January
Wednesday, January 1
Ọkùnrin náà, Mósè, ló jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.—Nọ́ń. 12:3.
Nígbà tí Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba Íjíbítì, kì í ṣe ọlọ́kàn tútù, ó sì máa ń tètè bínú. Kódà, lọ́jọ́ kan, ó pa ọkùnrin kan tó kà sí aṣebi, ó sì ronú pé ó yẹ kí Jèhófà fọwọ́ sí ohun tóun ṣe. Òótọ́ ni pé Mósè ní ìgboyà, àmọ́ ó tún yẹ kó jẹ́ ọlọ́kàn tútù kó tó lè di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jèhófà dá a lẹ́kọ̀ọ́ fún ogójì (40) ọdún, kó lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù, kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì jẹ́ onígbọràn. Ó fi ẹ̀kọ́ náà sílò, ó sì di aṣáájú tàbí alábòójútó tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. (Ẹ́kís. 2:11, 12; Ìṣe 7:21-30, 36) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Mósè jẹ́ fáwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà lónìí. Ẹ má tètè máa bínú táwọn míì bá yájú sí yín. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kẹ́ ẹ sì gbà pé ẹ̀yin náà máa ń ṣàṣìṣe. (Oníw. 7:9, 20) Bákan náà, ìlànà Jèhófà ni kẹ́ ẹ máa lò tẹ́ ẹ bá fẹ́ yanjú ìṣòro, kẹ́ ẹ sì máa fohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn míì sọ̀rọ̀. (Òwe 15:1) Tẹ́yin olórí ìdílé àtẹ̀yin alàgbà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà á dùn sí yín, ẹ̀ẹ́ mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé àti nínú ìjọ, ẹ̀ẹ́ sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn míì. w19.02 8 ¶1; 10 ¶9-10
Thursday, January 2
Àánú wọn . . . ṣe é.—Máàkù 6:34.
Kí nìdí tí àánú àwọn èèyàn náà fi ṣe Jésù? Ó kíyè sí i pé wọ́n “dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Bóyá Jésù rí àwọn kan lára wọn tó jẹ́ mẹ̀kúnnù tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ bí aago kí wọ́n lè pèsè fún ìdílé wọn. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn míì nínú wọn ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wọn máa yé Jésù dáadáa. Ó ṣeé ṣe kí Jésù náà ti kojú irú àwọn ìṣòro yìí rí. Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ àwọn míì máa ń jẹ Jésù lọ́kàn, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn. (Àìsá. 61:1, 2) Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù? Bíi ti Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn tó yí wa ká ló dà bí “àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,” onírúurú ìṣòro làwọn míì sì ń bá yí. Àmọ́, a ní ohun kan tó lè tù wọ́n nínú, ìyẹn sì ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfi. 14:6) Torí náà bíi ti Ọ̀gá wa, à ń wàásù ìhìn rere torí pé ‘àánú àwọn aláìní àtàwọn tálákà’ máa ń ṣe wá. (Sm. 72:13) Ìdí nìyẹn tá a fi ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́. w19.03 21-22 ¶6-7
Friday, January 3
Ìyìn ni fún Jèhófà, tó ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́.—Sm. 68:19.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ṣe fún wa tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ń fún wa lọ́pọ̀ nǹkan tá à ń gbádùn lójoojúmọ́, ó sì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa òun àtohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 8:31, 32) Ó tún ṣètò ìjọ Kristẹni ká lè máa rí ìtọ́sọ́nà àti ìrànwọ́ gbà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń bá wa gbé àwọn ìṣòro wa, ó sì ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Ìfi. 21:3, 4) Tá a bá ń ronú lórí gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, àwa náà á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká bẹ̀rù rẹ̀, a ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa dùn ún. Bó o sé ń rí bí àwọn ìlànà Jèhófà ṣe ń ṣe ẹ́ láǹfààní, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, Sátánì kò sì ní lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Nígbà tó o bá wá dé inú ayé tuntun, inú rẹ á dùn pé o yàn láti sin Jèhófà, wàá wá sọ pé, ìpinnu tó dáa jù tí mo ṣe láyé mi nìyẹn! w19.03 6 ¶14; 7 ¶19
Saturday, January 4
Ta ló ti rí aya tó dáńgájíá? Ó níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju iyùn.—Òwe 31:10.
Gbogbo ìdílé ló máa ṣe láǹfààní tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ń fi ìmoore hàn. Báwọn tọkọtaya bá mọyì ara wọn, àárín wọn á túbọ̀ gún régé. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní ṣòro láti gbójú fo àṣìṣe ara wọn. Tí ọkọ kan bá mọyì ìyàwó rẹ̀, kì í ṣe pé ó máa kíyè sí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe nìkan ni, kódà á ‘dìde, á sì yìn ín.’ (Òwe 31:28) Aya tó gbọ́n máa jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ mọ̀ pé òun mọyì rẹ̀, kódà á sọ àwọn ohun pàtó tí ọkọ rẹ̀ ń ṣe tó ń wú u lórí. Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ yín láti máa dúpẹ́ oore? Ẹ má gbàgbé pé ẹ̀yin làwọn ọmọ yín ń wò, ohun tẹ́ ẹ bá ń ṣe làwọn náà á máa ṣe. Torí náà, ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn tí wọ́n bá bá yín ṣe nǹkan, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lára yín. Bákan náà, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa dúpẹ́ oore táwọn èèyàn bá ṣe fún wọn. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá mọyì ohun táwọn míì ṣe fún wọn lóòótọ́, kò yẹ kí wọ́n pa á mọ́ra, ṣe ló yẹ kí wọ́n dúpẹ́. w19.02 17 ¶14-15
Sunday, January 5
Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!—Jóòbù 27:5.
Ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Jóòbù sọ yìí fi hàn pé ó ti pinnu pé òun máa jẹ́ oníwà títọ́. Jóòbù ò juwọ́ sílẹ̀, àwa náà ò sì gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀. Ẹ̀sùn kan náà ni Sátánì fi ń kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lónìí. Ó sọ pé o ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, pé tó o bá kojú àdánwò, wàá pa òfin Jèhófà tì kó o lè yọ ara rẹ nínú wàhálà, ó tún sọ pé ojú ayé lásán ni gbogbo bó o ṣe ń jọ́sìn Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5; Ìsí. 12:10) Báwo làwọn ẹ̀sùn yẹn ṣe rí lára rẹ? Ó ń ká ẹ lára, àbí? Àmọ́, wò ó báyìí ná, Jèhófà fọkàn tán ẹ pé wàá jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì gbà kí Sátánì dán ẹ wò. Àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́ fún ẹ láti fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú àti pé òpùrọ́ burúkú ni Sátánì. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Héb. 13:6) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní pé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run fọkàn tán wa! Ṣé o ti wá rí ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ oníwà títọ́? Èyí á jẹ́ ká lè fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa ká sì buyì kún orúkọ Jèhófà, á sì tún fi hàn pé a fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. w19.02 5 ¶9-10
Monday, January 6
Wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. —Jòh. 16:2.
Jésù jẹ́ kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa dojú kọ àdánwò. Ó wá tọ́ka sí àpẹẹrẹ tiẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n “mọ́kànle!” (Jòh. 16:1-4a, 33) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àkọsílẹ̀ fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti ìgboyà hàn bíi ti Jésù. Wọ́n dúró ti ara wọn nígbà ìṣòro láìka ohun tó lè ná wọn sí. (Héb. 10:33, 34) Bákan náà lónìí, àwa náà ń lo ìgboyà bíi ti Jésù. Bí àpẹẹrẹ, ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Nígbà míì, wọ́n lè ju àwọn ará wa sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe fún wọn, kódà tó bá gba pé ká gbèjà wọn. (Fílí. 1:14; Héb. 13:19) Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká máa fi ìgboyà wàásù nìṣó. (Ìṣe 14:3) Bíi ti Jésù, a ti pinnu pé àá máa wàásù nìṣó báwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ta kò wá tàbí tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa. w19.01 22-23 ¶8-9
Tuesday, January 7
Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú.—Héb. 10:24, 25.
Àwọn nǹkan wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa dáhùn lọ́nà táá gbé àwọn ará ró nípàdé? Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kó o máa múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀. Tó o bá ṣètò àkókò tí wàá fi máa múra ìpàdé sílẹ̀, tó o sì ń múra sílẹ̀ dáadáa, ọkàn rẹ á balẹ̀ láti dáhùn. (Òwe 21:5) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ múra ìpàdé sílẹ̀? Ó yẹ kó o kọ́kọ́ gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13; 1 Jòh. 5:14) Lẹ́yìn náà, wo àkòrí àpilẹ̀kọ náà, àwọn ìsọ̀rí tó wà níbẹ̀, àwọn àwòrán, ìbéèrè tó wà fún àtúnyẹ̀wò àtàwọn àpótí míì. Ẹ̀yìn ìyẹn ni kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì rí i pé o ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí. Ronú nípa ohun tó ò ń kà, kó o sì kíyè sí àwọn kókó tó o fẹ́ sọ nípàdé. Bó o bá ṣe múra sílẹ̀ tó ni wàá ṣe jàǹfààní tó nípàdé, ìyẹn á sì mú kó rọrùn fún ẹ láti dáhùn.—2 Kọ́r. 9:6. w19.01 9 ¶6; 11-12 ¶13-15
Wednesday, January 8
Kọ ìran náà sílẹ̀.—Háb. 2:2.
Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí Hábákúkù kọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ sílẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ẹ̀kọ́ náà sì ni pé kò yẹ ká bẹ̀rù láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà. Kódà, ó ní ká máa tú ọkàn wa jáde sí òun nínú àdúrà. (Sm. 50:15; 62:8) Hábákúkù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí ó gbà pé Ọ̀rẹ́ òun ni àti pé Bàbá òun ni. Hábákúkù ò jẹ́ kí ìṣòro tó gbà á lọ́kàn bo òun mọ́lẹ̀ débi táá fi gbẹ́kẹ̀ lé òye tara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sọ gbogbo ohun tó ń dà á lọ́kàn rú. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún wa lónìí! Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Olùgbọ́ àdúrà, gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa làá máa sọ fún un torí ohun tó rọ̀ wá pé ká ṣe nìyẹn. (Sm. 65:2) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa rí bí Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà wa. Á tù wá nínú, á sì tọ́ wa sọ́nà bí ìgbà tó gbá wa mọ́ra tìfẹ́tìfẹ́. (Sm. 73:23, 24) Jèhófà máa jẹ́ ká mọ bí ìṣòro wa ṣe rí lára òun. Ká sòótọ́, àdúrà jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. w18.11 13 ¶2; 14 ¶5-6
Thursday, January 9
Àwọn ẹni mímọ́ tó wà láyé àti àwọn ọlọ́lá, ń mú inú mi dùn jọjọ. —Sm. 16:3.
