October
Monday, October 1
Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.—Sm. 145:19.
Jèhófà ni “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú.” (Róòmù 15:5) Òun nìkan lọ̀rọ̀ wa yé, òun nìkan ló mọ ohun tá à ń bá yí, ó sì mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Torí náà, ó mọ ohun tá a nílò gan-an ká lè máa fara dà á. Àmọ́ lẹ́yìn tá a bá ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, báwo ló ṣe máa fún wa lókun ká lè máa fara dà á? Jèhófà ṣèlérí pé tá a bá ké pe òun pé kóun ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á, òun á “ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa. (1 Kọ́r. 10:13) Báwo ló ṣe máa ń ṣe é? Nígbà míì, ó lè mú ìṣòro náà kúrò. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ló máa ń fún wa lókun ká ‘lè fara dà á ní kíkún, ká sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’ (Kól. 1:11) Torí pé Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, ó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ó sì mọ ibi tá a lè mú nǹkan mọ́ra dé, kò ní jẹ́ kí ìṣòro ọ̀hún mu wá lómi débi tá ò fi ní lè jẹ́ olóòótọ́ sí i mọ́. w16.04 2:5, 6
Tuesday, October 2
Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run. —Mát. 22:21.
Bíbélì kọ́ wa pé ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ, àmọ́ ó tún sọ fún wa pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. (Ìṣe 5:29; Títù 3:1) Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe é? Jésù sọ ìlànà kan táá jẹ́ ká mọ ẹni tá a gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní. À ń san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì” tá a bá ń pa òfin ìjọba mọ́, tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn aṣojú ìjọba, tá a sì ń san owó orí. (Róòmù 13:7) Àmọ́, táwọn aláṣẹ bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́, àá sọ fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé a kò ní ṣe é. A kì í dá sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú òṣèlú. (Aísá. 2:4) Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà ti fàyè gba ìjọba èèyàn láti máa ṣàkóso, a kì í ta kò wọ́n. Bákan náà, a kì í dá sí ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tàbí ohunkóhun tó máa gbé orílẹ̀-èdè wa lárugẹ. (Róòmù 13:1, 2) A kì í gbìyànjú láti dojú ìjọba dé tàbí dìtẹ̀ sí ìjọba, a kì í kó sáwọn olóṣèlú lórí torí kí wọ́n lè ṣohun tá a fẹ́, a kì í dìbò, a kì í sì í di olóṣèlú. w16.04 4:1, 2
Wednesday, October 3
Jẹ́ kí ó rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè.—Mát. 18:17.
Bí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwa Kristẹni, àárín ara wa ló ti yẹ ká yanjú ẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Àmọ́, Jésù sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tó yẹ káwọn alàgbà dá sí. (Mát. 18:15-17) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí ẹni tó ṣẹ̀ bá kọ̀ láti tẹ́tí sí arákùnrin rẹ̀, tí kò tẹ́tí sáwọn ẹlẹ́rìí tó wá bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà, tí kò sì tún tẹ́tí sí ìjọ? Ó yẹ kí a ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí “ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí lóde òní ni pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Pé ohun tí ẹni yìí ṣe lè la ìyọlẹ́gbẹ́ lọ fi hàn pé “ẹ̀ṣẹ̀” náà kì í wulẹ̀ ṣe èdè àìyedè tí kò tó nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ (1) ẹ̀ṣẹ̀ táwọn méjèèjì lè yanjú láàárín ara wọn, (2) ó tún jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì débi pé ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́ tí wọn ò bá yanjú ẹ̀. Irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè ní ẹ̀tàn tàbí èrú nínú, ó sì lè ba èèyàn lórúkọ jẹ́, táwọn èèyàn bá ń tàn án kálẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí báyìí nìkan la máa gbé àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí Jésù sọ nínú Mátíù 18:15-17. w16.05 1:14
Thursday, October 4
Ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.—Éfé. 5:17.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí ò sí òfin pàtó kan nípa ẹ̀ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìwé Mímọ́, kò sí òfin pàtó kan tó sọ irú aṣọ táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa wọ̀. Báwo nìyẹn ṣe fi ọgbọ́n Jèhófà hàn? Yàtọ̀ sí pé àṣà, ìmúra àti bí wọ́n ṣe ń ránṣọ láwọn ibì kan yàtọ̀ sí ti ibòmíì, ọdọọdún ni nǹkan ń yí pa dà níbi gbogbo. Ká ní Bíbélì ti sọ pé irú àwọn aṣọ kan la gbọ́dọ̀ máa wọ̀ ni, ó dájú pé ohun tó bá sọ kò ní bóde mu mọ́ lónìí. Bákan náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò fún wa láwọn òfin jàn-àn-ràn jan-an-ran nípa irú iṣẹ́ tí Kristẹni kan lè ṣe, irú ìtọ́jú ìṣègùn tó lè gbà àti irú eré ìnàjú tó lè ṣe. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan tí kò sì sí òfin kan pàtó nípa ẹ̀ nínú Bíbélì? Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló kù sí láti ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa ká sì ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu táá sì múnú rẹ̀ dùn, kó má jẹ́ pé ohun tó bá kàn ti wù wá la máa ṣe.—Sm. 37:5. w16.05 3:2, 6
Friday, October 5
Ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—1 Tẹs. 2:13.
