ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es20 ojú ìwé 27-37
  • March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Sunday, March 1
  • Monday, March 2
  • Tuesday, March 3
  • Wednesday, March 4
  • Thursday, March 5
  • Friday, March 6
  • Saturday, March 7
  • Sunday, March 8
  • Monday, March 9
  • Tuesday, March 10
  • Wednesday, March 11
  • Thursday, March 12
  • Friday, March 13
  • Saturday, March 14
  • Sunday, March 15
  • Monday, March 16
  • Tuesday, March 17
  • Wednesday, March 18
  • Thursday, March 19
  • Friday, March 20
  • Saturday, March 21
  • Sunday, March 22
  • Monday, March 23
  • Tuesday, March 24
  • Wednesday, March 25
  • Thursday, March 26
  • Friday, March 27
  • Saturday, March 28
  • Sunday, March 29
  • Monday, March 30
  • Tuesday, March 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2020
es20 ojú ìwé 27-37

March

Sunday, March 1

Ò . . . ń ṣàkóso ohun gbogbo.​—1 Kíró. 29:12.

Tá a bá ka orí méjì àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a máa rí i pé Ádámù àti Éfà gbádùn òmìnira táwa ò ní lónìí. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ ni wọ́n ní, kò sóhun tó ń kó wọn láyà sókè, kò sì sẹ́ni tó ń ni wọ́n lára. Wọn kì í ṣàníyàn rárá nípa oúnjẹ tàbí iṣẹ́ tí wọ́n á ṣe, wọn ò ṣàìsàn, wọn ò sì bẹ̀rù pé àwọn máa kú. (Jẹ́n. 1:​27-29; 2:​8, 9, 15) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa òmìnira, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà nìkan ló lè ṣe ohunkóhun tó wù ú láìsí pé ẹnikẹ́ni ń yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. Ìdí ni pé òun ló dá ohun gbogbo, òun sì ni Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run. (1 Tím. 1:17; Ìṣí. 4:11) Àmọ́ gbogbo àwa èèyàn títí kan àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run ló níbi tí òmìnira wa mọ. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́, ó sì láṣẹ láti fún wa láwọn òfin àti ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ohun tí Jèhófà sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́. w18.04 4 ¶4, 6

Monday, March 2

Wo bí ẹsẹ̀ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá ṣe rẹwà tó.​—Àìsá. 52:7.

Nǹkan ò rọrùn nínú ayé Sátánì, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára wa. (2 Kọ́r. 4:​7, 8) Àmọ́ ẹ jẹ́ ká ronú nípa bó ṣe máa ṣòro tó fáwọn tí kò mọ Jèhófà láti fara da àwọn ìṣòro tó kúnnú ayé yìí. Bíi ti Jésù, àánú wọn máa ń ṣe wá, ìdí nìyẹn tá a fi ń ‘mú ìhìn rere nípa ohun tó sàn’ lọ fún wọn. Torí náà máa ní sùúrù fáwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Rántí pé àwa la lóye àwọn òtítọ́ Bíbélì yìí, àmọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè má gbọ́ àwọn òtítọ́ yẹn rí. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ti jingíri lọ́kàn wọn. Bákan náà, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé ẹ̀sìn táwọn ń ṣe ló jẹ́ káwọn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ìdílé wọn, kí àárín àwọn àtàwọn aládùúgbò wọn sì gún. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀sìn yẹn lè ti di ara àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ká tó sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n pa ìgbàgbọ́ wọn àtijọ́ tì, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n lóye òtítọ́ Bíbélì dáadáa kí wọ́n sì mọyì rẹ̀. Ìgbà yẹn ló máa tó rọrùn fún wọn láti pa ìgbàgbọ́ wọn àtijọ́ tì. Ká sòótọ́, ó lè gba àkókò káwọn èèyàn tó lè ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀.​—Róòmù 12:2. w19.03 23 ¶10, 12; 24 ¶13

Tuesday, March 3

Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.​—Máàkù 1:11.

Àpẹẹrẹ gidi ni Jèhófà fi lélẹ̀ tó bá di pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn ká sì máa gbóríyìn fún wọn. (Jòh. 5:20) Orí wa máa ń wú táwọn tó sún mọ́ wa bá fìfẹ́ hàn sí wa tí wọ́n sì yìn wá fún nǹkan rere tá a ṣe. Bákan náà, inú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin àtàwọn ìdílé wa máa dùn tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn tá a sì ń fún wọn níṣìírí. Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn èèyàn, á mú kí wọ́n túbọ̀ fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Jèhófà, ìgbàgbọ́ wọn á sì lágbára sí i. Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn. Tẹ́yin òbí bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn, tẹ́ ẹ sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn, wọ́n á túbọ̀ máa ṣe dáadáa. Gbólóhùn náà: “Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́” jẹ́ ká rí i pé Jèhófà fọkàn tán Jésù pé ó máa ṣe ìfẹ́ òun láìbọ́hùn. Torí pé Jèhófà fọkàn tán Ọmọ rẹ̀, ó yẹ káwa náà fọkàn tán Jésù láìsí iyèméjì pé ó máa mú gbogbo ìlérí Jèhófà ṣẹ. (2 Kọ́r. 1:20) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, àá túbọ̀ pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀ ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.​—1 Pét. 2:21. w19.03 8 ¶3; 9 ¶5-6

Wednesday, March 4

Òfin ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè nínú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.​—Róòmù 8:2.

