ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 67-77
  • July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Sunday, July 1
  • Monday, July 2
  • Tuesday, July 3
  • Wednesday, July 4
  • Thursday, July 5
  • Friday, July 6
  • Saturday, July 7
  • Sunday, July 8
  • Monday, July 9
  • Tuesday, July 10
  • Wednesday, July 11
  • Thursday, July 12
  • Friday, July 13
  • Saturday, July 14
  • Sunday, July 15
  • Monday, July 16
  • Tuesday, July 17
  • Wednesday, July 18
  • Thursday, July 19
  • Friday, July 20
  • Saturday, July 21
  • Sunday, July 22
  • Monday, July 23
  • Tuesday, July 24
  • Wednesday, July 25
  • Thursday, July 26
  • Friday, July 27
  • Saturday, July 28
  • Sunday, July 29
  • Monday, July 30
  • Tuesday, July 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 67-77

July

Sunday, July 1

Ṣe sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ti ẹnu rẹ jáde.​—Oníd. 11:36.

Ọmọbìnrin Jẹ́fútà yàn láti má ṣe lọ́kọ tàbí bímọ kó lè máa sin Jèhófà. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti pinnu pé àwọn ò ní tíì lọ́kọ tàbí láya, àwọn míì sì pinnu pé àwọn ò ní tíì bímọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àgbàlagbà kan ti pinnu pé àwọn á máa lò lára àkókò tó yẹ kí àwọn fi wà pẹ̀lú àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ àwọn fún Jèhófà. A rí lára wọn tó ń bá ètò Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ìkọ́lé, a sì rí àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sì ṣí lọ sí ìjọ tá a ti nílò àwọn akéde púpọ̀ sí i. Àwọn míì sì máa ń pinnu pé àwọn á ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Jèhófà mọyì báwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí ṣe ń yááfì àwọn nǹkan torí kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Héb. 6:​10-12) Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá lè yááfì àwọn nǹkan kan kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? w16.04 1:​16, 17

Monday, July 2

Wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.​—Jòh. 10:16.

Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun dà bí agbo àgùntàn kan, ó sì sọ pé òun ni olùṣọ́ àgùntàn agbo náà. Rò ó wò ná: Bí àgùntàn méjì bá wà lórí òkè, tí méjì míì wà níbi àfonífojì, tí ẹyọ kan wá wà ní ibòmíì, ṣé a lè sọ pé inú agbo kan làwọn àgùntàn márààrún yẹn wà? Rárá, torí pé ṣe làwọn àgùntàn tó wà nínú agbo kan máa ń wà pa pọ̀, wọn kì í fira wọn sílẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn wọn ni wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé. Torí náà, ká lè máa wà pẹ̀lú àwọn ará wa, ó yẹ ká máa lọ sípàdé déédéé. Tá a bá fẹ́ wà lára “agbo kan,” tá a sì fẹ́ máa tẹ̀ lé “olùṣọ́ àgùntàn kan,” àfi ká máa wá sípàdé déédéé. Ìpàdé wa máa ń mú ká wà pa pọ̀ bí ìdílé kan tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Sm. 133:1) Àwọn kan wà nínú ìjọ tí ìdílé wọn ti pa tì, ó lè jẹ́ àwọn òbí wọn tàbí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wọn. Àmọ́, Jésù ti ṣèlérí pé òun máa fún wọn ní ìdílé kan tó máa nífẹ̀ẹ́ wọn táá sì máa tọ́jú wọn. (Máàkù 10:​29, 30) Tó o bá ń wá sípàdé déédéé, o lè di bàbá, ìyá, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń ronú nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa wà ní gbogbo ìpàdé. w16.04 3:​9, 10

Tuesday, July 3

Nígbà tí ẹ bá sì dúró tí ẹ ń gbàdúrà, ẹ dárí ohun yòówù tí ẹ ní lòdì sí ẹnikẹ́ni jì í; kí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lè dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín pẹ̀lú.​—Máàkù 11:25.

Tá ò bá wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, asán ni ìjọsìn wa máa já sí. Àdúrà tá à ń gbà, ìpàdé tá à ń lọ, òde ẹ̀rí àtàwọn nǹkan míì tá à ń ṣe ò sì ní já mọ́ nǹkan kan. Tá ò bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, a ò lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 11:4; Éfé. 4:32) Ó pọn dandan kí àwa Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ronú jinlẹ̀ ká sì bi ara wa bóyá òótọ́ là ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn tá a sì lẹ́mìí ìdáríjì. Ṣé o máa ń dárí ji àwọn ará látọkàn wá? Ṣé inú rẹ máa ń dùn tí ẹ bá jọ wà nípàdé? Jèhófà retí pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́mìí ìdáríjì. Tí ẹ̀rí ọkàn rẹ bá sọ fún ẹ pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, ṣe ni kó o bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe irú àwọn àtúnṣe bẹ́ẹ̀. Baba wa ọ̀run máa gbọ́ irú àdúrà tá a fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ gbà.​—1 Jòh. 5:​14, 15. w16.05 1:​6, 7

Wednesday, July 4

A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí.​—Mát. 24:14.

