ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 77-87
  • August

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • August
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Wednesday, August 1
  • Thursday, August 2
  • Friday, August 3
  • Saturday, August 4
  • Sunday, August 5
  • Monday, August 6
  • Tuesday, August 7
  • Wednesday, August 8
  • Thursday, August 9
  • Friday, August 10
  • Saturday, August 11
  • Sunday, August 12
  • Monday, August 13
  • Tuesday, August 14
  • Wednesday, August 15
  • Thursday, August 16
  • Friday, August 17
  • Saturday, August 18
  • Sunday, August 19
  • Monday, August 20
  • Tuesday, August 21
  • Wednesday, August 22
  • Thursday, August 23
  • Friday, August 24
  • Saturday, August 25
  • Sunday, August 26
  • Monday, August 27
  • Tuesday, August 28
  • Wednesday, August 29
  • Thursday, August 30
  • Friday, August 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 77-87

August

Wednesday, August 1

Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.​—Ják. 1:4.

Ìjà ọ̀hún ti di àjàkú-akátá. Gbogbo òru mọ́jú ni Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi lé àwọn ará Mídíánì àtàwọn tó ń gbèjà wọn, nǹkan bíi kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n [32] ni wọ́n sì rìn bí wọ́n ti ń lé wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé àwọn ò tíì rẹ́yìn gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, torí náà, wọn ò dẹ̀yìn lẹ́yìn wọn. Ṣe ni Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣáà ń lé àwọn ọ̀tá náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun wọn. (Oníd. 7:22; 8:​4, 10, 28) Àwa náà ń ja ìjà kan tó le gan-an, tó sì ń tánni lókun. Sátánì, ayé búburú yìí àti àìpé tiwa fúnra wa làwọn ọ̀tá tá à ń bá jà. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọ̀tá yìí ti ń bá ọ̀pọ̀ lára wa fà á. Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà ti mú ká borí wọn. Àmọ́, a ò tíì rẹ́yìn wọn. Ó lè rẹ̀ wá nígbà míì tàbí kí gbogbo nǹkan tiẹ̀ tojú sú wa torí pé ó ti pẹ́ tá a ti ń retí òpin ètò búburú yìí. Jésù ti sọ fún wa pé a máa dojú kọ àwọn àdánwò tó le koko, wọ́n sì máa ṣe inúnibíni tó lé kenkà sí wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́, ó tún sọ pé àá borí tá a bá fara dà á.​—Lúùkù 21:19. w16.04 2:​1, 2

Thursday, August 2

Kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.​—Héb. 10:​24, 25.

Ní ìpàdé, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Jèhófà sì máa ń kọ́ wa lóhun tó fẹ́ ká ṣe àti bó ṣe fẹ́ ká máa gbé ìgbé ayé wa. (Aísá. 30:​20, 21) Kódà, táwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wá sípàdé, wọ́n máa ń rí i pé Ọlọ́run ló ń darí wa. (1 Kọ́r. 14:​23-25) Ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ohun tá à ń kọ́ ti ń wá, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló sì fi ń darí àwọn ìpàdé wa. Torí náà, tá a bá lọ sípàdé, ọ̀rọ̀ Jèhófà la lọ gbọ́, à ń rí bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, àá sì túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ sọ pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọ pọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.” (Mát. 18:20) Bíbélì tún sọ pé Jésù “ń rìn ní àárín” àwọn ìjọ. (Ìṣí. 1:20–2:1) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jèhófà àti Jésù wà pẹ̀lú wa, wọ́n sì ń gbé wa ró láwọn ìpàdé wa. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà tó bá rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe láti túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun àti Ọmọ rẹ̀? w16.04 3:​13, 14

Friday, August 3

Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.​—Oníw. 7:9.

Arábìnrin kan kí àwọn arákùnrin méjì kan, inú ọ̀kan lára wọn ò dùn sí bó ṣe kí wọn. Lẹ́yìn tí arábìnrin náà ti lọ tán, arákùnrin tínú rẹ̀ ò dùn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí sí ohun tí arábìnrin náà sọ. Síbẹ̀, arákùnrin kejì rán arákùnrin tó ń bínú náà létí pé arábìnrin náà ti ń fòtítọ́ sin Jèhófà láìka ìṣòro sí láti ogójì ọdún [40] sẹ́yìn, àti pé kì í ṣe pé arábìnrin náà mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ mú un bínú. Lẹ́yìn tí arákùnrin tó ń bínú náà ronú díẹ̀ lórí ohun tó gbọ́ yìí, ó sọ pé: “Òótọ́ lo sọ.” Bí wọ́n sì ṣe yanjú rẹ̀ nìyẹn. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Àwa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe tọ́rọ̀ kan tó lè fa aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ìfẹ́ máa ń mú kéèyàn dárí ji àwọn ẹlòmíì ni. (Òwe 10:12; 1 Pét. 4:8) Lójú Jèhófà, “ẹwà” ló jẹ́ tó o bá le “gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Torí náà, nǹkan tó yẹ kó o kọ́kọ́ bi ara ẹ téèyàn bá ṣẹ̀ ọ́ ni pé, ‘Ṣé mo lè gbójú fò ó? Ṣó tiẹ̀ yẹ kí n sọ ọ̀rọ̀ náà di bàbàrà?’ w16.05 1:​8, 9

Saturday, August 4

Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, . . . kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.​—Fílí. 2:13.

