ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 17-26
  • February

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • February
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Friday, February 1
  • Saturday, February 2
  • Sunday, February 3
  • Monday, February 4
  • Tuesday, February 5
  • Wednesday, February 6
  • Thursday, February 7
  • Friday, February 8
  • Saturday, February 9
  • Sunday, February 10
  • Monday, February 11
  • Tuesday, February 12
  • Wednesday, February 13
  • Thursday, February 14
  • Friday, February 15
  • Saturday, February 16
  • Sunday, February 17
  • Monday, February 18
  • Tuesday, February 19
  • Wednesday, February 20
  • Thursday, February 21
  • Friday, February 22
  • Saturday, February 23
  • Sunday, February 24
  • Monday, February 25
  • Tuesday, February 26
  • Wednesday, February 27
  • Thursday, February 28
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 17-26

February

Friday, February 1

Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.​—Jẹ́n. 6:22.

Torí pé Nóà ò tíì kan ọkọ̀ rí, ó gbára lé Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, kódà Bíbélì ní: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Nóà rí ọkọ̀ náà kàn, ó sì gba gbogbo ìdílé rẹ̀ là. Yàtọ̀ síyẹn, Nóà tún tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ yanjú. Kí ló jẹ́ kó ṣàṣeyọrí? Ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé ó máa fún òun ní ọgbọ́n tóun nílò. Àwọn ọmọ Nóà gbẹ̀kọ́ torí pé òun náà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn, ìyẹn ò sì rọrùn rárá nínú ayé burúkú tó ṣáájú Ìkún Omi yẹn. (Jẹ́n. 6:5) Báwo lẹ̀yin òbí náà ṣe lè “ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” lójú Jèhófà? Ẹ máa tẹ́tí sí Jèhófà. Ẹ máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa fi àwọn ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa sílò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí kan máa ń sapá gan-an, síbẹ̀ àwọn ọmọ wọn ṣì máa ń fi Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́, àwọn òbí tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí òtítọ́ lè wọ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì máa ń retí pé lọ́jọ́ kan, ọmọ àwọn máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. w18.03 30 ¶10-11

Saturday, February 2

Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.​—1 Pét. 4:9.

Ṣé ó máa ń wù ẹ́ láti gbàlejò àmọ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé kì í ṣe irú ẹ ló ń gbàlejò? Àwọn kan máa ń tijú, wọ́n sì máa ń ronú pé kò sí nǹkan táwọn máa bá ẹni náà sọ. Àwọn míì ò lówó lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń ronú pé àwọn ò lè tọ́jú àlejò bíi tàwọn míì nínú ìjọ. Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé, kì í ṣe bí ilé wa ṣe rẹwà tó ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe pé kó wà ní mímọ́, kó bójú mu, kó sì tuni lára. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, á rọrùn fún wa láti gbà wọ́n lálejò, a ò sì ní máa ṣàníyàn. Ká rántí pé ohun tó dáa jù ni pé ká jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn àlejò wa jẹ wá lógún. (Fílí. 2:4) Ọ̀pọ̀ wa la máa ń fẹ́ sọ àwọn ìrírí tá a ti ní fáwọn míì. Torí náà, ó lè jẹ́ ìgbà tá a bá gbàlejò tàbí tá a lọ kí àwọn èèyàn làwọn míì máa lè gbọ́ àwọn ìrírí wa. Alàgbà kan sọ pé: “Tí mo bá gba àwọn míì nínú ìjọ lálejò, ó máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ mọ̀ wọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì máa ń jẹ́ kí n mọ bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn àlejò wa, gbogbo wa la máa gbádùn ara wa. w18.03 17 ¶15-17

Sunday, February 3

Èé ti ṣe tí ìwọ fi ń jáfara? Dìde, kí a batisí rẹ.​—Ìṣe 22:16.

Àwọn òbí Kristẹni máa ń fẹ́ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run lè bà jẹ́ téèyàn bá ń fi ìrìbọmi falẹ̀ láìnídìí tàbí tó ń fòní-dónìí fọ̀la-dọ́la. (Ják. 4:17) Síbẹ̀, àwọn òbí máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ti ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn Kristẹni máa ṣe kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Àwọn alábòójútó àyíká kan sọ pé àwọn máa ń rí àwọn ọ̀dọ́ kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kí wọ́n ti lé lógún ọdún síbẹ̀ tí wọn ò tíì ṣèrìbọmi bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tọ́ wọn dàgbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ náà máa ń lọ sípàdé déédéé, wọ́n ń lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì gbà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Síbẹ̀ fáwọn ìdí kan, wọn ò fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Kí ló fà á? Nígbà míì, àwọn òbí wọn ló máa ń sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe sùúrù díẹ̀ ná kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. w18.03 8 ¶1-2

Monday, February 4

Ní . . . ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.​—Róòmù 15:5.

