ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 26-36
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, March 1
  • Saturday, March 2
  • Sunday, March 3
  • Monday, March 4
  • Tuesday, March 5
  • Wednesday, March 6
  • Thursday, March 7
  • Friday, March 8
  • Saturday, March 9
  • Sunday, March 10
  • Monday, March 11
  • Tuesday, March 12
  • Wednesday, March 13
  • Thursday, March 14
  • Friday, March 15
  • Saturday, March 16
  • Sunday, March 17
  • Monday, March 18
  • Tuesday, March 19
  • Wednesday, March 20
  • Thursday, March 21
  • Friday, March 22
  • Saturday, March 23
  • Sunday, March 24
  • Monday, March 25
  • Tuesday, March 26
  • Wednesday, March 27
  • Thursday, March 28
  • Friday, March 29
  • Saturday, March 30
  • Sunday, March 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 26-36

March

Friday, March 1

Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.​—Fílí. 2:3.

Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ rẹ tó máa ń múnú bí ẹ? O lè má gba ti ẹni yẹn, tó ò bá sì ṣọ́ra, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú burúkú wò ó. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ń gba àwọn míì lálejò, àárín wa á túbọ̀ gún, kódà ó lè pẹ̀tù sọ́kàn àwọn tó dà bí ọ̀tá wa. (Òwe 25:​21, 22) Tá a bá ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sẹ́nì kan tó múnú bí wa, ó lè jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Ó sì lè jẹ́ ká rí àwọn ibi tẹ́ni náà dáa sí, ìyẹn àwọn nǹkan tí Jèhófà rí tó fi fa ẹni náà wá sínú òtítọ́. (Jòh. 6:44) Tá a bá fìfẹ́ pe ẹnì kan tí kò rò pé a lè pe òun wá sílé wa, ìyẹn lè jẹ́ ká dọ̀rẹ́, kí àárín wa sì wọ̀. Kí la lè ṣe tí ìfẹ́ náà á fi tọkàn wa wá? Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká fi ìmọ̀ràn ẹsẹ ìwé mímọ́ tòní sọ́kàn. Ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn ọ̀nà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gbà sàn jù wá lọ, ìyẹn á jẹ́ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìfaradà, ìgbàgbọ́, ìgboyà àtàwọn ànímọ́ Kristẹni míì tí wọ́n ní. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ wọn, á sì mú kó rọrùn fún wa láti gbà wọ́n lálejò. w18.03 17 ¶18-19

Saturday, March 2

[Jèhófà] kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.​—2 Pét. 3:9.

Ọ̀kan lára ohun tó máa ń le jù fáwọn òbí ni bí wọ́n ṣe máa ṣègbọràn sí Jèhófà tí wọ́n bá yọ ọmọ wọn lẹ́gbẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ìyá kan tí wọ́n yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́, tí ọmọ náà sì kúrò nílé. Ìyá yẹn sọ pé: “Mo máa ń wá àwọn ìtẹ̀jáde wa kí n lè rí ìsọfúnni tí màá fi kẹ́wọ́ pé òun ló mú kí n máa bá ọmọ mi àti ọmọ ọmọ mi sọ̀rọ̀. Àmọ́, ọkọ mi jẹ́ kí n mọ̀ pé ọwọ́ Jèhófà lọmọ wa wà, àti pé ó ṣì ń bá a wí lọ́wọ́, torí náà a ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó máa tako ìtọ́ni Jèhófà.” Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gba ọmọ náà pa dà. Ìyá yẹn sọ pé: “Ó bọ̀wọ̀ fún èmi àti ọkọ mi gan-an torí ó mọ̀ pé a ṣègbọràn sí Ọlọ́run.” Tó o bá ní ọmọ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, ṣé wàá “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,” àbí òye tìrẹ lo máa gbára lé? (Òwe 3:​5, 6) Torí náà, gbà pé ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà ló dáa jù. Kódà, tí ìbáwí náà bá tiẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìwọ òbí ọmọ náà, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni kó o ṣe. Má kọ ìbáwí Jèhófà sílẹ̀, ṣe ni kó o tẹ́wọ́ gbà á. w18.03 31 ¶12-13

Sunday, March 3

Ẹ lọ . . . kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

Bíbélì ò sọ bó ṣe yẹ kéèyàn dàgbà tó kó tó ṣèrìbọmi. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘sọ di ọmọ ẹ̀yìn’ nínú Mátíù 28:19 túmọ̀ sí pé ká kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ kó lè di ọmọ ẹ̀yìn. Ọmọ ẹ̀yìn lẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jésù, tó lóye ohun tó kọ́, tó sì ń fi ẹ̀kọ́ náà sílò. Torí náà, ohun tó yẹ kó jẹ àwọn òbí lógún jù ni bí wọ́n ṣe máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré, kí wọ́n lè ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Òótọ́ ni pé ọmọ tó ṣì kéré gan-an ò lè ṣèrìbọmi, síbẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọdé lè lóye òtítọ́, kí wọ́n sì mọyì rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àtikékeré ni Tímótì ti mọyì òtítọ́. Èyí mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an. (2 Tím. 1:5; 3:​14, 15) Nígbà tó máa fi pé nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, ó ti tẹ̀ síwájú débi pé ó tóótun fún àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ.​—Ìṣe 16:​1-3. w18.03 9 ¶4-5

Monday, March 4

Kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́.​—Éfé. 4:23.

