ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 108-118
  • November

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • November
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Thursday, November 1
  • Friday, November 2
  • Saturday, November 3
  • Sunday, November 4
  • Monday, November 5
  • Tuesday, November 6
  • Wednesday, November 7
  • Thursday, November 8
  • Friday, November 9
  • Saturday, November 10
  • Sunday, November 11
  • Monday, November 12
  • Tuesday, November 13
  • Wednesday, November 14
  • Thursday, November 15
  • Friday, November 16
  • Saturday, November 17
  • Sunday, November 18
  • Monday, November 19
  • Tuesday, November 20
  • Wednesday, November 21
  • Thursday, November 22
  • Friday, November 23
  • Saturday, November 24
  • Sunday, November 25
  • Monday, November 26
  • Tuesday, November 27
  • Wednesday, November 28
  • Thursday, November 29
  • Friday, November 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 108-118

November

Thursday, November 1

Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.​—Òwe 27:11.

Sátánì ti sọ pé torí ohun táwa èèyàn ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 2:​4, 5) Ṣé Sátánì ti wá yí èrò tó ní nípa wa pa dà? Rárá o! Nígbà tí wọ́n lé e kúrò lọ́run, ó ṣì ń fẹ̀sùn kan àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́. (Ìṣí. 12:10) Sátánì ṣì ń sọ pé torí ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín. Bá a ṣe máa tako ìṣàkóso Ọlọ́run tá ò sì ní sin Jèhófà mọ́ ló ń wá. Tó o bá ń jìyà nígbà àdánwò, fojú inú wò ó pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ wà lápá kan, wọ́n fẹ́ mọ ohun tó o máa ṣe, wọ́n sì ń lérí pé wàá tó bọ́hùn. Jèhófà, Jésù Kristi Ọba wa, àwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì náà sì wà lápá kejì, wọ́n rí gbogbo bó o ṣe ń tiraka, wọ́n sì ń fún ẹ níṣìírí pé kó o mọ́kàn, wàá borí. Inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí ẹ tó ò ń fara dà á, tó o sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Wá wo ara rẹ bíi pé ìwọ gan-an ni Jèhófà ń bá sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ ìwé ojúmọ́ wa tòní. w16.04 2:​8, 9

Friday, November 2

Mú ẹnì kan tàbí méjì sí i dání pẹ̀lú rẹ.​—Mát. 18:16.

Tọ́rọ̀ náà bá wá yanjú, ó túmọ̀ sí pé o ti “jèrè arákùnrin rẹ” nìyẹn. Tọ́rọ̀ kan ò bá yanjú lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsapá la máa tó lọ sọ fáwọn alàgbà. Kì í sábàá ṣẹlẹ̀ pé ká gbé ìgbésẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà nínú Mátíù 18:​15-17 kọ́rọ̀ tó níyanjú. Ìyẹn sì wúni lórí gan-an torí pé ọ̀rọ̀ ti sábà máa ń yanjú kó tó di pé wọ́n á yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ torí pé kò ronú pìwà dà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó ṣẹ̀ náà á ti rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa, á sì ti ṣàtúnṣe. Ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ náà sì lè rí i pé kò sídìí fóun láti máa wá ẹ̀sùn sí onítọ̀hún lẹ́sẹ̀, kó sì dárí jì í. Èyí ó wù kó jẹ́, ohun tí Jésù sọ fi hàn pé kò yẹ káwọn alàgbà máa dá sí ọ̀rọ̀ tí ò tíì yẹ kí wọ́n dá sí. Tọ́rọ̀ náà ò bá lójútùú lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ẹ̀rí tó ṣe gúnmọ́ sì wà pé nǹkan ọ̀hún ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ làwọn alàgbà tó lè dá sí i. w16.05 1:​15, 16

Saturday, November 3

Wọn kì í ṣe apá kan ayé. ​—Jòh. 17:16.

A ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun torí pé Ìjọba Ọlọ́run là ń fojú sọ́nà fún. Torí pé a kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, a ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ẹnu wa sì gbà á láti sọ fáwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro èèyàn. Ìsìn èké ń dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, èyí sì máa ń fa ìyapa láàárín àwọn èèyàn. Àmọ́ torí pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun, a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé. (1 Pét. 2:17) Àmọ́ bí òpin ètò Sátánì yìí ṣe ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ láá túbọ̀ máa ṣòro fún wa láti wà láìdá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Lónìí, ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn ti di “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan” àti “olùwarùnkì,” wọ́n á sì túbọ̀ máa yapa sí i. (2 Tím. 3:​3, 4) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, nǹkan ti yí pa dà lágbo òṣèlú, torí náà wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn ará wa pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí òṣèlú àti ogun. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká pinnu báyìí pé a ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun kódà tí wọ́n bá fipá mú wa láti lọ́wọ́ sí i. w16.04 4:​3, 4

Sunday, November 4

Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.​—Gál. 6:7.

