ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 7-17
  • January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Tuesday, January 1
  • Wednesday, January 2
  • Thursday, January 3
  • Friday, January 4
  • Saturday, January 5
  • Sunday, January 6
  • Monday, January 7
  • Tuesday, January 8
  • Wednesday, January 9
  • Thursday, January 10
  • Friday, January 11
  • Saturday, January 12
  • Sunday, January 13
  • Monday, January 14
  • Tuesday, January 15
  • Wednesday, January 16
  • Thursday, January 17
  • Friday, January 18
  • Saturday, January 19
  • Sunday, January 20
  • Monday, January 21
  • Tuesday, January 22
  • Wednesday, January 23
  • Thursday, January 24
  • Friday, January 25
  • Saturday, January 26
  • Sunday, January 27
  • Monday, January 28
  • Tuesday, January 29
  • Wednesday, January 30
  • Thursday, January 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 7-17

January

Tuesday, January 1

Àwọn ènìyàn tí wọ́n kúndùn ìwà búburú kò lè lóye ìdájọ́.​—Òwe 28:5.

Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ṣe ń lọ sópin, bẹ́ẹ̀ làwọn ẹni ibi túbọ̀ ń “rú jáde bí ewéko.” (Sm. 92:7) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ni ò hùwà ọmọlúàbí mọ́. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé inú ayé yìí làwa náà ń gbé, báwo la ṣe lè “jẹ́ ìkókó ní ti ìwà búburú; síbẹ̀, [ká] dàgbà di géńdé nínú agbára òye”? (1 Kọ́r. 14:20) Ìdáhùn ìbéèrè yẹn wà nínú ẹsẹ Bíbélì tá a gbé ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní kà. Apá kan níbẹ̀ kà pé: “Àwọn tí ń wá Jèhófà lè lóye ohun gbogbo,” ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n lóye gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti múnú Jèhófà dùn. Òwe 2:7, 9 náà tún sọ pé Jèhófà máa ń “to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣánṣán.” Ìyẹn ló ń jẹ́ káwọn adúróṣánṣán “lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.” Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù ní irú ọgbọ́n yẹn. (Ìsík. 14:14) Bó sì ṣe rí fáwa èèyàn Ọlọ́run lónìí náà nìyẹn. Ìwọ ńkọ́? Ṣé o “lóye ohun gbogbo” tó yẹ kó o mọ̀ kó o lè múnú Jèhófà dùn? Ohun táá jẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o ní ìmọ̀ tó péye nípa Jèhófà. w18.02 8 ¶1-3

Wednesday, January 2

A batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa.​—Ìṣe 19:5.

Kò yẹ ká máa fipá mú àwọn ọmọ wa, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tàbí àwọn míì nínú ìjọ pé kí wọ́n ṣèrìbọmi, ìdí sì ni pé Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti wá sin òun. (1 Jòh. 4:8) Dípò ìyẹn, ṣe ni ká jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Tí wọ́n bá lóye ohun tí wọ́n kọ́, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ní káwọn Kristẹni máa ṣe, ìyẹn máa jẹ́ kó wù wọ́n láti ṣèrìbọmi. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Bíbélì ò sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ pé iye ọdún kan pàtó kó tó lè ṣèrìbọmi. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yàtọ̀ síra, ìtẹ̀síwájú wọn ò sì lè dọ́gba. Kò sí àní-àní pé ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ ìrìbọmi, síbẹ̀ ó tún yẹ kẹ́ni tó ṣèrìbọmi ronú lórí ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó ṣe túmọ̀ sí. Ó máa gba ìsapá ká tó lè ṣe ohun tí Jèhófà ní ká ṣe. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ gba àjàgà òun. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò gbọ́dọ̀ “tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.”​—2 Kọ́r. 5:15; Mát. 16:24. w18.03 6-7 ¶14-17

Thursday, January 3

Ẹ má gbàgbé aájò àlejò, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀, àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.​—Héb. 13:2.

Ṣé ìgbà kan wà tó yẹ kó o gba ẹnì kan lálejò, àmọ́ tí o kò ṣe bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àǹfààní kan lo gbé sọnù yẹn. Torí pé tá a bá ń gbàlejò, ó máa jẹ́ ká gbádùn àjọṣe pẹ̀lú àwọn míì, àá sì láwọn ọ̀rẹ́ tó ń báni kalẹ́. Ohun kan tó sì lè jẹ́ ká borí ìdánìkanwà ni pé ká máa gbàlejò. Àmọ́, o lè máa ronú pé, ‘Kí ló máa ń fà á táwọn kan kì í fẹ́ gbàlejò?’ Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fà á. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni pé ọwọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń dí gan-an torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa ń ṣe. Èyí máa ń mú káwọn kan ronú pé àwọn ò lè ráyè gbàlejò tàbí pé àwọn ò lè ṣe wàhálà ẹ̀. Tíwọ náà bá ń ronú bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí. Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn ìyípadà táá jẹ́ kó o lè gbàlejò tàbí táá mú kó o ráyè lọ kí àwọn míì? Ó ṣe tán, Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé ká máa gbàlejò. Torí náà, kò burú tá a bá ń wáyè gbàlejò, kódà ohun tó yẹ ká máa ṣe ni. Ìyẹn lè gba pé kó o dín àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe kù tàbí kó o sún wọn sígbà míì. w18.03 16 ¶13-14

Friday, January 4

Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.​—Lúùkù 4:43.