Kò sí àní-àní pé gbogbo wa la ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn láàyò. Ìwé Ìhìn Rere làwọn kan fẹ́ràn jù, ìyẹn àwọn ìwé tó jẹ́ ká rí bí Jésù ṣe gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ. (Jòh. 14:9) Àwọn Ìwé Bíbélì tó ní àsọtẹ́lẹ̀ nínú làwọn míì kúndùn, irú bí ìwé Ìṣípayá, ìyẹn ìwé tó jẹ́ ká mọ àwọn “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.” (Ìṣí. 1:1) Ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ wa làwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù ti tù nínú, a sì ti rí àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò gan-an kọ́ nínú ìwé Òwe. Ká sòótọ́, gbogbo èèyàn ni Bíbélì wúlò fún. Bá a ṣe fẹ́ràn Bíbélì náà la ṣe fẹ́ràn àwọn ìtẹ̀jáde wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, a mọyì àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà, irú bí àwọn ìwé, àwọn ìwé pẹlẹbẹ, àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìtẹ̀jáde wa míì. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń fún wa yìí ń mú ká wà lójú fò nípa tẹ̀mí, wọ́n ń jẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, wọ́n sì ń mú kí á jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—Títù 2:2. w16.05 5:1-3
Saturday, October 6
Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. Kò sí òfin kankan lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.—Gál. 5:22, 23.
Onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀mí mímọ́ lè gbà mọ wá. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, ní pàtàkì ká máa fi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwàhù. Ọ̀kan lára èso yìí ni ìfẹ́. A nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó ń wù wá ká máa ṣègbọràn sí i, a fẹ́ kó mọ wá, a sì gbà pé òfin rẹ̀ kò ni wá lára. Ẹ̀mí mímọ́ máa fún wa lágbára tí a ò fi ní jẹ́ kí ayé sọ wá dà bó ṣe dà. (Éfé. 2:2) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lọ́dọ̀ọ́, ẹ̀mí ìgbéraga táwọn aṣáájú ìsìn Júù ní wọ òun náà lẹ́wù, àmọ́ nígbà tó yá ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílí. 4:13) Torí náà, ẹ jẹ́ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe. Jèhófà máa ń gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀.—Sm. 10:17. w16.06 1:12
Sunday, October 7
Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá.—Ìṣí. 4:11.
Ká lè fi hàn pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run wa, a ò gbọ́dọ̀ ní ohun míì tá à ń júbà, àfi òun nìkan. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a ò gbọ́dọ̀ mú nǹkan míì mọ́ ìjọsìn wa, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í ṣe ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ọlọ́run tó wà tàbí pé òun ló lágbára jù láàárín wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn. Kó lè ṣe kedere pé Jèhófà nìkan là ń sìn, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ohunkóhun mìíràn má ṣe gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún? Nínú Òfin Mẹ́wàá, Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí òun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí. (Diu. 5:6-10) Èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà láìfura torí pé onírúurú ọ̀nà ni ìbọ̀rìṣà pín sí lóde òní. Àmọ́, torí pé Ọlọ́run wa jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo,” ohun tó ní ká ṣe kò tíì yí pa dà.—Máàkù 12:29. w16.06 3:10, 12
Monday, October 8
Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú.—Mát. 6:14.
Nígbà tí Pétérù bi Jésù pé ṣó yẹ ká dárí jini “títí dé ìgbà méje.” Jésù dá a lóhùn pé: “Mo wí fún ọ, kì í ṣe, títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé ó yẹ ká múra tán láti máa dárí jini, kódà ohun tó yẹ kó máa wù wá láti ṣe nígbà gbogbo nìyẹn. (Mát. 6:15; 18:21, 22) Ó yẹ ká rántí pé aláìpé làwa náà, a sì lè ṣẹ àwọn míì. Tá a bá kíyè sí i pé a ti ṣẹ ẹnì kan, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká lọ bá ẹni tá a ṣẹ̀, ká sì wá bá a ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Mát. 5:23, 24) Inú wa máa ń dùn táwọn míì bá dárí jì wá, torí náà ó yẹ káwa náà máa dárí ji àwọn míì. (1 Kọ́r. 13:5; Kól. 3:13) Tá a bá ń dárí ji àwọn míì, Jèhófà máa dárí ji àwa náà. Torí náà, táwọn míì bá ṣe ohun tó dùn wá, ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ tó máa ń fi àánú hàn sí wa tá a bá ṣàṣìṣe.—Sm. 103:12-14. w16.06 4:15, 17
Tuesday, October 9
Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́. —Róòmù 1:16.