Àwọn kan lè máa ronú pé ohun tó bá ṣáà ti wu àwọn làwọn lè ṣe. Àmọ́, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu táá sì múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ fi àwọn òfin àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì sọ́kàn ká sì tẹ̀ lé wọn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ rójú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ pa òfin rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ mọ́. (Jẹ́n. 9:4; Ìṣe 15:​28, 29) Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, á ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe ìpinnu tó bá ìlànà àti òfin inú Ìwé Mímọ́ mu. A lè ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan tó lè nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Awọn ìpinnu tá à ń ṣe lè ní ipa rere tàbí búburú lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Tá a bá ṣe ìpinnu tó dáa, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ lágbára, àmọ́ tá a bá ṣe èyí tí kò dára, á ba àjọṣe náà jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìpinnu tí kò dára lè mú àwọn míì kọsẹ̀, ó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì lè ba ìṣọ̀kan ìjọ jẹ́. Torí náà, àwọn ìpinnu tá a bá ṣe máa nípa lórí àwa fúnra wa àtàwọn míì.​—Róòmù 14:19. w16.05 3:​4, 5

Monday, November 5

Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.​— Aísá. 48:17.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo bá a ṣe ń sapá láti máa wáyè ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. (Éfé. 5:​15, 16) Ká sòótọ́, a lè má ráyè ka gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde wa bá a ṣe fẹ́. Síbẹ̀, nǹkan kan wà tó yẹ ká ṣọ́ra fún. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tọ́rọ̀ inú ẹ̀ ò kàn wá, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tó yẹ ká rí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe wá bíi pé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ò bá ipò wa mu. Tó bá sì jẹ́ pé àwa kọ́ ni wọ́n dìídì ṣe àwọn ìtẹ̀jáde kan fún ńkọ́? Ṣé a kàn máa ń fojú wo irú ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ gààràgà tàbí ṣe la kàn máa ń tọ́jú ẹ̀ láìkà? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń pàdánù àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó wúlò fún wa gan-an. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi sọ́kàn pé Ọlọ́run ni Orísun gbogbo àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà. w16.05 5:​5, 6

Tuesday, November 6

Bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.​—Gál. 6:1.

Jèhófà máa ń lo ìjọ Kristẹni àtàwọn alábòójútó láti mọ wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kàn. Bí àpẹẹrẹ, táwọn alàgbà bá kíyè sí i pé à ń jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, wọn kì í lo ọgbọ́n ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé onírẹ̀lẹ̀ ni wọ́n, Ọlọ́run ni wọ́n máa ń bẹ̀ pé kó fún àwọn ní ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n. Wọ́n máa ń ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, wọ́n á gbàdúrà nípa rẹ̀, wọ́n á sì tún ṣèwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Ìwádìí yìí á jẹ́ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe yẹ. Ní báyìí tá a ti mọ bí Ọlọ́run ṣe ń mọ wá, á jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará, á tún jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa títí kan àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọlọ́run kì í mú ẹnikẹ́ni ní ọ̀ranyàn pé kó yí pa dà, ṣe ló máa kọ́ onítọ̀hún láwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Bí onítọ̀hún bá sì fẹ́, á ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. w16.06 1:​13, 14

Wednesday, November 7

Ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́. ​—Jer. 45:5.

Àpọ́sítélì Jòhánù náà fún wa nírú ìkìlọ̀ yìí nígbà tó sọ pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó wà nínú ayé. Lára wọn ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Ó sọ pé téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan yìí, “ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.” (1 Jòh. 2:​15, 16) Èyí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò lóòrèkóòrè ká lè mọ̀ bóyá a ti ń nífẹ̀ẹ́ àwọn eré ìnàjú tí ayé ń gbé lárugẹ, bóyá a ti ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, títí kan àwọn aṣọkáṣọ àti ìwọ̀kuwọ̀ tó wọ́pọ̀ lóde òní. Ọ̀nà míì téèyàn tún lè gbà nífẹ̀ẹ́ ohun tó wà nínú ayé ni pé kéèyàn máa lépa àtilọ yunifásítì kó bàa lè ní “àwọn ohun ńláńlá.” Ní báyìí, a ti wà ní bèbè àtiwọ ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká fi ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ sọ́kàn. Tá a bá gbà pé “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni,” a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé òun nìkan là ń sìn, a sì ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́.​—Héb. 12:​28, 29. w16.06 3:14

Thursday, November 8

Ẹ máa wá Ìjọba [Ọlọ́run] nígbà gbogbo, a ó sì fi nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín.​—Lúùkù 12:31.