Nígbà tá a di ìránṣẹ́ Ọlọ́run, a ṣe àwọn àyípadà kan. Àwọn àyípadà yẹn sì yí ìgbésí ayé wa pa dà pátápátá. Kódà, lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi a ṣì ń ṣe àwọn àyípadà kan. Torí pé a kì í ṣe ẹni pípé, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ ní ìgbésí ayé wa. (Fílí. 3:​12, 13) Yálà ọmọdé ni wá àbí àgbàlagbà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe báyìí fi hàn pé mo túbọ̀ ń dẹni tẹ̀mí? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó ń hùwà bíi Kristi? Ṣé bí mo ṣe ń hùwà nípàdé fi hàn pé ẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí ni mí? Kí làwọn nǹkan tí mo máa ń sọ fi hàn nípa irú nǹkan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí? Ṣé mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, tí wọ́n bá sì gbà mí nímọ̀ràn, báwo ló ṣe máa ń rí lára mi? Kí ni aṣọ àti ìmúra mi ń sọ nípa irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an? Tí mo bá kojú àdánwò, kí ni mo máa ń ṣe? Ṣé òye mi ti kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ṣé mo sì ti di géńdé Kristẹni tó ní òye kíkún nípa Jèhófà?’ (Éfé. 4:13) Ìdáhùn wa sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí àbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀. w18.02 24 ¶4-5

Tuesday, March 5

Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!​—Sm. 144:15.

Àkókò tá à ń gbé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà ń kó àwọn èèyàn jọ, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Àwọn tá a kó jọ yìí ti di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè,” wọ́n ju mílíọ̀nù mẹ́jọ lọ, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.” (Ìṣí. 7:​9, 15; Aísá. 60:22) Kò tíì sí ìgbà kankan nínú ìtàn ẹ̀dá táwọn èèyàn tó pọ̀ tó báyìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn bíi tiwọn. Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àsìkò wa yìí, àwọn tí kò mọ Ọlọ́run máa ní ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn . . . , àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tím. 3:​1-4) Irú ìfẹ́ yìí yàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa fi hàn síra wa, kódà òdìkejì rẹ̀ ni. Àwọn tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan kì í láyọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù wọ́n pé kí wọ́n láyọ̀. Ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan yìí ló jẹ́ kí ayé di èyí “tí ó nira láti bá lò.” w18.01 22 ¶1-2

Wednesday, March 6

Àwọn tí ń wá Jèhófà lè lóye ohun gbogbo.​—Òwe 28:5.

Ìmọ̀ tó péye tí Nóà ní mú kó nígbàgbọ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Ìmọ̀ tó ní yìí ni kò jẹ́ kó ṣe ohun tó máa múnú bí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Ìdí nìyẹn tí kò fi bá àwọn èèyàn búburú rìn tí kò sì bá wọn kẹ́gbẹ́. Kò jẹ́ káwọn áńgẹ́lì burúkú tó sọ ara wọn di èèyàn yẹn tan òun jẹ bí wọ́n ṣe tan àwọn aláìgbọ́n jẹ. Ṣe làwọn èèyàn ń kan sárá sáwọn áńgẹ́lì yẹn torí agbára wọn àtohun tí wọ́n ń ṣe, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n máa jọ́sìn wọn. (Jẹ́n. 6:​1-4, 9) Yàtọ̀ síyẹn, Nóà mọ̀ pé àwọn èèyàn ni Ọlọ́run súre fún pé kí wọ́n bímọ kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì. (Jẹ́n. 1:​27, 28) Torí náà, ó mọ̀ pé ìbálòpọ̀ láàárín àwọn áńgẹ́lì tó sọ ara wọn di èèyàn àtàwọn obìnrin ò tọ̀nà, kò sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Èyí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ. Nígbà tó yá, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé òun máa mú Ìkún Omi wá sórí ilẹ̀ ayé. Ìgbàgbọ́ tí Nóà ní pé ohun tí Ọlọ́run sọ máa ṣẹ mú kó kan ọkọ̀ áàkì, òun àti ìdílé rẹ̀ sì la Ìkún Omi yẹn já.​—Héb. 11:7. w18.02 9 ¶8

Thursday, March 7

Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́.​—1 Kọ́r. 15:10.

Tó o bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kọ́fẹ pa dà. Àmọ́ o, ìwọ náà gbọ́dọ̀ tọ àwọn alàgbà lọ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Òwe 24:16; Ják. 5:​13-15) Torí náà, má jáfara, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ìyè àìnípẹ̀kun lo fi ń ṣeré yẹn! Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn rẹ ṣì ń dá ẹ lẹ́bi lẹ́yìn tí Jèhófà ti dárí jì ẹ́, kí lo lè ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tó bá ń rántí àwọn ìwà àìdáa tó ti hù sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Èmi ni mo kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì, èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 15:9) Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn lo ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá, tó o gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀, tó o sì tún sọ fáwọn alàgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ lọ́rùn mọ́. Torí náà, gbà pé Jèhófà ti dárí jì ẹ́ pátápátá!​—Aísá. 55:​6, 7. w18.01 11 ¶17-18

Friday, March 8

Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.​—Ják. 4:8.

