ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 118-128
  • December

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • December
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Saturday, December 1
  • Sunday, December 2
  • Monday, December 3
  • Tuesday, December 4
  • Wednesday, December 5
  • Thursday, December 6
  • Friday, December 7
  • Saturday, December 8
  • Sunday, December 9
  • Monday, December 10
  • Tuesday, December 11
  • Wednesday, December 12
  • Thursday, December 13
  • Friday, December 14
  • Saturday, December 15
  • Sunday, December 16
  • Monday, December 17
  • Tuesday, December 18
  • Wednesday, December 19
  • Thursday, December 20
  • Friday, December 21
  • Saturday, December 22
  • Sunday, December 23
  • Monday, December 24
  • Tuesday, December 25
  • Wednesday, December 26
  • Thursday, December 27
  • Friday, December 28
  • Saturday, December 29
  • Sunday, December 30
  • Monday, December 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 118-128

December

Saturday, December 1

Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.​—1 Pét. 5:9.

Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n fara da onírúurú àdánwò tí Sátánì lè gbé wá. Àpẹẹrẹ “àwọn tí wọ́n lo ìfaradà” máa kọ́ wa bá a ṣe lè máa sin Jèhófà láìyẹsẹ̀, ó máa fọkàn wa balẹ̀ pé a lè borí, ó sì máa rán wa létí pé Jèhófà máa san wá lẹ́san rere tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin. (Ják. 5:11) Ṣé àwọn kan ń ṣe àtakò tàbí inúnibíni sí ẹ. Bóyá alàgbà sì ni ẹ́ tàbí alábòójútó àyíká, tó o sì ń ronú pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe ń wọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn èèyàn ṣe inúnibíni tó rorò sí Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ọ̀dọ̀ àwọn ará lọkàn Pọ́ọ̀lù máa ń wà ní gbogbo ìgbà. (2 Kọ́r. 11:​23-29) Kò jẹ́ kó sú òun, àpẹẹrẹ rẹ̀ sì máa ń gbé àwọn míì ró. (2 Kọ́r. 1:6) Bí ìwọ náà bá ń fara da ìṣòro, wàá jẹ́ àwòkọ́ṣe fáwọn míì. w16.04 2:​11, 14

Sunday, December 2

Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.​—Mát. 28:​19, 20.

Yálà àwọn èèyàn gba tiwa àbí wọn ò gba tiwa, agbára káká la máa fi rẹ́ni tó máa lóun ò mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. O tiẹ̀ lè ti pàdé àwọn kan lóde ẹ̀rí tí wọ́n sọ pé àwọn ò fara mọ́ àwọn ohun tá a gbà gbọ́, àmọ́ tí wọ́n fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Bá a ṣe mọ̀, Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Mát. 24:14) Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló rò pé Ajíhìnrere làwọn tàbí pé àwọn ń wàásù ìhìn rere. Àmọ́, gbogbo tiwọn ò ju kí wọ́n máa ṣe ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́, kí wọ́n máa wàásù fáwọn ọmọ ìjọ tàbí kí wọ́n máa gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò, tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn míì sì rò pé ọ̀nà táwọn ń gbà wàásù ni báwọn ṣe ń kọ́lé ìwòsàn, ilé ìwé tàbí ilé àwọn ọmọ aláìlóbìí. Àmọ́, ṣé iṣẹ́ tí Jésù pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe nìyẹn? w16.05 2:​1, 2

Monday, December 3

Mo ké gbàjarè sí Késárì!​—Ìṣe 25:11.

Látọdún 1914 làwọn aláṣẹ ayé ti sọ ara wọn di ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. (Sm. 2:​2, 7-9) Ọlọ́run fàyè gba ìjọba èèyàn láti ṣàkóso torí pé wọ́n lè pa àlááfíà mọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Róòmù 13:​3, 4) Ọlọ́run tiẹ̀ sọ fún wa pé ká máa gbàdúrà kí àwọn aláṣẹ ìjọba lè jẹ́ ká jọ́sìn Jèhófà láìsí wàhálà kankan. (1 Tím. 2:​1, 2) Táwọn kan bá fẹ́ dí iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́wọ́, a lè ní káwọn aláṣẹ ràn wá lọ́wọ́. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe gan-an nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé Sátánì ló ń darí ìjọba èèyàn, kò sọ pé òun ló ń darí àwọn aláṣẹ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Lúùkù 4:​5, 6) Torí náà, kò yẹ ká máa sọ pé Èṣù ló ń darí ẹnì kan pàtó tó wà nípò àṣẹ. Bíbélì sọ pé a kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnì kankan ní búburú.​—Títù 3:​1, 2. w16.04 4:​5, 6

Tuesday, December 4

Ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.​—Éfé. 5:17.