Tá a bá mọyì ẹ̀bùn iyebíye tẹ́nì kan fún wa, a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọyì òmìnira tí Jèhófà fi jíǹkí wọn lẹ́yìn tó dá wọn nídè kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Láàárín oṣù mélòó kan péré tí wọ́n kúrò níbẹ̀, ṣe lọkàn wọn ń fà sí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní Íjíbítì, wọ́n sì ń ráhùn nípa ìpèsè Jèhófà. Kódà, wọ́n ronú láti pa dà sí Íjíbítì. Àbí ẹ ò rí nǹkan, ‘ẹja, apálá, bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti aáyù’ lásánlàsàn ni wọ́n kà sí pàtàkì ju òmìnira tí wọ́n ní láti sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́! Abájọ tí Jèhófà fi bínú sí wọn. (Núm. 11:​5, 6, 10; 14:​3, 4) Ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn jẹ́ fún wa lónìí! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé ká má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú òmìnira tí Jèhófà fún wa nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀.​—2 Kọ́r. 6:1. w18.04 9-10 ¶6-7

Thursday, March 5

Ó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ kún inú ayé. ​—Sm. 33:5.

Gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, bẹ́ẹ̀ la ò sì fẹ́ kí wọ́n rẹ́ wa jẹ. Inú wa kì í dùn táwọn èèyàn ò bá rí tiwa rò tàbí tí wọ́n fọwọ́ ọlá gbá wa lójú, kódà ó lè ṣe wá bíi pé a ò wúlò. Jèhófà mọ̀ pé ó máa ń wù wá pé káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, kí wọ́n má sì fi ẹ̀tọ́ wa dù wá. (Sm. 33:5) Ohun kan tó dájú ni pé Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì fẹ́ káwọn èèyàn máa fi ẹ̀tọ́ wa dù wá. Èèyàn á rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí téèyàn bá fara balẹ̀ wo Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè. Tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Òfin Mósè, a máa rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Róòmù 13:​8-10) A lè kíyè sí i pé ìfẹ́ ni Òfin Mósè dá lé torí pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ méjì péré ni gbogbo òfin náà rọ̀ mọ́, ìyẹn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa. (Léf. 19:18; Diu. 6:5; Mát. 22:​36-40) Torí náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òfin tó lé lọ́gọ́rùn-ún mẹ́fà (600) yẹn ló gbé ìfẹ́ Jèhófà yọ lọ́nà kan tàbí òmíì. w19.02 20-21 ¶1-4

Friday, March 6

Ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.​—Mát. 6:21.

Jóòbù kì í bá àwọn obìnrin tage, kì í sì í ṣẹ̀fẹ̀ rírùn. (Jóòbù 31:1) Ó mọ̀ pé kò dáa kóun máa tẹjú mọ́ obìnrin míì, bíi pé kóun bá a ṣe ìṣekúṣe. Lónìí, kò síbi téèyàn yíjú sí tí kò ní rí àwọn ohun tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè. Bíi ti Jóòbù, ṣé àwa náà kì í tẹjú mọ́ ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa? Ṣé a kì í wo àwòrán oníhòòhò tàbí ohunkóhun tó lè mú kó wù wá láti ṣèṣekúṣe? (Mát. 5:28) Tá a bá ń sapá láti kóra wa níjàánu lójoojúmọ́, ìyẹn á mú ká lè máa hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo. Jóòbù tún ṣègbọràn sí Jèhófà ní ti ojú tó fi ń wo àwọn ohun ìní tara. Jóòbù mọ̀ pé tó bá jẹ́ ohun ìní tara ni òun ń lé, òun máa ṣẹ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì lè fìyà jẹ òun. (Jóòbù 31:​24, 25, 28) Lónìí, bí àwọn èèyàn ṣe máa kó ohun ìní tara jọ pelemọ ni wọ́n ń wá. Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo owó àtàwọn ohun ìní tara làwa náà fi ń wò ó, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rọ̀ wá pé ká ṣe, ìwà tó tọ́ làá máa hù nígbà gbogbo.​—Òwe 30:​8, 9; Mát. 6:​19, 20. w19.02 6 ¶13-14

Saturday, March 7

Bí Baba ṣe nífẹ̀ẹ́ mi, èmi náà nífẹ̀ẹ́ yín.​—Jòh. 15:9.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, Jésù sì gbé ìfẹ́ yìí yọ nínú gbogbo ohun tó ṣe. (1 Jòh. 4:​8-10) Ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jésù gbà fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí wa ni bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. Yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí “àgùntàn mìíràn,” gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú ìfẹ́ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa nípasẹ̀ ìràpadà náà. (Jòh. 10:16; 1 Jòh. 2:2) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá wo àwọn nǹkan ìṣàpẹẹrẹ tí Jésù lò fún ìrántí ikú rẹ̀, àá rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì gba tiwa rò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Dípò kí Jésù tẹ́ tábìlì lọ rẹ-rẹ-rẹ nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, nǹkan díẹ̀ ló lò láti fi ṣe ètò náà, èyí sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn. Ìdí ni pé bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwọn ọmọlẹ́yìn yìí máa bá ara wọn ní onírúurú ipò táá sì pọn dandan pé kí wọ́n ṣe Ìrántí Ikú Kristi, kódà àwọn míì máa ṣe é nínú ẹ̀wọ̀n. (Ìfi. 2:10) Ǹjẹ́ wọ́n pa àṣẹ Jésù mọ́ lábẹ́ àwọn ipò tí kò bára dé yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Títí dòní, àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń sapá gan-an ká lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi. w19.01 24 ¶13-15

Sunday, March 8

Ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.​—Jòh. 8:32.