Èyí gba pé kó o máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀, kó o sì máa tẹ́tí sóhun tóun náà ń bá ẹ sọ. Ọ̀nà pàtàkì kan tó o lè gbà máa tẹ́tí sí Jèhófà ni pé kó o máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Ìyẹn ni pé kó o máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó ò ń kà. Bó o ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́, máa fi sọ́kàn pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò dà bí ìgbà tó ò ń kàwé torí àtiyege nínú ìdánwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ dà bíi pé ṣe lò ń rìnrìn-àjò, tó o sì ń wọ̀tún-wòsì kó o lè rí àwọn nǹkan tuntun. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí, á jẹ́ kó o lè túbọ̀ mọ àwọn ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ní, wàá tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà, òun náà á sì sún mọ́ ẹ. Ètò Ọlọ́run ti pèsè àwọn ohun tó máa jẹ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó nítumọ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórí ìkànnì jw.org/yo ni àrànṣe kan tá a pè ní Atọ́nà Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń mú kó rọrùn láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?” Tó o bá ń lo àwọn àrànṣe yìí dáadáa, á jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú.​—Sm. 119:105. w17.12 25 ¶8-9

Saturday, March 9

Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi.​—Aísá. 11:9.

Bíbélì sọ ìdí tí àwọn ẹranko ẹhànnà àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ á fi jọ máa gbé pọ̀, ó ní “ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” Níwọ̀n bí àwọn ẹranko ò ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, á jẹ́ pé àwa èèyàn ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ń ṣẹ sí lára (Aísá. 11:​6, 7) Ọ̀pọ̀ tó ń hùwà ẹhànnà bíi ti ìkookò tẹ́lẹ̀ ló ti wá dẹni pẹ̀lẹ́ báyìí. O lè ka ìrírí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” tó wà lórí ìkànnì jw.org/⁠yo. Àwọn kan tó ń hùwà ẹhànnà tẹ́lẹ̀ ti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfé. 4:​23, 24) Báwọn èèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń rídìí tó fi yẹ káwọn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í yí èrò wọn, ìwà wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ pa dà. Àwọn ìyípadà yẹn ò rọrùn, àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. w18.01 31 ¶15-16

Sunday, March 10

Olúkúlùkù [ni a óò mú wà láàyè] ní ẹgbẹ́ tirẹ̀.​—1 Kọ́r. 15:23.

Nígbà tí Bíbélì ń sọ bí àjíǹde ti ọ̀run ṣe máa rí, ó sọ pé àwọn tó ń lọ sọ́run á jíǹde “olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀.” Ó dá wa lójú pé àwọn tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé náà máa jíǹde ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ẹ wo bíyẹn ṣe máa wúni lórí tó. Àmọ́, ṣé àwọn tó kú ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ló máa kọ́kọ́ jíǹde táwọn èèyàn tó mọ̀ wọ́n á sì kí wọn káàbọ̀? Ṣé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ máa tètè jíǹde kí wọ́n lè darí àwọn èèyàn nínú ayé tuntun? Àwọn tí ò sin Jèhófà rárá ńkọ́? Ìgbà wo ni wọ́n máa jíǹde, ibo ni wọ́n sì máa jíǹde sí? Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló wà. Àmọ́ ká sòótọ́, ṣó yẹ ká máa yọ ara wa lẹ́nu báyìí nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ àtèyí tí kò ní ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ kò ní dáa ká kúkú dúró de ohun tí Jèhófà máa ṣe? Jèhófà fi dá wa lójú nípasẹ̀ Jésù pé àwọn òkú tó wà ní ìrántí òun máa jíǹde. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára.​—Jòh. 5:​28, 29; 11:23. w17.12 12 ¶20-21

Monday, March 11

Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo.​—Kól. 3:​18-20.

Kò sí àní-àní pé táwọn ọkọ, àwọn aya àtàwọn ọmọ bá ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, á ṣe wọ́n láǹfààní. Bíbélì gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” Tí ọkọ kan bá ń tẹ́tí sí ìyàwó rẹ̀, tó sì jẹ́ kó dáa lójú pé òun mọyì rẹ̀, ṣe ni irú ọkọ bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun, òun sì bọ̀wọ̀ fún un. (1 Pét. 3:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí ìyàwó kan bá sọ ni ọkọ rẹ̀ máa ṣe, síbẹ̀ tí ọkọ kan bá ń fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó rẹ̀, ìpinnu tó bá ṣe máa nítumọ̀. (Òwe 15:22) Ọkọ tó bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ kò ní fi dandan sọ pé kí ìyàwó òun bọ̀wọ̀ fún òun, kàkà bẹ́ẹ̀ tó bá mọyì ìyàwó rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ á túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un. Tí ọkọ kan bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn á mú kí gbogbo wọn túbọ̀ máa fayọ̀ sin Jèhófà, wọ́n á sì rí èrè ọjọ́ iwájú náà gbà. w17.11 28 ¶12; 29 ¶15

Tuesday, March 12

Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo . . . ayé.​—Kól. 2:8.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Kólósè ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn. (Kól. 1:9) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí ni mo ń wí, kí ènìyàn kankan má bàa fi àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà mọ̀ọ́mọ̀ ṣì yín lọ́nà. Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kól. 2:​4, 8) Pọ́ọ̀lù wá sọ ìdí táwọn èrò tàbí ìrònú tó gbayé kan nígbà yẹn kò fi tọ̀nà àti ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi fara mọ́ àwọn èrò yẹn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìrònú bẹ́ẹ̀ máa ń mú káwọn èèyàn rò pé àwọn gbọ́n tàbí pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ. Torí náà, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n kíyè sára, kó má bàa di pé wọ́n fàyè gba àwọn èrò yìí àtàwọn àṣà tí kò yẹ.​—Kól. 2:​16, 17, 23. w17.11 20 ¶1

Wednesday, March 13

Bí ọwọ́ rẹ tàbí ẹsẹ̀ rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.​—Mát. 18:8.