Ìgbà wo la máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà dà? Jésù sọ pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé yìí á máa bá a lọ títí di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Àwọn ẹlẹ́sìn míì wo ló tún ń wàásù ìhìn rere náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó jẹ́ mánigbàgbé yìí? Àwọn kan tá à ń bá pà dé lóde ẹ̀rí lè sọ pé, “Àwa ní ẹ̀mí mímọ́, àmọ́ ẹ̀yin lẹ̀ ń wàásù.” Àmọ́, ṣé bá a ṣe ń bá iṣẹ́ náà nìṣó tá ò sì jẹ́ kó sú wa ò fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa? (Ìṣe 1:8; 1 Pét. 4:14) Látìgbàdégbà, àwùjọ àwọn onísìn kan máa ń gbìyànjú àtiṣe ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe nígbà gbogbo, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn máa ń já sí. Àwọn kan ti lọ́wọ́ nínú ohun tí wọ́n pè ní iṣẹ́ ajíhìnrere, àmọ́ kì í pẹ́ tí wọ́n á fi gbé e jù sílẹ̀ tí wọ́n á sì pa dà sídìí ohun tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àwọn míì tiẹ̀ lè lọ wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ kí ni wọ́n ń báwọn èèyàn sọ? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn fi hàn pé kì í ṣe iṣẹ́ tí Jésù dá sílẹ̀ ni wọ́n ń ṣe. w16.05 2:​13, 16

Thursday, July 5

Ẹ̀yin ará, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀, ní gbígba ìtọ́sọ́nàpadà, ní gbígba ìtùnú, ní ríronú ní ìfohùnṣọ̀kan, ní gbígbé pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà. ​—2 Kọ́r. 13:11.

A gbọ́dọ̀ máa sapá lójoojúmọ́ tá a bá fẹ́ máa sọ irú ẹni tá a jẹ́ dọ̀tun ká sì gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ; ṣùgbọ́n kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:​22-24) Ohun tí Bíbélì sọ yìí pé ká “di tuntun” kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣe lẹ́ẹ̀kan táá dáwọ́ dúró, ó gba pé kéèyàn máa sapá lójoojúmọ́. Èyí wúni lórí gan-an. Ìdí sì ni pé ó jẹ́ kó dá wa lójú pé bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti ṣèrìbọmi, a ṣì lè máa sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. Ó dájú pé Bíbélì lè máa tún ìgbésí ayé wa ṣe lójoojúmọ́. w16.05 4:​8, 9

Friday, July 6

Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà.​—Òwe 3:12.

Ní báyìí tí Jèhófà ń mọ wá ká lè fìwà jọ ọ́, ṣe ló dà bíi pé a wà nínú Párádísè tẹ̀mí tó ń gbèrú sí i lójoojúmọ́. (Aísá. 64:8) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé èṣù là ń gbé, ọkàn wa balẹ̀, a sì ń láyọ̀ nínú Párádísè yìí. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a ti wá mọ Jèhófà, a sì ń gbádùn ìfẹ́ tó ń fi hàn sí wa. (Ják. 4:8) Nínú ayé tuntun, ṣe ni òjò ìbùkún Párádísè tẹ̀mí yìí á máa rọ̀ sórí wa. Láfikún sí Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí, nígbà yẹn a tún máa gbádùn Párádísè tó ṣeé fojú rí lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìgbà ọ̀tun ni ìgbà yẹn máa jẹ́ níbi gbogbo. Lásìkò yẹn, Jèhófà Amọ̀kòkò wa á ṣì máa mọ aráyé nìṣó, á máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀kọ́ náà á gadabú débi pé kò ní láfiwé. (Aísá. 11:9) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run máa sọ wá di pípé lérò àti lára, tó fi jẹ́ pé bí ẹni fẹran jẹ̀kọ la ó máa lóye ẹ̀kọ́ tí wọ́n bá ń kọ́ wa nígbà yẹn, àá sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́nà tó pé pérépéré. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ la ó máa ṣe, àti pé a gbà pé ìfẹ́ tó ní sí wa ló mú kó máa mọ wá. w16.06 1:​8, 9

Saturday, July 7

Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.​—Diu. 6:4.

Gbólóhùn yẹn wà lára ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lọ́dún 1473 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ sọdá odò Jọ́dánì kí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí. (Diu. 6:1) Mósè tó ti jẹ́ aṣáájú wọn fún ogójì [40] ọdún ló ń rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n nígboyà torí wọ́n máa tó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Èyí á gba pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Torí náà, ó dájú pé ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Mósè sọ máa wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn gan-an. Lẹ́yìn tí Mósè ti mẹ́nu ba àwọn Òfin Mẹ́wàá àtàwọn àṣẹ míì tí Jèhófà pa fún wọn, ó sọ ọ̀rọ̀ tó fakíki tó wà nínú Diutarónómì 6:​4, 5. Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ò mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wọn jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo” ni? Ó dájú pé wọ́n mọ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo làwọn ń sìn, ìyẹn Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. w16.06 3:​2, 3

Sunday, July 8

Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.​—Mát. 24:36.

