̀ranyàn pé kí Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti rà wá pa dà. Ó ṣe tán, aláìpé ni wá, a ò sì yẹ lẹ́ni tó yẹ kí Ọlọ́run àti Jésù rà pa dà. Síbẹ̀, ìràpadà yìí ló mú kí ìdáríjì ṣeé ṣe. Torí náà, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbáà ló jẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jì wá tó sì tún fún wa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ó yẹ ká mọyì ẹ̀bùn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ká sì jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé wa. w16.12 1:​1, 6, 7

Friday, June 22

Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí kò sí lábẹ́ òfin Ọlọ́run.​—Róòmù 8:7.

Ó ṣe pàtàkì ká yẹ ara wa wò dáadáa. Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú.” (Róòmù 8:6) Ọ̀rọ̀ ńlá nìyẹn o. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa kú nípa tẹ̀mí báyìí, tó bá sì tún dọjọ́ iwájú, á kú. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò sọ pé tẹ́nì kan bá ń ‘gbé èrò inú rẹ̀ ka àwọn ohun ti ẹran ara,’ ó di dandan kó kú. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣì lè yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ rántí arákùnrin tó fẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀ ní Kọ́ríńtì nígbà yẹn, ṣe ni wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Síbẹ̀, ó ronú pìwà dà, ó jáwọ́ nínú ìwà náà, wọ́n sì gbà á pa dà sínú ìjọ. (2 Kọ́r. 2:​6-8) Tí arákùnrin tó hùwà tó burú jáì ní Kọ́ríńtì bá lè yí pa dà, ó dájú pé Kristẹni tí kò hùwà tó burú tó yẹn lè yí pa dà. Torí náà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe ìyípadà tó yẹ tó bá ronú lórí ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù pé ikú ló máa gbẹ̀yìn ẹni tó bá ń ‘gbé èrò inú rẹ̀ ka ẹran ara.’ w16.12 2:​5, 12, 13

Saturday, June 23

Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.​—Sm. 55:22.

Ọkàn wa balẹ̀ pé tá a bá ‘ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà,’ ó máa ‘gbé wa ró’! Ó dá wa lójú hán-ún pé Ọlọ́run máa ṣe “ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò.” (Éfé. 3:20) Wò ó ná, kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run máa ṣe kọjá gbogbo ohun tí a béèrè, ó máa ṣe é lọ́pọ̀ yanturu, àní sẹ́, á tiẹ̀ ṣe é ju ọ̀pọ̀ yanturu lọ fún wa! Ká tó lè rí èrè náà gbà, a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà yóò bù kún ọ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún láti gbà, kìkì bí ìwọ kì yóò bá kùnà láti fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ kí o lè kíyè sára láti pa gbogbo àṣẹ yìí tí mo ń pa fún ọ lónìí mọ́. Nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún ọ, ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ gan-an.” (Diu. 15:​4-6) Ṣé ó dá ẹ lójú gan-an pé Jèhófà máa bù kún ẹ tó o bá ń fòótọ́ ọkàn sìn ín láìyẹsẹ̀? Àpẹẹrẹ púpọ̀ ló wà táá jẹ́ kó dá ẹ lójú. w16.12 4:​8, 9

Sunday, June 24

Ìwọ ni Jèhófà . . . ti yàn láti di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá.​—Diu. 7:6.

Jèhófà kò kàn ṣàdédé yàn wọ́n. Ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló mú ṣẹ. (Jẹ́n. 22:​15-18) Bákan náà, Jèhófà máa ń lo ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo nígbà tó bá ń pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí torí pé léraléra ni wọ́n pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Àmọ́ tí wọ́n bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa ń fínnú fíndọ̀ dárí jì wọ́n torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó sọ pé: “Èmi yóò wo àìṣòótọ́ wọn sàn. Èmi yóò nífẹ̀ẹ́ wọn láti inú ìfẹ́ àtinúwá tèmi.” (Hós. 14:4) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn tó bá di pé ká lo òmìnira tá a ní lọ́nà tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní! Nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan láyé àti lọ́run, ó dìídì fún àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn ní òmìnira torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ẹni tó kọ́kọ́ fún lẹ́bùn òmìnira yìí ni àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, tí Bíbélì pè ní “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (Kól. 1:15) Kí Jésù tó wá sáyé, ó yàn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà dípò táá fi lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Sátánì ọlọ̀tẹ̀. w17.01 2:​3, 4

Monday, June 25

Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.​—Héb. 6:10.