Nínú gbogbo àwọn tó tíì gbé ayé rí, Jésù ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Ó fi hàn jálẹ̀ ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé àpẹẹrẹ Jèhófà, Baba rẹ̀ lòun ń tẹ̀ lé. Ìfẹ́ Jèhófà ló ń ṣe lọ́rọ̀, lérò àti ní ìṣe, àwọn ìlànà Jèhófà ló sì ń tẹ̀ lé. (Jòh. 8:29; 14:9; 15:10) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tí wòlíì Aísáyà sọ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú, kẹ́ ẹ wá fi wé ohun tí Máàkù sọ nípa bí Jésù náà ṣe jẹ́ aláàánú. (Aísá. 63:9; Máàkù 6:34) Bíi ti Jésù, ṣé àwa náà máa ń fàánú hàn sáwọn èèyàn tá a mọ̀ pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́? Ṣé iṣẹ́ ìwàásù ló gbawájú ní ìgbésí ayé tiwa náà? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a jẹ́ ẹni tẹ̀mí. w18.02 21 ¶12

Saturday, January 5

[Ẹ máa tọ́ àwọn ọmọ yín dàgbà] nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.​—Éfé. 6:4.

Àǹfààní ńlá làwọn òbí ní láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, ìyẹn ò sì rọrùn rárá nínú ayé burúkú yìí. (2 Tím. 3:​1-5) Lóòótọ́, àwọn ọmọdé máa ń ní ẹ̀rí ọkàn, àmọ́ wọn kì í mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Torí náà, kí ẹ̀rí ọkàn wọn tó lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n sì máa bá wọn wí. (Róòmù 2:​14, 15) Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìbáwí” lè túmọ̀ sí “títọ́ ọmọ dàgbà.” Ọkàn àwọn ọmọ tí wọ́n bá ń fìfẹ́ bá wí máa ń balẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé òmìnira àwọn ní ààlà àti pé gbogbo ohun táwọn bá ṣe ló máa yọrí sí nǹkan kan, yálà sí rere tàbí búburú. Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà. Ẹ má sì gbàgbé pé bí wọ́n ṣe ń tọ́ ọmọ yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíì, ó sì máa ń yí pa dà látìgbàdégbà. Ó máa ń rọrùn fáwọn òbí tó bá ń tẹ́tí sí Ọlọ́run láti tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú torí pé ọgbọ́n Ọlọ́run ni wọ́n ń gbára lé, kì í ṣe òye tara wọn tàbí ìmọ̀ràn tí ayé ń fúnni lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́. w18.03 30 ¶8-9

Sunday, January 6

Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.​—Fílí. 2:12.

Ní báyìí tó o ti ṣèrìbọmi, ìwọ lo máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí, ká tiẹ̀ ló o ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fi kókó yìí sọ́kàn? Ìdí ni pé bí o ṣe ń dàgbà sí i, ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀lára rẹ àtàwọn ìṣòro tí ò ń kojú yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Bóyá ni ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan máa sọ pé òfin Jèhófà ti le jù kìkì nítorí pé kò jẹ kéèkì ọjọ́ ìbí ọmọ ilé ìwé rẹ̀. Àmọ́ bó ṣe ń dàgbà sí i, tí ìmọ̀lára rẹ̀ láti ní ìbálòpọ̀ sì ń lágbára sí i, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dá òun lójú pé pípa òfin Jèhófà mọ́ lohun tó bọ́gbọ́n mu jù.” Àwọn tó ti dàgbà kí wọ́n tó ṣèrìbọmi náà máa ń kojú àwọn ìṣòro tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀. Lára ohun tó lè dán ìgbàgbọ́ wọn wò ni àìlera, àìníṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo wa pátá la máa kojú àwọn ipò tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò, yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà.​—Ják. 1:​12-14. w17.12 24 ¶4-5

Monday, January 7

Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀.​—Éfé. 4:26.

Àwọn èèyàn fojú Dáfídì rí màbo, ṣàṣà làwọn tírú ẹ̀ tíì ṣẹlẹ̀ sí. Síbẹ̀, ọ̀rẹ́ Ọlọ́run yìí kò jẹ́ kíyẹn mú òun ṣìwà hù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sm. 37:8) Ìdí to ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká “jáwọ́” nínú ìbínú ni pé a fẹ́ fìwà jọ Jèhófà, tí “kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (Sm. 103:10) Yàtọ̀ síyẹn, àá jàǹfààní nípa tara tá a bá “jáwọ́” nínú ìbínú. Ìdí sì ni pé ìbínú máa ń fa àìsàn bí ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ẹ̀dọ̀, kéèyàn má lè mí dáadáa tàbí kí ẹ̀yà ara tá à ń pè ní àmọ́ má ṣiṣẹ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú bó ṣe yẹ. Téèyàn bá ń bínú, kò ní lè ronú lọ́nà tó já geere. Lọ́pọ̀ ìgbà, téèyàn bá fara ya, ó lè mú kéèyàn ní ìsoríkọ́ tí kì í tán bọ̀rọ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Kí wá la lè ṣe tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá nínú ìjọ, báwo la sì ṣe lè mú kí àlàáfíà jọba láàárín wa? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. w18.01 10 ¶14-15

Tuesday, January 8

Ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Ṣìọ́ọ̀lù. Ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.​—Sm. 16:10.