O lè máa wò ó pé, ‘Báwo la ṣe máa mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ gan-an nígbà tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò fún wa lófin pàtó kan nípa ohun tá a fẹ́ ṣe?’ Bí kò bá sí òfin pàtó kan nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, báwo la ṣe lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́? A lè ṣe bẹ́ẹ̀, tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà tá a sì gbà kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe fòye mọ ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù kọ́kọ́ gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ kó tó pèsè oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu. (Mát. 14:​17-20; 15:​34-37) Síbẹ̀, nígbà tébi ń pa á ní aginjù tí Èṣù sì dán an wò pé kó sọ òkúta di búrẹ́dì, ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 4:​2-4) Torí pé Jésù mọ èrò Bàbá rẹ̀ dunjú, ó mọ̀ pé kò yẹ kóun sọ òkúta di búrẹ́dì. Ó mọ̀ pé Jèhófà ò fẹ́ kóun lo irú agbára bẹ́ẹ̀ láti fi wá oúnjẹ fún ara òun. Bó ṣe kọ̀ láti sọ òkúta di búrẹ́dì yìí fi hàn pé ó gbà kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà, ó sì nígbàgbọ́ pé ó máa pèsè oúnjẹ fún òun. w16.05 3:​7, 8

Wednesday, December 5

Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.​—2 Tím. 3:16.

Òótọ́ ni pé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹnì kan tàbí àwùjọ àwọn èèyàn kan ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, á dáa ká kọ́kọ́ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè kà á bíi pé àwa gan-an ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀, kó sì fún wa ní ọgbọ́n ká lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó fẹ́ ká kọ́. (Ẹ́sírà 7:10; Ják. 1:5) Tó o bá ń ka ibì kan nínú Bíbélì, mú sùúrù díẹ̀ kó o sì bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí lohun tí mò ń kà yìí jẹ́ kí n mọ̀ nípa Jèhófà? Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí sílò nígbèésí ayé mi? Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí ran ẹlòmíì lọ́wọ́?’ Ó dájú pé tá a bá ronú lórí irú àwọn ìbéèrè yìí, àá rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nínú Bíbélì kíkà wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tí Jèhófà ní kí àwọn arákùnrin kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ kí wọ́n tó lè di alàgbà. (1 Tím. 3:​2-7) Torí pé èyí tó pọ̀ jù lára wa kì í ṣe alàgbà, a lè ronú pé bóyá làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kàn wá. Àmọ́ tá a bá ronú lórí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, àá rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. w16.05 5:​7, 8

Thursday, December 6

Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ní ọwọ́ mi.​—Jer. 18:6.

Nígbà táwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn dé ìlú Bábílónì, kò síbi tí wọ́n yíjú sí tí wọn ò rí ère òrìṣà táwọn èèyàn náà ń bọ, bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn náà kò yé bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Síbẹ̀, àwọn Júù tó jẹ́ adúróṣinṣin kò jẹ́ kí àwọn èèyàn ìlú Bábílónì sọ wọ́n dà bí wọ́n ṣe dà. Lára àwọn Júù bẹ́ẹ̀ ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta. (Dán. 1:​6, 8, 12; 3:​16-18) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pinnu pé Jèhófà tó jẹ́ Amọ̀kòkò àwọn nìkan làwọn máa jọ́sìn tọkàntara. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn! Ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbésí ayé Dáníẹ́lì ló lò nílùú Bábílónì, síbẹ̀ áńgẹ́lì Ọlọ́run pè é ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” (Dán. 10:​11, 19) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, amọ̀kòkò kan ló máa ń pinnu ohun tó fẹ́ fi amọ̀ mọ, ohun tó bá sì fẹ́ ló máa ṣe. Àwa tá à ń fòótọ́ inú sin Jèhófà lónìí mọ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó máa fi àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn èèyàn inú rẹ̀ mọ. (Jer. 18:6) Ọlọ́run tún láṣẹ láti fi ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ ohun tó bá fẹ́. Àmọ́, kì í mú wa lọ́ranyàn láti ṣe ohun tó bá fẹ́, ṣe ló máa ń fún wa láǹfààní láti yan ohun tó wù wá. w16.06 2:​1, 2

Friday, December 7

Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó.​—Héb. 13:5.

Sátánì máa ń lo ìpolówó ọjà láti mú ká ronú pé ó dìgbà tá a bá kó àwọn nǹkan ìní jọ tìrìgàngàn, títí kan àwọn nǹkan tá ò nílò ká tó lè láyọ̀. Ó mọ bó ṣe lè lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” láti dẹkùn mú wa. (1 Jòh. 2:​15-17; Jẹ́n. 3:6; Òwe 27:20) Oríṣiríṣi nǹkan ló kún inú ayé, títí kan àwọn nǹkan tó lòde àtèyí tí kò jọjú mọ́, àwọn míì tiẹ̀ máa ń fani mọ́ra gan-an. Ṣé o ti ra ohun tó wọ̀ ẹ́ lójú rí torí pé o rí ìpolówó rẹ̀ tàbí torí pé o rí i lọ́jà, àmọ́ tó o wá rí i nígbà tó yá pé kò wúlò fún ẹ rárá? Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń mú ayé sú ni, ó sì máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n lè fa ìpínyà ọkàn fún wa débi tá ò fi ní máa ka Bíbélì déédéé mọ́, tá ò sì ní máa múra ìpàdé sílẹ̀ mọ́. Ó lè mú ká máa pa ìpàdé jẹ, ká má sì lọ sóde ẹ̀rí déédéé mọ́. Rántí ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù fún wa pé: ‘Ayé àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń kọjá lọ.’ w16.07 1:​3, 4

Saturday, December 8

Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” . . .  ti wà, ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ.​—1 Kọ́r. 8:​5, 6.