Àwọn ohun tí ẹ̀dá nílò kò pọ̀, àwọn ohun tó wu ẹ̀dá ni ò lópin. Ó jọ pé ọ̀pọ̀ ò mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn nǹkan tó wù wọ́n àtàwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn? Àwọn ohun tá a “nílò” ni àwọn nǹkan kòṣeémáàní tá a gbọ́dọ̀ ní nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, a nílò oúnjẹ, aṣọ àti ilé. Àwọn nǹkan tó “wù” wá làwọn nǹkan tá a kàn fẹ́, àmọ́ tí kò pọn dandan pé ká ní wọn. Ohun táwọn èèyàn fẹ́ máa ń yàtọ̀ síra, ibi táwọn èèyàn ń gbé ló sì máa ń pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. Ní àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ohun táwọn èèyàn fẹ́ lè máà kọjá owó tí wọ́n fẹ́ fi ra fóònù, ọ̀kadà tàbí ilẹ̀ tí wọ́n lè fi kọ́lé. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, ó lè jẹ́ pé aṣọ olówó gọbọi ni wọ́n máa fẹ́ rà kún inú kọ́ńbọ́ọ̀dù wọn, wọ́n lè fẹ́ ilé tó tóbi ju èyí tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ lọ tàbí mọ́tò bọ̀gìnnì. Àmọ́, láìka ibi tá à ń gbé sí tàbí bá a ṣe lówó lọ́wọ́ tó, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá bá a ṣe máa kó àwọn nǹkan jọ, yálà a nílò wọn tàbí a ò nílò wọn, tàbí kẹ̀ bóyá agbára wa ká wọn tàbí agbára wa ò ká wọn.​—Héb. 13:5. w16.07 1:​1-3

Friday, November 9

Ẹ má sì máa wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.​—Róòmù 13:14.

Kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé tọ́pọ̀ ń lé kiri kò jẹ́ kí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí” jẹ wọ́n lọ́kàn mọ́. (Mát. 5:3) Bí wọ́n á ṣe kó nǹkan jọ ni wọ́n ń wá, èyí sì máa ń mú kí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” jọba lọ́kàn wọn. (1 Jòh. 2:16) Ká má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ayé máa darí wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run ni ká jẹ́ kó máa darí wa. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú ká lóye àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (1 Kọ́r. 2:12) Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé kò dìgbà tí nǹkan ńlá bá dojú kọ wá ká tó sùn nípa tẹ̀mí, tá ò bá ṣọ́ra àwọn nǹkan kéékèèké pàápàá lè mú ká sùn nípa tẹ̀mí. (Lúùkù 21:​34, 35) Àwọn míì tiẹ̀ lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń ṣọ́nà, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kíyẹn mú ká dẹra nù. (2 Pét. 3:​3-7) Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a gbọ́dọ̀ máa pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn ará láwọn ìpàdé ìjọ. w16.07 2:​13, 14

Saturday, November 10

Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá. . . . Ní ti àwọn ìrélànàkọjá wa, ìwọ tìkára rẹ yóò bò wọ́n.​—Sm. 65:​2, 3.

Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń gbàdúrà ni pé kí ara lè tù wọ́n, wọn ò gbà pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà. Ó yẹ kírú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.” (Jòh. 14:14) Ó ṣe kedere pé àwọn ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ohunkóhun.” Jòhánù mú kó dá wa lójú pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tíì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòh. 5:14) Inú wa máa ń dùn láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àdúrà kì í wulẹ̀ ṣe oògùn atura, kàkà bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àwa èèyàn lásánlàsàn lè dúró níwájú “ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Jèhófà! (Héb. 4:16) Ẹ jẹ́ ká kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà lọ́nà tó tọ́, sí Ẹni tó tọ́ àti fún ohun tó tọ́. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà, wọ́n á sì rí ìtùnú gbà nígbà ìṣòro.​—Sm. 4:1; 145:18. w16.07 4:​11, 12

Sunday, November 11

Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò máa fi ìbùkún fún ọ. Wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ, wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ, Láti sọ . . . fún àwọn ọmọ ènìyàn [nípa] ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀. ​—Sm. 145:​10-12.

Ó dájú pé irú èrò yìí ni gbogbo àwọn tó ń fọkàn sin Jèhófà náà ní. Àmọ́ tí àìlera tàbí ara tó ń dara àgbà kò bá jẹ́ kó o lè wàásù tó bó o ṣe fẹ́ ńkọ́? Máa rántí pé bó o ṣe ń wàásù fáwọn dókítà àtàwọn míì tó ń tọ́jú ẹ, ṣe nìwọ náà ń fògo fún Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ torí ohun tó o gbà gbọ́ ni wọ́n ṣe fi ẹ́ sẹ́wọ̀n, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà máa wàásù fáwọn tẹ́ ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n nígbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń múnú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Inú Jèhófà sì máa ń dùn tẹ́nì kan bá ń sìn ín láìka pé àwọn tó kù nínú ìdílé rẹ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 3:​1-4) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, o lè fi kún ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run kódà tí nǹkan ò bá rọrùn fún ẹ pàápàá. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ẹ tó o bá ń sapá láti fi kún ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. w16.08 3:​19, 20

Monday, November 12

Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ. ​—Éfé. 5:​22, 23.

Èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ń bu àwọn obìnrin kù o, kàkà bẹ́ẹ̀ ìlànà yìí máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láṣeyanjú. Ọlọ́run mẹ́nu kan iṣẹ́ yìí nígbà tó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà [Ádámù] máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́n. 2:18) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n máa fìfẹ́ lo ipò orí wọn bí Kristi tó jẹ́ “orí ìjọ” ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ìjọ. Tí ọkọ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ìyàwó rẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un, á máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, á sì máa tì í lẹ́yìn. Tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa bí Jésù náà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 13:​34, 35; 15:​12, 13; Éfé. 5:25) Ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn tọkọtaya Kristẹni gbọ́dọ̀ lágbára débi pé wọ́n á ṣe tán láti kú fún ara wọn tó bá gbà bẹ́ẹ̀. w16.08 2:​3, 4

Tuesday, November 13

Ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!​—Òwe 15:23.

Tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìwúrí fáwọn èèyàn, wọ́n á lè máa ṣe dáadáa. Ọ̀rọ̀ wa lè mú kí wọ́n túbọ̀ fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Ká má sì gbàgbé pé bá a ṣe ń nawọ́ nípàdé tá a sì ń dáhùn lọ́nà tó ń gbéni ró, à ń fún àwọn ará wa níṣìírí. Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, Nehemáyà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ rí okun gbà láti ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ọjọ́ méjìléláàádọ́ta [52] péré ni wọ́n fi parí mímọ ògiri Jerúsálẹ́mù! (Neh. 2:18; 6:​15, 16) Kì í ṣe pé Nehemáyà kàn ń darí àwọn tó ń kọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù, òun náà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. (Neh. 5:16) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí láàárín àwa èèyàn Jèhófà lónìí, àwọn alàgbà máa ń ṣe bíi ti Nehemáyà, wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò, wọ́n sì máa ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń lò ṣe. Bí àwọn alàgbà ṣe ń bá àwọn akéde ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tí wọ́n sì ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fún àwọn ará lókun.​— Aísá. 35:​3, 4. w16.09 1:​15, 16

Wednesday, November 14

Ìfẹ́ kì í . . . hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.​—1 Kọ́r. 13:​4, 5.

Àwa èèyàn Jèhófà ń sapá láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.” (Kól. 3:​2, 5) A ò ní fẹ́ ṣe ohun táá mú kó ṣòro fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Ìdí sì ni pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ oníṣekúṣe ṣì lè máa bá èròkerò jà lọ́kàn wọn. (1 Kọ́r. 6:​9, 10) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun táá mú kí ọkàn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tún máa fà sí ìṣekúṣe. Nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ó yẹ ká múra lọ́nà tó bójú mu, tí ọkàn wọn kò sì ní máa fà sí ìṣekúṣe. Òótọ́ ni pé gbogbo wa la lómìnira láti wọ ohun tó wù wá, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ múra lọ́nà táá mú kó rọrùn fáwọn ará wa láti jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. A ò gbọ́dọ̀ múra lọ́nà táá mú kí wọ́n máa ro èròkerò tàbí kí wọ́n máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ tàbí hùwàkiwà.​—1 Pét. 1:​15,16. w16.09 3:​9, 10

Thursday, November 15

Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú . . . Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà.​—Sm. 148:​12, 13.

Tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Kéèyàn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà kò ní káwọn ọmọ náà gba Jèhófà gbọ́,” Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ogún téèyàn ń fi lé ọmọ lọ́wọ́. Báwọn ọmọ ṣe ń dàgbà ni wọ́n ń nígbàgbọ́.” Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Iṣẹ́ ńlá làwa òbí ní láti mú káwọn ọmọ wa nígbàgbọ́, mo gbà pé iṣẹ́ yìí ló nira jù lára iṣẹ́ wa. . . . A lè dáhùn ìbéèrè wọn tán kínú wọn sì dùn, síbẹ̀ wọ́n tún lè béèrè ọ̀rọ̀ kan náà nígbà míì! Èsì tó o fún ọmọ kan lónìí tó tẹ́ ẹ lọ́rùn lè má fi bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn nígbà míì. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé àwọn ọ̀rọ̀ kan lè jẹ yọ lọ́pọ̀ ìgbà.” Tó o bá ti bímọ, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ yanjú, kí wọ́n sì nígbàgbọ́? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò lè dá a ṣe! (Jer. 10:23) Àmọ́, tá a bá gbára lé Jèhófà, àá ṣàṣeyọrí. w16.09 5:​1, 2

Friday, November 16

Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún.​—Òwe 3:27.

Òótọ́ kan ni pé á dáa káwọn tó jẹ́ àjèjì ṣe gbogbo ohun tí àwọn náà lè ṣe kára wọn lè mọlé. Wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rúùtù. Lákọ̀ọ́kọ́, Rúùtù ò fojú pa àṣà ilẹ̀ tó wà rẹ́ torí pé ó tọrọ àyè kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́. (Rúùtù 2:7) Kò ronú pé òun ṣáà lẹ́tọ̀ọ́ láti pèéṣẹ́, kó wá wọnú oko olóko láìgbàṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún dúpẹ́ fún inú rere tí wọ́n fi hàn sí i. (Rúùtù 2:13) Táwọn àjèjì náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á túbọ̀ níyì lójú àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àtàwọn ará ìlú. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ṣojúure sí onírúurú èèyàn, ó sì ń mú kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí dara pọ̀ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà nílùú wọn. Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ wa, ṣé kò ní dáa ká ṣe ohun táá jẹ́ kára tù wọ́n? w16.10 1:​17-19

Saturday, November 17

Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró.​—Héb. 12:2.