Dáfídì ò sọ pé òun kò ní kú láé tàbí pé òun ò ní wọ isà òkú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó ṣe kedere pé Dáfídì darúgbó, lẹ́yìn tó sì kú, ó “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì.” (1 Ọba 2:​1, 10) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ta wá ni Sáàmù 16:10 ṣẹ sí lára? Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, Pétérù bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú Sáàmù 16:10. (Ìṣe 2:​29-32) Ó sọ pé Dáfídì ti kú àti pé wọ́n ti sin ín, àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ yẹn kò sọ pé ẹnikẹ́ni bá Pétérù jiyàn nígbà tó sọ pé Dáfídì “ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde” Mèsáyà. Pétérù mú kọ́rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ dá àwọn èèyàn náà lójú nígbà tó fa ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 110:1 yọ. (Ìṣe 2:​33-36) Bí Pétérù ṣe fi Ìwé Mímọ́ kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn mú kó dá àwọn èèyàn tó pé jọ lójú pé Jésù ni “Olúwa àti Kristi.” Ó dá àwọn èèyàn náà lójú pé ìgbà tí Jésù jíǹde ni Sáàmù 16:10 nímùúṣẹ. w17.12 10 ¶10-12

Wednesday, January 9

Nípa iye àti nípa ìwọ̀n ni gbogbo rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí a kọ gbogbo ìwọ̀n náà sílẹ̀ ní àkókò yẹn.​—Ẹ́sírà 8:34.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń sa gbogbo ipá wọn láti jẹ́ olóòótọ́ àti olóye tó bá kan ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa lo àwọn ọrẹ tá à ń dá, wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. (Mát. 24:45) Wọ́n máa ń pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ fi àwọn ọrẹ náà ṣe, wọ́n á sì ṣe ohun náà lọ́nà tó yẹ. (Lúùkù 14:28) Pọ́ọ̀lù rí i dájú pé àwọn tóun fi ọrẹ náà rán “ṣe ìpèsè aláìlábòsí, kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.” (2 Kọ́r. 8:​18-21) Bíi ti Ẹ́sírà àti Pọ́ọ̀lù, ètò Jèhófà náà ní àwọn ìlànà tí kò lábùlà tí wọ́n ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣàkójọ àwọn ọrẹ tó ń wọlé, ká sì ná an síbi tó yẹ. (Ẹ́sírà 8:​24-33) Ọ̀pọ̀ nǹkan tuntun ni ètò Jèhófà ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èyí sì mú ká ná ju owó tó ń wọlé lọ láwọn àsìkò kan. Torí náà, ètò Ọlọ́run wá ronú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dín ìnáwó kù, wọ́n ṣàtúnṣe sáwọn nǹkan tá à ń ṣe kí wọ́n lè náwó tó ń wọlé sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. w18.01 19-20 ¶12-13

Thursday, January 10

Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín.​—Kól. 3:15.

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tá a sì jẹ́ onínúure, á rọrùn fún wa láti dárí jì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, tí Kristẹni kan bá sọ tàbí ṣe ohun kan tó dùn wá, á dáa káwa náà rántí ìgbà kan tá a sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó dun àwọn míì. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn nígbà tí wọ́n fìfẹ́ gbójú fo àṣìṣe wa, tí wọ́n sì fi inúure hàn sí wa? (Oníw. 7:​21, 22) Ẹ wo bínú wa ṣe dùn tó pé Jésù fi inúure hàn sí wa, ó sì mú káwa olùjọsìn tòótọ́ wà níṣọ̀kan. À ń jọ́sìn Ọlọ́run kan náà, ìhìn rere kan náà là ń wàásù, ìṣòro wa sì jọra. Torí náà, tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará, tá à ń fi inúure hàn sí wọn, tá a sì ń dárí jì wọ́n, àá pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ, àá sì lè pọkàn pọ̀ sórí èrè ọjọ́ iwájú náà. Àpẹẹrẹ àwọn tó jowú nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé owú jíjẹ lè mú kéèyàn pàdánù èrè ọjọ́ iwájú. Ẹ rántí pé owú ló mú kí Kéènì pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. Bákan náà, Kórà, Dátánì àti Ábírámù jowú Mósè, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n ta kò ó. Àpẹẹrẹ míì ni ti Ọba Sọ́ọ̀lù tó jowú Dáfídì torí pé ó ṣàṣeyọrí, ó sì ń wá bó ṣe máa pa á. w17.11 27 ¶9-10

Friday, January 11

Kí ìwọ tọsẹ̀ rẹ̀, kí o sì ṣe àyẹ̀wò, kí ó sì wádìí kínníkínní.​—Diu. 13:14.

Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ onídàájọ́ gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ wo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì náà ronú pìwà dà lóòótọ́. Kì í sábà rọrùn láti mọ̀ bóyá ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ó gba pé kí wọ́n mọ ojú tónítọ̀hún fi wo ẹ̀ṣẹ̀ tó dá àti bọ́rọ̀ náà ṣe dùn ún tó. (Ìṣí. 3:3) Ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà kó tó lè rí àánú gbà. Àwọn alàgbà kò dà bíi Jèhófà àti Jésù tó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn. Tó o bá jẹ́ alàgbà, báwo lo ṣe lè fòye mọ̀ bóyá ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Àkọ́kọ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n àti ìfòyemọ̀. (1 Ọba 3:9) Ìkejì, ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ẹrú olóòótọ́ kó o lè mọ ìyàtọ̀ láàárín “ìbànújẹ́ ti ayé” àti ojúlówó ìrònúpìwàdà, tí Bíbélì pè ní “ìbànújẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 7:​10, 11) Fara balẹ̀ wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn tó ronú pìwà dà àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni Bíbélì sọ nípa bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, ojú tí wọ́n fi wo ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an? w17.11 17 ¶16-17