Onírúurú ẹ̀yà làwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ìgbàanì, àwọn kan jẹ́ Júù, àwọn míì jẹ́ ọmọ Róòmù, Gíríìkì àtàwọn ẹ̀yà míì. Ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kálukú ń ṣe tẹ́lẹ̀, àṣà wọn àtohun tí wọ́n fẹ́ràn sì yàtọ̀ síra. Torí náà, ó ṣòro fún àwọn kan láti fi àwọn àṣà wọn àtijọ́ sílẹ̀ kí wọ́n sì fara mọ́ ọ̀nà ìjọsìn tuntun. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rán wọn létí pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ni àwọn Kristẹni ń sìn, ìyẹn Jèhófà. Báwo ni nǹkan ṣe rí nínú ìjọ Kristẹni lónìí? Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn láti ibi gbogbo máa rọ́ wá sínú ètò rẹ̀, tá a fi wé ibi ìjọsìn mímọ́ tó ga fíofío. Wọ́n á sọ pé: ‘[Jèhófà] yóò fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ (Aísá. 2:​2, 3) Inú wa mà dùn o pé à ń fojú ara wa rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń nímùúṣẹ! Àbájáde rẹ̀ ni pé àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà, èdè àti àṣà ló wà nínú ìjọ, síbẹ̀ wọ́n jùmọ̀ ń fìyìn fún Jèhófà. w16.06 3:​15, 16

Sunday, December 9

Ó sì gbé wa dìde pa pọ̀, ó sì mú wa jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.​—Éfé. 2:6.

Àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣì máa ṣe fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà tí wọ́n bá ń bá Kristi ṣàkóso lọ́run á kọjá àfẹnusọ. (Lúùkù 22:​28-30; Fílí. 3:​20, 21; 1 Jòh. 3:2) Wọ́n máa para pọ̀ jẹ́ “Jerúsálẹ́mù Tuntun,” ìyẹn ìyàwó Kristi. (Ìṣí. 3:12; 17:14; 21:​2, 9, 10) Wọ́n á pẹ̀lú Jésù láti ‘wo àwọn orílẹ̀-èdè sàn,’ wọ́n á sì mú kí aráyé jàǹfààní látinú àwọn ohun tí Jèhófà pèsè fún wọn kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí wọ́n sì dẹni pípé. (Ìṣí. 22:​1, 2, 17) Jèhófà máa fi inú rere rẹ̀ hàn sọ́mọ aráyé láwọn ọ̀nà tó yani lẹ́nu, ọ̀kan ni pé á jí àwọn òkú dìde. (Jóòbù 14:​13-15; Jòh. 5:​28, 29) Jèhófà máa jí àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ti kú kí Kristi tó fara rẹ̀ rúbọ. Bákan náà, ó máa jí gbogbo àwọn “àgùntàn mìíràn” tó fòótọ́ sìn ín títí dójú ikú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, gbogbo wọn á sì máa sin Jèhófà nìṣó.​—Jòh. 10:16. w16.07 4:​13-15

Monday, December 10

Ní irú àkókò yìí, ẹ ń sùn, ẹ sì ń sinmi!​—Máàkù 14:41.

Kéèyàn “wà lójúfò” nípa tẹ̀mí kọjá pé kó máa wu èèyàn láti ṣe ohun tó tọ́. Ọjọ́ mélòó kan kí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Gẹtisémánì tó wáyé, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí kan náà pé kí wọ́n máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà. (Lúùkù 21:36) Torí náà, ká tó lè máa ṣọ́nà nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà nígbà gbogbo. (1 Pét. 4:7) Jésù sọ pé òpin máa dé “ní wákàtí tí [a] kò ronú pé yóò jẹ́,” torí náà, kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká máa tòògbé nípa tẹ̀mí. Àsìkò yìí kọ́ ló yẹ ká máa lé àwọn nǹkan tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ àtàwọn nǹkan tí ara àìpé wa ń fẹ́. (Mát. 24:44) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àá rí ohun tí Ọlọ́run àti Kristi sọ pé àwọn máa ṣe fún wa láìpẹ́ àti ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣọ́nà. Torí náà, ó yẹ ká fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Ọlọ́run, ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì rí i pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ló gbawájú láyé wa. A gbọ́dọ̀ fiyè sí àkókò tá a wà yìí àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ká lè gbára dì fún ohun tó ń bọ̀. (Ìṣí. 22:20) Ìdí ni pé ẹ̀mí wa lè lọ sí i tá ò bá wà lójúfò! w16.07 2:​15-17

Tuesday, December 11

Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì. ​—Kól. 3:13.

