February
Saturday, February 1
Ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láìkù síbì kan.—2 Tím. 4:5.
Kò sí àní-àní pé àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe Jésù ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń tẹ́tí sí i. Táwa náà bá ń gba tàwọn èèyàn rò, ó dájú pé wọ́n á túbọ̀ máa tẹ́tí sí wa. Kí ló máa jẹ́ ká lẹ́mìí ìgbatẹnirò fáwọn tá à ń wàásù fún? Ó yẹ ká fi ara wa sípò wọn, ká sì ṣe ohun tá a máa fẹ́ káwọn náà ṣe sí wa. (Mát. 7:12) Ronú nípa ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan nílò. Lọ́nà kan náà, kò yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan náà làá máa sọ fún gbogbo ẹni tá a bá pàdé lóde ẹ̀rí. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fara balẹ̀ kíyè sí ipò wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ ká lè mọ ohun tá a máa sọ. Fọgbọ́n lo àwọn ìbéèrè táá mú kó sọ èrò ẹ̀. (Òwe 20:5) Tá a bá jẹ́ kí wọ́n sọ tọkàn wọn, ìyẹn á jẹ́ ká mọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn àtohun tí wọ́n nílò gan-an. Tá a bá sì ti mọ̀ ọ́n, ó yẹ ká sọ ohun tó máa tù wọ́n nínú bí Jésù náà ti ṣe.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 9:19-23. w19.03 20 ¶2; 22 ¶8-9
Sunday, February 2
Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́, ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.—Òwe 16:3.
Ádámù àti Éfà kò fi hàn pé àwọn mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wọn. Ìbéèrè náà ni pé ṣé àwa ní tiwa máa fi hàn pé a moore àti pé a mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wa? Tá a bá ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ṣèrìbọmi, ṣe là ń fi hàn pé a gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ tó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, a sì fọkàn tán an. Lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi, ohun tó kàn ni pé ká máa sapá láti fi ìlànà Jèhófà sílò lójoojúmọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìbọ́hùn. Kó o lè ṣàṣeyọrí, o gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Bákan náà, máa wà pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kó o sì máa fìtara kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. (Héb. 10:24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ ẹ sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ nígbàkigbà tó o bá fẹ́ ṣèpinnu. (Àìsá. 30:21) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá ṣàṣeyọrí.—Òwe 16:20. w19.03 7 ¶17-18
Monday, February 3
Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé wá láti òkè, ó ń wá látọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá. —Jém. 1:17.
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ni Jèhófà ń pèsè fún wa. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí àwọn ìtọ́ni gbà láwọn ìpàdé wa, nínú àwọn ìwé wa àti lórí ìkànnì wa. Ǹjẹ́ ìgbà kan wà tó o ka àpilẹ̀kọ kan tàbí tó o gbọ́ àsọyé kan, tàbí kẹ̀ tó o wo ètò tẹlifíṣọ̀n JW, tó o wá sọ pé, ‘Èmi gan-an lọ̀rọ̀ yìí kàn’? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe fún wa? (Kól. 3:15) Ọ̀nà kan ni pé tá a bá ń gbàdúrà, ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà gbogbo fún àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún wa. A lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa tá a bá ń mú káwọn ibi ìpàdé wa wà ní mímọ́ tónítóní. Torí náà, ó yẹ ká máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ará yòókù tí wọ́n bá ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ká sì máa tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe. Ó ṣe pàtàkì káwọn tó wà nídìí ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àtèyí tá a fi ń wo fídíò máa ṣe é jẹ́jẹ́, kó má bàa bà jẹ́. Tá a bá ń bójú tó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa déédéé, wọ́n á tọ́jọ́, àtúnṣe tá a máa ṣe kò sì ní tó nǹkan. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè ní owó tó pọ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ibòmíì láyé tàbí ká fi tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba míì ṣe. w19.02 18 ¶17-18
Tuesday, February 4
Bíńtín lèyí jẹ́ lára àwọn ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lásán ló ta sí wa létí nípa rẹ̀!—Jóòbù 26:14.
Jóòbù máa ń kíyè sí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà dá, ó sì máa ń ronú jinlẹ̀ nípa wọn. (Jóòbù 26:7, 8) Ẹnu yà á gan-an nígbà tó ń ronú nípa òfúrufú, kùrukùru, ààrá àti bí ilẹ̀ ayé ṣe rí. Síbẹ̀, ó gbà pé ohun tóun mọ̀ nípa àwọn nǹkan yẹn ò tó nǹkan. Ó tún mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní: “Mo ti fi àsọjáde ẹnu rẹ̀ ṣúra.” (Jóòbù 23:12) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣe mú kí Jóòbù bẹ̀rù Jèhófà kó sì bọ̀wọ̀ fún un. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn. Ìyẹn wá jẹ́ kó pinnu pé ìwà tó tọ́ lòun á máa hù láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe gan-an nìyẹn. Lónìí, ohun tá a mọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ti pọ̀ fíìfíì ju ohun táwọn èèyàn mọ̀ nígbà ayé Jóòbù lọ. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní odindi Bíbélì tó ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Gbogbo ohun tá a mọ̀ yìí máa jẹ́ ká ní ìbẹ̀rù Jèhófà. Ìbẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ tá a ní yìí á jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì ṣègbọràn sí i, ìyẹn lá sì jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa pé àá jẹ́ oníwà títọ́.—Jóòbù 28:28. w19.02 5 ¶12
Wednesday, February 5
Mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?—Sm. 118:6.