Saturday, January 12

Àwọn [ọmọ] yóò jẹ́ . . . aṣàìgbọràn sí òbí.​—2 Tím. 3:2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé, fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n ń mú káwọn èèyàn gbà pé irú ìwà yìí kò burú, ó ṣe kedere pé àìgbọràn kì í jẹ́ kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan wà nínú ìdílé. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Gíríìsì àtijọ́, tí ọmọ kan bá lu òbí rẹ̀, kò ní láǹfààní sáwọn ẹ̀tọ́ táwọn ọmọ ìbílẹ̀ máa ń ní. Bákan náà, lábẹ́ òfin ilẹ̀ Róòmù, ẹni tó bá ṣíwọ́ lu bàbá rẹ̀ jẹ̀bi ìpànìyàn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì rọ àwọn ọmọ pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn. (Ẹ́kís. 20:12; Éfé. 6:​1-3) Táwọn ọmọ kò bá fẹ́ máa hùwà bí àwọn ọmọ aláìgbọràn tó kúnnú ayé, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa ronú nípa àwọn nǹkan dáadáa táwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Táwọn ọmọ bá gbà pé Jèhófà Baba wa ọ̀run ló pàṣẹ pé káwọn jẹ́ onígbọràn, á rọrùn fún wọn láti máa ṣègbọràn. Táwọn ọmọ bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn òbí wọn, àwọn ọmọ míì náà á kọ́ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn nílé. w18.01 29 ¶8-9

Sunday, January 13

Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.​—Aísá. 32:2.

Lóde òní, tí Kristẹni kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó ṣe pàtàkì pé kó lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Kí nìdí? Àkọ́kọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló ṣètò pé káwọn alàgbà máa bójú tó irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Ják. 5:​14-16) Ìkejì, tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà, wọ́n á ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà rí ojúure Ọlọ́run, kó má sì pa dà sídìí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. (Gál. 6:1; Héb. 12:11) Ìkẹta, ojúṣe àwọn alàgbà ni láti fi ẹni tó ronú pìwà dà lọ́kàn balẹ̀ kí ara lè tù ú, kódà wọ́n ti dá àwọn alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pe àwọn alàgbà ní “ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Aísá. 32:2) Ìṣètò yìí fi hàn pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lọkàn wọn balẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n tọ àwọn alàgbà lọ, tí wọ́n sì rí ìrànwọ́ gbà. w17.11 10 ¶8-9

Monday, January 14

Ìbáwí a máa kó ẹ̀dùn-ọkàn-báni.​—Héb. 12:11.

Lóòótọ́, ó máa ń dunni gan-an tí wọ́n bá yọ èèyàn ẹni lẹ́gbẹ́, àmọ́ kò yẹ ká tún jọ máa ṣe àwọn nǹkan tá a jọ ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Kò yẹ ká jọ máa kàn síra lórí fóònù, nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí àtẹ̀jíṣẹ́, títí kan lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí ìkànnì àjọlò. Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “a máa retí ohun gbogbo,” lédè míì, kò yẹ ká sọ̀rètí nù pé ẹni tó fi Jèhófà sílẹ̀ lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (1 Kọ́r. 13:7) Tó o bá kíyè sí i pé ìbátan rẹ náà ti ń yíwà pa dà, o lè gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó lè gbọ́ àrọwà Jèhófà pé: “Padà sọ́dọ̀ mi.” (Aísá. 44:22) Jésù sọ pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ èèyàn èyíkéyìí ju òun lọ, a ò ní rí ìtẹ́wọ́gbà òun. Síbẹ̀, ó dá Jésù lójú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa nífẹ̀ẹ́ òun ju ẹnikẹ́ni lọ, kódà lójú àtakò ìdílé. Táwọn ará ilé rẹ bá ń fìtínà ẹ torí pé ò ń tẹ̀ lé Jésù, gbára lé Jèhófà. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á. (Aísá. 41:​10, 13) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù mọyì rẹ gan-an, wọ́n á sì san ẹ́ lẹ́san rere bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin. w17.10 16 ¶19-21

Tuesday, January 15

Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú . . . wọ ara yín láṣọ.​—Kól. 3:12.

Àánú máa ń ṣe wá tá a bá kíyè sí báwọn èèyàn ṣe ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ń darúgbó nítorí àìpé ẹ̀dá. Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé káwọn nǹkan yìí ti dohun ìgbàgbé. Ìdí nìyẹn tá a fi ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Àmọ́ ní báyìí ná, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá àgbàlagbà kan tó ní àìsàn tó máa ń mú kí arúgbó ṣarán. Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ òǹṣèwé sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan. Lọ́jọ́ yẹn, màmá rẹ̀ ṣèdọ̀tí sára, ibi tó ti ń gbìyànjú àtilọ wẹ̀, àwọn obìnrin méjì kan kanlẹ̀kùn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn obìnrin náà, wọ́n sì ti máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n bi màmá náà bóyá á fẹ́ kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Màmá náà dáhùn pé, “Ohun ìtìjú ni, àmọ́ mo fẹ́ kẹ́ ẹ ràn mí lọ́wọ́.” Àwọn arábìnrin náà bá a fọ àwọn ohun tó yẹ ní fífọ̀, lẹ́yìn náà, wọ́n po tíì fún un, wọ́n sì tún jọ sọ̀rọ̀ díẹ̀. Inú ọmọ màmá náà dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Mo bẹ́rí fún ẹ̀yin Ajẹ́rìí. Ohun tẹ́ ẹ̀ ń wàásù náà lẹ̀ ń ṣe.” Ṣé àánú àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn máa ń ṣe ẹ́, ṣó o sì máa ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?​—Fílí. 2:​3, 4. w17.09 9 ¶5; 12 ¶14

Wednesday, January 16

Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.​—1 Jòh. 3:18.