Àwọn wo gan-an ló ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí? A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni!” Kí ló mú kó dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀? Torí pé ohun tó yẹ ká wàásù là ń wàásù, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tún fi hàn pé ọ̀nà tó tọ́ là ń gbà ṣe iṣẹ́ náà. Ìdí tó yẹ la sì ń torí ẹ̀ wàásù, ìyẹn ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àtàwọn èèyàn, kì í ṣe torí ká lè rí owó kó jọ. Iṣẹ́ ìwàásù wa ló gbòòrò jù lọ, torí pé àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà là ń wàásù fún. Láti ọdún dé ọdún, a ó máa bá iṣẹ́ náà nìṣó, a ò sì ní dáwọ́ dúró títí tí òpin fi máa dé. Inú wa dùn bá a ṣe ń rí ohun táwa èèyàn Ọlọ́run ń gbé ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Àmọ́, kí ló mú kí gbogbo nǹkan yìí ṣeé ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yẹn nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. Ǹjẹ́ kí Baba wa onífẹ̀ẹ́ fún gbogbo wa lókun bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa, ká lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.​—2 Tím. 4:5. w16.05 2:​17, 18

Sunday, August 5

Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere. ​—Róòmù 12:9.

Tá a bá yàn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ tá a sì ń sapá láti ṣe é, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ múnú rẹ̀ dùn. A tún ń fi hàn pé a gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Sátánì ti sọ pé Jèhófà ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, torí náà tá a bá fínnúfíndọ̀ fi ara wa sábẹ́ Jèhófà tá a sì ń sapá láti ti ìṣàkóso rẹ̀ lẹ́yìn, ó dájú pé inú Jèhófà Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ máa dùn sí wa. (Jóòbù 2:​3-5; Òwe 27:11) Àmọ́, tí Jèhófà bá mú kí gbogbo ẹ̀ rọrùn fún wa débi pé a ò tiẹ̀ ní làágùn jìnnà ká tó lè ṣe ohun tó fẹ́, báwo la ṣe lè sọ pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí i àti pé lóòótọ́ la gbà kó máa darí wa? Torí náà, Jèhófà sọ pé ká sapá gidigidi ká lè ní àwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni. (2 Pét. 1:​5-7; Kól. 3:12) Ó retí pé ká ṣiṣẹ́ kára ká lè borí àwọn èrò tí kò tọ́ tá a máa ń ní àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. (Róòmù 8:5) Tá a bá ṣiṣẹ́ kára láti ṣàtúnṣe tó yẹ tá a sì ṣàṣeyọrí, inú wa máa dùn pé Bíbélì ṣì ń yí ìgbésí ayé wa pa dà. w16.05 4:​12, 13

Monday, August 6

Jèhófà, . . . ìwọ . . . ni Ẹni tí ó mọ wá.​—Aísá. 64:8.

Jèhófà mọ irú “amọ̀” tí kálukú wa jẹ́, ó sì máa ń fìyẹn sọ́kàn nígbà tó bá ń mọ wá. (Sm. 103:​10-14) Ọwọ́ tó fi ń mú kálukú wa yàtọ̀ síra, ó mọ ibi tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa kù sí, ibi tágbára wa mọ àti bí òye òtítọ́ tá a ní ṣe pọ̀ tó. Jésù Kristi jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àìpé wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ojú tí Jésù fi wo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, pàápàá jù lọ lórí ọ̀rọ̀ ta lọ̀gá tí wọ́n máa ń fà láàárín ara wọn. Tó o bá wà níbẹ̀ nígbà táwọn àpọ́sítélì ń bá ara wọn jiyàn, ṣé wàá sọ pé onírẹ̀lẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n á ṣeé tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún? Síbẹ̀, Jésù ò gbà pé ọ̀rọ̀ wọn kọjá àtúnṣe. Ó mọ̀ pé tóun bá ń fi sùúrù gbà wọ́n nímọ̀ràn, tí òun jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì ń rí bóun ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọ́n á ṣàtúnṣe tó yẹ. (Máàkù 9:​33-37; 10:​37, 41-45; Lúùkù 22:​24-27) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, táwọn àpọ́sítélì náà sì gba ẹ̀mí mímọ́, bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ ló gbà wọ́n lọ́kàn, wọn ò tún sọ̀rọ̀ nípa ta lọ̀gá mọ́.​—Ìṣe 5:42. w16.06 1:10

Tuesday, August 7

Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.​—Diu. 6:4.