Jèhófà ti gbéṣẹ́ fún àwa èèyàn rẹ̀ tá à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí pé ká wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) “Ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” làwa náà ń wàásù rẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Gbogbo ìbùkún tá à ń retí láti gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ nítorí pé Jèhófà fi inú rere hàn sí wa nípasẹ̀ Kristi. (Ìṣe 20:24; Éfé. 1:3) Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àwa ńkọ́, ṣé a lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù? (Róòmù 1:14, 15) Onírúurú ọ̀nà làwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ gbà ń jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wọn kọjá ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè jadùn ìfẹ́ yìí. w16.07 4:4, 5
Wednesday, October 10
Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.—Lúùkù 12:40.
Kí Jésù tó kú, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòh. 12:31; 14:30; 16:11) Jésù mọ̀ pé Èṣù máa fi àwọn èèyàn sínú òkùnkùn tẹ̀mí kí wọ́n má bàa fọkàn sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti pé Èṣù ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpin ti sún mọ́. (Sef. 1:14) Ìsìn èké ni Sátánì ń lò láti fọ́ ojú inú àwọn èèyàn. Kí lo máa ń kíyè sí tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé Èṣù ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́ tó fi jẹ́ pé wọn ò mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó pa ayé búburú yìí run àti pé Kristi ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run? (2 Kọ́r. 4:3-6) Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe làwọn èèyàn máa ń kọtí ikún tá a bá sọ fún wọn pé ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ayé yìí. Má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ débi tó ò fi ní wà lójúfò mọ́. Ìwọ náà mọ̀ pé ìyẹn léwu. w16.07 2:11, 12
Thursday, October 11
Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; . . . kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.—Éfé. 5:33.
Tí ọkọ ìyàwó bá rí ìyàwó rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn, inú àwọn méjèèjì á dùn débi pé téèyàn bá gẹṣin nínú wọn, kò lè kọsẹ̀ láé. Torí pé Jèhófà ní ire àwọn tọkọtaya lọ́kàn, ó fún wọn ní ìmọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú Bíbélì. Tí wọ́n bá tẹ̀ lé e, ìgbéyàwó wọn á dùn bí oyin, wọ́n á sì bára wọn kalẹ́. (Òwe 18:22) Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn tó ṣègbéyàwó máa “ní ìpọ́njú nínú ẹran ara.” (1 Kọ́r. 7: 28) Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe lè dín ìpọ́njú náà kù? Kí ló sì máa jẹ́ káwọn tọkọtaya bára wọn kalẹ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an láàárín tọkọtaya. Ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ (phi·liʹa lédè Gíríìkì) pọn dandan nínú ìgbéyàwó. Ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ọkùnrin àtobìnrin (eʹros) máa ń máyọ̀ wá, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ìdílé (stor·geʹ) ṣe kókó, pàápàá tí wọ́n bá ti ní ọmọ. Àmọ́ ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà (a·gaʹpe) ló máa ń jẹ́ kí ìgbéyàwó yọrí sí rere. w16.08 2:1, 2
Friday, October 12
Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.—1 Tím. 4:16.
Tímótì mọ béèyàn ṣe ń wàásù dáadáa, síbẹ̀ kí ìwàásù rẹ̀ tó lè méso jáde, ó gbọ́dọ̀ “máa fiyè sí” ọ̀nà tó ń gbà wàásù. Ìwàásù rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ dà bí adágún omi tí kì í kúrò lójú kan. Bí Tímótì bá fẹ́ kọ́rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, ó gbọ́dọ̀ máa lo onírúurú ọ̀nà láti wàásù. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Lónìí, a kì í sábà bá àwọn èèyàn nílé tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Láwọn ibòmíì, a kì í lè wọ àwọn ilé tàbí àdúgbò tó ní géètì. Bó bá jẹ́ pé bí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ṣe rí nìyẹn, á dáa kó o ronú lórí àwọn ọ̀nà míì tó o lè máa gbà polongo ìhìn rere. Ọ̀nà kan tó dáa tá a lè gbà tan ìhìn rere náà kalẹ̀ ni pé ká máa wàásù níbi térò pọ̀ sí. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ló ti rí i pé ọ̀nà ìwàásù yìí gbéṣẹ́ gan-an. Wọ́n máa ń ṣètò láti lọ sí àwọn ibùdókọ̀, ọjà, ibi ìgbọ́kọ̀sí àtàwọn ibòmíì térò máa ń pọ̀ sí. w16.08 3:14-16
Saturday, October 13
Ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ nà ró ṣánṣán.—Héb. 12:12.
Jèhófà fi àwọn ará kárí ayé jíǹkí wa, wọ́n sì ń fún wa níṣìírí. (Héb. 12:12, 13) Ọ̀pọ̀ Kristẹni nígbà yẹn lọ́hùn-ún ló rí irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Ohun kan náà ló sì ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Ṣe ni Áárónì àti Húrì gbé ọwọ́ Mósè sókè títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun. (Ẹ́kís. 17:8-13) Ó yẹ káwa náà máa wá ọ̀nà láti fún àwọn míì lókun, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn wo ló yẹ ká fún lókun? Àwọn tí ara wọn ti ń dara àgbà, àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn tí ìdílé wọn ń ṣenúnibíni sí, àwọn tí kò rẹ́ni fojú jọ àtàwọn téèyàn wọn kú. Ká má sì gbàgbé àwọn ọmọ táwọn ọ̀rẹ́ fẹ́ kí wọ́n máa ṣe bíi tiwọn. Àwọn ọ̀rẹ́ wọn yìí lè máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí àwọn ìwà tí kò tọ́ tàbí kí wọ́n máa lé àtirí towó ṣe, kí wọ́n sì lóókọ láwùjọ. (1 Tẹs. 3:1-3; 5:11, 14) Tẹ́ ẹ bá jọ wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lóde ẹ̀rí, ẹ máa lo àǹfààní yẹn láti gbé ara yín ró. Ẹ sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí tẹ́ ẹ jọ ń jẹun. w16.09 1:13, 14
Sunday, October 14
Ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 10:31.