Ìgbà tí Jésù wà láyé ló sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, Jèhófà fún un lágbára láti pa ayé Sátánì run. (Ìṣí. 19:​11-16) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jésù ti wá mọ ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Àmọ́ àwa ò mọ̀ ọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò títí dìgbà ìpọ́njú ńlá. Ohun kan ni pé àtilẹ̀ ni Jèhófà ti mọ ìgbà tí gbogbo nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀. Ó ti pinnu àkókò pàtó tí òpin máa dé. Ohun tó ń retí ni pé kí àkókò náà tó kí ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀, ó sì dájú pé “kì yóò pẹ́.” (Háb. 2:​1-3) Kí ló mú kí èyí dá wa lójú? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà máa ń ṣẹ lásìkò pàtó tó ní lọ́kàn. Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa dáàbò bo àwa náà nígbà ìpọ́njú ńlá, ó sì dá wa lójú pé kò ní já wa kulẹ̀. Àmọ́ ṣá o, tá a bá fẹ́ la òpin ètò búburú yìí já, àfi ká máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. w16.07 2:​4-6

Monday, July 9

Pétérù wí fún un pé: “Àní bí a bá mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀, síbẹ̀ a kì yóò mú èmi kọsẹ̀.” ​—Máàkù 14:29.

Gbogbo àwọn àpọ́sítélì ló pa Jésù tì nígbà tó nílò wọn jù. Pétérù ti fọ́nnu tẹ́lẹ̀ pé tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ fi Jésù sílẹ̀, òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 14:​27-31, 50) Àmọ́, nígbà tí wọ́n mú Jésù, gbogbo àwọn àpọ́sítélì títí kan Pétérù ló pa Jésù tì. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù tún sọ pé òun ò mọ Jésù rí. (Máàkù 14:​53, 54, 66-72) Síbẹ̀, Pétérù kábàámọ̀ ohun tó ṣe, Jèhófà sì lò ó fún ọ̀pọ̀ iṣẹ́. Ká sọ pé ìwọ náà wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà yẹn, ṣé wàá jẹ́ kí ohun tí Pétérù ṣe ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́? Lónìí, ǹjẹ́ wàá gbà pé Jèhófà lè fẹ́ fàyè sílẹ̀ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kan láti ronú pìwà dà, àti pé á mú àwọn nǹkan tọ́ lásìkò tó tọ́, á sì ṣe ìdájọ́ òdodo? Nígbà míì sì rèé, àwọn tó hùwà burúkú náà lè kọ ìbáwí Jèhófà, kí wọ́n má sì ronú pìwà dà. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé wàá gbà pé Jèhófà máa dá àwọn oníwà burúkú náà lẹ́jọ́ lákòókò tó yẹ, àti pé ó lè yọ wọ́n kúrò nínú ìjọ? w16.06 4:​8, 9

Tuesday, July 10

Kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Baba wa Ọlọ́run, .  . . tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in.​—2 Tẹs. 2:​16,17.

Ìbùkún ńlá tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ń mú wá ni ìtùnú tá a máa ń ní nígbà tọ́kàn wa bá dàrú. (Sm. 51:17) Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojúmọ́ tòní sí àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí nílùú Tẹsalóníkà. Ẹ wo bó ṣe tuni lára tó pé a ní Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń gba tiwa rò torí pé inú rere rẹ̀ ò ṣeé díwọ̀n. Torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, tí wọ́n bá fi dídàá wa, a ò lè ṣe ọ̀nà àbáyọ fúnra wa. (Sm. 49:​7, 8) Àmọ́ Jèhófà ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa, ìrètí àgbàyanu sì ni. Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èyí ni ìfẹ́ Baba mi, pé gbogbo ẹni tí ó rí Ọmọ tí ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:40) Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn ni ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì jẹ́ ká rí i pé ohun ribiribi ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù mọyì kókó yìí gan-an, ìyẹn ló jẹ́ kó sọ pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí ń mú ìgbàlà wá fún gbogbo onírúurú ènìyàn ni a ti fi hàn kedere.”​—Títù 2:11. w16.07 3:​14, 15

Wednesday, July 11

Kí ẹnikẹ́ni má sì ṣe àdàkàdekè sí aya ìgbà èwe rẹ̀.​—Mál. 2:15.