Kí àárín tọkọtaya tó lè gún, ó ṣe pàtàkì káwọn méjèèjì gbà pé àwọn lè ṣàṣìṣe. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa ‘fara dà á fún ara wọn, wọ́n á sì máa dárí ji ara wọn ní fàlàlà.’ Ó dájú pé àwọn méjèèjì á máa ṣàṣìṣe. Àmọ́ tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wọn, kí wọ́n dárí ji ara wọn, kí wọ́n sì máa fi ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. (Kól. 3:14) Yàtọ̀ síyẹn, “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. . . . Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́r. 13:​4, 5) Ó yẹ kẹ́ ẹ tètè máa yanjú èdèkòyédè tẹ́ ẹ bá ní kíákíá. Ọjọ́ yẹn ni kẹ́ ẹ yanjú ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kó dọjọ́ kejì. (Éfé. 4:​26, 27) Tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnì kejì rẹ tó o bá ṣẹ̀ ẹ́, o lè sọ pé: “Jọ̀ọ́ má bínú, ohun tí mo ṣe yẹn dùn mí gan-an.” Èyí gba pé kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà, àmọ́ tẹ́ ẹ bá lè tọrọ àforíjì, ẹ̀ẹ́ lè yanjú ìṣòro kíá, ìyẹn á sì jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọwọ́ ara yín dáadáa. w16.08 2:6

Wednesday, December 12

Ìtọ́ni rere ni ohun tí èmi yóò fi fún yín dájúdájú.​—Òwe 4:2.

Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí Jésù nígbà tó wà láyé. Síbẹ̀, ó wá ààyè láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run kí wọ́n sì di olùkọ́ tó jáfáfá. (Mát. 10:​5-7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Fílípì dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, síbẹ̀ òun náà wá ààyè láti dá àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lẹ́kọ̀ọ́ kí àwọn náà lè di ajíhìnrere tó dáńtọ́. (Ìṣe 21:​8, 9) Ǹjẹ́ irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lónìí? Ojoojúmọ́ ni iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ń pọ̀ sí i kárí ayé. Ó yẹ káwọn tí kò tíì ṣèrìbọmi mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n á ṣe máa wàásù fún àwọn míì, kí wọ́n sì mọ béèyàn ṣe ń kọ́ni. Bákan náà, ó tún ṣe pàtàkì kí àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. Àǹfààní lèyí jẹ́ fáwọn Kristẹni tó nírìírí láti kọ́ àwọn ẹni tuntun kí wọ́n lè fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. w16.08 4:​1, 2

Thursday, December 13

Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lera lókun, ẹ sì mú àwọn eékún tí ń gbò yèpéyèpé le gírígírí.​—Aísá. 35:3.

Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, ṣe ló ń mú ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Ó tún ń mú ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa ká sì jọ máa gbé ara wa ró bá a ṣe ń retí àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń fún àwọn míì lókun, à ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìṣòro kí wọ́n sì ní ìdánilójú pé ọ̀la máa dáa. (Aísá. 35:4) Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ ń mú káwa náà lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó sì ń mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Kò sí àní-àní pé ṣe là ń fún ara wa náà lókun. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun tó sì dáàbò bò wọ́n mú ká túbọ̀ nígbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà. Torí náà, ìṣòro yòówù kó dé, ‘má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ rọ jọwọrọ’! (Sef. 3:16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ké pe Jèhófà nínú àdúrà, kó o sì jẹ́ kí ọwọ́ ńlá agbára rẹ̀ fún ẹ lókun, kó sì máa ṣamọ̀nà rẹ títí wọnú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.​—Sm. 73:​23, 24. w16.09 1:​16-18

Friday, December 14

Àkókò wà fún gbogbo àlámọ̀rí àti nípa gbogbo iṣẹ́ ibẹ̀.​—Oníw. 3:17.

Nígbà tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa wọ̀, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń fi ìlànà tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ́kàn. Òótọ́ ni pé a máa ń wo bójú ọjọ́ ṣe rí ká tó pinnu ohun tá a máa wọ̀. A tún máa ń ronú lórí ibi tá à ń lọ àti bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀. Àmọ́, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ìlànà Jèhófà kì í yí pa dà bójú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà. (Mál. 3:6) Lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, ó lè ṣòro láti wọ aṣọ tó bójú mu, tó sì bo ara dáadáa torí ooru. Àmọ́, ara máa tu àwọn ará tí a kò bá wọ aṣọ tó fún pinpin tàbí tó ṣí ara sílẹ̀. (Jóòbù 31:1) Bákan náà, tá a bá lọ gbafẹ́ létíkun tàbí tá a lọ wẹ̀ lódò, ó yẹ ká wọ aṣọ tó bójú mu. (Òwe 11:​2, 20) Nínú ayé, táwọn èèyàn bá lọ wẹ̀ lódò wọ́n sábà máa ń bọ́ra sí ìhòòhò, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì sáwa tá à ń sin Jèhófà ni bí ìmúra wa ṣe máa fògo fún Ọlọ́run mímọ́ tá à ń sìn. w16.09 3:​11, 12

Saturday, December 15

Ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?​—Mát. 16:15.

Jésù máa ń fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Á dáa kíwọ náà ṣe bíi ti Jésù. Ìgbà tí ara tu gbogbo yín ló dáa jù pé kó o ní kí wọ́n sọ tinú wọn. Tí ohun tó o kọ́ ọmọ rẹ kò bá dá a lójú, má kanra mọ́ ọn. Fara balẹ̀ ṣàlàyé fún un, kíwọ náà sì gbọ́ tiẹ̀. Tí ọmọ rẹ bá ń béèrè ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, mọ̀ pé ṣe ló fẹ́ kó o tọ́ òun sọ́nà. Kódà nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, òun náà béèrè àwọn ìbéèrè gbankọgbì. (Lúùkù 2:46) Mọ àwọn ọmọ rẹ dáadáa, mọ ohun tí wọ́n ń rò, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn àtohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Má kàn gbà pé òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn kìkì torí pé wọ́n ń wá sípàdé, wọ́n sì ń bá ẹ lọ sóde ẹ̀rí. Ẹ jọ máa jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí lójoojúmọ́. Máa gbàdúrà fáwọn ọmọ rẹ, ẹ sì jọ máa gbàdúrà pọ̀. Sapá láti mọ ìgbà tí wọ́n ń kojú àdánwò, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́. w16.09 5:​3-5