Ó yẹ ká múra lọ́nà táá fògo fún Ọlọ́run mímọ́ tá à ń sìn, lọ́nà táá buyì kún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, táá sì fi ìgbatẹnirò hàn sáwọn tá à ń wàásù fún. (Róòmù 13:8-10) Ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa múra lọ́nà tó bójú mu pàápàá nígbà tá a bá ń lọ́wọ́ nínú ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà, irú bí ìgbà tá a bá ń lọ sípàdé tàbí tá à ń lọ sóde ẹ̀rí. A gbọ́dọ̀ múra ‘lọ́nà tí ó yẹ àwọn tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.’ (1 Tím. 2:10) Òótọ́ kan ni pé aṣọ tó bójú mu níbì kan lè má bójú mu níbòmíì. Torí náà, àwa èèyàn Jèhófà máa ń wo ohun tó bá àṣà ìbílẹ̀ ibi tá a wà mu, ká má bàa múra lọ́nà tó máa kọ àwọn èèyàn lóminú. Nígbà tá a bá ń lọ sí àpéjọ, a gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó bójú mu, tó sì yẹ ọmọlúàbí. Kò yẹ ká wọ àwọn aṣọ tó fún mọ́ra pinpin tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀ irú èyí táyé ń gbé lárugẹ lónìí. Tá a bá múra dáadáa, á yá wa lára láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àá sì lè wàásù nígbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ. w16.09 3:7, 8
Monday, October 15
Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.—Héb. 3:4.
Tó ò bá mọ bó o ṣe máa ṣàlàyé fáwọn èèyàn pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò tọ̀nà, á dáa kó o lo àfiwé tí Pọ́ọ̀lù lò. O tún lè lo àwọn ọ̀nà yìí tó bá jẹ́ pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀ sọ pé òun ò gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ní kó sọ ohun tó gbà gbọ́ gan-an àtohun tó nífẹ̀ẹ́ sí. (Òwe 18:13) Tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì, jẹ́ kó mọ̀ pé Bíbélì sọ àwọn nǹkan kan tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, ó ṣeé ṣe kíyẹn wú u lórí. Àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣẹ àti pé àwọn ìtàn inú rẹ̀ jóòótọ́ ló máa mú káwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Bákan náà, o lè sọ díẹ̀ lára àwọn ìlànà tó ṣeé mú lò nígbèésí ayé, bí èyí tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè. Àmọ́ o, máa rántí pé kó o lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lo ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, kì í ṣe torí kó o lè jiyàn. Torí náà, máa fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. Máa béèrè àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání, pọ́n àwọn èèyàn náà lé, kó o sì fi pẹ̀lẹ́tù sọ̀rọ̀, pàápàá tó bá jẹ́ àgbàlagbà lò ń bá sọ̀rọ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbà pẹ̀lú rẹ. w16.09 4:14-16
Tuesday, October 16
Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.—Róòmù 15:7.
Ohun kan wà tó o lè ṣe láti mú kára tu àwọn àjèjì tó wà níjọ yín. O lè bi ara rẹ pé: ‘Ká sọ pé ìlú onílùú lèmi náà wà, báwo ni màá ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe sí mi?’ (Mát. 7:12) Máa ṣe sùúrù fún wọn torí pé ara wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọlé ni. Ìwà wọn lè kọ́kọ́ ṣàjèjì sí wa, àmọ́ dípò ká máa retí pé kí wọ́n kọ́ àṣà wa, á dáa ká mọyì àṣà wọn. Tá a bá kà nípa ibi táwọn àjèjì tó wà níjọ wa ti wá àti àṣà wọn, àá túbọ̀ lóye wọn. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa, a lè ṣèwádìí nípa àwọn àjèjì tó wà níjọ wa tàbí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Ohun míì táá jẹ́ ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa ni pé ká ní kí wọ́n wá sílé wa, ká sì jọ jẹun. Torí pé Jèhófà “ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ṣé kò yẹ káwa náà ṣí ilẹ̀kùn wa fáwọn àjèjì tó “bá wa tan nínú ìgbàgbọ́”?—Ìṣe 14:27; Gál. 6:10; Jóòbù 31:32. w16.10 1:15, 16
Wednesday, October 17
Ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ẹni tí ó ti fara da irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—Héb. 12:3.
Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó nígbàgbọ́, ó wá sọ àpẹẹrẹ ẹni tó ta yọ jù lọ, ìyẹn Jésù Kristi Olúwa wa. Hébérù 12:2 sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Kódà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká ‘ronú jinlẹ̀’ dáadáa nípa bí Jésù ṣe lo ìgbàgbọ́ láìka àwọn àdánwò lílekoko tó kójú. Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni míì yàn láti kú dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Lára wọn ni ọmọ ẹ̀yìn náà Áńtípà. (Ìṣí. 2:13) Àwọn Kristẹni yìí láǹfààní láti jíǹde sí ọ̀run. Lóòótọ́, “àjíǹde tí ó sàn jù” ni Bíbélì sọ pé àwọn ẹni ìgbàanì tó nígbàgbọ́ ń retí, síbẹ̀ àjíǹde ti ọ̀run dára jùyẹn lọ. (Héb. 11:35) Lẹ́yìn ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914, Jèhófà jí àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ti kú dìde sí ọ̀run, kí wọ́n lè ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.—Ìṣí. 20:4. w16.10 3:12
Thursday, October 18
Ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ.—Héb. 3:13.
Àwọn òbí kan kì í gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn torí pé àwọn òbí tiwọn náà ò fìgbà kan gbóríyìn fún wọn. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí láàárín àwọn òṣìṣẹ́, débi pé àwọn òṣìṣẹ́ kan tiẹ̀ ń ráhùn pé àwọn ọ̀gá kì í rí tiwọn rò, ká má tíì sọ pé wọ́n á yìn wọ́n. Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dáa, tá a sì gbóríyìn fún un, à ń fún un níṣìírí nìyẹn. A lè fún àwọn míì níṣìírí tá a bá ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní, a sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń tu àwọn tó soríkọ́ nínú. (1 Tẹs. 5:14) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘gbà níyànjú’ túmọ̀ sí “fífa ẹnì kan mọ́ra.” Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa ń láǹfààní láti sọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn. (Oníw. 4:9, 10) Ṣó o máa ń wá àkókò tó dáa láti jẹ́ káwọn míì mọ ìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ wọn àti ìdí tó o fi mọyì wọn? Kó o tó dáhùn ìbéèrè yìí, á dáa kó o ronú lórí òwe kan tó sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o!’—Òwe 15:23. w16.11 1:3-5
Friday, October 19
Wòó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!—Sm. 133:1.
Nígbà tí Jèhófà ń sọ bí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe máa wà níṣọ̀kan lọ́jọ́ iwájú, Ó sọ pé: “Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran.” (Míkà 2:12) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún lo wòlíì Sefanáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara [ìyẹn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run], kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sef. 3:9) Inú wa mà dùn o, pé a láǹfààní láti máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan! Ó ṣe kedere pé ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ran àwọn ará Kọ́ríńtì àtàwọn míì lọ́wọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n fi sílò mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan, kí àlàáfíà wà, kí ìjọ sì wà ní mímọ́. (1 Kọ́r. 1:10; Éfé. 4:11-13; 1 Pét. 3:8) Torí pé àwọn tó ń wàásù wà níṣọ̀kan, ohun tí Olórun ní lọ́kàn fún ìran ènìyàn ti di èyi tí a ti tàn kálè kárí ayé. w16.11 2:16, 18
Saturday, October 20
Ẹ̀yin jẹ́ . . . “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá” ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn.—1 Pét. 2:9.
Ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn èèyàn ṣì ń rí Bíbélì kà lédè Gíríìkì tàbí Látìn. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ táwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Nígbà tí wọ́n bá sì ti lóye ohun tí Bíbélì sọ, ṣe ni wọ́n máa ń pa ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tì. Àmọ́ o, ẹ̀mí wọn lè lọ sí i tí wọ́n bá gbìyànjú láti kọ́ àwọn míì lóhun tí Bíbélì sọ. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ sọ èdè Gíríìkì àti Látìn mọ́, torí náà wọn ò lè ka Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ṣọ́ọ̀ṣì ò gbà kí wọ́n túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè táwọn èèyàn ń sọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn àlùfáà àtàwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ló lè ka Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé púrúǹtù làwọn kan lára àwọn àlùfáà náà. Bí ṣọ́ọ̀ṣì bá sì gbọ́ pé ẹnì kan ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, onítọ̀hún wọ gàù nìyẹn, wọ́n á sì fimú rẹ̀ dánrin. Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń dá ọgbọ́n kí wọ́n lè jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni àmì òróró tí Bíbélì pè ní “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” wá dà bíi tàwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò ṣeé ṣe fún wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó wà létòletò. Ó mà ṣé o, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ sínú akóló Bábílónì Ńlá! w16.11 4:8, 10, 11
Sunday, October 21
Àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 6:9.