Ẹgbàágbèje àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọn ò gbàgbé ìlérí Ọlọ́run, wọn ò sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn yingin bí wọ́n tiẹ̀ ń kojú àdánwò. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Rudolf Graichen, tí wọ́n bí nílẹ̀ Jámánì lọ́dún 1925. Ó rántí pé àwọn àwòrán ìtàn inú Bíbélì kan wà tí wọ́n gbé kọ́ sára ògiri ilé wọn. Ó wá sọ pé: “Àwòrán kan fi ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ọmọ ewúrẹ́ àti àmọ̀tẹ́kùn, ọmọ màlúù àti kìnnìún hàn​—tí gbogbo wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, tí ọmọdékùnrin kékeré kan sì ń dà wọ́n. . . . Irú àwòrán bẹ́ẹ̀ ṣì wà lọ́kàn mi títí di òní olónìí.” (Aísá. 11:​6-9) Àwọn àwòrán yẹn mú kó máa ronú nípa Párádísè, ó sì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun láìka inúnibíni tó dojú kọ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo ti ìjọba Násì kọ́kọ́ fojú Rudolf rí màbo, lẹ́yìn náà àwọn ọlọ́pàá Stasi náà tún pọ́n ọn lójú, ìyẹn lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ti orílẹ̀-èdè East Germany, síbẹ̀ Rudolf dúró gbọin. Ohun tójú Arákùnrin Rudolf rí kò tán síbẹ̀. Inú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück ni àìsàn ibà jẹ̀funjẹ̀fun ti pa màmá rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìṣòro mú kí bàbá rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì débi tó fi bọ́hùn, tó sì fọwọ́ síwèé pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. w16.10 3:​12-14

Sunday, November 18

Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, . . . ẹ tẹ́wọ́ gbà á, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. ​—1 Tẹs. 2:13.

Ọwọ́ pàtàkì làwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń mú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí pé a jẹ́ aláìpé, kò sẹ́ni tí wọn ò lè fún ní ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Tí wọ́n bá fún wa ní ìmọ̀ràn, kí la máa ṣe? Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni méjì tó ń jẹ́ Yúódíà àti Síńtíkè ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Èdèkòyédè wáyé láàárín àwọn obìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró yìí. Ó ṣeé ṣe kí èdèkòyédè tó wáyé láàárín wọn fa ìyapa nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà já sí fún wa, ó ṣeé ṣe káwọn arábìnrin yìí fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò. (Fílí. 4:​2, 3) Lónìí, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ. Àmọ́ tá a bá fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, irú èdèkòyédè yìí lè má ṣẹlẹ̀. Tírú ẹ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, àá tètè yanjú rẹ̀ kó tó di wàhálà. Tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àá máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú rẹ̀.​—Sm. 27:11. w16.11 3:​1-3

Monday, November 19

Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.​—Òwe 24:10.

Gbogbo wa la nílò ìṣírí, pàápàá jù lọ nígbà tá a wà lọ́mọdé. Olùkọ́ kan tó ń jẹ́ Timothy Evans sọ pé: ‘Bí àwọn ewéko ṣe nílò omi, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ nílò ìṣírí. Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn ọmọ, inú wọn máa dùn, á sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a ka àwọn kún.’ Àmọ́ àwọn àkókò tó nira gan-an là ń gbé báyìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́. Torí náà, ọ̀pọ̀ kì í sábà gbóríyìn fúnni mọ́. (2 Tím. 3:​1-5) Sátánì Èṣù máa ń fẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì torí ó mọ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Sátánì mú kí onírúurú àjálù dé bá Jóòbù, ó sì tún fi ẹ̀sùn èké kàn án kí Jóòbù lè rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. (Jóòbù 2:3; 22:3; 27:5) Táwa náà bá ń fún àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé níṣìírí, tá a sì ń gbóríyìn fáwọn tó wà nínú ìjọ, Èṣù ò ní rọ́wọ́ mú. Èyí máa mú kí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà nínú ìdílé àti nínú ìjọ. w16.11 1:​4, 6

Tuesday, November 20

[Ọlọ́run] pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.​—1 Pét. 2:9.