Kí ló yẹ kí Kristẹni kan yááfì tó bá fẹ́ kí Jèhófà máa fàánú hàn sóun? Ó gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan ọ̀hún lè sún un dẹ́ṣẹ̀. (Mát. 18:9) Tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fẹ́ kó o ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra, ṣé wàá yẹra fún wọn? Tó bá jẹ́ pé o sábà máa ń ṣàṣejù nídìí ọtí, ṣé wàá ṣì máa lọ sáwọn ibi tó o mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó o ti mu ọtí lámujù? Tó bá sì jẹ́ pé èròkerò ló sábà máa ń wá sí ẹ lọ́kàn, ṣé wàá yẹra fáwọn fíìmù, ìkànnì orí íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn nǹkan míì tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ? Ká rántí pé ohunkóhun tá a bá yááfì ká lè rí ojúure Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kò sóhun tó dunni tó kí Jèhófà pa èèyàn tì. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kò sóhun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó kí Jèhófà fi “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” hàn síni títí lọ fáàbàdà.​—Aísá. 54:​7, 8. w17.11 11 ¶12

Thursday, March 14

Èyí ni ègún tí ń jáde lọ . . . , nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń jalè . . . ti lọ láìfara gba ìyà.​—Sek. 5:3.

Sekaráyà 5:​3, 4 sọ pé ‘ègún náà yóò wọnú ilé olè, yóò sì wọ̀ sí àárín ilé rẹ̀, yóò sì pa á run pátápátá.’ Ó túmọ̀ sí pé kò sóhun tó lè dènà ìdájọ́ Ọlọ́run. Ibi yòówù kí ìránṣẹ́ Jèhófà ti hu ìwàkíwà, kódà kó jẹ́ inú òkùnkùn, ìdájọ́ Ọlọ́run máa bá a. Ó ṣeé ṣe kéèyàn jalè kó sì fi bò fún àwọn aláṣẹ, àwọn agbanisíṣẹ́, àwọn alàgbà tàbí òbí. Àmọ́ kò sóhun tó bò lójú Jèhófà, torí ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àṣírí gbogbo olè máa tú. (Héb. 4:13) Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa jù ni pé ká má kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ “nínú ohun gbogbo”! (Héb. 13:18) Ọ̀nà yòówù kéèyàn gbà jalè àti ohun yòówù kéèyàn jí, ó dájú pé Jèhófà kórìíra olè jíjà. Ohun tó dáa jù ni pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, ká máa hùwà tó bójú mu, ká má sì kẹ́gàn bá orúkọ rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní jẹ lára ìyà tí Jèhófà fi máa jẹ àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ tẹ òfin rẹ̀ lójú. w17.10 22 ¶6-7

Friday, March 15

Kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.​—Éfé. 4:3.

Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ṣì wá lóye tàbí wọ́n ṣàìdáa sí wa. (Róòmù 12:​17, 18) A lè yanjú ọ̀rọ̀ yẹn tá a bá bẹ ẹni náà pé kó má bínú, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ wá látọkàn. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn tọkọtaya máa wá àlàáfíà. Kò yẹ kí wọ́n máa ṣe bíi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn níta, àmọ́ kí wọ́n wá máa bára wọn yan odì nínú ilé, tàbí kí wọ́n máa bú ara wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa lu ara wọn. A gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, ó yẹ ká dárí jì í, ká sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán síbẹ̀. Tó bá jẹ́ lóòótọ́ la dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, a ò ní máa ronú nípa ohun tí wọ́n ṣe sí wa, torí pé ìfẹ́ kì í “kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́r. 13:​4, 5) Tá a bá ń di àwọn ará wa sínú, àárín wa ò ní gún, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sì lè bà jẹ́.​—Mát. 6:​14, 15. w17.10 10 ¶14-15

Saturday, March 16

Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ni ó rán mi sí yín.​—Sek. 6:15.

Àǹfààní wo ni ọ̀rọ̀ Sekaráyà ṣe àwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀? Jèhófà mú kó dá wọn lójú pé òun máa dáàbò bò wọ́n àti pé wọ́n máa kọ́ ilé náà parí. Ó dájú pé ohun tí Sekaráyà sọ fún wọn yẹn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ṣùgbọ́n, báwo làwọn kéréje yẹn ṣe máa ṣe iṣẹ́ ńlá yìí? Ọ̀rọ̀ tí Sekaráyà sọ lẹ́yìn ìyẹn mú kó dá wọn lójú pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ náà yọrí. Jèhófà sọ fún wọn pé láfikún sáwọn olóòótọ́ bíi Hélídáì, Tóbíjà àti Jedáyà, àwọn èèyàn púpọ̀ ṣì máa “wá, . . . wọn yóò sì kọ́ lára tẹ́ńpìlì Jèhófà.” Níwọ̀n bó ti dá àwọn Júù yẹn lójú pé Jèhófà wà lẹ́yìn àwọn, kíá ni wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé náà láìfi àtakò ọba Páṣíà pè. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Jèhófà sọ ìṣòro tó dà bí òkè di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ náà kúrò, wọ́n sì parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà lọ́dún 515 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ẹ́sírà 6:22; Sek. 4:​6, 7) Àmọ́, ọ̀rọ̀ Jèhófà kọjá ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó kan ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí. w17.10 29 ¶17

Sunday, March 17

Jẹ́ onígboyà . . . kí o sì gbé ìgbésẹ̀.​—1 Kíró. 28:20.