Iṣẹ́ táwa náà ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run lè yí pa dà látàrí àwọn ìpinnu tá a máa ń ṣe. Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́, àbí àgbàlagbà? Ṣé ara rẹ ṣì le dáadáa àbí ara ò fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́? Jèhófà máa ń kíyè sí ipò wa, ó sì máa ń wo ibi tó ti lè lò wá nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ohun tó ń retí ni pé ká ṣe ohun tágbára wa gbé, ó sì mọrírì ohunkóhun tá a bá ṣe. Inú Jésù máa ń dùn sí iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ọlọ́run bá gbé fún un, àwa náà sì lè láyọ̀ nínú iṣẹ́ tá à ń ṣe. (Òwe 8:​30, 31) Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn máa ń mọyì iṣẹ́ tó ní nínú ìjọ. Kì í banú jẹ́ báwọn míì bá ń gbé ohun ribiribi ṣe nínú ìjọ tàbí tí kò bá ní àfikún iṣẹ́ ìsìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń lo ara rẹ̀ tokunratokunra nínú iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe lọ́wọ́, ó sì ń láyọ̀ torí ó mọ̀ pé Jèhófà ló fún òun ní àǹfààní náà. Bákan náà, ó mọyì iṣẹ́ táwọn míì ń ṣe nínú ètò Jèhófà. Lóòótọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká bọlá fáwọn míì, ká sì máa fayọ̀ tì wọ́n lẹ́yìn.​—Róòmù 12:10. w17.01 3:​13, 14

Tuesday, June 26

Bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.​—Fílí. 2:22.

Àwọn ìgbà míì wà táwọn tí wọ́n faṣẹ́ lé lọ́wọ́ á máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ táwọn tó ti dàgbà ń ṣe. Ní báyìí táwọn tá a faṣẹ́ lé lọ́wọ́ ti ń ṣe iṣẹ́ tuntun, á bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó ti dàgbà kí wọ́n tó ṣèpinnu. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Tímótì àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi jọ ṣiṣẹ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì kò tó Pọ́ọ̀lù lọ́jọ́ orí. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: ‘Mò ń rán Tímótì sí yín, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa; yóò sì rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mo gbà ń ṣe nǹkan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù,’ (1 Kọ́r. 4:17) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn gan-an. Pọ́ọ̀lù fara balẹ̀ kọ́ Tímótì ní ‘àwọn ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.’ Ó ṣe kedere pé Tímótì fara balẹ̀ gbẹ̀kọ́ débi pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Tímótì á lè bójú tó ohun táwọn ará Kọ́ríńtì nílò nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fáwọn alàgbà lónìí, báwọn náà ṣe ń dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè múpò iwájú nínú ìjọ! w17.01 5:​13, 14

Wednesday, June 27

Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.​—Ìṣe 24:15.

Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn wà láàyè ni, kò fẹ́ ká kú. Torí pé òun ni Orísun ìyè, tó bá ti jí àwọn òkú dìde, á di Baba wọn. (Sm. 36:9) Òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àdúrà yẹn nígbà tó pe Jèhófà ní “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 6:9) Jèhófà máa lo Jésù láti jí àwọn òkú dìde. (Jòh. 6:​40, 44) Nígbà tí ayé bá di Párádísè, Jésù máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé òun ni “àjíǹde àti ìyè.” (Jòh. 11:25) Kì í ṣe àwọn èèyàn kéréje nìkan ló máa jàǹfààní àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe, torí Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá mi.” (Máàkù 3:35) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n máa jọ́sìn rẹ̀. Àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Kristi tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà lára àwọn tó máa sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”​—Ìṣí. 7:​9, 10. w17.02 2:​10, 11

Thursday, June 28

Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín.​—Héb. 13:17.