A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má di pé a mọ̀ọ́mọ̀ ń lọ́wọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, irú èyí táwọn ará kan ní Kọ́ríńtì dá kí wọ́n tó di Kristẹni. Ó ṣe pàtàkì ká fi ìmọ̀ràn yìí sílò tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la ti tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, tá ò sì fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ ‘jẹ ọ̀gá lórí wa.’ Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ṣe pàtàkì ká bi ara wa pé, ṣé mo ti pinnu pé màá jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà” kí n sì sa gbogbo ipá mí láti yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan kà sí ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké? (Róòmù 6:14, 17) Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó dá wa lójú pé Pọ́ọ̀lù ò lọ́wọ́ sí irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo tá a mẹ́nu bà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9-11. Síbẹ̀, ó jẹ́wọ́ pé òun máa ń ṣẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí ohun tí mo ń ṣe ni èmi kò mọ̀. Nítorí ohun tí mo ń fẹ́, èyí ni èmi kò fi ṣe ìwà hù; ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni èmi ńṣe.” (Róòmù 7:14, 15) Èyí fi hàn pé àwọn nǹkan míì wà tí Pọ́ọ̀lù kà sí ẹ̀ṣẹ̀, tó sì ń tiraka láti jáwọ́ nínú rẹ̀. (Róòmù 7:21-23) Ẹ jẹ́ káwa náà ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, ká pinnu láti jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà.” w16.12 1:15, 16
Monday, October 22
Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà . . . yóò sì gbé ọ ró.—Sm. 55:22.
Tí nǹkan bá tojú sú ẹ, tọ́kàn rẹ ò balẹ̀ tàbí tí àníyàn fẹ́ bò ẹ́ mọ́lẹ̀, sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà Baba rẹ ọ̀run. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro kan, á dáa kó o gbàdúrà àtọkànwá torí ìyẹn á ṣe ẹ́ láǹfààní ju kó o máa ṣàníyàn lọ. (Sm. 94:18, 19) Bó ṣe wà nínú Fílípì 4:6, 7 tá a bá ń gbàdúrà tọkàntọkàn, tá ò sì jẹ́ kó sú wa, Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa. Báwo ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa ń mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀, kára sì tù wá. Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Dípò tí wọn ì bá fi máa ṣàníyàn, ṣe ni Ọlọ́run mú kí ọkàn wọn balẹ̀, tí ara sì tù wọ́n pẹ̀sẹ̀ lọ́nà tó yani lẹ́nu. Ó lè rí bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà, torí pé, “àlàáfíà Ọlọ́run” á jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè yọjú. Jẹ́ kí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, pé: “Má wò yí ká, [tàbí ṣàníyàn] nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”—Aísá. 41:10. w16.12 3:3, 4
Tuesday, October 23
Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò.— Héb. 11:24.
Mósè náà kọ gbogbo ìṣura Íjíbítì sílẹ̀, “ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” (Héb. 11:25, 26) Ó yẹ káwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn adúrósinsin tó jẹ́ olódodo yìí, bíi Mósè, nípa lílo ẹ̀bùn òmìnira tá a ní láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lóòótọ́ ó lè rọ̀ wá lọ́rùn tí ẹlòmíì bá ṣèpinnu fún wa, àmọ́ ìyẹn ò ní jẹ́ ká rí ìbùkún téèyàn máa ń ní téèyàn bá fúnra rẹ̀ ṣèpinnu. Diutarónómì 30:19, 20 jẹ́ ká mọ ìbùkún téèyàn máa rí. Ní ẹsẹ 19, Ọlọ́run ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì yan ohun tí wọ́n máa ṣe. Ní ẹsẹ 20, Jèhófà fún wọn láǹfààní láti fi ohun tó wà lọ́kàn wọn hàn. Àwa náà lè yàn láti jọ́sìn Jèhófà. Ìdí pàtàkì tá a fi fẹ́ máa lo òmìnira wa lọ́nà tó tọ́ ni pé a fẹ́ fògo fún Jèhófà, a sì fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. w17.01 2:10, 11
Wednesday, October 24
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere . . . kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.—Sm. 37:3.
Jèhófà fẹ́ ká lo àwọn ẹ̀bùn tó fi jíǹkí wa bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ̀ pé inú wa máa dùn gan-an tá a bá ń lo àwọn ẹ̀bùn náà bó ṣe tọ́. Síbẹ̀, Jèhófà mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tá ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò sóhun tá a lè ṣe tá a fi lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ikú àti àìpé tá a jogún. Yàtọ̀ síyẹn, a ò lè darí ìgbésí ayé àwọn míì, torí pé gbogbo wa la lómìnira láti ṣe ohun tá a fẹ́. (1 Ọba 8:46) Bákan náà, bó ti wù ká gbọ́n tó tàbí ká nírìírí tó, ìkókó la ṣì jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Aísá. 55:9) Ipò yòówù ká wà, ó yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, ká gbà pé á ràn wá lọ́wọ́ àti pé á bá wa ṣe ohun tá ò lè dá ṣe. Síbẹ̀, ó yẹ káwa náà sapá, ká ṣe ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro tá a bá ní, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́. Lédè míì, ó yẹ ká ‘gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì máa ṣe rere’ àti pé ó yẹ ká “máa fi ìṣòtítọ́ báni lò.” w17.01 1:2-4
Thursday, October 25
Ìwọ alára bá mi sọdá, dájúdájú, èmi yóò sì pèsè oúnjẹ fún ọ lọ́dọ̀ mi ní Jerúsálẹ́mù.—2 Sám. 19:33.