Jèhófà gbéṣẹ́ ńlá kan fún Sólómọ́nì, ó ní kó bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn, ìyẹn kíkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Bíbélì ròyìn pé ilé yẹn máa jẹ́ “ọlọ́lá ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá ní ti ìtayọ alẹ́wàlógo ní gbogbo àwọn ilẹ̀.” Ohun tó mú kí ilé náà túbọ̀ tayọ ni pé ó jẹ́ “ilé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́.” (1 Kíró. 22:​1, 5, 9-11) Ọba Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà máa ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn, àmọ́ ọ̀dọ́ ni Sólómọ́nì, kò sì ní ìrírí. Ṣó máa lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà yanjú? Àbí bó ṣe jẹ́ ọ̀dọ́ àti aláìnírìírí yẹn máa mú kó nira fún un? Ohun kan ni pé, bí Sólómọ́nì bá máa ṣe iṣẹ́ náà yanjú, ó ṣe pàtàkì pé kó nígboyà, kó sì gbé ìgbésẹ̀. Bí Sólómọ́nì kò bá nígboyà, iṣẹ́ náà máa kà á láyà, kò sì ní lè ṣe é yanjú. Ẹ ò rí i pé ìyẹn á burú gan-an! Bíi ti Sólómọ́nì, àwa náà máa nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ká lè nígboyà, ká sì lè ṣe iṣẹ́ tó gbé fún wa yanjú. w17.09 28 ¶1-2; 29 ¶4-5

Monday, March 18

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.​—Aísá. 40:8.

Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ì bá ṣe rí ká ní kò sí Bíbélì? Kò ní sí ìtọ́sọ́nà kankan tí wàá máa tẹ̀ lé. O ò ní rí àlàyé èyíkéyìí nípa Ọlọ́run, nípa bó ṣe yẹ kó o máa gbé ìgbé ayé rẹ àti nípa ọjọ́ iwájú. Bákan náà, kò sí bó o ṣe máa mọ ohun tí Jèhófà ti ṣe fún aráyé nígbà àtijọ́. A dúpẹ́ pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí torí pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún jẹ́ kó dá wa lójú pé títí láé ni Ọ̀rọ̀ òun máa wà. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pétérù fa ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 40:8 yọ. Ẹsẹ yìí lè tọ́ka sí Bíbélì bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Bíbélì lódindi ni Pétérù ní lọ́kàn. (1 Pét. 1:​24, 25) Abájọ tó fi jẹ́ pé láti ọ̀pọ̀ ọdún wá làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè míì, kí wọ́n sì pín in kiri. Ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe, ìyẹn ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”​—1 Tím. 2:​3, 4. w17.09 18 ¶1-2

Tuesday, March 19

Aya rẹ̀ ni ọ́. Nítorí náà, báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?​—Jẹ́n. 39:9.

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń kojú irú àdánwò tí Jósẹ́fù kojú. (Jẹ́n. 39:7) Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kim. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ló máa ń ṣèṣekúṣe, tí wọ́n bá wá dé iléèwé, wọ́n á máa fọ́nu nípa bí wọ́n ṣe gbádùn ara wọn ní òpin ọ̀sẹ̀. Àmọ́ Kim ní tiẹ̀ kì í rí nǹkan sọ tí wọ́n bá ti dá ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀. Ó sọ pé bóun ò ṣe rẹ́ni fojú jọ láàárín wọn máa ń jẹ́ kó dà bíi pé “kò sẹ́ni tó rí tòun rò àti pé òun dá wà.” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tún máa ń fojú ọ̀dẹ̀ wò ó torí kò lẹ́ni tó ń fẹ́. Kim mọ̀ pé téèyàn bá wà lọ́dọ̀ọ́, ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, torí náà ó pinnu pé òun kò ní yan ọ̀rẹ́kùnrin. (2 Tím. 2:22) Àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ máa ń bi í pé ṣé lóòótọ́ ni kò tíì mọ ọkùnrin. Á wá lo àǹfààní yẹn láti ṣàlàyé ìdí tóun kò fi tíì ní ìbálọ̀pọ̀. Àmúyangàn ni ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa jẹ́ bẹ́ ò ṣe jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe, Jèhófà sì mọyì yín pẹ̀lú! w17.09 4 ¶8; 5 ¶10

Wednesday, March 20

Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.​—Sm. 37:8.