Àwa èèyàn Jèhófà lónìí kì í gba irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ láyè. Àmọ́ ká sọ pé ẹnì kan tó ti ṣèrìbọmi tó sì ti ṣègbéyàwó bá sá lọ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹlòmíì, tí wọ́n sì jọ ṣègbéyàwó lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ ẹni tí wọ́n fẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ni ìjọ máa ṣe? Tírú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ronú pìwà dà, wọ́n máa yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ kí wọ́n lè dáàbò bo ìjọ. (1 Kọ́r. 5:​11-13) Kí wọ́n tó lè gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ pa dà, ó gbọ́dọ̀ “mú àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde.” (Lúùkù 3:8; 2 Kọ́r. 2:​5-10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú ìwà yìí ṣọ̀wọ́n láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run, síbẹ̀ irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ìlànà kan tó sọ bó ṣe yẹ kó pẹ́ tó kí wọ́n tó gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ pa dà, ó lè tó ọdún kan tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ kí oníwà àìtọ́ náà tó lè fi hàn pé lóòótọ́ lòun ti ronú pìwà dà. Àmọ́ ó yẹ ká fi sọ́kàn pé tí wọ́n bá tiẹ̀ gbà á pa dà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣì máa jíhìn “níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.”​—Róòmù 14:​10-12. w16.08 1:​12, 13

Thursday, July 12

Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.​—1 Tím. 3:1.

Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a tú sí “nàgà fún” túmọ̀ sí kéèyàn nawọ́ kọ́wọ́ rẹ̀ lè tó ohun tó ń fẹ́. Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò yìí jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kọ́wọ́ rẹ̀ tó lè tẹ àwọn ohun tó ń lé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin kan tí kò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ronú nípa bó ṣe lè fi kún ohun tó ń ṣe nínú ìjọ. Ó mọ̀ pé kóun tó lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, òun gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ní láti dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè kó tó lè di alàgbà. Èyí fi hàn pé ó gba ìsapá kéèyàn tó lè tóótun láti ní àfikún iṣẹ́ èyíkéyìí nínú ìjọ. Lọ́nà kan náà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó bá fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà, tó fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba gbọ́dọ̀ sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́. w16.08 3:​3, 4

Friday, July 13

Àwọn . . . ni ìránṣẹ́ rẹ àti ènìyàn rẹ, tí o túnrà padà nípa agbára ńlá rẹ àti nípa ọwọ́ líle rẹ.​—Neh. 1:10.

Wo bó ṣe máa rí lára Nehemáyà nígbà tó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó sì rí i pé gbayawu ni ìlú náà wà torí pé ògiri tó yí i ká ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wó tán, ọkàn àwọn Júù tó ń gbébẹ̀ ò sì balẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń halẹ̀ mọ́ wọn káwọn tó ń tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́ bàa lè dáṣẹ́ dúró. Ṣé Nehemáyà náà wá jẹ́ kóhun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn mú òun rẹ̀wẹ̀sì débi pé kò lè ṣiṣẹ́ mọ́? Rárá! Bíi ti Mósè, Ásà àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà míì, Nehemáyà kì í fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré, ó sì máa ń gbára lé Jèhófà. (Ẹ́kís. 17:​8-13; 2 Kíró. 14:​8-13) Ohun tó ṣe náà nìyẹn nígbà tó dé Jerúsálẹ́mù. Jèhófà gbọ́ àdúrà Nehemáyà, ó sì mú kí ohun tó dà bí òkè ńlá lójú àwọn Júù di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ọlọ́run lo “agbára ńlá” àti “ọwọ́ líle” rẹ̀ láti fún ọwọ́ àwọn Júù tó ti rọ jọwọrọ lókun. (Neh. 2:​17-20; 6:9) Ṣó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣì ń lo “agbára ńlá” àti “ọwọ́ líle” rẹ̀ láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní lókun? w16.09 1:9

Saturday, July 14

Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 10:31.

Nígbà tí ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Netherlands ń sọ nípa àpérò kan táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ṣe, ó sọ pé: “Aṣọ tí àwọn èèyàn náà wọ̀ kò buyì kún àpérò náà rárá, pàápàá lásìkò ooru.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í múra bẹ́ẹ̀ nígbà àpéjọ wọn.” Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń gbóríyìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé a máa ń fi ‘aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wa lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, lọ́nà tí ó yẹ àwọn tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.’ (1 Tím. 2:​9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ yìí sí, síbẹ̀ ìlànà yìí kan náà làwọn arákùnrin ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra. Ó ṣe pàtàkì káwa èèyàn Jèhófà máa wọ aṣọ tó bójú mu, ohun tí Ọlọ́run tá à ń sìn náà sì fẹ́ nìyẹn. (Jẹ́n. 3:21) Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa aṣọ àti ìmúra fi hàn pé Ọlọ́run ní àwọn ìlànà tó fẹ́ káwa olùjọsìn rẹ̀ máa tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ irú aṣọ tá a máa wọ̀. Torí náà, tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀, kì í ṣohun tó wù wá nìkan ló yẹ ká máa rò. Ó tún yẹ ká máa ronú nípa ohun tó máa wu Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. w16.09 3:​1, 2

Sunday, July 15

Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn. ​—2 Pét. 1:21.