Ó yẹ kí inú wa máa dùn láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa “ní ìkọ̀kọ̀,” kódà bí kò bá tiẹ̀ sẹ́ni tó mọ ohun tá à ń ṣe. (Mát. 6:​1-4) Ó tún yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì máa bọlá fáwọn èèyàn. (Róòmù 12:10) Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nígbà tó ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbayì. (Jòh. 13:​3-5, 12-15) Ó yẹ káwa náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ká sì ṣe tán láti sin àwọn ẹlòmíì. Kódà, àwọn àpọ́sítélì ò fi bẹ́ẹ̀ lóye kókó yìí àfìgbà tí wọ́n rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Jòh. 13:7) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ torí bá a ṣe kàwé tó, torí àwọn ohun tá a ní tàbí torí àwọn àǹfààní tá a ní nínú ètò Jèhófà. (Róòmù 12:3) Tí wọ́n bá ń yin ẹnì kan, kò yẹ ká máa jowú, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló yẹ ká máa bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ yọ̀ kódà tá a bá tiẹ̀ rò pé ó yẹ kí wọ́n yin àwa náà fún ipa tá a kó nínú iṣẹ́ náà. w17.10 9 ¶9-10

Thursday, January 17

Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.​—1 Kọ́r. 9:23.

Ọ̀pọ̀ ti rí i pé táwọn bá ka Bíbélì fún àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí, ó máa ń nípa lórí wọn gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Arákùnrin kan lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ bàbá àgbàlagbà kan tó ti ń gba àwọn ìwé ìròyìn wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kàkà kí arákùnrin yìí kàn fún bàbá yẹn ní Ilé Ìṣọ́ tó jáde kẹ́yìn, ńṣe ló ka 2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4 tí wọ́n tọ́ka sí nínú ìwé ìròyìn náà. Ẹsẹ Bíbélì yẹn kà pé: “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” Ẹsẹ Bíbélì yìí wọ bàbá yẹn lọ́kàn débi pé ó ní kí arákùnrin náà tún un kà. Bàbá náà sọ pé òun àti ìyàwó òun nílò ìtùnú gan-an, èyí sì mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àbí ẹ ò rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń sa agbára nígbà tá a bá lò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù!​—Ìṣe 19:20. w17.09 26 ¶9-10

Friday, January 18

Kí o . . . kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.​—Jóòbù 2:5.

Ó dájú pé inú máa bí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ sóhun tí Sátánì ṣe yẹn, ojú burúkú ni wọ́n sì máa fi wò ó. Àmọ́, Jèhófà ò kù gìrì ṣe nǹkan. Ṣe ló bójú tó ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó tọ́ àti lásìkò tó yẹ. Ṣe ni Jèhófà ń fi sùúrù yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Ẹ́kís. 34:6; Jóòbù 2:​2-6) Àmọ́, kí nìdí tí Jèhófà fi ń mú sùúrù? Ìdí ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, ohun tó fẹ́ ni pé “kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9) Àpẹẹrẹ Jèhófà kọ́ wa pé kò yẹ ká máa kù gìrì ṣe nǹkan, ó sì yẹ ká máa ro ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ sọ dáadáa. Tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, ó yẹ kó o fara balẹ̀ ronú kó o lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o má bàa ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí ṣìwà hù. (Sm. 141:3) Ó rọrùn láti ṣìwà hù tínú bá ń bíni, ọ̀pọ̀ sì ti kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe.​—Òwe 14:29; 15:28; 19:2. w17.09 4 ¶6-7

Saturday, January 19

Kí o sì fi [adé náà] dé orí Jóṣúà ọmọkùnrin Jèhósádákì àlùfáà àgbà.​—Sek. 6:11.

Ṣé bí Sekaráyà ṣe dé Jóṣúà Àlùfáà Àgbà ládé wá túmọ̀ sí pé Jóṣúà ti di ọba? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Jóṣúà kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Dáfídì, torí náà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jọba. Àpẹẹrẹ ni ohun tí Sekaráyà ṣe yẹn, ó jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa yan ẹnì kan tó máa jẹ́ ọba àti àlùfáà títí láé. Bíbélì wá pe àlùfáà àgbà tí Sekaráyà dé ládé náà ní Ìrújáde tàbí Èéhù. Ìwé Mímọ́ mú kó ṣe kedere pé Jésù ni Èéhù náà. (Aísá. 11:1; Mát. 2:23) Jésù ni Ọba àti Àlùfáà Àgbà, òun sì tún ni aṣáájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà. Torí náà, Jésù ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó lè dáàbò bo àwa èèyàn Jèhófà nínú ayé Sátánì yìí. (Jer. 23:​5, 6) Láìpẹ́, ó máa ṣáájú àwọn ọmọ ogun Jèhófà láti dáàbò bo àwa èèyàn Ọlọ́run, á sì ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè kó lè fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. (Ìṣí. 17:​12-14; 19:​11, 14, 15) Àmọ́ kí Jésù tó gbé ìgbésẹ̀ yìí, ó ṣì ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti ṣe. w17.10 29 ¶12-14

Sunday, January 20

Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.​—Kól. 3:9.