Tá a bá fẹ́ dà bíi Kristi, ó ṣe pàtàkì ká mọ bí Kristi ṣe ń ronú ká sì mọ ohun tó máa ṣe lábẹ́ ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Bí Jésù ṣe máa wu Ọlọ́run lohun tó jẹ ẹ́ lógún. Torí náà, tá a bá fìwà jọ Jésù, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ronú bí Jésù ṣe ń ronú. Kí láá mú ká lè ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fojú rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, wọ́n gbọ́ ìwàásù rẹ̀, wọ́n rí bó ṣe fìfẹ́ bá onírúurú èèyàn lò àti bó ṣe ń fi ìlànà Ọlọ́run sílò. (Ìṣe 10:39) Lóòótọ́ àwa ò lè rí Jésù, àmọ́ Jèhófà ti fún wa láwọn ìwé Ìhìn Rere tó jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an, ìyẹn sì mú kó dà bíi pé a wà pẹ̀lú rẹ̀. Tá a bá ń ka àwọn ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà, ṣe là ń mú èrò wa bá ti Kristi mu. Èyí á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí,” ká sì ní “èrò orí kan náà” tí Kristi ní.​—1 Pét. 2:21; 4:1. w18.02 22 ¶15-16

Tuesday, February 5

Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.​—Róòmù 10:17.

Látìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwọn èèyàn, ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni pé wọ́n máa ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Ọ̀nà kejì, wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ àwọn míì tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀nà kẹta sì ni bí wọ́n ṣe ń rí ìbùkún Ọlọ́run torí pé wọ́n ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. (Aísá. 48:18) Bí Nóà ṣe ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa mọ̀. Kì í ṣe pé ó máa gbà pé Ọlọ́run wà nìkan ni, ó tún máa mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá ò lè rí bí “agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Torí náà, ó ṣe kedere pé kì í ṣe pé Nóà kàn gbà pé Ọlọ́run wà nìkan ni, ó tún nígbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀. Ó dájú pé Nóà ti gbọ́ nípa Jèhófà látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Lámékì bàbá Nóà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì bá Ádámù láyé. Àwọn míì tó tún jẹ́ mọ̀lẹ́bí Nóà ni Mètúsélà bàbá rẹ̀ àgbà àti baba ńlá rẹ̀ tó ń jẹ́ Járédì, kódà ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìndínláàádọ́rin [366] ọdún ni Nóà nígbà tí Járédì kú. (Lúùkù 3:​36, 37) Bó ti wù kó rí, àwọn ohun tí Nóà kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ó sì pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn.​—Jẹ́n. 6:9. w18.02 9 ¶4-5

Wednesday, February 6

Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.​—Éfé. 4:26.

Tí ará kan tàbí mọ̀lẹ́bí wa bá ṣẹ̀ wá, ó máa ń dùn wá wọ eegun. Tó bá nira fún wa láti gbàgbé ọ̀rọ̀ náà ńkọ́? Ṣó wá yẹ ká di ẹni náà sínú fún ọ̀pọ̀ ọdún? Ǹjẹ́ kò ní dáa ká tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà? Bí ọ̀rọ̀ náà bá ṣe ń pẹ́ nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa nira fún wa láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin wa. Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo lè gbé táá jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín yín? Àkọ́kọ́, rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà. Ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ahọ́n tútù bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀. Rántí pé ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà ni arákùnrin náà, Jèhófà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Sm. 25:14) Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ohun tó fẹ́ káwa náà máa ṣe nìyẹn. (Òwe 15:23; Mát. 7:12; Kól. 4:6) Ohun kejì ni pé kó o ronú dáadáa nípa ohun tó o fẹ́ bá arákùnrin náà sọ. Má ṣe ronú pé ńṣe ni arákùnrin náà mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀ ẹ́, fi sọ́kàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ náà dá kún ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín. w18.01 10 ¶15-16

Thursday, February 7

Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, . . . kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.​—Jòh. 13:34.

Àwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn ayé torí pé àwa máa ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sáwọn èèyàn. Ohun tá a mọ àwa èèyàn Jèhófà mọ́ nìyẹn látọjọ́ tó ti pẹ́. Jésù sọ pé ìfẹ́ aládùúgbò ni òfin kejì tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin Mósè lẹ́yìn ìfẹ́ fún Ọlọ́run tó jẹ́ àkọ́kọ́. (Mát. 22:​38, 39) Jésù tún sọ pé ìfẹ́ ni wọ́n máa fi dá àwọn ojúlówó Kristẹni mọ̀. (Jòh. 13:35) Kódà, àwọn Kristẹni máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Mát. 5:​43, 44) Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Ó ń lọ láti ìlú kan sí òmíì, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ó la ojú afọ́jú, ó mú àwọn arọ, adẹ́tẹ̀ àti adití lára dá. Kódà, ó jí òkú dìde. (Lúùkù 7:22) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ torí aráyé. Jésù ṣàgbéyọ ìfẹ́ Jèhófà Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Lọ́nà kan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn níbi gbogbo láyé. w18.01 29-30 ¶11-12

Friday, February 8

Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.​—Fílí. 4:13.