Kì í ṣe àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ́ Dáfídì nìkan ló bá ṣọ̀rẹ́. Ṣé o rántí orúkọ “ọlọ́lá” kan tó di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn Dáfídì? Jónátánì lorúkọ rẹ̀. Kódà, àjọṣe tó wà láàárín àwọn méjèèjì wà lára àwọn tí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì gbà lọ́wọ́ Dáfídì? Kí ló wá mú kí àárín wọn wọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn méjèèjì mọyì báwọn ṣe fìgboyà kojú àwọn ọ̀tá Jèhófà. (1 Sám. 13:3; 14:13; 17:48-50; 18:1) Tá a bá yan ọ̀rẹ́ láàárín àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, inú tiwa náà máa dùn bíi ti Dáfídì àti Jónátánì. Arábìnrin Kiera tó ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní kárí ayé pọ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ wọn ló wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àṣà wọn sì yàtọ̀ síra.” Tíwọ náà bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń mú ká wà níṣọ̀kan kárí ayé. w18.12 26 ¶11-13
Friday, January 10
Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.—Mát. 19:9.
Onírúurú nǹkan ni ìṣekúṣe túmọ̀ sí. Ó kan gbogbo ìbálòpọ̀ tí kì í ṣe láàárín ọkọ àti aya, bí àgbèrè, ṣíṣe aṣẹ́wó, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọkùnrin kan ṣe ìṣekúṣe, ìyàwó rẹ̀ lè pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé Jésù ò sọ pé tí ẹnì kan bá ṣe ìṣekúṣe (ìyẹn por·neiʹa), dandan ni kí ẹnì kejì rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìyàwó lè pinnu pé òun ò ní fi ọkọ òun sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ náà ṣèṣekúṣe. Ó ṣì lè nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀, ó lè pinnu láti dárí jì í kí wọ́n sì jọ sapá láti mú kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí. Òótọ́ kan ni pé, tó bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tó sì wà láìlọ́kọ, ó máa ní àwọn ìṣòro kan. Lára ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó àti ìbálòpọ̀. Ó lè máa ṣe é bíi pé kò rẹ́ni fojú jọ. Ìṣòro àtibójú tó àwọn ọmọ ńkọ́? (1 Kọ́r. 7:14) Bí ìyàwó náà bá tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́, ó máa kojú àwọn ìṣòro kan tó bá pinnu láti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. w18.12 12 ¶10-11
Saturday, January 11
Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun tó burú.—Sm. 97:10.
Jèhófà kórìíra àìṣòdodo. (Aísá. 61:8) Lóòótọ́, Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, ìyẹn sì lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́, síbẹ̀ ó gbà wá níyànjú pé káwa náà kórìíra àìṣòdodo. Tá a bá ń ronú lórí ìdí tí Jèhófà fi kórìíra ìwàkiwà, àwa náà á rí ìdí tí àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ fi burú. Ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí ìwàkiwà èyíkéyìí. Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwàkiwà làwa náà fi ń wò ó, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìwà kan burú bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ọ́ ní tààràtà. Bí àpẹẹrẹ, ijó fìdígbòdí ti ń gbèèràn gan-an nínú ayé. Àwọn kan máa ń sọ pé kò sóhun tó burú nínú ijókíjó yìí torí pé àwọn méjèèjì ò kúkú ní ìbálòpọ̀. Àmọ́ ṣé Jèhófà tó kórìíra gbogbo onírúurú ìwà burúkú máa ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé, tá a bá ń kó ara wa níjàánu, tá a sì kórìíra gbogbo nǹkan tí Jèhófà kórìíra, ìyẹn á jẹ́ ká yẹra pátápátá fún gbogbo ìwà burúkú.—Róòmù 12:9. w18.11 25 ¶11-12
Sunday, January 12
Ìṣòtítọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè.—Háb. 2:4.
Ó dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú pé ìlérí yìí máa ṣẹ débi pé ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yẹn yọ nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. (Róòmù 1:17; Gál. 3:11; Héb. 10:38) Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, tá a nígbàgbọ́, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ìṣòro yòówù ká kojú, a máa rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. Àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú yìí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ronú lé. Ẹ̀kọ́ pàtàkì làwa tá à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí kọ́ nínú ìwé Hábákúkù. Jèhófà ṣèlérí pé gbogbo àwọn olóòótọ́ tó bá nígbàgbọ́ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé òun ló máa rí ìyè. Torí náà, láìka ìṣòro yòówù ká máa bá yí, ẹ má ṣe jẹ́ ká bọ́hùn. Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Hábákúkù jẹ́ kó dá àwa náà lójú pé, ó máa tì wá lẹ́yìn, ó sì máa gbà wá là. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ká ṣe kò ju pé ká gbẹ́kẹ̀ lé òun, ká sì fi sùúrù dúró dìgbà tí Ìjọba rẹ̀ máa nasẹ̀ dé orí ilẹ̀ ayé. Nígbà yẹn, àwọn aláyọ̀ àtàwọn ọlọ́kàn tútù tó ń jọ́sìn Jèhófà ló máa kún ilẹ̀ ayé.—Mát. 5:5; Héb. 10:36-39. w18.11 16-17 ¶15-17
Monday, January 13
[Ẹ máa] rìn nínú òtítọ́.—3 Jòh. 4.