Kì í ṣòní, kì í ṣàná làwọn aláṣẹ ti máa ń ṣe inúnibíni sáwa èèyàn Jèhófà. Onírúurú ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn wá, àmọ́ ohun tó ń bí wọn nínú ni pé a yàn láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Nígbà míì, wọ́n lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n lè fìyà burúkú jẹ wá. Àmọ́ lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, a ò ní gbẹ̀san, àá sì jẹ́ onínú tútù láìka ohun yòówù kí wọ́n ṣe sí wa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tí àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta ìyẹn Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà fi lélẹ̀ fún wa. Wọ́n fohùn pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé ìdí táwọn ò fi ní jọ́sìn ère tí ọba gbé kalẹ̀. Wọ́n ṣe tán láti fara mọ́ ohunkóhun tí Jèhófà bá fàyè gbà. (Dán. 3:1, 8-28) Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta yẹn nígbà táwọn míì bá fúngun mọ́ wa pé ká ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ Jèhófà? A gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 118:7) Táwọn èèyàn bá fẹ̀sùn kàn wá, a máa ń fohùn pẹ̀lẹ́ dá wọn lóhùn, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. (1 Pét. 3:15) Bó ti wù kó rí, a kì í gbà kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni ba àjọṣe wa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run jẹ́. w19.02 10-11 ¶11-13
Thursday, February 6
Ẹ mọ́kàn le!—Jòh. 16:33.
Tá a bá ń ronú nípa àǹfààní tí ìràpadà Jésù ṣe wá, àá túbọ̀ nígboyà. (Jòh. 3:16; Éfé. 1:7) Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, ohun kan wà tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà náà. Ohun náà ni pé ká máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa ń kà nígbà Ìrántí Ikú Kristi ká sì máa ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn ikú Jésù. Nígbà tá a bá wá pé jọ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àá túbọ̀ lóye ohun tí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún, àá sì túbọ̀ mọyì ìràpadà tí Jésù ṣe. Tá a bá mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa àti àǹfààní tí ìràpadà yẹn ṣe àwa àtàwọn míì, ìrètí wa á túbọ̀ dájú, àá sì lè fara da àdánwò èyíkéyìí láìbẹ̀rù. (Héb. 12:3) A mà dúpẹ́ o, pé Jésù ni Àlùfáà Àgbà wa ní ọ̀run, ó sì ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí wa lọ́dọ̀ Ọlọ́run! (Héb. 7:24, 25) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a mọyì Jésù, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ìrántí ikú rẹ̀, bó ṣe pàṣẹ pé ká máa ṣe é.—Lúùkù 22:19, 20. w19.01 22 ¶8; 23-24 ¶10-11
Friday, February 7
Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí inú rẹ dùn sí ọrẹ ìyìn àtọkànwá mi.—Sm. 119:108.
Jèhófà fún wa láǹfààní láti yin òun. Ìdáhùn wa nípàdé wà lára “ẹbọ ìyìn” tá à ń rú sí Jèhófà, kò sì sẹ́ni tó lè bá wa rú u. (Héb. 13:15) Ṣé irú ẹbọ kan náà ni Jèhófà ń retí látọ̀dọ̀ wa tàbí lédè míì, ṣé ọ̀nà kan náà ló retí pé ká máa gbà dáhùn nípàdé? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀! Àwọn ìpàdé wa dà bí ìgbà tí àwọn ọ̀rẹ́ kóra jọ, tí wọ́n sì jọ ń jẹun. Jẹ́ ká sọ pé àwọn ará mélòó kan ṣètò àpèjẹ ráńpẹ́ kan níjọ yín, wọ́n sì ní kíwọ náà gbé nǹkan dání, kí lo máa ṣe? Ó ṣeé ṣe kó o ṣàníyàn nípa ohun tó o máa gbé wá, àmọ́ ó dájú pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí gbogbo èèyàn lè gbádùn ẹ̀. Bí àwọn ìpàdé wa náà ṣe rí nìyẹn. Jèhófà ló pè wá, ó sì ti tẹ́ tábìlì oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ síwájú wa. (Sm. 23:5; Mát. 24:45) Inú rẹ̀ máa dùn tá a bá mú ẹ̀bùn tó dáa jù wá bó ti wù kó kéré tó. Torí náà, máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, kó o sì dáhùn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wàá máa jẹun lórí tábìlì Jèhófà nìkan ni, wàá tún máa mú ẹ̀bùn wá fún àwọn ará ìjọ. w19.01 8 ¶3; 13 ¶20
Saturday, February 8
Àwọn tó ń tẹ̀ lé ọlọ́run mìíràn ń sọ ìbànújẹ́ wọn di púpọ̀.—Sm. 16:4.
Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, ìṣekúṣe wà lára ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìsìn èké. (Hós. 4:13, 14) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ ìsìn èké torí pé wọ́n gbádùn ìṣekúṣe. Àmọ́ ṣé ìyẹn fún wọn láyọ̀ tó wà pẹ́ títí? Kò sóhun tó jọ ọ́! Dáfídì sọ pé, àwọn tó bá ń sin ọlọ́run míì máa ní ìbànújẹ́ tó pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń fìyà jẹ àwọn ọmọdé. (Aísá. 57:5) Kò sí àní-àní pé Jèhófà kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀! (Jer. 7:31) Bákan náà lónìí, ìsìn èké fàyè gba ìṣekúṣe, kódà wọ́n fọwọ́ sí kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin, kí obìnrin sì máa fẹ́ obìnrin. Àmọ́ bíi ti ayé ìgbà yẹn, ìbànújẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. (1 Kọ́r. 6:18, 19) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ́wọ́ sí irú ìwà bẹ́ẹ̀ ṣe ń ní ìbànújẹ́ púpọ̀. Torí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹ́tí sí Jèhófà Baba yín ọ̀run. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé ire yín ló máa jẹ́ tẹ́ ẹ bá ń ṣègbọràn sí i. Ẹ fi sọ́kàn pé ìgbádùn téèyàn máa ń rí nídìí ìwà burúkú ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìbànújẹ́ tó máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀.—Gál. 6:8. w18.12 27-28 ¶16-18
Sunday, February 9
Irú ìwà kan náà ni màá . . . hù sí ọ.—Hós. 3:3.
Tí Kristẹni kan bá ṣèṣekúṣe, á di pé kí ẹnì kejì rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ ṣèpinnu. Jésù sọ pé ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ lè pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀ kóun sì fẹ́ ẹlòmíì. (Mát. 19:9) Lọ́wọ́ kejì, ẹni náà lè pinnu pé òun á dárí jì í. Kò sí ohun tó burú ńbẹ̀. Ẹ rántí pé Hósíà gba Gómérì pa dà. Lẹ́yìn tí Gómérì pa dà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, Hósíà sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ ní àjọṣe pẹ̀lú ọkùnrin míì mọ́. Hósíà alára kò sún mọ́ Gómérì fúngbà díẹ̀. (Hós. 3:1-3) Àmọ́ nígbà tó yá, ó dájú pé Hósíà bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà tí wọ́n sì tún ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. (Hós. 1:11; 3:4, 5) Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? Tí Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ bá pinnu pé òun ò ní fi ẹnì kejì òun sílẹ̀, tó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ìyẹn ló máa fi hàn pé ó ti dárí jì í. (1 Kọ́r. 7:3, 5) Ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín wọn fi hàn pé kò tún ní lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ mọ́. Ohun tó kù ni pé káwọn méjèèjì wá bí wọ́n ṣe máa ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì máa fojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó wò ó. w18.12 13 ¶13
Monday, February 10
Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.—Òwe 22:3.
Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe láwọn ipò kan. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká ṣèpinnu lójú ẹsẹ̀. Àmọ́, tá a bá ti pinnu ṣáájú ohun tá a máa ṣe, kò ní bá wa lójijì. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fi ìlọ̀kulọ̀ lọ Jósẹ́fù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jósẹ́fù kọ̀. Ìyẹn fi hàn pé ó ti ronú dáadáa nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo jíjẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni. (Jẹ́n. 39:8, 9) Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún ìyàwó Pọ́tífárì pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Èyí jẹ́ ká rí i pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìṣekúṣe lòun náà fi wò ó. Ìwọ náà ńkọ́? Kí lo máa ṣe tí ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹ tage? Tí ẹnì kan bá fi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tàbí àwòrán ìhòòhò ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù, kí ni wàá ṣe? Tó o bá ti ronú ṣáájú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tó o sì ti pinnu ohun tí wàá ṣe, á rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́. w18.11 25 ¶13-14
Tuesday, February 11
Màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà.—Háb. 3:18.
Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ ni pé “Èmi yóò yọ̀ nínú Olúwa; èmi yóò jó yíká nínú ìdùnnú fún Ọlọ́run.” Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn fún gbogbo wa lónìí! Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ṣèlérí amọ́kànyọ̀ fún wa, ó tún mú kó dá wa lójú pé láìpẹ́ láìjìnnà, gbogbo ìlérí náà máa ṣẹ. Kò sí àní-àní pé ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú ìwé Hábákúkù ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Háb. 2:4) Ká lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń (1) gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún un; (2) tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbogbo ìtọ́ni tó ń fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀, (3) jẹ́ olóòótọ́ bá a ṣe ń fi sùúrù dúró de Jèhófà. Ohun tí Hábákúkù ṣe gan-an nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ìdààmú tó bá a ló fi bẹ̀rẹ̀ ìwé rẹ̀, àmọ́ ìdùnnú ló fi parí rẹ̀, torí pé Jèhófà tù ú nínú. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hábákúkù, kó lè ṣe àwa náà bí ẹni pé Jèhófà gbá wa mọ́ra tọkàntọkàn! Ó dájú pé ìyẹn máa tù wá nínú nínú ayé tó ṣókùnkùn birimù-birimù yìí. w18.11 17 ¶18-19
Wednesday, February 12
[Kristi] kú fún gbogbo wọn kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.—2 Kọ́r. 5:15.
Ohun míì wà tó mú káwa Kristẹni tòótọ́ gbà pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Kò sí àní-àní pé Jésù náà nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó fi gbà láti kú nítorí tiwa. Ó dájú pé ìfẹ́ yìí máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ ṣèlérí pé ‘ìpọ́njú tàbí wàhálà’ ò lè “yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi.” (Róòmù 8:35, 38, 39) Nígbà míì, àwọn ìṣòro kan lè máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa tàbí kó má jẹ́ ká láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, tá a bá ronú lórí bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, a máa ní okun láti fara da àwọn ìṣòro náà. (2 Kọ́r. 5:14) Kódà tó bá jẹ́ àwọn ìṣòro tó lékenkà irú bí àjálù, àtakò, ìjákulẹ̀ tàbí ìdààmú ọkàn là ń kojú, ìfẹ́ tí Kristi ní sí wa lè fún wa lókun tá a nílò ká má bàa sọ̀rètí nù. w18.09 14 ¶8-9
Thursday, February 13
Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.—Sm. 86:11.
Ká má bàa fi òtítọ́ sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ gba gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́, ká sì máa pa wọ́n mọ́. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé òtítọ́ Bíbélì ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa, ká sì máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bíi ti Dáfídì, a gbọ́dọ̀ pinnu pé bíná ń jó, bíjì ń jà, àá máa rìn nínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn nǹkan tá a ti yááfì, kó sì máa ṣe wá bíi pé ká pa dà sídìí wọn. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, a gbọ́dọ̀ di òtítọ́ mú ṣinṣin. A ò lè gba àwọn kan gbọ́, ká sì pa àwọn tó kù tì. Ó ṣe tán, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa rìn nínú “òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 16:13) Ká má bàa sú lọ kúrò nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń fọgbọ́n lo àkókò wa. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa fàkókò ṣòfò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìgbafẹ́, tẹlifíṣọ̀n tàbí àwọn nǹkan míì tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí, wọ́n lè gba àkókò tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí àkókò tá à ń lò fún àwọn nǹkan míì nínú ìjọsìn wa. w18.11 10 ¶7-8
Friday, February 14
Mo ti tu ọkàn mi lára, mo sì ti mú kó pa rọ́rọ́.—Sm. 131:2.
Nígbà tí nǹkan bá ṣàdédé yí pa dà fún wa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, kíyẹn sì fa ìdààmú ọkàn. (Òwe 12:25) Ó tiẹ̀ lè ṣòro láti gbà pé òótọ́ lohun tó ṣẹlẹ̀. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀? (Sm. 131:1-3) Láìka ìṣòro yòówù ká máa kojú, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tó ń tuni lára, tó sì ń dáàbò bo agbára èrò orí wa. (Fílí. 4:6, 7) Torí náà, tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà nígbàkigbà tí àníyàn bá fẹ́ bò wá mọ́lẹ̀, àlàáfíà Ọlọ́run máa fún wa lókun táá jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ ìsìn wa nìṣó láì sọ̀rètí nù. Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ó tún máa ń jẹ́ ká rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù.—Jòh. 14:26, 27. w18.10 27 ¶2; 28 ¶5, 8
Saturday, February 15
Ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́. —Sek. 8:16.
Kí ni nǹkan tó tíì ṣọṣẹ́ burúkú jù lọ fọ́mọ aráyé? Irọ́ pípa ni! Kéèyàn parọ́ túmọ̀ sí pé kéèyàn sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ kó lè tan àwọn míì jẹ. Ta ló kọ́kọ́ pa irọ́? “Èṣù” ni, kódà Jésù Kristi pè é ní “baba irọ́.” (Jòh. 8:44) Ìgbà wo ló parọ́ àkọ́kọ́? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Èṣù pa irọ́ àkọ́kọ́ nínú ọgbà Édẹ́nì. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Ádámù àti Éfà ń gbádùn nínú Párádísè tí Ẹlẹ́dàá fi wọ́n sí. Bí Èṣù ṣe wọlé dé wẹ́rẹ́ nìyẹn. Ó kúkú mọ̀ pé Ọlọ́run ti pàṣẹ fún tọkọtaya yẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ lára “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú. Síbẹ̀, Sátánì lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀, ó ní: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú [irọ́ àkọ́kọ́ rèé]. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́n. 2:15-17; 3:1-5. w18.10 6 ¶1-2
Sunday, February 16
Aláyọ̀ ni àwọn tí ọkàn wọn mọ́, torí wọ́n máa rí Ọlọ́run.—Mát. 5:8.