Ó lè jẹ́ pé o ṣì kéré nígbà tó o ṣèrìbọmi. Àmọ́, òní la rí kò sẹ́ni tó mọ̀la, o ò mọ ìpèníjà tó lè dé lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, o gbọ́dọ̀ máa rántí pé o ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bí iná ń jó, bí ìjì ń jà, ìfẹ́ Jèhófà ni wàá ṣe. Lédè míì, ohun tó o sọ ni pé o ò ní fi Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé àti Ọ̀run sílẹ̀, kódà bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn òbí rẹ kò bá sin Jèhófà mọ́. (Sm. 27:10) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀. (Fílí. 4:​11, 12) Jèhófà fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun. Àmọ́ tó ò bá fẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ ìwọ àti Jèhófà já, tó o sì fẹ́ ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí, o gbọ́dọ̀ sapá gan-an. Ìwé Fílípì 2:12 sọ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” Torí náà, o gbọ́dọ̀ máa ronú bí àárín ìwọ àti Jèhófà á ṣe túbọ̀ gún régé tí wàá sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i láìka ìṣòro yòówù kó yọjú. Má ṣe dá ara rẹ lójú pé mìmì kan ò lè mì ọ́. Rántí pé a rí àwọn kan tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ tí wọ́n di aláìṣòótọ́. w17.12 24 ¶4, 6-7

Saturday, February 9

Èmi, ní tèmi, ti fínnú-fíndọ̀ fún ọ ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí.​—1 Kíró. 29:17.

Jèhófà buyì kún wa bó ṣe fún wa láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ àgbàyanu yìí. Ó jẹ́ kó dá wa lójú pé a máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà tá a bá ń ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn. (Mál. 3:10) Jèhófà ti ṣèlérí pé ẹni tó jẹ́ ọ̀làwọ́ kò ní ṣaláìní láé, torí wọ́n máa ń sọ pé òkè òkè lọwọ́ afúnni ń gbé. (Òwe 11:​24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, a máa láyọ̀ tá a bá ń fúnni torí pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Torí náà, àwọn ọmọ wa àtàwọn ẹni tuntun gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa fi owó àtàwọn nǹkan míì ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn àti pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wọ́n máa rí tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní. Tá a bá fún un lára àwọn ohun ìní wa, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì mọyì gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa. Nígbà táwọn èèyàn ń ṣe ọrẹ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì, “àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ lórí ṣíṣe tí wọ́n ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe.” (1 Kíró. 29:9) Torí náà, ẹ jẹ́ kí inú tiwa náà máa dùn bá a ṣe ń mú nínú àwọn nǹkan tí Jèhófà fún wa, tá a sì fi ń ta á lọ́rẹ. w18.01 21 ¶18-19

Sunday, February 10

Olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.​—1 Kọ́r. 15:23.

Àjíǹde àkọ́kọ́ máa wáyé lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ tí “wíwàníhìn-ín” Kristi bẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró tó wà láàyè nígbà ìpọ́njú ńlá ni “a ó gbà lọ dájúdájú nínú àwọsánmà.” (1 Tẹs. 4:​13-17; Mát. 24:31) “A óò yí gbogbo [wọn] padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.” (1 Kọ́r. 15:​51, 52) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni lónìí ni kì í ṣe ẹni àmì òróró, torí náà wọn ò ní lọ sọ́run láti bá Kristi ṣàkóso. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń retí ìgbà tí ayé búburú yìí máa wá sópin rẹ̀ ní “ọjọ́ Jèhófà.” Kò sẹ́ni tó mọ ìgbà tí òpin ayé yìí máa dé gan-an, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé kò ní pẹ́ mọ́. (1 Tẹs. 5:​1-3) Lẹ́yìn náà, àjíǹde kan tó yàtọ̀ máa wáyé, ìyẹn àjíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn tó jíǹde máa di pípé, wọn ò sì ní kú mọ́. w17.12 11 ¶15; 12 ¶18-19

Monday, February 11

Níbi tí owú àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà.​—Ják. 3:16.