Nígbà ayé Jésù, àwọn kan wà tó kọ́kọ́ gba ẹ̀kọ́ Jésù, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n pa ẹ̀kọ́ náà tì. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, àwọn èèyàn náà tẹ̀ lé e lọ sí òdìkejì Òkun Gálílì. Jésù wá sọ ohun kan tó yà wọ́n lẹ́nu, ó sọ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín.” Dípò kí wọ́n sọ pé kí Jésù ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn, ṣe ni ọ̀rọ̀ yẹn bí wọn nínú, wọ́n wá sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Torí náà, “ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.” (Jòh. 6:53-66) Lónìí, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan ti jẹ́ kí òtítọ́ bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àwọn míì sì ti jẹ́ kí ohun tí arákùnrin kan ṣe tàbí tó sọ mú wọn kọsẹ̀. Ìbáwí táwọn kan gbà ló jẹ́ kí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, èdèkòyédè táwọn kan sì ní pẹ̀lú Kristẹni míì ló jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. w18.11 9 ¶3-5
Tuesday, January 14
Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi. —Mát. 23:10.
Tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lóye ìdí tí ètò Ọlọ́run fi fún wa láwọn ìtọ́ni tuntun kan, á dáa ká ronú lórí bí Kristi ṣe darí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú nípa bó ṣe darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Jóṣúà àti bó ṣe darí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo ìgbà làwọn ìtọ́ni Jésù máa ń bọ́gbọ́n mu, wọ́n sì ń dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ká sì wà níṣọ̀kan. (Héb. 13:8) “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa ń fún wa láwọn ìtọ́ni tá a nílò lásìkò tó yẹ. (Mát. 24:45) Èyí sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Tá a bá ronú lórí bí Kristi ṣe ń darí wa, a máa rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Yàtọ̀ sí pé Jésù ń pèsè ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí, ó tún ń fún wa lókun ká lè pọkàn pọ̀ sí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù láyé yìí, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù.—Máàkù 13:10. w18.10 25 ¶13-16
Wednesday, January 15
[Ẹ] máa rìn lọ́nà tó yẹ pípè tí a pè yín, pẹ̀lú gbogbo ìrẹ̀lẹ̀.—Éfé. 4:1, 2.
Àpẹẹrẹ kan tó ta yọ nípa bó ṣe yẹ ká máa kó ara wa níjàánu nígbà táwọn míì bá ṣẹ̀ wá wà nínú 2 Sámúẹ́lì 16:5-13. Ṣíméì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Ọba Sọ́ọ̀lù bú Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kódà ó tiẹ̀ ń sọ òkúta lù wọ́n. Síbẹ̀, Dáfídì fara dà á láìka pé ó láṣẹ láti pa Ṣíméì lẹ́nu mọ́. Kí ló mú kí Dáfídì lè kóra ẹ̀ níjàánu? Ohun tó wà nínú Sáàmù kẹta jẹ́ ká mọ ohun tó ran Dáfídì lọ́wọ́. Àkọlé tó wà ní Sáàmù kẹta jẹ́ ká mọ̀ pé Dáfídì ló kọ orin yẹn nígbà tó ń “fẹsẹ̀ fẹ ní tìtorí Ábúsálómù ọmọkùnrin rẹ̀.” Ẹsẹ 1 àti 2 bá ohun tó wà ní Sámúẹ́lì Kejì orí 16 mu gẹ́lẹ́. Sáàmù 3:4 wá jẹ́ ká rí i pé Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó ní: “Èmi yóò fi ohùn mi pe Jèhófà, òun yóò sì dá mi lóhùn.” Táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dùn wá, ó yẹ káwa náà gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Dáfídì. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí á sì jẹ́ ká lè fara dà á. Ǹjẹ́ o lè ronú àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé kó o kó ara rẹ níjàánu tàbí kó o tiẹ̀ dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́? Ṣé ó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́? w18.09 6-7 ¶16-17
Thursday, January 16
Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá.—1 Kọ́r. 3:9.
Tá à bá ń wàásù ó yẹ ká máa gba tàwọn èèyàn rò ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn ní gbogbo ìgbà. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa dunjú. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn tá a fẹ́ lọ wàásù fún ò mọ̀ pé à ń bọ̀. Torí náà, ó yẹ ká wá àwọn èèyàn lọ nígbà tá a mọ̀ pé ó máa rọ̀ wọ́n lọ́rùn. (Mát. 7:12) Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín máa ń pẹ́ kí wọ́n tó jí láwọn òpin ọ̀sẹ̀, bóyá torí wọ́n máa ń fẹ́ sinmi dáadáa? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ lè kọ́kọ́ fi ìjẹ́rìí òpópónà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tàbí kẹ́ ẹ lọ wàásù níbi térò pọ̀ sí, ẹ sì lè lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tẹ́ ẹ ti mọ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀. Lónìí, ọwọ́ àwọn èèyàn máa ń dí gan-an, torí náà, á dáa ká má ṣe pẹ́ jù lọ́dọ̀ wọn ní pàtàkì nígbà àkọ́kọ́. Ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí, ó ṣe tán àwọn èèyàn máa ń sọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ò kágbọ̀n. (1 Kọ́r. 9:20-23) Tí àwọn tá à ń wàásù fún bá rí i pé a gba tiwọn rò, a ò sì lo àkókò tó pọ̀ jù, wọ́n lè fẹ́ tẹ́tí sí wa nígbà míì. Ó dájú pé tá a bá ń fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Jèhófà sì lè lò wá láti fa ẹnì kan wá sínú òtítọ́.—1 Kọ́r. 3:6, 7. w18.09 32 ¶15-17
Friday, January 17
Aláyọ̀ ni àwọn oníwà tútù, torí wọ́n máa jogún ayé.—Mát. 5:5.
