ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 37-46
  • April

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • April
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Monday, April 1
  • Tuesday, April 2
  • Wednesday, April 3
  • Thursday, April 4
  • Friday, April 5
  • Saturday, April 6
  • Sunday, April 7
  • Monday, April 8
  • Tuesday, April 9
  • Wednesday, April 10
  • Thursday, April 11
  • Friday, April 12
  • Saturday, April 13
  • Sunday, April 14
  • Monday, April 15
  • Tuesday, April 16
  • Wednesday, April 17
  • Thursday, April 18
  • Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
    Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
    Friday, April 19
  • Saturday, April 20
  • Sunday, April 21
  • Monday, April 22
  • Tuesday, April 23
  • Wednesday, April 24
  • Thursday, April 25
  • Friday, April 26
  • Saturday, April 27
  • Sunday, April 28
  • Monday, April 29
  • Tuesday, April 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 37-46

April

Monday, April 1

Ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.​—Éfé. 4:8.

Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun táwọn alàgbà yìí ń ṣe? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn, ká sì máa fara wé àwọn àpẹẹrẹ dáadáa tí wọ́n ń fi lélẹ̀. Ọ̀nà míì ni pé, tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn látinú Bíbélì, ká ṣe ohun tí wọ́n sọ. (Héb. 13:​7, 17) Ẹ máa rántí pé àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì fẹ́ ká túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá kíyè sí pé à ń pa ìpàdé jẹ tàbí pé ìtara tá a ní ti ń dín kù, ó dájú pé wọ́n á tètè wá bí wọ́n á ṣe ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n máa tẹ́tí sí wa, wọ́n á sì fún wa níṣìírí àti ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹ, ṣé wàá gbà pé ọ̀nà kan tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí ẹ nìyẹn? Ẹ má gbàgbé pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn alàgbà láti wá sọ ibi tá a kù sí fún wa.Torí náà, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn alàgbà tó wà níjọ yín rọrùn? Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, kó o sì jẹ́ ẹni tó ń moore. Tí wọ́n bá pe àfiyèsí ẹ sáwọn nǹkan kan, gbà pé ṣe ni Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn sí ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jàǹfààní, àwọn alàgbà náà á sì túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ wọn. w18.03 31 ¶15-16

Tuesday, April 2

Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.​—Òwe 27:11.

Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ máa ń yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, òtítọ́ máa ń tètè yé àwọn ọmọ kan ju àwọn míì lọ. Bákan náà, àtikékeré ni òtítọ́ ti máa ń jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ kan, táá sì wù wọ́n láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, àwọn míì lè dàgbà díẹ̀ kí wọ́n tó pinnu láti ṣèrìbọmi. Torí náà, àwọn òbí tó gbọ́n kì í ti ọmọ wọn pé kó lọ ṣèrìbọmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń kíyè sí ibi tí òye ọmọ kọ̀ọ̀kan mọ, wọ́n sì máa ń fìyẹn sọ́kàn tí wọ́n bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Inú àwọn òbí máa ń dùn tí ọmọ wọn bá fi ohun tó wà nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sọ́kàn. Síbẹ̀, wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìdí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn òbí bi ara wọn pé, ‘Ṣé òtítọ́ ti jinlẹ̀ lọ́kàn ọmọ mi débi tó fi lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kó sì ṣèrìbọmi?’ w18.03 9 ¶6

Wednesday, April 3

Ó ti búra sí ohun tí ó burú fún ara rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò yí padà.​—Sm. 15:4.

Tá a bá ti sọ fẹ́nì kan pé a máa wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kò yẹ ká yẹ àdéhùn wa. Ẹni tó fẹ́ gbà wá lálejò lè ti ṣètò ọ̀pọ̀ nǹkan sílẹ̀ fún wa, tá ò bá lọ, gbogbo ìsapá ẹ̀ máa já sásán. (Mát. 5:37) Àwọn kan ti yẹ àdéhùn tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ẹnì kan torí pé wọ́n fẹ́ lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíì tó dà bíi pé ó sàn ju ẹni tó kọ́kọ́ pè wọ́n. Àmọ́, ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dáa? Dípò tá a fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká lọ sọ́dọ̀ ẹni tá a ti bá ṣàdéhùn, ká sì mọrírì ohunkóhun tó bá fún wa. (Lúùkù 10:7) Àmọ́ o, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lohun kan ṣẹlẹ̀ tá ò fi ní lè lọ, ó yẹ ká tètè sọ fún ẹni tó fẹ́ gbà wá lálejò. Àwọn kan máa ń sọ pé ‘báyìí là ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ibòmíì ni.’ Òótọ́ sì ni torí pé láwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, kò sóhun tó burú tẹ́nì kan bá lọ sílé ẹlòmíì láìsọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ wọn ò nífẹ̀ẹ́ sírú ẹ̀ níbòmíì. Láwọn ilẹ̀ kan, ohun tó dáa jù ni wọ́n fi máa ń ṣàlejò, àmọ́ láwọn ibòmíì, ohun kan náà ni onílé àtàlejò máa jẹ. Bákan náà, láwọn ibì kan, ó dìgbà tí wọ́n bá pe ẹnì kan lẹ́ẹ̀mejì sí ẹ̀ẹ̀mẹta kó tó lè gbà láti wá, àmọ́ níbòmíì, ìwà àrífín ni tẹ́nì kan bá kọ̀. Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú ẹni tó gbà wá lálejò dùn. w18.03 18 ¶20-21

Thursday, April 4

Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.​—Héb. 6:1.

Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ìmọ̀ Bíbélì nìkan ò lè sọ wá dẹni tẹ̀mí. (1 Ọba 4:​29, 30; 11:​4-6) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí la tún nílò yàtọ̀ sí ìmọ̀ Bíbélì? A tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Kól. 2:​6, 7) Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’ Tó o bá máa fi kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí tán, wàá rí bó o ṣe lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé rẹ. Tó bá sì jẹ́ pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí tán, wá àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì táá jẹ́ kó o fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí. (Kól. 1:23) Ohun míì tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o máa ronú nípa ohun tó ò ń kọ́, kó o sì máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè fi wọ́n sílò. Ẹ máa fi sọ́kàn pé ìdí tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń ṣàṣàrò ni pé a fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a sì fẹ́ pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. (Sm. 40:8; 119:97) Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká sapá láti yẹra fáwọn nǹkan tó lè mú ká jó rẹ̀yìn nípa tẹ̀mí.​—⁠Títù 2:​11, 12. w18.02 24-25 ¶7-9

Friday, April 5

[Nóà] di ajogún òdodo tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́.​—Héb. 11:7.

Tá a bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ bíi ti Nóà, ó yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa fi àwọn nǹkan tá a kọ́ sílò, ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà, kó sì sọ wá di irú ẹni tí Ọlọ́run fẹ́. (1 Pét. 1:​13-15) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run máa dáàbò bò wá káwọn ètekéte Èṣù àti ẹ̀mí ayé yìí má bàa ràn wá. (2 Kọ́r. 2:11) Ẹ̀mí ayé yìí ló ń mú káwọn èèyàn máa ṣe ìṣekúṣe kí wọ́n sì máa hùwà ipá, ó sì tún ń mú kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbà wọ́n lọ́kàn. (1 Jòh. 2:​15, 16) Kódà, ó lè mú káwọn tí iná ẹ̀mí wọn ti ń jó rẹ̀yìn máa ronú pé á pẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run tó dé. Ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Jésù ń fi àkókò wa yìí wé ìgbà ayé Nóà, kì í ṣe ìwà ipá àti ìṣekúṣe àwọn èèyàn náà ló tẹnu mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ bí wọn ò ṣe wà lójúfò nípa tẹ̀mí ló tẹnu mọ́. (Mát. 24:​36-39) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé lóòótọ́ ni mo mọ Jèhófà? Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ mi máa ń jẹ́ kí n fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò, ṣé mo sì máa ń fi kọ́ àwọn míì?’ Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ìwọ náà ń “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.”​—Jẹ́n. 6:9. w18.02 9-10 ¶8-10

Saturday, April 6

Yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.​—2 Tím. 3:5.

Ká sòótọ́, a ò lè sá fáwọn èèyàn ayé pátápátá torí pé a jọ ń gbé, a jọ ń ṣiṣẹ́, a sì jọ ń lọ síléèwé. Àmọ́ a lè pinnu pé a ò ní máa ronú bíi tiwọn, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní hùwà bíi tiwọn. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń bá àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn kẹ́gbẹ́. Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú káwọn míì wá sin Jèhófà. Máa wá ọ̀nà láti wàásù fáwọn èèyàn, kó o sì máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o máa sọ ohun tó tọ́ lásìkò tó yẹ. Ó yẹ ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà wa máa gbógo fún Ọlọ́run dípò àwa. Jèhófà ti fún wa ní ìtọ́ni pé ká “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Títù 2:​11-14) Tá a bá ń fi ìtọ́ni Jèhófà sílò, àwọn èèyàn á kíyè sí wa, àwọn míì sì lè sọ pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”​—⁠Sek. 8:23. w18.01 31 ¶17-18

Sunday, April 7

Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn.​—2 Tím. 3:2.

Ṣó burú téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀? Rárá kò burú. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu, kódà ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀. Jésù náà sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Máàkù 12:31) Tá ò bá nífẹ̀ẹ́ ara wa, a ò lè nífẹ̀ẹ́ àwọn míì. Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Éfé. 5:​28, 29) Torí náà, kò sóhun tó burú tá a bá nífẹ̀ẹ́ ara wa. Ìfẹ́ tí 2 Tímótì 3:2 sọ kì í ṣe irú ìfẹ́ tó yẹ ká ní. Irú ìfẹ́ yìí ò dáa, ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan sì ni. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan máa ń ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. (Róòmù 12:3) Wọn ò mọ̀ ju tara wọn lọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, kàkà kí wọ́n gbà pé àwọn ṣàṣìṣe àwọn míì ni wọ́n máa ń dá lẹ́bi. Irú àwọn onímọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ kì í ní ojúlówó ayọ̀. w18.01 23 ¶4-5

Monday, April 8

Ẹ . . . fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.​—Kól. 3:15.

Bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń mú kó o tẹ́tí sí Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni àdúrà ń mú kó o lè bá a sọ̀rọ̀. Kò yẹ ká wo àdúrà bí àṣà kan lásán tàbí bí oògùn àwúre táwọn èèyàn gbà pé ó ń jẹ́ káwọn rọ́wọ́ mú nínú ohun táwọn ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Jèhófà fẹ́ kó o bá òun sọ̀rọ̀. (Fílí. 4:6) Torí náà, tó o bá ní ìdààmú ọkàn èyíkéyìí, Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.” (Sm. 55:22) Ṣó o gbà lóòótọ́ pé àdúrà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fi dá ẹ lójú pé àdúrà ti ran àwọn lọ́wọ́. Á ran ìwọ náà lọ́wọ́! Kì í ṣe ìgbà tó o bá nílò ìrànwọ́ Jèhófà nìkan ló yẹ kó o máa gbàdúrà. Nígbà míì, àwọn ìṣòro wa lè gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní rántí àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣe fún wa. Torí náà, o ò ṣe pinnu pé lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá máa ronú nípa àwọn nǹkan mẹ́ta, ó kéré tán, tí Jèhófà ṣe fún ẹ? Lẹ́yìn náà, gbàdúrà kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fáwọn nǹkan náà. w17.12 25-26 ¶10-11

Tuesday, April 9

Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.​—2 Tím. 3:15.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú òtítọ́, tí wọ́n sì yàn láti sin Jèhófà. (Sm. 1:​1-3) Tó o bá jẹ́ òbí, kò sí àní-àní pé wàá máa wọ̀nà fún ọjọ́ táwọn ọmọ rẹ máa ṣèrìbọmi. (Fi wé 3 Jòhánù 4.) Ó dájú pé ẹ̀yin òbí fẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ ìwé mímọ́, tá a wá mọ̀ lónìí sí Bíbélì lódindi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé báwọn ọmọ ṣe máa ń tètè lóye nǹkan yàtọ̀ síra, ó ṣe kedere pé àwọn ọmọ kéékèèké lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Ètò Jèhófà sì ti pèsè onírúurú ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn fídíò tẹ́yin òbí lè lò láti kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Máa rántí pé báwọn ọmọ rẹ bá lóye Ìwé Mímọ́, ìpìlẹ̀ wọn á lágbára, wọ́n á sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà bí wọ́n ṣe ń dàgbà. w17.12 18 ¶1; 19 ¶4

Wednesday, April 10

Ọkọ ni orí aya rẹ̀.​—Éfé. 5:23.

Tó bá jẹ́ pé ọkọ rẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé ìwà tó ń hù sí ẹ kò dáa tó, kí ni wàá ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìwà rẹ̀ tó kù díẹ̀ káàtó lò ń ránnu mọ́ ṣáá, ṣéyẹn á mú kó yíwà pa dà? Tíyẹn bá tiẹ̀ mú kó ṣe ohun tó o fẹ́, ǹjẹ́ o rò pé ìyẹn á mú kó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́? Kò jọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tó o bá ń bọ̀wọ̀ fún un, ìyẹn á jẹ́ kí ìdílé yín tòrò, á sì mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Kódà, ó lè mú kí ọkọ rẹ wá ṣe ìsìn tòótọ́, kí ẹ̀yin méjèèjì sì tipa bẹ́ẹ̀ rí èrè ọjọ́ iwájú gbà. (1 Pét 3:​1, 2) Tó bá jẹ́ pé ìyàwó rẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé kì í bọ̀wọ̀ fún ẹ tó, kí ni wàá ṣe? Tó o bá ń pariwo mọ́ ọn kó lè mọ̀ pé ìwọ ni olórí, ṣéyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ọlọ́run fẹ́ kó o fìfẹ́ lo ipò orí rẹ kó o sì fìwà jọ Jésù. Jésù tó jẹ́ orí ìjọ máa ń fìfẹ́ hàn, ó sì máa ń mú sùúrù. (Lúùkù 9:​46-48) Tí ọkọ kan bá ń fara wé Jésù, ìyẹn lè mú kí ìyàwó rẹ̀ wá ṣe ìsìn tòótọ́. w17.11 28-29 ¶13-14

Thursday, April 11

Ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.​—Héb. 3:4.