Òmìnira yẹn máa gbà wá lọ́wọ́ ìsìn èké, àìmọ̀kan àti ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán. Kò tán síbẹ̀ o, lọ́jọ́ iwájú a tún máa ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ìwọ náà máa ní òmìnira yẹn báyìí tó o bá ‘dúró nínú ọ̀rọ̀ Kristi’ tó o sì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò. (Jòh. 8:31) Nípa bẹ́ẹ̀, wàá “mọ òtítọ́,” kì í ṣe torí pé o kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìkan, àmọ́ torí pé ò ń fi sílò nígbèésí ayé rẹ. Téèyàn bá tiẹ̀ rí towó ṣe nínú ayé tó ń lọ sópin yìí, ìgbádùn náà kì í tọ́jọ́, torí pé òní la rí, kò sẹ́ni mọ̀la. (Ják. 4:​13, 14) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o máa rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Tím. 6:19) Ohun kan ni pé Jèhófà kì í fipá múni rìn lójú ọ̀nà yẹn, ọwọ́ wa nìyẹn kù sí. Torí náà fi Jèhófà ṣe “ìpín” rẹ. (Sm. 16:5) Kó o sì mọyì ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “ohun rere” tó fún ẹ. (Sm. 103:5) Ní paríparí ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé òun nìkan ló lè fún ẹ ní ayọ̀, táá sì jẹ́ kí ayé rẹ dùn títí láé.​—Sm. 16:11. w18.12 28 ¶19, 21

Monday, March 9

Kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀. ​—1 Kọ́r. 7:11.

Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá ká lè máa fojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo ìgbéyàwó wò ó. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí àìpé tá a jogún. (Róòmù 7:​18-23) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘kí aya má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀.’ Síbẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kan pínyà. (1 Kọ́r. 7:10) Pọ́ọ̀lù ò sọ ohun tó mú kí wọ́n pínyà. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe torí pé ọkọ kan ṣèṣekúṣe, èyí tó lè mú kí ìyàwó pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun á sì fẹ́ ẹlòmíì. Pọ́ọ̀lù sọ pé kí aya kan tó ti pínyà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ “wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.” Ìdí ni pé tọkọtaya ṣì làwọn méjèèjì lójú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé ìṣòro yòówù kí wọ́n ní, tí kò bá ti jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe, ṣe ni kí wọ́n yanjú ẹ̀. Àwọn méjèèjì lè tọ àwọn alàgbà lọ pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́. Àwọn alàgbà máa fún wọn nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. w18.12 13 ¶14-15

Tuesday, March 10

Ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.​—Mát. 6:33.

Lónìí, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, ká sì ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. (Mát. 28:​19, 20; Ják. 4:8) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì ronú pé ire wa làwọn ń wá lè máa rọ̀ wá pé ká bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn nǹkan míì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọ̀gá ẹ fẹ́ fún ẹ ní ìgbéga, á sì tún fi kún owó ẹ, àmọ́ ìgbéga náà ò ní jẹ́ kó o fi bẹ́ẹ̀ ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí, kí ni wàá ṣe? Tó bá jẹ́ pé ọmọléèwé ni ẹ́, tí wọ́n fún ẹ láǹfààní láti lọ kàwé sí i, tíyẹn sì máa gba pé kó o kúrò nílé lọ síbi tó jìn, kí ni wàá ṣe? Ṣé ìgbà yẹn ló yẹ kó o ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí tàbí fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn míì kó o tó ṣèpinnu? Á dáa kó o mọ èrò Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, kó o sì pinnu ohun tí wàá ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Tó bá wá ṣẹlẹ̀, kò ní bá ẹ lábo. Ó ṣe tán, o ti pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló máa gbawájú láyé rẹ. w18.11 27 ¶18

Wednesday, March 11

Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ. ​—Òwe 4:23.

Ọ̀dọ́ ni Sólómọ́nì nígbà tó di ọba Ísírẹ́lì. Kò pẹ́ sígbà tó gorí oyè ni Jèhófà fara hàn án lójú àlá tó sì sọ fún un pé: ‘Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.’ Sólómọ́nì dáhùn pé ọ̀dọ́ ni òun àti pé òun ò ní ìrírí. Ó wá sọ pé kí Jèhófà fún òun ní “ọkàn-àyà ìgbọràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn” Jèhófà. (1 Ọba 3:​5-10) Ohun tí Sólómọ́nì béèrè yìí fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ gan-an. Abájọ tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ Sólómọ́nì! (2 Sám. 12:24) Inú Ọlọ́run dùn sí ohun tí Sólómọ́nì béèrè débi pé ó fún un ní “ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye.” (1 Ọba 3:12) Ní gbogbo àkókò tí Sólómọ́nì fi fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ó rí ìbùkún gbà. Bí àpẹẹrẹ, òun ló láǹfààní àtikọ́ tẹ́ńpìlì  “fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (1 Ọba 8:20) Jèhófà fún un ní ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó gbajúmọ̀ gan-an. Bákan náà, àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tó sọ wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn ìwé mẹ́ta tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ni ìwé Òwe. w19.01 14 ¶1-2

Thursday, March 12

Ẹ má . . . jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín.​—Róòmù 12:2.