Kí ọkàn àyà wa tó lè mọ́ gaara, a ò gbọ́dọ̀ máa ro èròkerò, àwọn nǹkan rere ló sì yẹ kó gbà wá lọ́kàn. Èyí ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. (2 Kọ́r. 4:2; 1 Tím. 1:5) Báwo làwọn tí ọkàn wọn mọ́ gaara ṣe ń “rí Ọlọ́run,” nígbà tó jẹ́ pé “kò sí ènìyàn tí ó lè rí [Ọlọ́run] kí ó sì wà láàyè síbẹ̀”? (Ẹ́kís. 33:20) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “rí” lè túmọ̀ sí kéèyàn “mọ ohun kan, kó fojú inú wo nǹkan tàbí kó fòye mọ ohun kan.” Torí náà, àwọn tó bá fi “ojú ọkàn-àyà” wọn rí Ọlọ́run làwọn tó mọ irú Ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ tí wọ́n sì mọyì àwọn ànímọ́ rẹ̀. (Éfé. 1:18) Bákan náà, a tún lè “rí Ọlọ́run” tá a bá ń kíyè sí bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. (Jóòbù 42:5) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń fọkàn yàwòrán àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí fàwọn tí ọkàn wọn mọ́ gaara tí wọ́n sì ń fòótọ́ inú sìn ín. w18.09 20 ¶13, 15-16
Monday, February 17
Ọgbọ́n ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, torí náà ní ọgbọ́n.—Òwe 4:7.
Tá a bá ń ṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé ó tọ̀nà, ó dájú pe Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu. Òótọ́ ni pé ìmọ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn gbọ́n, àmọ́ ó dìgbà téèyàn bá ṣe ìpinnu tó tọ́ ká tó lè pe irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ọlọ́gbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèrà máa ń ṣe ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n gbọ́n. Ìdí ni pé wọ́n máa ń fọgbọ́n kó oúnjẹ jọ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de àsìkò òjò. (Òwe 30:24, 25) Gbogbo ìgbà ni Kristi tí Bíbélì pè ní “ọgbọ́n Ọlọ́run” máa ń ṣe ohun tó tẹ́ Baba rẹ̀ lọ́rùn. (1 Kọ́r. 1:24; Jòh. 8:29) Ká fi sọ́kàn pé ká kàn mọ ohun tó tọ́ nìkan ò tó, Ọlọ́run tún fẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́. Ó sì dájú pé ó máa bù kún àwọn tó bá ń ṣe ohun tó tọ́, tí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì ń fara dà á. (Mát 7:21-23) Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ara lè tu àwọn tó wà nínú ìjọ, kí wọ́n sì lè máa fìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà nìṣó. Ká sòótọ́, ó máa ń gba àkókò àti sùúrù ká tó lè ṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé ó tọ̀nà, àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Tá a bá sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a máa láyọ̀ lónìí, títí láé layọ̀ wa á sì máa pọ̀ sí i. w18.09 7 ¶18
Tuesday, February 18
Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò . . . kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.—Gál. 6:4.
Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí àwọn èèyàn pípé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú òun kí ohun tí òun ní lọ́kàn lè ṣẹ. Láìka àìpé táwa èèyàn ti jogún sí, àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lè bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ni wá bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 3:5-9) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run kà wá yẹ láti jọ ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí! Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nìkan kọ́ ni àwọn ọ̀nà tá a lè gbà bá Jèhófà ṣiṣẹ́. Àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni tá a bá ń ran ìdílé wa àtàwọn ará lọ́wọ́, tá a lẹ́mìí aájò àlejò, tá à ń yọ̀ǹda ara wa fún àwọn iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, tá a sì ń mú iṣẹ́ ìsìn wa gbòòrò sí i. (Kól. 3:23) Àmọ́ ká má ṣe fi ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà wé tàwọn míì. Ìdí ni pé ọjọ́ orí wa, ìlera wa, ipò tí kálukú wà àtohun tá a lè ṣe yàtọ̀ síra. w18.08 23 ¶1-2
Wednesday, February 19
Ṣáà máa retí rẹ̀! Torí yóò ṣẹ láìkùnà.—Háb. 2:3.