Téèyàn bá jẹ́ onínú tútù, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó láyọ̀? Àwọn kan ti fìgbà kan rí jẹ́ oníjàgídíjàgan, wọ́n sì máa ń fa wàhálà gan-an. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n yíwà pa dà. Ní báyìí, wọ́n ti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, wọ́n sì ti láwọn ànímọ́ àtàtà bí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra.” (Kól. 3:9-12) Torí náà, wọ́n ní àlàáfíà, wọ́n sì ń láyọ̀ torí pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Yàtọ̀ síyẹn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa “jogún ilẹ̀ ayé.” (Sm. 37:8-10, 29) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn onínú tútù máa “jogún ilẹ̀ ayé”? Àwọn ẹni àmì òróró máa jogún ilẹ̀ ayé nígbà tí wọ́n bá di ọba àti àlùfáà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lórí ayé. (Ìṣí. 20:6) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olóòótọ́ yòókù tí kò lọ sọ́run máa jogún ilẹ̀ ayé ní ti pé Jèhófà máa jẹ́ kí wọ́n máa gbé títí láé lórí rẹ̀. Nígbà yẹn, Jèhófà máa sọ wọ́n di pípé, wọ́n á sì máa gbádùn ayọ̀ àti àlàáfíà títí lọ kánrin kése. w18.09 19 ¶8-9
Saturday, January 18
Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀.—Jém. 1:19.
Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì. (Jẹ́n. 18:32; Jóṣ. 10:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìjíròrò tó wáyé nínú Ẹ́kísódù 32:11-14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan kí Jèhófà gbọ́ tẹnu Mósè kó tó ṣe ohun tó ní lọ́kàn, síbẹ̀ ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Mósè, kí Mósè lè sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lọ́kàn rẹ̀. Tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan máa ń ṣàṣìṣe, a lè má fẹ́ tẹ́tí sírú ẹni bẹ́ẹ̀ débi tá a fi máa ṣiṣẹ́ lórí ohun tó sọ. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí gbogbo àwọn tó bá ń ké pè é tí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Tí Jèhófà bá lè rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó lè tẹ́tí sí àwọn èèyàn bí Ábúráhámù, Rákélì, Mósè, Jóṣúà, Mánóà, Èlíjà àti Hesekáyà, ṣé kò yẹ kí èmi náà máa tẹ́tí sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi? Ṣé mo lè túbọ̀ yẹ́ wọn sí, kí n gbọ́ èrò wọn, tó bá sì ṣeé ṣe kí n ṣiṣẹ́ lórí àwọn àbá tó dáa tí wọ́n bá mú wá? Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ mi tàbí nínú ìdílé mi tó yẹ kí n tẹ́tí sí? Báwo ni mo ṣe lè ran ẹni náà lọ́wọ́?’—Jẹ́n. 30:6; Oníd. 13:9; 1 Ọba 17:22; 2 Kíró. 30:20. w18.09 6 ¶14-15
Sunday, January 19
Ẹni tó bá lawọ́ máa láásìkí, ẹni tó bá sì ń mára tu àwọn míì, ara máa tu òun náà.—Òwe 11:25.
Kò rọrùn láti jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ayé yìí torí pé àwọn onímọtara-ẹni-nìkan ló yí wa ká, èyí sì lè mú kí ṣíṣe oore súni nígbà míì. Àmọ́ Jésù sọ pé àṣẹ méjì tó tóbi jù ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, èrò wa àti okun wa àti pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Máàkù 12:28-31) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà, Jésù náà sì lawọ́. Àwọn méjèèjì jẹ́ ká mọ̀ pé táwa náà bá jẹ́ ọ̀làwọ́, a máa ní ayọ̀ tòótọ́. Tá a bá ń fi tọkàntọkàn fún Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa láwọn nǹkan tá a ní, ṣe là ń mú ìyìn wá fún Jèhófà, a sì máa ṣe ara wa àtàwọn míì láǹfààní. Kò sí àní-àní pé ìwọ náà ń sapá láti lo ara rẹ fáwọn míì, ní pàtàkì àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. (Gál. 6:10) Tó o bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀ torí pé àwọn èèyàn máa mọyì rẹ, wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. w18.08 22 ¶19-20
Monday, January 20
Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́. —Jòh. 7:24.