Àwọn kan kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dá sọ́rọ̀ wọn tàbí kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. Wọ́n máa ń sọ pé: “Ohun tó bá wù mí ni màá ṣe.” Wọ́n gbà pé àwọn lè ṣèpinnu láìsí pé ẹnì kan ń yẹ àwọn lọ́wọ́ wò. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni darí wọn, kódà wọn kì í fẹ́ fara wé ẹnikẹ́ni. Ká fi sọ́kàn pé bá a ṣe ń jẹ́ kí Jèhófà darí èrò wa kò túmọ̀ sí pé a ò lómìnira láti pinnu ohun tá a fẹ́. 2 Kọ́ríńtì 3:17 sọ pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” Bí àpẹẹrẹ, a lómìnira láti yan irú ẹni tó wù wá láti jẹ́. A lè yan ohun tó wù wá, a sì lè pinnu ohun tá a máa ṣe. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fún wa lómìnira yìí, síbẹ̀ ká fi sọ́kàn pé ó níbi tí òmìnira wa mọ. (1 Pét. 2:16) Tó bá dọ̀rọ̀ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, Jèhófà fẹ́ ká gbé ìpinnu wa ka èrò rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. w18.11 19 ¶5-6

Friday, March 13

Démà ti pa mí tì torí ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan yìí.​—2 Tím. 4:10.

Nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn nǹkan tẹ̀mí ló jẹ wá lógún jù, kì í ṣe nǹkan tara. Inú wa dùn gan-an láti yááfì àwọn nǹkan tara ká lè ra òtítọ́. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a lè máa rí i pé àwọn míì ń ra àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tàbí kí wọ́n máa gbádùn àwọn nǹkan tuntun tó lòde. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe wá bíi pé a fi nǹkan du ara wa bá a ṣe yááfì àwọn nǹkan tara. Ìyẹn lè mú kí àwọn ohun kòṣeémáàní tá a ní má tẹ́ wa lọ́rùn mọ́, ká wá bẹ̀rẹ̀ sí í lé nǹkan tara. Èyí jẹ́ ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Démà. Ìfẹ́ tó ní fún “ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí” mú kó pa iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tì. Kí nìdí tí Démà fi pa Pọ́ọ̀lù tì? Ó lè jẹ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara ju iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣe fún Jèhófà tàbí kó jẹ́ pé ó ti sú u láti máa yááfì àwọn nǹkan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, Bíbélì ò sọ. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn débi tá a fi máa gbé òtítọ́ iyebíye sọ nù. w18.11 10 ¶9

Saturday, March 14

Ó dájú pé ẹ ò ní kú.​—Jẹ́n. 3:4.

Irọ́ burúkú ni Sátánì pa yìí torí ó mọ̀ dáadáa pé tí Éfà bá jẹ èso náà, ó máa kú. Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà àti Ádámù rú òfin Ọlọ́run, àìgbọràn yìí ló sì ṣekú pa wọ́n. (Jẹ́n. 3:6; 5:5) Àmọ́ àwọn nìkan kọ́ ló jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yìí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ló mú kí ‘ikú tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.’ Kì í ṣèyẹn nìkan, òun ló mú kí “ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba . . . , àní lórí àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ ní ìfarajọ ìrélànàkọjá Ádámù.” (Róòmù 5:​12, 14) Ìdí nìyẹn tá ò fi gbádùn ìlera tó pé, tá ò sì wà láàyè títí láé bí Ọlọ́run ṣe ní lọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára káká lèèyàn fi ń lo àádọ́rin (70) ọdún, “àkànṣe agbára ńlá” sì ni téèyàn bá lè lo ọgọ́rin (80) ọdún. Síbẹ̀, ìgbésí ayé ọ̀hún kún fún “ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́.” (Sm. 90:10) Ẹ ò rí i pé àdánù gbáà lèyí, irọ́ tí Sátánì pa lọ́jọ́ kìíní àná ló sì fà á! Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Sátánì, ó sọ pé: ‘Kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀.’ (Jòh. 8:44) Títí di báyìí, òtítọ́ ò sí nínú Sátánì torí pé ó ṣì ń parọ́ kó lè “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìfi. 12:9) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kí Èṣù fi irọ́ tú wa jẹ. w18.10 6-7 ¶1-4

Sunday, March 15

Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá àlàáfíà, torí a máa pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run.​—Mát. 5:9.

Àwọn tó bá ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì máa ń láyọ̀. Jákọ́bù sọ pé: “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Ják. 3:18) Tí àárín àwa àti ẹnì kan nínú ìjọ tàbí nínú ìdílé wa kò bá gún régé, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa fi àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù, a sì máa láyọ̀. Jésù sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa wá àlàáfíà nígbà tó sọ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”​—Mát. 5:​23, 24. w18.09 21 ¶17

Monday, March 16

Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.​—Jòh. 13:34.

Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n (30) ìgbà tí Jésù mẹ́nu kan ìfẹ́. Ó dìídì tẹnu mọ́ ọn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòh. 15:​12, 17) Ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ló máa jẹ́ kó hàn kedere pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n. (Jòh. 13:35) Ìfẹ́ tí Jésù ń sọ yìí kì í ṣe ìfẹ́ oréfèé lásán àmọ́ ó jẹ́ ìfẹ́ tó máa ń mú kéèyàn fara ẹ̀ jìn fáwọn míì. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòh. 15:​13, 14) Lónìí, ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ ni pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú, a wà níṣọ̀kan, a sì máa ń fi ara wa jìn fáwọn míì. (1 Jòh. 3:​10, 11) Inú wa dùn gan-an pé láìka ẹ̀yà, àwọ̀, èdè àti ibi tá a ti wá sí, ìfẹ́ tòótọ́ làwa èèyàn Jèhófà ní sí ara wa. w18.09 12 ¶1-2

Tuesday, March 17

Tí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún ìdílé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́.​—1 Tím. 5:8.

Jèhófà ń fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bójú tó ìdílé wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká ṣiṣẹ́ ká lè pèsè fún ìdílé wa. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá máa ń wà nílé kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn jòjòló. Àwọn ọmọ kan sì ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà. Ká sòótọ́, àwọn ojúṣe yìí ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, o lè má fi bẹ́ẹ̀ ráyè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ má bọkàn jẹ́! Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá rí i pé à ń pèsè fún ìdílé wa. (1 Kọ́r. 10:31) Tó bá jẹ́ pé àwọn ojúṣe ìdílé tó ò ń bójú tó kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ǹjẹ́ o lè ran àwọn míì lọ́wọ́? Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń tọ́jú àwọn aláìlera, àwọn aláìsàn, àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn míì. O lè kíyè sí àwọn tó wà nínú ìjọ rẹ kó o lè mọ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ nìyẹn, ó sì lè jẹ́ pé Jèhófà ń lò ẹ́ láti dáhùn àdúrà ẹni náà.​—1 Kọ́r. 10:24. w18.08 24 ¶3, 5

Wednesday, March 18

Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, ó gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.​—Ìṣe 7:​9, 10.

Jósẹ́fù ni Jékọ́bù fẹ́ràn jù nínú gbogbo ọmọ tó bí. Àmọ́ nígbà tí Jósẹ́fù wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á sóko ẹrú torí pé wọ́n ń jowú rẹ̀. (Jẹ́n. 37:​2-4, 23-28) Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá (13) ni Jósẹ́fù fi jẹ palaba ìyà. Ẹrú ni ní Íjíbítì, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi jù ú sẹ́wọ̀n. Ní gbogbo àsìkò yìí, kò fojú kan bàbá rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ gan-an. Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tí kò fi kárísọ, tí kò sì sọ̀rètí nù? Nígbà tí Jósẹ́fù ń jìyà lẹ́wọ̀n, ó ṣeé ṣe kó máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ran òun lọ́wọ́. (Jẹ́n. 39:21; Sm. 105:​17-19) Ó tún ṣeé ṣe kó máa rántí àlá tó lá nígbà tó wà ní kékeré, kíyẹn sì jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. (Jẹ́n. 37:​5-11) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló tú ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà. (Sm. 145:18) Jèhófà dáhùn àdúrà Jósẹ́fù, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun máa “wà pẹ̀lú rẹ̀” láìka gbogbo ìṣòro tó ń kojú sí. w18.10 28 ¶3-4

Thursday, March 19

Àwọn tó sún mọ́ tálákà pàápàá máa ń kórìíra rẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá olówó ṣọ̀rẹ́.​—Òwe 14:20.

Bí ẹnì kan ṣe lówó tó lè mú ká máa gbé e gẹ̀gẹ̀ tàbí ká fojú yẹpẹrẹ wò ó. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú pàtàkì wo àwọn olówó, ká sì máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí kò ní. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Bí a ṣe rí i nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní, lábẹ́ ìmísí, Sólómọ́nì sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò ṣeé já ní koro nípa àwa èèyàn aláìpé. Kí ni òwe yìí kọ́ wa? Àwọn èèyàn máa ń sọ pé, ‘olówó layé mọ̀.’ Táwa náà ò bá ṣọ́ra, ó lè máa wù wá láti bá àwọn ará tó lówó ṣọ̀rẹ́, ká sì máa yẹra fáwọn tí kò ní. Àmọ́, ó léwu tá a bá ń fi bí ẹnì kan ṣe lówó tó pinnu irú ẹni tó jẹ́. Kí nìdí? Ó lè fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú ìjọ, á wá di pé kólówó máa ṣọ̀rẹ́ olówó. Jákọ́bù kìlọ̀ pé irú nǹkan báyìí ti fa ìyapa nínú àwọn ìjọ kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ják. 2:​1-4) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má ṣe fàyè gba èrò yìí torí pé ó lè fa ìyapa nínú ìjọ, ká sì rí i dájú pé a kì í fi báwọn èèyàn ṣe rí dá wọn lẹ́jọ́. w18.08 10 ¶8-10

Friday, March 20

Ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín. ​—1 Pét. 4:8.