Àwọn ọkùnrin mélòó kan fi ìgboyà túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè táwọn èèyàn ń sọ láàárín ọdún 1501 sí 1540. Bíbélì dé ọwọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kà á dáadáa. Bí wọ́n ṣe ń kà á, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń béèrè pé: ‘Ibo ni pọ́gátórì wà nínú Bíbélì? Ṣé Bíbélì ló ní kéèyàn máa sanwó fún àlùfáà kéèyàn tó sìnkú? Ṣé inú Bíbélì náà ni wọ́n ti rí póòpù àtàwọn kádínà?’ Àrífín gbáà làwọn aṣáájú ìsìn ka gbogbo ìyẹn sí. Wọ́n ní ta ni ń jẹun tájá ń jùrù! Bó ṣe di pé wọ́n tutọ́ sókè nìyẹn tí wọ́n sì fojú gbà á. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kan àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí pé wọn ò gba ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́ mọ́. Tí ṣọ́ọ̀ṣì bá dájọ́ ikú fẹ́ni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn, ìjọba á mú onítọ̀hún wọ́n á sì pa á. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn máa ka Bíbélì, wọn ò sì fẹ́ kí wọ́n máa ṣe ọ̀fíntótó ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Wọ́n ṣàṣeyọrí déwọ̀n àyè kan. Síbẹ̀, àwọn onígboyà kan wà tí wọn ò jẹ́ kí Bábílónì Ńlá kó jìnnìjìnnì bo àwọn. Wọ́n ti tọ́ adùn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò, wọn ò sì fẹ́ kẹ́nì kan dí wọn lọ́wọ́ àtimáa jadùn ẹ̀ nìṣó! w16.11 4:13

Wednesday, November 21

Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ kì yóò purọ́.​—Òwe 14:5.

Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. (Éfé. 4:25) Sátánì ni “baba irọ́,” Ananíà àti ìyàwó rẹ̀ sì kú torí pé wọ́n parọ́. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ fara wé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, torí náà, a ò ní máa parọ́. (Jòh. 8:44; Ìṣe 5:​1-11) Àmọ́, ti pé ẹnì kan ò parọ́ kò túmọ̀ sí pé ẹni náà jẹ́ olóòótọ́. Tá a bá mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, a máa jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá a bá ńṣe. Kéèyàn parọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́. Kì í ṣe irọ́ pípa nìkan ni Jèhófà fẹ́ ká yẹra fún, àmọ́ ó fẹ́ ká yẹra fún gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà àìṣòótọ́. Ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.” Ó wá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n á fi jẹ́ mímọ́. Ó ní: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ jalè, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ tanni jẹ, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣèké, ẹnikẹ́ni sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.” (Léf. 19:​2, 11) Ó ṣeni láàánú pé ẹnì kan ti lè pinnu pé òun ò ní parọ́ mọ́, síbẹ̀ kó máa tan àwọn míì jẹ. w16.12 1:​17, 18

Thursday, November 22

Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.​—Fílí. 4:7.

A tún lè rí ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jésù sọ nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èèyàn sọ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ tù wọ́n nínú gan-an. Àwọn èèyàn máa ń wá sọ́dọ̀ Jésù torí pé ó máa ń tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú, ó ń fáwọn tó ti rẹ̀ lókun, ó sì máa ń gbé àwọn tó ti sọ̀rètí nù ró. (Mát. 11:​28-30) Jésù máa ń gba tàwọn èèyàn rò, títí kan àwọn tó fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn tó ní ìbànújẹ́ ọkàn àtàwọn tí ara ń ni. (Máàkù 6:​30-32) Jésù ṣèlérí pé òun máa tu àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nínú, á sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà. Kò dìgbà tí Jésù bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kó tó lè tù ẹ́ nínú. Ní báyìí tí Jésù ti ń jọba lọ́run, ó ń kíyè sí ẹ, ó sì ń gba tìẹ rò. Torí náà, tó o bá ń ṣàníyàn, á fàánú hàn sí ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní “àkókò tí ó tọ́.” Ó dájú pé Jésù lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro rẹ, á sì mú kó o ní ìgboyà àti ìrètí.​—Héb. 2:​17, 18; 4:16. w16.12 3:​4, 6

Friday, November 23

Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi.​—Jẹ́n. 6:13.

Nígbà ayé Nóà, àwọn èèyàn máa ń hùwà ipá gan-an, wọ́n sì máa ń ṣe ìṣekúṣe. (Jẹ́n. 6:​4, 9-12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà fìtara kéde ìparun tó ń bọ̀, síbẹ̀ kò lè fipá mú àwọn èèyàn burúkú yẹn láti yí pa dà, kò sì lè mú kí Ìkún-omi náà dé ṣáájú ìgbà tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. Ohun tí Nóà lè ṣe ni pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pa àwọn èèyàn burúkú run bó ṣe ṣèlérí, àti pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní àsìkò tó ní lọ́kàn. (Jẹ́n. 6:17) Àwọn èèyàn burúkú ló kúnnú ayé lónìí, a sì mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa pa wọ́n run. (1 Jòh. 2:17) Ohun kan ni pé a ò lè fipá mú àwọn èèyàn pé kí wọ́n yí pa dà lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ‘ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.’ A sì mọ̀ pé kò sóhun tá a lè ṣe láti mú kí “ìpọ́njú ńlá” dé ṣáájú àsìkò tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. (Mát. 24:​14, 21) Bíi ti Nóà, ó ṣe pàtàkì pé káwa náà nígbàgbọ́ tó lágbára, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa tó dá sọ́rọ̀ náà. (Sm. 37:​10, 11) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí ọjọ́ tó ní lọ́kàn láti pa ayé búburú yìí run lé ọjọ́ kan.​—Háb. 2:3. w17.01 1:​5-7

Saturday, November 24

Èmi, Jèhófà, . . . Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. ​—Aísá. 48:17.