Sunday, December 16

Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.​—Mát. 5:3.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣí. 14:6) Iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. Èyí ti mú káwọn kan lára wa kọ́ èdè tuntun. Àwọn míì ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, nígbà táwọn míì ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ nílẹ̀ àjèjì. Àwọn míì sì ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè míì nílùú ìbílẹ̀ wọn. Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ká sì tún rí i pé ìdílé wa ń ṣe déédéé nípa tẹ̀mí. Àmọ́ nígbà míì ọwọ́ wa máa ń dí débi pé a lè má fi bẹ́ẹ̀ ráyè láti dá kẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì tún ní àwọn ìṣòro míì. Yàtọ̀ sí pé àwọn tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì máa ń kọ́ èdè tuntun, wọ́n tún ní láti rí i dájú pé àwọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.​—1 Kọ́r. 2:10. w16.10 2:​1-3

Monday, December 17

Àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.​—Mát. 26:52.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń fínná mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ ìrètí ọjọ́ iwájú ń mú ká máa yọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló wà lẹ́wọ̀n láwọn orílẹ̀-èdè bí Eritrea, Singapore àti South Korea. Ìdí tí ọ̀pọ̀ wọn sì fi wà lẹ́wọ̀n ni pé wọ́n ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù pé kí wọ́n má ṣe gbé idà sókè sí ẹnikẹ́ni. Ìṣòro tí èyí tó pọ̀ jù lára àwa èèyàn Jèhófà ń kojú yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn tá a sọ tán yìí. A lè má kojú irú inúnibíni tí wọ́n dojú kọ, síbẹ̀, àwọn kan lára wa níṣòro àtijẹ-àtimu, ogun abẹ́lé tàbí ìjábá tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè àwọn míì ló kó wọn sí ìṣòro. Ńṣe làwọn míì ń fara wé Mósè àtàwọn baba ńlá ìgbàanì, wọ́n yááfì ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Wọ́n sì ń tiraka kí afẹ́ ayé má bàa dẹkùn mú wọn. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n ní mú kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa mú ohun gbogbo tọ́, á sì mú kí wọ́n jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.​—Sm. 37:​5, 7, 9, 29. w16.10 3:​15,16

Tuesday, December 18

Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.​—Sm. 34:18.

Nígbà tí ẹ̀rù ń ba Jeremáyà tó sì rẹ̀wẹ̀sì, Jèhófà fún un nígboyà. (Jer. 1:​6-10) Ẹ tún wo bó ṣe máa rí lára wòlíì Dáníẹ́lì tó ti dàgbà nígbà tí Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan sí i kó lè fún un lókun. Áńgẹ́lì náà pe Dáníẹ́lì ní ọkùnrin “fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” (Dán. 10:​8, 11, 18, 19) Ṣé ìwọ náà lè fún àwọn míì níṣìírí, irú bí àwọn akéde, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tàbí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti dàgbà, tí wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ lókun mọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà àti Jésù ti jọ ṣiṣẹ́ fún àìlóǹkà ọdún kí Jésù tó wá sáyé, síbẹ̀ Jèhófà gbóríyìn fún un, ó sì fún un níṣìírí nígbà tó wà láyé. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù gbọ́ tí Bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:17; 17:5) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run gbóríyìn fún Jésù, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé inú òun dùn sí ohun tó ń ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jésù wà nínú ìdààmú lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti fún un lókun.​—Lúùkù 22:43. w16.11 1:​7, 8

Wednesday, December 19

Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.​—Oníw. 7:9.

Tí ẹnì kan bá fojú pa wá rẹ́ tàbí tí wọ́n rẹ́ wa jẹ, inú máa ń bí wa kì í sì í rọrùn láti pa á mọ́ra. Táwọn èèyàn bá ṣàìdáa sí wa torí ibi tá a ti wá tàbí torí àwọ̀ wa tàbí torí àwọn nǹkan míì, ó máa ń ká wa lára gan-an. Àmọ́, ó máa dùn wá gan-an tó bá jẹ́ pé àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ló ṣe irú ẹ̀ sí wa. Ìdí nìyẹn tó fi dáa ká máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé ká máa ṣe sùúrù, ká má sì tètè máa bínú. (Òwe 16:32) Kò yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan máa ká wa lára ju bó ṣe yẹ lọ, ká sì kọ́ bá a ṣe lè túbọ̀ máa dárí jini. Ìdí ni pé ọwọ́ kékeré kọ́ ni Jèhófà àti Jésù fi ń mú ọ̀rọ̀ dídárí jini. (Mát. 6:​14, 15) Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ṣó yẹ kí n túbọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń dárí jini? Ṣó sì yẹ kí n túbọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń pa nǹkan mọ́ra? Àwọn tí kì í gbọ́kàn kúrò lórí ọ̀rọ̀ sábà máa ń kanra, wọ́n sì máa ń dinú. Èyí lè mú káwọn èèyàn máa yẹra fún wọn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa sọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa, kíyẹn sì dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ.​—Léf. 19:​17, 18. w16.11 3:​4-6

Thursday, December 20

Àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?​—2 Kọ́r. 6:14.

Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn míì máa ń kóra jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní nǹkan bí ọdún 1870. Níbẹ̀rẹ̀, ohun tí Arákùnrin Russell ní lọ́kàn ni bó ṣe máa mọ èyí tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lára àwọn ìsìn tó wà nígbà yẹn. Torí náà, ó fara balẹ̀ gbé ẹ̀kọ́ onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì yẹ̀ wò, títí kan àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, ó sì wò ó bóyá ẹ̀kọ́ wọn bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu. Kò pẹ́ tó fi mọ̀ pé kò séyìí tó rọ̀ mọ́ Bíbélì délẹ̀délẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mélòó kan, ó ronú pé wọ́n á tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tóun àtàwọn yòókù rẹ̀ ṣàwárí nínú Bíbélì, wọ́n á sì máa fi kọ́ ìjọ wọn. Etí ikún làwọn àlùfáà yẹn kọ sí gbogbo àlàyé tó ṣe. Ó wá di pé káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Russell àtàwọn yòókù rẹ̀ ṣèpinnu, ìpinnu náà sì ni pé àwọn ò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ìsìn tó ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni. w16.11 4:14

Friday, December 21

Ẹ jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín nísinsìnyí bí ẹrú fún òdodo pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́ níwájú.​—Róòmù 6:19.

Tá a bá ń ronú nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, a máa yẹra fáwọn ìwà bí ìṣekúṣe, ìmutípara àtàwọn ìwà míì táwọn ará Kọ́ríńtì ń hù kí wọ́n tó di Kristẹni. (1 Kọ́r. 6:​9-11) Àmọ́, àwọn ìwà yìí nìkan kọ́ la máa yẹra fún. Tá a bá mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kì í ṣe ìṣekúṣe nìkan la máa yẹra fún, a ò ní máa wo ìwòkuwò. Tá a bá jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara wa bí ẹrú fún òdodo, kì í ṣe pé a máa yẹra fún ìmutípara nìkan, a ò tiẹ̀ ní dé bèbè àtimu ọtí yó. Ó lè gba pé ká sapá gan-an ká tó lè borí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, àmọ́ ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè borí. Ó yẹ ká pinnu pé a máa yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì àtèyí táwọn èèyàn kà sí ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké. Òótọ́ ni pé kò sí béèyàn ṣe mọ̀ ọ́n rìn, kórí má mì, síbẹ̀ a lè sapá láti borí ẹ̀ṣẹ̀ bí Pọ́ọ̀lù náà ti ṣe. Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú àwọn ara kíkú yín, tí ẹ ó fi máa ṣègbọràn sí àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn.”​—Róòmù 6:12; 7:​18-20. w16.12 1:​16, 19-21

Saturday, December 22

Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.​—Gál. 5:​22, 23.

Jésù ṣèlérí pé tá a bá bẹ Baba wa ọ̀run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kò ní ṣàì fún wa. (Lúùkù 11:​10-13) Àwọn ànímọ́ rere tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́ gan-an. (Kól. 3:10) Bó o ṣe ń fi àwọn ànímọ́ yìí ṣèwàhù, àárín ìwọ àtàwọn èèyàn á túbọ̀ gún régé. Wàá wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó sábà máa ń fa àníyàn kò ní wáyé. Ká sòótọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa jẹ́ kó o fi ara rẹ sábẹ́ “ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run,” kó o sì “kó gbogbo àníyàn [rẹ] lé e.” (1 Pét. 5:​6, 7) Bó o ṣe ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀, wàá máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o rí ojúure Ọlọ́run àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀. (Míkà 6:8) Tó o bá mọ̀wọ̀n ara ẹ, tó ò sì ṣe ju ara ẹ lọ, wàá máa gbára lé Jèhófà, àníyàn ò sì ní bò ẹ́ mọ́lẹ̀. w16.12 3:​7, 12

Sunday, December 23

Nóà [jẹ́] oníwàásù òdodo. ​—2 Pét. 2:5.

Bíbélì pe Nóà ní “oníwàásù òdodo” torí pé ó fìtara kéde ìparun tó máa dé bá ayé ìgbà yẹn. Ó dájú pé iṣẹ́ ìwàásù yẹn mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára. Yàtọ̀ sí pé ó wàásù, ó tún fi tọkàntara ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì. (Héb. 11:7) Bíi ti Nóà, àwa náà máa ń sapá láti ṣe “púpọ̀ nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń kọ́ àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn, a sì máa ń bójú tó wọn. A máa ń yọ̀ǹda ara wa láwọn àpéjọ wa, a sì tún máa ń ṣe onírúurú iṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àti ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa ń lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, torí a mọ̀ pé ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìlérí Ọlọ́run túbọ̀ dájú. Láìsí àní-àní, bá a ṣe ń wàásù ń mú ká máa bá eré ìje ìyè náà nìṣó láì ṣàárẹ̀.​—1 Kọ́r. 9:24. w17.01 1:​8, 9

Monday, December 24

Nítorí olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.​—Gál. 6:5.

Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ó níbi tí òmìnira wa mọ, a ò sì lè ṣèpinnu fáwọn míì. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n tí wọ́n bá ṣèpinnu. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní òmìnira, ìpinnu tí kálukú máa ṣe sì lè yàtọ̀ síra nígbà míì. Kódà, ọ̀rọ̀ yìí kan ìwà wa àti ìjọsìn wa. Tá a bá gbà pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa “ru ẹrù ti ara rẹ̀,” àá máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n nítorí àwọn náà ní ẹ̀bùn òmìnira láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n, títí kan ṣíṣe ìpinu ara ẹni lóri àwọn ọ̀ràn kan tí a lè má kà sí. (1 Kọ́r. 10:​32, 33)Ẹ̀bùn ńlá ni Jèhófà fún wa nígbà tó fún wa lómìnira, a sì mọyì báwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ ṣe ń darí wa. (2 Kọ́r. 3:17) À ń gbádùn òmìnira yìí gan-an torí pé ó ń jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn yìí, ká máa lò ó lọ́nà tó ń fògo fún Ọlọ́run, ká sì máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n tí wọ́n bá ṣèpinnu. w17.01 2:​15, 17, 18

Tuesday, December 25

Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.​—Jòh. 8:28.

Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú tó dáa wò wá, kò dìgbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́nnu tàbí tá à ń ṣe àwọn nǹkan táwọn èèyàn á fi gba tiwa, ṣe ló yẹ ká ní ‘ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ìwà tútù.’ (1 Pét. 3:​3, 4; Jer. 9:​23, 24) Ojú tá a fi ń wo ara wa máa hàn nínú bá a ṣe ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń ṣe sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, bá ò tiẹ̀ sọ ọ́ ní tààràtà, a lè dọ́gbọ́n máa sọ pé a ní àwọn àǹfààní kan táwọn míì ò ní tàbí pé a ní àwọn ìsọfúnni kan tí wọn ò ní, a sì lè máa ṣe bíi pé a sún mọ́ àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú jù wọ́n lọ. Ó sì lè jẹ́ pé àwa àtàwọn kan la jọ ṣe ohun kan láṣeyọrí, àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ bíi pé àwa nìkan la dá ṣe nǹkan náà. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ìdí tó sì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ohun tóun ń sọ ti wá, kì í ṣe ọgbọ́n orí òun àbí èrò òun. w17.01 4:12

Wednesday, December 26

Ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.​—Jẹ́n. 2:17.

Kò ṣòro fún Ádámù àti Éfà láti lóye òfin yẹn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ni wọ́n lára láti pa á mọ́. Ó ṣe tán, kì í ṣe èso igi yẹn nìkan ló wà nínú ọgbà, igi tí wọ́n lè jẹ èso rẹ̀ pọ̀ gan-an. Sátánì Èṣù lo ejò láti mú kí Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run. (Jẹ́n. 3:​1-5; Ìṣí. 12:9) Sátánì sọ pé kò yẹ kí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn ò lè jẹ lára èso “gbogbo igi ọgbà”? Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘A jẹ́ pé ẹ ò lè ṣe ohun tó wù yín nìyẹn.’ Ó wá gbé irọ́ ńlá kan kalẹ̀, pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Ó sì wá bó ṣe máa yí Éfà lọ́kàn pa dà kó bàa rú òfin Ọlọ́run, ó ní: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là.” Sátánì dọ́gbọ́n sọ pé torí Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n rí ọ̀ọ́kán ló ṣe ní kí wọ́n má jẹ èso náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sátánì gbé wọn gẹṣin aáyán pé wọn “yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” w17.02 1:​8, 9

Thursday, December 27

Wòlíì kan láti àárín ìwọ fúnra rẹ, ní àárín àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbé dìde fún ọ-òun ni kí ẹ̀yin fetí sí.​—Diu. 18:15.

Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ẹni yẹn máa jẹ́ “aṣáájú àti aláṣẹ.” (Aísá. 55:4) Lábẹ́ ìmísí, Dáníẹ́lì pe ẹni yẹn ní “Mèsáyà Aṣáájú.” (Dán. 9:25) Níkẹyìn, Jésù Kristi pe ara rẹ̀ ní “Aṣáájú” àwa èèyàn Ọlọ́run. (Mát. 23:10) Tinútinú làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi tẹ̀ lé e, wọ́n sì tún jẹ́rìí sí i pé òun ni Jèhófà yàn ṣe aṣáájú. (Jòh. 6:​68, 69) Kí ló jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jésù Kristi ni Jèhófà yàn láti máa darí àwa èèyàn rẹ̀? Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jòhánù tó batisí rẹ̀ rí i “tí ọ̀run ń pínyà, àti pé, bí àdàbà, ẹ̀mí bà lé e.”(Máàkù 1:​10-12) Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run fún un lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà lára rẹ̀. (Ìṣe 10:38) Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ mú kí Jésù ní ìfẹ́, ayọ̀ àti ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó sì lo àwọn ànímọ́ yìí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Jòh. 15:9; Héb. 12:2) Jésù nìkan ló fi àwọn ànímọ́ yìí hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Èyí sì fi hàn kedere pé òun ni Jèhófà yàn ṣe aṣáájú àwa èèyàn Ọlọ́run. w17.02 3:​15, 16

Friday, December 28

Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín.​—Héb. 13:7.

Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ sí í múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni. Lọ́jọ́ yẹn, “Pétérù dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá náà,” wọ́n sì kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 2:​14, 15) Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà sì di onígbàgbọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun yìí “ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 2:42) Àwọn àpọ́sítélì yìí ló ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìnáwó nínú ìjọ. (Ìṣe 4:​34, 35) Àwọn náà sì ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n ní: “Àwa yóò fi ara wa fún àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń rán àwọn Kristẹni tó nírìírí lọ wàásù láwọn ilẹ̀ míì tí iṣẹ́ ìwàásù náà kò tíì dé. (Ìṣe 8:​14, 15) Nígbà tó yá, àwọn alàgbà kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró kún àwọn àpọ́sítélì kí wọ́n lè máa bójú tó ìjọ. Àwọn yìí ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ olùdarí, wọ́n sì ń darí bí nǹkan ṣe ń lọ ní gbogbo ìjọ.​—Ìṣe 15:2. w17.02 4:4

Saturday, December 29

Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, . . . ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.​—Róòmù 13:7.

Ẹ̀mí ayé Sátánì ti mú káwọn èèyàn sọ àwọn kan di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Lára àwọn táráyé ń gbógo fún ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àwọn olóṣèlú, àwọn eléré ìdárayá, àwọn tó ń ṣe eré orí ìtàgé, àwọn olórin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n ti sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di ọlọ́run. Torí náà, tèwe tàgbà ló máa ń ṣe bíi tiwọn, kódà wọ́n máa ń káṣà bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, bí wọ́n ṣe ń múra àti bí wọ́n ṣe ń hùwà. Àwa Kristẹni tòótọ́ kì í gbé àwọn èèyàn gẹ̀gẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Nínú gbogbo àwọn tó ti gbé ayé rí, Kristi nìkan ló fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé. (1 Pét. 2:21) Inú Ọlọ́run kò ní dùn tá a bá ń bọlá fáwọn èèyàn kọjá bó ṣe yẹ. Òótọ́ kan tó yẹ ká máa rántí ni pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Torí náà, kò sídìí láti sọ èèyàn èyíkéyìí di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. w17.03 1:​6-8

Sunday, December 30

Ọkàn-àyà Ásà wà ní pípé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀.​—1 Ọba 15:14.

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè yẹ ọkàn rẹ̀ wò bóyá òun ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin Ọlọ́run. Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo ti pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ni màá máa ṣe, ṣé màá máa gbèjà ìjọsìn tòótọ́, tí màá sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́?’ Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan nínú ìdílé rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan dẹ́ṣẹ̀, tí kò ronú pìwà dà, tí wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, kí ni wàá ṣe? Ṣé wàá lo ìgboyà, kó o sì pinnu pé o ò ní bá onítọ̀hún ṣe mọ́? Kí lọkàn rẹ máa sọ pé kó o ṣe? O lè fi hàn pé tọkàntọkàn lo gbára lé Jèhófà bíi ti Ásà, nígbà tó o bá dojú kọ àtakò, títí kan àwọn ìṣòro tó dà bí òkè. Àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ lè máa bú ẹ tàbí kí wọ́n máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. Àwọn ará ibiṣẹ́ rẹ sì lè máa bú ẹ torí pé o máa ń gbàyè láti lọ sí ìpàdé àtàwọn ìgbòkègbodò Kristẹni míì, tàbí torí pé o kì í sábà ṣe àṣekún iṣẹ́. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Ásà. (2 Kíró. 14:11) Kó o sì ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu tó sì tọ́. Máa rántí pé Ọlọ́run ran Ásà lọ́wọ́, ó sì dájú pé á ran ìwọ náà lọ́wọ́. w17.03 3:​6-8

Monday, December 31

Àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.​—Òwe 21:5.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká má ṣe máa kánjú ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Tá a bá ń fara balẹ̀ tá a sì ń ronú jinlẹ̀ dáadáa ká tó ṣèpinnu, ó ṣeé ṣe ká ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (1 Tẹs. 5:21) Kí olórí ìdílé kan tó ṣèpinnu, ó yẹ kó fara balẹ̀ ṣèwádìí nínú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kó sì tún tẹ́tí sí èrò àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀. Rántí pé Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó tẹ́tí sí ìyàwó rẹ̀. (Jẹ́n. 21:​9-12) Ó tún yẹ káwọn alàgbà máa fara balẹ̀ ṣèwádìí kí wọ́n tó ṣèpinnu. Tí wọ́n bá sì rí àwọn ìsọfúnni tó mú kó pọn dandan pé kí wọ́n yí ìpinnu tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà, kò yẹ kí wọ́n lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọn kì í ronú pé àwọn ará ò ní bọ̀wọ̀ fáwọn mọ́ tí àwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí wọ́n ṣe tán láti yí èrò wọn àti ìpinnu wọn pa dà nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ohun tó sì yẹ kí gbogbo wa máa ṣe nìyẹn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àlàáfíà máa wà nínú ìjọ, ohun gbogbo á sì máa lọ létòlétò.​—Ìṣe 6:​1-4. w17.03 2:16

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́