Ká sọ pé aṣọ rẹ dọ̀tí, ó sì ń rùn, kí lo máa ṣe? Ó dájú pé wàá tètè bọ́ ọ kúrò lọ́rùn. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ, pé ká jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ó ṣe pàtàkì ká fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwa Kristẹni sílò pé: “Ẹ mú gbogbo [ìwà burúkú] kúrò lọ́dọ̀ yín.” Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀kan yẹ̀wò lára wọn, ìyẹn àgbèrè. (Kól. 3:​5-9) Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a tú sí “àgbèrè” túmọ̀ sí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “sọ àwọn ẹ̀yà” wọn “di òkú ní ti àgbèrè,” ìyẹn ni pé kí wọ́n má ṣe fàyè gba èrò tàbí ìfẹ́ ọkàn èyíkéyìí tó lè mú kí wọ́n ṣe àgbèrè. Èdè ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò fi hàn pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti gbé irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn. Síbẹ̀, ó dájú pé tá a bá sapá, a lè borí irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀. w17.08 18 ¶5-6

Monday, January 21

Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.​—Mík. 7:7.

Bí àwọn nǹkan ṣe rí lásìkò wa yìí jọ bó ṣe rí lásìkò wòlíì Míkà. Àsìkò tí Ọba Áhásì tó jẹ́ ọba burúkú wà lórí oyè ni Míkà gbáyé, onírúurú ìwà burúkú ló sì kún ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àní sẹ́, Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn náà ti gbówọ́ nínú ìwà ibi. (Míkà 7:​1-3) Míkà mọ̀ pé kò sóhun tí òun lè ṣe nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Tá a bá nígbàgbọ́ bíi ti Míkà, ṣe lá máa wù wá láti dúró de Jèhófà. Ọ̀rọ̀ wa yàtọ̀ pátápátá sí ti ẹlẹ́wọ̀n kan tó kàn ń dúró de ọjọ́ ikú rẹ̀. Kò sí ohun tó lè ṣe ju pé kó dúró de ọjọ́ náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù ú pé kóun kú. Àmọ́, kì í ṣe bọ́rọ̀ tiwa ṣe rí nìyẹn. Ó máa ń wù wá láti dúró de Jèhófà torí pé ó dá wa lójú pé á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Èyí máa ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tó pinnu gẹ́lẹ́, ìyẹn sì ni àsìkò tó dáa jù! Ìdí nìyẹn tá a fi ń ‘fara dà á ní kíkún, pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ìdùnnú.’ (Kól. 1:​11, 12) Torí náà, tá a bá sọ pé à ń dúró de Jèhófà, àmọ́ tá à ń ráhùn, tá a sì ń fapá jánú pé Jèhófà ò tètè gbé ìgbésẹ̀, inú Jèhófà ò ní dùn sí wa.​—Kól. 3:12. w17.08 4 ¶6-7

Tuesday, January 22

Jèhófà ń mú ìtura bá àwọn ọlọ́kàn tútù.​—Sm. 147:6.

Ǹjẹ́ a lè rí ìtura gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà? Ó ṣe pàtàkì pé ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Tá a bá máa nírú àjọṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù. (Sef. 2:3) Àwọn ọlọ́kàn tútù gbà pé Ọlọ́run máa gbèjà àwọn lásìkò tó tọ́, á sì dá wọn nídè lọ́wọ́ ìyà tó ń jẹ wọ́n. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn gan-an. Bákan náà, Ọlọ́run máa ń “rẹ àwọn ẹni burúkú wá sí ilẹ̀.” (Sm. 147:6b) Ó dájú pé a ò fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, àbí? Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa títí ayé, tá ò sì fẹ́ kó bínú sí wa, ó yẹ ká kórìíra ohun tó kórìíra. (Sm. 97:10) Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ kórìíra ìṣekúṣe. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó lè mú ká ṣe ìṣekúṣe, kódà a ò gbọ́dọ̀ wo ìwòkuwò. (Sm. 119:37; Mát. 5:28) Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, àmọ́ gbogbo ohun tá a bá ṣe ká lè rí ojúure Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ o, ká tó lè ja ìjà yìí ní àjàṣẹ́gun, ó ṣe pàtàkì pé ká gbára lé Jèhófà, kì í ṣe ara wa. Ṣe ló yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. w17.07 19-20 ¶11-13

Wednesday, January 23

Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín.​—Òwe 19:17.

Bá a ṣe ń fi owó ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn tún fi hàn pé a ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́. Ó jẹ́ ká lè máa lo owó wa láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó lówó lọ́wọ́ àmọ́ tí wọn ò lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tàbí lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ máa ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fowó ti iṣẹ́ ìwàásù náà lẹ́yìn. Owó tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn ni ètò Ọlọ́run ń lò láti jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn ìtẹ̀jáde wa dé àwọn ilẹ̀ tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù, àmọ́ táwọn èèyàn ibẹ̀ ń wá sínú ètò Ọlọ́run gan-an. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ bíi Kóńgò, Madagásíkà àti Rùwáńdà, ìgbà kan wà táwọn ará wa máa ń pebi mọ́nú kí wọ́n lè ní Bíbélì. Ìdí sì ni pé Bíbélì wọ́nwó gan-an, kódà owó iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kan tàbí owó oṣù kan ni wọ́n á tù jọ kí wọ́n tó lè ra Bíbélì. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ọrẹ tá à ń ṣe ti mú kí “ìmúdọ́gba” wà, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún ètò Ọlọ́run láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè wọn kí wọ́n sì pín in fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìdílé títí kan àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀.​—2 Kọ́r. 8:​13-15. w17.07 9 ¶11

Thursday, January 24

Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.​—Òwe 27:11.