Kò sí Ọlọ́run tòótọ́ mìíràn àfi Jèhófà; kò sí ọlọ́run bíi rẹ̀. (2 Sám. 7:22) Torí náà, Mósè ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọn ò gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run míì yàtọ̀ sí Jèhófà. Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe bí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tó ń bọ onírúurú òrìṣà. Àwọn orílẹ̀-èdè yẹn gbà pé àwọn òrìṣà yẹn ló ń darí àwọn ohun àdáyébá kan bí omi, afẹ́fẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n sì tún gbà pé àwọn òrìṣà míì jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òrìṣà kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Íjíbítì máa ń bọ òrìṣà Ra, tí wọ̀n gbà pé ó ń darí oòrùn, Nut ni wọ́n gbà pé ó ń darí òfuurufú, Geb ni wọ́n kà sí òòṣà ilẹ̀ àti Hapi tí wọ́n pè ní òrìṣà Náílì yàtọ̀ sí àwọn ẹranko onírúurú tí wọ́n ń bọ. Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá tí Jèhófà mú wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì mú kó ṣe kedere pé òtúbáńtẹ́ lásán làsàn làwọn òrìṣà wọn. Báálì ni òléwájú lára àwọn òòṣà tí àwọn ọmọ Kénáánì ń bọ, wọ́n sì gbà pé òun ni òrìṣà ìbímọlémọ, tó ń darí òfuurufú, òjò àti ìjì. Báálì yìí kan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká ń bọ. (Núm. 25:3) Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa rántí pé “Jèhófà kan ṣoṣo” ni Ọlọ́run táwọn ń sìn, òun sì ni “Ọlọ́run tòótọ́.”​—Diu. 4:​35, 39. w16.06 3:​4, 5

Wednesday, August 8

Kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan. ​—Mát. 28:20.

Títí dòní, Jésù ṣì fọkàn tán Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Tá a bá ronú lórí ohun tí Jèhófà ń tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a máa rí i pé ó kàmàmà. Kò sí àwùjọ míì tó ń wàásù òtítọ́ kárí ayé, torí pé Jèhófà ò darí wọn bó ṣe ń darí ìjọ rẹ̀ tó wà níṣọ̀kan lónìí. Ìwé Aísáyà 65:14 sọ nípa bí ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa rí, ó ní: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń yọ̀ nítorí àwọn nǹkan rere tí wọ́n ń gbé ṣe bí Jèhófà ṣe ń darí wọn. Àmọ́, àwọn tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì ń kérora bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé. A gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti ètò rẹ̀, ká sì kọ́ ara wa ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn míì bá ṣàṣìṣe. w16.06 4:​10-12

Thursday, August 9

Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. ​—Mát. 25:13.

A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká wà lójúfò látinú ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe nígbà àtijọ́. Láyé àtijọ́, àwọn ìlú ńlá bíi Jerúsálẹ́mù máa ń ní odi gìrìwò tó yí i ká. Odi yìí máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, àtorí odi yìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ti máa ń ṣọ́ ohun tó ń lọ láyìíká torí pé ó ga dáadáa. Tọ̀sántòru làwọn ẹ̀ṣọ́ yìí sì máa ń wà lórí odi náà àti lẹ́nu bodè. Iṣẹ́ wọn ni láti ta àwọn ará ìlú lólobó tí wọ́n bá rí ewu tó ń bọ̀. (Aísá. 62:6) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí wà lójúfò, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ohun tó ń lọ láyìíká wọn, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wẹ́rẹ́ logun á wọlé táá sì pa àwọn èèyàn. (Ìsík. 33:6) Òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Ó sọ pé ohun tó mú káwọn ọmọ ogun Róòmù ráyè wọ Ilé Gogoro Antonia tí wọ́n kọ́ mọ́ odi Jerúsálẹ́mù ni pé àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu bodè ti sùn lọ fọnfọn! Àtibẹ̀ làwọn ọmọ ogun Róòmù ti rọ́ wọ tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì dáná sun ún. Èyí ló fa ìpọ́njú tó tíì burú jù lọ táwọn Júù fojú winá nílùú Jerúsálẹ́mù. w16.07 2:​2, 7, 8

Friday, August 10

Ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.​—2 Pét. 3:17.

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìbùkún là ń gbádùn torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, síbẹ̀ kò yẹ ká máa ronú pé Ọlọ́run ò ní bínú tá a bá ń hu ìwàkiwà. Àwọn Kristẹni kan wà láyé ọjọ́un tí wọ́n fẹ́ “sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run . . . di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” (Júúdà 4) Àwọn Kristẹni aláìṣòótọ́ yẹn gbà pé àwọn lè máa dẹ́ṣẹ̀ torí pé aláàánú ni Jèhófà, á sì dárí ji àwọn. Ohun tó wá burú ńbẹ̀ ni pé wọ́n ń tan àwọn ará míì sínú ìwà àìnítìjú wọn. Lónìí, ńṣe lẹni tó bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lò. (Héb. 10:29) Sátánì ti mú káwọn kan lára àwa Kristẹni òde òní máa ronú pé àwọn lè máa dẹ́ṣẹ̀ báwọn ṣe fẹ́ torí pé àánú Ọlọ́run pọ̀. Òótọ́ ni pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà, síbẹ̀ ó retí pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti borí àwọn ohun tó máa ń mú ká dẹ́ṣẹ̀. w16.07 3:​16, 17

Saturday, August 11

Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà. ​—Mát. 19:9.

Tí tọkọtaya bá kọ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àmọ́ tí kì í ṣe torí panṣágà, wọn ò ní lè fẹ́ ẹlòmíì. Ọkọ tàbí aya lè dárí ji ẹnì kejì rẹ̀ tó ṣe panṣágà àmọ́ tó ronú pìwà dà, bí wòlíì Hóséà náà ṣe dárí ji Gómérì ìyàwó rẹ̀ tó ṣe panṣágà. Jèhófà náà dárí ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n jọ́sìn àwọn òrìṣà míì. (Hós. 3:​1-5) Àmọ́ ohun kan rèé o, tí ẹnì kan bá mọ̀ pé ọkọ tàbí aya òun ti ṣe panṣágà, tó sì wá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ti dárí jì í nìyẹn kò sì lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn tí Jésù sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, ó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn” láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya. Ó tún wá sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.” (Mát.19:​10-12) Ọ̀pọ̀ ló ti pinnu pé àwọn ò ní ṣègbéyàwó káwọn lè sin Jèhófà láìsí ìpínyà ọkàn. Ó yẹ ká gbóríyìn fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. w16.08 1:​15, 16

Sunday, August 12

Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í. . . . Kò sí àìní kankan fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.​—Sm. 34:​8, 9.