Tá a bá jẹ́ onínúure, tá a sì ń fìfẹ́ bá àwọn míì lò, a ò ní máa jowú wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú.” (1 Kọ́r. 13:4) Tá a bá ń fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará wa wò wọ́n, tá a sì gbà pé ọmọ ìyá ni gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ, a ò ní máa jowú wọn. Ìyẹn á mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àá sì máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, tó sọ pé: “Bí a bá ṣe ẹ̀yà ara kan lógo, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a yọ̀.” (1 Kọ́r. 12:​16-18, 26) Torí náà, ṣe ló yẹ ká máa bá ẹni tó ṣàṣeyọrí yọ̀ dípò ká máa jowú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jónátánì ọmọ Ọba Sọ́ọ̀lù. Kò jowú nígbà tí Jèhófà yan Dáfídì láti jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fún Dáfídì níṣìírí. (1 Sám. 23:​16-18) Ṣé àwa náà lè máa fìfẹ́ àti inú rere hàn bíi ti Jónátánì? w17.11 27 ¶10-11

Tuesday, February 12

Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́. Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà.​—Aísá. 11:​3, 4.

Jèhófà rí i pé Òfin Mósè wà nínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀. Kò fẹ́ ká máa rin kinkin mọ́ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ inú Òfin yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ ká lóye “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ,” ìyẹn àwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ òfin náà, ó sì fẹ́ ká máa fi wọ́n sílò. (Mát. 23:23) Òfin Mósè ṣàgbéyọ “kókó ìmọ̀ àti ti òtítọ́” nípa Jèhófà àtàwọn ìlànà òdodo rẹ̀. (Róòmù 2:20) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlú ààbò kọ́ àwọn alàgbà nípa bí wọ́n ṣe lè máa “fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́,” ó sì jẹ́ kí gbogbo wa mọ bá a ṣe lè máa ṣe “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú sí ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Sek. 7:9) Òótọ́ ni pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ Jèhófà kò yí pa dà, ó ṣì jẹ́ Ọlọ́run aláàánú àti onídàájọ́ òdodo. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni pé à ń jọ́sìn Ọlọ́run tó dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, torí náà a lè fìwà jọ ọ́, ká sì rí ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀! w17.11 13-14 ¶2-3; 17 ¶18-19

Wednesday, February 13

Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀.​—Òwe 3:13.

Àwọn arákùnrin tó ń kọ́ni lórí pèpéle ní láti rí i dájú pé orí Ìwé Mímọ́ ni àsọyé wọ́n dá lé. (Jòh. 7:16) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Má ṣe jẹ́ kí ìrírí, àpèjúwe tàbí ọ̀nà tó o gbà sọ àsọyé rẹ gba àfiyèsí àwùjọ ju àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o kà lọ. Bákan náà, ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Bíbélì àti kéèyàn fi Bíbélì kọ́ni. Ká sòótọ́, bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà bá ti pọ̀ jù, àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ lè má rí nǹkan kan dì mú. Torí náà, fara balẹ̀ yan àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà. Lẹ́yìn náà, kà á lọ́nà tó nítumọ̀, ṣàlàyé rẹ̀, ṣàkàwé rẹ̀, kó o sì jẹ́ kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀. (Neh. 8:8) Tí wọ́n bá ní kó o sọ àsọyé, rí i pé o lóye ìwé àsọyé náà àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ inú rẹ̀. Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ṣe tan mọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́.​—Ẹ́sírà 7:10. w17.09 26 ¶11-12

Thursday, February 14

Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.​—Sek. 1:3.

Ọdún ayọ̀ ni ọdún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà. Ìdí sì ni pé ọdún yẹn ni wọ́n kúrò nígbèkùn Bábílónì lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún tí wọ́n ti wà níbẹ̀. Inú wọn dùn gan-an lẹ́yìn tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tó di ọdún 536 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀. Ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kọjá, iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà ṣì wà bó ṣe wà. Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn Ọlọ́run nílò ẹni tó máa ta wọ́n jí, kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí wọ́n sì ṣíwọ́ àtimáa fi ìfẹ́ tara wọn ṣáájú. Jèhófà rán wòlíì Sekaráyà sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́dún 520 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni kó lè rán wọn létí ìdí tí òun fi dá wọn nídè kúrò ní Bábílónì. Ó ṣe tán, orúkọ Sekeráyà túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Rántí,” ìyẹn á sì jẹ́ káwọn èèyàn náà rántí ohun kan tó ṣe pàtàkì. Ohun náà ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ti gbàgbé ìdí tí Jèhófà fi dá wọn nídè, Jèhófà ní tiẹ̀ kò gbàgbé wọn. (Sek. 1:​3, 4) Ó jẹ́ kó dá wọn lójú pé òun máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn òun, àmọ́ ó jẹ́ kó ṣe kedere sí wọn pé òun kò ní gba ìjọsìn àfaraṣe-má-fọkàn-ṣe. w17.10 21-22 ¶2-3

Friday, February 15

Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.​—Éfé. 4:32.