Lónìí áwọn èèyàn ń ṣi òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ohun tí ó bá wù wọ́n lò wọ́n sì tún fi ń pa àwọn míì lára. Bí Bíbélì ṣe sọ náà ló rí, pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “aláìlọ́pẹ́.” (2 Tím. 3:​1, 2) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò ṣi òmìnira tá a ní yìí lò. Àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní ṣì í lò? Gbogbo wa la lómìnira láti yan ẹni tá a máa bá ṣọ̀rẹ́, irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti irú eré ìnàjú tá a máa ṣe. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, a lè sọ òmìnira yìí di “bojúbojú fún ìwà búburú.” Ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ wa lọ́rùn la máa ń ṣe tàbí tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé àwọn èèyàn ayé. (1 Pét. 2:16) Dípò tá a fi máa lo òmìnira wa láti ṣe ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ wa lọ́rùn, á dáa ká pinnu pé àá “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”​—Gál. 5:13; 1 Kọ́r. 10:31. w17.01 2:​12-14

Sunday, November 25

Gbàrà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, . . . mo sì ń bá a lọ ní gbígbààwẹ̀ àti ní gbígbàdúrà níwájú Ọlọ́run ọ̀run.​—Neh. 1:4.

Àpẹẹrẹ Nehemáyà jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kò ní máa gbára lé òye rẹ̀ tó bá gba àfikún iṣẹ́ tàbí tí iṣẹ́ rẹ̀ bá yí pa dà nínú ètò Ọlọ́run. Báwo lẹnì kan ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé òye tàbí ìrírí rẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, alàgbà kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í yanjú ọ̀rọ̀ kan nínú ìjọ láì kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà. Àwọn míì sì lè ti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe tán kí wọ́n tó bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìpinnu náà. Ṣé a lè sọ pé àwọn yìí mọ̀wọ̀n ara wọn? Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ̀ pé kò sí bóun ṣe lè gbọ́n tó tóun á gbọ́n tó Jèhófà, kò sì ní kọjá àyè rẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọ́run. Torí náà, tó bá di pé ká bójú tó ohun kan tá a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ máa gbára lé òye tiwa torí pé kì í ṣe agbára wa tàbí ìrírí wa ló ṣe pàtàkì jù. (Òwe 3:​5, 6) Nínú ayé, àwọn èèyàn máa ń wá bí wọ́n á ṣe wà nípò tó ga ju tàwọn míì lọ. Àmọ́ àwa Kristẹni kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ, a kì í ronú pé a dáa ju àwọn míì lọ torí pé a láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbà pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo wa, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.​—1 Tím. 3:15. w17.01 4:​7, 8

Monday, November 26

Ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.​—Sm. 115:16.

Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àwa èèyàn ni pé ká máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:28; Sm. 37:29) Àìmọye ẹ̀bùn ni Jèhófà fi jíǹkí Ádámù àti Éfà táá jẹ́ kí wọ́n gbádùn ayé wọn. (Ják. 1:17) Jèhófà fún wọn ní òmìnira àti làákàyè, ó sì tún mú kí wọ́n lè fìfẹ́ hàn, kí wọ́n sì gbádùn àjọṣe alárinrin. Ọlọ́run máa ń bá Ádámù sọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kó mọ ohun tóun fẹ́ kó ṣe. Ádámù tún mọ bó ṣe lè bójú tó ara rẹ̀ àti bó ṣe máa bójú tó àwọn ẹranko àti ilẹ̀ inú ọgbà náà. (Jẹ́n. 2:​15-17, 19, 20) Jèhófà ṣẹ̀dá Ádámù àti Éfà lọ́nà tó jẹ́ pé wọ́n lè gbóòórùn, wọ́n lè ríran, wọ́n lè tọ́ nǹkan wò, wọ́n lè gbọ́ràn, wọ́n sì lè mọ̀ bí ohun kan bá fara kàn wọ́n. Gbogbo nǹkan yìí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n gbádùn Párádísè ẹlẹ́wà tí wọ́n ń gbé. Ádámù àti Éfà láǹfààní àtiṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni, títí ayé ni wọ́n á máa kọ́ ẹ̀kọ́ mọ́ ẹ̀kọ́, tí wọ́n á sì máa ṣàwárí àwọn ohun tuntun. Jèhófà fẹ́ kí Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ tó pé pérépéré. Ayé yìí ni Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé títí láé, ká sì máa ṣàmúlò àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀. w17.02 1:​6, 7

Tuesday, November 27

Kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀ láti inú èyí tí ó wà . . . kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí . . . mọ́.​—Diu. 17:​18, 19.