Jèhófà tu wòlíì rẹ̀ nínú ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun máa dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Ìyẹn ni pé, Jèhófà máa tó sọ ẹkún rẹ̀ dayọ̀. Ṣe ló dà bí ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ fún Hábákúkù pé: “Ṣe sùúrù, fọkàn tán mi. Màá dáhùn àdúrà rẹ, kódà tó bá tiẹ̀ ń pẹ́ lójú ẹ!” Jèhófà wá jẹ́ kó mọ̀ pé òun ti ní àkókò pàtó kan lọ́kàn tóun máa mú àwọn ìlérí òun ṣẹ. Ó fún Hábákúkù níṣìírí pé kó ní sùúrù. Ó dájú pé Jèhófà ò ní já wòlíì rẹ̀ kulẹ̀. Ó yẹ káwa náà ní sùúrù bá a ṣe ń dúró de Jèhófà, ká sì máa tẹ́tí sí ohun tó ń sọ fún wa. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, ọkàn wa á sì balẹ̀ láìka ìṣòro yòówù ká kojú. Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó sọ pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Olùpàkókòmọ́, ká má sì da ara wa láàmú nípa “àwọn ìgbà tàbí àsìkò” tí Ọlọ́run ò tíì fi hàn wá. (Ìṣe 1:7) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú wa, ẹ jẹ́ ká ní sùúrù, ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbàgbọ́, ká sì máa fọgbọ́n lo àkókò wa bá a ṣe ń fi gbogbo okun wa sin Jèhófà.—Máàkù 13:35-37; Gál. 6:9. w18.11 16 ¶13-14
Thursday, February 20
Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.—Ìṣe 10:28.
Àwọn Júù gbà pé aláìmọ́ làwọn tí kì í ṣe Júù, irú èrò yìí sì ni Pétérù náà ní. Àmọ́ àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí Pétérù yí èrò rẹ̀ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ó rí ìran àgbàyanu kan. (Ìṣe 10:9-16) Bíi ti Pétérù, a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò dáadáa, ká sì ṣe tán láti jẹ́ káwọn míì ràn wá lọ́wọ́ ká lè fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wa. Kí ni nǹkan míì tá a tún lè ṣe? Tá a bá jẹ́ kí ọkàn wa túbọ̀ gbòòrò sí i, ìfẹ́ á borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó bá wà lọ́kàn wa. (2 Kọ́r. 6:11-13) Ṣé àwọn ọmọ ìlú rẹ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń sọ èdè kan náà lo sábà máa ń bá kẹ́gbẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o túbọ̀ gbòòrò sí i. Lára ohun tó o lè ṣe ni pé kó o bá àwọn tó wá láti ẹ̀yà míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kó o pè wọ́n wá jẹun nílé rẹ. (Ìṣe 16:14, 15) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ onírúurú èèyàn, ìyẹn á sì jẹ́ kó o borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. w18.08 9 ¶3, 6; 10 ¶7
Friday, February 21
Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀.—1 Kọ́r. 10:32.
Àwọn Kristẹni kan máa ń fara wé àwọn èèyàn ayé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ijó tí kò yẹ Kristẹni àtàwọn ìwà tí kò dáa làwọn kan máa ń hù láwọn àpèjẹ. Àwọn míì máa ń gbé fọ́tò àtàwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ ọmọlúàbí sórí ìkànnì àjọlò. Wọn kì í ṣàpẹẹrẹ tó dáa, wọ́n sì lè kéèràn ran àwọn míì tó ń sapá láti máa hùwà rere nínú ìjọ. (1 Pét. 2:11, 12) Ohun tí ayé yìí ń gbé lárugẹ ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi ohun ìní ẹni ṣe àṣehàn.” (1 Jòh. 2:16) Àmọ́ torí pé a jẹ́ ti Jèhófà, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ‘kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé sílẹ̀, ká sì máa fi àròjinlẹ̀, òdodo àti ìfọkànsìn Ọlọ́run gbé nínú ètò àwọn nǹkan yìí.’ (Títù 2:12) Ó yẹ kó hàn nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe pé èèyàn Jèhófà la jẹ́, yálà nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ìmúra wa, bá a ṣe ń jẹ, bá a ṣe ń mu, ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́ wa àtàwọn nǹkan míì. w18.07 25 ¶13-14
Saturday, February 22
Ojú wa ń wo Jèhófà Ọlọ́run wa, títí á fi ṣojú rere sí wa.—Sm. 123:2.