Àwọn tó máa ń tètè bínú sábà máa ń bú èébú tí inú bá ń bí wọn. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ìdílé tòrò. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká yẹra fún ìbínú, ọ̀rọ̀ èébú àti ìlọgun. (Éfé. 4:31) Ìkìlọ̀ yìí bọ́gbọ́n mu torí pé àwọn ìwà yìí sábà máa ń fa wàhálà, wọ́n sì máa ń dá ìjà sílẹ̀. Àwọn èèyàn inú ayé ò rí ohun tó burú nínú kéèyàn máa bínú, àmọ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa. Ọ̀pọ̀ wa ti sapá gan-an láti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a sì ti gbé ìwà tuntun wọ̀. (Kól. 3:​8-10) Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ èébú, irọ́ pípa wà lára àwọn ìwà àtijọ́ tó yẹ ká yẹra fún. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn sábà máa ń parọ́ kí wọ́n má bàa san owó orí tàbí kí wọ́n má bàa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fẹ́ kí gbogbo àwa olùjọ́sìn rẹ̀ máa “bá aládùúgbò [wa] sọ òtítọ́,” ká má sì “máa purọ́.” (Éfé. 4:25; Kól. 3:9) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ kódà tí òtítọ́ náà ò bá bára dé tàbí tó bá máa kó ìtìjú bá wa.​—Òwe 6:​16-19. w17.08 18 ¶3, 5; 20 ¶12-13, 15

Thursday, March 21

Ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré.​—Sm. 147:15.

Lónìí, Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré” ní ti pé ó máa ń tọ́ wa sọ́nà ní gbogbo ìgbà tá a bá nílò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, à ń jàǹfààní gan-an bá a ṣe ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣe jáde. A tún ń jàǹfààní bá a ṣe ń wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW, tá à ń lọ sórí ìkànnì jw.org, tá à ń bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ àti nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará wa. (Mát. 24:45) Ṣé ìwọ náà kíyè sí i pé Jèhófà tètè máa ń fún wa láwọn ìtọ́sọ́nà tá a nílò lásìkò? Onísáàmù náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì gan-an. Àwọn nìkan ni Ọlọ́run fún ní “ọ̀rọ̀” rẹ̀ àtàwọn “ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀.” (Sm. 147:​19, 20) Lóde òní, Jèhófà dá wa lọ́lá ní ti pé àwa nìkan là ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn. Torí pé a mọ Jèhófà, a sì ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù 147, ǹjẹ́ àwa náà ní ìdí tó pọ̀ láti máa “yin Jáà,” ká sì máa rọ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? w17.07 20 ¶15-16; 21 ¶18

Friday, March 22

Kò sí ènìyàn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí ń kó wọnú àwọn iṣẹ́ òwò ìgbésí ayé, kí ó bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun.​—2 Tím. 2:4.

Lónìí, gbogbo àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà lókè yìí sílò, títí kan àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Wọn ò jẹ́ kí onírúurú ìpolówó ọjà àtàwọn nǹkan míì táyé ń gbé lárugẹ mú kí wọ́n máa lépa ọrọ̀, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí sọ́kàn pé: ‘Ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’ (Òwe 22:7) Ohun tí Sátánì fẹ́ ká ṣe ni pé ká máa fi gbogbo ayé wa lépa bá a ṣe máa rí towó ṣe. Ohun táwọn kan ṣe ti mú kí wọ́n tọrùn bọ gbèsè tó gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọdún láti san. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń yáwó ní báǹkì fi kọ́lé, àwọn míì sì ń yáwó fi lọ sílé ìwé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ń yáwó torí kí wọ́n lè ra mọ́tò olówó gọbọi tàbí kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó táyé gbọ́ tọ́run mọ̀. A lè fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n tá a bá jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, tá ò tọrùn bọ gbèsè, tá a sì ń ra kìkì ohun tá a nílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé Ọlọ́run là ń sìnrú fún kì í ṣe ètò ìṣòwò inú ayé yìí.​—1 Tím. 6:10. w17.07 10 ¶13

Saturday, March 23

Mo ka gbogbo àṣẹ ìtọ́ni nípa ohun gbogbo sí èyí tí ó tọ̀nà; Gbogbo ipa ọ̀nà èké ni mo kórìíra.​—Sm. 119:128.

Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso ayé àtọ̀run torí pé ó máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé; nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ní inú dídùn sí.” (Jer. 9:24) Kì í ṣe òfin táwọn èèyàn aláìpé gbé kalẹ̀ ni Jèhófà ń wò kó tó pinnu ohun tó tọ́. Òun fúnra rẹ̀ ló máa ń pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ torí pé onídàájọ́ òdodo ni, ìdí nìyẹn tó fi gbé òfin kalẹ̀ fáwa èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ [rẹ̀],” torí náà ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo òfin àti ìlànà tó fún wa ló tọ̀nà. (Sm. 89:14) Lọ́wọ́ kejì, pẹ̀lú gbogbo atótónu Sátánì pé ìṣàkóso Jèhófà ò dáa, títí di báyìí, àìṣòdodo ló kún inú ayé Sátánì. w17.06 28 ¶5

Sunday, March 24

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, . . . ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ . . . òtítọ́.​—2 Sám. 7:28.

Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́. (Sm. 31:5) Torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó máa ń jẹ́ káwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ mọ òtítọ́ inú Bíbélì. Àtìgbà tí wọ́n ti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ la ti ń ṣìkẹ́ àwọn ohun tá à ń kọ́, ì bá à jẹ́ látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, àwọn àpéjọ àgbègbè àti àyíká, tàbí láwọn ìpàdé ìjọ. Bá a ṣe ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ látìgbà yẹn la ti ní ohun tí Jésù pè ní “ibi ìtọ́jú ìṣúra,” ibẹ̀ la sì ń kó àwọn òtítọ́ tá a mọ̀ sí, yálà ògbólógbòó tàbí tuntun. (Mát. 13:52) Tá a bá ń wá àwọn òtítọ́ náà kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti gba àwọn òtítọ́ tuntun tó ṣeyebíye sínú “ibi ìtọ́jú ìṣúra” wa. (Òwe 2:​4-7) Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe bẹ́ẹ̀? A gbọ́dọ̀ máa dá kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa ṣe ìwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde wa. Èyí ló máa jẹ́ ká ṣàwárí àwọn òtítọ́ tá a lè pè ní “tuntun” torí pé a ò lóye wọn tẹ́lẹ̀. (Jóṣ. 1:​8, 9; Sm. 1:​2, 3) Torí náà, ó yẹ kó máa yá wa lára láti wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ kí òtítọ́ tó wà nínú ìṣúra wa lè pọ̀ sí i. w17.06 12 ¶13-14

Monday, March 25

Ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.​—Jer. 29:12.

Ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò tíì ṣègbéyàwó lọ bá alàgbà kan tó ti ṣègbéyàwó. Ó ṣe díẹ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin náà ti ń ronú lórí ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:28 tó sọ pé: “Àwọn tí wọ́n [ṣègbéyàwó] yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” Ọ̀dọ́kùnrin náà wá bi alàgbà yẹn pé: “Kí ni ‘ìpọ́njú’ tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ, báwo sì ni màá ṣe kojú rẹ̀ tí n bá gbéyàwó?” Kí alàgbà náà tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó sọ fún ọ̀dọ́kùnrin náà pé kó ronú lórí ọ̀rọ̀ kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́r. 1:​3, 4) Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń tù wá nínú tá a bá níṣòro. Ìwọ náà lè rántí àwọn ìgbà tí Jèhófà ti ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó sì tọ́ ẹ sọ́nà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dá wa lójú pé ire wa ni Jèhófà ń fẹ́ bó ṣe fẹ́ ire fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà àtijọ́.​—Jer. 29:11. w17.06 4 ¶1-2

Tuesday, March 26

Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn àtìpó.​—Sm. 146:9.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará wa tó ń wá ibi ìsádi nílò àwọn nǹkan ìní tara, síbẹ̀ ohun tí wọ́n nílò jù lọ ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì tún fà wọ́n mọ́ra. (Mát. 4:4) Àwọn alàgbà lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa rí ìtẹ̀jáde gbà lédè wọn, kí wọ́n sì tún kàn sí àwọn ará tó ń sọ èdè wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ibi ìsádi ni kò sí pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sí ládùúgbò àti ìjọ tí wọ́n ti mọ̀ dáadáa. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìdí ni pé tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí àwọn ará ìlú wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:33) Tá a bá jẹ́ kí ara wọn mọlé dáadáa nínú ìjọ, ṣe làwa náà ń fìwà jọ Jèhófà tó ń dáàbò bo àwọn àjèjì. Ó lè ṣòro fáwọn tó ń wá ibi ìsádi láti pa dà sílùú wọn torí pé àwọn tó ń fa wàhálà náà ṣì ń ṣàkóso. Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Tó bá jẹ́ èmi ni irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, báwo ni màá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí mi?’​—Mát. 7:12. w17.05 6 ¶15-16

Wednesday, March 27

Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.​—Mát. 24:12.

Tá a bá jẹ kí ìrẹ̀wẹ̀sì borí wa, ìgbàgbọ́ wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, èyí sì lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run di tútù. Nínú ayé búburú tí Sátánì ń darí yìí, gbogbo wa pátá la máa ń kojú ìṣòro. (1 Jòh. 5:19) Ìṣòro táwọn kan lára wa ń kojú ni ara tó ń dara àgbà, àìlówó lọ́wọ́ àti àìsàn. Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan tàbí kí ohun tá à ń fẹ́ má tẹ̀ wá lọ́wọ́, ó sì lè jẹ́ pé àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa ló ń mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ìṣòro yìí mú ká ronú pé Jèhófà ti fi wá sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ronú lórí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa. Ìwé Sáàmù 136:23 sọ nípa Jèhófà pé: “Ó rántí wa nínú ipò rírẹlẹ̀ wa: nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ohun tó dájú ni pé, Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀ torí pé ìfẹ́ tó ní fáwa ìránṣẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀. Torí náà, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń dáhùn àdúrà wa.​—Sm. 116:1; 136:​24-26. w17.05 18 ¶8

Thursday, March 28

Bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.​—Mát. 6:15.