A máa rí ìtùnú tá a bá ń ronú lórí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, a mọ ìdí tá a fi ń kojú àdánwò. Kì í ṣe pé Jèhófà ń bínú sí wa la ṣe ń kojú àdánwò, kàkà bẹ́ẹ̀ àdánwò ń jẹ́ ká lè fi hàn pé a fara wa sábẹ́ àkóso Ọlọ́run. Tá a bá fara da àdánwò, a máa wà ní “ipò ìtẹ́wọ́gbà,” èyí sì máa jẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ dájú. (Róòmù 5:​3-5) Ìtàn Jóòbù jẹ́ ká rí i pé “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Ják. 5:11) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa san àwa àti gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ lẹ́san. Tá a bá ń fi kókó yìí sọ́kàn, èyí á mú ká lè ‘fara dà á ní kíkún, ká sì ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’ (Kól. 1:11) Ká sòótọ́, tá a bá ń kojú ìṣòro, kì í rọrùn láti fi sọ́kàn pé bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso lohun tó ṣe pàtàkì jù. Torí náà, ó yẹ ká máa rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bá a ṣe máa fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run la fara mọ́ tá a bá ń kojú àdánwò. w17.06 26 ¶15-16

Friday, January 25

Ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.​—Lúùkù 12:15.

Lóde òní, ohun tó jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lógún ni àwọn nǹkan tó lòde, bí aṣọ, fóònù, àtàwọn nǹkan míì. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ̀, ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kì í ṣe bí mo ṣe máa ní ọkọ̀ tó le ńlẹ̀ àtàwọn aṣọ tó lòde ni mò ń rò ṣáá tí mo sì ń wá kiri débi pé mi ò ń ráyè múra ìpàdé? Ṣé àwọn nǹkan tara tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ ló ń gba gbogbo àkókò mi tí mi ò fi ń ráyè gbàdúrà tàbí ka Bíbélì?’ Tá a bá kíyè sí i pé ìfẹ́ tá a ní fáwọn nǹkan tara ti ń mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Kristi jó rẹ̀yìn, á dáa ká ronú lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. Jésù sọ pé “kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.” Ó tún sọ pé: “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Ìdí sì ni pé àwọn “ọ̀gá” méjèèjì yìí fẹ́ kéèyàn fi gbogbo ọkàn sin àwọn. (Mát. 6:24) Torí pé a jẹ́ aláìpé, a gbọ́dọ̀ máa sapá kí “àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa” má bàa borí wa, títí kan àwọn nǹkan tara.​—Éfé. 2:3. w17.05 25-26 ¶15-16

Saturday, January 26

Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.​—1 Kọ́r. 9:23.

Lóòótọ́ aláìpé ni wá, a sì dà bí ohun èlò tá a fi amọ̀ ṣe. Síbẹ̀, ìhìn rere tá à ń polongo jẹ́ ìṣúra torí pé ó lè mú kí àwa àtàwọn tó ń tẹ́tí sí wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Torí pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Róòmù 1:​14, 15; 2 Tím. 4:2) Èyí mú kó lè fara da àwọn àtakò tó lékenkà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (1 Tẹs. 2:2) Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù bíi ti Pọ́ọ̀lù? Ọ̀nà kan tí Pọ́ọ̀lù gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù ni pé ó máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bíi tàwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ìgbàanì, àwa náà máa ń wàásù láti ilé dé ilé, níbi térò pọ̀ sí àti lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. (Ìṣe 5:42; 20:20) Bí ipò wa bá ṣe gbà, àwa náà lè ronú lórí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, a lè gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí ká tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. A tún lè kọ́ èdè míì tàbí ká lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lórílẹ̀-èdè wa tàbí lórílẹ̀-èdè míì.​—Ìṣe 16:​9, 10. w17.06 10-11 ¶8-9

Sunday, January 27

Gbogbo òkè ńlá àti gbogbo erékùṣù ni a sì ṣí kúrò ní àyè wọn.​—Ìṣí. 6:14.

Èyí táwọn ètò ayé yìí ń ṣe nínú ìwà ibi pọ̀ ju èyí táwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń ṣe lọ. Ronú nípa àìmọye èèyàn táwọn ètò ẹ̀sìn ti ṣì lọ́nà, wọn ò sòótọ́ fún wọn nípa Ọlọ́run, wọn ò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Bíbélì ṣeé gbára lé, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò sòótọ́ nípa bí ayé ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwa èèyàn àtàwọn irọ́ míì bẹ́ẹ̀. Kí ni ká sọ nípa àwọn ìjọba tó ń sọ ara wọn di arógunyọ̀, tí wọ́n ń dá ogun abẹ́lé sílẹ̀, tí wọ́n ń fìyà jẹ àwọn tálákà àtàwọn tí kò ní olùgbèjà? Àwọn ìjọba jẹgúdújẹrá tó tún ń ṣe ojúṣàájú ńkọ́? Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ni ò ro tàwọn míì mọ́ tiwọn, wọ́n ń ba àyíká jẹ́, wọ́n ń gbọ́n àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ní àgbọ́ngbẹ, wọ́n sì ń rẹ́ àwọn oníbàárà wọn jẹ kí wọ́n lè jẹ èrè gọbọi, èyí sì ń mú kí àìmọye èèyàn máa ráágó nínú ìṣẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa mi àwọn ìjọba ayé yìí àtàwọn ètò tó gbára lé wọn jìgìjìgì, á sì ṣí wọn nídìí pẹ̀lú gbogbo àwọn alátìlẹyìn rẹ̀, tí wọ́n lòdì sí Ìjọba Ọlọ́run.​—Jer. 25:​31-33. w17.04 11 ¶7-8

Monday, January 28

Èmi kì yóò mú ìyọnu àjálù náà wá ní àwọn ọjọ́ rẹ̀.​—1 Ọba 21:29.