Tá a bá ń wojú Jèhófà, a ò ní máa bínú nítorí àṣìṣe àwọn míì, a ò sì ní jẹ́ kíyẹn ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Èyí ṣe pàtàkì pàápàá tó bá jẹ́ pé àwa náà ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run bíi ti Mósè. Òótọ́ ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ‘máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀ yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.’ (Fílí. 2:12) Síbẹ̀ ká fi sọ́kàn pé bí àǹfààní tá a ní bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa ṣe máa pọ̀ tó. (Lúùkù 12:48) Àmọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, kò sóhun tó máa fa ìkọ̀sẹ̀ fún wa, kò sì sóhun táá mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Sm. 119:165; Róòmù 8:37-39) Nǹkan ò rọrùn rárá lásìkò tá à ń gbé yìí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wojú Ẹni “tí ń gbé ní ọ̀run” nígbà gbogbo, ká lè fòye mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe. (Sm. 123:1) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà àti ìṣe àwọn míì ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. w18.07 16 ¶19-20
Sunday, February 23
Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè . . . fògo fún Baba yín.—Mát. 5:16.
Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí iye àwa èèyàn Jèhófà túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé ìmọ́lẹ̀ wa ń tàn kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2017, ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́wàá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la darí. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe. Gbogbo àwọn tó wá ló kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run pèsè ìràpadà náà. (1 Jòh. 4:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwa èèyàn Jèhófà ń sọ kárí ayé, síbẹ̀ a wà níṣọ̀kan, a sì jùmọ̀ ń yin Jèhófà Baba wa ọ̀run. (Ìṣí. 7:9) Èdè yòówù ká máa sọ tàbí ibi yòówù ká máa gbé, a lè máa “tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Fílí. 2:15) Bá a ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tá a wà níṣọ̀kan, tá a sì ń wà lójúfò nípa tẹ̀mí ń fògo fún Jèhófà. w18.06 21 ¶1-3
Monday, February 24
Rábì, jẹun.—Jòh. 4:31.
Ìdáhùn tí Jésù fún wọn jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó ń gbádùn ọ̀rọ̀ tó ń bá obìnrin náà sọ débi pé kò ṣe tán àtijẹun. Iṣẹ́ ìwàásù dà bí oúnjẹ fún Jésù torí pé ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe nìyẹn, gbogbo èèyàn sì ni Jésù fẹ́ wàásù fún títí kan obìnrin ará Samáríà yẹn. (Jòh. 4:32-34) Jákọ́bù àti Jòhánù ò tètè lóye ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn yìí. Nígbà kan, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rìnrìn-àjò gba Samáríà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tí wọ́n lè sùn mọ́jú. Àmọ́ àwọn ará Samáríà ò gbà wọ́n sílé. Èyí múnú bí Jákọ́bù àti Jòhánù, wọ́n wá sọ fún Jésù pé kó jẹ́ káwọn pe iná wá láti ọ̀run kó lè jẹ ìlú náà run. Àmọ́ Jésù bá wọn wí lọ́nà mímúná. (Lúùkù 9:51-56) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jákọ́bù àti Jòhánù ò ní sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ká sọ pé Gálílì tó jẹ́ ìlú wọn làwọn èèyàn ti kọ̀ láti gbà wọ́n sílé. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ẹ̀tanú tí wọ́n ní sáwọn ará Samáríà ló mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn ará Samáríà tẹ́tí sí àpọ́sítélì Jòhánù nígbà tó wàásù lágbègbè náà, ó sì ṣeé ṣe kójú tì í tó bá rántí ohun tó sọ pé kó ṣẹlẹ̀ sílùú wọn lọ́jọ́ kìíní àná.—Ìṣe 8:14, 25. w18.06 10-11 ¶12-13
Tuesday, February 25
Ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè.—Éfé. 6:14.
Tá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì darí ìgbésí ayé wa, á rọrùn fún wa láti máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa parọ́? Ìdí ni pé ọ̀kan gbòógì nínú àwọn nǹkan tí Sátánì fi ń gbéjà kò wá ni irọ́ pípa. Irọ́ máa ń tàbùkù sẹ́ni tó pa á, ó sì máa ń ṣàkóbá fẹ́ni tó bá gba irọ́ náà gbọ́. (Jòh. 8:44) Torí náà, láìka pé a jẹ́ aláìpé, ó yẹ ká sapá láti máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. (Éfé. 4:25) Àmọ́ ká sòótọ́, kì í rọrùn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Abigail sọ pé: “Nígbà míì, ó lè dà bíi pé òótọ́ ò lérè, pàápàá tó bá jẹ́ pé irọ́ máa kó wa yọ nínú wàhálà kan.” Kí wá nìdí tó fi máa ń sòótọ́ nígbà gbogbo? Ó ní: “Sísọ òtítọ́ máa ń jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn rere. Àwọn òbí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sì fọkàn tán mi.” Victoria tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] sọ pé: “Tó o bá ń sòótọ́, tó o sì ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, àwọn kan lè halẹ̀ mọ́ ẹ. Síbẹ̀, àǹfààní tó o máa rí kì í ṣe kékeré, lára ẹ̀ ni pé: Wàá nígboyà, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.” Ẹ ò rí i báyìí pé ó ṣe pàtàkì ká fi ‘òtítọ́ di abẹ́nú wa lámùrè’ nígbà gbogbo. w18.05 28 ¶3, 5
Wednesday, February 26
Ẹ máa ṣọ́nà.—Mát. 24:42.