Básíláì tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún yìí ò gbà láti gbé láàfin. Kí nìdí? Àgbàlagbà ni, torí náà ó sọ fún Dáfídì pé òun ò fẹ́ dẹ́rù pa á. Ìdí nìyẹn tí Básíláì fi ní kí Dáfídì mú Kímúhámù tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ dípò òun. (2 Sám. 19:31-37) Torí pé Básíláì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Lóòótọ́ kò gbà láti gbé láàfin, àmọ́ kì í ṣe torí pé kò ní lè ṣe iṣẹ́ yẹn tàbí torí pé kò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni yọ òun lẹ́nu ní báyìí tóun ti dàgbà. Ó gbà pé nǹkan ò rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ àti pé ó níbi tágbára òun mọ. Kò fẹ́ ṣe ju ohun tágbára rẹ̀ gbé lọ. (Gál. 6:4, 5) Tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa dé ipò iwájú tàbí bá a ṣe máa gbayì ló gbà wá lọ́kàn, wẹ́rẹ́ báyìí ni ìgbéraga á wọ̀ wá lẹ́wù, àá sì máa figagbága pẹ̀lú àwọn míì. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ wa lè má tẹ ohun tá à ń lé. (Gál. 5:26) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí ìmọ̀wọ̀n ara ẹni ló máa jẹ́ kí gbogbo wa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bá a ṣe ń lo àwọn ẹ̀bùn wa àti okun wa láti bọlá fún Ọlọ́run ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́.—1 Kọ́r. 10:31. w17.01 4:5, 6
Friday, October 26
Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.—Jẹ́n. 1:31.
Àwọn nǹkan àgbàyanu ni Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa dá. Gbogbo nǹkan tó dá ni ò láfiwé. (Jer. 10:12) Ó ṣe kedere pé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá ló ní ààlà ibi tí wọ́n lè dé. Báwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí ṣe lófin tí wọ́n ń tẹ̀ lé bẹ́ẹ̀ làwọn ohun abẹ̀mí náà lófin tí wọ́n ń tẹ̀ lé kí gbogbo nǹkan lè máa lọ létòletò. (Sm. 19:7-9) Torí náà, gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá láyé àti lọ́run ló ní àyè tiẹ̀, wọ́n sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ dá wọn. Jèhófà fi àwọn ìlànà kan lélẹ̀ táwọn nǹkan tó dá gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, agbára òòfà ló jẹ́ kí òfuurufú wà níbi tó wà látọjọ́ yìí, òun náà ló ń darí òkun tó sì ń mú ká máa gbádùn àwọn nǹkan tó wà láyé. Àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ ló ń darí gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá, títí kan àwa èèyàn. Torí náà, báwọn nǹkan ṣe ń lọ létòletò yìí fi hàn pé Jèhófà lóhun kan lọ́kàn tó fi dá ayé yìí àtàwa èèyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá ń wàásù, á dáa ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Ẹni tó ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu yìí.—Ìṣí. 4:11. w17.02 1:4, 5
Saturday, October 27
Mósè . . . ni Ọlọ́run rán Gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso àti olùdáǹdè láti ọwọ́ áńgẹ́lì.—Ìṣe 7:35.
Lẹ́yìn ikú Mósè, áńgẹ́lì kan tí Bíbélì pè ní “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà” fún Jóṣúà lágbára láti ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sójú ogun nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ọmọ Kénáánì jà. (Jóṣ. 5:13-15; 6:2, 21) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọba Hesekáyà kojú àwọn àkòtagìrì ọmọ ogun Ásíríà tí wọ́n wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo, “áńgẹ́lì Jèhófà tẹ̀ síwájú láti jáde lọ, ó sì ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] balẹ̀.” (2 Ọba 19:35) Ohun kan ni pé ẹni pípé làwọn áńgẹ́lì tó ran àwọn ọkùnrin yẹn lọ́wọ́, àmọ́ àwọn ọkùnrin náà kì í ṣe ẹni pípé. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Mósè kò gbógo fún Jèhófà. (Núm. 20:12) Jóṣúà kò wádìí lọ́wọ́ Jèhófà kó tó bá àwọn ará Gíbéónì dá májẹ̀mú. (Jóṣ. 9:14, 15) Ìgbà kan wà tí Hesekáyà gbéra ga. (2 Kíró. 32:25, 26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọkùnrin yẹn, Jèhófà retí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí wọn. Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti máa ran àwọn aṣojú rẹ̀ lọ́wọ́. Ó ṣe kedere pé Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn rẹ̀. w17.02 3:7-9
Sunday, October 28
Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.—Ìṣí. 5:13.