Bí Bíbélì ṣe sọ ni Gálátíà 2:​11-14, ìbẹ̀rù èèyàn ló mú kí Pétérù ṣe àṣìṣe. (Òwe 29:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù mọ̀ pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba àwọn tí kì í ṣe Júù, síbẹ̀ kò fẹ́ káwọn Júù tó wá láti ìjọ ní Jerúsálẹ́mù fojú burúkú wo òun, torí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn tí kì í ṣe Júù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò ó lójú, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ìwà àgàbàgebè ló hù yẹn. (Ìṣe 15:12; Gál. 2:13) Ó dájú pé Pétérù fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí Pọ́ọ̀lù fún un. A ò sì rí i nínú Ìwé Mímọ́ pé Pétérù pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní. Kódà nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí Pétérù láti kọ lẹ́tà méjì tó wá di apá kan Bíbélì. Jésù, tó jẹ́ orí ìjọ ṣì ń lo Pétérù nínú ìjọ. (Éfé. 1:22) Èyí fún àwọn ará náà láǹfààní láti fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìdáríjì, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fara wé Jésù àti Bàbá rẹ̀. A nígbàgbọ́ pé kò sẹ́ni tó jẹ́ kí àṣìṣe ọkùnrin tó jẹ́ aláìpé yìí mú òun kọsẹ̀. w17.04 27 ¶16-18

Friday, March 29

Nípa sísọ àwọn ìlú ńlá náà Sódómù àti Gòmórà di eérú, [Ọlọ́run] dá wọn lẹ́bi, ní fífi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.​—2 Pét. 2:6.

Jèhófà pa àwọn èèyàn ìlú náà run, ó sì fòpin sí ìwàkiwà wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún tipa bẹ́ẹ̀ fi “àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.” Bí Jèhófà ṣe fòpin sí gbogbo ìwàkiwà táwọn èèyàn ìgbà yẹn hù jẹ́ kó dá wa lójú pé á fòpin sí ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù lóde òní nígbà tó bá pa ayé búburú yìí run. Kí ló máa rọ́pò ìwàkiwà? Iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ làá máa ṣe nínú Párádísè. Ẹ wo bí inú wa ti máa dùn tó bá a ṣe ń sọ ayé di Párádísè, tá à ń kọ́lé fúnra wa àti fáwọn èèyàn wa. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa nígbà tá a bá ń kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀, tá a sì ń kọ́ wọn nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ti ṣe fáráyé. (Aísá. 65:​21, 22; Ìṣe 24:15) Ojoojúmọ́ làá máa ṣe àwọn ohun táá máa múnú wa dùn, táá sì máa fògo fún Jèhófà! w17.04 12 ¶11-12

Saturday, March 30

Ẹni tí ó bá ń jáde bọ̀, tí ó jáde wá láti àwọn ilẹ̀kùn ilé mi . . . yóò di ti Jèhófà.​—Oníd. 11:31.

Nígbà ti Jẹ́fútà jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí, ó lè ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ọmọ òun náà ló máa jáde wá pàdé òun. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá, torí pé ó máa gba pé káwọn méjèèjì yááfì ohun kan. Nígbà tí Jẹ́fútà rí ọmọbìnrin rẹ̀, ṣe ló ‘fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya’ ó sì sọ pé ọ̀rọ̀ náà kó ẹ̀dùn ọkàn bá òun. Ọmọbìnrin náà wá lọ “sunkún lórí ipò wúńdíá” rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jẹ́fútà kò lọ́mọ ọkùnrin, ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó ní yìí kò sì ní lọ́kọ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé á bímọ. Torí náà, bí Jẹ́fútà kò ṣe ní lọ́mọ-ọmọ túmọ̀ sí pé orúkọ ìdílé rẹ̀ lè pa rẹ́. Àmọ́, kì í ṣe ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́fútà sọ pé: ‘Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí i pa dà.’ Ọmọ náà wá fèsì pé: “Ṣe sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ti ẹnu rẹ jáde.” (Oníd. 11:​35-39) Kò sí àní-àní pé adúróṣinṣin làwọn méjèèjì, ohun tó sì wà lọ́kàn wọn ni bí wọ́n ṣe máa mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Ọlọ́run Olódùmarè ṣẹ, láìka ohun tó máa ná wọn sí.​—Diu. 23:​21, 23; Sm. 15:4. w17.04 4 ¶5-6

Sunday, March 31

Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn.​—Míkà 7:7.

Jósẹ́fù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù náà ní ẹ̀mí ìdúródeni. Wọ́n hùwà ìkà tó burú jáì sí i. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á sóko ẹrú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. Lẹ́yìn náà, ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ parọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀, wọ́n sì tìtorí ẹ̀ jù ú sẹ́wọ̀n. (Jẹ́n. 39:​11-20; Sm. 105:​17, 18) Ibi ni wọ́n fi ń san gbogbo rere tó ń ṣe, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ dípò kí wọ́n máa yìn ín. Ọdún mẹ́tàlá [13] lẹ́yìn náà, gbogbo nǹkan yí pa dà bìrí. Wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n sì sọ ọ́ di igbá kejì Ọba Íjíbítì. (Jẹ́n. 41:​14, 37-43; Ìṣe 7:​9, 10) Ṣé ìwà ìkà tí wọ́n hù sí Jósẹ́fù mú kó di àwọn èèyàn náà sínú? Ṣẹ́yẹn mú kí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà jó rẹ̀yìn? Rárá. Kí ló mú kí Jósẹ́fù lè fi sùúrù dúró de Jèhófà? Ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà ló jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ̀. Èyí hàn nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀ sọ, ó ní: “Ní tiyín, ẹ ní ibi lọ́kàn sí mi. Ọlọ́run ní in lọ́kàn fún rere, fún ète ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ti òní yìí, láti pa àwọn ènìyàn púpọ̀ mọ́ láàyè.” (Jẹ́n. 50:​19, 20) Kò sí àní-àní pé Jósẹ́fù gbà pé ó bọ́gbọ́n mu bí òun ṣe dúró de Jèhófà. w17.08 4 ¶6; 6 ¶12-13

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́