Kí wọ́n lè máa gbé ẹ̀kọ́ òtítọ́ jáde lónírúurú èdè, wọ́n dá àjọ kan sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1884, tí wọ́n pè ní Zion’s Watch Tower Tract Society, Arákùnrin Russell sì jẹ́ ààrẹ àjọ náà. Ọwọ́ gidi ló fi mú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbangba-gbàǹgbà ló sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn. Ó fòye mọ̀ pé nígbà tí Kristi bá pa dà wá, a ò ní fojú lásán rí i, àti pé “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” máa dópin lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:24) Arákùnrin Russell lo gbogbo àkókò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì náwó nára kó lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó ṣe kedere pé, Arákùnrin Russell ni Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ orí ìjọ lò lásìkò yẹn. Arákùnrin Russell kò wá báwọn èèyàn á ṣe máa gbógo fún un. Lọ́dún 1896, ó sọ pé: “A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa júbà wa tàbí àwọn ìwé wa, a ò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè wá ní Ẹni Ọ̀wọ̀ tàbí Rábì. Bẹ́ẹ̀ la ò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa fi orúkọ wa pe ara rẹ̀.” Ó wá sọ nígbà tó yá pé: “Iṣẹ́ yìí kì í ṣe tèèyàn.” w17.02 4:​8, 9

Friday, June 29

Ọgbọ́n afọgbọ́nhùwà ni láti lóye ọ̀nà ara rẹ̀.​—Òwe 14:8.

Gbogbo wa láwọn ìpinnu tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Kì í ṣe gbogbo ìpinnu tá a fẹ́ ṣe ló máa jẹ́ ọ̀rọ̀ ikú tàbí ìyè. Àmọ́, púpọ̀ lára àwọn ìpinnu tá à ń ṣe máa nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé wa. Torí náà, tá a bá mọ bá a ṣe lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Àmọ́ tá a bá ṣe ìpinnu tí kò dáa, ó lè yọrí sí ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́. Kí lá jẹ́ ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? Ó ṣe pàtàkì pé ká nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ká sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ àti pé á fún wa lọ́gbọ́n láti ṣèpinnu tó tọ́. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká gba Ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́, ká sì fọkàn tán àwọn ìtọ́ni rẹ̀. (Ják. 1:​5-8) Bá a ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àá túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé e. Nípa bẹ́ẹ̀, á mọ́ wa lára láti máa yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò ká tó ṣèpinnu. w17.03 2:​2, 3

Saturday, June 30

Ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.​—2 Kíró. 20:12.

Jèhóṣáfátì ṣe bíi ti bàbá rẹ̀ Ásà, ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà táwọn àkòtagìrì ọmọ ogun wá gbéjà kò ó. (2 Kíró. 20:​2-4) Ká sòótọ́, àyà Jèhóṣáfátì já, àmọ́ ó pinnu pé òun máa wá Jèhófà. Nínú àdúrà rẹ̀, ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé òun àtàwọn èèyàn òun kò ní ‘agbára kankan níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí,’ àti pé àwọn ò mọ ohun táwọn máa ṣe. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa tòní. Nígbà míì, àwa náà lè má mọ ohun tá a máa ṣe, ẹ̀rù sì lè máa bà wá bíi ti Jèhóṣáfátì. (2 Kọ́r. 4:​8, 9) Àmọ́, ká rántí pé Jèhóṣáfátì gbàdúrà níṣojú gbogbo èèyàn pé òun àtàwọn èèyàn òun ò lágbára táwọn lè fi jà. (2 Kíró. 20:5) Ẹ̀yin olórí ìdílé náà lè ṣe bíi ti Jèhóṣáfátì, ẹ bẹ Jèhófà pé kó tọ́ yín sọ́nà, kó sì fún yín lágbára láti kojú àwọn ìṣòro yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kójú tì yín láti gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lójú àwọn tó wà nínú ìdílé yín. Àdúrà bẹ́ẹ̀ máa mú kí wọ́n rí i pé ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọlọ́run ran Jèhóṣáfátì lọ́wọ́, ó sì máa ran ẹ̀yin náà lọ́wọ́. w17.03 3:​12, 13

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́