Àwọn dókítà sọ pé téèyàn bá ń fàánú hàn, á ní ìlera tó dáa, àárín òun àtàwọn míì á sì gún régé. Tó o bá ń ṣàánú àwọn èèyàn, wàá láyọ̀, o ò ní kárísọ, wàá ní alábàárò, o ò sì ní máa ro èrò òdì. Ká sòótọ́, wàá jàǹfààní tó o bá ń fàánú hàn. Àwọn Kristẹni tó máa ń fìfẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, torí wọ́n mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ làwọn ń ṣe. Téèyàn bá lójú àánú, á jẹ́ òbí rere, ọkọ tàbí aya tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, á sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ṣeé finú hàn. Ó ṣe tán, béèyàn bá da omi síwájú, á tẹlẹ̀ tútù, lọ́nà kan náà, ẹni bá ń ṣàánú àwọn èèyàn náà máa rí àánú gbà. (Mát. 5:7; Lúùkù 6:38) Kì í ṣe torí ká lè rí àánú gbà nìkan la ṣe ń fàánú hàn sáwọn èèyàn. Ìdí pàtàkì tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ fara wé Jèhófà, Ọlọ́run àánú àti ìfẹ́, a sì fẹ́ máa bọlá fún un. Òun ló fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti fara wé e, ká máa fìfẹ́ bá àwọn ará wa lò lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ká sì máa fàánú hàn sáwọn aládùúgbò wa.​—Òwe 14:31. w17.09 12 ¶16-17

Saturday, February 16

Yóò sì ṣàkóso lórí ìtẹ́ rẹ̀, òun yóò sì di àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀.​—Sek. 6:13.

Yàtọ̀ sí pé Jésù jẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà, Jèhófà tún yàn án pé kó “kọ́ tẹ́ńpìlì” òun. Lóde òní, lára iṣẹ́ ìkọ́lé tí Jésù ń ṣe ni bó ṣe dá àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá, tó sì mú ìjọ Kristẹni pa dà bọ̀ sípò lọ́dún 1919. Ó tún yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” sípò láti máa bójú tó iṣẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe ní apá ti ilẹ̀ ayé nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí. (Mát. 24:45) Kódà, ohun tí Jésù ń ṣe báyìí ni pé ó ń yọ́ àwa èèyàn Jèhófà mọ́ kí ìjọsìn wa lè túbọ̀ jẹ́ mímọ́. (Mál. 3:​1-3) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, òun àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa mú káwọn olóòótọ́ di pípé. Lẹ́yìn ìyẹn, kìkì àwọn tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà nìkan ló máa kù nínú ayé tuntun. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìjọsìn tòótọ́ á wá gbilẹ̀! w17.10 29 ¶15-16

Sunday, February 17

Kí ó sì máa gbé nínú [ìlú ààbò rẹ̀] títí di ìgbà ikú àlùfáà àgbà.​—Núm. 35:25.

Ìgbésẹ̀ pàtàkì kan wà tó yẹ kẹ́ni tó ṣèèṣì pààyàn gbé kó tó lè rí àánú gbà. Ó gbọ́dọ̀ sá lọ sí ìlú ààbò tó sún mọ́ ọn jù lọ. (Jóṣ. 20:4) Kì í ṣe ìgbà yẹn lẹni náà á máa yan fanda kiri. Tí kò bá tètè sá lọ sílùú ààbò, kó sì dúró síbẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ lè lọ sí i. Èyí gba pé kó yááfì àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, ó máa fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, á fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kò sì ní kúrò nílùú ààbò yẹn títí tí àlùfáà àgbà fi máa kú. Àmọ́ àwọn ohun tó yááfì tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kí Kristẹni kan tó ronú pìwà dà tó lé rí àànú Ọlọ́run gbà, ó gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan. Lóòótọ́ ó gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, àmọ́ ó tún gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké tó lè mú kéèyàn dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Tá a bá sapá láti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, a sì mọyì àánú tó fi hàn sí wa.​—2 Kọ́r. 7:​10, 11. w17.11 10-11 ¶10-11

Monday, February 18

Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn.​—1 Pét. 4:9.

