Bó O Ṣe Máa Lo Ìwé Yìí
Nínú àwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé e, wàá rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti àlàyé tá a ṣe lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàkigbà lo lè ka ẹsẹ ojúmọ́ àti àlàyé tá a ṣe lórí rẹ̀, àwọn kan ti rí i pé ó ṣàǹfààní gan-an téèyàn bá kà á láàárọ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè ronú lórí ohun tí wọ́n bá kà jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ náà. Ohun tó ṣàǹfààní jù ni pé kí ìdílé jùmọ̀ ka ẹsẹ ojúmọ́ pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà oúnjẹ àárọ̀ làwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́.
Inú Ilé Ìṣọ́ (w) April 2017 sí March 2018 la ti mú àwọn àlàyé tá a ṣe lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà jáde. Nọ́ńbà tó tẹ̀ lé Ilé Ìṣọ́ ń tọ́ka sí ojú ìwé tá a ti mú àlàyé náà jáde. Lẹ́yìn ìyẹn, wàá rí nọ́ńbà ìpínrọ̀ tó o ti lè rí àfikún àlàyé nínú Ilé Ìṣọ́. (Wo àpẹẹrẹ tó wà nísàlẹ̀.) Inú àpilẹ̀kọ tá a ti mú àlàyé jáde lo ti máa rí àfikún ìsọfúnni lórí kókó ọ̀rọ̀ tá a bá gbé yẹ̀ wò.