Àwọn ọ̀dọ́ máa ń lo okun wọn láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Òwe 20:29) Àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé míì. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n sì ń tún un ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ míì sì máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ níbi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ló sì ń tan ìhìn rere náà dé àwọn abúlé àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Onísáàmù náà kọrin pé: ‘Àwọn tí ń wá Jèhófà kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.’ (Sm. 34:10) Jèhófà kì í gbàgbé àwọn tó ń fìtara sìn ín. Táwa náà bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, àwa náà ń tọ́ Jèhófà wò nìyẹn, àá sì rí i pé lóòótọ́ ló jẹ́ ẹni rere. Tá a bá ń fi gbogbo okun, agbára àti ọkàn wa sin Jèhófà, ayọ̀ wa á kọjá àfẹnusọ. w16.08 3:​5, 8

Monday, August 13

Èmi yóò gbà yín là, ẹ óò sì di ìbùkún. Ẹ má fòyà. Kí ọwọ́ yín le.​—Sek. 8:13.

Jèhófà lágbára láti fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, á sì ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kíró. 29:12) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ká bàa lè borí àwọn àtakò Sátánì àtàwọn ìṣòro tí ayé Èṣù yìí ń gbé kò wá. (Sm. 18:39; 1 Kọ́r. 10:13) Bákan náà, Jèhófà fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun míì tún ni àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá à ń rí gbà lóṣooṣù. Ọ̀rọ̀ kan tó ń fúnni níṣìírí wà nínú Sekaráyà 8:​9, 13. Ìgbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ ni wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó sì dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn wúlò fún wa gan-an. Ohun míì tó ń fún wa lókun ni ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń kọ́ láwọn ìpàdé wa, àwọn àpéjọ àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà yìí ń mú kó máa wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, ó mú ká ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ ká bójú tó àwọn ojúṣe wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Sm. 119:32) Ṣó máa ń wù ẹ́ láti wà láwọn ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ yìí kó o lè máa rókun gbà? w16.09 1:​10, 11

Tuesday, August 14

Kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.​—Róòmù 12:2.

Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà kórìíra àwọn ìmúra tí kì í jẹ́ ká dá ọkùnrin mọ̀ yàtọ̀ sí obìnrin, irú èyí tó lòde lónìí. (Diu. 22:5) Nínú ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa ìmúra, a rí i kedere pé Ọlọ́run ò fẹ́ kí ọkùnrin máa múra bí obìnrin tàbí kí obìnrin máa múra bí ọkùnrin. Kò sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìmúra tí kì í jẹ́ kéèyàn mọ̀ bóyá ọkùnrin lẹnì kan tàbí obìnrin. Tó bá dọ̀rọ̀ ìmúra, Bíbélì ní àwọn ìlànà tó lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa. Àwọn ìlànà yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láìka ibi tá à ń gbé tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa àti bójú ọjọ́ ṣe rí. A ò nílò òfin jàn-ràn-jan-ran nípa irú aṣọ tó yẹ ká wọ̀ àtèyí tí kò yẹ ká wọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì là ń tẹ̀ lé bí kálukú wa ṣe ń yan irú aṣọ tó wù ú láti wọ̀. w16.09 3:​3, 4

Wednesday, August 15

Gbogbo wọ́n sì pa á tì, wọ́n sì sá lọ.​—Máàkù 14:50.

Ohun míì tó tún lè mú kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára ni pé kó máa ronú lórí báwọn tó kọ Bíbélì ṣe lo ìgboyà, tí wọn ò sì fi dúdú pe funfun. Àwọn òǹkọ̀wé míì láyé ọjọ́un máa ń pọ́n àwọn aṣáájú wọn ju bó ṣe yẹ lọ, wọ́n sì máa ń gbógo fún orílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́, ní ti àwọn wòlíì Jèhófà, bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ ni wọ́n máa ń sọ. Wọn ò daṣọ bo àṣìṣe àwọn èèyàn wọn, títí kan tàwọn ọba wọn. (2 Kíró. 16:​9, 10; 24:​18-22) Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò bo àṣìṣe tiwọn àti tàwọn míì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (2 Sám. 12:​1-14;) Torí pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní làwọn kan ṣe gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. (Sm. 19:​7-11) Ó ṣe kedere pé àwọn ìlànà Bíbélì ń dáàbò bò wá torí pé a kì í lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké àtàwọn àṣà tó ń mú àwọn èèyàn lẹ́rú. (Sm. 115:​3-8) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ti fi nǹkan míì pe Ọlọ́run, wọn ò sì fún Jèhófà ní ògo tó yẹ ẹ́. Àwọn tó sọ pé kò sí Ọlọ́run gbà pé bí ayé yìí bá máa dáa, ọwọ́ àwa èèyàn ló wà. Àmọ́, ó ṣe kedere pé kò sí báwa èèyàn ṣe lè mú ìgbà ọ̀tun bá ayé.​—Sm. 146: 3, 4. w16.09 4:​10, 11

Thursday, August 16

Ẹ jẹ́ kí ó pèéṣẹ́ . . . , ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fìtínà rẹ̀.​—Rúùtù 2:15.