Àwọn tó ń ronú bí ayé ṣe ń ronú kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Tá ò bá ṣọ́ra, wọ́n lè kó èèràn ràn wá, ìyẹn sì lè jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. Lóde òní, èrò ayé ló gbòde kan, wọ́n sì ń gbé e lárugẹ lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, níbi iṣẹ́ àti níléèwé. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà àti pé àwọn ò ṣe ẹ̀sìn kankan. Wọn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n wádìí bóyá Ọlọ́run wà lóòótọ́, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n máa ṣe bó ṣe wù wọ́n láìfi ti Ọlọ́run pè. (Sm. 10:⁠4) Àwọn míì jọ ara wọn lójú gan-an, kódà wọ́n máa ń sọ pé, “Kò dìgbà tí mo bá gba Ọlọ́run gbọ́ kí n tó mọ ohun tó tọ́.” Ṣé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé kò sí Ẹlẹ́dàá? Àwọn kan ń ṣèwádìí nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ láti mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà, àmọ́ ọ̀rọ̀ ti dàrú mọ́ wọn lójú torí pé ìsọfúnni tí wọ́n rí ti pọ̀ jù. Ká sòótọ́, ohun tí kò sọnù ni wọ́n ń wá kiri, torí pé ìdáhùn ìbéèrè náà ò le. Tó bá jẹ́ pé ilé kan ò lè wà láìsí ẹni tó kọ́ ọ, mélòómélòó làwọn nǹkan abẹ̀mí bí ẹranko àtàwa èèyàn! w17.11 20-21 ¶2-4

Friday, April 12

Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.​—Mál. 3:16.

Máa ronú nípa ìdí tó fi yẹ kó o máa pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Máa fi sọ́kàn pé lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ wà lára ìjọsìn rẹ. Mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù ń kíyè sí gbogbo àwọn tó ń sapá láti pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi, tó jẹ́ ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ́dún. A fẹ́ kí Jèhófà àti Jésù mọ̀ pé a máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti wá síbi Ìrántí Ikú Kristi àfi tó bá kọjá agbára wa tàbí torí àìlera tó le gan-an. Tá a bá ń fi hàn pé ìpàdé ṣe pàtàkì sí wa, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ rí ìdí tó fi yẹ kí orúkọ wa wà nínú “ìwé ìrántí” ìyẹn “ìwé ìyè,” níbi tí orúkọ àwọn tó máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun wà. (Ìṣí. 20:15) Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ ronú nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà.​—2 Kọ́r. 13:5. w18.01 13 ¶4-5

Saturday, April 13

Kí ó sì sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá wọ̀nyí.​—Jóṣ. 20:4.

Tí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn bá ti wà nílùú ààbò, kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i. Jèhófà sọ nípa àwọn ìlú ààbò náà pé: ‘Kí wọ́n jẹ́ ibi ìsádi fún yín.’ (Jóṣ. 20:​2, 3) Jèhófà ò sọ pé kí wọ́n tún dá ẹjọ́ míì fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà, òfin ò sì fàyè gba olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ láti wọnú ìlú ààbò wá pa ẹni náà. Torí náà, ọkàn ẹni tó ṣèèṣì pààyàn balẹ̀ pé kò sẹ́ni tó máa wá pa òun. Níwọ̀n ìgbà tó bá ti wà nílùú ààbò, Jèhófà máa dáàbò bò ó. Àmọ́ ìlú ààbò yìí kì í ṣe ẹ̀wọ̀n. Ìdí ni pé ó lè ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó lè ran àwọn míì lọ́wọ́, kó sì sin Jèhófà bó ṣe fẹ́. Èyí fi hàn pé ó lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, kó sì láyọ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ṣì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà. Ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé ojú ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku ni Jèhófà fi ń wo àwọn. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tí Jèhófà bá ti dárí jì ẹ́, á fàánú hàn sí ẹ, kò sì ní máa fojú ẹlẹ́ṣẹ̀ wò ẹ́ mọ́. w17.11 9 ¶6; 11 ¶13-14

Sunday, April 14

Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí a . . . máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan! ​—Sm. 133:1.

Ọ̀nà tá a lè gbà mú kí ìṣọ̀kan wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ronú lórí ohun táwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún. Kó tó di alẹ́ ọjọ́ yẹn àti lálẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an, ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí àkàrà aláìwú àti wáìnì pupa náà ṣàpẹẹrẹ. (1 Kọ́r. 11:​23-25) Àkàrà aláìwú dúró fún ara pípé tí Jésù fi rúbọ, wáìnì náà sì dúró fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó ta sílẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe pé ká kàn lóye ohun táwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ yẹn dúró fún nìkan. Ó tún yẹ ká máa rántí pé ńṣe ni ìràpadà Jésù mú ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà àti Jésù ṣe fìfẹ́ tó ga jù lọ hàn sí wa. Jèhófà yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún wa, Jésù náà sì fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Tá a bá ń ronú lórí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wa yìí, á mú káwa náà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìfẹ́ tí gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run ní fún Jèhófà dà bí okùn tó so gbogbo wa pọ̀ tó sì ń mú ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan. w18.01 14 ¶11

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀: Nísàn 9) Mátíù 26:6-13

Monday, April 15

Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.​—1 Jòh. 4:9.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an, ó sì mọyì wa. Tinútinú ló fi yọ̀ǹda kí Ọmọ rẹ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa ká lè rí ìgbàlà àti ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Tí Jèhófà ò bá mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Èṣù á fìyẹn kẹ́wọ́, á sọ pé irọ́ ni Ọlọ́run ń pa àti pé alákòóso tí kò fẹ́ ire fáwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ni. Ìyẹn á tún fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ àwọn alátakò tó ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.” (2 Pét. 3:​3, 4) Torí náà, Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, á sì rí i dájú pé àwọn olóòótọ́ èèyàn rí ìgbàlà nígbà tó bá fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. (Aísá. 55:​10, 11) Ohun míì ni pé ìfẹ́ ni Jèhófà fi ń ṣàkóso. Torí náà, ó dá wa lójú pé títí láé ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, á sì máa ṣìkẹ́ wọn.​—Ẹ́kís. 34:6. w17.06 23 ¶7

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 9) Mátíù 21:1-11, 14-17

Tuesday, April 16

[Ọlọ́run] nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.​—1 Jòh. 4:10.