Lára ohun táwọn kan ṣèwádìí nípa rẹ̀ ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, wọ́n tún wá ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ làwọn ìtàn inú Bíbélì, àti bí sáyẹ́ǹsì àtàwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ti Bíbélì lẹ́yìn. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan téèyàn á fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ ni Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ẹsẹ yìí ló jẹ́ ká mọ àkòrí Bíbélì lódindi, ìyẹn ni pé Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, á sì jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn lo èdè àpèjúwe láti jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa dá aráyé nídè kúrò lọ́wọ́ ìyà táráyé ti ń jẹ látọjọ́ Ádámù. Ọ̀nà wo lo lè gbà ṣèwádìí nípa Jẹ́nẹ́sísì 3:15? Ọ̀nà kan ni pé kó o ṣàkọsílẹ̀ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì ṣe wáyé. Bó o ṣe ń ṣèwádìí, máa kíyè sí àwọn ibi tí Bíbélì ti tọ́ka sí àwọn tọ́rọ̀ kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, àti bó ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ. Kọ àwọn ẹsẹ yẹn sílẹ̀, wàá wá rí i pé ńṣe làwọn ẹsẹ yẹn so kọ́ra, ọ̀kan tẹ̀lé èkejì, á sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé òótọ́ ni pé “ẹ̀mí mímọ́ ló darí” àwọn wòlíì àtàwọn míì tó kọ Bíbélì. w16.09 4:8

Monday, July 16

Ta ní mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn?​—1 Kọ́r. 4:7.

Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Pétérù ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn tí kì í ṣe Júù bíi tiẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá ó borí èrò yẹn. (Ìṣe 10:​28, 34, 35; Gál. 2:​11-14) Lọ́nà kan náà, tá a bá kíyè sí i pé àwa náà máa ń fojú tí kò tọ́ wo àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa, á dáa ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yí èrò wa pa dà. (1 Pét. 1:22) Ká máa rántí pé kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbàlà, torí pé aláìpé ni gbogbo wa, láìka ìlú tàbí orílẹ̀-èdè tá a ti wá sí. (Róòmù 3:​9, 10, 21-24) Torí náà, kí nìdí tẹ́nì kan á fi máa rò pé òun sàn ju ẹlòmíì lọ? Ojú tí Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn èèyàn ló yẹ káwa náà fi máa wo àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bíi tiẹ̀ pé wọn ‘kì í ṣe àjèjì àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé Ọlọ́run.’ (Éfé. 2:19) Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa fojú tó tọ́ wo àwọn tí èdè tàbí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa, àá fìwà jọ Ọlọ́run.​—Kól. 3:​10, 11. w16.10 1:9

Tuesday, July 17

Ó . . . ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.​—Sm. 1:2.

Kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá fẹ́ láyọ̀, tá a sì fẹ́ ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Sm. 1:​1-3; Ìṣe 17:11) Bíi tàwọn olóòótọ́ ìgbàanì, àwa náà gbọ́dọ̀ máa ronú nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí fún wa. (Mát. 24:45) Torí náà, tá a bá mọyì ohun tá à ń kọ́ látinú àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè yìí, a máa dà bí àwọn olóòótọ́ ìgbàanì tí wọ́n ní ìdánilójú pé Ìjọba táwọn ń retí náà máa dé. (Héb. 11:1) Ohun pàtàkì míì tó mú kí ìgbàgbọ́ àwọn olóòótọ́ ìgbàanì lágbára ni àdúrà. Bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà tí wọ́n sì ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wọn, ṣe ni ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ ń lágbára.​—Neh. 1:​4, 11; Sm. 34:​4, 15, 17; Dán. 9:​19-21. w16.10 3:​7, 8

Wednesday, July 18

Bí mo bá sì ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ńláńlá nípò padà, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.​—1 Kọ́r. 13:2.

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an nígbà tó dáhùn ìbéèrè táwọn kan bi í pé: “Èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?” (Mát. 22:​35-40) Torí pé ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì lo àwọn ànímọ́ yìí pa pọ̀ kódà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n “gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀.” (1 Tẹs. 5:8) Jòhánù náà sọ pé: “Èyí ni àṣẹ [Ọlọ́run], pé kí a ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi, kí a sì máa nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòh. 3:23) Lóòótọ́ ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì, àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, kò ní sídìí láti nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run mọ́ torí pé wọ́n á ti ṣẹ. Nígbà yẹn, ayé tuntun tá à ń retí á ti dé. Àmọ́, títí ayé làá ṣì máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.”​—1 Kọ́r. 13:13. w16.10 4:​15-17

Thursday, July 19

Àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.​—Ìṣe 16:5.

Àwọn arákùnrin tí ìgbìmọ̀ olùdarí rán jáde máa ń fi “àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí” ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ. (Ìṣe 16:4) Bí àwọn ará ṣe ń pa àwọn àṣẹ yìí mọ́, ńṣe ni “àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” Lónìí, tí a bá gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, kí ló yẹ ká ṣe? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn ká sì máa tẹrí ba. (Diu. 30:16; Héb. 13:​7, 17) Nínú ètò Ọlọ́run, kò yẹ ká máa ṣe tinú wa tàbí ká máa ṣàríwísí torí irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ìfẹ́ àti àlàáfíà wà nínú ìjọ, ó sì máa ń dá ìyapa sílẹ̀. Ó dájú pé kò sí ẹnì kankan táá fẹ́ fìwà jọ Dìótíréfè tó ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn tó ń múpò iwájú tí kì í sì í bọ̀wọ̀ fún wọn. (3 Jòh. 9, 10) A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fún àwọn míì níṣìírí láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run bá fún wa? Ṣé mo máa ń tètè gba ìtọ́ni táwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú fún wa, ṣé mo sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn?’ w16.11 2:​10, 11

Friday, July 20

Ẹ wá àlàáfíà ìlú ńlá tí mo mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn.​—Jer. 29:7.