Ọ̀rọ̀ tí Bóásì bá Rúùtù sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ Rúùtù jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an, ìdí sì ni pé ó lóye àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ torí pé àjèjì ni. Torí náà, ó sọ fún un pé àwọn obìnrin ni kó máa bá ṣiṣẹ́ káwọn ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ nínú oko má bàa yọ ọ́ lẹ́nu. Kódà, Bóásì rí i pé Rúùtù rí oúnjẹ jẹ dáadáa, ó sì rómi mu bíi tàwọn òṣìṣẹ́ yòókù. Yàtọ̀ síyẹn, Bóásì ò fọ̀rọ̀ gún Rúùtù lára, kàkà bẹ́ẹ ṣe ló ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un. (Rúùtù 2:​8-10, 13, 14) Bóásì mọyì bí Rúùtù ṣe ń tọ́jú Náómì ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì tún gbóríyìn fún un torí pé ó ti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Bóásì ṣojúure sí Rúùtù torí pé Jèhófà náà nífẹ̀ẹ́ obìnrin yìí àti pé ó ti ‘wá ìsádi lábẹ́ ìyẹ́ apá Ọlọ́run Ísírẹ́lì.’ (Rúùtù 2:​12, 20; Òwe 19:17) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, tá a bá fojúure hàn sí “gbogbo onírúurú ènìyàn,” wọ́n lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n á sì rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn.​—1 Tím. 2:​3, 4. w16.10 1:​10-12

Friday, August 17

Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi.​—Sm. 34:4.

Àwa náà lè sọ gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Jèhófà torí a mọ̀ pé á gbọ́ tiwa, á sì fún wa lókun táá mú ká láyọ̀ bá a ṣe ń fara dà á. Tá a bá wá rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wa, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. (1 Jòh. 5:​14, 15) Torí pé ìgbàgbọ́ jẹ́ ọ̀kan lára èso tẹ̀mí, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà lóòrèkóòrè pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ bí Jésù ṣe rọ̀ wá pé ká ṣe. (Lúùkù 11:​9, 13) Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a fẹ́ nìkan làá máa béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ‘nǹkan àgbàyanu’ tá ò lè kà tán ni Jèhófà ti ṣe tó sì yẹ ká máa dúpẹ́ fún lójoojúmọ́! (Sm. 40:5) Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó wà lẹ́wọ̀n “bí ẹni pé a dè [wá] pẹ̀lú wọn.” Bákan náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà fún gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé pàápàá jù lọ “àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín [wa].” Ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára bá a ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa.​—Héb. 13:​3, 7. w16.10 3:​8, 9

Saturday, August 18

A ti gbà yín là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; èyí kì í sì í ṣe ní tìtorí tiyín, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.​—Éfé. 2:8.

Lóde òní, àwa èèyàn Jèhófà ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Èyí ti mú káwa èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ, tá à ń gbé níbi gbogbo láyé máa gbé nínú Párádísè tẹ̀mí. Ìdí sì ni pé à ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wa nínú Párádísè tẹ̀mí yìí. (Gál. 5:​22, 23) Kò sí àní-àní pé ìgbàgbọ́ tó lágbára àti ìfẹ́ tòótọ́ ló so wá pọ̀! Kò sí ẹ̀dá èèyàn tó lè sọ pé òun lọpẹ́ tọ́ sí fún ohun tá à ń gbádùn yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run lọpẹ́ yẹ torí pé òun ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Èyí ti mú káwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà, ó sì tún jẹ́ “àmì fún àkókò tí ó lọ kánrin tí a kì yóò ké kúrò.” (Aísá. 55:13) Ńṣe ni Párádísè tẹ̀mí yìí á túbọ̀ máa gbilẹ̀ títí dìgbà tí gbogbo olódodo máa di pípé, tí wọ́n á máa fayọ̀ sin Jèhófà, tí wọ́n á sì máa yin orúkọ rẹ̀ títí ayé. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà! w16.10 4:​18, 19

Sunday, August 19

Àwọn kan ń rìn ségesège láàárín yín.​—2 Tẹs. 3:11.

A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni táwọn alàgbà ń fún wa látinú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa nípa àwọn tó ń ṣe ségesège nínú ìjọ. Nígbà yẹn, àwọn kan ò ṣiṣẹ́ rárá nínú ìjọ, ṣe ni “wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.” Ó dájú pé àwọn alàgbà ti máa fún wọn ní ìmọ̀ràn, àmọ́ wọn ò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà. Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ní kí wọ́n ṣe fún irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ó ní: ‘Ẹ sàmì sí ẹni yìí, kí ẹ sì dẹ́kun bíbá a kẹ́gbẹ́.’ Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò sọ pé ká sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di ọ̀tá. (2 Tẹs. 3:​11-15) Lónìí, àwọn alàgbà lè pinnu pé á dáa káwọn sọ àsọyé kan láti kìlọ̀ fún ìjọ nípa ìwà tẹ́nì kan ń hù, tí irú ìwà bẹ́ẹ̀ sì lè ran àwọn ẹlòmíì nínú ìjọ. Ó lè jẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (1 Kọ́r. 7:39) Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ ká sọ pé o mọ ẹni tí ọ̀rọ̀ yẹn ń bá wí, ṣé wàá ṣì máa bá ẹni náà ṣe wọléwọ̀de? Tó o bá yẹra fún un, òun náà á mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí ohun tóun ń ṣe, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ yí pa dà. w16.11 2:13

Monday, August 20

Láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn. ​—Ìṣe 20:30.

Nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe. Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn náà ló di “ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” (1 Pét. 2:​9, 10) Ní gbogbo ìgbà táwọn àpọ́sítélì fi wà láyé, àwọn ni wọ́n ń bójú tó ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà káàkiri. Àmọ́ nígbà táwọn àpọ́sítélì náà kú, àwọn ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ “àwọn ohun àyídáyidà” kí wọ́n lè “fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (2 Tẹs. 2:​6-8) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọkùnrin tá à ń sọ yìí ló jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ, tí wọ́n wá sọ ara wọn di bíṣọ́ọ̀bù nígbà tó yá. Bó ṣe di pé wọ́n ka ara wọn sí àwùjọ aṣáájú nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín.” (Mát. 23:8) Àwọn ọkùnrin yẹn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ ayé táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí bí Aristotle àti Plato fi ń kọ́ni, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ ìjọ dípò ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. w16.11 4:8

Tuesday, August 21

Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú àwọn ara kíkú yín.​—Róòmù 6:12.

Ká tó di Kristẹni, a máa ń dẹ́ṣẹ̀, kódà a lè má mọ bí ohun tá à ń ṣe ṣe burú tó lójú Ọlọ́run. Ṣe la dà bí “ẹrú fún ìwà àìmọ́ àti ìwà àìlófin.” Torí náà, a lè sọ pé a “jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:​19, 20) Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, a ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wa, a ya ara wa sí mímọ́ a sì ṣe ìrìbọmi. Àtìgbà yẹn ló ti ń wù wá láti jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà” sí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Ọlọ́run. Ní báyìí, Ọlọ́run ti “dá [wa] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀” a sì ti “di ẹrú fún òdodo.” (Róòmù 6:​17, 18) Tá a bá ń fi àìpé kẹ́wọ́, tá a wá ńṣe ohun tó wù wá, ńṣe là ń “jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso” wa. Ọwọ́ wa ló wà tá a bá fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàkóso wa tàbí kó má ṣàkóso wa. Ìbéèrè náà ni pé, Ṣé ìwọ fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàkóso rẹ? Á dáa kó o bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń jẹ́ kí àìpé mú kí n máa ro èròkerò kí n sì jẹ́ kó tì mí ṣe ohun tí kò dáa? Ṣé mo ti di òkú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀? Ṣé mo wà láàyè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù?’ Ìdáhùn wa sinmi lórí bóyá a mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí wa tàbí a ò mọyì rẹ̀. w16.12 1:​11, 12

Wednesday, August 22

Gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí . . . àlàáfíà.​—Róòmù 8:6.

Ọ̀kan lára ohun tó ń mú kọ́kàn wa balẹ̀ ni pé a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà lè wà nínú ìdílé wa, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tá  a jọ wà nínú ìjọ. A mọ̀ pé aláìpé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Torí náà, àìgbọ́ra-ẹni-yé lè wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, a máa ń  tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé: ‘Wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ.’ (Mát. 5:24) Ó túbọ̀ máa rọrùn fún wa láti wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa tá a bá ń rántí pé “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà” ni gbogbo wa ń sìn. (Róòmù 15:33; 16:20) Tá a bá ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí,’ a máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Èyí sì ju àlàáfíà èyíkéyìí tá a lè ní lọ. Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ìmúṣẹ rẹ̀ gbòòrò gan-an lónìí, ó ní, Jèhófà yóò ‘pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé e mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’​—Aísá. 26:3; Róòmù 5:1. w16.12 2:​5, 18, 19

Thursday, August 23

Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa.​—Fílí. 4:4.

Kódà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé Èṣù yìí, Jèhófà ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀. Jèhófà ń mú ká máa gbá yìn-ìn nínú Párádísè tẹ̀mí, a sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún. (Aísá. 54:13) Bí Jésù ṣe sọ ọ́ náà ló rí, Jèhófà ń bù kún wa báyìí, torí pé a wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (Máàkù 10:​29, 30) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé à ń fi taratara wá Ọlọ́run, a tún ń gbádùn ìbàlẹ̀ ọkàn, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tí kò láfiwé. (Fílí. 4:​5-7) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ‘lẹ́yìn tí o bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, wàá rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.’ (Héb. 10:​35, 36) Torí náà, jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára, kó o sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ó dá ẹ lójú pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni wàá ti gba ẹ̀san yíyẹ.​— Kól. 3:​23, 24. w16.12 4:​17, 20

Friday, August 24

Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.​—2 Kọ́r. 3:17.