Jèhófà tó jẹ́ ‘olùṣàyẹ̀wò ọkàn,’ fojú àánú hàn sí Áhábù. (Òwe 17:3) Báwo ni ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe lọ́tẹ̀ yìí ṣe máa rí lára àwọn tó mọ̀ nípa ìwà ìkà tí Áhábù hù? Ó ṣeé ṣe kí èyí dán ìgbàgbọ́ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Nábótì wò. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni kò ní jẹ́ kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀. Wọ́n á máa bá ìjọsìn wọn nìṣó torí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà kò ní yí ìdájọ́ po láé. (Diu. 32:​3, 4) Jèhófà máa san Nábótì àtàwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé wọn lẹ́san nígbà àjíǹde, ó sì dájú pé ìdájọ́ òdodo pípé nìyẹn. (Jóòbù 14:​14, 15; Jòh. 5:​28, 29) Láfikún sí i, ẹni tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa rántí pé “Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.” (Oníw. 12:14) Ká fi sọ́kàn pé tí Jèhófà bá fẹ́ ṣèdájọ́, ó tún máa ń wo àwọn nǹkan míì tó lè má hàn sáwa. Torí náà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ò ní jẹ́ ká ṣinú rò débi pé àá fi Jèhófà sílẹ̀. w17.04 24 ¶8-9

Tuesday, January 29

Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà.​—Òwe 17:17.

Látàrí bí nǹkan ṣe rí nínú ayé yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló sá kúrò nílùú láti lọ máa gbé ní ibùdó àwọn tó ń wá ibi ìsádi. Èyí kì í sì í rọrùn rárá. Ẹ wo bó ṣe máa rí kéèyàn fẹ́ kọ́ èdè tuntun, àṣà tuntun àti òfin tuntun. Èèyàn á wá iléèwé táwọn ọmọ rẹ̀ máa lọ, á sì tún kọ́ àwọn ọmọ náà kí wọ́n má bàa yàyàkuyà. Yàtọ̀ síyẹn, á tún máa san owó orí, gbogbo èyí ló sì fẹ́ ṣe lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹ ò rí i pé kò ní rọrùn rárá. Torí náà, ṣé a lè fi sùúrù ran àwọn ará tó níṣòro yìí lọ́wọ́, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀? (Fílí. 2:​3, 4) Nígbà míì, ìjọba lè mú kó ṣòro fáwọn ará wa yìí láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ. Àwọn iléeṣẹ́ ìjọba míì máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn ará pé àwọn ò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọn ò bá gba iṣẹ́ tí wọ́n fún wọn. Irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sì lè mú kí wọ́n máa pa ìpàdé jẹ. Ìhàlẹ̀ yẹn ti mú káwọn ará kan gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká tètè kàn sáwọn ará tó ń wá ibi ìsádi ní gbàrà tí wọ́n bá dé. Ó yẹ ká jẹ́ kí wọ́n rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí wọ́n bá rí i pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, tá a sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́, èyí máa fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.​—Òwe 12:25. w17.05 5 ¶9-10

Wednesday, January 30

Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.​—Mát. 24:12.

Lára àmì tí Jésù sọ pé a fi máa mọ̀ pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” ni pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mát. 24:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pe ara wọn ní èèyàn Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run di tútù. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni nígbà yẹn ń fìtara polongo “ìhìn rere nípa Kristi,” wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni bíi tiwọn, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. (Ìṣe 2:​44-47; 5:42) Àmọ́ ó dunni pé àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dẹra nù, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní di tútù. Nígbà tí Jésù Kristi ń bá àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń gbé ní Éfésù sọ̀rọ̀, ó ní: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣí. 2:4) Kí ló fà á táwọn Kristẹni yẹn fi dẹra nù? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó gbòde kan lágbègbè yẹn ló kéèràn ràn wọ́n.​—Éfé. 2:​2, 3. w17.05 17 ¶1-3

Thursday, January 31

Ìwọ gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.​—Mát. 5:33.

Aṣáájú tó jẹ́ akínkanjú ni Jẹ́fútà, jagunjagun tí kì í bẹ̀rù sì ni. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Hánà, ó ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ Ẹlikénà, ó sì mọ ilé tọ́jú. Olùjọ́sìn Jèhófà ni Jẹ́fútà Onídàájọ́ àti Hánà. Yàtọ̀ síyẹn, kí lohun míì táwọn méjèèjì tún fi jọra? Àwọn méjèèjì ló jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a yàn láti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un. Nínú Bíbélì, téèyàn bá jẹ́jẹ̀ẹ́ ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ṣèlérí fún Ọlọ́run lẹ́yìn tó ti ronú dáadáa pé òun á gbé ìgbésẹ̀ kan tàbí pé òun á fún Ọlọ́run ní ohun kan tàbí pé òun á ṣe àkànṣe iṣẹ́ kan. Ó sì lè jẹ́ pé òun á máa yàgò fún àwọn nǹkan kan. Wọn kì í fipá mú ẹnikẹ́ni jẹ́jẹ̀ẹ́. Síbẹ̀ lójú Ọlọ́run, ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ́ tẹ́nì kan jẹ́, àìgbọ́dọ̀máṣe sì ni. Ìdí ni pé téèyàn bá jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣe lonítọ̀hún búra pé òun máa ṣe ohun kan tàbí pé òun ò ní ṣe é.​—Jẹ́n. 14:​22, 23; Héb. 6:​16, 17. w17.04 3 ¶1-2

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́