Àwọn tó ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn yẹn ń bá ìgbésí ayé wọn lọ nílùú Bábílónì. Àwọn tó mú wọn lẹ́rú gbà wọ́n láyè déwọ̀n àyè kan pé kí wọ́n máa bójú tó ara wọn. Kódà, àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn lè lọ síbi tó wù wọ́n nílùú Bábílónì. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ káràkátà àti òwò ṣíṣe, ojúkò ni Bábílónì jẹ́ láyé ọjọ́hun. Àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n wú jáde nínú ilẹ̀ ìlú náà fi hàn pé ọ̀pọ̀ Júù ló di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nídìí káràkátà, àwọn míì sì di ọ̀gá nídìí iṣẹ́ ọnà. Kódà, àwọn kan lára wọn di ọlọ́rọ̀. Ó ṣe kedere pé bí nǹkan ṣe rí nígbèkùn Bábílónì yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú lábẹ́ àwọn ará Íjíbítì ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. (Ẹ́kís. 2:​23-25) Àmọ́ ṣó ṣì máa ṣeé ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa jọ́sìn Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? Lásìkò tí wọ́n wà nígbèkùn yẹn, kò dájú pé wọ́n á lè ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbọ́ pé Bábílónì kì í dá àwọn ẹrú rẹ̀ sílẹ̀. Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa dá àwọn èèyàn òun nídè, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó dájú pé ìlérí Ọlọ́run kò ní lọ láìṣẹ.​—Aísá. 55:11. w16.11 4:​3, 5

Saturday, July 21

A kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀.​—Róòmù 6:2.

Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àwọn Kristẹni yẹn ti “kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀” nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè? Ọlọ́run mú kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni ìgbàanì jàǹfààní látinú ìràpadà. Nípasẹ̀ ìràpadà, ó dárí jì wọ́n, ó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, ó sì sọ wọ́n dọmọ. Èyí mú kí wọ́n nírètí láti lọ sí ọ̀run. Tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó ní wọ́n jẹ́ ‘òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì wà láàyè tí wọ́n sì ń sin Ọlọ́run. Ó fi Jésù ṣe àpẹẹrẹ, torí Jésù kú nínú ẹran ara àmọ́ Ọlọ́run jí i dìde sí ọ̀run, ó sì fún un ní àìleèkú. Torí náà, ikú kò ní agbára lórí Jésù mọ́. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró torí wọ́n ka ara wọn sí ‘òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ alààyè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Róòmù 6:​9, 11) Ìgbésí ayé wọn ti yàtọ̀. Wọ́n jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀. Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n kú ní ti ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. w16.12 1:​9, 10

Sunday, July 22

Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.​—Róòmù 8:6.

“Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí” kò túmọ̀ sí pé kẹ́ni náà máa ṣe bí áńgẹ́lì. Kò sì túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti bó ṣe ń ka Bíbélì nìkan láá máa sọ ṣáá. Ẹ rántí pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni olóòótọ́ míì tó gbáyé nígbà yẹn gbádùn ìgbésí ayé wọn. Wọ́n gbádùn oúnjẹ aládùn, wọ́n mu, wọ́n ṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀ wọn ṣègbéyàwó, wọ́n sì ní ìdílé. (Máàkù 6:3; 1 Tẹs. 2:9) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni olóòótọ́ yẹn kò jẹ́ kí àwọn ìgbádùn yìí gbà wọ́n lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ pípa àgọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń ṣe, síbẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ló gba Pọ́ọ̀lù lọ́kàn jù. (Ìṣe 18:​2-4; 20:​20, 21, 34, 35) Ohun tó sì ní káwọn ará tó wà ní Róòmù máa ṣe nìyẹn. Èyí fi hàn pé ìjọsìn Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù gbájú mọ́. Ó yẹ káwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.​—Róòmù 15:​15, 16. w16.12 2:​5, 15, 16

Monday, July 23

Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un. ​—Òwe 19:17.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì àwọn ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀, bó ti wù kó kéré tó. Ó mọ àwọn ohun tó ń bà wá lẹ́rù àtàwọn ohun tó ń kó àníyàn bá wa. Tí ìṣòro àtijẹ àtimu, àìsàn tàbí ẹ̀dùn ọkàn kò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, Jèhófà lóye wa ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó ò ń kojú. (Héb. 6:​10, 11) Ká rántí pé a lè sọ ìṣòro wa fún Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà,” ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa gbọ́ tiwa. (Sm. 65:2) Bíbélì sọ pé: “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. Kódà, ó lè lo àwọn ará láti pèsè ìrànlọ́wọ́ yìí. (2 Kọ́r. 1:3) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá fàánú hàn sáwọn èèyàn. (Mát. 6:​3, 4) Ó sì ṣèlérí pé òun máa san èrè fún wa. w16.12 4:​13, 14

Tuesday, July 24

Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.​—2 Kọ́r. 3:17.