Tó bá jẹ́ pé àwọn òfin àti ìlànà wà tá a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé, ṣé a lè sọ pé a ní òmìnira lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, a lómìnira! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tá a bá láwọn ìlànà tó ń tọ́ wa sọ́nà, ó máa dáàbò bò wá. Bí àpẹẹrẹ, a lè pinnu pé a fẹ́ wọkọ̀ lọ sílùú kan tó jìnnà. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé kò sí òfin ìrìnnà lójú ọ̀nà tá a fẹ́ gbà, táwọn èèyàn ń wa mọ́tò níwàkuwà, tí wọ́n sì ń sá eré àsápajúdé, ṣé ọkàn wa máa balẹ̀? Ó dájú pé ọkàn wa ò ní balẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká láwọn òfin àti ìlànà táá máa darí wa tí gbogbo wa bá máa gbádùn òmìnira tá a ní. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì táá jẹ́ ká rí bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tá a bá ń ṣèpinnu. Ó kọjá àyè rẹ̀ torí pé ó jẹ èso tí Ọlọ́run ní kó má jẹ. Òmìnira tí Ádámù ṣì lò yìí ló fà á táwa èèyàn fi ń jìyà látọdún yìí wá. (Róòmù 5:12) Ìkìlọ̀ gidi lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù yìí jẹ́ fún wa, pé ká má ṣi òmìnira wa lò, ká sì rí i pé à ń tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà. w17.01 2:​6, 8

Saturday, August 25

Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ. ​—Róòmù 12:3.

Kí onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tó gba iṣẹ́ tuntun, á kọ́kọ́ béèrè ohun tí iṣẹ́ náà máa gbà pé kóun ṣe. Lẹ́yìn ìyẹn, á fara balẹ̀ kíyè sí ipò ara rẹ̀. Téèyàn bá fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fi í sádùúrà, èèyàn ò ní ṣe kọjá ohun tágbára rẹ̀ gbé. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ láá fi sọ pé òun ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà. Tá a bá gba iṣẹ́ tuntun, ẹ jẹ́ ká máa rántí Gídíónì tó gbára lé Jèhófà, tó sì jẹ́ kó tọ́ òun sọ́nà. Tá a bá ṣe bíi tiẹ̀, àá ṣàṣeyọrí. Ó ṣe tán, Jèhófà ló ní ká “jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá òun rìn.” (Míkà 6:8) Torí náà, tá a bá gba iṣẹ́ tuntun, ó ṣe pàtàkì ká ronú tàdúràtàdúrà lórí ohun tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ sọ pé ká ṣe. Ó yẹ ká ṣe tán láti mú èrò wa bá ti Jèhófà mu. Ká máa rántí pé kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa tàbí òye wa ló jẹ́ ká láǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. (Sm. 18:35) Torí pé à ń bá Jèhófà rìn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní jẹ́ ká jọ ara wa lójú, a ò sì ní ro ara wa pin. w17.01 3:​17, 18

Sunday, August 26

Òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.​—1 Kọ́r. 15:58.

Jésù mọ̀ pé iṣẹ́ tóun wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé máa tó parí, ó sì mọ̀ pé àwọn míì lá máa bá iṣẹ́ náà lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀, Jésù fọkàn tán wọn, ó sì sọ fún wọn pé wọ́n máa ṣe ju iṣẹ́ tóun ṣe lọ. (Jòh. 14:12) Ó fara balẹ̀ dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, wọ́n sì wàásù ìhìn rere náà débi gbogbo táwọn èèyàn ń gbé nígbà yẹn. (Kól. 1:23) Lẹ́yìn tí Jésù ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ, Jèhófà jí i dìde sọ́run, ó sì gbé iṣẹ́ tó pọ̀ sí i fún un, ó wá wà nípò tó “ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa.” (Éfé. 1:​19-21) Tá a bá fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà dójú ikú kí Amágẹ́dọ́nì tó dé, Jèhófà máa jí wa dìde sínú ayé tuntun. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló sì máa wà níbẹ̀ fún wa láti ṣe. Àmọ́ ní báyìí ná, iṣẹ́ pàtàkì kan wà tó yẹ kí gbogbo wa máa ṣe, iṣẹ́ náà sì ni pé ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. Torí náà, a rọ gbogbo wa lọ́mọdé lágbà pé ká ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” w17.01 5:​17, 18

Monday, August 27

Èmi ni Jèhófà; Èmi kò yí padà.​—Mal. 3:6.

Jésù ti san ìràpadà náà, kò sì ní tún un san mọ́. (Héb. 9:​24-26) Ìràpadà náà mú ká bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Ọpẹ́lọpẹ́ Kristi tó kú fún wa, a ti bọ́ lọ́wọ́ ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì, a ò sì bẹ̀rù ikú mọ́. (Héb. 2:​14, 15) Àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣeé fọkàn tán. Bó ṣe dájú pé bí ilẹ̀ bá ṣú ilẹ̀ máa mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló dá wa lójú pé Jèhófà ò ní já wa kulẹ̀ láé. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà kì í yí pa dà. Ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa kọjá ìwàláàyè. Ó fún wa ní ìfẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwa fúnra wa sì ti wá mọ̀, a sì ti gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní nínú ọ̀ràn tiwa gbọ́. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:16) Ó dájú pé ayé yìí máa di Párádísè. Àá gbádùn ara wa gan-an, àá sì gbé ìfẹ́ Ọlọ́run yọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pa ohùn wa pọ̀ mọ́ tàwọn áńgẹ́lì lókè ọ̀run tí wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún àti ògo àti ọgbọ́n àti ìdúpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun ni fún Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé. Àmín.”​—Ìṣí. 7:12. w17.02 2:​16, 17

Tuesday, August 28

Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.​—2 Kọ́r. 7:1.