Látìgbà tí Jèhófà ti ṣèlérí pé Olùgbàlà kan máa rà wá pa dà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ló ti gbà pé òun ti rà wá pa dà. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tó ṣeyebíye kó lè rà wá pa dà. (Jòh. 3:16) A mà dúpẹ́ o, fún ìfẹ́ tó ga tí Jèhófà fi hàn sí wa yìí! A máa ń fìfẹ́ hàn torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún máa ń jẹ́ kó nira fún wa láti fìfẹ́ hàn, síbẹ̀ a lè fìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, Ébẹ́lì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nígbà tó fi èyí tó dáa jù nínú ẹran ọ̀sìn rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà. (Jẹ́n. 4:​3, 4) Bákan náà, Nóà fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn ní ti pé ọ̀pọ̀ ọdún ló fi kìlọ̀ fún wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tẹ́tí sí i. (2 Pét. 2:5) Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí Ábúráhámù fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó fi hàn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló gbawájú lọ́kàn òun, kì í ṣe ìfẹ́ tòun. (Ják. 2:21) Ẹ jẹ́ káwa náà fara wé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí, ká máa fìfẹ́ hàn bí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún wa. w17.10 7-8 ¶3-4

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 10) Mátíù 21:18, 19; 21:12, 13; Jòhánù 12:20-50

Wednesday, April 17

Àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.​—Héb. 4:15.

Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé iṣẹ́ tí Jésù Àlùfáà Àgbà wa ń ṣe máa jẹ́ “kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16) Torí náà, tó o bá fẹ́ sá di Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé kó o lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù. Má kàn wò ó bíi pé gbogbo èèyàn ni Jésù kú fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa wò ó bíi pé ìwọ gan-an ni Jésù kú fún. (Gál. 2:​20, 21) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọlá ìràpadà Jésù ni Jèhófà ń wò tó fi ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìràpadà Jésù ló mú kó o nírètí ìyè àìnípẹ̀kun. Bákan náà, máa wò ó bíi pé ìwọ ni Jèhófà dìídì fún ní ẹ̀bùn ìràpadà náà. Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò yẹ ká máa bẹ̀rù pé ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà tàbí pé ó máa fìyà ẹ̀ jẹ wá. (Sm. 103:​8-12) Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú háún pé Jèhófà máa ń dárí jini pátápátá. w17.11 11-12 ¶14-17

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 11) Mátíù 21:33-41; 22:15-22; 23:1-12; 24:1-3

Thursday, April 18

Èmi . . . ṣe ìbéèrè . . . nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi.​—Jòh. 17:​20, 21.

Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, Jésù gbàdúrà pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wà níṣọ̀kan bí òun pẹ̀lú Baba òun ti wà. Ó dájú pé Jèhófà dáhùn àdúrà tí Jésù gbà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá gbà pé Jèhófà ló rán Jésù wá sáyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpàdé wa máà ń mú ká wà níṣọ̀kan, Ìrántí Ikú Kristi túbọ̀ mú kó ṣe kedere pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níṣọ̀kan. Àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọ̀ wọn sì yàtọ̀ síra máa ń kóra jọ pọ̀ láwọn ibi ìpàdé wa kárí ayé. Láwọn ibì kan, àwọn kan ò gbà pé ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tí àwọ̀ wọn tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra máa kóra jọ láti jọ́sìn pa pọ̀. Tí wọ́n bá sì rí irú ẹ̀, ṣe ni inú máa ń bí wọn. Àmọ́ irú ìkórajọpọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Jèhófà àti Jésù dùn! Kò ya àwa èèyàn Jèhófà lẹ́nu pé a wà níṣọ̀kan. Kódà Jèhófà ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀.​—Ìsík. 37:​15-17; Sek. 8:23. w18.01 14 ¶7-9

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 12) Mátíù 26:1-5, 14-16; Lúùkù 22:1-6

Ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi
Lẹ́yìn Tí Oòrùn Bá Wọ̀
Friday, April 19

Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ti di olórí igun ilé.​—Sm. 118:22.