Tá a bá sọ pé a bọlá fún ẹnì kan, ó túmọ̀ sí pé a ka ẹni náà sí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a sì bọ̀wọ̀ fún un. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń bọlá fún àwọn tó ṣe nǹkan àrà ọ̀tọ̀ tàbí àwọn tó wà nípò àṣẹ. Àmọ́ ó yẹ ká bi ara wa pé, ta ló yẹ ká bọlá fún, kí sì nìdí tó fi yẹ ká bọlá fún irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ìwé Ìṣípayá 5:13 sọ pé ó yẹ ká bọlá fún “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Orí kẹrin ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká máa bọlá fún Jèhófà. Àwọn áńgẹ́lì ń pa ohùn wọn pọ̀, wọ́n sì ń yin Jéhófà, “Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé.” Wọ́n ń sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”—Ìṣí. 4:9-11. w17.03 1:1,
Monday, October 29
Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.—Òwe 28:26.
Ọ̀rọ̀ kan wà táwọn èèyàn kan máa ń sọ, wọ́n á ní: Ohun tọ́kàn rẹ bá ti ní kó o ṣe ni kó o ṣe. Àmọ́ ó léwu gan-an tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra ká má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa tàbí bí nǹkan ṣe rí lára wa pinnu ohun tá a máa ṣe. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í dáa téèyàn bá ṣe ohun tí ọkàn rẹ̀ sọ. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé aláìpé ni wá, ọkàn wa sì máa ń “ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jer. 3:17; 13:10; 17:9; 1 Ọba 11:9) Torí náà, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tọ́kàn wa bá ti ní ká ṣe là ń ṣe tí à ń jẹ́ kí bí nǹkan ṣe rí lára wa pinnu ohun tí a máa ṣe? Bí àpẹẹrẹ, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ṣèpinnu nígbà tá a ṣì ń bínú? Ó ṣeé ṣe ká mọ ìdáhùn tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí wa rí. (Òwe 14:17; 29:22) Àbí kẹ̀, ṣó rọrùn kéèyàn ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání lásìkò tó rẹ̀wẹ̀sì? (Núm. 32:6-12; Òwe 24:10) Ó ṣe kedere pé a lè ṣàṣìṣe, tá a bá jẹ́ kí bí nǹkan ṣe rí lára wa pinnu àwọn ohun pàtàkì tá a máa ṣe. w17.03 2:12, 13
Tuesday, October 30
Mo rìn níwájú rẹ nínú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré. —2 Ọba 20:3.
Aláìpé ni wá, torí náà a máa ń ṣàṣìṣe. Àmọ́, a dúpẹ́ pé Jèhófà kì í ṣe sí wa “gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,” pàápàá jù lọ tá a bá ronú pìwà dà, tá a sì bẹ Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé kó wo ọlá ẹbọ ìràpadà Jésù mọ́ wa lára. (Sm. 103:10) Síbẹ̀, bí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì, kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ máa “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré” sìn ín. (1 Kíró. 28:9) Téèyàn bá máa fi “ọkàn-àyà pípé pérépéré” sin Ọlọ́run, ó gba pé kéèyàn sìn ín tọkàntara jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹni. Àpapọ̀ ohun tẹ́nì kan jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún ni Bíbélì sábà máa ń pè ní “ọkàn.” Ìyẹn sì kan ìfẹ́ ọkàn ẹni, ohun téèyàn ń rò, irú ẹni téèyàn jẹ́, ìwà téèyàn ń hù, ohun téèyàn lè ṣe, ohun tó ń mú kéèyàn ṣe nǹkan àti àfojúsùn ẹni. Ẹni tó ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin Jèhófà kì í ṣe ojú ayé. Ìjọsìn rẹ̀ kì í ṣe àfaraṣe-má-fọkàn-ṣe. Àwa ńkọ́? Lóòótọ́ aláìpé ni wá, àmọ́ tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntara láìbọ́hùn, tá ò sì ṣe ojú ayé, a jẹ́ pé ọkàn tó pé pérépéré la fi ń sin Jèhófà.—2 Kíró. 19:9. w17.03 3:1, 3
Wednesday, October 31
[Jèhófà] ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.—Sm. 138:6.
Táwa náà bá ṣàṣeyọrí nínú ohun kan, Jèhófà lè ‘fi wá sílẹ̀ láti dán wa wò,’ ká lè fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan ti lè ṣiṣẹ́ kára láti múra àsọyé tó ní, tó sì wá sọ àsọyé náà ní àpéjọ ńlá. Ká sọ pé ọ̀pọ̀ ló gbóríyìn fún un torí pé wọ́n gbádùn àsọyé náà, kí ni arákùnrin náà máa ṣe bí wọ́n ṣe ń yìn ín? Á dáa ká rántí ọ̀rọ̀ Jésù nígbà táwọn èèyàn bá ń yìn wá, ó ní: “Nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’ ” (Lúùkù 17:10) Ẹ jẹ́ ká máa rántí àpẹẹrẹ Hesekáyà táwọn èèyàn bá ń yìn wá. Ẹ̀mí ìgbéraga ni kò jẹ́ kí Hesekáyà mọyì àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ṣe fún un. (2 Kíró. 32:24-27, 31) Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún wa, a ò ní gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà la máa gbógo fún torí gbogbo ìgbà ló máa ń tì wá léyìn. w17.03 4:12-14