Ọwọ́ tá a bá fi mú àwọn ará wa máa fi hàn bóyá a mọyì àǹfààní tá a ní láti jẹ́ èèyàn Jèhófà. Tá a bá ń fi sọ́kàn pé èèyàn Jèhófà làwọn ará wa, gbogbo ìgbà làá máa fi ìfẹ́ àti inúure hàn sí wọn. (1 Tẹs. 5:15) Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:35) Málákì sọ ohun kan tó gbàfiyèsí, ó sọ pé báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, Jèhófà ń “fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀.” (Mál. 3:16) Ó dájú pé Jèhófà “mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.” (2 Tím. 2:19) Gbogbo ohun tá à ń sọ, tá a sì ń ṣe pátápátá ló mọ̀. (Héb. 4:13) Ká fi sọ́kàn pé tá ò bá fi inúure hàn sáwọn ará wa, Jèhófà ń “fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀.” Bákan náà, Jèhófà máa ń mọ̀ tá a bá ṣe inúure sáwọn ará, tá a ràn wọ́n lọ́wọ́, tá a dárí jì wọ́n, tá a sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn.​—Héb. 13:16. w18.07 26 ¶15, 17

Saturday, March 21

[Jèhófà] ni kí o rọ̀ mọ́.​—Diu. 10:20.

Kò sí àní-àní pé ti Jèhófà ló yẹ ká ṣe. Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó lágbára, tó gbọ́n, tó sì nífẹ̀ẹ́ tó Ọlọ́run wa! Ó dájú pé kò sẹ́ni tí kò ní fẹ́ wà lọ́dọ̀ Jèhófà. (Sm. 96:​4-6) Síbẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan wà tó fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kojú àdánwò. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kéènì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kéènì sọ pé òun ń sin Jèhófà, síbẹ̀ Jèhófà ò fojúure wo ìjọsìn Kéènì. Ìdí sì ni pé ìkórìíra ti ń jọba lọ́kàn rẹ̀. (1 Jòh. 3:12) Jèhófà wá kìlọ̀ fún Kéènì pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?” (Jẹ́n. 4:​6, 7) Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún Kéènì pé, “Tó o bá ronú pìwà dà, tó o sì dúró sọ́dọ̀ mi, èmi náà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀.” Àmọ́ Kéènì ò gba ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún un. w18.07 17 ¶1, 3; 18 ¶4

Sunday, March 22

Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn.​—Mát. 5:16.

Ó dájú pé ọ̀nà kan tá a lè gbà jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn ni pé ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:​19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, a tún lè fi ìwà wa yin Jèhófà torí pé àwọn tá à ń wàásù fún àtàwọn tó ń rí wa ń kíyè sí ìwà wa. Bá a ṣe ń rẹ́rìn-ín sí wọn, tá a sì ń fọ̀yàyà kí wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ púpọ̀ nípa wa àti Ọlọ́run tá à ń sìn. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà.” (Mát. 10:12) Àwọn èèyàn lágbègbè tí Jésù ti wàásù sábà máa ń gba àwọn àjèjì sílé wọn. Àmọ́, torí bí nǹkan ṣe rí lónìí, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gba àjèjì sílé mọ́. Síbẹ̀, tá a bá fọ̀yàyà kí àwọn tá a fẹ́ wàásù fún, tá a ṣe bí ọ̀rẹ́ sí wọn, tá a sì fohùn tútù ṣàlàyé ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ wọn, ọkàn wọn á balẹ̀, ara á sì tù wọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀rín músẹ́ nìkan ti tó láti fa àwọn èèyàn mọ́ra. Àwọn tó ń wàásù níbi térò pọ̀ sí ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Tó o bá ń wàásù níbi térò pọ̀ sí, wàá kíyè sí i pé ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti mú àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a bá rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, tá a sì fọ̀yàyà kí wọn. w18.06 22 ¶4-5

Monday, March 23

Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.​—Ìṣe 10:34.

Àwọn Júù nìkan ni àpọ́sítélì Pétérù máa ń bá ṣe wọléwọ̀de. Àmọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú, Pétérù wàásù fún ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù. (Ìṣe 10:​28, 35) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù ṣọ̀rẹ́, wọ́n sì jọ ń jẹun. Àmọ́ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù nílùú Áńtíókù, kò sì bá wọn jẹun mọ́. (Gál. 2:​11-14) Èyí mú kí Pọ́ọ̀lù bá Pétérù wí, Pétérù sì gba ìbáwí náà. Nígbà tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sàwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù ní Éṣíà Kékeré, ó sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará. (1 Pét. 1:1; 2:17) Ó dájú pé àwọn àpọ́sítélì kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù pé àwọn gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (Jòh. 12:32; 1 Tím. 4:10) Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fojú tó dáa wo àwọn míì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ kó tó mọ́ wọn lára. Àwọn Kristẹni yẹn gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, èyí sì jẹ́ kí wọ́n máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n.​—Kól. 3:​10, 11. w18.06 11 ¶15-16

Tuesday, March 24

Ẹ dúró gbọn-in . . . kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀.​—Éfé. 6:14.