“Àwọn akọ́lé,” ìyẹn àwọn tó jẹ́ aṣáájú lára àwọn Júù kọ Mèsáyà sílẹ̀. Kì í ṣe pé wọ́n kẹ̀yìn sí Jésù nìkan ni tàbí pé wọn ò gbà á ní Mèsáyà. Ohun tí wọ́n ṣe burú jùyẹn lọ, ṣe ni wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. (Lúùkù 23:​18-23) Ó ṣe kedere pé àwọn ló ṣokùnfà ikú Jésù. Báwo ni Jésù ṣe lè di “olórí igun ilé” lẹ́yìn tí wọ́n kọ̀ ọ́, tí wọ́n sì pa á? Ohun tó máa jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe ni pé kí Jésù jíǹde. Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa “Jésù Kristi ará Násárétì, ẹni tí ẹ̀yín kàn mọ́gi ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 3:15; 4:​5-11; 1 Pét. 2:​5-7) Orúkọ Ọmọ Ọlọ́run tó jíǹde yìí ni Ọlọ́run “fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”​—Ìṣe 4:12; Éfé. 1:20. w17.12 9-10 ¶6-9

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 13) Mátíù 26:17-19; Lúùkù 22:7-13 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tóòrùn wọ̀: Nísàn 14) Mátíù 26:20-56

Saturday, April 20

Ẹ ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.​—1 Kọ́r. 11:26.

Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, ó sọ pé: “Wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. [Jésù] yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí, wọn yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan ọ̀run sí ìkángun rẹ̀ kejì.” (Mát. 24:​29-31) Kíkó tí a óò ‘kó àwọn àyànfẹ́ jọ pọ̀’ ń tọ́ka sí ìgbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù máa lọ gba èrè wọn ní ọ̀run. Èyí máa wáyé lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá àmọ́ ṣáájú ogun Amágẹ́dọ́nì. Ẹ̀yìn náà ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ṣẹ́gun àwọn ọba ayé. (Ìṣí. 17:​12-14) Ìrántí Ikú Kristi tá a bá ṣe kẹ́yìn ká tó kó àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró lọ sọ́run la máa ṣe gbẹ̀yìn, torí pé Jésù á ti dé nígbà yẹn. w18.01 16 ¶15

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 14) Mátíù 27:1, 2, 27-37

Sunday, April 21

Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde.​—Ìṣe 2:32.

Ní báyìí tó ti wà lọ́run, Jésù ò lè rí ìdíbàjẹ́ torí pé ó máa wà “títí láé àti láéláé.” (Ìṣí. 1:​5, 18; Róòmù 6:9; Kól. 1:18; 1 Pét. 3:18) Ó sì ti ṣèlérí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé wọ́n máa bá òun ṣàkóso lọ́run. (Lúùkù 22:​28-30) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn míì náà máa jíǹde lọ sọ́run, ó ní: “Olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” (1 Kọ́r. 15:​20, 23) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí ló jẹ́ ká mọ ìgbà tí àjíǹde ti ọ̀run máa wáyé. Ó máa wáyé “nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” A mọ̀ pé ọdún 1914 ni ìgbà “wíwàníhìn-ín” Jésù bẹ̀rẹ̀ kò sì tíì parí, àti pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti sún mọ́lé gan-an. w17.12 10 ¶11; 11 ¶14-16

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 15) Mátíù 27:62-66 (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tóòrùn wọ̀: Nísàn 16) Mátíù 28:2-4

Monday, April 22

Èmi-èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú.​—Aísá. 51:12.

Jèhófà, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ náà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Ó ṣe tán, òun náà ti pàdánù àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́, àwọn bí Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, Mósè àti Ọba Dáfídì. (Núm. 12:​6-8; Mát. 22:​31, 32; Ìṣe 13:22) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó dá wa lójú pé taratara ni Jèhófà fi ń retí ìgbà tó máa jí àwọn olóòótọ́ yìí dìde. (Jóòbù 14:​14, 15) Nígbà tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n á láyọ̀, wọ́n á sì ní ìlera tó jí pépé. Yàtọ̀ síyẹn, “ẹni tí [Ọlọ́run] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe,” ìyẹn Jésù Ọmọ rẹ̀ náà kú ikú oró. (Òwe 8:​22, 30) Kò sí bá a ṣe lè ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe máa dun Jèhófà tó. (Jòh. 5:20; 10:17) Ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ká sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà, ká sì jẹ́ kó mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tá a ní ṣe rí lára wa. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lóye wa, ó mọ ẹ̀dùn ọkàn wa, ó sì ń pèsè ìtùnú tá a nílò gan-an!​—2  Kọ́r. 1:​3, 4. w17.07 13 ¶3-5

Bíbélì Kíkà Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: (Ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú mọmọ: Nísàn 16) Mátíù 28:1, 5-15

Tuesday, April 23

Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.​—Héb. 6:10.