Jèhófà sọ pé ká lawọ́ sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (1 Jòh. 3:17) Síbẹ̀, kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ torí ohun tá a máa rí gbà lọ́wọ́ wọn. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Àwọn wo ni mo máa ń gbà lálejò? Ṣé àwọn tó sún mọ́ mi àbí àwọn tó gbajúmọ̀ àtàwọn tí mo lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn ni mo máa ń gbà lálejò? Ṣé mo máa ń lawọ́ sáwọn ará tá ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra àtàwọn tí kò ní lọ́wọ́?’ (Lúùkù 14:​12-14) Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ká sọ pé ìṣòro bá Kristẹni kan torí pé ó ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Ṣé wàá ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Tàbí kẹ̀, kí ni wàá ṣe tẹ́nì kan tó o gbà lálejò kò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ? Ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní sílò. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀ torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe lò ń ṣe.​—Ìṣe 20:35. w17.10 9 ¶12

Tuesday, February 19

Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?​—Jẹ́n. 39:9.

Ìyàwó Pọ́tífárì ń fa ojú Jósẹ́fù mọ́ra torí pé ó dáa lọ́mọkùnrin, ó sì dùn-ún wò. Àmọ́, Jósẹ́fù ò kó sínú ìdẹwò yìí. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dójú ẹ̀, ṣe ni Jósẹ́fù sá kúrò lọ́dọ̀ obìnrin náà. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù? Ó lè gba pé ká sá tá ò bá fẹ́ rú òfin Ọlọ́run. (Òwe 1:10) Bí àpẹẹrẹ, kí àwọn kan tó di Ẹlẹ́rìí, wọ́n jẹ́ alájẹkì, ọ̀mùtí, amusìgá, ajoògùnyó, oníṣekúṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà lẹ́yìn tí wọ́n ṣèrìbọmi, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n tún lọ́wọ́ sáwọn ìwà yẹn. Tírú ẹ̀ bá wá sí ẹ lọ́kàn, ronú lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà tí o kò bá kóra rẹ níjàánu tó o sì ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Á dáa kó o ronú lórí àwọn ipò tó lè dẹ ẹ́ wò, kó o sì yẹra fún àwọn ipò náà. (Sm. 26:​4, 5; Òwe 22:3) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé o kojú ìdẹwò, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o lè kóra rẹ níjàánu. w17.09 4-5 ¶8-9

Wednesday, February 20

Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo, kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn yóò lè gbà yín sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.​—Lúùkù 16:9.

Ọ̀nà kan tá a lè gbà bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́ ni pé ká má ṣe tara bọ ètò ìṣòwò ayé yìí, dípò bẹ́ẹ̀, ká máa fayé wa àtohun tá a ní wá ọrọ̀ tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù, bàbá ìgbàgbọ́ fi ilẹ̀ Úrì tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù sílẹ̀, ó sì ń gbé nínú àgọ́ bí Jèhófà ṣe sọ fún un, ìyẹn sì mú kó dọ̀rẹ́ Jèhófà. (Héb. 11:​8-10) Ọlọ́run ló gbẹ́kẹ̀ lé, kò sì fìgbà kan wá bó ṣe máa kó ọrọ̀ jọ torí tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nìyẹn. (Jẹ́n. 14:​22, 23) Irú ìgbàgbọ́ yẹn ni Jésù rọ̀ wá pé ká ní nígbà tó ń sọ fún ọ̀dọ́kùnrin kan tó lówó pé: “Bí ìwọ bá fẹ́ jẹ́ pípé, lọ ta àwọn nǹkan ìní rẹ, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Mát. 19:21) Ọ̀dọ́kùnrin yẹn kò nírú ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní. Àmọ́ àwọn míì wà tó nírú ìgbàgbọ́ yẹn. w17.07 10 ¶12

Thursday, February 21

[Jèhófà] ṣèlérí láti fi [ilẹ̀ náà] fún [Ábúráhámù] gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, àti lẹ́yìn rẹ̀ fún irú-ọmọ rẹ̀, nígbà tí kò tíì ní ọmọ kankan.​—Ìṣe 7:5.

Nǹkan bí irínwó ó lé ọgbọ̀n [430] ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù sọdá Yúfírétì ni Ọlọ́run tó sọ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di orílẹ̀-èdè kan, táá gba Ilẹ̀ Ìlérí náà. (Ẹ́kís. 12:​40-42; Gál. 3:17) Ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà ló jẹ́ kó ní sùúrù. (Héb. 11:​8-12) Tayọ̀tayọ̀ ni Ábúráhámù fi dúró de Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí ló ṣẹ lójú rẹ̀. Ẹ wo bí inú Ábúráhámù ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé! Á yà á lẹ́nu pé àwọn ibi tí wọ́n ti sọ ìtàn ìgbésí ayé òun àti tàwọn àtọmọdọ́mọ òun pọ̀ gan-an nínú Bíbélì. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó bá mọ̀ pé òun kó ipa ribiribi nínú bí Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa mú irú-ọmọ kan jáde! Ó dájú pé inú rẹ̀ á dùn pé òun dúró de Jèhófà. w17.08 5-6 ¶10-11

Friday, February 22

Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti . . . ìwà àìmọ́.​—Kól. 3:5.

Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a tú sí “ìwà àìmọ́” kọjá ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe nìkan. Ó kan mímu sìgá àti ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn. (2 Kọ́r. 7:1; Éfé. 5:​3, 4) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń tọ́ka sí àwọn ìwàkiwà míì tẹ́nì kan lè máa hù ní ìkọ̀kọ̀, irú bíi kó máa ka ìwé tó ń mú kọ́kàn fà sí ìṣekúṣe tàbí kó máa wo ìwòkuwò, èyí sì lè mú kẹ́ni náà máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Àwọn tí ìwòkuwò ti di bárakú fún máa ń ní “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo,” èyí sì lè mú kí wọ́n jingíri sínú ìṣekúṣe. Ìwádìí fi hàn pé bí ọkàn àwọn ọ̀mùtí àtàwọn tó ń lo oògùn olóró ṣe máa ń fà sí ìmukúmu, bẹ́ẹ̀ náà lọkàn àwọn tó ń wo ìwòkuwò ṣe máa ń fà sí àwòrán ìṣekúṣe. Ó ṣe kedere pé ohun tí ìwòkuwò máa ń yọrí sí kò dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í níyì lójú ara wọn, wọn kì í jára mọ́ṣẹ́, ilé wọn kì í sábà tòrò, ìgbéyàwó wọn lè tú ká, kódà wọ́n lè gbẹ̀mí ara wọn. w17.08 19 ¶8-9

Saturday, February 23

Nítorí pé ó ti sọ ọ̀pá ìdábùú àwọn ẹnubodè rẹ di alágbára; ó ti bù kún àwọn ọmọ rẹ ní àárín rẹ. Ó fi àlàáfíà sí ìpínlẹ̀ rẹ.​—Sm. 147:​13, 14.

Nígbà tí onísáàmù náà ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ó sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. Ó dájú pé ọkàn onísáàmù náà máa balẹ̀ pé Jèhófà á dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀! Àwọn ìṣòro rẹ lè mú kó o máa ṣàníyàn. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa fún ẹ lọ́gbọ́n táá jẹ́ kó o fara dà á. Onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé, “ó ń fi àsọjáde rẹ̀ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé; ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré.” Ó tún sọ pé Jèhófà máa ń ‘fúnni ní ìrì dídì, ó ń tú ìrì dídì wínníwínní ká, ó sì ń ju omi dídì.’ Lẹ́yìn náà ló béèrè pé: “Ta ní lè dúró níwájú òtútù rẹ̀?” Ó tún wá sọ pé Jèhófà ń “rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde, ó sì ń yọ́ wọn.” (Sm. 147:​15-18) Jèhófà Ọlọ́run wa ló lágbára jù lọ láyé àtọ̀run, òun ló sì gbọ́n jù, òun ló ń darí ìrì dídì tàbí yìnyín. Torí náà, ìṣòro yòówù ká ní, Jèhófà lágbára láti bá wa ṣẹ́gun wọn, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. w17.07 20 ¶14-15

Sunday, February 24

Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo.​—Ìṣí. 4:11.

Ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà ń gbà ṣàkóso àti pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dáa jù. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. Torí pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso gbogbo èèyàn àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì. Sátánì ò dá ohunkóhun. Torí náà, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Ìwà ọ̀yájú gbáà ni òun àti tọkọtaya àkọ́kọ́ hù bí wọ́n ṣe tako ìṣàkóso Jèhófà. (Jer. 10:23) Òótọ́ ni pé ẹ̀dá tó lómìnira ni wọ́n, àmọ́ ṣé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀? Rárá o. Lóòótọ́, òmìnira tí ẹ̀dá èèyàn ní lè jẹ́ kí wọ́n yan ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Àmọ́, ìyẹn ò ní kí wọ́n kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá wọn. Ó ṣe kedere pé, wọ́n ṣi òmìnira wọn lò bí wọ́n ṣe kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, abẹ́ ìṣàkóso Jèhófà ló yẹ kí gbogbo èèyàn pátápátá fi ara wọn sí. w17.06 27-28 ¶2-4

Monday, February 25

Bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà.​—Ìṣe 20:24.

Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, táwa náà bá mọyì iṣẹ́ ìwàásù, àá máa wàásù nìṣó láìka àtakò sí. (Ìṣe 14:​19-22) Láwọn ọdún 1930 àti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1940, àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kojú ọ̀pọ̀ àtakò àti inúnibíni. Àmọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù, wọ́n dúró gbọin láìyẹsẹ̀, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. Ká lè gbèjà ẹ̀tọ́ tá a ní láti wàásù, àwọn arákùnrin máa ń lọ sí kóòtù. Lọ́dún 1943, Arákùnrin Nathan H. Knorr sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ẹjọ́ tá a jàre ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó ní: “Ẹ̀yin lẹ jẹ́ ká jàre àwọn ẹjọ́ yìí. . . . Ìdúróṣinṣin àwọn èèyàn Ọlọ́run ló mú kí wọ́n dá wa láre.” Torí náà, ó ṣe kedere pé tá ò bá jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù di tútù, a máa borí àtakò. Tá a bá ka iṣẹ́ ìwàásù sí ìṣúra tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún wa, kì í ṣe wákàtí tá a fẹ́ ròyìn níparí oṣù ló máa ṣe pàtàkì jù sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.” 2 Tím. 4:5. w17.06 11-12 ¶11-12

Tuesday, February 26

Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.​—Mát. 22:37.

Tí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run bá jinlẹ̀, èyí á mú ká máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, ká lẹ́mìí ìfaradà, ká sì kórìíra ohun búburú. (Sm. 97:10) Àmọ́, Sátánì àti ayé búburú yìí fẹ́ mú ká dẹra nù, kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lè di tútù. Èrò tí kò tọ́ làwọn èèyàn inú ayé ní nípa ìfẹ́. Kàkà kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn, Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tím. 3:2) Ohun tí ayé Sátánì sì ń gbé lárugẹ ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòh. 2:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara gbà wọ́n lọ́kàn, ó ní: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú . . . nítorí pé gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Róòmù 8:​6, 7) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìjákulẹ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó ń fi ìgbésí ayé wọn lé nǹkan tara àtàwọn tó fẹ́ràn ìṣekúṣe.​—1 Kọ́r. 6:18; 1 Tím. 6:​9, 10. w17.05 18 ¶5-6

Wednesday, February 27

Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.​—2 Tẹs. 3:10.

Táwọn ará tó ń wá ibi ìsádi bá lẹ́mìí ìmoore, tí wọn ò sì máa béèrè tibí béèrè tọ̀hún, ó dájú pé inú àwọn ará tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ máa dùn. Ká sòótọ́, kì í rọrùn tó bá jẹ́ pé ojú àwọn míì là ń wò ká tó lè rí àwọn nǹkan tá a nílò. Ìdí nìyẹn tó fi dáa káwọn tó ń wá ibi ìsádi wá bí wọ́n á ṣe máa ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fúnra wọn. Èyí á jẹ́ kí wọ́n níyì, káwọn ará sì bọ̀wọ̀ fún wọn. (2 Tẹs. 3:​7-9) Síbẹ̀, wọ́n ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Kò dìgbà tá a bá lówó rẹpẹtẹ ká tó ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tí wọ́n nílò jù ni àkókò wa àti ìgbatẹnirò tá a bá fi hàn sí wọn. Ó lè jẹ́ àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ la máa ṣe fún wọn, bíi ká jẹ́ kí wọ́n mọ bá a ṣe ń wọkọ̀ èrò. A lè mú wọn lọ sọ́jà tí wọ́n á ti ra oúnjẹ aṣaralóore tí kò wọ́n. Bákan náà, a lè mú wọn lọ síbi tí wọ́n á ti ra àwọn irinṣẹ́ bíi maṣíìnì ìránṣọ tàbí àwọn irinṣẹ́ míì tó lè máa mówó wọlé fún wọn. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ara wọn lè mọlé níjọ tuntun tí wọ́n wà. Tó bá ṣeé ṣe, a lè máa gbé wọn lọ sípàdé. Bákan náà, ó yẹ ká máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ká sì tún ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè wàásù fáwọn èèyàn lágbègbè wa. w17.05 5 ¶11-12

Thursday, February 28

Ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà.​—1 Pét. 2:2.

Àwọn tó fẹ́ràn nǹkan tara kì í ro nǹkan míì ju bí wọ́n ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún. Ìdí sì ni pé èrò wọn ò bá ti Ọlọ́run mu. (1 Kọ́r. 2:14) Torí pé agbára ìwòye wọn kò já geere, ó ṣòro fún wọn láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Héb. 5:​11-14) Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé àwọn nǹkan tara ni wọ́n máa ń lé ṣáá, síbẹ̀ wọn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. (Oníw. 5:10) Àmọ́ o, ṣíṣe kù, téèyàn ò bá fẹ́ kí àwọn ohun ìní tara gba òun lọ́kàn jù, ó ṣe pàtàkì kó máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Torí pé Jésù máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún un láti borí ìdẹwò. Táwa náà bá ń fàwọn ìlànà Jèhófà sílò, a ò ní máa lépa àwọn nǹkan ìní tara. (Mát. 4:​8-10) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù ju àwọn nǹkan ìní tara lọ. w17.05 26 ¶17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́