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó lo òmìníra tó ní láti kọ àwọn ìdánwò tí alátakò gíga jùlọ gbé dìde sí i. (Mát.4:10) Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, àdúrà tó gbà fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló wà lọ́kàn rẹ̀. Ó sọ pé: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kìí ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa lílo òmìnira tí a ní láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run! Ó ṣeé ṣe ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù torí pé àwòrán Ọlọ́run làwa náà. (Jẹ́n. 1:26) Àmọ́, ó níbi tí òmìnira wa mọ, a ò lè máa ṣe bó ṣe wù wá láìsí ẹni tó ń yẹ̀ wá lọ́wọ́ wò. Nínú Bíbélì, Ọlọ́run fún wa láwọn òfin àti ìlànà tá a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aya gbọ́dọ̀ fara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn, kí àwọn ọmọ sì máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn.​—Éfé. 5:22; 6:1. w17.01 2:​4, 5

Wednesday, July 25

Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ. ​—Róòmù 12:3.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń yí pa dà lásìkò wa yìí. Apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà náà ò sì dúró sójú kan, ṣe ló ń gbèrú sí i, ìyẹn sì ń béèrè pé ká yí ọ̀pọ̀ nǹkan pa dà. Bí ìyípadà náà bá sì kàn wá, ẹ jẹ́ ká fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, torí pé ire tiwa kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, kàkà bẹ́ẹ̀ ire Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ ká máa rò. Tá a bá lérò tó tọ́, á jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara nínú ara kan, ṣùgbọ́n tí gbogbo ẹ̀yà ara náà kò ní ẹ̀yà iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.” (Róòmù 12:​4, 5) Ìyípadà yòówù kó dé bá wa, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ire Ìjọba Jèhófà lè túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú. Ẹ̀yin àgbàlagbà, ẹ máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. Ẹ̀yin arákùnrin tá a faṣẹ́ lé lọ́wọ́, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà tẹ́ ẹ jọ wà. Ẹ̀yin aya, ẹ fara wé Pírísílà tó jẹ́ aya Ákúílà tó máa ń ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣí kiri tí ipò wọn sì ń yí pa dà.​—Ìṣe 18:2. w17.01 5:​15, 16

Thursday, July 26

Èmi sì ni ó kéré jù lọ.​—Oníd. 6:15.

Àpẹẹrẹ àtàtà ni Gídíónì tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹni. Lẹ́yìn tí Gídíónì gbà láti ṣe iṣẹ́ Jèhófà, ó rí i dájú pé òun lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ó sì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. (Oníd. 6:​36-40) Ọmọ akin ni Gídíónì, kò bẹ̀rù rárá. Síbẹ̀, ó fọgbọ́n ṣe iṣẹ́ náà. (Oníd. 6:​11, 27) Kò wo iṣẹ́ náà bí ohun táá fi gbayì. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó parí iṣẹ́ náà, ṣe ló pa dà sílé rẹ̀. (Oníd. 8:​22, 23, 29) Kéèyàn mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ kò ní kéèyàn má nàgà fún tàbí gba àfikún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. Ó ṣe tán Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ síwájú. (1 Tím. 4:​13-15) Àmọ́ ṣó dìgbà tí iṣẹ́ èèyàn bá yí pa dà, kéèyàn tó gbà pé òun ń tẹ̀ síwájú? Kò di dandan. A lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe lọ́wọ́, lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sapá láti ní àwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni, ká sì máa sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe lọ́wọ́. w17.01 3:​15, 16

Friday, July 27

Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.​—1 Jòh. 4:9.

Kì í ṣe ohun kékeré ló ná Jèhófà láti pèsè ìràpadà náà. (1 Pét. 1:19) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an débi pé ó gbà kí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kú nítorí wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé Jésù ti wá di bàbá wa dípò Ádámù. (1 Kọ́r. 15:45) Yàtọ̀ sí pé Jésù mú ká ní ìyè, ó tún jẹ́ ká pa dà di ara ìdílé Ọlọ́run. Torí ìràpadà tí Jésù san, Jèhófà gba àwa èèyàn pa dà sínú ìdílé rẹ̀ láìfọwọ́ rọ́ ìlànà òdodo rẹ̀ tì. Ẹ wo bó ṣe máa dùn tó nígbà táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bá di pípé! Nígbà yẹn, àwọn tó wà nínú ìdílé Ọlọ́run, láyé àti lọ́run yóò wà níṣọ̀kan. Àá wá di ọmọ Ọlọ́run ní ti gidi. (Róòmù 8:21) Tá a bá mọyì ìràpadà, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú káwọn míì jàǹfààní ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run fún wa yìí. w17.02 1:​17, 19

Saturday, July 28

Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?​—Mát. 24:45.

Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013 jẹ́ ká mọ̀ pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró, àwọn ló sì para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń panu pọ̀ ṣe ìpinnu. Lọ́nà wo? Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà máa ń ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí sì máa ń mú kí àárín wọn gún kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. (Òwe 20:18) Nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ọdọọdún ni wọ́n máa ń yí ẹni tó jẹ́ alága pa dà torí pé kò sí èyíkéyìí lára wọn tó gbà pé òun lọ́lá ju àwọn tó kù lọ. (1 Pét. 5:1) Ohun kan náà ni ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò máa ń ṣe. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ka ara rẹ̀ sí ọ̀gá àwọn yòókù, kàkà bẹ́ẹ̀ arákùnrin ni wọ́n kara wọn sí, wọ́n sì gbà pé “ará ilé” làwọn àti pé ẹrú olóòótọ́ ló ń bọ́ àwọn tó sì ń bójú tó àwọn. Ìgbìmọ̀ Olùdarí kò sọ pé Ọlọ́run mí sí àwọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe ẹni pípé tí kò lè ṣàṣìṣe. Torí náà, wọ́n lè ṣàṣìṣe nínú àlàyé tí wọ́n ń ṣe lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì àti nínú àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún agboolé ìgbàgbọ́. w17.02 4:​10-12

Sunday, July 29

[Ọlọ́run] kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa.​—Róòmù 8:32.

Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ìràpadà náà ni pé ká lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, ká ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ká sì ṣe ìrìbọmi. Ìrìbọmi tá a ṣe fi hàn pé “a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) Torí pé ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe, ó fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa fìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. (1 Jòh. 4:​8-11) A lè fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ “ọmọ Baba [wa] tí ń bẹ ní ọ̀run” tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn aládùúgbò wa. (Mát. 5:​43-48) A rántí pé lẹ́yìn tí Jésù ní ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó tún sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:​37-40) Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn bí Jésù ṣe pa á láṣẹ. Bá a ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, ńṣe là ń gbé ògo Ọlọ́run yọ. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run tó lè “di pípé nínú wa,” ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, pàápàá jù lọ àwọn ará wa.​—1 Jòh. 4:​12, 20. w17.02 2:​13, 14

Monday, July 30

Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.​—1 Ọba 18:21.

O lè ronú pé ìpinnu yẹn kò ṣòro ṣe rárá, torí pé ohun tó bọ́gbọ́n mu tó sì máa ṣeni láǹfààní ni pé kéèyàn jọ́sìn Jèhófà. Ó sì dájú pé kò sẹ́ni tó láròjinlẹ̀ tó máa sọ pé Báálì lòun á sìn. Síbẹ̀, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń “tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra.” Abájọ tí wòlíì Èlíjà fi rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n sin Jèhófà, torí pé ìyẹn ni ìjọsìn tòótọ́. Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Àkọ́kọ́ ni pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà mọ́, wọn ò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọn kì í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọn ò fi ọgbọ́n rẹ̀ ṣèwà hù, wọn ò sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Ká ní wọ́n ń fọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù ni, wọ́n á máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Sm. 25:12) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbà káwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká kó èèràn ràn wọ́n, wọ́n sì tún gbà kí wọ́n máa ṣèpinnu fún wọn. Àwọn èèyàn ilẹ̀ yẹn kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà, torí náà wọ́n mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa bọ̀rìṣà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti kìlọ̀ fún wọn pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn tí wọn ò bá ṣọ́ra.​—Ẹ́kís. 23:2. w17.03 2:​6, 7

Tuesday, July 31

[Hesekáyà] sì fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe sí wẹ́wẹ́.​—2 Ọba 18:4.

Bá a ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ Hesekáyà, a lè rí àwọn ohun kan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, tàbí tó lè má jẹ́ ká pọkàn pọ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ fara wé àwọn èèyàn ayé tí wọ́n ti sọ àwọn èèyàn bíi tiwọn di òrìṣà lórí ìkànnì àjọlò. Ohun kan ni pé àwọn Kristẹni kan gbádùn kí wọ́n máa bá àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìkànnì yìí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nínú ayé ti ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ lílo ìkànnì àjọlò, wọ́n máa ń tẹ àmì kan tó fi hàn pé àwọn ń tẹ̀ lé àwọn tí wọn ò mọ̀ rí. Wọ́n máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti wo fọ́tò àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n máa kà nípa wọn. Tá ò bá ṣọ́ra, àwa náà lè máa fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Kristẹni kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń tẹ àmì kan tí wọ́n fi ń sọ pé àwọn fẹ́ràn àwọn nǹkan tó ń gbé sórí ìkànnì àjọlò, ó sì lè máa bínú torí pé àwọn kan tó ti ń tẹ̀ lé e tẹ́lẹ̀ lórí ìkànnì àjọlò ò tẹ̀ lé e mọ́. Àwa náà lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń ṣọ́ra kí n má lọ sọ àwọn èèyàn di òrìṣà? Ṣé mi ò kì í lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì?’​—Éfé. 5:​15,16. w17.03 3:​14, 17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́