Lóde òní, ẹgbàágbèje àwọn èèyàn ló ń wá sínú ètò Ọlọ́run, tinútinú ni wọ́n sì ń lo ‘àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí’ láti ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń lo àkókò wọn, okun wọn àtàwọn ohun ìní wọn fún ìtìlẹ́yìn tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí. (Òwe 3:9) Jèhófà kò ní gbàgbé ìfẹ́ wa àti iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Títí láé ni Jèhófà á máa rántí àwọn ohun tá a ṣe. Gbogbo ohun tá à ń gbé ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí fi hàn pé Jèhófà ń bù kún wa àti pé Kristi ló ń darí wa. Inú ètò tí mìmì kan ò lè mì, tó sì máa wà títí láé la wà. Torí náà, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn pé o wà lára àwọn èèyàn Jèhófà, kó o sì máa “fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run [rẹ].” (Sek. 6:15) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà lábẹ́ ààbò Ọba àti Àlùfáà Àgbà wa. Torí náà, máa sa gbogbo ipá rẹ láti ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àwọn ọmọ ogun máa bójú tó ẹ, á sì dáàbò bò ẹ́ jálẹ̀ ayé búburú yìí àti títí láé! w17.10 30 ¶18-19

Wednesday, April 24

Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo, kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn yóò lè gbà yín sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.​—Lúùkù 16:9.

Láìpẹ́ gbogbo ètò Sátánì máa forí ṣánpọ́n, ì báà jẹ́ ti ìṣèlú, ẹ̀sìn èké tàbí ètò ìṣòwò. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì àti Sefanáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wúrà àti fàdákà, ìyẹn ohun táwọn oníṣòwò kà sí pàtàkì kò ní wúlò mọ́ tó bá yá. (Ìsík. 7:19; Sef. 1:18) Báwo ló ṣe máa rí lára wa tó bá jẹ́ pé “ọrọ̀ àìṣòdodo” la fi gbogbo ayé wa kó jọ àmọ́ tá a wá pàdánù ọrọ̀ tòótọ́ nígbẹ̀yìn? Ṣe ló máa dà bí ẹni tó fi gbogbo ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ kó lè kówó jọ tìrìgàngàn àmọ́ tó wá rí i pé ayédèrú owó lòun ti fi gbogbo ayé òun kó jọ. (Òwe 18:11) Ohun tó dájú ni pé irú ọrọ̀ bẹ́ẹ̀ máa kùnà láìpẹ́. Torí náà, lo owó tó o ní láti bá Jèhófà àti Jésù dọ́rẹ̀ẹ́. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kò sóhun tá a ṣe láti kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run tó máa gbé, torí ohun tó máa jẹ́ ká ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà nìyẹn. w17.07 11 ¶16

Thursday, April 25

Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín.​—Éfé. 5:​1, 2.

Àwọn Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ torí pé wọn ò fẹ́ kí ojú ti àwọn tàbí torí kí wọ́n má bàa já àwọn míì kulẹ̀. (Òwe 28:13) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fìfẹ́ hàn, torí pé ó máa ṣàkóbá fún ẹni náà àtàwọn míì. Kódà, ó lè má jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìjọ, ó sì lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́. (Éfé. 4:30) Bí Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará lóòótọ́, á sọ ohun tó ṣe fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. (Ják. 5:​14, 15) Ìfẹ́ ni ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù. (1 Kọ́r. 13:13) Òun ló ń jẹ́ káwọn èèyàn dá wa mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá àti pé à ń fara wé Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Bí èmi kò bá ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.’ (1 Kọ́r. 13:2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé a ní ìfẹ́, kì í ṣe “ní ọ̀rọ̀” nìkan bí kò ṣe “ní ìṣe àti òtítọ́” pẹ̀lú.​—1 Jòh. 3:18. w17.10 11 ¶17-18

Friday, April 26

Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.​—Ìṣe 5:29.

Jósẹ́fù lo ìgboyà nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ kó bá òun sùn. Jósẹ́fù mọ̀ pé ojú òun á rí màbo tóun ò bá ṣe ohun tí obìnrin náà fẹ́. Síbẹ̀ ó lo ìgboyà, dípò tó fi máa gbà láti bá obìnrin náà sùn, ṣe ló já ara rẹ̀ gbà mọ́ ọn lọ́wọ́ tó sì sá lọ. (Jẹ́n. 39:​10, 12) Ẹlòmíì tó lo ìgboyà ni Ráhábù. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ amí wá sílé rẹ̀ ní Jẹ́ríkò, ìbẹ̀rù lè mú kó sọ pé òun ò ní lè gbà wọ́n sílé. Àmọ́ torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó lo ìgboyà, ó dáàbò bo àwọn ọkùnrin náà, ó sì mú kí wọ́n pa dà sílé láìséwu. (Jóṣ. 2:​4, 5, 9, 12-16) Àwọn àpọ́sítélì ò jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n nígbà táwọn Sadusí halẹ̀ mọ́ wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ kọ́ni nípa Jésù mọ́. (Ìṣe 5:​17, 18, 27-29) Ìgboyà tí Jósẹ́fù, Ráhábù, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ní ló jẹ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ rere. Kì í ṣe torí pé wọ́n jọ ara wọn lójú ni wọ́n ṣe nígboyà, kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Onírúurú nǹkan làwa náà ń kojú tó máa gba pé ká nígboyà. Dípò tá a fi máa gbára lé ara wa, ṣe ni ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.​—2 Tím. 1:⁠7. w17.09 29 ¶6-9

Saturday, April 27

Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.​—Kól. 3:9.