Àwọn irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ tí wọ́n dè mọ́ ara wọn ni wọ́n fi ṣe àwo ìgbàyà táwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń lò. Wọ́n sì fi awọ tó nípọn de àwọn irin náà kó lè bo àyà àwọn ọmọ ogun. Ó lè gba pé kó máa yẹ ìhámọ́ra náà wò lóòrèkóòrè kó lè rí i dájú pé ó dúró bó ṣe yẹ kó lè dáàbò bo ọkàn rẹ̀, kò sì ní jẹ́ káwọn nǹkan yẹn pa á lára. Àfiwé yìí bá a mu gan-an torí pé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà máa ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. (Òwe 4:23) Ó dájú pé ọmọ ogun kan ò ní pààrọ̀ àwo ìgbàyà tí wọ́n fi ojúlówó irin ṣe fún èyí tó jẹ́ gbàrọgùdù. Lọ́nà kan náà, kò yẹ ká fi ohun tá a rò pé ó tọ́ rọ́pò àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Ìdí ni pé òye wa ò tó nǹkan, a ò sì lè fi ọgbọ́n orí wa dáàbò bo ara wa. (Òwe 3:​5, 6) Torí náà, ó yẹ ká máa yẹ ‘àwo ìgbàyà’ tí Jèhófà fún wa wò déédéé, ká lè rí i dájú pé ó ṣì ń dáàbò bo ọkàn wa. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Èyí máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti gbé “àwo ìgbàyà” wọ̀, ìyẹn ni pé á rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà.​—Sm. 111:​7, 8; 1 Jòh. 5:3. w18.05 28 ¶3-4, 6-7

Wednesday, March 25

Àwọn èèyàn náà ń bá Mósè jà.​—Nọ́ń. 20:3.

Láìka bí Mósè ṣe fara ẹ̀ jìn fáwọn èèyàn náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ṣì ń ráhùn. Kì í ṣe torí omi nìkan, wọ́n tún ń ráhùn sí Mósè bíi pé òun ni ò jẹ́ kí wọ́n rómi mu. (Núm. 20:​1-5, 9-11) Inú bí Mósè gan-an, èyí sì mú kó gbaná jẹ. Dípò kó ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé kó bá àpáta náà sọ̀rọ̀, ṣe ló sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn èèyàn náà, ó sì gbógo fún ara rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ó lu àpáta náà lẹ́ẹ̀mejì, omi sì bú jáde. Ìgbéraga àti ìbínú ló mú kí Mósè ṣe àṣìṣe ńlá yẹn. (Sm. 106:​32, 33) Torí pé Mósè ṣi inú bí fúngbà díẹ̀, Jèhófà ò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 20:12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ sapá ká lè jẹ́ ọlọ́kàn tútù nígbà gbogbo. Tá a bá jẹ́ kí ànímọ́ yìí sọnù kódà fúngbà díẹ̀, ìgbéraga lè mú ká sọ̀rọ̀ tàbí ká ṣe ohun tá a máa pa dà kábàámọ̀. Ìkejì, ìdààmú ọkàn lè jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì, torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù kódà tá a bá ní ìdààmú ọkàn. w19.02 12-13 ¶19-21

Thursday, March 26

A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. ​—Mát. 24:14.

Ǹjẹ́ àṣẹ tí Jésù pa pé ká máa wàásù ṣòro láti pa mọ́? Rárá o. Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àjàrà náà, ó sọ pé àwọn tó ń wàásù ìhìn rere máa ní ayọ̀. (Jòh. 15:11) Kódà, ó fi dá wa lójú pé ìdùnnú òun máa di tiwa. Lọ́nà wo? Bá a ṣe sọ ṣáájú, Jésù fi ara rẹ̀ wé igi àjàrà, ó sì fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé ẹ̀ka igi. (Jòh. 15:5) Igi ló máa ń gbé ẹ̀ka igi ró, torí náà tí ẹ̀ka kan bá ṣì wà lára igi, á máa rí omi àtàwọn èròjà míì tó nílò látara igi náà. Lọ́nà kan náà, táwa náà bá wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tá a sì ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, a máa ní irú ayọ̀ tí Jésù ní bó ṣe ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Jòh. 4:34; 17:13; 1 Pét. 2:21) Hanne tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé ní ogójì [40] ọdún sọ pé, “Inú mi máa ń dùn lẹ́yìn tí mo bá dé láti òde ẹ̀rí, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó wù mí láti máa wàásù nìṣó.” Kò sí àní-àní pé ayọ̀ tá à ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù máa ń fún wa lókun, ìyẹn sì ń jẹ́ ká lè máa bá iṣẹ́ náà lọ kódà táwọn kan ò bá fẹ́ gbọ́ wa.​—Mát. 5:​10-12. w18.05 17 ¶2; 20 ¶14

Friday, March 27

A . . . yàn mí láti jẹ́ . . . olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ní ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.​—1 Tím. 2:7.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló fún àwọn ará níṣìírí jù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ẹ̀mí mímọ́ rán an pé kó lọ wàásù fáwọn Gíríìkì, àwọn ará Róòmù àtàwọn míì tó ń jọ́sìn ọlọ́run púpọ̀. (Gál. 2:​7-9) Pọ́ọ̀lù rìnrìn-àjò jákèjádò ilẹ̀ Gíríìsì, Ítálì àti ibi tá a wá mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí, ó ń wàásù, ó sì ń dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe Júù. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yìí “jìyà lọ́wọ́ àwọn ará ilẹ̀ ìbílẹ̀ [wọn]” torí náà, wọ́n nílò ìṣírí. (1 Tẹs. 2:14) Nígbà tó di nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tuntun tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín nínú àwọn àdúrà wa, nítorí láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín.” (1 Tẹs. 1:​2, 3) Ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa fún ara wọn níṣìírí, ó ní: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró lẹ́nì kìíní-kejì.”​—1 Tẹs. 5:11. w18.04 18-19 ¶16-17

Saturday, March 28

A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà.​—Máàkù 13:10.

Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ Jèhófà lò ń fayé rẹ ṣe, á máa wù ẹ́ láti sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn èèyàn. Níwọ̀n bí iṣẹ́ ìwàásù ti jẹ́ kánjúkánjú, òun ló yẹ kó gbawájú láyé wa. Torí náà, ṣé o lè ṣètò ara rẹ lọ́nà tí wàá fi túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà? Àmọ́ tó bá jẹ́ pé o kì í gbádùn iṣẹ́ ìwàásù ńkọ́? Kí lo lè ṣe? Ohun méjì yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́: Àkọ́kọ́, máa múra sílẹ̀ dáadáa. Ìkejì, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayọ̀ tí wàá rí á kọjá àfẹnusọ. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í múra bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn ọmọléèwé rẹ sábà máa ń béèrè. Ọ̀kan lára ìbéèrè tí wọ́n lè bi ẹ́ ni, “Kí ló mú kó o gbà pé Ọlọ́run wà?” Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tá a dìídì ṣe fún ẹ̀yin ọ̀dọ́, àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa mú kó o lè dáhùn ìbéèrè yẹn. Lọ́wọ́ ìsàlẹ̀, wàá rí “Ìwé Àjákọ fún Àwọn Ọ̀dọ́.” Ọ̀kan lára àwọn ìwé àjákọ yìí ní àkọlé náà “Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbà Pé Ọlọ́run Wà?” Ìwé àjákọ náà máa jẹ́ kó o lè wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. w18.04 27 ¶10-11

Sunday, March 29

Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀.​—Jẹ́n. 1:28.

Lóòótọ́ Ádámù àti Éfà lómìnira, síbẹ̀ ó níbi tí òmìnira wọn mọ. Bí Ọlọ́run ṣe dá wọn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà táwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mọ̀ pé táwọn bá máa wà láàyè àwọn gbọ́dọ̀ máa mí, káwọn máa jẹun, káwọn máa sùn, káwọn sì máa ṣe àwọn nǹkan míì. Àmọ́ ṣé wọ́n á ka àwọn nǹkan yẹn sí ìnira? Rárá o, torí Jèhófà ti dá wọn lọ́nà táá mú kí wọ́n gbádùn àwọn nǹkan yẹn. (Sm. 104:​14, 15; Oníw. 3:​12, 13) Jèhófà dìídì pàṣẹ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n fi àwọn ọmọ wọn kún ayé kí wọ́n sì máa bójú tó ilẹ̀ ayé. Ṣé àṣẹ yìí ká wọn lọ́wọ́ kò ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìdí tí Ọlọ́run fi pàṣẹ yìí ni pé ó fẹ́ káwa èèyàn náà lọ́wọ́ nínú mímú ohun tó ní lọ́kàn fáráyé ṣẹ, ìyẹn sì ni pé kí ilẹ̀ ayé di Párádísè níbi tí àwọn èèyàn pípé á máa gbé títí láé. (Sm. 127:3; Aísá. 45:18) Èyí fi hàn pé títí láé ni Ádámù àti Éfà ì bá fi máa gbádùn ìgbéyàwó wọn. w18.04 4-5 ¶7-8

Monday, March 30

Gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun sì di onígbàgbọ́.​—Ìṣe 13:48.

Tá a bá ń mú sùúrù fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, a ò ní retí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè ṣàlàyé fún ẹnì kan pé àwa èèyàn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ òtítọ́ yìí, wọ́n lè rò pé téèyàn bá ti kú, ó parí nìyẹn. Àwọn míì sì rò pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run. Arákùnrin kan sọ bó ṣe máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti ṣàlàyé kókó yìí. Á kọ́kọ́ ka Jẹ́nẹ́sísì 1:​28, á wá bi onílé pé ibo ni Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn máa gbé, báwo ló sì ṣe fẹ́ kí ìgbésí ayé wa rí. Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé, “Ó fẹ́ ká máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn ìyẹn, arákùnrin náà á ka Àìsáyà 55:​11, á wá bi onílé bóyá ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ti yí pa dà. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á dáhùn pé rárá. Paríparí ẹ̀, arákùnrin náà á ka Sáàmù 37:​10, 11, á sì bi onílé pé báwo ni nǹkan ṣe máa rí fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Bó ṣe ń lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà yìí ti mú kó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti rí i pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn rere gbádùn títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. w19.03 24 ¶14-15; 25 ¶19

Tuesday, March 31

Ẹ fetí sí i.​—Mát. 17:5.

Ó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa fetí sí Ọmọ òun, ká sì máa ṣègbọràn sí i. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, léraléra ló sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wà lójúfò. (Mát. 24:42; 28:​19, 20) Ó tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa sa gbogbo ipá wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn. (Lúùkù 13:24) Jésù tẹnu mọ́ ọn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì máa pa àṣẹ òun mọ́. (Jòh. 15:​10, 12, 13) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wúlò gan-an! Bó ṣe wúlò nígbà yẹn náà ló ṣe wúlò títí dòní. Jésù sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” (Jòh. 18:37) A lè fi hàn pé à ń fetí sí ohùn Jésù tá a bá ń ‘fara dà á fún ara wa, tá a sì ń dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Kól. 3:13; Lúùkù 17:​3, 4) Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé à ń fetí sí Jésù ni pé ká máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní àkókò tó rọrùn àti ní àkókò tí kò rọrùn.”​—2 Tím. 4:2. w19.03 10 ¶9-10

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́