Lójú Jèhófà, ọ̀kan náà ni gbogbo wa láìka ìlú tá a ti wá, ẹ̀yà tàbí èdè wa sí. Ẹnikẹ́ni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin ni Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà á. (Gál. 3:26-28; Ìṣí. 7:9, 10) Ó dájú pé àwa náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀tanú pọ̀ níbi tá a gbé dàgbà ńkọ́? A lè ronú pé a kì í ṣojúsàájú àmọ́ kó jẹ́ pé a ṣì lẹ́mìí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ká má sì mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ni Jèhófà lò láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun kì í ṣojúsàájú, síbẹ̀ Pétérù fúnra rẹ̀ tún ṣe ẹ̀tanú sáwọn tí kì í ṣe Júù lẹ́yìn ìgbà yẹn. (Gál. 2:11-14) Báwo wá ni a ò ṣe ní máa fi ìrísí dáni lẹ́jọ́? Ó yẹ ká fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara wa wò dáadáa ká lè mọ̀ bóyá ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ṣì wà lọ́kàn wa. (Sm. 119:105) Nígbà míì, a lè bi ẹnì kan tá a fọkàn tán kó lè sọ fún wa tó bá rí i pé a ní ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìdí ni pé àwa fúnra wa lè má mọ̀. Ó ṣe tán ìpàkọ́ onípàkọ́ làá rí, ẹni ẹlẹ́ni ló ń báni rí tẹni. (Gál. 2:11, 14) Ẹ̀mí yìí lè ti jingíri sọ́kàn wa ká má sì mọ̀. w18.08 9 ¶5-6
Tuesday, January 21
Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn.—Mát. 5:16.
Bi ara rẹ pé: ‘Táwọn míì bá rí mi, ṣé wọ́n máa gbà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí? Ṣé mo máa ń lo àǹfààní tó bá yọjú láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí?’ Ó máa dun Jèhófà gan-an tó bá rí i pé lẹ́yìn tóun yàn wá láti jẹ́ èèyàn rẹ̀, ṣe là ń díbọ́n tá ò sì jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí rẹ̀ la jẹ́. (Sm. 119:46; Máàkù 8:38) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ti jẹ́ kó ṣòro láti ‘fìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín.’ Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí “ẹ̀mí ayé” máa darí wọn débi pé wọn ò yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé. (1 Kọ́r. 2:12) Ẹ̀mí burúkú yìí sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn máa ‘hùwà lọ́nà ti ara wọn.’ (Éfé. 2:3) Bí àpẹẹrẹ, láìka gbogbo ìkìlọ̀ tá a ti gbà lórí ọ̀rọ̀ ìmúra, àwọn Kristẹni kan ṣì nífẹ̀ẹ́ sáwọn aṣọ tí kò yẹ ọmọlúàbí. Wọ́n máa ń wọ àwọn aṣọ tó fún mọ́ra pinpin àtèyí tó ṣí ara sílẹ̀, kódà wọ́n máa ń wọ̀ ọ́ lọ sípàdé àtàwọn àpéjọ Kristẹni míì. Àwọn míì máa ń gẹ irun tàbí ṣe irun bíi tàwọn èèyàn ayé. (1 Tím. 2:9, 10) Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wà láàárín èrò, ẹ ò ní mọ̀ bóyá èèyàn Jèhófà ni wọ́n tàbí “ọ̀rẹ́ ayé.”—Ják. 4:4. w18.07 24-25 ¶11-12
Wednesday, January 22
Arákùnrin . . . ni gbogbo yín.—Mát. 23:8.
Ọ̀nà kan tí gbogbo wa gbà jẹ́ “arákùnrin” ni pé àtọ̀dọ̀ Ádámù la ti ṣẹ̀ wá. (Ìṣe 17:26) Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ torí wọ́n gbà pé Jèhófà ni Baba wọn ọ̀run. (Mát. 12:50) Bákan náà, gbogbo wọn ti di ìdílé ńlá kan nípa tẹ̀mí torí pé ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ wọn ti mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé táwọn àpọ́sítélì bá ń kọ lẹ́tà sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn, wọ́n sábà máa ń sọ pé, ‘ẹ̀yin ará.’ (Róòmù 1:13; 1 Pét. 2:17; 1 Jòh. 3:13) Lẹ́yìn tí Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo wa, ó tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Mát. 23:11, 12) Ìgbéraga wà lára ohun tí kò jẹ́ káwọn àpọ́sítélì yẹn wà níṣọ̀kan. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn Júù máa ń gbéra ga nítorí ẹ̀yà wọn. Ọ̀pọ̀ wọn gbà pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ torí pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ni wọ́n. Àmọ́ Jòhánù Oníbatisí sọ fún wọn pé: “Ọlọ́run ní agbára láti gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù láti inú òkúta wọ̀nyí.”—Lúùkù 3:8. w18.06 9-10 ¶8-9
Thursday, January 23
Ẹni tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ.—Òwe 17:27.
Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó bí wa nínú tàbí tí ìwà rẹ̀ máa ń múnú bí wa, ṣé a máa ń ronú ká tó sọ̀rọ̀? Ṣé a sì máa ń kóra wa níjàánu? (Òwe 10:19; Mát. 5:22) Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, Bíbélì sọ pé ká “yàgò fún ìrunú.” Àmọ́ ìrunú ta ni ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ? Ti Jèhófà ni. (Róòmù 12:17-21) Dípò ká bínú tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, ṣe ló yẹ ká ṣe sùúrù, ká jẹ́ kí Jèhófà bójú tó ọ̀rọ̀ náà nígbà tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀. Àmọ́ tá a bá ń wá bá a ṣe máa gbẹ̀san, a jẹ́ pé a ò wojú Jèhófà mọ́, a ò sì bọ̀wọ̀ fún un nìyẹn. Ṣé a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà tó dé kẹ́yìn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní máa ronú pé bá a ṣe ń ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀ sàn ju ìtọ́ni tuntun tá a gbà lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làá máa tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tí Jèhófà bá fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀. (Héb. 13:17) Lẹ́sẹ̀ kan náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká “má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (1 Kọ́r. 4:6) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà, à ń wojú Jèhófà nìyẹn. w18.07 15-16 ¶17-18
Friday, January 24
Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ síwájú, ká dàgbà nípa tẹ̀mí.—Héb. 6:1.
Bí òtítọ́ ṣe ń jinlẹ̀ lọ́kàn wa, àá túbọ̀ máa mọyì àwọn ìlànà Jèhófà. Ìdí ni pé ohun kan pàtó ni òfin máa ń dá lé, àmọ́ ìlànà gbòòrò gan-an, a sì lè lò ó ní onírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kékeré kan lè má mọ̀ pé ó léwu téèyàn bá ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, torí náà àwọn òbí rẹ̀ máa fún un lófin kó má bàa kó sí wàhálà. (1 Kọ́r. 15:33) Ṣùgbọ́n bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà tó sì ń gbọ́n sí i, á bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì. Tó bá yá, àwọn ìlànà yìí á jẹ́ kó lè fọgbọ́n yan àwọn táá máa bá kẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 13:11; 14:20) Torí náà, tá a bá ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ẹ̀rí ọkàn wa á túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ǹjẹ́ a ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè ṣèpinnu tó tọ́ ká sì múnú Jèhófà dùn? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn òfin àtàwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì máa jẹ́ ká ‘pegedé ní kíkún, ká sì gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.’—2 Tím. 3:16, 17. w18.06 19 ¶14; 20 ¶16-17
Saturday, January 25
Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an? —Lúùkù 10:29.
Jésù jẹ́ káwọn Júù rí i pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará Samáríà tó bá di pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. (Lúùkù 10:25-37) Kí Jésù tó lọ sọ́run, ó pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù “ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó lè ṣe iṣẹ́ yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ fa ẹ̀mí ìgbéraga àti ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wọn. Kí Jésù lè múra wọn sílẹ̀ láti wàásù fún onírúurú èèyàn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sọ ohun tó dáa nípa àwọn tí kì í ṣe Júù. Bí àpẹẹrẹ, ó yin ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí kì í ṣe Júù torí pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ta yọ. (Mát. 8:5-10) Ní Násárétì ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, Jésù ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe fi ojúure hàn sí àwọn tí kì í ṣe Júù bí opó Sáréfátì tó jẹ́ ará Foníṣíà àti Náámánì ará Síríà tó jẹ́ adẹ́tẹ̀. (Lúùkù 4:25-27) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù wàásù fún obìnrin kan tó jẹ́ ará Samáríà, ó sì tún lo ọjọ́ méjì ní ìlú Samáríà nígbà tó rí i pé àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ òun.—Jòh. 4:21-24, 40. w18.06 10 ¶10-11
Sunday, January 26
Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.—Éfé. 6:11.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwa Kristẹni wé ọmọ ogun kan tó wà lójú ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tẹ̀mí là ń jà, síbẹ̀ ẹni gidi làwọn ọ̀tá wa. Ọ̀jáfáfá ọmọ ogun ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n sì ti ń jagun. Ó lè kọ́kọ́ ṣe wá bíi pé a ò lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yìí, pàápàá tá a bá jẹ́ ọ̀dọ́. Torí náà, báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè kojú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí kí wọ́n sì borí? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀dọ́ lè ṣẹ́gun, kódà wọ́n tiẹ̀ ti ń ṣẹ́gun! Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ń “bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa.” Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, ṣe ni wọ́n tún máa ń dira ogun. Bíi tàwọn akínkanjú ọmọ ogun, wọ́n ti “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.” (Éfé. 6:10-12) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìhámọ́ra táwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń wọ̀ ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nínú àpèjúwe yìí.—Ìṣe 28:16. w18.05 27 ¶1-2
Monday, January 27
Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.—Mát. 6:9.
Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi ń wàásù ni pé, à ń yin Jèhófà lógo, a sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Jòh. 15:1, 8) A ò lè ṣe ohunkóhun láti túbọ̀ sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Torí mímọ́ ni, kò sì lábùkù kankan bó ti wù kó kéré mọ. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyè sí ohun tí wòlíì Àìsáyà sọ, ó ní: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́.” (Aísá. 8:13) Lára ọ̀nà tá a lè gbà sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ni pé, ká gbà pé kò sí orúkọ míì bíi tiẹ̀, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè kà á sí mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà fáwọn èèyàn àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé, ṣe là ń fi hàn pé afọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́ ni Sátánì àti pé irọ́ gbuu ló pa mọ́ Jèhófà. (Jẹ́n. 3:1-5) Bákan náà, à ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ tá a bá ń jẹ́ káwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mọ̀ pé Jèhófà ni gbogbo “ògo àti ọlá àti agbára” tọ́ sí.—Ìfi. 4:11. w18.05 18 ¶3-4
Tuesday, January 28
Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà . . . Jèhófà, ò ń mú inú mi dùn, nítorí àwọn ohun tí ò ń ṣe; mò ń kígbe ayọ̀ nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.—Sm. 92:1, 4.
Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká láwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni pé a fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ìfẹ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣe fún wa. Ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ronú àwọn nǹkan tí Jèhófà fún ẹ. Òun ló jẹ́ kó o wà láàyè, ó jẹ́ kó o mọ òtítọ́, ó jẹ́ kó o mọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ kó o wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì jẹ́ kó o ní ìrètí láti wà láàyè títí láé. Torí náà, o lè fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó o bá fi ìjọsìn rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ ọn. Tó o bá láwọn àfojúsùn tẹ̀mí, Jèhófà máa kíyè sí gbogbo ìgbésẹ̀ tó ò ń gbé kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn yẹn, èyí sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Kò sí bó o ṣe kéré tó, tí o ò lè ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. O ò ṣe ronú lórí àwọn nǹkan pàtàkì tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó o sì sapá kọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀ wọ́n.—Fílí. 1:10, 11. w18.04 26 ¶5-6
Wednesday, January 29
Ibi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, òmìnira á wà níbẹ̀.—2 Kọ́r. 3:17.
Àwọn ará Róòmù ìgbàanì gbà pé ọ̀gá làwọn tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe ìdájọ́ òdodo, ká gbèjà òmìnira, ká sì lo òfin bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ibẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ Kristẹni ìgbà yẹn ń gbé. Síbẹ̀, iṣẹ́ àṣekúdórógbó táwọn ẹrú ṣe ló mú kí ilẹ̀ Róòmù gbayì kó sì lágbára. Ìgbà kan wà tó tiẹ̀ jẹ́ pé tá a bá kó èèyàn mẹ́wàá jọ, àá rí ẹrú mẹ́ta nínú wọn. Abájọ tí ọ̀rọ̀ bí gbogbo èèyàn ṣe máa wà lómìnira ṣe gba àwọn èèyàn lọ́kàn, títí kan àwọn Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ gan-an nípa òmìnira nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. Àmọ́ kì í ṣe òmìnira táwọn èèyàn ń jà fún ló ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí táwọn olóṣèlú ṣèlérí. Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti àǹfààní tá à ń rí nínú ẹbọ ìràpadà Kristi ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ ń polongo fáwọn èèyàn, kì í ṣe bí àwọn olóṣèlú ṣe máa mú òmìnira wá. Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ káwọn Kristẹni mọ Ẹni tó ń fúnni ní òmìnira tòótọ́. w18.04 8 ¶1-2
Thursday, January 30
Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì ti béèrè pé òun fẹ́ gba gbogbo yín, kó lè kù yín bí àlìkámà. Àmọ́ mo ti bá yín bẹ̀bẹ̀, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa yẹ̀; ní ti ìwọ, gbàrà tí o bá pa dà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun. —Lúùkù 22:31, 32.
Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí fún àpọ́sítélì Pétérù. Pétérù wà lára àwọn tó múpò iwájú nínú ìjọ Ọlọ́run láyé àtijọ́. (Gál. 2:9) Àwọn nǹkan tó ṣe lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì àti lẹ́yìn ìgbà yẹn fún àwọn ará lókun. Lẹ́yìn tó ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sọ fáwọn Kristẹni pé: “Mo kọ̀wé sí yín ní ọ̀rọ̀ díẹ̀, láti fún yín ní ìṣírí àti ìjẹ́rìí àfi-taratara-ṣe pé èyí ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ ti Ọlọ́run; ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú rẹ̀.” (1 Pét. 5:12) Àwọn lẹ́tà tí Pétérù kọ nígbà yẹn fún àwọn ará níṣìírí, ó sì ń fún àwa náà níṣìírí lónìí. Kò sí àní-àní pé a nílò ìṣírí yìí gan-an bá a ṣe ń retí ìgbà tí àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ.—2 Pét. 3:13. w18.04 17 ¶12-13
Friday, January 31
Ẹni tó bá ń fara balẹ̀ wo inú òfin pípé tó jẹ́ ti òmìnira, tí kò sì yéé wò ó . . . máa múnú rẹ̀ dùn. —Jém. 1:25.
Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló máa ń fẹ́ ṣe ohun tó wù wọ́n, kí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé bí wọ́n ṣe fẹ́. Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn máa ń gbà wá òmìnira yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń wọ́de kiri láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn, àwọn míì sì máa ń jìjàgbara tàbí kí wọ́n dá rògbòdìyàn sílẹ̀ kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́ ṣé àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ kọ́wọ́ àwọn èèyàn tẹ òmìnira tí wọ́n ń wá? Rárá o, lọ́pọ̀ ìgbà ṣe ni nǹkan túbọ̀ máa ń nira sí i, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló sì máa ń ṣòfò. Èyí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníw. 8:9) Nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, Jákọ́bù sọ ohun tó máa jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́, kọ́kàn wa sì balẹ̀. Jèhófà tó fún wa ní òfin pípé yẹn mọ ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀, ká sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ó fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀, lára ẹ̀ ni pé wọ́n ní òmìnira tòótọ́. w18.04 3 ¶1-3