Ká sòótọ́, àtibọ́ àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kì í ṣe ohun téèyàn lè dá ṣe fúnra rẹ̀. Àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ sapá gan-an kí wọ́n tó lè fi àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀. Síbẹ̀ wọ́n ṣàṣeyọrí torí pé wọ́n jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. (Lúùkù 11:13; Héb. 4:12) Káwọn nǹkan yìí tó lè ran àwa náà lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì déédéé, ká máa ronú lé e lórí, ká sì máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ ká lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Jóṣ. 1:8; Sm. 119:97; 1 Tẹs. 5:17) Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa múra ìpàdé sílẹ̀, ká sì máa pésẹ̀ síbẹ̀ déédéé. (Héb. 10:​24, 25) Láfikún síyẹn, ó yẹ ká máa jadùn oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà pèsè fún wa lónírúurú ọ̀nà. (Lúùkù 12:42) Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ bọ́ àwọn ìwàkiwà sílẹ̀ pátápátá. Àmọ́, ṣé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa nìyẹn ká tó lè rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀? Rárá o. A tún gbọ́dọ̀ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.​—Kól. 3:10. w17.08 21 ¶16-17

Sunday, April 28

Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; jẹ́ kí ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ.​—Sm. 13:5.

Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn hùwà àìdáa sí Ọba Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtikékeré ni Jèhófà ti yàn án pé òun ló máa jọba, síbẹ̀ nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni Dáfídì fi dúró kó tó di ọba ní Júdà. (2 Sám. 2:​3, 4) Láàárín àkókò yìí, Ọba Sọ́ọ̀lù tó ti di aláìṣòótọ́ ń wá bó ṣe máa gbẹ̀mí Dáfídì. Èyí ló mú kí Dáfídì máa sá kiri nínú aginjù, àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó sá lọ sórílẹ̀-èdè míì. Kódà lẹ́yìn tí wọ́n pa Sọ́ọ̀lù lójú ogun, Dáfídì ṣì ní láti dúró fún odindi ọdún méje kó tó di ọba gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (2 Sám. 5:​4, 5) Kí nìdí tí Dáfídì fi mú sùúrù? Dáfídì gbà pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní kì í yẹ̀. Bí Dáfídì ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún un jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà máa dá òun nídè. (Sm. 13:6) Ó ṣe kedere pé Dáfídì gbà pé ó bọ́gbọ́n mu bí òun ṣe dúró de Jèhófà. w17.08 6 ¶14-15

Monday, April 29

Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.​—Ìṣe 10:34.

Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún ni èdè ń yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ kan táwọn èèyàn ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ ti nítumọ̀ míì lónìí. Ó ṣeé ṣe kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí èdè tìẹ náà. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí èdè Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìwé Bíbélì. Èdè Hébérù àti Gíríìkì táwọn èèyàn ń sọ nísinsìnyí yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ẹ̀dà tí wọ́n túmọ̀ ni gbogbo àwọn tó bá fẹ́ lóye Bíbélì máa kà, títí kan àwọn tó ń sọ èdè Hébérù àti Gíríìkì lóde òní. Àwọn kan rò pé á dáa káwọn kọ́ èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ káwọn lè ka Bíbélì tí wọ́n fi èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ. Àmọ́ kò pọn dandan. A dúpẹ́ pé Bíbélì ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000]. Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n” máa ka Bíbélì, kí wọ́n sì jàǹfààní nínú rẹ̀. (Ìṣí. 14:6) Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ pé kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa tó nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn dọ́gba-dọ́gba? w17.09 19 ¶4

Tuesday, April 30

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.​—Òwe 17:27.

Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan nínú ìdílé rẹ lẹ́gbẹ́, ó ṣe pàtàkì kó o kó ara rẹ níjàánu, kó má bàa di pé ò ń bá onítọ̀hún ṣe wọléwọ̀de. Kò rọrùn kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu nírú àwọn ipò yìí, àmọ́ wàá ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá gbà pé ohun tí Jèhófà ní kó o ṣe nìyẹn àti pé àpẹẹrẹ rẹ̀ lò ń tẹ̀ lé. Àpẹẹrẹ àtàtà kan tí Bíbélì sọ ni ti Ọba Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára wà lọ́wọ́ rẹ̀, kò ṣìwà hù nígbà tí Sọ́ọ̀lù àti Ṣíméì ṣe ohun tó dùn ún. (1 Sám. 26:​9-11; 2 Sám. 16:​5-10) Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì kò kó ara rẹ̀ níjàánu. A lè rántí ìgbà tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti ìgbà tó fẹ́ lọ pa gbogbo ilé Nábálì run. (1 Sám. 25:​10-13; 2 Sám. 11:​2-4) Síbẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Dáfídì. Àkọ́kọ́, àwọn alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n má bàa ṣi agbára wọn lò. Ìkejì ni pé kò yẹ káwa Kristẹni dá ara wa lójú jù, bíi pé a ò lè kó sínú ìdẹwò.​—1 Kọ́r. 10:12. w17.09 5-6 ¶12-13

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́