Ilé Ìṣọ́ June 1, 1973 béèrè ìbéèrè kan pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn tí kò tíì ṣíwọ́ nínú sìgá mímú àti àṣìlò tábà yẹ lẹ́ni tó lè ṣèrìbọmi?’ Ìtẹ̀jáde yẹn wá dáhùn pé: ‘Ẹ̀rí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé wọn ò yẹ.’ Lẹ́yìn tí Ilé Ìṣọ́ yẹn ti jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó ṣàlàyé pé bí ẹnì kan bá kọ̀ tí kò jáwọ́ nínú sìgá mímu, kí wọ́n yọ onítọ̀hún lẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 5:7) Ó wá fi kún un pé: ‘Orí ìpinnu tá a dé yìí kì í ṣe bí ẹni pàṣẹ wàá tàbí bí ẹni jẹ gàba léni lórí. Ìpinnu náà lè dà bí èyí tó le, àmọ́ ìpinnu Ọlọ́run ni, ó sì wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.’ Ìwé kan tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Ìgbà gbogbo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa ń yí ẹ̀kọ́ wọn pa dà kí wọ́n lè tẹ̀ síbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ̀ sí.” Ẹ̀sìn mélòó ló múra tán láti gbé gbogbo ìpinnu wọn karí Ìwé Mímọ́, kódà táwọn ìpinnu kan kò bá tiẹ̀ bá àwọn ọmọ ìjọ wọn lára mu? w17.02 4:15

Wednesday, August 29

Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga. ​—Mát. 23:12.

Olùṣọ́ àgùntàn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ la mọ àwọn alàgbà yìí sí. Torí pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọn kì í gbà káwọn èèyàn máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀ bí àwọn gbajúgbajà. Wọ́n yàtọ̀ sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn òde òní àtàwọn tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí Jésù sọ nípa wọn pé: “Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù, àti ìkíni ní àwọn ibi ọjà.” (Mát. 23:​6, 7) Àwọn alàgbà tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń ṣe ohun tí Jésù sọ pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní aṣáájú, nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Mát. 23:​8-11) Torí pé àwọn alàgbà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, inú àwọn ará níbi gbogbo láyé máa ń dùn láti bọlá fún wọn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. w17.03 1:​14, 15

Thursday, August 30

Nítorí olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.​—Gál. 6:5.

Ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló wà láti ṣèpinnu, tá a bá sì máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ó ṣe pàtàkì ká lóye Ìwé Mímọ́ dáadáa. Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ kí ẹlòmíì ṣèpinnu fún wa, ojúṣe wa ni. Dípò táwọn míì á fi máa ṣèpinnu fún wa, ó yẹ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì ṣe é. Kí ló lè mú kẹ́nì kan jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún òun? Ó lè jẹ́ torí àtiṣe ohun táwọn míì ń ṣe, ìyẹn sì máa ń mú kéèyàn ṣèpinnu tí kò tọ́. (Òwe 1:​10, 15) Síbẹ̀, ohun yòówù káwọn èèyàn rọ̀ wá pé ká ṣe, àwa la máa pinnu bóyá ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́ la máa tẹ̀ lé àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún wa, ó túmọ̀ sí pé ohun tí wọ́n fẹ́ la yàn láti ṣe. Yálà a mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí a ò mọ̀, ìpinnu kan la ṣe yẹn, àmọ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í sábà dáa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn ará tó wà ní Gálátíà pé ó léwu tí wọ́n bá ń jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún wọn. (Gál. 4:17) Àwọn kan wà nínú ìjọ yẹn tí wọ́n fẹ́ máa ṣèpinnu fáwọn míì kí wọ́n lè kẹ̀yìn wọn sáwọn àpọ́sítélì. w17.03 2:​8-10

Friday, August 31

Nígbà tí [Jòsáyà] ṣì jẹ́ ọmọdékùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀; ní ọdún kejìlá sì ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀.​—2 Kíró. 34:3.

Jòsáyà nítara fún ìjọsìn Ọlọ́run. Bíi ti Jòsáyà, ó yẹ káwọn ọmọdé bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà ní báyìí tí wọ́n ṣì wà ní kékeré. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ọba Mánásè tó yí pa dà kúrò nínú ìwà búburú tó ń hù ló kọ́ Jòsáyà pé aláàánú ni Ọlọ́run. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, sún mọ́ àwọn àgbàlagbà tó ń fọkàn sin Jèhófà, tí wọ́n wà nínú ìdílé rẹ àti nínú ìjọ, kó o lè mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere sí wọn. Bákan náà, rántí pé Ìwé Mímọ́ tí Jòsáyà kà wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì mú kó ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Tíwọ náà bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀, wàá sì túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, á mú kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti wàásù fáwọn míì káwọn náà lè wá sin Ọlọ́run. (2 Kíró. 34:​18, 19) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá rí àwọn ọ̀nà tó o lè gbà mú iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣiṣẹ́ lórí àwọn nǹkan tó o kíyè sí bí Jòsáyà ti ṣe. w17.03 3:​18, 19

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́