Àǹfààní wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe àwọn ọkùnrin tó darí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn? Àpẹẹrẹ kan ni Ọba Jòsáyà. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí ìwé kan tó ní Òfin Mósè nínú, akọ̀wé Jòsáyà kà á sí i létí. Jòsáyà jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà, torí náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà run, òun àtàwọn aráàlú sì ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, irú èyí tẹ́nì kan ò ṣe rí. (2 Ọba 22:11; 23:​1-23) Torí pé Jòsáyà àtàwọn aṣáájú míì tó bẹ̀rù Jèhófà gbà kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà, kíá ni wọ́n ṣàtúnṣe sí bí wọ́n ṣe ń darí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn àtúnṣe yẹn sì mú káwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn ọba tó ṣàkóso àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ló pa òfin Ọlọ́run mọ́. Jèhófà bá àwọn kan lára wọn wí, ó rọ àwọn kan lóye, ó sì fàwọn míì rọ́pò wọn. (1 Sám. 13:​13, 14) Nígbà tí àsìkò sì tó lójú Jèhófà, ó yan ẹnì kan tó lọ́lá ju gbogbo àwọn tó tíì jẹ́ aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀ lọ. w17.02 3:​11, 12, 14

Wednesday, November 28

Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti ṣe [ọkùnrin] ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ẹni bí Ọlọ́run, o sì wá fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.​—Sm. 8:5.

Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní “àwòrán ara rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé àwa èèyàn lè fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run hàn, lọ́nà tó yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, àwa èèyàn lè fi ìfẹ́ hàn, ká fi inú rere hàn, ká sì fi ìyọ́nú hàn. Ọlọ́run tún fún àwa èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn ká lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Róòmù 2:​14, 15) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń nífẹ́ẹ̀ ohun tó bá mọ́ tó sì rẹwà, wọ́n sì máa ń fẹ́ gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì. Yálà wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ àbí wọn ò mọ̀, wọ́n ń gbé ògo Jèhófà yọ, torí náà, dé ìwọ̀n àyè kan, ó yẹ ká bọlá fún wọn ká sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ máa gbé àwọn èèyàn gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. w17.03 1:​5, 6

Thursday, November 29

Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá. ​—Jónà 3:10.

Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kì í ṣe bí àwa èèyàn, tá a máa ń bínú rangbọndan, tíyẹn á sì mú ká ṣìwà hù. Lẹ́yìn tí Jèhófà rí i pé àwọn èèyàn náà ti ronú pìwà dà, ó pinnu pé òun ò ní pa wọ́n run mọ́. Bí Jèhófà ṣe yí èrò rẹ̀ pa dà yìí fi hàn pé ó gba tàwọn èèyàn náà rò, ó káàánú wọn, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Bákan náà, àwọn ìgbà míì wà tó máa bọ́gbọ́n mu pé ká yí ìpinnu kan pa dà. Ó lè jẹ́ torí ipò nǹkan tó yí pa dà. Àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà náà yí ìpinnu rẹ̀ pa dà torí pé ipò nǹkan yí pa dà. (1 Ọba 21:​20, 21, 27-29; 2 Ọba 20:​1-5) Nígbà míì, a lè yí ìpinnu kan pa dà torí pé a rí àwọn ìsọfúnni tuntun gbà. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan parọ́ mọ́ Mefibóṣẹ́tì ọmọ-ọmọ Sọ́ọ̀lù níwájú Ọba Dáfídì. Àmọ́ lẹ́yìn tí Dáfídì wá mọ ìdí ọ̀rọ̀ náà, ó yí ìpinnu tó ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà.​—2 Sám. 16:​3, 4; 19:​24-29. w17.03 2:​14, 15

Friday, November 30

Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.​—Fílí. 4:5.

Tí ìṣòro kan bá yọjú, ó yẹ ká wá àwọn ìlànà Bíbélì tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà, ká sì fàwọn ìlànà náà sílò bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kóun máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 4:20) Àmọ́, ká sọ pé lọ́jọ́ kan tó ti pinnu pé òun fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí, ọkọ rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pé òun á fẹ́ kó wà pẹ̀lú òun nílé. Ọkọ náà sọ pé á dáa káwọn jọ wà pa pọ̀ lọ́jọ́ yẹn torí pé ó ti ṣe díẹ̀ táwọn méjèèjì ti jọ wà pa pọ̀. Arábìnrin náà lè ronú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan, bí èyí tó sọ pé ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run àtèyí tó ní ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:​19, 20; Ìṣe 5:29) Àmọ́, ó yẹ kó tún ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé káwọn aya tẹrí ba fáwọn ọkọ wọn, àtèyí tó sọ pé ká máa gba tàwọn míì rò. (Éfé. 5:​22-24) Ìbéèrè náà ni pé, ṣé ọkọ arábìnrin náà ta kò ó pé òun ò gbọ́dọ̀ rí i kó lọ sóde ẹ̀rí mọ́, àbí ó wulẹ̀ fẹ́ kí wọ́n jọ wà pa pọ̀ lọ́jọ́ yẹn nìkan? Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa fi ìlànà Jèhófà sílò bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. w17.03 4:17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́