Ó yẹ ká túbọ̀ wà lójúfò pàápàá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí torí pé nǹkan túbọ̀ ń burú sí i. Ọkàn wa balẹ̀ pé àkókó tí Jèhófà ti pinnu ló máa gbé ìgbésẹ̀. (Mát. 24:42-44) Àmọ́, bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ náà, ẹ jẹ́ ká ní sùúrù, ká sì túbọ̀ wà lójúfò. Ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa gbàdúrà láìdabọ̀. (1 Pét. 4:7) A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti ń ṣọ́nà fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ sin Jèhófà. Tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tá a sì ń bá àwọn ará kẹ́gbẹ́, àá túbọ̀ máa láyọ̀, a ò tiẹ̀ ní mọ̀gbà tí àkókò máa lọ. (Éfé. 5:16) Inú wa dùn pé Jèhófà ò pa wá tì bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe. Bákan náà, ó fún wa láwọn alàgbà tí Bíbélì pè ní “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.” (Éfé. 4:8, 11, 12) Torí náà, nígbàkigbà táwọn alàgbà bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ, mọyì wọn kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n àti ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ. w18.06 24-25 ¶15-18
Thursday, February 27
Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ máa dúró nínú ìfẹ́ mi.—Jòh. 15:10.
Jésù ò kàn sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n wà nínú ìfẹ́ òun, àmọ́ ó ní kí wọ́n “dúró nínú ìfẹ́ [òun].” Kí nìdí? Ìdí ni pé, ó gba ìfaradà ká tó lè máa bá a lọ láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti ọdún dé ọdún. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “dúró” nínú Jòhánù 15:4-10 kó lè tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní ìfaradà. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Kristi, ká sì rí ojú rere rẹ̀? A gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́. Ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ sì ṣe nìyẹn, ó ní: ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.’ Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 13:15) Tá a bá pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká máa wàásù, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mát. 17:5; Jòh. 8:28) Tá a bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, àwọn náà máa jẹ́ ká dúró nínú ìfẹ́ wọn, wọn ò sì ní fi wá sílẹ̀ láé. w18.05 18 ¶5-7
Friday, February 28
Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.—Òwe 21:5.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, o ní láti pinnu ibi tó o máa kàwé dé, irú iṣẹ́ tó o máa ṣe àtàwọn nǹkan míì. Tó o bá ti pinnu ohun tó o fẹ́ fayé rẹ ṣe, kò ní nira fún ẹ láti ṣèpinnu. Tó o bá ti tètè pinnu ohun tó o fẹ́ fayé rẹ ṣe, ọwọ́ rẹ á tètè tẹ ohun tó ò ń lé. A gbóríyìn fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ tó wà láwọn ìjọ wa kárí ayé. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ lára yín lẹ̀ ń fayé yín sin Jèhófà, ẹ sì ti pinnu àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ìyẹn ń mú kẹ́ ẹ máa láyọ̀, ó sì ń mú kẹ́ ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà ní gbogbo apá ìgbésí ayé yín. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ ń fi ìlànà Jèhófà sọ́kàn tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Sólómọ́nì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. . . . Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Jèhófà mọyì ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa lọ́pọ̀lọpọ̀, ó nífẹ̀ẹ́ yín gan-an, ó ń dáàbò bò yín, ó ń tọ́ yín sọ́nà, ó sì ń bù kún yín. w18.04 26 ¶7; 27 ¶9
Saturday, February 29
Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. —Jòh. 13:34.
Àpọ́sítélì Jòhánù wà lára àwọn tó múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni láyé àtijọ́. Òun náà wà lára àwọn tó kọ Ìhìn Rere nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Ìwé tó kọ yìí fún àwọn Kristẹni ìgbà yẹn níṣìírí gan-an, ó sì ń fún àwa náà níṣìírí lónìí torí pé ìròyìn amọ́kànyọ̀ ló wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù nìkan ló ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Jésù sọ pé ìfẹ́ la fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ mọ̀. (Jòh. 13:35) Yàtọ̀ sí Ìhìn Rere tí Jòhánù kọ, ó tún kọ àwọn lẹ́tà mẹ́ta sáwọn Kristẹni kó lè fún wọn níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ṣé ọkàn wa kì í balẹ̀ tá a bá rántí pé “ẹ̀jẹ̀ Jésù . . . ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀”? (1 Jòh. 1:7) Tí ọkàn wa bá sì ń dá wa lẹ́bi, ṣé inú wa kì í dùn tá a bá ka ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé, “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ”? (1 Jòh. 3:20) Yàtọ̀ síyẹn, Jòhánù nìkan ló sọ pé, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8, 16) Nínú lẹ́tà kejì àti kẹta tí Jòhánù kọ sáwọn Kristẹni, ó fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—2 Jòh. 4; 3 Jòh. 3, 4. w18.04 18 ¶14-15